Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ọ̀kan nínú Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


Ọ̀kan nínú Krístì

Ó jẹ́ nínú àti nípasẹ̀ òtítọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan sí Jésù Krístì nìkan ni a lè ní ìrètí láti jẹ́ ọ̀kan.

Bí Ààrẹ Dallin H. Oals ti ṣe àkíyèsí, òní ni Ìsinmi Ọ̀pẹ, ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀sẹ̀ Mímọ́, tí ó fàmì fífí ẹ̀yẹ wọ Jérúsálẹ́mù Olúwa, ìjìyà Rẹ̀ ní Gẹ́tsémánè àti ikú lórí àgbélèbú ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ lẹ́hìnnáà, àti Àjínde ológo Rẹ̀ ní Ọjọ́ Ìsinmi Àjínde. Ẹ jẹ́ kí a yanjú láti máṣe gbàgbé ohun tí Krísti faradà láti ràwápadà láé .1 Kí a má sí ṣe sọ ìbonimọ́lẹ̀ ayọ̀ tí a ó ní lẹ́ẹ̀kansi ní Ọdún Àjínde bí a ti ngbèrò ìṣẹ́gun Rẹ̀ lórí isa-òkú àti ẹ̀bùn àjínde gbogbogbò.

Ní ìrọ̀lẹ́ ṣíwájú àwọn àdánwò àti ìkànmọ́ àgbélèbú tí ó ndúró dè E, Jésù darapọ̀ mọ́ oúnjẹ́ Irékọjá pẹ̀lú àwọn Àpóstélì Rẹ̀. Ní òpin Oúnjẹ-alẹ́ ìkẹhìn, nínú Àdúrà Ẹ̀bẹ̀, Jésù bẹ̀ baba Rẹ̀ ní àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Baba Mímọ́, nípa orúkọ yín ẹ pa [àwọn Àpóstélì mi] mọ́ àwọn ẹni tí ìwọ ti fún me, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan, bí àwà ṣe jẹ́.”2

Lẹ́hìnnáà, pẹ̀lú ìrọ̀rùn, ó mú kí ẹ̀bẹ̀ Rẹ̀ karí gbogbo àwọn onígbàgbọ́.

“Kìí sì íṣe kìkì àwọn wọ̀nyí ni mo ngbàdúrà fún, ṣùgbọ́n fún àwọn pẹ̀lú tí yíò gbà mí gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ wọn;

Kí gbogbo wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan; gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti jẹ́ nínú mi, àti èmi nínú rẹ, kí àwọn pẹ̀lú kí ó lè jẹ́ ọ̀kan nínú wa.”3

Dídi ọ̀kan jẹ́ àkòrí òòrèkóòrè nínú ìhìnrere Jésù Krístì àti nínú ìbáṣe Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ọmọ Rẹ̀, Pẹ̀lú ọ̀wọ̀ sí ìlú Síónì ní ọjọ́ Enoch, a sọọ́ wípé “wọ́n jẹ́ ọ̀kàn kan àti inú kan.”4 Nípa àwọn Ènìyàn Mímọ́ ìṣaájú ní Ìjọ àtijọ́ ti Jésù Krístì, Májẹ̀mú Titun ṣe àkọsílẹ̀ pé, “Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn lára wọn tí wọ́n gbàgbọ́ jẹ́ ọkàn kan àti inú kan.”5

Ní àkokò ti arawa, Olúwa kìlọ̀ pé, “Mo wí fún yín, ẹ jẹ́ ọ̀kan; bí ẹ̀yin kò bá jẹ́ ọ̀kan ẹ̀yin kìí ṣe tèmi.”6 Ní àárín àwọn èrèdí tí Olúwa fúnni bí ìdí tí àwọn Ènìyàn Mímọ́ ìṣaájú ní Missouri ṣe kùnà láti gbé ibi Síónì kan kalẹ̀ ni pé “wọn kò ní ìrẹ́pọ̀ gẹ́gẹ́bí ìdàpọ̀ tí a bèèrè nípa òfin sẹ̀lẹ́stíà.”7

Nígbàtí Ọlọ́run bá borí nínú gbogbo ọkàn àti inú, àwọn ènìyàn ni a júwé pé wọ́n wà s “ní ọ̀kan, àwọn ọmọ Krístì.”8

