Hòsánnà sí Ọlọ́run Gíga Jùlọ
Jésù Krístì fi ìṣẹ́gun wọ Jerusalem àti pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti ọ̀sẹ̀ náà tí ó tẹ̀lé jẹ́ àpẹrẹ ẹ̀kọ́ tí a lè lò nínú ayé wa ní òní.
Ní òní, bí a ti wi, à ndarapọ̀ mọ́ àwọn onígbàgbọ́ káàkiri àgbáyé láti buọlá fún Jésù Krístì ní Ọjọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ yí. Ní bíi ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́hìn, Ọjọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ fi àmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ ìkẹhìn ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé ikú Jésù Krístì. Ó jẹ́ pàtàkì jùlọ nínú àkọọ́lẹ̀-ìtàn ènìyàn.
Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ kíkéde Jésù Krístì tí a ṣe ìlérí ní ìsẹ́gun wíwọ inú Jerusalem Rẹ̀ ní sísúnmọ́ ìkànmọ́ àgbélèbú àti Àjínde Rẹ̀.1 Nípa àwòṣe tọ̀run, Ètùtù Ìrúbọ Rẹ̀ parí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé ikú Rẹ̀, ó sì mu ṣeéṣe fún wa láti gbé pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run fún àìlópin.
Àwọn ìwé mímọ́ sọ fún wa pé ọ̀sẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èrò tí wọ́n dúró ní ẹnu ọ̀nà ìlú láti rí “Jésù wòlíì ti Nazareth Galilee.”2 Wọ́n “mú ẹ̀ka igi màrìwò ọ̀pẹ, wọ́n sì lọ síwájú láti pàdé rẹ̀, wọ́n sì nké: Hòsánnà: Alábùkún ni Ọbá Ísráẹ́lì tí ó nbọ̀ ní orúkọ Olúwa.”3
Àkọsílẹ̀ ti Bíbélì náà tí ó ti pẹ́ gan rán mi létí wíwà ní yíyàn síṣẹ́ Ìjọ ní Takoradi, Ghana. Pẹ̀lú ìyanu, mo wà níbẹ̀ ní Ọjọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ.
Mo níláti pín Èèkàn Takoradi Ghana láti dá Èèkàn Mpintsin Ghana sílẹ̀. Ní òní, àwọn ọmọ Ìjọ ẹgbẹ̀rún ọgọ́ọ̀rún kan ni ó wà ní Ghana.4 (A kí ẹni-ọ̀wọ́ Ọlọ́lá jùlọ Ọba Nii Tackie Teiko Tsuru II ti Accra, Ghana, ẹnití ó wà pẹ̀lú wa lóni.) Ní pípàdé àwọn Ènìyàn Mímọ́ wọ̀nyí, mo ní ìmọ̀lára ìfẹ́ ìjìnlẹ̀ àti ìfọkànsìn wọn sí Olúwa. Mo fi ìfẹ́ títóbi mi hàn fún wọn àti pé Ààrẹ Ìjọ fẹ́ràn wọn. Mo tọ́ka sí àwọn ọ̀rọ̀ Olùgbàlà tí a kọsílẹ̀ láti ọwọ́ Jòhánù: “Kí ẹ fẹ́ràn ara yín, bi èmi ti fẹ́ràn yín.”5 Wọ́n sọ ọ́ di “Mo fẹ́ràn ìpàdé àpapọ̀.”6
Bí mo ti nwòkè àti ilẹ̀ àwọn ìlà ti àwọn arákùnrin àti aràbìnrin àti ẹbí wọn nínú ilé ìjọsìn, mo lè rí dídán ẹ̀rí àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì ní ojú wọn. Mo ní ìmọ̀lára ìfẹ́ wọn láti jẹ́ ara ìlọsíwájú Ìjọ Rẹ. Àti pé nígbàtí àwọn akọrin nkọrin wọ́n kọrin bí àwọn ángẹ́lì.
Bíi Ọjọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ àtijọ́, ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì tí wọ́n kórajọ láti gbé oríyìn fún Un bí àwọn wọnnì ní ẹnu ọ̀nà Jerusalem ti ṣe tí wọ́n wà, pẹ̀lú màrìwò ọ̀pẹ ní ọwọ́ wọn, kígbe, “Hòsánnà … : Alábùkún ni ẹni tí ó nbọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.”7
Àní àwọn òṣìṣẹ́ nínú ìjọ ni wọ́n nbu ọlá fún Ọjọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ. Bí mo ti nsọ̀rọ̀ láti orí pẹpẹ, mo ní àkíyèsí láti ojú fèrèsé tí wọ́n nfi tayọtayọ rìn lọ sí pópónà tí wọn nju màrìwò ọ̀pẹ ní ọwọ́ wọn sókè, ní púpọ̀ bí àwọn tí ó wà nínú fọ́tò yí Ó jẹ́ ìwò kan tí èmi kò ní gbàgbé láéláé—gbogbo wa ní ọjọ́ náà wà níjíjọ́sìn Ọba àwọn Ọba.
