“Ẹ Dúró Jẹ́ẹ́, Kí Ẹ Sì Mọ̀ Pé Èmi Ni Ọlọ́run”
A lè dúró jẹ́ẹ́ kí a sì mọ̀ pé Ọlọ́run ni Baba wa Ọ̀run, àwa ni ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì sì ni Olùgbàlà wa.
Nígbà ilé ṣíṣí àìpẹ́ àti ọjọ́ ìròhìn fún ilé Olúwa titun, mo darí ẹgbẹ́ àwọn oníròhìn kan lórí ìrìnkiri nínú ilé mímọ́ náà. Mo júwe èrèdí àwọn tẹ́mpìlì nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn mo sì fèsì sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbèèrè títayọ̀ wọn.
Ṣíwájú wíwọ yàrá sẹ̀lẹ́stíà, mo ṣàlàyé pé yàrá yí nípàtàkì nínú ilé Olúwa pẹ̀lú àmì nṣojú àláfíà àti ẹwà ilé tọ̀run sí èyí tí a lè padà lẹ́hìn ayé yí. Mo fihàn sí àwọn àlejò wa pé a kò ní sọ̀rọ̀ nígbàtí a bá wà nínú yàrá sẹ́lẹ́stíà, ṣùgbọ́n inú mi yíò dùn láti dáhùn ìbèèrè eyikeyi lẹ́hìn tí a bá lọ síbi tókàn lórí ìrìnkiri wa.
Lẹ́hìn tí a kúrò nínú yàrá sẹ́lẹ́stíà àti bí a ti kórajọ ní ibi tókàn, mo bèèrè lọ́wọ́ àwọn àlejò wa bí wọ́n bá ní àkíyèsí kankan tí wọ́n fẹ́ láti pín. Ọ̀kan lára àwọn oníròhìn náà pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn wípé, “Èmi kò tíì ní ìrírí ohunkóhun bíi ti èyí rí ní gbogbo ayé mi. Èmi kò mọ̀ pé ibi jẹ́jẹ́ bẹ́ẹ̀ wà nínú ayé; èmi kò gbàgbọ́ pé irú ìdúrójẹ́ẹ́ bẹ́ẹ̀ ṣì ṣeéṣe.”
Mo di lílù nípa òdodo àti ọ̀rọ̀ líle ẹni yí. Àti pé ìfèsì oníròhìn náà fàmìsí ìwò pàtàkì kan nípa ìdúrójẹ́ẹ́—bíborí àti yíyí ìdàrúdàpọ̀ ti ìta àyíká wa jáde.
Bí mo ti jíròrò ọ̀rọ̀ oníròhìn náà lẹ́hìnwá tí mo sì ronú lórí ìṣísẹ̀ ìgbé ayé wa òde òní—ṣíṣaápọn, aruwo, yíyísápákan, ìdàmú, àti ìyíká tí ó dàbí ó nfẹ́ dojúkọ wa léraléra—ìwé-mímọ́ kan wá sínú mi: “Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run.”
Mo gbàdúrà pé kí Ẹ̀mí Mímọ́ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ní òyè bí a ti nyẹ ìwọ̀n gígajù àti mímọ́jù ti ìdúrójẹ́ẹ́ nínú ayé wa wò—ìdúrójẹ́ẹ́ inú ti-ẹ̀mí ti ọkàn náà tí ó nmú wa mọ̀ àti láti rántí pé Ọlọ́run ni Baba wa Ọ̀run, àwa ni ọmọ Rẹ̀, àti pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà wa. Ìbùkún alámì yí wà fún gbogbo àwọn ọmọ Ìjọ tí wọ́n ntiraka lotitọ láti di “àwọn ènìyàn májẹ̀mú Olúwa.”
Dúró Jẹ́ẹ́
Ní 1833 àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní Missouri jẹ́ àwọn ibi-àfẹ́dé líle ìninilára. Àwọn ènìyàn búburú ti lé wọn kúrò ní ilé wọn ní Agbègbè Jackson, àti pé àwọn ọmọ Ìjọ kan ti gbìyànjú láti gbé ara wọn kalẹ̀ ní àwọn agbègbè míràn nítòsí. Ṣùgbọ́n ìninilára náà tẹ̀síwájú, àti ìdẹ́rùbà ikú lọ́pọ̀lọpọ̀. Nínú àwọn ipò ìpènijà wọ̀nyí, Olúwa fi àwọn ìkọ́ni wọ̀nyí fún Wòlíì Joseph Smith ní Kirtland, Ohio:
“Nítorínáà, ẹ jẹ́kí ọkàn yín ní ìtùnú nípa Síónì; nítorí gbogbo ẹran ara wà ní ọwọ́ mi; ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì mọ̀ pé Èmi ni Ọlọ́run.”
