Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Níní-ààyè sí Agbára Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn Májẹ̀mú
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


13:9

Níní-ààyè sí Agbára Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn Májẹ̀mú

Bí ẹ ti nrìn ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú, látinú ìrìbọmi sí tẹ́mpìlì àti ní gbogbo ayé, èmi ṣe ìlérí agbára fún yín láti lọ ní ìlòdì sí ìṣàn àdánidá ti ayé.

Ní Oṣù Kọkànlá tó kọjá, mo ní ànfàní yiya Tẹ́mpìlì Belém Brazil sí mímọ́. Ó ayọ̀ kan láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ìjọ tí a yàsọ́tọ̀ ní ìhà àríwá Brazil tí a yà sọ́tọ̀. Ní àkokò náà, mo kọ́ pé Belém ni ọ̀nà-tààrà sí odò alágbára jùlọ ní àgbáyé, Odò Amazon.

Pẹ̀lú agbára odò náà, ẹ̀ẹ̀mejì lọ́dun, ohunkan tí ó dàbí àìjẹ́ àdánidá nṣẹlẹ̀. Nígbàtí òòrùn, òṣùpá, àti ilẹ̀ ayé wà ní ìbámu bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ìjì olómi alágbára tí ó nṣàn sókè odò, ní ìlòdì sí ìṣàn àdánidá ti omi náà. Ìjì mítà gíga mẹ́fà1 tí ó nrìn jìnnà tó bíi àwọn àádọ́ta kilómítà2 lílọsókè ni a ti kọ sílẹ̀. Ohun asán yí, tí a mọ̀ káàkiri bíi ihò olómi kan, ni à nkàsí pororokà, ni ti ìbílẹ̀ tàbí “híhó nlá” nítorí ti aruwo tí ó npa. A lè parí déédé pé àní Amazon alágbára gbọ́dọ̀ yọ̀ọ̀dà sí àwọn agbára tọ̀run.

Gẹ́gẹ́bí Amazon, a ní ìṣàn àdánidá sí ìgbé ayé wa; a sí ní láti ṣe ohun tí ó nwá tinútinú. Bíiti Amazon, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ tọ̀run a lè ṣe àwọn ohun tí ó dàbí àìjẹ́ àdánidá. Lẹ́hìn gbogbo rẹ̀, kìí ṣe àdánidá fún wa láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ọlọ́kàn tútù, tàbí ní ìfẹ́ láti jọ̀wọ́ àwọn ìfẹ́ wa sí ti Ọlọ́run. Síbẹ̀síbẹ̀ ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nìkan ni a lè di yíyípadà, kí a padà láti gbé ní iwájú Ọlọ́run, kí a sì ṣe àṣeyege àyànmọ́ ìpín ayérayé wa.

Láìdàbí Amazon, a lè yàn bóyá a ó yọ̀ọ̀dà sí àwọn agbára tọ̀run tàbí “kí a lọ pẹ̀lú ìṣan náà.”3 Lílọ ní ìlòdì sí ìṣàn náà lè ṣòrò. Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá yọ̀ọ̀da “sí àwọn ìdùnmọ́ni ti Ẹ̀mí Mímọ́” kí a sì mú àwọn ìtẹ́sí ìmọ̀tara-ẹni-nìkan ti ọkùnrin tàbí obìnrin ti ẹlẹ́ran ara kúrò,4 a lè gba agbára ìyípadà Olùgbàlà sínú ayé wa, agbára láti ṣe àwọn ohun tó ṣòro.

Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ wa bí a ó ti ṣe èyí. Ó ṣe ìlérí pé, “Ẹni kọ̀ọ̀kan tí ó ba dá àwọn májẹ̀mú nínú omi ìrìbọmi àti nínú àwọn tẹ́mpìlì—tí ó sì pa wọ́n mọ́—ní ààyè púpọ̀ sí agbára Jésù Krístì … [láti gbé] wa ga kọjá fífà ti ìṣubú ayé yí.”5 Ní ọ̀rọ̀ míràn, a lè ní ààyè sí agbára Ọlọ́run, Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá somọ́ Ọ nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú mímọ́ nìkan.

