Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Atẹ̀lé Ọmọ-Aládé Àláfíà.
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


Àwọn Atẹ̀lé Ọmọ-Aládé Àláfíà.

Bí a ti ntiraka láti mú àwọn ìhùwàsí bíi ti Olùgbàlà dàgbà, a le di àwọn ohun èlò ti àláfíà Rẹ̀ nínú ayé.

Ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tí a fifún Sekaríà,1 Jésù wọ Ìlú Mímọ́ náà bíi aṣẹ́gun ní gígun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, èyítí, nínú ìwé ìtàn litíréṣọ̀, a kà sí àmì àtijọ́ ti ilé ọba àwọn Júù,”2 bí ó ti yẹ Ọba àwọn ọba àti Ọmọ-Aládé Àlãfíà.3 Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ aláyọ̀ àwọn ọmọẹ̀hìn tí wọ́n tẹ́ aṣọ wọn ni ó yiká pẹ̀lú, màrìwò ọ̀pẹ, àti ewé míràn sílẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà ibití Jésù gbà kọjá. Wọ́n yin Ọlọ́run, wọ́n nsọ pẹ̀lú ohùn rara pé, “Alábùkún ni Ọba tí ó nbọ̀ wá ní orúkọ Olúwa: àláfíà, àti ògo lókè ọ̀run.”4 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, “Hòsánnà sí Ọmọ Dáfídì: Ìbùkún ni fún ẹni náà tí nbọ̀wá ní orúkọ Olúwa; Hòsánnà ní ibi gíga jùlọ.”5 Ìṣẹ̀lẹ̀ ọlọ́lá yí, èyí tí a nṣe àjọyọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ yí tí a mọ̀ sí Ọjọ́ Ìsinmi Ọpẹ, jẹ́ ohun aláyọ̀ ìṣáajú sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ onírora tí yío wáyé láàrin ọ̀sẹ̀ búburú náà ní píparí sí ìrúbọ àìmọtaraẹni Olùgbàlà àti ìyanu nlá ti ibojì tó ṣófo.

Àwa bíi atẹ̀lé Rẹ̀, a jẹ́ ènìyàn Rẹ̀ ọ̀tọ̀, tí a pè láti kéde àwọn ìwà rere Rẹ̀,6 akéde àláfíà náà tí a fi inúrere tó bẹ́ẹ̀ fifúnni nípasẹ̀ Òun àti ẹbọ ètùtù Rẹ̀. Àláfíà yi ni ẹ̀bùn kan tí a ṣèlérí fún gbogbo ẹnití ó bá yí ọkàn wọn sí Olùgbàlà tí wọ́n sì gbé pẹ̀lú òdodo; irú àláfíà bẹ́ẹ̀ nfún wa ní okun láti gbádùn ayé kíkú ó sì nmú kí ó ṣeéṣe fúnwa láti faradà àwọn àdánwò onírora ti ìrìn àjò wa.

Ní 1847, Olúwa fi àwọn ìkọ́ni pàtó kan fún Àwọn Ènìyàn Mímọ́ aṣaájú, tí wọ́n nílò àlàáfíà láti dúró jẹ́ẹ́ àti ní ìṣọ̀kan bí wọ́n ti dojúkọ àwọn ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀ nínú ìrìn àjò wọn sí ìhà ìwọ̀-oòrùn. Láàrin àwọn ohun mĩràn, Olúwa pàṣẹ fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ náà láti “dáwọ́ ìjà dúró ọ̀kan pẹ̀lú ẹlòmíràn; dáwọ́ dúró lati sọ̀rọ̀ ibi ọ̀kan nípa ẹlòmíràn.”7 Àwọn ìwé mímọ́ fi múlẹ̀ pé àwọn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ òdodo tí wọ́n sì tiraka láti rìn nínú ìwà pẹ̀lẹ́ ti Ẹmí Olúwa ni a ṣe ìlérí àláfíà fún tí wọ́n nílò láti rẹ́hìn àwọn ọjọ́ ìdàrúdàpọ̀ nínú èyí tí a ngbé lóni.8

Bíi ọmọ-ẹ̀hìn ti Ọmọ-Aládé Àláfíà, a ti kọ́wa láti gbé pẹ̀lú “ọkàn tí a hun papọ̀ nínú ìṣọ̀kan àti nínú ìfẹ́ ọ̀kan sí ẹlòmíràn.”9 Wòlíì wa àyànfẹ́, Ààrẹ Russell M. Nelson, sọ ní àìpẹ́ yí pé, “Ìjà ṣe àìbọ̀wọ̀ fún ohun gbogbo tí Olùgbàlà dúró fún àti tí Ó kọ́ni.”10 Wòlíì wa bẹ̀bẹ̀ bákannáà pé kí a ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti parí àwọn ìjà araẹni tí ó njà nínú ọkàn wa àti nínu ìgbé ayé wa.”11

