Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Jíjẹ́ Olõtọ́ dé Òpin
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Jíjẹ́ Olõtọ́ dé Òpin

Nípa ọwọ́ Rẹ̀, ẹyin yío le mú gbogbo Goliath tí ó bá farahàn nínú ayé yín wálẹ̀.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, ní òní èmi yíò fẹ́ láti bá ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sọ̀rọ̀ tààrà—ẹ̀yin ọ̀dọ́ Ìjọ.

Ó ti jẹ́ ọdún kan láti ìgbà tí a ti pe Àwọn Àjọ Ààrẹ Gbogbogbo ti Àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin wa. Ohun púpọ̀ ti ṣẹlẹ̀ láàrin ọdún tó kọjá yi!

A ti pàdé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín a sì ti jọ ṣe àṣàrò àwọn ìkọ́ni Krístì papọ̀. A ti kọ àwọn orin, ní àwọn ọ̀rẹ́ titun, a sì sìn pẹ̀lú yín ní àwọn agbègbè wa. A ti fún wa ní okun nípa fífetísílẹ̀ sí àwọn ẹ̀rí yín ní àwọn ìpàdé àpapọ̀ ọ̀dọ́ àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àgbáyé. A sì ti jọsìn papọ̀ nínú ilé Olúwa.

Ní àkókò kọ̀ọ̀kan, a ti pín ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa Jésù Krístì. Ti alẹ́ òní kí yíò yàtọ̀; mo ní ọ̀rọ̀ kan fún yín, ẹ̀yin ọ̀dọ̀ Ìjọ ti Jésù Krístì.

Àwọn Ìbèéré Nlá

Ǹjẹ́ ó jẹ́ kàyéfì rí fún yín bí ẹ ṣe lè jẹ́ olootọ sí Ọlọ́run nígbàtí ẹ ngbé nínú ayé ẹ̀ṣẹ̀? Níbo ni ẹ ti gba agbára láti lọ síwájú àti láti tẹ̀síwájú ní ṣiṣe rere? Báwo ni ẹ ṣe nní ìrírí ayọ̀ tòótọ́?

Mo rò pé ìrírí David àti Goliath lè ṣe ìrànlọ́wọ́.

Dáfídì àti Goliath

Nínú Májẹ̀mú Láéláé, àwọn ọmọ ogun Fílístínì njagun pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti pé ní gbogbo òwúrọ̀ àti ní gbogbo ìrọ̀lẹ́, òmìrán Fílístínì kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Goliath á pe èyíkéyìí ọmọ Ísírẹ́lì láti bá òun jà.

Àwòrán
Dáfídì àti Goliath

Láàrin àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì ni Dáfídìì gbé, ọ̀dọ́ olùṣọ́ àgùntàn tó kéré gan-an ju Goliath lọ, ṣùgbọ́n tó ní òmìrán ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi! Dáfídì yọ̀nda ara rẹ̀ láti ja. Àní ọba pàápàá gbìyànjú láti yí i lọ́kàn padà, ṣùgbọ́n Dáfídì yàn láti fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sìnu Jésù Kristi.

Tẹ́lẹ̀rí, Dáfídì ti bá kìnnìún jà àti béárì bákannáà. Láti inú àwọn ìrírí wọ̀nyí, ó mọ̀ pé Ọlọ́run ti dáàbò bò òun ó sì mú òun ṣẹ́gun. Sí Dáfídì, ìdíiṣẹ́ Ọlọ́run jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì jùlọ. Nítorínáà, ní kíkún fún ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kan tí kì yíò kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ó kó àwọn òkúta dídán marun jọ, ó mú kànnàkànnà rẹ̀, ó sì lọ kojú òmìrán náà.

Àwòrán
Òkúta marun ti Dáfídì

Àwọn ìwé mímọ́ sọ fún wa pé òkúta àkọ́kọ́ tí Dáfídì jù ba Goliath ní iwájú orí, ó sì parí ayé rẹ̀.

Wíwákiri fún Ìdáhùn náà

Nígbà tí Dáfídì lo òkúta kanṣoṣo láti pa Goliath, ó múra sílẹ̀ pẹ̀lú marun. Pẹ̀lú marun! Èyí jẹ́ kí nronú nípa bí mo ṣe lè múra sílẹ̀ láti kojú ayé.

Bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òkúta Dáfídì bá dúró fún okun tí a nílò láti borí nínú ìgbésí ayé wa nkọ́? Kínni àwọn òkúta marun wọ̀nnì lè jẹ́? Mo ronú nípa àwọn tóṣeéṣe wọ̀nyí:

  1. Òkúta ti ìfẹ́ mi fún Ọlọ́run.

  2. Òkúta ti ìgbàgbọ́ mi nínú Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.

  3. Òkúta ti ìmọ̀ nípa ìdánimọ̀ tòótọ́ mi.

  4. Òkúta ti ìrònúpìwàdà mi lojojúmọ́.

  5. Òkúta ti ààyè mi sí agbára Ọlọ́run.

Ẹ jẹ́ kí á sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe jẹ̀ alábùkún fún nípasẹ̀ àwọn agbára wọ̀nyí.