Ṣíwájú kí a tó dá ilẹ̀ ayé, Ọlọ́run gbé àwọn májẹ̀mú kalẹ̀ bí ṣíṣètò nípa èyí tí a ó da arawa pọ̀ mọ́ Ọ. Dídá lórí ayérayé, òfin àìyípadà, Ó fi àwọn ipò tí a ko lè dúnádúrà níbití a ti yípadà, ní ìgbàlà, àti ìgbéga hàn. Nínú ayé yí, a lè dá àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí nípa kíkópa nínú àwọn ìlànà oyè-àlùfáà kí a sì ṣe ìlérí láti ṣe ohun tí Ọlọ́run bá ni kí a ṣe, àti ní ìgbẹ̀hìn, Ọlọ́run ṣe ìlérí àwọn ìbùkùn kan pàtó fún wa.6

Májẹ̀mú kan ni ẹ̀jẹ́ pé a níláti múrasílẹ̀ fún, ní òye kedere, àti iyì tán pátápátá.7 Dídá májẹ̀mú kan pẹ̀lú Ọlọ́run yàtọ̀ sí ṣíṣe ìlérí lásán. Àkọ́kọ́, àṣẹ oyè-àlùfáà ni a nílò. Ìkejì, ìlérí àìlera kò ní okun ìsopọ̀ láti gbé wa ga kọjá fífà ìṣàn àdánidá. A ndá májẹ̀mú nìkàn nígbàtí a bá nwá láti gbé arawa lé yíyàtọ̀ gan láti múu ṣẹ.8 A ndi àwọn ọmọ májẹ̀mú Ọlọ́run àti ajogún ìjọba Rẹ̀, nípàtàkì nígbàtí a bá fi arawa sí ìbámu pátápátá pẹ̀lú májẹ̀mú náà.

Ọ̀ràn náà ipa-ọ̀nà májẹ̀mú tọ́ka sí onírurú àwọn májẹ̀mú níbití a ti nwá sọ́dọ̀ Krístì tí a sì sopọ̀ sí I. Nípasẹ̀ sísopọ̀ májẹ̀mú yí, a ní ààyè sí agbára ayérayé. Ipa-ọ̀nà nbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti ìrònúpìwàdà, tí ìrìbọmi àti gbígba Ẹ̀mí Mímọ́ tẹ̀lé.9 Jésù Krístì fi bí a ó ti wọ ipa-ọ̀nà náà hàn wá nígbàtí Òun ṣe ìrìbọmi.10 Gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ Májẹ̀mú Titun Ìhìnrere nínú Márkù àti Lúkù, Baba Ọ̀run sọ̀rọ̀ tààrà sí Jésù níbi ìrìbọmi Rẹ̀, wípé, “Èyí ni àyànfẹ́ Ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.” Nígbàtí a bá bẹ̀rẹ̀ lórí ipa-ọ̀nà májẹ̀mú nípasẹ̀ ìrìbọmi, mo lè ròó tí Baba Ọ̀run nwí irú ohun kannáà sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa: “Èyí ni ọmọ mi ọ̀wọ́n tí inú mi dùn sí. Tẹramọ́ lílọsíwájú.”11