Ẹ jẹ́kí á gbèrò àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí ní wíwo ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ ti Krístì ní fún wa àti tí àwa, bíi atẹ̀lé Rẹ̀, nlépa láti ní fún ọmọnìkejì wa. Ìwé mímọ́ ṣe ìtumọ̀ irú ìfẹ́ yìí bíi ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́.12 Nígbàtí a bá rò nípa ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, iyè wa máa nsáábà yí sí àwọn iṣe inúrere àti àwọn ìpèsè ẹ̀bùn láti ṣe ìmúfúyẹ́ ìjìyà àwọn tí wọ́n nní ìrírí àwọn ìṣòro àfojúrí, ti ohun èlò, tàbí ti ẹ̀dùn ọkàn. Síbẹ̀, ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ kò ní í ṣe sí ohun kan tí a pèsè fún ẹlòmíràn nìkan, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìhùwàsí ti Olùgbàlà ó sì le di apákan ìwà tiwa. Kò jẹ́ ohun pé Olúwa kọ́ wa láti wọ ara wa ní aṣọ pẹ̀lú ìdè ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, èyítí ó jẹ́ ìdè jíjẹ́ pípé àti àláfíà.”13 Láìsí ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, a kò jẹ́ nkankan,14 a kò sì le jogún ààyè tí Olúwa ti pèsè fún wa nínú àwọn ibùgbé ti Baba wa Ọ̀run.15

Jésù fi àpẹrẹ hàn ní pìpè ohun tí ó túmọ̀ sí láti ní ìdè jíjẹ́ pípé àti àláfíà, pàápàá nígbàtí Ó ndojúkọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ onírora tí ó ṣíwájú ikú ajẹ́rĩkú Rẹ̀. Ẹ ronú fún ìgbà díẹ̀ nípa ohun tí Jésù le ti mọ̀lára bí Ó ti nfi ìrẹ̀lẹ̀ wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀, ní mímọ̀ pé ọ̀kan ninú wọn yío fi Òun hàn ní òru náà gan-an.16 Tàbí nígbàtí Jésù, ní àwọn wákàtí lẹ́hìnwá, fi tàánú-tàánú ṣe ìwòsàn etí ọ̀kan lára àwọn ènìyàn tí wọ́n tẹ̀lé Júdásì, olùfihàn Rẹ̀, láti mú Un.17 Tàbí àní nígbàtí Olùgbàlà, bí Ó ti ndúró níwájú Pílátù, di fífi ẹ̀sùn kàn láìyẹ nípasẹ̀ àwọn àlùfáà àgbà àti àwọn alàgbà, tí Òun kò sì sọ ọ̀rọ̀ kan tako àwọn ẹ̀sùn irọ́ náà tí wọ́n fi kojú Rẹ̀, Ó sì fi gómìnà Romù náà sílẹ̀ ní yíyàlẹ́nu.18

Nípasẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú mẹ́ta wọ̀nyí, Olùgbàlà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ó ndààmú pẹ̀lú ìpọ̀jú ìbànújẹ́ àti àárẹ̀, kọ́ wa nípa àpẹrẹ Rẹ̀ pé “ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ nfi ara dà pẹ́, ó sì ní àánú; … kìí ṣe ìlara; … kìí gbé ara rẹ̀ ga, kìí fẹ̀, kìí hùwà àìtọ́, kìí wá ohun ti ara rẹ̀, a kìí múu bínú, [bẹ́ẹ̀ni] kìí gbìrò ohun búburú.”19

Abala pàtàkì mĩràn láti tẹnumọ́ àti ọ̀kan tó ní àwọn àyọrísí tààrà lórí jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn wa àti bí a ti le polongo àláfíà ti Olùgbàlà, ni bí a ti nṣe sí ọmọnìkejì wa. Ní àkókò iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ìkọ́ni Olùgbàlà fojúsùn, kìí ṣe ìwọnyí nìkan, ṣùgbọ́n ní pàtó, lórí àwọn ìwà rere ti ìfẹ́, ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, sùúrù, ìrẹ̀lẹ̀, àti ìyọ́nú—àwọn ìhùwàsí ìpìlẹ̀ sí àwọn ẹnití wọ́n fẹ́ di sísúnmọ́ sí Òun síi kí wọn ó sì polongo àláfíà Rẹ̀. Irú àwọn ìhùwàsí bẹ́ẹ̀ jẹ́ àwọn ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bí a sì ti ntiraka láti mú wọn dàgbà, a ó bẹ̀rẹ̀ sí rí àwọn ìyàtọ̀ àti àwọn àìlera aládũgbò wa pẹ̀lú ìkãnú, ìmọ̀lára, ìtẹríba, àti ìfaradà. Ọkan lára àwọn àmì to nfihàn pé a nsún mọ́ Olùgbàlà síi a sì ndàbí Rẹ̀ síi ni ìfẹ́ni, sùúrù, àti ọ̀nà rere pẹ̀lú èyítí a fi nbá àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa ṣe, ní èyíkéyí àwọn ipò.

