Jésù Krístì Ni Ìrànlọ́wọ́
A lè bá Olùgbàlà ṣe pọ̀ láti pèsè ìrànlọ́wọ́ ti ara àti ti ẹ̀mí fún àwọn wọnnì nínú àìní—kí a sì rí ìrànlọ́wọ́ tí ara wa nínú èto náà.
Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi àti ìrètí nínú ohun tí wọ́n ti gbọ́ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀, àwọn olùtọ́jú ọkùnrin ẹlẹ́gbà kan mú un wá sọ́dọ̀ Jésù. Wọ́n lo ọ̀nà titun láti mú un dé ibẹ̀—wọ́n ṣí òrùlé, wọ́n sì gbe ọkùnrin náà kalẹ̀, sórí ibùsùn rẹ̀, sí ibi tí Jésù ti nkọ́ni. “Nígbàtí Jésù “rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí [fún ọkùnrin ẹlẹ́gbà náà pé], a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́.”1 Àti lẹ́hìnnáà, “Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ ní ọ̀nà rẹ sí ilé rẹ.”2 Lójúkannáà ọkùnrin ẹlẹ́gbà náà dìde, ó sì gbé àkéte rẹ̀, ó sì lọ sí ilé, “ó sì nyìn Ọlọ́run lógo.”3
Kí la tún mọ̀ nípa àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n pèsè ìtọ́jú fún ọkùnrin ẹlẹ́gbà náà? A mọ̀ pé Olùgbàlà mọ ìgbàgbọ́ wọn. Nígbàtí wọ́n sì ti rí Olùgbàlà tí wọ́n sì ti gbọ́ tí wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́rìí sí àwọn iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀, “ó yà wọ́n lẹ́nu” wọ́n sì “fi ògo fún Ọlọ́run.”4
Jésù Krístì ti pèsè ìmúláradá tí a nírètí fún—ti ìrànlọ́wọ́ ara kúrò nínú ìrora àti àwọn àbájáde mímúni dùbúlẹ̀ ti àìsàn líle. Ní pàtàkì, Olùgbàlà tún pèsè ìrànlọ́wọ́ ti ẹ̀mí ní wíwẹ ọkùnrin náà mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
Àti pé àwọn ọ̀rẹ́—nínú ìsapá wọn láti tọ́jú ẹni kan tí ó wà nínú àìní, wọ́n rí orísun ìrànlọ́wọ́; wọ́n rí Jésù Krístì.
Mo jẹ́rìí pé Jésù Krístì ni ìrànlọ́wọ́. Nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì, a lè rí ìrànlọ́wọ́ kúrò nínú ẹrù àti àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ kí a sì ràn wá lọ́wọ́ nínú àwọn àìlera wa.
Àti nítorípé a fẹ́ràn Ọlọ́run, tí a sì ti dá májẹ̀mú láti sìn Ín, a lè ṣe ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Olùgbàlà láti ṣèrànwọ́ láti pèsè ìrànlọ́wọ́ ti ara àti ti ẹ̀mí fún àwọn wọnnì nínú aíní—àti ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kí á rí ìrànlọ́wọ́ tiwa nínú Jésù Krístì.5
OWòlíì wa àyànfẹ́, Ààrẹ Russell M. Nelson, pè wá láti ṣẹ́gun ayé kí a sì rí ìsinmi.6 Ó túmọ̀ “ìsinmi tòótọ́” bí “ìrànlọ́wọ́ àti àláfíà.” Ààrẹ Nelson wípé, ”Nítorípé Olùgbàlà, nípasẹ̀ Ètùtù àìlópin Rẹ̀, ra ẹnìkọ̀ọ̀kan wa padà kúrò nínú àìlera, àṣìṣe, àti ẹ̀ṣẹ̀, àti nítorípé Ó ní ìrírí gbogbo ìrora, ìdàmú, àti ẹrù tí ẹ ti ní rí, nígbànáà, bí ẹ ṣe nronúpìwàdà ní tòótọ́ tí ẹ sì nwá ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, ẹ lè dìde kọjá ewu ayé yí nísisìyí.”7 Èyí ni ìrànlọ́wọ́ tí Jésù Kristi fi fún wa!
Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ngbé àfiwé àpò-ẹ̀hìn. Ó lè jẹ́ apẹ̀rẹ̀ kan tí ó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ní orí rẹ tàbí àpò tàbí àdìpọ̀ àwọn ohun tí a fi aṣọ wé, tí a sì jù sí èjìká yín. Ṣùgbọ́n fún èrò wa, ẹ jẹ́ kí á pè é ní àpò-ẹ̀hìn kan.
Àfiwé àpò-ẹ̀hìn yí ni ibití a ti gbé àwọn ẹrù ìnira ti gbígbé nínú ayé ṣíṣubú. Àwọn ẹrù wa dàbí àwọn àpáta nínú àpò-ẹ̀hìn. Ní gbogbogbò, àwọn oríṣi mẹ́ta ni ó wa:
-
Àwọn àpáta níbẹ̀ ti a ṣe fúnra wa nítorí ẹ̀ṣẹ̀.
-
Àwọn àpáta nínú àpò-ẹ̀hìn wa nítorí àwọn ìpinnu tí kò dára, àìṣedéédé, ati àìníwàrere àwọn ẹlòmíràn.
-
Àti àwọn àpáta tí a gbé nítorí à ngbé ní ipò ìṣubú. Lára ìwọ̀nyí ni àwọn àpáta àrùn, ìrora, àìlera, ìbànújẹ́, ìjákulẹ̀, ìdánìkanwà, àti àbájáde àwọn ìjámbá àmúwá ìṣẹ̀dá.
Mo fi tayọ̀tayọ̀ kéde pé àwọn ẹrù ikú wa, àwọn àpáta wọ̀nyí nínú ìṣàpẹrẹ àpò-ẹ̀hìn wa, kò nílò kí ó wúwo.
Jésù Krístì lè mú kí ẹrù wa fúyẹ́.
Jésù Krístì lè gbé àwọn ẹrù wa sókè.
Jésù Krístì pèsè ọ̀nà kan fún wa láti bọ́ lọ́wọ́ ìwúwo ẹ̀ṣẹ̀.
Jésù Krístì ni ìrànlọ́wọ́ wa.
Ó wípé:
“Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó nṣiṣẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín [èyí ni, ìrànlọ́wọ́ àti àláfíà].
“Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmí: ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.
“Nítorí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.”8
Pé àjàgà náà rọrùn, ẹrù náà sì fúyẹ́ jẹ́ ní rírò pé a bọ́ sínú àjàgà náà pẹ̀lú Olùgbàlà, pé a pín àwọn ẹrù wa pẹ̀lú Rẹ̀, pé a jẹ́ kí Ó gbé ẹrù wa sókè. Èyí túmọ̀ sí wíwọ inú májẹ̀mú ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, àti pípa májẹ̀mú náà mọ́, èyí tí, Ààrẹ Nelson ti ṣàlàyé pé ó, “nmú ohun gbogbo nípa ìgbé ayé rọrùn. Ó wípé,”Síso ara yín pẹ̀lú Olùgbàlà túmọ̀ sí pé ẹ ní ààyè sí okun àti agbára ìràpadà Rẹ̀.”9
Nítorínáà kínìdí tí a nṣahun pẹ̀lú àwọn àpáta wa? Kínìdí ti olùṣèré irú eré bọ́ọ̀lù kan tí ó ti rẹ̀ kọ̀ láti kúrò ní òkè nígbàtí olùrànlọ́wọ́ kan wà níbẹ̀ tí ó ṣetán láti parí eré náà? Kínìdí tí èmi yìó fi nìkan takú lórí ipò mi nígbàtí Olùrànlọ́wọ́ dúró ní síṣetán láti tọ́jú rẹ̀ pẹ̀lú mi?
Gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni, “Jésù Krístì … dúró pẹ̀lú ọwọ́ ṣíṣí sílẹ̀, ní ìrètí àti ìfẹ́ láti wòsàn, dáríjì, wẹ̀mọ́, fúnlókún, sọdi-ọ̀tun. àti yà wá sí mímọ́.”10
Nítorínáà kínìdí tí a fi takú láti nìkan máa gbé àwọn àpáta wa?
Ó jẹ́ níní lọ́kàn bíi ìbéèrè araẹni fún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín láti rò.
Fún mi, ó jẹ́ igbákejì ìgbéraga láti ìgbà-pípẹ́. “Mo ti ní èyí,” Mo sọ. “Kò sí ìyọnu; Èmi yìó sọ ọ́ di ṣíṣe. ” Ó jẹ́ ẹlẹ́tàn nlá tí ó fẹ́ kí nsápamọ́ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run, láti yípadà kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀, láti lọ nìkan ṣe é.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, èmi kò lè nìkan lọ ṣe é, àti pé èmi kò nílò bẹ́ẹ̀, èmi kì yíò si ṣeé. Ní yíyàn láti jẹ́ síso mọ́ Olùgbàlà mi, Jésù Krístì, nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú tí mo ti dá pẹ̀lú Ọlọ́run, “Mo lè ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ Kristi tí ó nfún mi lókun.”11
Àwọn olùpamọ́ májẹ̀mú jẹ́ alábùkún pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olùgbàlà.
Ronú lórí àpẹrẹ inú Ìwé ti Mọ́mọ́nì yí: Àwọn ènìyàn Alma ni a ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú “àwọn iṣẹ́-ṣíṣe lórí wọn, àti … àwọn olùṣàkóso iṣẹ́ lórí wọn.”12 Ní kíkà wọ́n léèwọ̀ láti gbàdúrà sókè, wọ́n “tú ọkàn wọn jáde sí [Ọlọ́run]; ó sì mọ ìrònú ọkàn wọn.”13
Ó sì ṣe tí “ohùn Olúwa tọ́ wọ́n wá nínú ìpọ́njú wọn, tí ó wípé: Ẹ gbé orí i yín sókè, kí ẹ sì tújúká, nítorítí èmi mọ̀ nípa májẹ̀mú tí ẹ̀yin ti dá pẹ̀lú mi; èmi yíò sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ènìyàn mi, èmi yíò sì gbà wọ́n kúrò nínú ìgbèkùn.
“Èmi yíò sì dẹ ẹrù tí a gbé lée yín ní éjìká, pé ẹ̀yin kò lè mọ̀ ọ́ lórí ẹ̀hìn nyín.”14
Àwọn ẹrù wọn ni a “sọ di fífúyẹ́,” àti pé “Olúwa sì fún wọn lókun kí wọ́n lè fi ìrọ̀rùn ru ẹrù wọn, wọ́n sì tẹrí ba pẹ̀lú ìdùnnú àti pẹ̀lú sùúrù fún gbogbo ìfẹ́ Olúwa.”15
Àwọn olùpamọ́ májẹ̀mú wọ̀nnì rí ìrànlọ́wọ́ ní irú ìtùnú, sùúrù àti inú dídùn tó pọ̀ síi, ìrọ̀rùn nínú àwọn ẹrù wọn kí wọ́n lè di fífúyẹ́, àti ìtúsílẹ̀ níkẹhìn.16
Báyìí ẹ jẹ́ kí á padà sí àfiwé àpò-ẹ̀hìn ti ara wa.
Ìrònúpìwàdà, nípasẹ̀ Ètùtù ti Jésù Krístì, ní ohun tí ó ràn wá lọ́wọ́ ní ti ìwúwo àwọn àpáta ẹ̀ṣẹ̀. Àti pé nípa ẹ̀bùn nlánlà yìí, àánú Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ àwọn ohun tó wúwo àti ní ìdàkejì àìṣeéṣe ti àwọn ìbéèrè ìdájọ́ òdodo.17
Ètùtù Jésù Kristi tún jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti gba okun láti dáríji, èyí tó gbàwá láàyè láti lè tú ẹrù tí a rù nítorí ìlòdìsí àwọn ẹlòmíràn.18
Njẹ́, báwo ni Olùgbàlà ṣe ràn wá lọ́wọ́ ní nú àwọn ẹrù ti gbígbé nínú ayé tí ó ti ṣubú pẹ̀lú àwọn ara kíkú tí ó wà lábẹ́ ìbànújẹ́ àti ìrora?
