Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
A Nílò àwọn Onílàjà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


19:4

A Nílò àwọn Onílàjà

Ẹ ní agbára òmìnira yín láti yan ìjà tàbí ìlàjà. Mo rọ̀ yín láti yàn láti jẹ́ onílàjà, nísisìyí àti nígbàgbogbo.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ó jẹ́ ayọ̀ kan láti wà pẹ̀lú yín. Ní oṣù mẹ́fà tí ó kọjá, ẹ ti wà ní ọkàn mi àti nínú àdúrà mi lemọ́lemọ́. Mo gbàdúrà pé Ẹ̀mí Mímọ́ yíò sọ ohun tí Olúwa nfẹ́ kí ẹ gbọ́ bí èmi ṣe nbá yín sọ̀rọ̀.

Ní ìgbà ìkọ́ṣẹ́ iṣẹ́ abẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, mo ran oníṣẹ́ abẹ kan lọ́wọ́ ẹnití ó ngé ẹ̀sẹ̀ kan tí ó kún fún àrùn àkóràn púpọ̀ gidi. Iṣẹ́ abẹ náà le. Nígbànáà láti fikún àìbalẹ̀ ọkàn náà, ọ̀kan lára ẹgbẹ́ náà ṣe iṣẹ́ àìdáa kan, oníṣẹ́ abẹ náà si tújádé ní irunú. Ní àárín ìbínú rẹ̀, ó ju ọ̀bẹ iṣẹ́-abẹ rẹ̀ tí ó kún fún kòkòrò sílẹ̀. Ó dúró lórí iwájú-apá mi !

Gbogbo ènìyàn nínú yàrá iṣẹ́ abẹ—yàtọ̀ sí oníṣẹ́ abẹ tí kò ṣe pàrọwà sí—bẹ̀rù fún ewu ìrúfin ti iṣẹ́ abẹ yí. Pẹ̀lú ìmoore, èmì kó ní ìkọlù. Ṣùgbọ́n ìrírí yí fi ìtẹ̀mọ́ra pípẹ́ sí mi lára. Ní wákàtí náà gan, mo ṣe ìlérí fúnra mi pé ohunkóhun tí ó bá ṣẹlẹ̀ nínú yàrá iṣẹ́ abẹ mi , èmì kò ní sọ àkóso ẹ̀dùn ọkàn mi nù láé . Bákannáà mo ṣèlérí ní ọjọ́ náà láti máṣe ju ohun kankan sọnù nínú ìbínú láé—bóyá ó jẹ́ ọ̀bẹ iṣẹ́ abẹ tàbí àwọn ọ̀rọ̀ ìbínú.

Àní nísisìyí, ní àwọn díkédì lẹ́hìn náà, mo rí arami ní ríronú bí ọbẹ iṣẹ́ abẹ náà tí ó dúró lórí apá mi bá ti lóró ju ìjà olóró tí ó nyọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ti ìlú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbáṣepọ̀ lẹnu ní òní. Ìmọ́gbọ́nwá ti ìlú àti ìfínjú dàbí ẹnipé ó ti parẹ́ kúrò ní ìgbà ṣọ̀túnṣòsìn yí àti ìtara àwọn àríyànjiyàn.

Ìwà-lásán, àbùkù-wíwá, àti ìsọ̀rọ̀ ibi sí àwọn ẹlòmíràn gbogbo ti wọ́pọ̀ jù. Púpọ̀ jù àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n, òṣèlú, olùdánilárayá, àti àwọn onígbọ̀wọ́ míràn tí wọ́n nju àbùkù síni léraléra. Mo ní àníyàn gidi pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni ó dàbí pé wọ́n gbàgbọ́ pé ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láti dánilẹ́bi, ṣáátá, àti láti gan ẹnìkẹ́ni tí kò bá fara ḿọ wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ dàbí wọ́n nyára láti ba orúkọ ti ẹlòmíràn jẹ́ pẹ̀lú ìkẹdùn àti ẹnu ọ̀fà alágbára!