Ààrẹ Russell M. Nelson ti kìlọ̀ fún wa láti mú Ọjọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ jẹ́ “mímọ́ nítòótọ́ nípa rírántí, kìí ṣe àwọn màrìwò tí à njùsókè láti buọlá fún wíwọlé Jésù sí Jerusalem nìkan, ṣùgbọ́n nípa rírántí àwọn àtẹ́lẹwọ́ ti ọwọ́ Rẹ̀.” Nígbànáà Ààrẹ Nelson tọ́ka sí Isaiah, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ nípa Olùgbàlà tí ó ṣe ìlérí pé, “Èmi kò ní gbàgbé yín láéláé,”pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Kíyèsi, mo ti gbé yín lé orí àtẹ́lẹwọ́ ọwọ́ mi.”8
Olúwa mọ̀ ní àkọ́kọ́ pe ayé ikú le. Àwọn àpá Rẹ̀ rán wa léti pé Òun ti “sọ̀kalẹ̀ kọjá … ohun gbogbo”9 kí Òun lè tù wá nínú nígbàtí a bá njìyà kí ó sì jẹ́ àpẹrẹ wa láti “dúró ní ọ̀nà rẹ,”10 Ọ̀nà Rẹ̀, kí “Ọlọ́run lè wà pẹ̀lú [wa] títíláé àti láéláé.”11
Ọjọ́ Ìsìnmi Ọ̀pẹ kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ nìkan, ojú ewé míràn nínú àkọọ́lẹ̀-ìtàn pẹ̀lú ọjọ́ kan, àkokò àti ibìkan ni. Jésù Krístì fi ẹ̀yẹ wọnú Jerusalem àti pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti ọ̀sẹ̀ náà tí ó tẹ̀lé e jẹ́ àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ tí a lè lò nínú ayé wa lónìí.
Ẹ jẹ́ kí a wo àwọn ẹ̀kọ́ ayérayé kan tí ó wémọ́ ìparí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní Jerúsálẹ́mù.
Àkọ́kọ́, àsọtẹ́lẹ̀. Fún àpẹrẹ, wòlíì Zechariah sọtẹ́lẹ̀ nípa fífi ẹ̀yẹ̀ wọ̀nú Jésúsálẹ́mù Jésù Krístì, àní jíjúwe pé Òun yíò gun orí dọ́nkì.12 Jésù sọ̀rọ̀ Àjínde Rẹ̀ síwájú bí Ó ti múrasílẹ̀ láti wọnú ìlú, ó wípé:
“Kíyèsi, à nlọ sí Jérúsálẹ́mù; a ó sẹ́ Ọmọ ènìyàn sí àwọn àlùfáà àti àwọn agbowóde, wọn ó sì da lẹ́bi ikú.
“Wọn ó sì fi lé àwọn Gentile lọ́wọ́ láti kẹ́gàn, àti láti kàn án mọ́ àgbélèbú: ós ì jí dìde ní ọjọ́ kẹ́ta, .”13
Ìkejì, olùbárin Ẹ̀mí Mímọ́. Joseph Smith kọ́ni pé, “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè mọ̀ pé Jésù ni Olúwa, bíkòṣe nípa Ẹ̀mí Mímọ́.”14 Olùgbàlà ṣe ìlérí fún àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ pé15 ní bi Oúnjẹ Alẹ́ Ìkẹhìn16 ní yàrá òke,17 “Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láé ní ìtùnú.”18 Wọn kò ní dánìkan wà láti gbé àwọn òtítọ́ ìhìnrere síwájú ṣùgbọ́n wọn ìbá ti ní àṣepé ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ láti tọ́ wọn sọ́nà. “Àláfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín, àláfíà mi ni mo fún yín,” Ó ṣe ìlérí; “kìí ṣe bí ayé ti í funni, ni èmi fi fún yín.”19 Pẹ̀lú ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ a ní irú ìdánilójú kannáà—pé a “lè ní Ẹ̀mí rẹ̀ pẹ̀lú [wa] nígbàgbogbo”20 àti pé “nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́ [a] lè mọ òtítọ́ ohun gbogbo.”21