Nígbàtí Olùgbàlà tí ó jíǹde farahàn sí àwọn ènìyàn Ìwé ti Mọ́mọ́nì àtijọ́, Ó ṣàkíyèsí pẹ̀lú àìtẹ́wọ́gbà pé ní ìgbà àtijọ́ àríyànjiyàn ti wà láàrín àwọn ènìyàn nípa ìrìbọmi àti àwọn ọ̀ràn míràn. Ó pàṣẹ:

Kí àríyànjiyàn ó má sì ṣe wà lãrín yín, bí ó ti wà ṣãjú àkokò yĩ; bẹ̃ni kí àríyànjiyàn ó má ṣe wà lãrín yín nípa àwọn ohun àfiyèsí tí ó wà nínú ẹ̀kọ́ mi, bí ó ti wà ṣãjú àkokò yĩ.

Nítorí lootọ, lootọ, ni mo wí fún yín, ẹni tí ó bá ní ẹ̀mí ìjà kìí ṣe ti èmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti eṣù, ẹni tí ó jẹ́ baba ìjà.”9

Nínú ayé tí ó kún fún ìjà, báwo ni a ṣe lè ní àṣeyege ìrẹ́pọ̀, nípàtàkì nínú Ìjọ níbibtí a níláti ní “Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan, ìrìbọmi kan”?10 Páùlù fún wa ní kọ́kọ́rọ́:

“Nítorípé iye ẹ̀yin tí a ti ṣe ìrìbọmi fún sínú Krístì ti gbé Krístì wọ̀.

“Kò sí Júù tàbí Greek, kò sí ìgbèkùn tàbí òmìnira, kò sí akọ tàbí abo: nítorí gbogbo yín jẹ́ ọ̀kan nínú Krístì.”11

A ti pọ̀ jù lóríṣiríṣi nígbàmíràn a sì ti wà ségesège jù láti lè kórajọ papọ̀ bí ọ̀kan lórí ohunkóhun míràn tàbí lábẹ́ orúkọkórúkọ míràn. Nínú Jésù Krístì nìkan ni a lè di ọ̀kan nítòótọ́.

Dídi ọ̀kan nínú Krístì nṣẹlẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan—ẹnìkọ̀ọ̀kan wa nbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú arawa. A jẹ́ ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀mí méjèèjì nígbàmíràn a sì njagun ní àárín arawa. Bí Páùlù ti fihàn:

“Nítorí mo láyọ nínú òfin Ọlọ́run ní àtinúwa èníyàn;

“Ṣùgbọ́n mo rí òfin míràn [nínu] ẹ̀yà [ara mi], ní àtakò sì òfin inú mi, ó sì nmú mi wá sínú ìdè sí òfin ẹ̀ṣẹ̀ èyí tí ó wà nínú ẹ̀yà ara mi.”12

Jésù bákannáà jẹ́ ti ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀mí A dán An wò; Ó ní ìmọ̀; Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyege ìrẹ́pọ̀ nínú wa.13 Nítorínáà, fífa lórí ìmọ́lẹ̀ àti oore ọ̀fẹ́ Krístì, à ntiraka láti fún ẹ̀mí wa—àti Ẹ̀mí Mímọ́—ní ìṣẹ́gun lórí ti ara. Nígbàtí a bá sì kùnà, Krístì, nípa Ètùtù Rẹ̀, ti fún wa ní ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà àti ànfàní láti gbìyànjú lẹ́ẹ̀kansi.