Àkọ́kọ́, òkúta ti ìfẹ́ mi si Ọlọ́run. Fífẹ́ Ọlọ́run ni òfin nlá àkọ́kọ́. Atọ́nà Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ kọ́ wa pé: “Ọlọ́run fẹràn yín. Òun ni Baba yín. Ìfẹ́ pípé Rẹ̀ lè mí síi yín láti fẹràn Rẹ̀. Nígbàtí ìfẹ́ yín fún Baba Ọ̀run bá jẹ́ ipá pàtàkì jùlọ nínú ìgbésí ayé yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpinnu yío di ìrọ̀rùn síi.”

Ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àti ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ wa pẹ̀lú Rẹ̀ nfún wa ní okun tí a nílò láti yí ọkàn wa padà kí a sì borí àwọn ìpèníjà wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn síi.

Èkejì, òkúta ti ìgbàgbọ́ mi nínú Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. Nígbà tí Jésù Krístì wá sí ayé, Ó jìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, Ó sì gbé àwọn ìbànújẹ́ wa, ìrora wa, àìlera wa, àti àìsàn ti ara àti ti ọpọlọ wa lé ara rẹ̀. Ìdí nìyí tí Ó fi mọ bí Ó ṣe lè ràn wá lọ́wọ́. Níní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì túmọ̀ sí láti gbẹ́kẹ̀lé ọgbọ́n Rẹ̀, àkokò Rẹ̀, ìfẹ́ Rẹ̀ ní kíkún, àti agbára Rẹ̀ láti ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Òkúta ti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì yíò ṣẹ́gun èyíkèyí “òmìrán” ninu ayé wa. A lè borí ayé ṣíṣubú yí nítorí Òun ti kọ́kọ́ borí rẹ̀.

Nọ́mbà kẹta, òkúta ti ìmọ̀ ti ìdánimọ̀ tòótọ́ mi. Wòlíì wa àyànfẹ́, Ààrẹ Russell M. Nelson, kọ́ wa pé àwọn ìdánimọ̀ wa tó ṣe pàtàkì jùlọ ni bí àwọn ọmọ Ọlọ́run, àwọn ọmọ májẹ̀mú, àti ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì.

Ohun gbogbo nyípada nígbàtí mo bá mọ ẹni tí mo jẹ. Nígbàtí mo bá nṣeyèméjì àwọn agbára mi, nígbà púpọ̀ mo máa nṣe àtúnsọ fún ara mi ninu ọkàn mi tàbí sí ìta pé, “Ọmọbìnrin Ọlọ́run ni mí, Ọmọbìnrin Ọlọ́run ni mí,” bí iye ìgbà tí mo nílò rẹ̀ bá ti pọ̀ tó títí tí èmi o tún fi ní ìmọ̀lára ìgboyà láti tẹ̀ síwájú.

Ẹ̀kẹ́rin, Òkúta ti ìrònúpìwàdà mi ojojúmọ́. Nínú atọ́nà Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, a kà pé: “Ìrònúpìwàdà kì í ṣe ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀; ó jẹ́ ọ̀nà ti Olùgbàlà fi nsọ wá di òmìnira kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Láti ronúpìwàdà túmọ̀ sí láti yípadà―láti yà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó túmọ̀ sí láti dára si kí à sì gba ìdáríjì. Irú ìyípadà yí kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ àkokò-kan; ó jẹ́ ìlànà tí ó nlọ lọ́wọ́.”

Kò sí ohun tí ó nfúnni ní òmìnira díẹ̀ si ju kí a ní ìmọ̀lára ìdáríjì Ọlọ́run àti mímọ̀ pé a mọ́ àti ní ìlàjà pẹ̀lú Rẹ̀. Ìdáríjì ṣeéṣe fún gbogbo ènìyàn.

Òkúta karun ni òkúta ti ààyè mi sí agbára Ọlọ́run. Àwọn májẹ̀mú tí a dá pẹ̀lú Ọlọ́run, bí irù àwọn tí a ṣe nínú ìlànà ìrìbọmi, nfún wa ní ààyè sí agbára ìwàbíọlọ́run. Agbára Ọlọ́run jẹ́ agbára gidi kan tí ó nrànwá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìpèníjà, ṣe àwọn ìpinnu tí ó dára, ó sì nfikún ipá wa láti farada àwọn ipò tó nira. Ó jẹ́ agbára kan pẹ̀lú èyí tí a lè dàgbà nínú àwon ìleṣe pàtó tí a nílò.

Atọ́nà Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ ṣe àlàyé pé: “Àwọn májẹ̀mú so yín pọ̀ mọ́ Baba Ọ̀run àti Olùgbàlà. Wọ́n nmú agbára Ọlọ́run pọ̀ si ní ìgbésí ayé yín.”

Ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ nípa àsopọ̀ náà. Ẹ rántí nígbàtí Krístì kọ́ni ní ìyàtọ̀ laarin ilé tí a kọ́ sórí àpáta àti ọ̀kan lórí iyanrìn? Alàgbà Dieter F. Uchtdorf ṣàlàyé pé: “Ilé kò kàn dúró nínú ìjì nítorípé ilé náà lágbára. Bákànnáà kò kàn lè dúró nítorí àpáta náà lágbára. Ilé náà dúró nínú ìjì nítorípé a so ó gbọnin-gbọnin mọ́ àpátà tó lágbára náà. Ó jẹ́ pé okun ìsopọ̀ náà ni ó ṣe pàtàkì.”

Àwòrán
Ilé tí a kọ́ sórí àpáta.

Ìsopọ̀ ti ara ẹni wa pẹ̀lú Jésù Kristi yíò fún wa ní ìgboyà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ láti tẹ̀ síwájú laarin àwọn ènìyàn tí kò bọ̀wọ̀ fún ìgbàgbọ́ wa tàbí tí wọ́n nfìyà jẹ wá. Krístì npè wa láti fi Òun sínú èrò wa nígbà gbogbo; Ó nsọ fún wa pé, “Ẹ máa wò ọ̀dọ̀ mí nínú gbogbo èrò ìnú.” Ríronú nípa Olùgbàlà nfún wa ní èrò inú mímọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu, láti gbé ìgbésẹ̀ láìbẹ̀rù, àti láti sọ bẹ́ẹ̀ kọ́ sí ohun tí ó lòdì sí àwọn ẹ̀kọ́ Ọlọ́run. Nígbàtí ọjọ́ mi bá ṣòro tí mo sì ní ìmọ̀lára pe mi ò lè gbà síi mọ́, ríronú nípa Krístì nmú àláfía wá fún mi ó sì nfún mi ní ìrètí.

Báwo ni a ṣe lè fà nínú agbára Jésù Krístì yí? Gbígbọ́ràn sí àwọn májẹ̀mú wa àti mímú ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì pọ̀ sì jẹ́ àwọn kókó.

Ìbá wùmí ní tòótọ́ pé David ní òkúta kan sí i; èyí yíò jẹ́ òkúta ti ẹ̀rí mi. Ẹ̀ri wa ni a nmú dàgbà nípasẹ̀ àwọn ìrírí ti ara-ẹni ti ẹ̀mí nínú èyítí a dá ipá àtọ̀runwá mọ̀ nínú ìgbésí ayé wa. Kò sí ẹni tí ò lè gba ìmọ̀ náà lọ́wọ́ wa. Mímọ ohun tí a mọ̀ láti inú gbígbé àwọn ìrírí ti ẹ̀mí wa jẹ́ àìdíyele. Jíjẹ́ òtítọ́ sí ìmọ̀ náà nfún wa ní òmìnira. Ó nfún wa ní ayọ̀! Bí a bá fẹ́ràn òtítọ́, a ó wá a, lọ́gán tí a bá sì ri i, a ó jà fún un.

Ìfipè Kan

Gẹ́gẹ́bí mo ti yan òkúta nọ́mbà kẹfà, mo pè yín láti pàdé pẹ̀lú kílásì yín, iyejú, tàbí ẹbí kí ẹ sì ronú nípa àwọn agbára míràn tí ẹ nílò láti ní láti dúró bí olotọ sí Ọlọ́run, nítorínáà, kí ẹ sí borí ayé.

ìlérí Kan

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, Krístì ní ìtara láti bá wa lọ nínú ìrìn àjò ìgbésí ayé wa. Mo ṣèlérí fún yín, bi ẹ ti di ọ̀pá irin náà mú, ẹ̀yin yíò rìn ní ọwọ́ ninu ọwọ́ pẹ̀lú Jésù Krístì. Òun yíò máa tọ́ yín sọ́nà, Òun yíò sì máa kọ́ yín. Nípa ọwọ́ Rẹ̀, ẹyin yío le mú gbogbo Goliath tí ó bá farahàn nínú ayé yín wálẹ̀.

Ẹ̀rí

Mo jẹ́rìí pé ayọ̀ wà nínú àdúrà gbígbà lójojúmọ́, nínú kíka Ìwé ti Mọ́mọ́nì lójojúmọ́, nínú jíjẹ oúnjẹ Olúwa ní gbogbo ọjọ́ Ìsinmi, àti ní lílọ sí sẹ́mínárì—àní ní òwúrọ̀ kùtùkùtù! Ayọ̀ wà nínú ṣíṣẹ rere.

Ayọ̀ wà nínú jíjẹ́ olootọ sí Ọlọ́run gbogbo àgbáyé, Olùgbàlà aráyé, Ọba àwọn ọba. Ayọ̀ wa ní jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì.

Ọlọ́run ni Baba wa. Ó mọ àwọn ìfẹ́ ọkàn yín àti àwọn lílèṣe yín, Ó sì gbẹ́kẹ̀lé yín.

Ẹ̀yin ọ̀dọ́ ọ̀wọ́n, Jésù Kristi yíò ràn yín lọ́wọ́ láti jẹ́ olootọ dé òpin. Nípa àwọn òtítọ́ wọ̀nyí, ni mo jẹ́ ẹ̀rí mi ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