Ìbínú kòlè yínilọ́kan padà láé. Ìjà-gbangba kìí gbé ẹnikẹ́ni ga. Ìjà kò lè darí sí àbáyọ ìmísí. Pẹ̀lú àbámọ̀, a nrí ìwà ìjà nígbàmíràn àní nínú àwọn ipò ara wa. À ngbọ́ nípa àwọn wọnnì tí wọ́n nrẹ ọkọ tàbí aya àti àwọn ọmọ wọn sílẹ̀, tí wọ́n nlo ìtújáde ìbínú láti darí àwọn ẹlòmíràn, àti ti àwọn tí wọ́n nfiyàjẹ ọmọlẹ́bí wọn pẹ̀lú “ìtọ́jú ìpalọ́lọ́.” A gbọ́ nípa àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn ọmọdé tí wọ́n npaniláyà àti ti àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n nfi àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn ṣẹ̀sín.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, èyí kò gbọ́dọ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀. Bí àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì, a níláti jẹ́ àpẹrẹ bí a ó ti bá àwọn ẹlòmíràn lo—nípàtàkì nígbàtí a bá ní àwọn èrò inú tó yàtọ̀. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà ìrọ̀rùn láti mọ àtẹ̀lé tòótọ́ ti Jésù Krístì ni bí ẹni náà ti nṣe ìṣesí pẹ̀lú àánú sí àwọn ẹ̀nìyàn míràn.

Olùgbàlà mu èyí hàn kedere nínú àwọn ìwàásù Rẹ̀ ní àwọn àwòràn ìlàjì ayé méjèèjì. “Alábùkún fún ni onílàjà,” ni Ó wí.1 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbá ọ léti ọ̀tún, yí ti òsìn si pẹ̀lú.”2 Lẹ́hìnnáà, bẹ́ẹ̀ni, Ó sì fún wọn ní ìkìlọ̀ ti ó pe ẹnìkọ̀ọ̀kan wa níjà pé: “Ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín, ẹ súre fún àwọn ẹnití nfi yín ré, ẹ máa ṣe oore fún àwọn tí ó kórìra yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tí nfi àránkan bá yín lò, tí wọn sì nṣe inúnibíni sí yín.”3

Ṣíwájú ikú Rẹ̀, Olùgbàlà pàṣẹ fún àwọn Àpóstélì Méjìlá Rẹ̀ láti fẹ́ràn ara wọn bí Oùn ti fẹ́ràn wọn.4 Nígbànáà Ó fikun pé, “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yíò mọ̀ pé ẹ jẹ́ ọmọẹ̀hìn mi, tí ẹ bá fẹ́ràn ara yín.”34

Ọ̀rọ̀ Olùgbàlà hàn kedere pé: Àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ tòótọ́ ngbéga, ngbésókè, ngbàníyànjú, nyílọ́kànpadà, wọ́n sì nmísíni—bíotiwù kí ipò náà le tó. Àwọn ọmọẹ̀hìn tòótọ́ ti Jésù Kristì jẹ́ onílàjà.6

Òní ni Ọjọ́ Ìsinmi Ọpẹ. À nmurasílẹ̀ láti ṣe ayẹyẹ ìṣẹ̀lẹ̀ ọlọ́lá jùlọ tí a kọ́sílẹ̀ rí ní ayé, èyí tí ó jẹ́ Ètùtù àti Àjínde Olúwa Jésù Krístì. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà dídárajùlọ tí a fi lè bu ọlá fún Olùgbàlà ni láti di onílàjà.7

Ètùtù Olùgbàlà mu ṣeéṣe fún wa láti borí gbogbo ibi—pẹ̀lú ìjà. Máṣe ṣe àṣìṣe nípa rẹ̀: ìjà jẹ́ ibi! Jésù Krístì kéde pé àwọn tí wọ́n bá ní “ẹ̀mí ìjà” kĩ ṣe Tirẹ̀, ṣùgbọ́n “ti èṣù nií ṣe, ẹnití íṣe bàbá ìjà, [èṣù] sì máa nrnú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn rú sókè láti bá ara wọn jà pẹ̀lú ìbínú, ọ̀kan pẹ̀lú òmíràn.”8 Àwọn tí wọ́n nrú ìjà síta nmú ojú ewé kan jáde látinú ìwé-ìṣeré Sátánì, bóyá wọ́n dàmọ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. “Kò sí ẹnití ó lè sìn olúwa méjì.”9 A kò lè ti ètò Sátánì lẹ́hìn pẹ̀lú ìsọ̀rọ̀ èébú wa kí a sì rò pé a ṣì lè sin Ọlọ́run.

