Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ohùn ìdùnnú kan!
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


9:46

Ohùn ìdùnnú kan!

Kíkọ́ àwọn tẹ́mpìlì ti jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ohun pàtàkì jùlọ fún gbogbo àwọn wòlíì láti ìgbà Wòlíì Joseph Smith.

“Nísisìyí, kíni à ngbọ́ nínú ìhìnrere èyí tí a ti gbà? Ohùn ìdùnnú kan! Ohùn àánú kan láti ọ̀run; àti ohùn òtítọ́ látinú ilẹ̀-ayé; ìdùnnú ayọ̀ fún àwọn okú; ohùn ti ìdùnnú kan fún alààyè àti òkú; ìdùnnú ayọ̀ nlá.”1

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé ṣe láti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti ọ̀dọ̀ Wòlíì Joseph Smith kí a má sì ṣe jáde sínú ẹ̀rín nlá!

Ìhó ayọ̀ tí Joseph fi hàn ní tòótọ́ ṣe àkótán ayọ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àti ti ọlánla tí a rí nínú ètò nla ìdùnnú Ọlọ́run Baba wa Ọ̀run, gẹ́gẹ́bí a ti fi dáwalójú, “àwọn ènìyàn wà kí wọ́n lè rí ayọ̀.”2

Gbogbo wa ni a pariwo fún ayọ̀3 ní ayé ìṣaájú ikú nígbàtí a gbọ́ ètò ìdùnnú ti Ọlọ́run, a sì tẹ̀síwájú láti kígbe fún ayọ̀ nihin bí a ti ngbé gẹ́gẹ́bí ètò Rẹ̀. Ṣùgbọ́n kí gan-an ni ipò ọ̀rọ̀ ìkéde aláyọ̀ yìí láti ọ̀dọ̀ wòlíì? Kí ló ru ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ àti àtọkànwá wọ̀nyí sókè?

Wòlíì Joseph ti nkọ́ni nípa ìrìbọmi fún àwọn òkú. Èyí jẹ́ ìfihàn ológo nítòótọ́ tí a gbà pẹ̀lú ayọ̀ nlá. Nígbàtí àwọn ọmọ Ìjọ kọ́kọ́ gbọ́ pé wọ́n lè ṣe ìrìbọmi fún àwọn olólùfẹ́ wọn tí wọ́n ti kú, inú wọn dùn. Wilford Woodruff wípé, “Ní ìgbàtí mo gbọ́ ọ, ọkàn mi fò fun ayọ!”4

Ìrìbọmi fún àwọn òkú kì í ṣe òtítọ́ kan ṣoṣo tí Olúwa yíò ṣípayá tí yíò sì mú padà bọ̀ sípò nìkan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀bùn míràn wà, tàbí àwọn ẹ̀bùn látòkè wá, tí Ọlọ́run ti ní ìtara láti fi fún àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Rẹ̀.

Àwọn ẹ̀bùn míràn wọ̀nyí pẹ̀lú àṣẹ oyèàlùfáà, àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà, àwọn ìgbéyàwó tí yíò wà títí láé, fífi èdìdi dì àwọn ọmọ mọ́ àwọn òbí wọn nínú ẹbí Ọlọ́run, àti níkẹhìn ìbùkún pípadà sílé sí iwájú Ọlọ́run Baba wa Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Kristi. Gbogbo ìbùkún yí ṣeéṣe nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì.

Nítorí Ọlọ́run ka àwon wọ̀nyí sí nínú àwọn ìbùkún mímọ́ àti gíga jùlọ Rẹ̀,5 Ó pàṣẹ pé kí á kọ́ àwon ilé mímọ́ kalẹ̀ níbití Ó ti lè fi ẹ̀bùn iyebíye wọ̀nyí lé àwon ọmọ Rẹ̀.6 Àwọn ilé wọ̀nyí yíò jẹ́ ilé Rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé. Awon ile wonyi yoo je tẹ́mpìlì níbití èyí tí a bá fi èdìdi dì tàbi sopọ̀ ní ilẹ̀ ayé ní oruko Rẹ̀, ati nipa ọ̀rọ̀ Re ati aṣe Rẹ yío jẹ́ fífi èdìdi dì ní ọ̀run.7

Bí ọmọ ìjọ lónìí, ó lè rọrùn fún fún díẹ̀ lára wa láti mú àwọn òtítọ́ ayérayé ológo wọ̀nyí yẹpẹrẹ. Wọ́n ti di ìṣẹ̀dá kejì síwa. Nígbà míràn, ó máa nṣèrànwọ́ tí a bá rí wọn lójú àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn fún ìgbà àkọ́kọ́. Èyí hàn sí mi nípasẹ̀ ìrírí àìpẹ́ kan.