A nfi ìgbà pùpọ̀ rí àwọn ènìyàn tí wọn nkópa nínú àwọn ọ̀rọ̀ òdì àti ti àbùkù pàápàá nípa àwọn ìwà, àwọn àìlera, àti èrò inú àwọn ẹlòmíràn, nípàtàkì nígbàtí irú àwọn ìwà àti èrò inú bẹ́ẹ̀ bá yàtọ̀ tàbí tako bí àwọn ti nṣe tàbí ronú. Ó wọ́pọ̀ gan-an láti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní sísọ irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ sí àwọn ẹlòmíràn, àwọn ẹnití wọ́n kan nṣe àtúnsọ ohun tí wọ́n gbọ́ láì mọ gbogbo àwọn ipò tó yí nkan náà ká ní tòótọ́. Pẹ̀lú ẹ̀dùn, ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn nṣe àtìlẹ́hìn fún irú ìhùwàsí yí ní orúkọ pé ó fẹ́ bá àwọn òtítọ́ jọ àti àkóyawọ́. Láì pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ, àwọn ìbánisọ̀rọ̀ ìgbàlódé nfi ọ̀pọ̀ ìgbà darí àwọn ènìyàn sí àwọn àtakò ara ẹni àti àwọn ìjà líle, tó nṣe ìdásílẹ̀ àwọn ìjákulẹ̀, àwọn ọgbẹ́ ọkàn, àti ìtànkálẹ̀ ìbínú gbígbóná.

Néfì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn, ọ̀tá yío gbógun yío sì rú àwọn ènìyàn sókè sí ìbínú tako ohun tí ó jẹ́ rere.20 Àwọn ìwé mímọ́ kọ́ni pé “ohunkohun tí ó bá npe àti tí ó nfanimọ́ra láti ṣe rere, àti láti fẹ́ràn Ọlọ́run, àti láti sìn Ín, jẹ́ ìmísí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”21 Ní ọ̀nà kejì, “èyítí ó sì jẹ́ búburú wá láti ọ̀dọ̀ èṣù; nítorítí èṣù jẹ ọ̀tá sí Ọlọ́run, a sì mã bá a jà títí, a sì mã pèni àti fani láti ṣẹ̀ àti láti ṣe èyítí ó burú títí.”22

Ní gbígbèrò ìkọ́ni ti wòlíì yí, kò jẹ́ ohun tó yani lẹ́nu pé ọ̀kan nínú àwọn ètò ọ̀tá ní láti rú ìṣọ̀tá àti ìkóríra sókè nínú ọkàn àwọn ọmọ Ọlọ́run. Ó máa nyọ̀ nígbàtí ó bá rí àwọn ènìyàn tí wọ́n nbaniwí, nṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì nba ara wọn jẹ́. Ìhùwàsí yí le ba ìwà, orúkọ rere, àti ìgbẹ́kẹ̀lé araẹni, nípàtàkì nígbàtí wọ́n bá dá ẹni náà lẹ́jọ́ ní àìdára tó. Ó ṣe pàtàkì láti tọ́ka rẹ̀ jádé pé nígbàtí a bá fi ààyè gba irú ìṣesí yi nínú ìgbé ayé wa, a nfi ààye sílẹ̀ nínú ọ̀kan wa fún ọ̀tá láti gbin èso àìgbọ́-araẹni-yé ní ààrin wa, ní wíwu èwu síṣubú sínú panpẹ́ ijẹkújẹ rẹ̀.

Bí a kò bá ṣọ́ra pẹ̀lú àwọn èrò, àwọn ọ̀rọ̀, àti àwọn ìṣe wa, a le pári sí jíjẹ́ dídojúrú nípa ẹ̀tàn àrékérekè ọ̀tá, ní pípa àwọn ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní àyíká àti àwọn olólùfẹ́ wa run.

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin, àwa bíi ènìyàn ọ̀tọ̀ ti Olúwa àti alátilẹhìn àlàáfíà Rẹ̀, a kò le fi ààyè gbà láti jẹ́kí àwọn ẹ̀tàn ẹni ibi náà láti ní ààyè nínú ọkàn wa. A kò le gbé irú ẹrù olóró bẹ́ẹ̀ èyítí ó npa àwọn ìmọ̀lára, àwọn ìbáṣepọ̀, àti àwọn ìgbé ayé papàá run. Ìhìnrere dúró fún ìròhìn rere ti ayọ nlá.

