Gbogbo Rẹ̀ Ó Dára Nítorí àwọn Májẹ̀mú Tẹ́mpìlì
Kò sí ohun tó ṣe pàtàkì ju bíbu ọlá fún àwọn májẹ̀mú yín tí ẹ ti dá tàbí tí ẹ lè dá nínú tẹ́mpìlì.
Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìrnin mi, abala ìpàdé àpapọ̀ yí ti jẹ́, ìgbà mímọ́, fún mi. Mo dúpẹ́ fún ìyànṣíṣẹ́ láti sọ̀rọ̀ sí àwọn míllíọ́nù àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn àti àwọn ọ̀rẹ́ wa káàkiri àgbáyé. Mo nifẹ yín, mo sì mọ̀ pé Olúwa nífẹ yín.
Àwọn àádọ́tá ọdùn ó lé sẹ́hìn, mo ní ànfàní nlá láti sìn bí ààrẹ ti kọ́lẹ́jì Ricks, ní Rexburg, Idaho. Ní òwúrọ̀ Ọjọ́ Karun Oṣù Kẹfà, 1976, ìyàwó mi, Kathy, àti èmi wakọ̀ láti Rexburg lọ sí Tẹ́mpìlì Ìṣubú Idaho láti wà níbi èdidì ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan. Bẹ́ẹ̀ni, pẹ̀lú àwọn ọmọdékùnrin wa mẹ́rin nínú ilé wa ní àkokò náà, ìrìnàjò tẹ́mpìlì wa lè di ṣíṣe-yọrí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ olùgbóyà olùtọ́jú ọmọ-ọwọ́ nìkan! A fi àwọn ọmọ iyebíye wa sílẹ̀ sí ìkáwọ́ rẹ̀ a sì mú ìrìn, kúkurú ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lọ.
Ìrírí wa nínú tẹ́mpìlì ní ọjọ́ náà jẹ́ ìyanu, bíi ti ìgbàgbogbo. Bákannáà, lẹ́hìn ìparí èdidì tẹ́mpìlì—àti bí a ṣe nmúra láti padà sílé—a kíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ tẹ́mpìlì àti olùkópa tí wọ́n nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú àìfọkànbalẹ̀ ní ibi ibèbè tẹ́mpìlì. Ní àkokò díẹ̀, ọ̀kàn lára àwọn òṣìṣẹ́ tẹ́mpìlì wí fún wa pé Agbami Teton titun ní ìlà-òòrùn Idaho tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ti wo! Ju bí ọgọ́rin bíllíọ̀nù galọnu (300 kúbíkì mítà míllíọ̀nù) omi nṣàn látinú agbami náà àti sínú igun-mẹ́rin máìlì ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (775 igun-mẹ́rin kílómítà) àwọn agbègbè àfonífojì. Ọ̀pọ̀ ìlú Rexburg wà lábẹ́ omi, pẹ̀lú àwọn ilé àti ọkọ̀ tí àgbàrá-omi gbé lọ. Ìdá méjì nínú mẹ́ta ẹgbẹ̀rún mẹ́sán àwọn olùgbé di aláìnílé-lórí lójijì.
Bí ẹ ti lè rò, àwọn èrò àti àníyàn wa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ yí sí ààbò àti wíwà-láláfíà àwọn àyànfẹ́ ọmọ wa, ọgọgọ́ọ̀rún àwọn akẹkọ kọ́lẹ́jì àti ẹ̀ka, àti ìletò kan tí a fẹ́ràn. A wà ní ọgbọ̀n máìlì ó dín (àádọ́ta kilómítà) kúrò nílé, àti pé síbẹ̀síbẹ̀ ní ọjọ́ yí, ṣíwájú kí fóònù àgbéká àti ọ̀rọ àtẹ̀jíṣẹ́ tó dé, a kò ní ọ̀nà láti bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, tàbí kí a lè wa ọkọ̀ láti Ìṣubú Idaho padà sí Rexburg, bí gbogbo àwọn ọ̀nà ti wà ní pípadé.
