Àwọn Tẹ́mpìlì, Ilé Olúwa Nkún Ilẹ̀-ayé
Bí ẹ ti nwá ní yíyẹ àti pẹ̀lú àdúrà sí ilé mímọ́ Rẹ̀, ẹ yíò di ìhámọ́ pẹ̀lú agbára Rẹ̀.
Njẹ ẹ kò fẹ́ràn àwọn ọ̀rọ̀ dídára tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ tán? “Èmi ó fún yín lókun, ràn yín lọ́wọ́, n ó sì mú yín dúró, … ìdìmú nípa ọwọ́ òdodo, agbára àìlópin mi.” Olúwa nfún àwọn Ènìyàn Mímọ́ ti gbogbo ọjọ́ orí lókun bí wọ́n ti nwá sí ilé mímọ́ Rẹ̀. Láti Kinshasa sí Zollikofen sí Fukuoka sí Oakland, àwọn ọ̀dọ́, nípa ọgbọ́n ara wọn, nkún àwọn ibi ìrìbọmi ní àkúnwọ́sílẹ̀. Ní àtẹ̀hìnwá, ọ̀pọ̀ àwọn àyànfẹ́ òṣìṣẹ́ ìlànà ní irun funfun—ṣùgbọ́n kìí ṣe bayi mọ́. Àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere tí a pè, ojíṣẹ́ ìhìnrere iṣẹ́-ìsìn, àti àwọn ojíṣẹ́ ìhìnrere ìpadàbọ̀ wà ní àyíká igun gbogbo. Káàkiri àgbáyé, ìmọ̀lára ìdàgbà kan nmú wa súnmọ́ ilé Olúwa.
Bí ọdún kan sẹ́hìn, ọ̀rẹ́ ẹbí ọ̀wọ́n kan, ọjọ́ orí marundinlọgọrun, ngbé lórí etíkun ìlà-oòrùn Ilú Amẹ́ríkà, ẹnití a ti kọ́ nípasẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere fún àádọ́rin ọdún, wí fún ọmọbìnrin rẹ̀ pé, “Mo fẹ́ láti lọ sí tẹ́mpìlì pẹ̀lú rẹ.”
Ọmọbìnrin rẹ̀ fèsì pé, “Ó dára, ìyá, o nílò láti ṣe ìrìbọmi lakọkọ.”
“Ó dára,” ó fèsì, “nígbànáà, mo fẹ́ láti ṣe ìrìbọmi.” Ó Ṣe Ìrìbọmi. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́hìnnáà, ó fi pẹ̀lú ọ̀wọ̀ wọ ibi ìrìbọmi tẹ́mpìlì. Àti pé ju oṣù kan sẹ́hìn, ó gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì ti ara rẹ̀ ó si ṣe èdidì. “Ìmọ̀ àti agbára Ọlọ́run ngbòòrò; Ìbòjú lórí ayé nbẹ̀rẹ̀ láti já.”
Ṣe ẹ ti ronú ìdí tí Olúwa yíò fi darí wòlíì Rẹ̀ láti fi àwọn tẹ́mpìlì Rẹ̀ sọlẹ̀ káàkiri ilẹ̀ ayé? Kínìdí tí Òun yíò fi, ní àkokò yí pàtó, fi ire tí a nílò fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ pé nípa idamẹwa mímọ́ wọn, ọgọọgọrun àwọn ilé Olúwa ni a ti lè kọ́?