Níbi ìrìbọmi àti nígbàtí a bá nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa,12 à njẹri pé a ní ìfẹ́ láti gbé orúkọ Jésù Krístì lé orí arawa.13 Nínú ọ̀rọ̀ yí, ẹ jẹ́ kí a ṣọ́ra nípa òfin Májẹ̀mú Láéláé, “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ lásán.”14 Sí àwọn etí-ìgbọ́ wa òní, èyí lè dún bí ìdínàmọ́ ní ìlòdì sí àìní-ọ̀wọ̀ lílo orúkọ Olúwa. Òfin náà pẹ̀lú pé, ṣùgbọ́n àní ìlànà rẹ̀ jinlẹ̀ si. Ọ̀rọ̀ Hébérù ṣe ìyírọ̀pada-èdè náà bí “mú” tí ó túmọ̀sí láti “gbé sókè” tàbí “gbé,” bí ẹnìkan yíò ti ṣe àsíá tí ó nfi olùgbé hàn pẹ̀lú ẹgbẹ́ kan tàbí ẹnìkọ̀ọ̀kan.15 Ọ̀rọ̀ náà tì a yípadà bí “òfò” tí ó túmọ̀sí “òfo” tàbí “ẹ̀tàn.”16 Òfin náà kí a maṣe pe orúkọ Olúwa lásán le túmọ̀ sí báyìí, “Ẹ kò gbọ́dọ̀ rí ara yín bí ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì àyàfi tí ẹ bá nwá láti ṣe aṣojú Rẹ̀ dáadáa.”

A ndi àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ a sì nṣojú Rẹ̀ dáadáa nígbàtí a bá mọ̀ọ́mọ̀ tí a si fi ọ̀pọ̀ gbé orúkọ Jésù Krístì lé orí arawa nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú. Àwọn májẹ̀mú nfún wa ní agbára láti dúró lórí ipa-ọ̀nà májẹ̀mú nítorí ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Jésù Krístì àti Baba wa Ọ̀run a yípadà. A wà ní ìsopọ̀ sí Wọn nípasẹ̀ sísopọ̀ ti májẹ̀mú kan.

Ipa-ọ̀nà májẹ̀mú ndarí sí àwọn ìlànà tẹ́mpìlì, bí irú ìfúnni-ní ẹ̀bùn tẹ́mpìlì.17 Ìfúnni-ní ẹ̀bún tẹ́mpìlì ni ẹ̀bùn Ọlọ́run ti àwọn májẹ̀mú mímọ́ tí ó so wá pọ̀ mọ́ Ọ si ní kíkún. Nínú ìfunni ní ẹ̀bùn agbára, a dá májẹ̀mú láti tiraka láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, ìkejì, láti ronúpìwàdà pẹlú ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀; ìkẹ́ta, láti gbé ìgbé ayé ìhìnrere ti Jésù Krístì. À nṣe èyí nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀, dídá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run bí a ti gba àwọn ìlànà ìgbàlà àti ìgbéga, ní pípa àwọn májẹ̀mú wọnnì mọ́ ní gbogbo ayé wa, kí a sì tiraka láti gbé àwọn òfin nlá méjì láti fẹ́ràn ọlọ́run àti aladugbo. Ìkẹ́rin, à, ndá májẹ̀mú láti pa òfin ìparaẹnimọ́ mọ́, àti, ikarun, láti ya arawa sọ́tọ̀ àti ohungbogbo tí Olúwa fi bùkún wa pẹ̀lú gbígbé Ìjọ Rẹ̀ ga.18

Nípa dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì mọ́, a kọ́ nípa àwọn èrò Olúwa a sì gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́.19 A ngba ìdarí fún ìgbé ayé wa. A ndàgbà nínú ipò-ọmọlẹ́hìn wa kí a má baà dúró bí àwọn ọmọ aláìmọ̀kan.20 Jù bẹ́ẹ̀, kí a gbé pẹ̀lú ìwò ayérayé kí a sì ní ìwúrí si láti sin Ọlọ́run àti àwọn míràn. A ngba àníkún okun láti mú àwọn èrò wa ṣẹ nínú ayé ikú. À nní ààbò kúrò nínú ibi,21 a sì njèrè agbára títóbi jù sí àtakò àdánwò kí a sì ronúpìwàdà nígbátí a bá kọsẹ̀.22 Nígbàtí a bá ṣìnà, ìrántí àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú Ọlọ́run nrànwá lọ́wọ́ láti padà sí ipa ọ̀nà. Nípa sísopọ̀ mọ́ agbára Ọlọ́run, à ndi pororoca, ara wa kí a lè lòdì sí ìṣàn ayé, ní gbogbo ìgbé ayé wa àti sí àwọn ayérayé. Nígbẹ̀hìn, àwọn àyànmọ́ ìpín wa nyípadà nítorí ipa ọ̀nà májẹ̀mú tí ó ndarí sí ìgbéga àti ìyè ayérayé.23

