Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, nísisìyí yíò jẹ́ ànfàní mi láti gbé àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, àwọn Àádọ́rin Agbègbè, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò Ìjọ kalẹ̀ fún ìbò ìmúdúró yín.

Ẹ jọ́wọ́ ẹ fi àtìlẹhìn yín hàn bí ẹ ti nṣe. Bí a bá rí àwọn wọ̀nni tí wọń tako eyikeyi nínú àwọn àbá, a bèèrè pé kí ẹ kàn sí ààrẹ èèkàn yín.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró Russell Marion Nelson bí wòlíì, aríran, àti olùfihàn àti Ààrẹ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn; Dallin Harris Oaks bí Olùdámọ̀ràn Kínní; àti Henry Bennion Eyring bí Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkinní.

Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.

Àwọn wọnnì tó bá tàkòó, tí ẹnikẹ́ni bá wà, lè fihàn.

A dalaba pé kí ṣe imúdúró Dallin H. Oaks bí Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá àti Jeffrey R. Holland bí Aṣojú Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá.

Àwọn to bá faramọ, jọ̀wọ́ ṣàpẹrẹ.

Alátakò kankan tó bá wa lè fihàn.

A dalaba kí a ṣe imúdúró àwọn wọ̀nyí bí ọmọ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá: Jeffrey R. Holland, Dieter F. Uchtdorf, David A. Bednar, Quentin L. Cook, D. Todd Christofferson, Neil L. Andersen, Ronald A. Rasband, Gary E. Stevenson, Dale G. Renlund, Gerrit W. Gong, Ulisses Soares, àti Patrick Kearon

Àwọn tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Alátakò kankan lè fihàn bẹ́ẹ̀.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn olùdámọ̀ràn nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá bí àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Ìlòdì, bí èyíkéyi bá wá, nípa irú àmì kannáà.

Àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò Àádọ́rin wọ̀nyí ni a ó dá sílẹ̀ látinú ìyànsíṣẹ́ wọn tí a ó sì fún wọn ní ipò àgbà, bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́ Ìkínní Oṣù Kẹjọ, 2024: Àwọn Alàgbà Ian S. Ardern, Shayne M. Bowen, Paul V. Johnson, S. Gifford Nielsen, Brent H. Nielson, Adrián Ochoa, Gary B. Sabin, àti Evan A. Schmutz.

Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti fi ìmoore hàn sí àwọn arákùnrin wọ̀nyí àti ìyàwó wọn fún iṣẹ́-ìsìn ìfọkànsìn wọn káàkiri Ìjọ lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ìnawọ́ sókè.

Bákannáà a dá [Alàgbà Carlos A. Godoy] kúrò ní sínsìn bí ọmọ Àjọ Ààrẹ Àádọ́rin, bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́ Kínní Oṣù Kẹ́jọ, 2024.

Àwọn tí wọ́n fẹ́ láti fi ìmoore hàn sí [Alàgbà Carlos A. Godoy] fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ nínú ipò èyí lè ṣe bẹ́ẹ̀.

A kíyèsi pẹ̀lú ìdúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Àádọ́rin Agbègbè tí wọ́n ti parí iṣẹ́-ìsìn wọn ní ọdún tí ó kọjá yí àti àwọn tí a lè rí orúkọ́ wọn ní ibi ayélujára Ìjọ.

Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ wa ní fífi ìmoore hàn sí àwọn arákùnrin wọ̀nyí àti ẹbí wọn fún àwọn ọdún iṣẹ́ ìsin títayọ wọn lè fihàn.

A nawọ́ ìdásílẹ̀ sí Àjọ Ààrẹ Gbogbogbò Ilé-ẹ̀kọ́ Ọjọ́-ìsinmi, bẹ̀rẹ̀ láti Ọjọ́ Kínní Oṣù Kẹjọ, 2024 bí ìwọ̀nyí: Mark L. Pace bí Ààrẹ, Milton Camargo bí Olùdámọ̀ràn Ìkínní, àti Jan E. Newman bí Olùdámọ̀ràn Ìkejì.

Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ wa ní fífi ìmoore hàn sí àwọn arákùnrin wọ̀nyí fún iṣẹ́ ìsin ìfọkànsìn wọn lè fihàn.

A da laba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn ìwọ̀nyí bí ọmọ Àjọ Ààrẹ Àádọ́rin: Alàgbà Marcus B. Nash, tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ ní Oṣù Kínní, àti àwọn Alàgbà [Michael T. Ringwood], [Arnulfo Valenzuela], àti [Edward Dube], tí yíò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn wọn ní Ọjọ́ Kínní Oṣù Kẹjọ, 2024.

Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.

Alátakò kankan tó bá wa lè fihàn.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn àwọn yí bí Aláṣẹ Gbogbogbò Àádọ́rin: David L. Buckner, Gregorio E. Casillas, Aroldo B. Cavalcante, I. Raymond Egbo, D. Martin Goury, Karl D. Hirst, Christopher H. Kim, Sandino Roman, Steven D. Shumway, Michael B. Strong, àti Sergio R. Vargas.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Àwọn alátakò, nípa irú àmì kannáà.