Ìkẹ́ta, jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn. Jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn tòótọ́ ni ìfaramọ́ àìkùnà, ìgbọràn sí àwọn òfin ayérayé, àti ìfẹ́ Ọlọ̀run, àkọ́kọ́ àti ìṣíwájú jùlọ. Láì ṣiyèméjì. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn tí wọ́n gbé oríyìn pẹ̀lú màrìwò ọ̀pẹ yìn In bí Mesiah. Ìyẹn ni ẹni tí Òun jẹ́ gàn. Wọ̀n sún mọ́ Ọ, àwọn iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀, àti àwọn ìkọ́ni Rẹ̀. Ṣùgbọ́n ìpọ́nni fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò pẹ́. Àwọn kan tí wọ́n ti kígbe ṣíwájú, “Hosanna”22 láìpẹ́ yípadà wọ́n sì ké pé, “Kàn án mọ́ àgbélèbú.”23
Ìkẹ́rin, Ètùtù Jésù Krístì.24 Ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn Rẹ̀, títẹ̀lé Ọjọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ, Ó gbé Ètùtù olókìkì Rẹ̀ jáde, látinú ìrora Gethsemane sí ẹ̀sín àdánwò Rẹ̀, ìpalára Rẹ̀ lórí àgbélèbú, àti ìsìnkú Rẹ̀ ní ìsà-òkú yíyá. Ṣùgbọ́n kò dúró níbẹ̀. Pẹ̀lú ìpè ọlọ́lá Rẹ̀ bí Olùràpadà gbogbo àwọn ọmọ Baba Ọ̀run, ọjọ́ mẹ́ta lẹ́hìnnáà Ó jáde wá látinú isà-òkú náà, ó jínde,25 bí Ó ti sọtẹ́lẹ̀.
Ṣé à nfi ìmoore hàn lóòrèkóòrè fún Ètùtù àìláfiwé ti Jésù Krístì? Njẹ́ a ní ìmọ̀lára ti agbára ìyàsímímọ́ rẹ, báyìí nísisìyí? Iyẹn ni ìdí tí Jésù Krístì, Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti Aláṣetán Ìgbàlà wa, fi lọ sí Jérúsálẹ́mù, láti gba gbogbo wa la. Njẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nínú Álmà gún ni: “Bí ẹ̀yin bá ti rí ìyípadà ọkàn, tí ẹ̀yin bá sì fẹ́ láti kọ orin ìfẹ́ ti ìràpadà, mo bẽrè, ṣé ẹ̀yin lè ṣe bẹ̃ nísisìyí?”26 Mo lè sọ nítòótọ́, akọrin ní Takoradi ní Ọjọ́ ìsinmi Ọ̀pẹ ti kọ ”orin ìfẹ́ ìràpadà.”
Ní ọ̀sẹ tí ó kẹ́hìn ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé ikú Rẹ̀, Jésù Krístì fúnni ní òwe àwọn wúndíá mẹwa.27 Ó kọ́ni nípa ìpadàbọ̀ Rẹ̀ sí àwọn wọnnì tí wọ́n múrasílẹ láti gbà Á, kìí ṣe pẹ̀lú màrìwò ọ̀pẹ ní ọwọ́ wọn ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere nínú wọn. Ó lo àwòrán ti fìtílà tí a tàn tí ó sì njó, pẹ̀lú òróró ṣíṣẹ́kù láti mu jó, bí ìjúwe ti ìfẹ́ láti gbé ní ọ̀nà Rẹ̀, gba òtítọ́ Rẹ̀ mọ́ra, àti pín ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀.
Ẹ mọ ìtàn náà. Àwọn wúndíà mẹwa ṣojú àwọn ọmọ Ìjọ, àti ọkọ ìyàwó ṣojú Jésù Krístì.
Àwọn wúndíà mẹwa gbé fìtílà wọn wọ́n sì “lọ síwájú láti pàdé ọkọ-ìyàwó.”28 Marun jẹ́ ọlọgbọ́n, wọ́n múrasílẹ̀ pẹ̀lú òróró nínú fìtílà àti díẹ̀ láti tọrẹ, àti pé marun jẹ́ aláìgbọ́n, fìtílà kú láìsí òróró ní ìpamọ́. Nígbatí ìpè wá, “Kíyèsi, ọkọ-ìyàwó dé; ẹ jáde kí ẹ lọ í pàdé rẹ̀,”29 àwọn marun tí wọ́n “gbọ́n tí wọ́n sì [ti] gba òtítọ́, tí wọ́n sì [ti] gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí atọ́nà wọn”30 ti ṣetán fún “ọba wọn àti aṣòfin wọn,”31 pé “ògo rẹ̀ [yíò] wà lórí wọn.”32 Àwọn marun míràn ngbìyànjú tipátipá láti rí òróró. Ṣùgbọ́n ó ti pẹ́ jù. Ìrìn náà lọ síwáju láìsí i wọn. Nígbàtí wọ́n kànkù tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ fún wíwọlé, Olúwa fèsì pé “Èmi kò mọ̀ yín.”33
Báwo ni a ó ṣe ní ìmọ̀lára bí Òun bá wí fún wa pé, “Èmi kò mọ̀ yín!”
