Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìròhìn Ẹ̀ka Jíjẹ́rí Ìṣírò owó Ìjọ, Ọdún 2022
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


Ìròhìn Ẹ̀ka Jíjẹ́rí Ìṣírò owó Ìjọ, Ọdún 2022

Sí Àjọ Ààrẹ Ìkínní ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn

Ẹ̀yin Arákùnrin Ọ̀wọ́n: Ní dídarí nípa ìfihàn, bí a ṣe kọ́sílẹ̀ nínú ipín 120 ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, Ìgbìmọ̀ lórí Lílo àwọn Idamẹwa—tí ó jẹ́ àkópọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá, àti Àjọ Alákòóso Bíṣọ́pù—fi àṣẹ sí níná àwọn owó Ìjọ. Àwọn ẹka Ìjọ ngbé owó jáde ní ìbámu sí àwọn ìṣúná, àwọn ìṣètò, àti àwọn ìlànà tí a fi ọwọ́ sí.

Jíjẹ́rí Ìṣírò owó Ìjọ, èyí tí ó ní àkópọ̀ àwọn akọ́ṣẹmọṣẹ tí wọ́n ní ìwé ẹ̀rí tí ó sì wà ní òmìnira kúrò ní gbogbo àwọn ẹ̀ka Ìjọ míràn àti ile-iṣẹ àdáwà, ní ojúṣe láti ṣe ìjẹ́rìí ìṣírò owó fún èrò ti pípèsè ìdánilójú tí ó ní ìkàsí nípa àwọn ìdáwó tí a gbà, ìnáwó tí a ṣe, àti dídá-ààbò bo àwọn ohun ìní Ìjọ.

Ní dídá lórí ìjẹ́rí ìṣírò tí a ṣe, Ẹka Jíjẹ́rí Ìṣírò ti Ìjọ ní èrò pé, ní gbogbo ọ̀nà ohun-èlò tí ó ṣe kókó, ìdáwó tí a gbà, ìnáwó tí a ṣe, àti àwọn ohun-ìní Ìjọ fún ọdún 2022 ní a ti kọ sílẹ̀ tí a sì ti lò ní ìbámu sí àwọn ìṣúná Ìjọ tí a fi ọwọ́ sí, àwọn ìṣètò, àti àwọn ìṣesí ìṣírò ṣíṣe. Ìjọ tẹ̀lé àwọn ìṣesí tí a kọ́ àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ nípa gbígbé ní ààrin ìṣúná-owó, yíyẹra fún gbèsè, àti ìfi-pamọ́ fún ìgbà àìní kan.

Ní gbígbé kalẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀,

Ẹ̀ka Jíjẹ́rí Ìṣírò owó Ìjọ

Jared B. Larson

Olùdarí Àgbà

Tẹ̀