Ní òwúrọ̀ yí, Ààrẹ Oaks fi ìwò ẹlẹ́wà ti àwọn tẹ́mpìlì tí à nkọ́ káàkiri àgbáyé hàn. Kathy àti èmi wà ní Philippines láìpẹ́. Ẹ ronú nípa iṣẹ́ ìyanu yí: Tẹ́mpìlì Manila ni a yàsímímọ́ ní 1984. Ó jẹ́ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ṣíwájú kí a tó parí tẹ́mpìlì kejì ní Ìlú Cebu ní 2010. Nísisìyí, ọdún mẹ́rìnlá lẹ́hìnnáà, àwọn tẹ́mpìlì mọ́kànlá ni à nkọ́, yàwòrán, tàbí múrasílẹ̀ fún yíyàsímímọ́. Láti àríwá sí gúsù: Laoag, Tuguegarao, Santiago, Urdaneta, Alabang, Naga, Tacloban City, Iloilo, Bacolod, Cagayan de Oro, àti Davao. Ó yanilẹ́nu láti rí àwọn iṣẹ́ àrà Ọlọ́run!
Ní àgbáyé káàkiri, àwọn ilé Olúwa nbọ̀ wá súnmọ́ wa. Kínìdí ní ọjọ́ wa?
Oúnjẹ Alẹ́ Ìkẹhìn
Olúwa kìlọ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, ìrẹ̀wẹ̀sì yíò wà ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ènìyàn yíò “jẹ́ olólùfẹ́ ti ara wọn,” gbogbo ohun [yíò] wà ní rúdurùdu,” ìdàmú yíò wà, àti pé “ọkàn àwọn ènìyàn [yíò] mú wọn kùnà.” Dájúdájú a ti ri tí ọkàn àwọn ọkùnrin àti obìnrin nmú wọn kùnà: àwọn ẹ̀tàn ayé, ìdàmú àwọn ohùn fífanimọ́ra, ìpatì ìṣìkẹ́ ti-ẹ̀mí, ìrẹ̀wẹ̀sì látinú àwọn ìbèèrè ọmọẹ̀hìn. Bóyá ẹ ti ní ìbànújẹ́ bí ẹ ti nrí ẹnìkan tí ẹ fẹ́ràn, ẹnití ó ti sọ̀rọ̀ lódodo nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Jésù Krístì lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin ní ìgbà kan, tí ó jẹ́ ẹ̀rí nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì, tí ó sì ṣèrànwọ́ láti gbé ìjọba Ọlọ́run ga, lójijì tí ó kúrò, ó kérejù ní bayi, kúrò nínú àwọn ìgbàgbọ́ rẹ̀ lọ́kùnrin tàbí lóbìrin síwájú ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Ìjọ. Àmọ̀ràn mi sí yín ni kí ẹ máṣe sọ ìrètí nù! Gbogbo rẹ̀ dára! Nítorí pẹ̀lú Ọlọ́run, kò sí ohun tí kò ṣeéṣe.
Pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ rúdurùdu yí àti àìgbàgbọ́ inú ayé, Olúwa ṣe ìlérí pé àwọn ènìyàn olódodo yíò wà, àwọn ènìyàn tí wọ́n nyára dúró de ìpadàbọ̀ Rẹ̀; àwọn ènìyàn kan tí wọ́n dúró nínú àgbékalẹ̀ mímọ́ tí wọn kò sì yẹsẹ̀ kúrò nínú àyè wọn. Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ènìyàn olódodo tí wọ́n tako àwọn ẹ̀tàn ọ̀tá, nkó ìgbàgbọ́ wọn níjánu, ní ríronú sẹ̀lẹ́stíàl, tí wọ́n sì nní ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá nínú Olùgbàlà, Jésù Krístì.
Kínìdí tí Olúwa fi nmú àwọn ọgọọgọrun tẹ́mpìlì Rẹ̀ wá sítòsí wa nísisìyí? Èrèdí kan ni pé ní àárín ìrúkèrúdò àti àwọn àdánwò àgbáyé, Ó ti ṣe ìlérí láti fúnlókun àti láti bùkún àwọn Ènìyàn Mímọ́ májẹ̀mú Rẹ̀, àti pé àwọn ìlérí ni a si nmúṣẹ.