Ní tòótọ́, kò sí ọ̀kankan nínú wa tí ó pé, àti dájúdájú, àwọn ìgbà kan wà nígbàtí a njẹ́ títànjẹ sínú irú ìwà yí. Nínú pípé ìfẹ́ Rẹ̀ àti ìmọ̀ ohun gbogbo ti àwọn ìtẹ̀sí àwa ẹ̀dá ènìyàn, Olùgbàlà máa nfi ìgbà gbogbo gbìyànjú láti kìlọ̀ fúnwa nípa irú àwọn ewu bẹ́ẹ̀. Ó kọ́ni pé, “Nítorí pẹ̀lú irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá dá, ni ẹ̀yin yío di dídá lẹ́jọ́: àti pẹ̀lú irú òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ̀n, òun ni á ó tún fi wọ̀n fún yín.”23

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin mi, bí a ti ntiraka láti mú àwọn ìhùwàsí bíi ti Krístì dàgbà, a le di àwọn ohun èlò ti àláfíà Rẹ̀ nínú ayé ní ìbámu sí àpẹrẹ tí Òun Fúnrarẹ̀ fi lélẹ̀. Mo pè yín láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí a le fi yí ara wa padà sí agbéniga àti alátilẹ́hìn ènìyàn, ènìyàn tí ó ní ọkàn níní òye àti dídáríjì, ènìyàn tí ó máa nwò fún èyítí ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlòmíràn, tí o máa nrántí nígbà gbogbo pé “bí ohunkóhun bá jẹ́ ìwà rere, yẹ ní fífẹ́, tàbí ti ìhìn rere tàbí yẹ fún yíyìn, àwa nlépa àwọn ohun wọ̀nyí.”24

Moṣe ìlérí fún yín pé bí a ti nlépa tí a sì nmú àwọn ìhùwàsí wọ̀nyí dàgbà, a ó di ọ̀rẹ́ a ó sì ní ìfura síi àti díẹ̀ síi sí àwọn àìní àwọn ènìyàn ẹlẹ́gbẹ́ wa25 a ó sì ní ìrírí ayọ̀, àláfíà, àti ìdàgbà ti ẹ̀mí.26 Láìṣiyèméjì, Olúwa yío dá àwọn aápọn wa mọ̀ yío sì fún wa ní àwọn ẹ̀bùn tí a nílò láti jẹ́ onípamọ́ra àti onísùúrù síi pẹ̀lú àwọn ìyàtọ̀, àwọn àìlera, àti àwọn àìpé ara wa. Síwájú síi, yíó ṣeéṣe fúnwa síi láti tako ìfẹ́ inú láti máa mú àṣìṣe tàbí láti máa mú inú bí àwọn tí wọ́n bá pa wá lára. Ìfẹ́ wa láti dáríjì, bí Olùgbàlà ti ṣe, sí àwọn tí wọ́n ṣe àìdára sí wá tàbí tí wọ́n sọ̀rọ̀ ibi nípa wa yíó pọ̀ síi dájúdájú yío sì di apákan ìwà wa.

Njẹ́ lóni, ní Ọjọ́ Ìsinmi Ọpẹ yi, kí a le ta àwọn ẹ̀wù ìfẹ́ wa àti àwọn imọ̀ ọ̀pẹ ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ sí òde, ní rírìn nínú àwọn ojú ẹ̀sẹ̀ ti Ọmọ-Aládé Àlãfíà náà bí a ti nmúra láti ṣe àjọyọ̀ ìyanu ti ibojì òfìfo ní Ọjọ́ Ìsinmi tó nbọ̀ yí. Bí arákùnrin àti arábìnrin nínú Krístì, ẹ jẹ́kí a fi tayọ̀tayọ̀ kéde pé, “Hòsánnà sí Ọmọ Dáfídì: Ìbùkún ni fún ẹni náà tí nbọ̀wá ní orúkọ Olúwa; Hòsánnà ní ibi gíga jùlọ.”27

Mó jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù Krístì wà láàyè àti pé ìfẹ́ pípé Rẹ̀, tí a fihàn nípasẹ̀ ètùtù Rẹ̀, jẹ́ nínà sí gbogbo ẹnití ó bá ní ìfẹ́ inú láti rìn pẹ̀lú Rẹ̀ kí wọn ó sì gbádùn àláfíà nínú ayé yí àti ní ayé tí nbọ̀. Mo sọ àwọn nkan wọ̀nyí ní orúkọ mímọ́ ti Olùgbàlà àti Olùràrapà náà, Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