Pípa àwọn májẹ̀mú tí a dá nínú omi ìrìbọmi àti nínú àwọn tẹ́mpìlì mọ́ bákannáà npèsè wa pẹ̀lú okun láti kojú àwọn ìdánwò àti ìrora ayé ikú.24 Ẹ̀kọ́ tí ó wà pẹ̀lú àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí nmú ọ̀nà wa rọrùn ó sì npèsè ìrètí, ìtùnú, àti àláfíà.

Àwọn òbí-òbí mi Lena Sofia àti Matts Leander Renlund gba agbára Ọlọ̀run nípasẹ̀ májẹ̀mú ìrìbọmi wọn nígbàtí wọ́n darapọ̀ mọ́ Ìjọ ní 1912 ní Finland. Inú wọn dùn láti jẹ́ ara ẹ̀ka àkọ́kọ́ ti Ìjọ ní Finland.

Leander kú látinú ikọ-fée ní ọdún marun sẹ́hìn nígbàtí Lena ní oyún pẹ̀lú ọmọ kẹwa wọn. Ọmọ náà, baba mi, ni a bí ní oṣù kejì lẹ́hìn ikú Leander. Nígbẹ̀hìn Lena kò sin ọkọ rẹ̀ nìkan lásán ṣùgbọ́n méje lára àwọn ọmọ rẹ̀ mẹwa. Bí tálákà opó kan, ó làkàkà. Fún ogun ọdún òun kò ní ìsinmi alẹ́ rere. Ní ojú ọjọ́, ó rápálá láti pèsè oúnjẹ fún ẹbí rẹ̀. Ní alẹ́, ó ntọ́jú àwọn ọmọ ẹbí tí wọ́n nkú lọ. Ó nira láti ronú bí òun ó ti jàjàbọ́.

Lena faradà nítorí ó mọ̀ pé olóògbé ọkọ rẹ̀ àti àwọn ọmọ lè jẹ́ tirẹ̀ nínú àwọn ayérayé. Ẹ̀kọ́ ti àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì, pẹ̀lú ti àwọn ẹbí ayérayé, mú àláfíà wá fun nítorí ó nígbẹ́kẹ̀lẹ́ nínú agbára edidì. Nígbàtí ó wà nínú ayé ikú, òun kò gba ẹ̀bùn agbára tàbí kí a fi èdidì dìí sí Leander, ṣùgbọ́n Leander dúró títí bí okun pàtàkì nínú ayé rẹ̀ àti apàkan ìrètí nlá rẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la.

Ní 1938 Lena fi àwọn àkọsílẹ̀ ṣọwọ́ kí a lè ṣe àwọn ìlànà tẹ́mpìlì fún àwọn ọmọ ẹbí rẹ̀ olóògbé, àwọn kan tí a fi ṣọwọ́ ṣíwájú láti Finland. Lẹ́hìn tí ó kú , a ṣe àwọn ìlànà tẹ́mpìlì nípasẹ̀ àwọn míràn fún un, Leander, àti àwọn ọmọ rẹ̀ olóògbé. Nípa ìrọ́pò, ó gba ẹ̀bùn agbára, Lena àti Leander ni a fi èdidì dì sí ara wọn, àti àwọn ọmọ wọn olóògbé àti baba mi ni a sì fi èdidì di sí wọn. Bíiti àwọn míràn, Lena “kú sínú ìgbàgbọ́, lái gba àwọn ìlérí, ṣùgbọ́n ní rírí wọn níwájú, … [ó] rọ̀ wọ́n, ó sì gbà wọ́n mọ́ra.”25