Yíyàn wa kanṣoṣo ni láti dúró sí ilé-ìtura ìbílẹ̀ kan ní Ìṣubú Idaho ní alẹ́ náà. Kathy àti èmi kúnlẹ̀ nínú yàrá ilé-ìtura kékere wa a sì fi ìrẹ̀lẹ̀ bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Baba Ọ̀run fún ààbò àwọn àyànfẹ́ ọmọ wa àti ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn míràn tí ìkọlù ìṣẹ̀lẹ́ olóró náà ti pa lára. Mo rántí tí Kathy nlọ-bọ̀ ní ilẹ̀ títí di àfẹ̀mọ́júmọ́ wákàtí òwúrọ̀ náà pẹ̀lú ìdàmú nípa àwọn ọmọ rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn àníyàn ti ara mi, mo lè fi ọkàn mi sí ìsinmi tí mo sì sùn lọ.
Kò pẹ́ lẹ́hìnnáà tí olólùfẹ́ ojúgbà ayèrayé mi jí mi tí ó sí wípé, “Hal, báwo ni o ṣe lè sùn ní irú àkokò bayi?”
Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nígbànáà wá sí inú àti ọkàn mi yékéyéké. Mo wí fún ìyàwó mi pé: “Kathy, ohun yíówù kí àbájáde jẹ, gbogbo rẹ̀ ó dára nítorí tẹ́mpìlì. A ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run a si ti ṣe èdidì bí ẹbí ayérayé.”
Ní àkokò náà, àfí bíìpé Ẹ̀mí Olúwa fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nínú ọkàn wa àti iye-inú nípa ohun tí àwa méjèèjì ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ láti jẹ́ òtítọ́: àwọn ìlànà èdidì, tí a rí nínú ilé Olúwa nìkan tí a sì npínfúnni nípasẹ̀ àṣẹ oye-àlùfáà títọ́, tí ó dè wá papọ̀ bí ọkọ àti ìyàwó, àti àwọn ọmọ wa tí a ti ṣe èdidì wọn sí wa. Kò sí ìdí láti bẹ̀rù rárá lótítọ́, a sì dúpẹ́ láti mọ̀ lẹ́hìnnáà pé àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin wa wà láláfíà.
Bóyá ẹ̀là-ọ̀rọ̀ yí látẹnu Ààrẹ Thomas S, Monson ó júwe ohun tí Kathy àti èmi ní ìmọ̀lára rẹ̀ ní alẹ́ àìmánigbàgbé náà. “Bí a ṣe nlọ sí tẹ́mpìlì, oníruru ọ̀nà ti ẹ̀mí àti ìmọ̀lára àláfíà kan ni ó lè wá sọ́dọ̀ wa. … A ó di àwọn ọ̀rọ̀ Olùgbàlà tí ó jẹ́ ìtumọ̀ otítọ́ gan mú nígbàtí Ó sọ pé: ‘Àláfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín, àláfíà mi ni mo fún yín. … Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàmú, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ó wárìrì [Jòhánù 14:27].’”
Mo ti di alábùkún láti ní ìmọ̀lára àláfíà ní gbogbo ìgbà tí mo bá wọn inú tẹ́mpìlì mímọ́. Mo rántí ọjọ́ àkọ́kọ́ tí mo rin wọnú Tẹ́mpìlì Salt Lake. Mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin kan.
Mo wòkè níbi òrùlé funfun gíga tí ó mú kí iyàrá náà mọ́lẹ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ dàbí i pé ó ṣí sílẹ̀ sí òfúrufú. Ati pé ní àkokò náà, èrò náà wá sínú mi ní àwọn ọ̀rọ̀ kedere wọ̀nyí: “Mo ti wà nínú ibi ìmọ́lẹ̀ yí tẹ́lẹ̀.” Ṣùgbọ́n ní kété lẹ́hìnnáà tí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá sínú ọkàn mi, kìí ṣe nínú ohùn arami pé: “Rárá, o kò dé ibi rí tẹ́lẹ̀. Ò nrántí àkokò kan ṣíwájú kí wọ́n tó bi ọ. O ti wà nínú ibi mímọ́ bí èyí níbi tí Olúwa lè wá.”
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo fi ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé bí a ti nlọ sí tẹ́mpìlì, a lè ránwalétí nípa ìwà-ẹ̀dá ayérayé ti àwọn ẹ̀mí wa, ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Baba àti Ọmọ àtọ̀runwá Rẹ̀, àti ìfẹ́ ìgbẹ̀hìn wa láti padà sí ilé wa ọ̀run.
Ní àwọn ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ àìpẹ́, Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni:
“Ibi ààbò jùlọ láti wà níti ẹ̀mí ni gbígbé nínú àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì yín.”