Àwọn ìlérí láti Tẹ́mpìlì Kirtland
Báwo ni àwọn ilé mímọ́ wọ̀nyí ṣe nfi okun, ìtùnú, àti ààbò fún wa? À nrí ìdáhùn nínú àwọn ẹ̀bẹ̀ Wòlíì Joseph Smith nínú ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Kirtland. Inú tẹ́mpìlì ni àwọn Ènìyàn Mímọ́ ti kọ́kọ́ kọ, “A ó kọrin a ó sì kígbe pẹ̀lú àwọn ogun ọ̀run.” Olùgbàlà Fúnrarẹ̀ farahàn, àwọn wòlíì àtijọ sì padà, wọ́n sì fi àfikún àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà sí ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere.
Ní ọ̀ràn mímọ́ nínú Tẹ́mpìlì Kirtland, wòlíì gbàdúrà pé nínú ilé mímọ́ Olúwa, àwọn Ènìyàn Mímọ́ yíò wà ní àhámọ́ pẹ̀lú agbára Ọlọ́run, pé orúkọ Jésù Krístì yíò wà lórí wọn, pé àwọn ángẹ́lì Rẹ̀ yíò ní àṣẹ lórí wọn, àti pé wọn yíò dàgbà nínú Olúwa wọn ó sì gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́. Àwọn ẹ̀bẹ̀ alágbára wọ̀nyí ní ìmúṣẹ nínú ayé wa bí a ti njọ́sìn lotitọ nínú ilé Olúwa.
Di Ìhámọ́ra pẹ̀lú Òdodo
Nínú ilé Rẹ̀, bí ọ̀rọ̀ a fún wa ní ẹ̀bùn pẹ̀lú agbára tọ̀run. Ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì àti ìfẹ́ wa fún Un ni a fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ tí a sì ndá ààbò bò. A ní ìdánilójú ti-ẹ̀mí nípa ìdánimọ̀ òtítọ́ àti àwọn èrèdí ìgbé ayé wa. Bí a ti njẹ́ olotitọ, a di alabùkúnfún pẹ̀lú ààbò látinú àwọn ìdánwò àti ìdàmú. A nní ìmọ̀lára ìfẹ́ Olùgbàlà bí Ó ti ngbé wa ga kúrò nínú àwọn ìṣòro àti ìkorò wa. A di àhámọ́ra pẹ̀lú agbára Ọlọ̀run.
Orúkọ Rẹ̀ wà lóri Wa
Nínú ilé mímọ́ Rẹ̀, à ngbé orúkọ Rẹ̀ lé orí ara wa pátápátá. Nígbàtí a bá ṣe ìrìbọmi, à nfi ìgbàgbọ́ wa hàn nínú Rẹ̀ àti ìfẹ́ wa láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Nínú tẹ́mpìlì, à ṣe ìlérí mímọ́, nípasẹ̀ májẹ̀mú wa, láti tẹ̀lé E títíláé.
Àwọn ọ̀dọ̀ Ìjọ yí lámì gidi. Nínú ayé ṣíṣòro, wọ́n ngbé orúkọ Krístì lé orí arawọn. Ní Ìlú Heber, Utah, ìpàdé gbangbà kan ni a ṣe láti sọ̀rọ̀ yékéyéké nípa ìṣètò tẹ́mpìlì fún kíkọ́. Ọgọrun mẹta àwọn ọ̀dọ́ kún ẹ̀gbẹ́ ibùdókọ̀ láti fi àtìlẹhìn wọn hàn fún tẹ́mpìlì tí à ngbèrò. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan, tó bá àwọn asáájú ìjọba sọ̀rọ̀ ní ibi àpèjọ fi ìgboyà ṣe àlàyé pé, “Mo ní ìrètí láti ṣe ìgbeyàwó nínú tẹ́mpìlì yí. [Tẹ́mpìlì náà yíó ràn mí lọ́wọ́] láti pa ara mi mọ́ ní mímọ́ àti láìléèrí.” Òmíràn júwe tẹ́mpìlì bí àmì ìmọ́lẹ̀ àti ìrètí. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin Ìjọ káàkiri ayé nrọ̀mọ́ orúkọ Jésù Krístì.