Ní ọdún tó kọja, ní kété ṣaájú ìtúnyàsímímọ́ ti Tẹ́mpìlì Tokyo Japan, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlejò tí kìí ṣe ti ìgbàgbọ́ wa ṣàbẹ̀wò sí tẹ́mpìlì náà. Ọ̀kan nínú irú ìrìn àjò bẹ́ẹ̀ ní arònújinlẹ̀ olùdarí kan láti ẹ̀sìn míràn nínú. A kọ́ àlejò wa nípa ètò ìdùnnú ti Baba Ọ̀run, ipa títóbi jùlọ ti Jésù Krístì nínú ètò ynáà, àti ẹ̀kọ́ pé àwọn ẹbí lè wà ní ìṣọ̀kan títí ayérayé nípasẹ̀ ìlànà èdìdì.

Ní ìparí ìrìn àjò wa, mo pe ọ̀rẹ́ wa láti pín ìmọ̀lára ​​rẹ̀. Ní títọ́ka sí ìṣọ̀kan àwọn ẹbí—ti àtijọ́, ti ìsisìyí, àti ti ọjọ́ iwájú—ọkùnrin rere yìí béèrè pẹ̀lú òtítọ́ pé, “Njẹ́ àwọn ọmọ ìjọ rẹ tilẹ̀ lóye ní tòótọ́ bí ẹ̀kọ́ yí ti jinnlẹ̀ tó?” Ó fi kún un pé, “Ó ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ ọ̀kan lára ​​àwọn ẹ̀kọ́ kan ṣoṣo tó lè so ayé yìí tó ti pínyà tó bẹ́ẹ̀ pọ̀.”

Ó ti jẹ́ àkíyèsí alágbára tó. Iṣẹ́-ọnà dídára tẹ́mpìlì kò jọ́ ọkùnrin yí lójú pẹ̀lú ìrọ̀rùn ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ nípa ẹ̀kọ́ ìjinlẹ̀ tó yànilẹ́nu pé awọn ẹbí wà ní ìṣọ̀kan ní sísopọ̀ mọ́ Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì títí láé.8

Nítorínáà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu nígbà tí ẹnìkan tí kì í ṣe ti ìgbàgbọ́ wa bá mọ̀ ọlánlá ohun tó nṣẹlẹ̀ nínú tẹ́mpìlì. Ohun tí ó lè wọ́pọ̀ tàbí jẹ́ àṣetúnṣe fún wa ni a nrí nígbà míràn nínú ẹwà àti ọlánlá rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn tí wọ́n gbọ́ tàbí tí wọ́n ní ìmọ̀lára rẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́.

Láti ìgbà Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì, kíkọ́ àwọn tẹ́mpìlì ti jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ohun pàtàkì jùlọ fún gbogbo àwọn wòlíì láti ìgbà Wòlíì Joseph Smith. Àti pé ó rọrùn láti ní oyè kínìdí.

Nígbàtí Wòlíì Joseph nkọ́ni nípa ìrìbọmi fún àwọn òkú, ó fi òtítọ́ nlá míràn hàn. Ó kọ́ni pé: “Jẹ́ kí nfi dá yín lójú pé ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ìlànà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òkú àti alààyè tí a kò lè rékọjá lọ́fẹ̀ẹ́, ní ti ìgbàlà wa. Nítorí ìgbàlà wọn ṣe pàtàkì ó sì ṣe kókó fún ìgbàlà wa, … àwọn láìsí àwa a kò lè sọ wọ́n di pípé—bẹ́ẹ̀ ni a kò lè sọ wá di pípé láìsí àwọn òkú wa.”9

Bí a ṣe ríi, ìnílò fún àwọn tẹ́mpìlì àti iṣẹ́ náà tí a ṣe fún àwọn alààyè àti àwọn okú jẹ́ kedere.

Ọ̀tá wà ní ìṣọ́ra. Agbára rẹ̀ wà nínú ewu nípa àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú tí a ṣe nínú àwọn tẹ́mpìlì, ó sì nṣe ohunkóhun tí ó lè ṣe láti gbìyànjú láti dá iṣẹ́ náà dúró. Kínìdí? Nítorípé ó mọ̀ nípa agbára tí ó nwá látinú iṣẹ́ mímọ́ yí. Bí a ṣe nya tẹ́mpìlì titun kọ̀ọ̀kan sọ́tọ̀, agbára ìgbàlà Jésù Krístì ngbòòrò síi jákèjádò ayé láti dojú ìjà kọ ìsapá ọ̀tá náà àti láti ràwápadà bí a ti ntọ̀ ọ́ wá. Bí àwọn tẹ́ńpìlì àti àwọn olùpa májẹ̀mú mọ́ ṣe npọ̀ síi ní iye, ọ̀tá ndà aláìlágbára sí i.