Bí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa bá “gbé Krístì wọ̀,” nígbànáà lápapọ̀ a lè ní ìrètí láti di ọ̀kan, bí Páùlù ti sọ, “ara Krístì.”14 Láti “gbé Krístì wọ̀” gan pẹ̀lú mímú òfin Rẹ̀ “àkọ́kọ́ àti nla”15 jẹ́ ìfaramọ́ wa àkọ́kọ́ àti títóbijùlọ, tí a bá sì ní ìfẹ́ Ọlọ́run, a ó pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.16

Ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin grows as we wa nínú ara Krístì ndàgbà bí a ti ngbọ́ òfin kejì—tí ó so mọ́ àkọ́kọ́ daindain—láti ní ìfẹ́ àwọn ẹlòmíràn bíi ti arawa.17 Àní mo sì lérò pé ìrẹ́pọ̀ pípé si yíò wà ní àárín wa bí a bá tẹ̀lé ìfihàn gíga si àti mímọ́ si Olùgbàlà nípa òfin kejì yí —láti ní ìfẹ́ ẹlòmíràn kìí ṣe bí a ti ní ìfẹ́ arawa nìkan ṣùgbọ́n bí Òun ti ní ìfẹ́ wa.18 Ní àkópọ̀, ó jẹ́ pé “gbogbo ènìyàn nwá ìfẹ́ aladugbo rẹ̀, wọ́n sì nṣe àwọn ohun gbogbo pẹ̀lú ojú kan sí ògo Ọlọ́run.”19

Ààrẹ Marion G. Romney, Olùdámọ̀ràn kan tẹ̀lẹ̀ nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní, ní ṣíṣe àlàyé bí a ti lè gba ìfaradà àláfíà àti ìrẹ́pọ̀, wípé:

“Bí ẹnìkan ṣoṣo, tí ó yọ̀ọ̀da fún Sátánì bá, kún fún àwọn iṣẹ́ ara, òun ó jagun nínú ararẹ. Bí àwọn méjì bá yọ̀ọ̀da, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn a jagun nínú ara wọn wọn ó sì jà pẹ̀lú ara wọn. Bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ bá yọ̀ọ̀da, àwùjọ a [kó] ire wàhàlà àti ìjà nlá. Bí àwọn alakóso orílẹ̀ èdè kan bá yọ̀ọ̀da, ìjà gbogbogbò yíò wa.”

Ààrẹ Romney tẹ̀síwájú pé: “Bí àwọn iṣẹ́ ara bá ní ìlò káríayé, bẹ́ẹ̀ náà ni ìhìnrere àláfíà ti ṣe. Bí ènìyàn kan bá gbé e, òun ó ní àláfíà nínú ararẹ̀. Bí àwọn ènìyàn méjì bá gbé e, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yíò ní àláfíà nínú arawọn. Bí àwọn ọmọ orílè èdè bá gbé e, orílẹ̀ èdè náà a ní àláfíà ilé. Nígbàtí àwọn orílẹ̀ èdè bá wà tó tí wọ́n ngbádùn èso ti Ẹ̀mí láti darí àwọn ọ̀ràn ayé, nígbànáà, àti nígbànáà nìkan, ni àwọn ìlù-ogun kò ní dún mọ́, àti pé àsíà ogun ó di wíwém’ọ́. … (Wo Alfred Lord Tennyson, “Locksley Hall,” The Complete Poetical Works of Tennyson, ed. W. J. Rolfe, Boston, Houghton–Mifflin Co., 1898, p. 93, lines 27–28.)”20

Nípa “gbígbé Krístì wọ,” ó di ṣíṣé bóyá láti yanjú tàbí láti gbé àwọn ìyàtọ́, àríyànjiyàn, àti ìjà sẹgbẹ. Ìyára àpẹrẹ kan ti bíborí ìyapa ni a rí nínú àkọọ́lẹ̀-ìtàn Ìjọ wa. Alàgbà Brigham Henry Roberts (tí a mọ̀ sí B. H. Roberts), tí a bí ní England ní 1857, sìn bí ọmọ Ìgbìmọ̀ Àkọ́kọ́ ti Àádọ́rin—ohun tí a tọ́ka sí ní òní bí Àjọ Ààrẹ Áádọ́rin. Alàgbà Roberts jẹ́ olùṣe alágbára olùdá ààbo bò ti ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere àti ti Ìjọ ní àwọn ìgbà líle jùlọ rẹ̀.