Àwa, bíi ti wúndíà mẹwa, ní fìtílà; ṣùgbọ́n njẹ́ a ní òróró? Mo bẹ̀rù pé àwọn kan tí wọ́n kàn ngbáyé ní etí orí òróró tíntín, wọn kò ráyè nítorí àwọn ìgbádùn ti ayé kò jẹ́ kí wọ́n múra dáradára Òróró nwá látinú gbígbàgbọ́ àti ṣíṣe ìṣe lórí àsọtẹ́lẹ̀ àti ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì alààyè, Ààrẹ Nelson ní pàtàkì, àwọn Olùdámọ̀ràn rẹ̀, àti àwọn Àpóstélì Méjìlá. Òróró nkún inú ẹ̀mí wa nígbàtí a bá gbọ́ tí a sì ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí Mímọ́ àti ìṣe lórí ìtọ́sọ́nà tọ̀run. Òróró ndà sínú ọkàn wa nígbàtí àwọn àṣàyàn wa ba fihàn pé a ní ìfẹ́ Olúwa kí a sì fẹ́ràn ohun tí Ó fẹ́ràn. Òróró nwá látinú ìrònúpìwàdà àti wíwá ìwòsàn ti Ètùtù Jésù Krístì.
Bí ẹ bá nwá láti kún inú ohun tí àwọn kan pè ní “ìtò garawa kan,” èyí ni kí: Ẹ kún garawa yín pẹ̀lú òróró ní àwòrán ti omi ìyè Jésù Krístì,34 èyí ni aṣojú ìgbé ayé àti ìkọ́ni Rẹ̀. Ní ìlòdì, fífi àmì sí ibi jíjìnréré tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ híhàn tí kò ní fi ìmọ̀lára ẹ̀mí yín sílẹ̀ lódidi tàbí ìtẹlọ́run láé; gbígbé ẹ̀kọ́ tí a kọ́ni láti ẹnu Jésù Krístì yíò ṣe. Mo dárúkọ wọn ṣíwájú: ẹ rọ̀mọ́ àsọtẹ́lẹ̀ àti àwọn ìkọ́ni ti wòlíì, ẹ ṣe ìṣe lórí àwọn ìṣíletí ti Ẹ̀mí Mímọ́, di ọmọẹ̀hìn tòótọ́, àti wíwá agbára ìwòsàn Ètùtù Olúwa wa. Ìtò garawa náà yíò gbé yín dé ibìkan tí ẹ fẹ́ láti lọ—padà sí ọ̀dọ̀ Baba ní Ọ̀run.
Ọjọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ́ náà ní Takoradi jẹ́ ìrírí pàtàkì gan fún mi nítorí tí mo pín in pẹ̀lú àwọn olotitọ ìjọ arákùnrin àti arábìnrin. Nítorínáà ó ti wà ní kọ́ntínẹ̀ntì àti àwọn erékùṣù kárí ayé. Ọkàn àti ẹ̀mí mi, bíi tiyín, nlọ́ra láti ké, “Hòsánnà sí Ọlọ́run Gíga Jùlọ.”35
Bíótilẹ̀jẹ́pé a kò dúró ní ẹnu ọ̀nà Jerusalem ní òní pẹ̀lú àwọn màrìwò ní ọwọ́ wa, àkokò náà yíò wá nígbàtí, bí a ti sọtẹ́lẹ̀ nínú Ìfihàn, “ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn púpọ̀, èyí tí ẹ̀nìkẹ́ni kò lè ka oye, gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè, àti ìdílé, àti ènìyàn, àti èdè, [yíò dìde] níwájú ìtẹ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-àgùtàn, tí a wọ ní aṣọ fúnfún, àti màrìwò ní ọwọ́ wọn.”36
Mo fi ìbùkún mi bí Àpóstélì Jésù Krístì sílẹ̀ pẹ̀lú yín pé ẹ ó fi aápọn tiraka láti gbé ìgbé òdodo àti láti wà ní àárín àwọn wọnnì tí wọ́n wà, pẹ̀lú màrìwò ní ọwọ́ wọn, yío kéde Ọmọ Ọlọ́run, Olùràpadà nlá gbogbo wa. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.