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, Ó nṣe irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ wa! Àwa bíi ọmọ ẹgbẹ́ májẹ̀mú ti Ìjọ Rẹ̀, a ṣèlérí “láti ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn tí nṣọ̀fọ̀” àti “láti tù àwọn tí wọ́n nílò ìtùnú nínú.”19 Nítorípé a “wá sínú agbo Ọlọ́run” a sì “npè wá ní ènìyàn rẹ̀,” a “múra tán láti ru àwọn ẹrù ọmọnìkejì wa, kí wọ́n lè fúyẹ́.”20
Ìbùkún májẹ̀mú wa ni láti ṣe àjọṣe pẹ̀lú Jésù Krístì ní pípèsè ìrànlọ́wọ́, ní ti ara àti ti ẹ̀mí, fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run. Awa jẹ ọ̀nà kan nípasẹ̀ èyí tí Ó npèsè ìrànlọ́wọ́.21
Àti bẹ́ẹ̀, bíi ti àwọn ọ̀rẹ́ ọkùnrin tí ó ní àrùn ẹ̀gbàá, a “ntu aláìlera lára, ngbé ọwọ́ tí ó relẹ̀ sókè, a sì nfún eékún àìlera lókun.”22 A “nru…ẹrù ọmọnìkejì wa, àti nípa bẹ́ẹ̀ a nmú òfin Krístì ṣẹ.”23 Bí a ti nṣe bẹ́ẹ̀, a ó mọ̀ Ọ́, a ó dàbí Rẹ̀, a ó sì rí ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀.24
Kíni ìrànlọ́wọ́ jẹ́?
Ó jẹ́ mímúkúrò tábì sísọ di fífúyẹ́ ti ohun kan tí ó ní ìrora, ní wàhálà, tàbí tí ó ndẹ́rù pa, tàbí agbára láti farada. Ó tọ́ka sí ẹnikan tí ó gba ipò ẹlòmíràn. Ó jẹ́ àtúnse lábẹ́ òfin ti àṣìṣe kan.25 Ọ̀rọ̀ Anglo-Faranse náà wá láti Faransé àtijọ́, ọ̀rọ̀ náà olùrànlọ́wọ́, tàbí “láti gbé dìde,” àti láti Latin relevare, tàbí “gbé dìde lẹ́ẹ̀kansi.”26
Ẹ̀yin arákùnrin àti ẹ̀yin arábìnrin, mo jẹ́rìí pé Jésù Krístì ni ìrànlọ́wọ́. Mo jẹ́ríì pé Ó jìnde lẹ́ẹ̀kansíi ní ijọ́ kẹ́ta àti pé, lẹ́hìn tí ó ti mú Ètùtù ìfẹ́ àti àìlópin ṣẹ, Ó dúró pẹ̀lú ọwọ́ ṣíṣí, tí ó nfúnwa ní ànfàní láti dìde lẹ́ẹ̀kansi, láti jẹ́ gbígbàlà, àti láti jẹ́ gbígbé ga àti láti dà bíi Tirẹ̀. Ìrànlọ́wọ́ tí Ó fúnni jẹ́ àìnípẹ̀kun.
Bíi ti àwọn obìnrin tí ángẹ́lì ṣe àbẹ̀wò sí ní òwúrọ̀ Ọjọ́ àjínde àkọ́kọ́, mo fẹ́ láti “yára lọ” àti pẹ̀lú “ayọ̀ nlá” láti mú ọ̀rọ̀ náà wá pé Ó ti jínde.27 Ní orúkọ ọmọ Rẹ̀ Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, àmín.