Mo gbàgbọ́ pé ìkìlọ̀ Olúwa láti “dúró jẹ́ẹ́” ní púpọ̀ nínú ju kí a máṣe sọ̀rọ̀ tàbí rìn lásán. Bóyá èro-inú Rẹ̀ ni fún wa láti rántí kí a sì gbára lé E àti agbára Rẹ̀ “ní gbogbo ìgbà àti nínú ohun gbogbo, àti ní ibi gbogbo kí [a] lè wà nínú rẹ̀.” Bayi, “dúró jẹ́ẹ́” bóyá ọ̀nà kan láti rán wa létí láti dójúkọ Olùgbàlà láìkùnà bí orísùn ìgbẹ̀hìn ti ìdúrójẹ́ẹ́ ti ọkàn láti fún wa lókun láti ṣe áti láti borí àwọn ohun líle.
Gbéró lorí Àpátá
Ìgbàgbọ́ tòótọ́ máa nní ìdojúkọ nínú àti lórí Olúwa Jésù Krístì—nínú Rẹ̀ bí Ọmọ Kanṣoṣo àti Àtọ̀runwa Baba Ayérayé àti lórí Rẹ̀ àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìràpadà tí Ó múṣẹ.
“Nítorítí ó ti ṣe ìdáhùn sí àwọn ohun tí ofin bẽrè fún, ó sì ti gbà gbogbo àwọn ti ó gbàgbọ́ nínú rẹ̀; àwọn tí ó sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ yíò rọ̀ mọ́ ohun rere gbogbo; nítorí èyí ó ṣe alágbàwí fún èyítí í ṣe tí àwọn ọmọ ènìyàn.”
Jésù Krístì ni Olùràpadà wa, Olùlàjà wa, àti Alágbàwí wa pẹ̀lú Baba Ayérayé àti àpáta lórí èyí tí a níláti gbé ìpìnlẹ̀ ti-ẹ̀mí ayé wa ró lé.
Hẹ́lámánì ṣàlàyé, “Ẹ rántí, ẹ rántí pé lórí àpáta Olùràpadà wa, ẹnití íṣe Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, ni ẹ̀yin níláti gbé ìpìlẹ̀ yín lé; pé nígbàtí èṣù bá sì fẹ́ ẹ̀fũfù líle rẹ̀ wá, bẹ̃ni, ọ̀pá rẹ̀ nínú ìjì, bẹ̃ni, nígbàtí gbogbo àwọn òkúta yìnyín rẹ̀ àti ìjì líle rẹ̀ bá rọ̀ lé yín kò lè ní agbára lórí yín láti fà yín sínú ọ̀gbun òṣì àti ègbé aláìlópin, nítorí àpáta èyítí a gbé yín lé, lórí èyítí íṣe ìpìlẹ̀ tí o dájú, ìpìlẹ̀ èyítí ènìyàn kò lè ṣubú lórí rẹ̀ bí nwọ́n bá gbé lé e lórí.”
Ìfàmìsí ti Krístì bí “àpáta” lórí ẹnití a níláti gbé ìpìnlẹ̀ ìgbé ayé wa ró sí ni ó lẹkọ jùlọ. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kíyèsi nínú ẹsẹ yí pé Olùgbàlà kìí ṣe ìpìlẹ̀. Ṣùgbọ́n, a kìlọ̀ fún wa láti gbé ìpìlẹ̀ ti-ẹ̀mí araẹni wa ró lórí Rẹ̀.
Ìpìlẹ̀ náà ni ara ilé tí ó so ó mọ́ ilẹ̀. Ìpìlẹ̀ líle npèsè ààbò látinú àwọn àjálù àdánidá àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ipa ìparun míràn. Ìpìlẹ̀ dáadáa bákannáà npín ìwúwo ìkọ́lé lórí ibi títóbi láti yẹra fún pípalẹ́rù ẹ̀rùpẹ̀ abẹ́ tí ó sì npèsè ìtẹ́jú òde fún kíkọ́.
Ìsopọ̀ líle tí ó sì ṣeé gbẹ́kẹ̀lé ní àárín ilẹ̀ àti ìpìlẹ̀ kan ṣe pàtàkì bí ìkọ́lé kan bá níláti wà gbọingbọin kí ó sì dúróṣinṣin fún ìgbà pípẹ́. Àti nípàtàkì fún àwọn irú kíkọ́, tí ó rọ̀mọ́ pínnì àti ọ̀pá irin ni a lè lò láti lẹ̀ ìpìlẹ̀ ilé mọ́ “àpáta,” líle, àpáta líle abẹ́ òkè àwọn ohun-èlò bí iyanrìn àti wẹ́rẹ́kúta.
