Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àkọsílẹ̀ nípa Ohun Tí Mo Ti Rí àti Ti Mo Ti Gbọ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


11:49

Àkọsílẹ̀ nípa Ohun Tí Mo Ti Rí àti Ti Mo Ti Gbọ́

Kò tíì sí àkókò dídárajù kan rí láé láti jẹ́ ọmọ-ìjọ ti Ìjọ Jésù Krístì.

Lẹ́hìn tí mo parí ní ilé ìwé òfin, ìyàwó mi, Marcia, àti èmi yàn láti darapọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ òfin kan tí wọ́n yan òfin ìpèlẹ́jọ́ láàyò. Bí mo ti bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́-ẹnu-iṣẹ́ mi, mo lo púpọ̀ àkókò mi ní ṣíṣe ìmúrasílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́rìí láti jẹ́ri ní ibi ìpèlẹ́jọ́. Mo yára kọ́ ẹkọ́ pé òtítọ́ njẹ́ pípinnu ninu yàrá ìgbẹ́jọ́ bí àwọn ẹlẹ́rìí, lábẹ́ ìbúra, ti jẹ́rìí nipa jíjẹ́ òtítọ́ ohun tí wọ́n ti rí àti tí wọ́n ti gbọ́. Bí àwọn ẹlẹ́rìí ti njẹ́rìí, àwọn ọ̀rọ̀ wọn ni a nká sílẹ̀ tí a sì nfi pamọ́. Ṣíṣe pàtàkì àwọn ẹlẹ́rìí tó wúlò sì nfi ìgbà gbogbo wà ní ọ̀gangan iwájú ìmúrasílẹ̀ mi.

Kò gba àkókò pípẹ́ fún mí láti ríi pé awọn ẹ̀là ọ̀rọ̀ kannáà gan-an tí mo nlò ní ojojumọ́ bí amòfin ni awọn ẹ̀là ọ̀rọ̀ ti mo nlò ninu awọn ìbánisọ̀rọ̀ ìhìnrere mi. “Ẹlẹ́rìí” ati “ẹ̀rí” ni àwọn ẹ̀là ọ̀rọ̀ tí a nlò bí a ti npín ìmọ̀ àti àwọn ìmọ̀lára wa nipa jíjẹ́ òtítọ́ ti ìhìnrere Jésù Krístì.

Nígbàtí a mú mi dúró bíi Àádọrin Agbègbè tuntun, mo ṣí àwọn ìwé mímọ́ láti kọ́ àwọn ojúṣe mi, mo sì ka Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 107:25, èyítí ó wí pé, “Àwọn Àádọ́rin ni a pè bákannáà … láti jẹ́ àwọn ẹlẹ́rìí pàtàkì sí àwọn Kèfèrí àti ní gbogbo àgbáyé.” Bí ẹ ti le fi ojú inú wòó, a fa ojú mi sí ẹ̀là ọ̀rọ̀ “àwọn ẹlẹ́rìí pàtàkì.” Ó di kedere sí mi pé mo ní ojúṣe kan láti gbé ẹ̀rí mi—láti jẹ́ri nipa orukọ Jésù Krístì—níbikíbi ti mo bá rin ìrìnàjò lọ ní àgbáyé.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àpẹrẹ ló wà ninu àwọn ìwé mímọ́ nipa àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí-óṣojúmi-kòró tí wọ́n sì jẹ́ri sí ohun tí wọ́n rí àti tí wọ́n gbọ́.

Bí wòlíì ìgbàanì Mọ́mọ́nì ti bẹ̀rẹ̀ àkọsílẹ̀ rẹ̀, ó kọ pé, “Àti nísisìyí èmi, Mọ́mọ́nì, kọ àkọsílẹ̀ nípa àwọn ohun tí mo ti rí àti tí mó tí gbọ́, mo sì pè é ní Ìwé ti Mọ́mọ́nì.”