Ẹ̀yin arakùnrin àti arábìnrin mi, bí a ṣe nṣesí ara wa ṣe kókó! Bí a ṣe nsọ̀rọ̀ sí àti nípa àwọn ẹlòmíràn ní ilé, ní ilé ìjọsìn, ní ibi iṣẹ́, àti ní orí ayélujára ṣe kókó. Ní òní, mò nba wa sọ̀rọ̀ kí a ba àwọn elòmíràn ṣe ní ọ̀nà gíga si, mímọ́ si. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ fi etísílẹ̀ dáadáa. “Bí ohunkóhun bá jẹ́ ìwà rere, yẹ ní fífẹ́, tàbí ti ihìn rere tàbí yẹ fún yíyìn”10 èyí ni a lè sọ nípa ènìyàn míràn—bóyá sí ojú rẹ̀ tàbí ní ẹ̀hìn rẹ̀—èyí níláti jẹ́ òṣùwọn ìbárasọ̀rọ̀ wa .

Bí tọkọtayà kan ní wọ́ọ̀dù yín bá kọrasílẹ̀, tàbí ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere tètè padà sílé, tàbí ọ̀dọ́mọdé kan nṣiyèméjì ẹ̀rí rẹ̀, wọn kò nílò ìdájọ́ yín. Wọ́n nílò láti ní ìrírí ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ Jésù Krístì tí ó hàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ yín àti ìṣe.

Bí ọ̀rẹ́ kan lórí ìròhìn àwùjọ bá ní ìwòye tó lágbára ti òṣèlú tàbí ti ìbákẹ́gbẹ́ àwùjọ tí ó rú òfin ohun gbogbo tí ẹyin gbàgbọ́, ìbínú kan, tí ó ngé àlàyé kúrú nípa yín kò ní ṣe ìrànwọ́. Gbígbé afára ti níní ìmọ̀ ga yíò gba ọ̀pọ̀ púpọ̀ láti ọ̀dọ̀ yín, ṣùgbọ́n èyí gan ni ohun tí ọ̀rẹ́ yín nílò.

Ìjà nlé Ẹ̀mí kúrò—ní ìgbà gbogbo. Ìjà tún nmú èrò irọ́ wá pé ìdojúkọ ni ọ̀nà sí yíyanjú àwọn ìyàtọ̀; ṣùgbọ́n kìí ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. Ìjà jẹ́yíyàn kan. Lílàjà jẹ́ yíyàn kan. Ẹ ní agbára òmìnira yín láti yan ìjà tàbí ìlàjà. Mo rọ̀ yín láti yàn láti jẹ́ onílàjà, nísisìyí àti nígbàgbogbo.11

Ẹ̀yin arákùrnin àti arábìnrin, a lè yí ayé padà bí ọ̀rọ̀ gan—ẹnì kan àti ìbáraṣe kan ní àkokò kan. Báwo? Nípa ṣíṣe àwòṣebí a ti lè ṣe àkóso àwọn ìyàtọ̀ òtítọ́ ti èrò pẹ̀lú ìbámú ọ̀wọ̀ àti ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tó níyì.

Àwọn ìyàtọ̀ èrò jẹ́ ara ìgbé ayé. Mo nṣiṣẹ́ ní ojojúmọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Olúwa tí a yà sọ́tọ̀ tí wọn kìí wo ọ̀ràn ní ọ̀nà kannáà. Wọ́n mọ̀ pé mò nfẹ́ láti gbọ́ àwọn èrò wọn àti imọ̀lára òtítọ́ nípa ohun gbogbo tí à nsọ̀rọ̀ lé—nípàtàkì àwọn kókó ọ̀ràn.