Lena gbé bí ẹnipé òun ti dá àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí nínú ayé rẹ̀. Ó mọ̀ pé ìrìbọmi rẹ̀ àti àwọn májẹ̀mú oúnjẹ Olúwa so ó mọ́ Olùgbàlà. Ó “jẹ́ kí àdùn wíwá ibi mímọ́ [ti Olùràpadà] mú ìrètí wá sí ọkàn ìsọdahoro [rẹ̀].”26 Lena rò ó bí ọ̀kan lára àánú nlá Ọlọ́run tí ó kọ́ nípa àwọn ẹbí ayérayé ṣíwájú níní ìrírí àwọn àjálù nínú ayé rẹ̀. Nípasẹ̀ májẹ̀mú, ó gba agbára Ọlọ́run láti ní ìfaradà tí ó sì dìde kọjá ìrẹ̀wẹ̀sì fífà àwọn ìpènijà àti ìṣòrò rẹ̀.

Bí ẹ ti nrìn ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú, látinú ìrìbọmi sí tẹ́mpìlì àti ní gbogbo ayé, èmi ṣe ìlérí agbára fún yín láti lọ ní ìlòdì sí ìṣàn àdánidá ti ayé—agbára láti kọ́, agbára láti ronúpìwàdà, àti agbára láti di yíyàsí mímọ́, àti agbára láti rí ìrètí, ìtunú, àní àti ayọ̀ bí ẹ ti ndojúkọ àwọn ìpènijà ìgbé ayé. Mo ṣe ìlérí ààbò fún yín àti ẹbí yín ní ìlòdì sí agbára èṣù, nípàtàkì nígbàtí ẹ bá mú tẹ́mpìlì jẹ́ kókó ìdojúkọ nínú ayé yín.

Bí ẹ ti nwá sọ́dọ̀ Krístì tí ẹ sì nso mọ́ Ọ àti Baba wa Ọ̀run nípa májẹ̀mú, ohunkan tí ó dàbí àìjẹ́ àdánidá nṣẹlẹ̀. Ẹ ti di yíyípòpadà ẹ sì ti di pípé nínú Jésù Krístì.27 Ẹ di àwọn ọmọ májẹ̀mú Ọlọ́run àti àwọn ajogún nínú ìjọba Rẹ̀.28 Mo lè rò Ó tí ó nwí fún yín pé, “Èyí ni ọmọ mi ọ̀wọ́n ẹnití inú mi dùn sí gidigidi. Káàbọ̀ sílé.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Bíi ogun ẹsẹ̀.

  2. Bíi ọgbọ̀n máìlì.

  3. A ní àṣàyàn kan nítorí Ọlọ́run ti fún wa ní ànfàní láti yàn àti láti ṣe ìṣe fún arawa. Ẹ wo Ìtọ́nisọ́nà sí àwọn Ìwé-mímọ́, “Agbára Òmìnira,” scriptures.ChurchofJesusChrist.org; 2 Nefi 2:27; Mose 7:32.