Ní irú ọ̀nà kannáà, ìpìlẹ̀ ìgbé ayé wa gbúdọ̀ wà ní ìsopọ̀ sí àpáta Krístì bí a bá fẹ́ dúró ṣinṣin àti gbọingbọin. Àwọn májẹ̀mú àti ìlànà ti ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Olùgbàlà ni a lè fi wé ìrọ̀mọ́ pínnì àti ọ̀pá irin tí a lò láti so ilé mọ́ àpáta-líle. Gbogbo ìgbà tí a bá fi òtítọ́ gba, yẹ̀wò, rántí, tí a sì tún àwọn májẹ̀mú mímọ́ ṣe, àwọn ìrọ̀mọ̀ ti ẹ̀mí wà wà ní ààbò gbọingbọin àti ṣinṣin láéláé sí “àpáta” Jésù Krístì.
“Nítorí èyí, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run lè ní ìrètí dájúdájú fún ayé tí ó dára jù, bẹ̃ni, àní àyè ní apá ọ̀tún Ọlọ́run, ìrètí èyítí nwá nípa ìgbàgbọ́, tí ó sì rọ̀ mọ́ ọkàn ènìyàn, èyítí yíò mú wọn dúró gbọingbọin àti ní ìdúróṣínṣin, tí wọn sì kún fún iṣẹ́ rere ní gbogbo ìgbà, tí a sì darí wọn láti yìn Ọlọ́run lógo.”
Pẹ̀lú àlékún àti púpọ̀si “ní ìgbà ìṣètò,” “ìwàrere [ntún] èrò wa ṣe láìsimi,” ìgbẹ́kẹ̀lé wa “sì [nlágbára àti lágbára si] níwájú Ọlọ́run,” àti pé “Ẹ̀mí Mímọ́ ó [jẹ́] ojúgbà wa léraléra.” À ó di fífẹsẹ̀múlẹ̀, ní gbòngbò, gbékalẹ̀, àti fìdíkalẹ̀ síi. Bí a ṣe ngbé ìpìlẹ̀ ìgbé ayé wa lórí Olùgbàlà, à di alábùkúnfún láti “dúró jẹ́ẹ́”—láti ní ìdánilójú ti ẹ̀mí pé Ọlọ́run ni Baba wa Ọ̀run, àwa sì ni ọmọ Rẹ̀, àti pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà wa.
Àwọn Ìgbà Mímọ́, Ibi Mímọ́, àti Ilé náà
Olúwa npèsè àwọn ìgbà mímọ́ àti ibi mímọ́ láti ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìrírí àti láti kọ́ nípa dídúró jẹ́ẹ́ inú ti ọ̀kan wa.
Fún àpẹrẹ, Ọjọ́-ìsinmi ni ọjọ́ Ọlọ́run, àkokò mímọ́ kan tí a yàsọ́tọ̀ láti jọ́sìn Baba ní orúkọ Ọmọ Rẹ̀, láti kópa nínú àwọn ìlànà oyè-àlùfáà, àti láti gba àti láti tún àwọn májẹ̀mú wa ṣe. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ à njọ́sìn Olúwa ní ìgbà àṣàrò ilé wa àti bí “ọmọlàkeji-ilú pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́” nínú oúnjẹ Olúwa àti àwọn ìpàdé míràn. Ní ọjọ́ mímọ́ Rẹ̀, àwọn èrò, ìṣe, àti ìhùwàsí wa jẹ́ àmì tí a nfún Ọlọ́run àti ìfihàn ìfẹ́ wa fún Un. Ní ọjọọ́ọ̀jọ Ìsinmi, bí a ó bá, a lè dúró jẹ́ẹ́ kí a sì mọ̀ pé Ọlọ́run ni Baba wa Ọ̀run, àwa ni ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì sì ni Olùgbàlà wa.
Gbùngbun àwòrán ìjọsìn Ọjọ́-ìsinmi wa ni láti “lọ sí ilé àdúrà kí a sì fi oúnjẹ Olúwa [wa] fúnni lórí ọjọ́ mímọ́ [Olúwa].” Àwọn “ilé [ti] àdúrà” nínú èyí tí a kórajọ ní Ọjọ́-ìsìnmi ni àwọn ilé ìpàdé àti àwọn ilé míràn tí a fàṣẹ sí—àwọn ibi mímọ́ ti ọ̀wọ̀, ìjọ́sìn, àti ikẹkọ. Ilé ìpàdé kọ̀ọ̀kan àti ilé ni a yàsímímọ́ nípasẹ̀ àṣẹ oyè-àlùfáà bí ibikan níbití Ẹ̀mí Olúwa lè gbé àti níbití àwọn ọmọ Ọlọ́run ti lè wá “sí ìmọ̀ Olùràpadà wọn.” Bí a ó bá, a lè “dúró jẹ́ẹ́” nínú àwọn ibi mímọ́ ìjọsìn wa kí a si mọ̀ dájú títí pé Ọlọ́run ni Baba wa Ọ̀run, àwa ni ọmọ Rẹ̀, àti pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà wa.