Àwọn ángẹ́lì láarín Wa
Nínú Tẹ́mpìlì Kirtland, Wòlíì Joseph gbàdúrà pé “àwọn ángẹ́lì [yíò] ní àṣẹ lórí [àwọn Ènìyàn Mímọ́].” Ṣíṣe àwọn ìlànà déédé fún àwọn babanla wa nínú tẹ́mpìlì nmú ìfẹsẹ̀múlẹ̀ dídùn àti dídájú wá pé ìgbé ayé yíò tẹ̀síwájú kọjá ìkelè.
Bíótilẹ̀jẹ́pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìrírí wa nínú ilé Olúwa jẹ́ mímọ́ jùlọ láti pín ní gbangba, àwọn kan ni a lè pín. Ogójì ọdún sẹ́hìn, nígbàtí à ngbé ní Florida, Kathy àti èmi lọ sí tẹ́mpìlì ní Atlanta, Georgia. Ní alẹ́ Ọjọ́rú, Ọjọ́ Kẹsan Oṣù Karun, 1984, bí a ti parí abala kan nínú tẹ́mpìlì, òṣìṣẹ́ tẹ́mpìlì kan dé ọ̀dọ̀ mi ó sì bèèrè bí mo bá ní àkokò láti ṣe ìgbaniwọlé kan péré ṣíwájú ìlànà. Orúkọ ẹni náà tí mo rọ̀pò kò wọ́pọ̀. Orúkọ rẹ̀ ni Eleazer Cercy.
Ní ọjọ́ kejì, tẹ́mpìlì kún fún àwọn Ènìyàn mímọ́. Bí mo ti múrasílẹ̀ láti ṣe ẹ̀bùn tẹ́mpìlì mi kejì ní ọjọ́ náà, a fún mi ní orúkọ ẹni náà tí ẹ̀mi ó rọ́pò. Pẹ̀lú ìyàlẹ́nu, orúkọ náà ni ẹni kannáà ẹnìkan láti alẹ́ ṣíwájú, Eleazer Cercy. Mo nímọ̀lára Ẹ̀mí Olúwa bí ẹ̀bùn tẹ́mpìlì ti parí. Lẹ́hìnwá ní ọ̀sán náà, bí a ti nrìn nínú tẹ́mpìlì, Kathy rí àgbàlagbà ọ̀rẹ́ ẹbí kan, Arábìnrin Dolly Fernandez, ẹnití ó ngbé ní Atlanta nísisìyí. Pẹ̀lú àìsí ọkùnrin ọmọ ẹbí rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó bèèrè bí ó bá ṣeéṣe kí èmi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ ní ṣíṣe èdidì baba rẹ̀ sí àwọn òbí rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ni a bu-ọlá fún mi.
Bí mo ti kúnlẹ̀ ní òpin pẹpẹ fún ìlànà mímọ̀ yí, mo gbọ́ orúkọ náà nígbàkan si tí a ti kọ sí inú mi nísisìyí, baba rẹ̀, Eleazer Cercy. Mo gbàgbọ́ ní kíkún pé ní àtẹ̀lé ayé yí, èmi ó pàdé n ó sì rọ̀mọ́ ọkùnrin kan tí a mọ̀ nínú ayé ikú rẹ bí Eleazer Cercy.
Ọ̀pọ̀ àwọn ìrírí wa nínú ilé Olúwa nmú ayọ̀ ìfihàn àláfíà àti jẹ́jẹ́ wá ju ìlàjà eléré lọ. Ṣùgbọ́n ní ìdánilójú: àwọn ángẹ́lì ní àṣẹ lórí wa!
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́.
Ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ ni a fún wa bí a ti fi ẹsẹ̀ wa múlẹ̀ bí ọmọ Ìjọ. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ bí a ti nṣe àbápín búrẹ́dì àti omi ní yíyẹ ní ìrántí Olùgbàlà wa, a ṣe ìlérí fún wa pé Ẹ̀mí Rẹ̀ yíò wà pẹ̀lú wa nígbàgbogbo. Bí a ti nwá pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn sí ilé Olúwa, ibi mímọ́ jùlọ lórí ilẹ̀-ayé, à ndàgbà nínú Olúwa a sì lè “gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́.” Nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́, à nkún fún àláfíà àti ayọ̀ àti ìrètí àìlèsọ. À ngba okun láti dúró bí àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ àní nígbàtí a bá rí arawa ní òde àwọn ibi mímọ́.
Ààrẹ Russell M. Nelson kéde pé “Olùgbàlà àti Olùràpadà wa, Jésù Krístì, yio ṣe lára àwọn iṣẹ́ alágbára Rẹ̀ laarin ìsisìyí sí ìgbà tí Yìó padà wá lẹ́ẹ̀kansi. A ó rí ìfihàn àwọn iṣẹ́-ìyanu pé Ọlọ́run Baba àti Ọmọ Rẹ̀ … Jésù Krístì … nṣe àkóso lórí Ìjọ yí nínú ọlánlá àti ògo.” Sísọ ilẹ̀-ayé pẹ̀lú àwọn ilé Olúwa ni ìfihàn iṣẹ́ nlá àti iṣẹ́ ìyanu.
Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ àyànfẹ́ mi, bí a bá lè tí a kò sì ti mú lílọ sí tẹ́mpìlì wa pọ̀si tẹ́lẹ̀, ẹ jẹ́ kí a wá àkokò si déédé láti sìn nínú ilé Olúwa. Ẹ jẹ́ kí a gbàdúrà fún àwọn tẹ́mpìlì tí a ti kéde káàkiri ayé—kí a lè ra àwọn ohun ìní, pé àwọn ìjọba yíò fi àṣẹ sí àwọn ètò, pé àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹ́bùn yíò ri tí ẹ̀bùn wọn ó nígbéga, àti pé àwọn ìyàsímímọ́ mímọ́ yíò mú àṣẹ ti ọ̀run àti ìbẹwò àwọn ángẹ́lì wá.
Àwọn Ìlérí
Tẹ́mpìlì gangan jẹ́ ilé Olúwa. Mo ṣe ìlérí pé bí ẹ ti nwá ní yíyẹ tí ẹ sì nfi pẹ̀lú àdúrà wá sí ilé Olúwa, ẹ ó di ìhámọ́ra pẹ̀lú agbára Rẹ̀, orúkọ Rẹ̀ yíò sì wà lórí yín, àwọn ángẹ́lì Rẹ̀ yíò ní àṣẹ lórí yín, àti pé ẹ ó dàgbà nínú ìbùkún ti Ẹ̀mí Mímọ́.
Olúwa ṣèlérí pé, “Olúkúlùkù àwọn ọkàn tí ó bá kọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, àti tí ó ké pe orúkọ mi, tí ó sì gbọràn sí ohùn mi, àti tí ó pa àwọn òfin mi mọ́, yíò rí ojú mi yíò sì mọ̀ pé Èmi ni.” Àwọn ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wà láti rí ojú Krístì, kò sì sí ibi tí ó dára jù nínú ilé mímọ́ Rẹ̀.
Ní ọjọ́ ìdàmú àti rúdurùdu yí, mo jẹri pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tẹ́mpìlì wa ni ilé Rẹ̀ àti pé òun ó ṣèrànwọ́ láti dá wa sí, dá ààbò bò wá, àti múra wa sílẹ̀ fún ọjọ́ ológo nígbàtí, pẹ̀lú gbogbo àwọn ángẹ́lì Rẹ̀ mímọ́, Jésù Krístì ó padà nínú ọlánlá, agbára, àti ògo nlá. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.