  4. Wo Mòsíàh 3:19

  5. Russell M. Nelson, “Ẹ Ṣẹ́gun Ayé kí ẹ sì Rí Ìsinmi,” Liahona, Nov. 2022, 96, 97.

  6. Wo Ìtọ́sọ́nà sí àwọn Ìwé Mímọ́, “Májẹ̀mú,” scriptures.ChurchofJesusChrist.org.

  7. Gbogbo ènìyàn máa nṣubú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ní sùúrù pẹ̀lú àwọn ìṣubú wa ó sì ti fún wa ní ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà àní lẹ́hìn jíjá májẹ̀mú kan. Bí Alàgbà Richard G. Scott ti kọ́ni, “Olúwa nrí àwọn àìlèra ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ju bí Ó ti [nrí] ìṣọ̀tẹ̀ … [nítorí] nígbàtí Olúwa bá sọ̀rọ̀ àwọn àìlera, ó jẹ́ pẹ̀lú àánú nígbàgbogbo” (“Okun Araẹni nípasẹ̀ Ètùtù Jesù Krístì,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2013, 83). Bayi, a kò níláti ṣiyèméjì nípa agbára Olùgbàlà láti ràn wá lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn àìlera wa. Bákannáà, fífi ìfura já májẹ̀mú pẹ̀lú ètò ọkàn líle láti ronúpìwàdà lẹ́hìnwá—ní ọ̀rọ̀ míràn, àròtẹ́lẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrònúpìwàdà—jẹ́ ìlòdì sí Olúwa (wo Heberu 6:4–6).

  8. Wo Robert Bolt, Ọkùnrin Kan fún Gbogbo Àkokò: Eré Kan nínú àwọn Ìṣe Méjì (1990), xiii–xiv, 140.

  9. Wo 2 Néfì 31:17–18.

  10. Wo 2 Néfì 31:4–15.

  11. Lúkù ṣe àkọsílẹ̀, “Ẹ̀mí mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan si ti ọ̀run wá, tí ó wípé, ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi” (Luku 3:22). Márkù ṣe àkọsílẹ̀, “Ohùn kan sì ti ọ̀run wá, wípé, Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi” (Marku 1:11). Àní ìyírọ̀padà ti William Tyndale’s hàn si ó sì farapẹ ju Ẹ̀yà king James. Nínú ìyírọ̀padà rẹ̀, ohùn Baba Ọ̀run wípé, “Èyí ni àyànfẹ́ Ọmọ mi ẹni tí inú mi dùn sí” (Brian Moynahan, God’s Bestseller: William Tyndale, Thomas More, àti Kíkọ Bíbélì Èdè-Gẹ̀ẹ́sì—Ìtàn Kan nípa Ìpànìyàn àti Ìfihàn [2002], 58). Matteu nìkan ròhìn pé ohùn náà ni a darí káàkiri, wípé, “Sì kíyèsi ohùn kan láti ọ̀run, wípé, Èyí ni àyànfẹ́ Ọmọ mi ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi” (Máttéù 3:17). Ìhìnrere Johánù nìkan ròhìn nípa ìrìbọmi láti ọwọ́ Jòhánù Onítẹ̀bọmi: “Èmi sì ti ri, èmi sì ti jẹri pé èyí ni Ọmọ Ọlọ́run” (Johanu 1:34).

  12. Wo 2 Nefì 31:13; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20:77.

  13. Ààrẹ Dallin H. Oaks ṣe àlàyé pàtàkì nípa ọ̀ràn náà “ní ìfẹ́” bí a ti ntún májẹ̀mú ìrìbọmi wa ṣe pẹ̀lú oúnjẹ Olúwa: “Ó ṣe kókó pé nígbàtí a bá nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa kí a máṣe jẹri pé kí a gbé orúkọ Jésù Krísti lé orí wa. À njẹri pé a ní ìfẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. [Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20:77.] Òtítọ́ náà pé a njẹri sí ìfẹ́ wa nìkan ndá àbá pé ohunkan míràn ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú kí a tó gbé orúkọ mímọ́ náà lé orí wa nínú ọgbọ́n pàtàkì jùlọ” (“Gbígbé Orúkọ Jésù Krístì Lé Orí Ara Wa,” Ẹ́nsáìnì, May 1985, 81). Ohun “kan míràn” tọ́ka sí àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì àti ìgbéga ọjọ́-ọ̀la.

  14. Ẹ́ksódù 20:7.

  15. Wo James Strong, The New Strong’s Expanded Exhaustive Concordance of the Bible (2010), Greek dictionary section, number 2189.

  16. Wo James Strong, The New Strong’s Expanded Exhaustive Concordance of the Bible, Hebrew dictionary section, page 273, number 7723.