Àwọn Àpóstélì Olùgbàlà, Pétérù àti Jòhánnù wo ọkùnrin kan sàn ní orúkọ Jésù Krístì ti Násárẹ́tì. Nígbàtí a pàṣẹ fún wọn láti máṣe sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jésù, wọ́n fèsì pé:

“Bóyá ó tọ́ ní ojú Ọlọ́run láti fetísílẹ̀ sí ẹ̀yin jù sí Ọlọ́run, ẹ dájọ́.

“Nítorí a kò lè ṣàì sọ àwọn ohun tí a ti rí àti tí a ti gbọ́.”

Ẹ̀rí míràn tó fipá múni wá láti ọ̀dọ̀ Àwọn Ènìyàn Mímọ́ inú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, awọn ẹnití wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí ìbẹ̀wò Olùgbàlà Jésù Krístì. Ẹ fetísí àpèjúwe yí nipa ẹ̀rí wọn: “Báyĩ sì ni ọ̀nà tí wọ́n fi jẹ̃rí síi: Ojú kò ríi rí, bẹ̃ni etí kò gbọ́, tẹ́lẹ̀ rí, àwọn ohun nlá àti yíyanilẹ́nu tóbẹ́ẹ̀ bí àwa ti rí tí a sì gbọ́ tí Jésù bá Baba sọ.”

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, loni mo kède ẹ̀rí mi mo sì ṣe àkọsílẹ̀ kan nípa ohun tí mo ti rí àti ti mo ti gbọ́ ní ìgbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ mímọ́ mi bíi Àádọ́rin ti Olúwa Jésù Krístì. Ní síṣe bẹ́ẹ̀ mo jẹ́rìí sí yín nípa olùfẹ́ni Bàbá Ọ̀run kan àti Ọmọ Rẹ̀ aláànú, Jésù Krístì, ẹnití ó jìyà, tí ó kú, tí ó sì tún dìde láti fi ìyè ayérayé fún àwọn ọmọ Ọlọ́run. Mo jẹ́rí nipa “iṣẹ́ ìyanu àti yíyanilẹ́nu kan” àti pé Olúwa ti fi ọwọ́ Rẹ̀ lé lẹ́ẹ̀kansíi láti mú ìhìnrere Rẹ̀ padàbọ̀sípò ní orí ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ àwọn wòlíì alààyè àti àwọn àpóstélì Rẹ̀. Mo jẹ́rìí pé dá lórí ohun tí mo ti rí àti tí mo ti gbọ́, kò tíì sí àkókò tó dárajù láti jẹ́ ọmọ-ijọ ti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ju òní lọ. Mo mọ èyí nípa ìmọ̀ tèmi, ní òmìnira sí èyíkéyi orísun míràn, nitorí ohun tí mo ti rí àti tí mo ti gbọ́

Ní ọdún àgbà mi ní ilé ìwé gíga, láti parí ní sẹ́mínírì, mo níláti dá gbogbo tẹ́mpìlì mẹ́ẹ̀dógún ti Ìjọ mọ̀. Àwòrán tẹ́mpìlì kọ̀ọ̀kan wà níwájú kíláàsì wa, mo sì níláti mọ ibití ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn wà. Nísisìyí, ní àwọn ọdùn lẹ́hìnwá, yío jẹ́ ìpèníjà nlá—pẹ̀lú 335 àwọn tẹ́mpìlì tó nṣiṣẹ́ tàbí tí a ti kéde—láti dá ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ̀. Mo ti fúnra ara mi rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ile Olúwa wọ̀nyí, mo sì jẹ́ri pé Olúwa nfi àwọn ìbùkún áti àwọn ìlànà Rẹ̀ fún púpọ̀ àti púpọ̀ síi lára àwọn ọmọ Rẹ̀ káàkiri àgbáyé.