Àwòrán
Ọ̀dọ́ B. H. Roberts

Ní 1895, bákannáà, iṣẹ́ ìsìn Alàgbà Roberts nínù Ìjọ ni a fi sínú ewu nípa ìjà. B. H. Ni a ti yàn bí aṣojú sí àpéjọ tí o kọ òfin kan fún Utah nígbàtí ó di ìpínlẹ̀. Lẹ́hìnwá, ó pinnu láti di olùdìje fún Aṣòfin ṣùgbọ́n kò gba àṣẹ tàbí fi tó Àjọ Ààrẹ Ìkínní létí. Ààrẹ Joseph F. Smith, olùdámọ̀ràn kan nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní, ṣe ìbáwí fún B. H. Fún ìkùná náà nínú ìpàdé gbogbogbò oyè-àlùfáà. Alàgbà Roberts pàdánù ìbò náà ó sì ní ìmọ̀lára pé ìjákulẹ̀ rẹ̀ ní íṣe ní apákan sí ìsọ̀rọ̀ Ààrẹ Smith. Ó digun mọ́ àwọn olórí Ìjọ nínú àwọn ọ̀rọ̀ òṣèlú kan àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò. Ó kúrò ní ṣíṣe aápọn iṣẹ́ ìsìn Ìjọ. Nínú ìpàdé gígùn nínú Tẹ́mpìlì Salt Lake pẹ̀lú àwọn ọmọ Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Ìgbìmọ àwọn Méjìlá, B. H. takú síbẹ̀ ní dída ararẹ̀ láre. Lẹ́hìnnáà, “Ààrẹ [Wilford] Woodruff fún [Alàgbà Roberts] ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tún ipò rẹ̀ yẹ̀wò. Bí ó bá takù láìronúpìwàdà, wọ́n yíò dá a sílẹ̀ kúrò nínú àádọ́rin.”21

Nínú àwọn ìpàdé ìkọ̀kọ̀ ṣíṣẹ̀ntẹ̀lé pẹ̀lú Heber J. Grant àti Francis Lyman, B. H. nì àkọ́kọ́ kọ̀ kò àyọrísí, ṣùgbọ́n ìfẹ́ àti Ẹ̀mí Mímọ́ borí nígbẹ̀hìn. Omijé wá sí ojú rẹ̀. Àwọn Àpóstélì méjì fèsì sí àwọn àṣìṣe àtiìkùnsínú kan tí wọ́n rò pé ó ndá B. láàmú. H. àti àwọn kúrò pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ àtọkànwá fún ìlàjà. Ní òwúrọ̀ tó tẹ̀le, lẹ́hìn àdúrà gígùn, Alàgbà Roberts fi àkọsílẹ̀ ránpẹ́ ránṣẹ́ sí àwọn Alàgbà Grant àti Lyman pé òun ṣetán láti tún ṣe ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀.22

Nígbàtí ó pàdé pẹ̀lú Àjọ Ààrẹ Ìkínní lẹ́hìnnáà, Alàgbà Roberts wípé, “Mo lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa mo sì gba ìmọ́lẹ̀ àti àṣẹ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ láti juwọ́lẹ̀ sí àṣẹ Ọlọ́run.”23 Níní ìwúrí nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, B. H. Roberts dúró bi olótítọ́ kan ó sì jẹ́ olùṣe olórí Ìjọ dé òpin ìgbé ayé rẹ̀.24

Àwòrán
Alàgbà B. H. Roberts

Bákannáà a lè ri nínú àpẹrẹ yí pé ìrẹ́pọ̀ kò kan túmọ̀ sí fífaramọ pé gbogbo ènìyàn níláti ṣe ohun ti arákùnrin tàbí arábìnrin ararẹ̀ tàbí lọ ni ọ̀nà tí arákùnrin tàbí arábìnrin ararẹ̀. A kò lè jẹ́ ọ̀kàn àyàfi bí gbogbo wa bá tẹ àwọn ìtiraka wa sí èrò káríkárí. Ó túmọ̀ sí pé, nínú ọ̀rọ B. H. Roberts, jíjuwọ́lẹ̀ sí àṣẹ Ọlọ́run. A jẹ́ ọmọ ìjọ ara Krístì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ní mímú àwọn ìṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣẹ ní àwọn ìgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀—etí, ojú, orí, ọwọ́, ẹsẹ̀—síbẹ̀ gbogbo wọn jẹ́ ara kan.25 Nítorínáà, ìfojúsùn wa ni “Kí ìyapa kí ó máṣe sí nínú ara; ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara kí ó má ṣe ìtọ́jú kannáà fún ara wọn.”26