A ṣe àkíyèsí pé àwọn Àádọ́rin Agbègbè titun mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ni a múdúró nínú àwọn ìpàdé olórí àpapọ̀ gbogbogbò ní Ọjọ́bọ̀, Ọjọ́ Kẹrin Oṣù Kẹ́rin, lẹ́hìnnáà a kéde rẹ̀ sí orí ibi ayélujára Ìjọ. A pè yín láti ṣe ìmúdúró àwọn arákùnrin wọ̀nyí nínú yíyàn síṣẹ́ wọn titun.

Àwọn tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Àwọn alátakò, nípa irú àmì kannáà.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn Àjọ Ààrẹ Ilé-Ẹ̀kọ́ Gbogbogbò Ọjọ́-ìsinmi, bẹ̀rẹ̀ láti Ọjọ́ Kínní, Oṣù Kẹ́jọ, 2024: Paul V. Johnson Bí Ààrẹ, Chad H Webb bí Olùdámọ̀ràn Kínní, àti Gabriel W. Reid bí Olùdámọ̀ràn Kejì.

Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.

Alátakò kankan lè ṣe àmì bẹ́ẹ̀.

A kíyèsi pé Arákùnrin Reid nsìn lọ́wọ́lọ́wọ́ bí ààrẹ Míṣọ̀n Ausralia Sydney àti pé nítorínáà kò si ní Ìlú Salt Lake fún ìpàdé àpapọ̀.

A dalaba pé kí a ṣè ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò bí a ṣe gbé wọn kalẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa nínawọ́ sọ́kè.

Àwọn alátakò, kankan to báwa.

A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, fún ìtẹ̀síwájú ìgbàgbọ́ yín àti àdúrà ní ìtìlẹhìn àwọn olórí Ìjọ.

Àwọn Ìyípadà sí Àwọn Àádọ́rin Agbègbè

Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a ṣe ìmúdúró fún nínú abala àwọn olórí kan tí a ṣe bí ara ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò:

Daniel A. Abeo, Mauricio A. Araújo, Randy T. Austin, Michel D. Avegnon, Philip J. Barton, Bradley S. Bateman, Eber Antônio Beck, Eric D. Bednar, Jared Black, Bryan G. Borela, Jaime A. Bravo, Juan G. Cardenas, Sancho N. Chukwu, Mark J Cluff, Danilo F. Costales, Daniel A. Cruzado, Gregorio Davalos, Julio N. Del Sero, Ryan E. Dobbs, Stephen W. Dyer, Brik V. Eyre, Denny Fa‘alogo, Timothy L. Farnes, Martín P. Fernández, Luis A. Ferrizo, Ángel J. Gómez, Georgie E. Guidi, Shinjiro Hara, Daniel L. Harris, Todd D. Haynie, Thomas Hengst, John R. Higgins, Niels O. Jensen, Fritzner A. Joseph, Kyoni Kasongo, John S. K. Kauwe III, Dan Kawashima, J. Joseph Kiehl, Carl F. Krauss, Yew Mun Kwan, Woo Cheol Lee, Wai Hung Mak, David R. Marriott, Ignatius Maziofa, Derek B. Miller, Albert Mutariswa, Marvin I. Palomo, Kyung Yeol Park, Domingo J. Perez, Oscar A. Perez, Raul Perez, Gayle L. Pollock, Pierre Portes, Marco A. Quezada, Stephen T. Rockwood, Guillermo Rojas, Kgomotso T. Sehloho, Sandro Alex Silva, Juswan Tandiman, Asuquo E. Udobong, Dwayne J. Van Heerden, Shih Ning (Steve) Yang, Juan F. Zorrilla, Leopoldo Zuñiga.

Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a ó dásílẹ̀ ní tàbí ṣíwájú Ọjọ́ Ìkínní Oṣù Kẹ́jọ, 2024:

Solomon I. Aliche, Guillermo A. Alvarez, Daren R. Barney, Julius F. Barrientos, James H. Bekker, David L. Buckner, Glenn Burgess, Marcos Cabral, Gregorio E. Casillas, Dunstan G. B. T. Chadambuka, Alan C. K. Cheung, Paul N. Clayton, Michael Cziesla, Hiroyuki Domon, Mernard P. Donato, I. Raymond Egbo, Zachary F. Evans, Sapele Fa‘alogo Jr., Saulo G. Franco, David Frischknecht, John J. Gallego, Efraín R. García, Robert Gordon, Mark A. Gottfredson, D. Martin Goury, Michael J. Hess, Bhanu K. Hiranandani, Richard S. Hutchins, Tito Ibañez, Eustache Ilunga, Akinori Ito, Anthony M. Kaku, Christopher H. Kim, H. Moroni Klein, Stephen Chee Kong Lai, V. Daniel Lattaro, Thabo Lebethoa, Tarmo Lepp, Itzcoatl Lozano, Kevin Lythgoe, Clement M. Matswagothata, Edgar P. Montes, Luiz C. D. Queiroz, Ifano Rasolondraibe, Eduardo D. Resek, Tomás G. Román, Ramon E. Sarmiento, Steven D. Shumway, Luis Spina, Jared W. Stone, Michael B. Strong, Djarot Subiantoro, Carlos G. Süffert, Voi R. Taeoalii, Karim Del Valle, Sergio R. Vargas, Helmut Wondra.

Tẹ̀