Àwọn ọ̀rẹ́ mi ni FamilySearch ti kọ́ mi pé àwọn orúkọ titun tó ju mílíọ̀nù kan lọ ni a nfikún ní ojojúmọ́. Bi o kò bá rí baba nlá rẹ lánàá, mo pè ọ́ láti wò lẹ́ẹ̀kansíi lọ́la. Nigbàtí ó bá dé ibi kíkójọ Isráẹ́lì ni ẹ̀gbẹ́ kejì ìkelè. Kò tíì sí àkókò dídárajù kan rí láé láti jẹ́ ọmọ-ìjọ ti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ju òní yí lọ.

Bí a ti tọ́ àwọn ọmọ wa ní Twin Falls, Idaho, ìwòye wa nìpa Ìjọ káríayé ní òdiwọ̀n. Nígbàti a pè mí láti jẹ́ Aláṣẹ Gbogbogbò, Marcia àti èmi ni a yàn láti sìn ní Agbègbè Pacific, ni ibikan tí a kò tíì dé rí. Ó dùn mọ́ wa lati rí àwọn èèkàn láti òkè New Zealand dé ìsàlẹ̀, pẹ̀lú tẹ́mpìlì kan tí wọ́n yà sí mímọ́ ní 1958. Ó jẹ́ ìkan lára àwọn mẹ́ẹ̀dógún wọnnì ti mo níláti kọ́ sórí ni sẹ́mínárì. A rí àwọn tẹ́mpìlì ni gbogbo ilú nlá ni Australia, pẹ̀lú àwọn èèkàn káàkiri ìpín-ilẹ̀-ayé náà. A ní àwọn iṣẹ́ yíyàn ni Samoa, níbití àwọn èèkàn 25 wà, áti Tonga, nibití ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ìlàjì àwọn ara ilú ni ọmọ-ìjọ ti Ìjọ. A ní iṣẹ́ yíyàn kan ní erékùsù ti Kiribati, níbití a ti rí awọn èèkàn méjì. A ní àwọn iṣẹ́ yíyàn láti bẹ àwọn èèkàn wò ní Ebeye ni àwọn Erékùsù Marshall àti Daru ni Papue New Guinea.

Lẹ́hìn iṣẹ́-ìsìn wa ni àwọn Erékùsù Pacific, a yàn wá láti lọ sìn ní Philippines. Sí ìyàlẹ́nu mi, Ìjọ Jésù Krístì ní Philippines ndàgbà tayọ ohunkóhun tí mo ti mọ̀. Nísisìyí àwọn èèkàn 125, àwọn mísọ̀n 23, àti àwọn tẹ́mpìlì 13 tó nṣiṣẹ́ tàbí tí wọ́n ti kéde ló wà. Mo jẹ́ri ìjọ kan tí ó ní àwọn ọmọ-ìjọ tó ju 850,000 lọ ní orílẹ̀-èdè náà. Báwo ni mo ti pàdánù àgbékalẹ̀ Ìjọ Krístì káàkiri àgbáyé?

Lẹ́hìn ọdún mẹ́ta ni Philippines, a yàn mí láti sìn ni Ẹ̀ka ti Iṣẹ́ Ìrànṣẹ́ Ìhìnrere. Iṣẹ́ yíyàn náà mú wa lọ sí àwọn mísọ̀n ní gbogbo àgbáyé. Ìwòye mi ní ti Ìjọ káríayé ti Olùgbàlà gbilẹ̀ síi ni ọ̀nà tó lápẹrẹ. A yan Marcia àti èmi làti bẹ̀ àwọn mísàn wò ni Asia. A ri gbùngbùn èèkàn rírẹwà kan ni Singapore, pẹ̀lu ayanilẹ́nu, olootọ́ awọn ọmọ-ìjọ. A bẹ̀ awọn ọmọ-ìjọ àti àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wò ní ilé ìjọsìn kan ni Kota Kinabalu, Malaysia. A pàdé àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ni Hong Kong a sì kópa ninu ìpàdé àpapọ̀ ti èèkàn yíyanilẹ́nu kan pẹ̀lú àwọn olõtọ́, olùfọkànsìn Ènìyàn Mímọ́.