Ohun gbogbo tí a gbàgbọ́ àti gbogbo ìrètí tí Ọlọ́run ti ṣe sí àwọn ènìyàn májẹ̀mú Rẹ̀ wá papọ̀ nínú tẹ́mpìlì.”
“Ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó ndá àwọn májẹ̀mú … nínú àwọn tẹ́mpìlì—tí wọ́n sì npa wọn mọ́—ní ààyè púpọ̀ sí agbára ti Jésù Krístì.”
Bákannáà ó kọ́ni pé “níwọ̀n ìgbàtí a bá ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, à nfi ààyè àìmọ́kànle sílẹ̀ títíláé. Ọlọ́run kò ní pa ìbáṣepọ̀ Rẹ̀ tì pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti fi irú ìsopọ̀ kan bẹ́ẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú Rẹ̀. Nítóótọ́, gbogbo àwọn tí wọ́n ti dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú Ọlọ́run ní ààyè sí irú ìfẹ́ àti àánú pàtàkì kan.”
Lábẹ́ ìdarí ipò olórí Ààrẹ Nelson, Olúwa ti yára, yíò sì tẹ̀síwájú láti yára, sí kíkọ́ àwọn tẹ́mpìlì káàkiri àgbáyé. Èyí yíò fi àyè gba gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run láti gba àwọn ìlànà ìgbàlà àti ìgbéga àti láti dá àti láti pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́. Yíyege láti dá àwọn májẹ̀mú mímọ́ kìí ṣe ìtiraka ìgbà-kan ṣùgbọ́n àwòṣe ìgbá-ayé. Olúwa ti wípé yíò gba ọkàn kíkún, okun, àti agbára.
Kíkópa lemọ́lemọ́ nínú àwọn ilànà tẹ́mpìlì lè dá àwòṣe ti ìfọkànsìn sílẹ̀ sí Olúwa. Nígbàtí ẹ bá pa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì yín mọ́ tí ẹ sì nrántí wọn, ẹ lè pe ojúgbà Ẹ̀mí Mímọ́ sí fífún lókun àti sísọdimímọ́ yín.
Nígbànáà ẹ lè ní ìrírí ìmọ̀lára ìmọ́lẹ̀ àti ìrétí tí ó njẹ́ ẹ̀rí pé àwọn ìlérí náà jẹ́ òtítọ́. Ẹ ó wá láti mọ pé gbogbo májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run ni ànfàní kan láti sún mọ́ Ọ, èyí tí yíò dá ìfẹ́ sílẹ̀ nínú ọkàn yín láti pa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì mọ́.
A ti ṣe ìlérí fún wa pé, “Nítorí májẹ̀mú wa pẹ̀lú Ọlọ́run, Òun kò ní ṣàárẹ̀ láé nínú àwọn ìtiraka Rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́, a kò sì ní tán sùúrù tó kún fún àánú Rẹ̀ pẹ̀lú wa láé.”
Nípa àwọn májẹ̀mú èdidì nínú tẹ́mpìlì ni a ti lè gba ìdánilójú àwọn ìsopọ̀ ìfẹ́ni ẹbí tí yíò tẹ̀síwájú lẹ́hìn ikú àti títí di àìlópin. Bíbu-ọlá fún májẹ̀mú ìgbeyàwó àti ẹbí tí a ṣe nínú tẹ́mpìlì Ọlọ́run yíò pèsè ààbò kúrò nínú ibi ìmọtaraẹni-nìkàn àti ìgbéraga.
Ìtọ́jú léraléra ti àwọn arákùnrin àti arábìnrin fún ara wọn yíò wá nìkan pẹ̀lú ìtiraka lemọ́lemọ́ láti darí ẹbí yín ní ọ̀nà Olúwa. Fún àwọn ọmọ ní ànfàní láti gbàdúrà fún ara wọn. Ní ìwóye kíákíá nípa àwọn ìbẹ̀rẹ̀ asọ̀, àti àwọn ìṣe ìdámọ̀ dídára ti iṣẹ́ ìsìn àìní-ìmọtaraẹni-nìkan, nípàtàkì sí ara wọn. Nígbàtí arákùnrin àti arábìnrin bá gbàdúrà fún ara wọn tí wọ́n sì nsin ara wọn, àwọn ọkàn yíò di rírọ̀ yíò sì yípadà sí ara wọn àti sí àwọn òbí wọn.