Ààrẹ Dallin H. Oaks àti Ààrẹ Henry B. Eyring

Àwọn akọni olùdámọ̀ràn mi méjì, Ààrẹ Dallin H. Oaks àti Ààrẹ Henry B. Eyring, jẹ́ àpẹrẹ ní ọ̀nà tí wọ́n fi nfi àwọn ìmọ̀lára wọn hàn—ní pàtàkì nígbàtí wọ́n lè yàtọ̀. Wọ́n nṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ àìlábàwọ́n fún ara wọn. Ìkankan kò daba pé òun mọ̀ dáradára julọ àti nítorínáà ó gbọ́dọ̀ dá ààbò bo ipò rẹ̀ pẹ̀lú ìrorò. Ìkankan kò ṣe àfihàn ìnílò láti díje pẹ̀lú ìkejì. Nítorí ọ̀kọ̀ọ̀kan kún fún ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, “ìfẹ́ àìlábàwọ́n ti Krístì,”12 àwọn ìsọ̀rọ̀ wa lè ní ìdarí nípasẹ̀ Ẹ̀mí Olúwa. Mò ṣe fẹ́ràn tí mo sì bú ọlá fún àwọn ọkúnrin nlá méjì wọ̀nyí tó!

Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ni ẹ̀rọ̀ fún ìjà. Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ni ẹ̀bùn ti ẹ̀mí tí ó nràn wá lọ́wọ́ láti mú ènìyàn ẹlẹ́ran ara kúrò, ẹni tí ó ní ìmọ̀tara nìkan, onígbèjà, olùgbéraga, àti òjowú. Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ni kókó ìwà ti àtẹ̀lé tòótọ́ Jésù Krístì.13 Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ṣe ìtúmọ̀ onílàjà kan.

Nígbàtí a bá rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run tí a sì gbàdúrà pẹ̀lú gbogbo okun ọkàn wa, Ọlọ́run yíò fún wa ní ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́.14

Àwọn wọnnì tí a bùkún pẹ̀lú ẹ̀bùn títayọ yí a máa nní ìpamọ́ra àti àànú. Wọn kìí ṣe ìlara sí àwọn ẹlòmíràn àti pé wọn kìí ní ìtẹ̀mọ́ nínú ìṣe pàtàkì ti ara wọn. A kìí mú wọn bínú wọn kìí sì gbèrò ibi sí àwọn ẹlòmíràn.15

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ni ìdáhùn sí ìjà tí ó nṣe wá ní àìsàn ní òní. Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ nmú wa “ṣèrànwọ́ láti gbé àjàgà ẹnìkejì wa”16 dípò gbígbé àwọn àjàgà lé orí ara wa síi. Ìfẹ́ mímọ́ Krístì fi ààyè gbà wá “láti dúró bí ẹlẹri Ọlọ́run ní ìgbà gbogbo àti nínú ohun gbogbo”17nípàtàkì nínú àwọn ipò líle. Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ nfi ààyè gbà wá láti júwe bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin Krístì ti nsọ̀rọ̀ àti bí wọ́n ti nṣe—ní pàtàkì nígbàtí a bá wà lábẹ́ iná.

Nísisìyí, èmi kò sọ̀rọ̀ nípa “àláfíà ní iyekíye.”18 Mò nsọ̀rọ̀ nípa ṣíṣesí àwọn ẹlòmíràn ní àwọn ọ̀nà tí ó wà lemọ́lemọ́ pẹ̀lú pípa àwọn májẹ̀mú tí ẹ dá mọ́ nígbà tí ẹ bá ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa. A dá májẹ̀mú láti rántí Olùgbàlà nígbàgbogbo. Nínú àwọn ipò tí ó lágbára gidi tí ó sì kún fún ìjà, mo pè yín láti rántí Jésù Krístì. Ẹ gbàdúrà láti ní ìgboyà àti ọgbọ́n láti sọ tàbí ṣe ohun tí Òun ó ṣe. Bi a ti ntẹ̀lé Ọba Àláfíà, a ó di àwọn onílàjà Rẹ̀.

Ní ojú àmì yí ẹ lè máa ronú pé ọ̀rọ̀ yí yíò ran ẹnìkan tí ẹ mọ̀ lọ́wọ́ lódodo. Bóyá ẹ nretí pé yíò ràn arákùnrin tàbí arábìnrin lọ́wọ́ láti di rere síi fún yín. Mo mọ̀ pé yíò ri bẹ́ẹ̀! Ṣùgbọ́n bákannáà mo ní ìrètí pé ẹyin yíò wòó jinlẹ̀ nínú ọkàn yín láti rí bí èérún ìgbéraga tàbí owú jíjẹ ti ndí yín lọ́wọ́ láti di onílàjà.19