Ìrírí yí jẹ́ àṣetúnṣe bí a ti pàdé àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ati awọn ọmọ-ìjọ káàkiri Europe, ní Latin Amẹrika, ní Caribbean, ati ní Afríkà. Ìjọ Jésù Krístì nní ìrírí ìdàgbàsókè títayọ ni Afríka.

Mo jẹ́ ẹlẹ́rìí-óṣojúmi-kòró ti Ìmúpadábọ́sípò ìhìnrere Jésù Krístì tó nlọ lọ́wọ́, àti ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ti Joseph Smith pé “òtítọ́ Ọlọ́run yíò lọ síwájú pẹ̀lú ìgboyà, pẹ̀lú ọlá, àti ní òmìnira, títí tí yíó fi wọ inú gbogbo ìpín-ilẹ̀-ayé, tí yío bẹ gbogbo ibi gíga wò, tí yío gbá gbogbo orílẹ̀-èdè, tí yío sì dún ní gbogbo ètí.”

Àwọn àgbàíyanu ìránṣẹ́ ìhìnrere wa ti wọ́n bo gbogbo àgbáyé nisisìyí jẹ́ 74,000 ni agbára. Ní ṣíṣe iṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ìjọ, ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún ìribọmi tí wọ́n nṣe ni oṣooṣù. Ní àìpẹ́ yí ó ti jẹ́ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin ẹni ọdún 18-, 19-, àti 20 ni, pẹ̀lu ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa, wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìyanu nlá ti kíkójọ yí. A nrí àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin àti ọ̀dọ́mọkùnrin wọ̀nyí ni àwọn ìletò kékèké ti Vanuatu ati ní à wọn ilú nlá ti New York, Paris, àti London. Mo ti wò wọn tí wọ́n nkọ́ni nipa Olùgbàlà nínú àwọn àkójọpọ̀ jíjìnnà ní Fiji àti àwọn àkójọpọ̀ títobi díẹ̀ síi ni àwọn ibi bíi Texas, California, ati Florida ni United States.

Ẹ ó rí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ni gbogbo kọ̀rọ̀ ilẹ̀ ayé, tí wọ́n nsọ ọgọ́ta (60) àwọn èdè tó yàtọ̀, tí wọ́n sì nṣe ìmúṣẹ àṣẹ nlá Olùgbàlà ninu Máttéù 28 pé: “Ẹ lọ nítorínáà, kí ẹ sì kọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ní síṣe ìrìbọmi fún wọn ní orúkọ Baba, àti ti Ọmọ, àti ti Ẹ̀mí Mímọ́.” Mo bu ọlá fún àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere Ìjọ ti tẹ́lẹ̀ àti lọ́wọ́lọ́wọ́, mo sì rán àwọn ìran wa tó ndìde létí ìfipe Ààrẹ Russell M. Nelson láti wá kí ẹ sì kó Ísráẹ́lì jọ.

Mo jẹrìí lóni pé mo ti ṣe àkíyèsí ìjìnlẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Olùgbàlà yí pẹ̀lú ojú tèmi mo sì ti gbọ́ ọ pẹ̀lú etí tèmi. Mo jẹ̀ ẹlẹ́rìí kan ti iṣẹ́ Ọlọ́run káàkiri ayé. Kò tíì sí àkókò dídárajù kan rí láé láti jẹ́ ọmọ-ìjọ ti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ju òní yí lọ.