Tẹ́mpìlì ni ibi mímọ́ míràn tí a yàsọ́tọ̀ nípàtàkì fún jíjọ́sìn àti sísin Ọlọ́run àti kíkọ́ àwọn òtítọ́ ayérayé. À nronú, ṣe ìṣe, a sì nmúra yàtọ̀ nínú ilé Olúwa kúrò ní àwọn ibikíbi míràn tí a lè lọ déédé. Nínú ilé mímọ́ Rẹ̀, bí a ó bá, a lè dúró jẹ́ẹ́ kí a sì mọ̀ pé Ọlọ́run ni Baba wa Ọ̀run, àwa ni ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì sì ni Olùgbàlà wa.
Kókó àwọn èrèdí ti ìgbà mímọ́ àti ibi mímọ́ jẹ́ ọkànnáà ní ìbádọ́gbà: láti fi ìfojúsí wa sórí Baba wa Ọ̀run àti èto Rẹ̀ léraléra, Olúwa Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀, agbára ìgbéga ti Ẹ̀mí Mímọ́, àti àwọn ìlérí tí ó rọ̀mọ́ àwọn ìlànà mímọ́ àti májẹ̀mú ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Olùgbàlà.
Ní òní mo tún ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kan tí mo ti tẹnumọ́ sọ. Ilé wa níláti jẹ́ àpapọ̀ ti ìgbà mímọ́ àti ibi mímọ́ níbití àwọn olúkúlùkù àti ẹbí ti lè “dúró jẹ́ẹ́” kí wọ́n sì mọ̀ pé Ọlọ́run ni Baba wa Ọ̀run, àwa ni ọmọ Rẹ̀, àti pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà wa. Fífi ile wa sílẹ̀ láti jọ́sìn ní Ọjọ́-ìsinmi àti ní ilé Olúwa dájúdájú ṣe pàtàkì. Ṣùgbọ́n bí a ti npadà sí ilé wa pẹ̀lú ìwòye ti-ẹ̀mí nìkan àti okun tí a gbà ní àwọn ibi mímọ́ wọnnì àti àwọn ṣíṣe ni a lè mú idojúkọ wa dúró lórí kókó èrèdí ti ayé ikú nígbànáà kí a borí àwọn àdánwò tí ó gbilẹ̀ gidi nínú ayé ṣíṣubú wa.
Ọjọ́-ìsìnmi, tẹ́mpìlì, àti àwọn ìrírí tí ó nlọ lọ́wọ́ nílàtì fún wa ní ààbò pẹ̀lú agbára Ẹ̀mí Mímọ́, pẹ̀lú lílọ lọ́wọ́ àti ìsopọ̀ májẹ̀mú alágbárajù sí Baba àti Ọmọ, àti pẹ̀lú “ìrètí pípé dídán kan” nínú àwọn ìlérí ayérayé Ọlọ́run.
Bí ilé àti Ìjọ ti nkórajọ papọ̀ ní ọ̀kan nínú Krístì, a lè ní ìdàmú ní ẹ̀gbẹ́ gbogbo, ṣùgbọ́n a kò ní ní ìrẹ̀wẹ̀sì ní inú àti ọkàn wa. A lè ní ìpayà nípa àwọn ipò àti ìpènijà wa, ṣùgbọ́n a kò ní wà láìní-ìrètí. A lè di nínilára, ṣùgbọ́n bákannáà a ó damọ̀ pé a kò dáwà. A lè gba okun ti-ẹ̀mí láti di àti láti dúró gbọingbọin, ṣinṣin, àti lòótọ́.
Ìlérí àti Ẹrí
Mo ṣèlérí pé bí a ti nkọ́ ìpìnlẹ̀ ìgbé ayé wa lórí “àpáta” ti Jésù Krístì, a lè di alábùkúnfún nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ láti gba ẹnìkan àti ìdúrójẹ́ẹ́ ti-ẹ̀mí ti ọkàn tí ó mu ṣeéṣe fún wa láti mọ̀ àti láti rántí pé Ọlọ́run ni Baba wa Ọ̀run, àwa ni ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì ni Olùgbàlà wa, a sì lè di alábùkún láti ṣe àti láti borí àwọn ohun líle.
Mo fi pẹ̀lú ayọ̀ jẹri pé Ọlọ́run ni Baba wa Ọ̀run, àwa ni àwọn ọmọ Rẹ̀, àti pé Jésù Krístì ni Olùràpadà wa àti “àpátà” ìgbàlà wa. Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Olúwa Jésù Krístì, àmín.