Bí ẹ bá rònú nípa ṣíṣe ìrànwọ́ láti kó Ísráẹ́lì jọ àti nípa gbígbé àwọn ìbáṣepọ̀ tí yíò dúró títí ayérayé ga, nísisìyí ni àkokò náà láti gbé ìkorò sẹgbẹ. Nísisìyí ni àkokò láti dáwọ́dúró ní ìtẹnumọ́ pé ọ̀nà yín ni kó jẹ́ tàbí kò sí ọ̀nà rárá. Nísisìyí ni àkokò láti dá àwọn ohun tí ó nmú àwọn míràn rìn lórí àwọn èèpo-ẹyin fún ẹ̀rù mímú yín bínú dúró. Nísisìyí ni àkokò láti ri àwọn ohun ìjà ogun mọ́lẹ̀.20 Bí àkójọ ìsọ̀rọ̀ yín bá kún fún àwọn èébú àti ẹ̀sùn, nísisìyí ni àkokò láti gbé wọn kúrò.21 Ẹyin yíò dìde bí alágbára nípa tẹ̀mí ọkùnrin tàbí obìnrin ti Krístì.

Tẹ́mpìlì lè ràn wá lọ́wọ́ nínú ìgbèrò wa. Níbẹ̀ ni a ti nfún wa ní ẹ̀bùn pẹ̀lú agbára Ọlọ́run, tí ó nfún wa ní okun láti borí Sátánì, olùdẹsí gbogbo ìjà.22 Ẹ lé e jáde nínú àwọn ìbáṣepọ̀ yín! Bákannáà ẹ kíyèsí pé a nbá ọ̀tà wí nígbà gbogbo tí a wo èdè-àìyédè kan sàn tàbí kọ̀ láti mú ìbínú. Dípò bẹ́ẹ̀, a lè fi àánú ìrọ́nú tí ó jẹ́ ìwà ọmọẹ̀hìn tòótọ́ ti Jésù Krístì hàn. Àwọn Olùlàjà ntú ọ̀tá ká.

Ẹ jẹ́ kí àwà bí ènìyàn kan di ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ lórì òkè—ìmọ́lẹ̀ tí kò “lè di fífi pamọ́.”23 Ẹ jẹ́ kí a fihàn pé ọ̀nà tó ní ọ̀wọ̀ kan wà láti yanjú àwọn ọ̀ràn líle àti ọ̀nà òye láti ṣe àwọn àríyànjiyàn wa. Bí ẹ ti njúwe ifẹ́ àìlẹ́gbẹ́ tí àwọn àtẹ̀lé Jésù Krístì nfihàn, Olúwa yíò gbé àwọn ìtiraka yín ga kọjá èrò gíga yín.

Àwọ̀n ìhìnrere ni àwọ̀n títóbi jùlọ ní ayé. Ọlọ́run pe gbogbo ènìyàn láti wá sọ́dọ̀ Rẹ̀, “dúdú àti funfun, òndè àti òmìnira, akọ àti abo.”17 Àyè wà fún gbogbo ènìyàn. Bákannáà, kò sí ààyè kankan fún ẹ̀tanú, ìdálẹ́bi, tàbí ìjà eyikeyi.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, dídárajùlọ ṣì nbọ̀wá fún àwọn tí wọn nlo ìgbé ayé wọn láti gbé àwọn ẹlòmíràn ga. Ní òní mo pè yín láti yẹ ipo ọmọlẹ́hìn yí wò nínú ọ̀nà ìṣesí yín gan sí ẹlòmíràn. Mo bùkún yín làti ṣe àwọn àtúnṣe tí ẹ lè nílò kí ìwà yín lè jẹ́ bíbọlá-fún, pẹ̀lú ọ̀wọ̀, àti àtẹ̀lé aṣojú Jésù Krístì tòótọ́.

Mo bùkún yín láti rọ́pò ogun pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀, aáwọ̀ pẹ̀lú níní ìmọ̀, àti ìjà pẹ̀lú àánú.

Ọlọ́run wà láàyè! Jésù ni Krístì. Ó dúró ní orí Ìjọ Rẹ̀. Àwa ni Ìránṣẹ́ Rẹ̀. Òun yíò ràn wá lọ́wọ́ láti di àwọn olùlàjà Rẹ̀. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.