Ìrẹ́pọ̀ kò gba irúkannáà, ṣùgbọ́n ó gba ìbárẹ́. A lè ní ọkàn wa papọ̀ nínú ìfẹ́, jẹ́ ọ̀kan nínú ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́, àti síbẹ́síbẹ́ túraká fún àwọn ẹgbẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, jiyàn lórí onírurú ọ̀ràn òṣèlú, jíròrò nípa ibiafb´dé àti ọ̀nà ẹ̀tọ́ láti ṣe àṣeyege wọn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú àwọn ohun míràn. Sùgbọ́n a kò lè jiyàn tàbí jà pẹ̀lú ìbínú tàbí asọ̀ fún ara wa láé. Ni Olùgbàlà wípé:

“Nítorí lóotọ́, lóotọ́ ni mo wí fún yín, ẹnití ó bá ní ẹ̀mí asọ̀ kĩ ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ti èṣù nií ṣe, ẹnití íṣe baba asọ̀, òun a sì máa rú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn sókè láti bá ara wọn jà pẹ̀lú ìbínú, ọ̀kan sí òmíràn.

“Ẹ kíyèsĩ, èyí kĩ íṣe ẹ̀kọ́ mi, láti rú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn sókè pẹ̀lú ìbínú, ọ̀kan sí òmíràn; ṣùgbọ́n èyĩ ni ẹ̀kọ́ mi, pé kí a mú irú ohun wọnnì kúrò.”27

Ọdún kan sẹ́hìn, Ààrẹ Russell M. Nelson bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Kò sí ẹnìkankan lára wa tí ó lè ṣe àkóso àwọn orílẹ̀-èdè tàbí ìṣe àwọn ẹlòmíràn àní tàbí àwọn ọmọ ìjọ ti ẹbí ara wa. Ṣùgbọ́n a lè ṣe àkòso arawa. Ìpè mi ní òní, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ni láti parí àwọn ìjà tí ó njà nínú ọkàn yín, ilé yín, àti ayé yín. Ẹ ri ohunkóhun àti gbogbo ìrò láti pa àwọn ẹlòmíràn lára mọ́lẹ̀—bóyá iro láti bínú, ahọ́n mímú, tàbí ìkorira fún ẹnìkan tí ó ti pa yín lára. Olùgbàlà pàṣẹ fún wa láti yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ míràn,[wo 3 Nefi 12:39], láti fẹ́ràn àwọn ọ̀tá wa, àti láti gbàdúrà fún àwọn wọnnì tí wọ́n nlò wá nílókulò. [wo 3 Néfì 12:44].”28

Mo wí lẹ́ẹ̀kansi pé nínú àti nípasẹ̀ òdodo ẹnìkọ̀ọ̀kan wa sí àti ìfẹ́ Jésù Krístì nìkan ni a lè ní ìrètí láti jẹ́ ọ̀kàn—ọ̀kan nínú, ọ̀kan nínú ilé, ọ̀kan nínú Ìjọ, nígbẹ̀hìn ọ̀kan ní Síónì, àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, ọ̀kan pẹ̀lú Baba àti Ọmọ àti Ẹ̀mí Mímọ́.

Mo padà sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti Ọ̀sẹ̀ Mímọ́ àti ìsṣ´gun ti Olùràpada wa. Àjínde Jésù Krístì njẹ́ ẹ̀rí àtọ̀runwá Rẹ̀ àti pé Ó ti borí ohun gbogbo. Àjínde Rẹ̀ njẹ́ ẹ̀rí pé, ní ìsopọ̀ si I nípa májẹ̀mú, àwa pẹ̀lú lè borí ohun gbogbo kí a sì di ọ̀kan. Mo jẹ́ ẹ̀rí Àjínde Rẹ̀ pé nípasẹ̀ Rẹ̀, àìkú àti ìyè arárayé jẹ́ òdodo.

Ní òwúrọ̀ yí, mo jẹ́ ẹ̀rí Àjínde Rẹ̀ lódodo àti gbogbo ohun tí ó wémọ, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