Ní apákan, èyí ni ohun tí a júwe nípasẹ̀ Málákì bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ nípa wòlíì Elijah pé: “Òun yío gbin àwọn ìlérí tí a ṣe fún àwọn baba sí inú ọkàn àwọn ọmọ, ọkàn àwọn ọmọ yío sì yí sí àwọn baba wọn. Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, gbogbo ilẹ̀ ayé yíò ṣòfò pátápátá ní bíbọ̀ rẹ̀.”
Àwọn àdánwò, ìpenijà, àti ìrora-ọkàn yíò wá sọ́dọ̀ gbogbo wa dájúdájú. Kò sí ìkankan lárá wa tí ó ní òmìnira kúrò nínú “àwọn ẹ̀gún [ti] ẹran-ara.” Síbẹ̀, bí a ti nlọ sí tẹ́mpìlì tí a sì nrántí àwọn májẹ̀mú wa, a lè múràsílẹ̀ láti gba ìdarí araẹni látọ̀dọ̀ Olúwa.
Nígbàtí Kathy àti èmi ṣe ìgbeyàwó tí a si ṣe èdidì ní Tẹ́mpìlì Logan Utah, Alàgbà Spencer W. Kímball nígbànáà ṣe èdidì náà. Nínú ọ̀rọ̀ díẹ̀ tí ó sọ, ó fún wa ní àmọ̀ràn yí: “Hal àti Kathy, ẹ gbé ìgbé ayé kí ẹ lè rìn lọ nírọ̀rùn, nígbàtí ìpè bá dé.”
Ṣíwájú, a kò ní òye ohun tí àmọ̀ràn túmọ̀sí fún wa, ṣùgbọ́n a ṣe dídára wa jùlọ láti gbé ìgbé ayé wa ní irú ọ̀nà tí a ó fi múrasílẹ̀ láti sin Olúwa nígbàtí ìpè náà bádé. Lẹ́hìn tí a ti ṣe ìgbeyàwó fún bíi ọdún mẹ́wá, ìpè àìró kan wá láti ọ̀dọ̀ Kọ̀míṣọ́nà Ilé-ẹ̀kọ́ Ìjọ, Neal A. Maxwell.
Àmọ̀ràn ìfẹ́ni tí a fúnni látẹnu Ààrẹ Kimball nínú tẹ́mpìlì láti lè “rìn kúrò ní ìrọ̀rùn” di òdodo. Ó jẹ́ ìpè kan láti fi ohun tó dàbí ipò ẹbí tó níbámu sílẹ̀ láti sìn ní ibi kan tí a yàn tí èmi kò mọ̀ ohunkankan nípa rẹ̀. Bákannáà, ẹbí wa ṣetán láti kúrò nítorí wòlíì kan, nínú tẹ́mpìlì mímọ́, ibi ìfihàn kan, a rí ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú fún èyí tí a ti múrawásílẹ̀ nígbànáà.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo jẹ́ ẹ̀rí pé kò sí ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ju bíbu-ọlá fún àwọn májẹ̀mú yín tí ẹ ti dá tàbí tí ẹ lè dá nínú tẹ́mpìlì. Ibi èyíówù kí ẹ wà lórí ọ̀nà ipa májẹ̀mú, mo rọ̀ yín láti yege kí ẹ sì di yíyẹ láti lọ sí tẹ́mpìlì. Ẹ ṣe ìbẹ̀wò lemọ́lemọ́ bí àwọn ipò yíò ti fi àyè gbà. Ẹ dá kí ẹ sì pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Mo lè mu irú òtítọ́ kannáà tí mo pín pẹ̀lú Kathy ní àárín òru ní bíi díkédì marun sẹ́hìn nínú yàrá ilé-ìtura Ìṣubú Idaho kékeré dá yín lójú pé: “Bíótiwù kí àbájáde náà jẹ́, gbogbo rẹ̀ yíò dára nítorí tẹ́mpìlì.”
Mo fún yín ní ẹ̀rí ìdánilójú pé Jésù ni Krístì. Ó wà láàyè ó sì ndarí Ìjọ Rẹ̀. Àwọn Tẹ́mpìlì jẹ́ ilé Olúwa. Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì alààyè Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Mo nifẹ rẹ̀, mo sì nifẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan yín. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.