Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, bí a ti kede, nísisìyí èmi yíò gbé àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, àwọn Àádọ́rin Agbègbè, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò Ìjọ kalẹ̀ fún ìbò ìmúdúró yín.

Ẹ jọ́wọ́ e fi àtìlẹhìn yín hàn bí ẹ ti nṣe níbikíbi tí ẹ lè wà. Bí a bá rí àwọn wọ̀nni tí wọń tako eyikeyi nínú àwọn àbá, a bèèrè pé kí ẹ kàn sí ààrẹ èèkàn yín.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró Russell Marion Nelson bí wòlíì, aríran, àti olùfihàn àti Ààrẹ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn; Dallin Harris Oaks bí Olùdámọ̀ràn Kínní; àti Henry Bennion Eyring bí Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkinní.

Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.

Àwọn wọnnì tó bá tàkòó, tí ẹnikẹ́ni bá wà, lè fihàn.

A dalaba pé kí a ṣe imúdúró Dallin H. Oaks bí Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá àti M. Russell Ballard bí Aṣojú Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá.

Àwọn to bá faramọ, jọ̀wọ́ ṣàpẹrẹ.

Alátakò kankan tó bá wa lè fihàn.

A dalaba pé kí a ṣe imúdúró àwọn wọ̀nyí bí ọmọ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá: M. Russell Ballard, Jeffrey R. Holland, Dieter F. Uchtdorf, David A. Bednar, Quentin L. Cook, D. Todd Christofferson, Neil L. Andersen, Ronald A. Rasband, Gary E. Stevenson, Dale G. Renlund, Gerrit W. Gong, àti Ulisses Soares.

Àwọn tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Alátakò kankan lè fihàn bẹ́ẹ̀.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn olùdámọ̀ràn nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá bí àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Ìlòdì, bí èyíkéyi bá wá, nípa irú àmì kannáà.

Àwọn Aláṣẹ Gbogbo Àádọ́rin wọ̀nyí ni a ó dá sílẹ̀ kúrò nínú yíyàn síṣẹ́ wọn tí a ó sì fún wọn ní ipò àgbà, bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́ Ìkínní, Oṣù Kẹjọ, 2023: Àwọn Alàgbà Benjamín De Hoyos, Juan A. Uceda, àti Kazuhiko Yamashita.

Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ wa ní fífi ìmoore hàn sí àwọn arákùnrin wọ̀nyí àti ìyàwó wọn àti ẹbí wọn fún iṣẹ́-ìsìn ìfọkànsìn wọn káàkiri ayé lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìnawọ́ sókè.

Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a dásílẹ̀ kúro nínú ìyànsíṣẹ́ wọn, ní kíákíá: J. Kimo Esplin àti Alan T. Phillips.

Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ wa ní fífi ìmoore hàn sí àwọn arákùnrin wọ̀nyí fún iṣẹ́ ìsin wọn tó tayọ, jọ̀wọ́ fihàn.

A kíyèsi pẹ̀lú ìdúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Àádọ́rin Agbègbè tí wọ́n ti parí iṣẹ́-ìsìn wọn ní ọdún tí ó kọjá yí àti àwọn tí a lè rí orúkọ́ wọn ní ibi ayélujára Ìjọ.

Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ wa ní fífi ìmoore hàn sí àwọn arákùnrin wọ̀nyí fún iṣẹ́ ìsin títayọ lè fihàn.

Ní kíákíá, báyìí a dá àwọn arákùnrin Ahmad S. Corbitt àti Bradley Ray Wilcox sílẹ̀ kúrò ní sísìn bí Olùdámọ̀ràn Ìkínní àti Ìkejì nínú Àjọ Ààrẹ àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin.

Gbogbo ẹnití ó bá fẹ́ láti fi ìmoore hàn sí àwọn Arákùnrin wọ̀nyí fún iṣẹ́-ìsìn wọn lè fihàn bẹ́ẹ̀.

A nawọ́ ìdásílẹ̀ sí Àjọ Ààrẹ Gbogbogbò àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin láti Ọjọ́ Ìkínní Oṣù Kẹjọ, 2023 bí ìwọ̀nyí: Bonnie H. Cordon bí Ààrẹ, Michelle D. Craig bí Olùdámọ̀ràn Ìkínní, àti Rebecca L. Craven bí Olùdámọ̀ràn Ìkejì.

Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ wa ní fífi ìmoore hàn sí àwọn arábìnrin wọ̀nyí fún iṣẹ́ ìsin olùfọkànsìn wọn, jọ̀wọ́ fihàn.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn wọ̀nyí bí Aláṣẹ Gbogbogbò Àádọ́rin: Ahmad S. Corbitt, Robert M. Daines, J. Kimo Esplin, Christophe G. Giraud-Carrier, àti Alan T. Phillips.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Àwọn alátakò, nípa irú àmì kannáà.