Ní àwọn ọjọ́ àkọ́kọ́ ti Ìjọ, àwọn kan yíò ṣàníyàn nígbà wo ni a ó kéde tẹ́mpìlì titun kan, nítorí wọn yíò wípé, “A kò bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ tẹ́mpìlì kan láìjẹ́ pé agogo ọ̀run àpáàdì bẹ̀rẹ̀ sí dún.” Ṣùgbọ́n Brigham Young fi ìgboyà fèsì pé, “Mo fẹ́ gbọ́ dídún wọn lẹ́ẹ̀kan sí i.”10

Ní ayé iku yí, a kò ní sa fún ogun láéláé, ṣùgbọ́n a lè ní agbára lórí ọ̀tá. Agbára àti okun náà wá látọ̀dọ̀ Jésù Krístì bí a ṣe nṣe tí a sì npa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì mọ́.

Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé: “Àkókò nbọ̀ nígbàtí àwọn tí kò gbọ́ràn sí Olúwa yíò yapa kúrò lára ​​àwọn tí wọ́n nṣe. Ìdíye-lófò wa tó ní ààbò jùlọ ni láti tẹ̀sìwájú láti yẹ fún gbígbà wọlé sí ilé mímọ́ Rẹ̀.”11

Nihin ni díẹ̀ nínú àwọn ìbùkún tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún wa nípasẹ̀ wòlíì Rẹ̀:

Njẹ́ ẹ nílò àwọn iṣẹ́ ìyanu? Wòlíì wa ti wípé: “Mo ṣèlérí fún yín pé Olúwa yíò mú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Ó mọ̀ pé ẹ nílò wá bí ẹ ti nṣe àwọn ìrúbọ láti sìn àti láti jọ́sìn nínú àwọn tẹ́mpìlì Rẹ̀.”12

Njẹ́ ẹ nílò ìwòsàn àti agbára ìmúlókun ti Olùgbàlà Jésù Krístì? Ààrẹ Nelson fi dáwalójú pé “gbogbo ohun tí a kọ́ nínú tẹ́mpìlì … mú òye wa nípa Jésù Krístì pọ̀ sí i. … Bí a ti npa àwọn májẹ̀mú wa mọ́, Ó nbùkún wa pẹ̀lú agbára ìwòsàn, ìmúlókun. Rẹ̀ Àti pé áà, bí a ó ṣe nílò agbára Rẹ̀ tó ní àwọn ọjọ́ iwájú.”14

Ní Ọjọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ àkọ́kọ́, bí Jésù Krístì ti nwọ Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú ìṣẹgun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì yọ̀ wọ́n sì yin Ọlọ́run pẹ̀lú ohùn rara … wípé, Ìbùkún ni fún Ọba tí nbọ̀wá ní orúkọ Olúwa.”15

Ó ti bamu tó pé ní Ọjọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ ti ọdún 1836, a ya tẹ́mpìlì Kirtland sọ́tọ̀. Ní àkókò náà, àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì pẹ̀lú nyọ̀. Nínú àdúrà ìyàsímímọ́ náà, Wòlíì Joseph Smith kéde àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn wọ̀nyí:

“Áà Olúwa Ọlọ́run Alágbára, gbọ́ tiwa … kí o sì dá wa lohùn láti ọ̀run wá, … níbití ìwọ jóko lórí ìtẹ́, pẹ̀lú ògo, ọlá, agbára, ọlánlá, [àti] ipá. …

“… Rànwálọ́wọ́ nípa agbára Ẹ̀mí Rẹ, kí a lè da ohun wa pọ̀ pẹ̀lú àwọn Séráfù dídán, mímọ́lẹ̀ yí ìtẹ́ rẹ ká, pẹ̀lú ìyìn, ní kíkọrin Hòsánnà sí Ọlọ́run àti Ọ̀dọ́-Àgùtàn!

“Kí O sì jẹ́kí àwọn wọ̀nyí … àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ ó kígbe sókè fún ayọ̀.”16

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, lónìí lọ́jọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ yí, ẹ jẹ́ kí a tún ní ìmọ̀lára láti yin Ọlọ́run mímọ́ wa kí a sì yọ̀ nínú oore Rẹ̀ sí wa. “Kíni à gbọ́ nínú ìhìnrere èyí tí a ti gbà? Nítòótọ́ “ohùn ayọ̀ kan!”17

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ ó ní ìmọ̀lára ayọ̀ púpọ̀ àti púpọ̀ síi bí ẹ ti nwọnú àwọn tẹ́mpìlì mímọ́ Olúwa. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ ó ní ìrírí ayọ̀ tí Òun ní fún yín lẹ́hìnnáà, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.