Bóyá iṣẹ́ ìyanu ti ìmúpadàbọ̀sípò tó ní ìmísí jùlọ ti èmi ti jẹ́rìí sí ni ẹ̀yin, olootọ́ ọmọ-ìjọ ti Ìjọ náà ní ilẹ̀ gbogbo. Ẹ̀yin, Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, ni a ṣe àpèjúwe láti ọwọ́ Néfì ninu Ìwé ti Mọ́mọ́nì, bí ó ti rí ọjọ́ wa tí ó sì jẹ́ri pé, “Ó sì ṣe tí èmi, Néfì, kíyèsí agbára Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, pé ó sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn mímọ́ ti ìjọ Ọ̀dọ́-àgùtàn náà, àti sórí àwọn ènìyàn májẹ̀mú Olúwa, àwọn tí a fọ́nká sórí gbogbo ojú ilẹ̀ ayé; a sì dì wọ́n lámùrè pẹ̀lú òdodo àti pẹ̀lú agbára Ọlọ́run nínú ògo nlá.”

Mo jẹ́rìí pé mo ti rí pẹ̀lú ojú tèmi ohun ti Néfì rí—ẹ̀yin, Ẹ̀yin Ènìyàn Mímọ́ májẹ̀mú ní gbogbo ilẹ̀, tí ẹ dì ìhámọ́ra pẹ̀lú òdodo àti agbára Ọlọ́run. Bí mo ti wà lórí aga-ìwàásù ní ọ̀kan ninu àwọn orílẹ̀ èdè nlá wọ̀nyí, Olúwa tẹ ohun kan mọ́ ọkàn mi tí Ọba Bẹ́njámínì kọ́ni ninu Mòsíà 2 ninu Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Brent, “Èmi fẹ́ kí ẹyin ó ronú lórí ipò alábùkún-fún àti ìdùnnú ti àwọn wọnnì tí wọ́n pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Nítorí ẹ kíyèsíi, wọ́n jẹ́ alábùkúnfún nínú ohun gbogbo, àti ní ti ara àti ti ẹ̀mí.”

Mo jẹ́ ẹ̀rí sí yín pé mo ti rí èyí pẹ̀lú ojú tèmi mo sì gbọ́ ọ pẹ̀lú etí tèmi bí mo ti pàdé yín, ẹ̀yin olódodo Ènìyàn Mímọ́ Ọlọ́run káàkiri ilẹ̀ ayé tí ẹ npa àwọn òfin mọ́. Ẹ̀yin ni ọmọ májẹ̀mú ti Baba. Ẹ̀yin ni ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì. Ẹ̀yin bákannáà mọ ohun tí mo mọ̀ nítorípé ẹ ti gba ẹ̀rí ti ara ẹni yín nipa jíjẹ́ òtítọ́ ti ìhìnrere Jésù Krístì tí a mú padàbọ̀sípọ̀. Olùgbàlà kọ́ni pé, “Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ojú yín, nítorítí wọn rí: àti etí yín, nítorítí wọn gbọ́.”

Ní abẹ́ ìdarí Olúwa àti ìṣàkóso àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì Rẹ̀, a ó tẹ̀síwájú láti máa pèsè àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere, láti máa ṣe kí a sì máa pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́, láti máa ṣe àgbékalẹ̀ Ìjọ Krístì káàkiri ayé, kí a sì gba àwọn ìbùkún tó nwá bí a ti npa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. A wà ni ìṣọ̀kan. A jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. A mọ̀ Ọ́ a sì fẹ́ràn Rẹ̀.

Mo darapọ̀ mọ́ gbogbo yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, bí a ti fi ìṣọ̀kan jẹ́ri pé àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́ òtítọ̀. A ṣe àkọsílẹ̀ kan nípa ohun tí a ti rí àti ti a ti gbọ́. Ẹ̀yin àti èmi ni ẹlẹ́rìí ti ó jẹ́ri. Pẹ̀lú agbára ẹ̀rí ìṣọ̀kan yi ni a tẹ̀síwájú lati máa sún síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ ninu Olúwa Jésù Krístì a`ti ìhìnrere Rẹ̀. Mo kéde ẹ̀ri mi pé Jésù Krístì wà láàyè. Òun ni Olùgbàlà wa àti Olùràpadà wa. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.