A ṣe àkíyèsí pé àwọn Àádọ́rin Agbègbè titun mọ́kànlélọ́gọ́ta ni a múdúró nínú àwọn ìpàdé olórí àpapọ̀ gbogbogbò ní Ọjọ́bọ̀, Ọgbọnjọ́ Oṣù Kẹ́ta, lẹ́hìnnáà a kéde rẹ̀ sí orí ibi ayélujára Ìjọ.

A pè yín láti ṣe ìmúdúró àwọn arákùnrin wọ̀nyí nínú yíyàn síṣẹ́ wọn titun.

Àwọn tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Àwọn alátakò, nípa irú àmì kannáà.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn Àjọ Ààrẹ àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin Gbogbogbò titun, láti bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́ Kínní, Oṣù Kẹ́jọ, 2023: Emily Belle Freeman bí Àarẹ, Tamara Wood Runia bí Olùdámọ̀ràn Ìkínní, áti Andrea Muñoz Spannaus bí Olùdámọ̀ràn Ìkejì.

Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.

Alátakò kankan lè ṣe àmì bẹ́ẹ̀.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn Àjọ Ààrẹ àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin Gbogbogbò titun, láti bẹ̀rẹ̀ ní kíákíá: Bradley Ray Wilcox bí Olùdámọ̀ràn Ìkínní àti Michael T. Nelson bí Olùdámọ̀ràn Ìkejì.

Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.

Alátakò kankan lè ṣe àmì bẹ́ẹ̀.

A dalaba pé kí a ṣè ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò bí a ṣe gbé wọn kalẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa nínawọ́ sọ́kè.

Àwọn alátakò, to báwa.

A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, fún ìtẹ̀síwájú ìgbàgbọ́ yín àti àdúrà ní ìtìlẹhìn àwọn olórí Ìjọ.

Àwọn Ìyípadà sí Àwọn Àádọ́rin Agbègbè

Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a ṣe ìmúdúró fún nínú abala àwọn olórí kan tí a ṣe bí ara ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò:

Isaías Alcala, John D. Amos, Johnny O. Baddoo, Victor O. Bassey, Adrian Bettridge, A. Kaulle Bezerra, Carlos G. Cantero, Emerson B. Carnavale, Orlando A. Castaños, Bun Huoch Eng, Hutch U. Fale, Fernando R. García, Tomás García, C. Alan Gauldin, Aaron T. Hall, Darwin W. Halvorson, Jed J Hancock, Henry Herrera, Ndalamba Ilunga, Samuel M. T. Koivisto, Carlos J. Lantigua, Esau Lara, Stephen J. Larson, Thabo Lebethoa, G. Kenneth Lee, Israel Marin, Wayne E. Maurer, Lee G. McCann II, Robert Mendenhall, Adrian Mendez, Siyabonga Mkhize, Javier F. Monestel, Thomas B. Morgan, Jared V. Ormsby, Z. Rudy Palhua, Arturo D. Palmieri, Kenneth Pambu, Hugo O. Panameño, Kevin J. Parks, Paul Picard, David J. Pickett, Martin Pilka, Irineu E. Prado, Christopher R. Price, Miguel Ribeiro, James N. Robinson, Edward B. Rowe, Robert Schwartz, Gregory A. Scott, Dominic R. Sénéchal, Kofi G. Sosu, Michael B. Strong, Nithya Kumar Sunderraj, Thomas A. Thomas, Alejandro H. Treviño, Nefi M. Trujillo, Chimaroke G. Udeichi, Fernando Valdes, Helton C. Vecchi, Brent B. Ward, àti Tomasito S. Zapanta.

Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a ó dásílẹ̀ ní tàbí ṣíwájú Ọjọ́ Ìkínní, 2023:

Richard K. Ahadjie, Duane D. Bell, Hubermann Bien Aimé, Víctor R. Calderón, Michel J. Carter, Daniel Córdova, John N. Craig, William H. K. Davis, Fernando P. Del Carpio, Richard J. DeVries, Kylar G. Dominguez, Torben Engbjerg, Kenneth J. Firmage, Edgar Flores, Silvio Flores, Carlos A. Genaro, Mark A. Gilmour, Sergio A. Gómez, Roberto Gonzalez, Virgilio Gonzalez, Spencer R. Griffin, Marcel Guei, Oleksiy H. Hakalenko, Matthew S. Harding, David J. Harris, Kevin J. Hathaway, José Hernández, Glenn M. Holmes, Richard Neitzel Holzapfel, Okechukwu I. Imo, Michael D. Jones, Pungwe S. Kongolo, Ricardo C. Leite, Aretemio C. Maligon, Edgar A. Mantilla, Lincoln P. Martins, Carl R. Maurer, Daniel S. Mehr II, Glen D. Mella, Tomas S. Merdegia Jr., Allistair B. Odgers, R. Jeffrey Parker, Victor P. Patrick, Denis E. Pineda, Henrique S. Simplicio, Jeffrey H. Singer, Michael L. Staheli, Jeffrey K. Wetzel, Michael S. Wilstead, àti David L. Wright.

Tẹ̀