  17. Alàgbà David A. Bednar kọ́ni: “Májẹ̀mú ìrìbọmi lérò ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la kedere tàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó sì nwo iwájú sí tẹ́mpìlì. … Ètò ti gbígbé orúkọ Jésù lé orí arawa tí ó bẹ̀rẹ̀ nínú omi ìrìbọmi ntẹ̀síwájú ó sì ngbòòrò nínú ilé Olúwa. Bí a ti dúró nínú omi ìrìbọmi, a nkọjú sí tẹ́mpìlì. Bí a ti nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa, a nkọjú sí tẹ́mpìlì. A jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti ránti Olùgbàlà nígbàgbogbo kí asì pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ bíi mímúrasílẹ̀ láti kópa nínú àwọn ìlànà mímọ́ ti tẹ́mpìlì àti láti gba àwọn ìbùkún gíga jùlọ tí ó wà nípasẹ̀ orúkọ àti nípa àṣẹ ti Olúwa Jésù Krístì. Bayi, nínú àwọn ìlànà tẹ́mpìlì mímọ́ à ngbé orúkọ Jésù Krístì pátápátá àti ní kíkún si” (“Dídi Orúkọ Kan Mú Pẹ̀lú Ọ̀wọ̀ àti Dídúró,” Liahona, May 2009, 98). Ètò náàlè má parí títí “a ó fi dàbí rẹ̀” (Mórónì 7:48), nígbàtí a bá ti yípadà ní kíún.

  18. Bí a yi ṣe àlàyé nínú Ìwé Ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 27.2 (ChurchofJesusChrist.org), àwọn májẹ̀mú ni láti gbé ìgbé ayé òfin ti ìgbọràn, gbọ́ran sí òfin ìrúbọ, gbọ́ran sí òfin ìhìnrere Jésù Krístì, pa òfin ìparaẹnimọ́ mọ́, kí ẹ sì pa òfin ìyàsọ́tọ̀ mọ́; bákannáà ẹ wo David A. Bednar “Ẹ Jẹ́ Kí Ilé Yí Di Kíkọ́ sí Orúkọ Mi,” Liahona, May 2020, 84–87.

  19. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 109:14-15. Alàgbà D. Todd Christofferson kọ́ni, “Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ‘Ẹ̀mí Mímọ́’ pẹ̀lú ohun tí Jésù júwe bíi ‘ìlérí ìyè ayérayé èyí tí mo fi fún un yín, àní ògo ìjọba sẹ̀lẹ́stíà; ògo èyí tí ó jẹ́ ti ìjọ Àkọ́bí, àní ti Ọlọ́run, Ẹni mímọ́ jùlọ, nípasẹ̀ Jésù Krístì Ọmọ rẹ̀’ (D&C 88:4–5)” (“Agbára Àwọn Májẹ̀mú,” Liahona, May 2009, 23, note 5).

  20. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 109:15.

  21. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 109:22, 25-26.

  22. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 109:21.

  23. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 109:15, 22; Russell M. Nelson, “Agbára Àkokò Ti Ẹ̀mí,” Liahona, May 2022, 98.

  24. Wo Russell M. Nelson,”Bíborí Ayé àti láti Wá Ìsinmi,” 96; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:20. Gbogbo ìgbà tí ẹ bá wá láti tẹ̀lé àwọn ìṣílétí Ẹ̀mí, gbogbo ìgbà tí ẹ bá ṣe ohunkóhun rere—àwọn ohun tí “ènìyàn ẹlẹ́ran ara” kò lè ṣe, ẹ̀ nṣẹ́gun ayé” (“Bíborí Ayé àti láti Wá Ìsinmi,” 97).

  25. Hébérù 11:13.

  26. Olùràpadà Ísráẹ́lì,” Àwọn Orin, no. 6, ẹsẹ 5. Èyí ni orin tí Lena Sofia Relund fẹ́ràn jùlọ.

  27. Wo Mórónì 10:30–33.

  28. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 132:19–20.