Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ̀kọ́ Alágbára, Agbo Ìwàrere ti Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Ẹ̀kọ́ Alágbára, Agbo Ìwàrere ti Krístì

Mo pè yín láti gbé ìgbé ayé ẹ̀kọ́ Krístì léraléra, kí ẹ ṣe àtúnṣe, àti ìmọ̀ọ́mọ̀ àti ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlòmíràn ní ọ̀nà wọn.

Ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, ìyàwó mi Ruth, ọmọbìnrin wa, Ashley, àti èmi darapọ̀ mọ́ àwọn arìnrìn-àjò míràn lórí àbẹ̀wò-síbìkan lórí kéyákì ní ìpínlẹ̀ Hawaii ní Ìlú Amẹ́ríkà. Kéyákì ni ó súnmọ́ ìsàlẹ̀ omi, kenó bí ọkọ̀ ojú-omi nínú èyí tí ọ̀wakọ̀ náà joko ní ìdojúkọ síwájú tí ó sì nlo bílédì méjì ìyíkọ̀ láti tìí síwájú-sí-ẹ̀hìn àti ní ẹ̀gbẹ́ kan àti lẹ́hìnnáà sí òmíràn. Ètò náà ni láti yí sí erékùṣù méjì kékeré ní òdì etí-òkun ti Oahu kí a sì padà lẹ́ẹ̀kansi. Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nítorí bí ọ̀dọ́mọkùnrin, mo ti yí Kéyákì sọdá adágún òkè-gíga. Hubris kìí yọrí síre, àbí ó rí bẹ́ẹ̀?

Atọ́nà wa nfún wa ní àwọn ìkọ́ni ó sì nfi kéyákì òkun tí a ó lò hàn wá. Wọ́n yàtọ̀ sí àwọn tí mo ti yí tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó yẹ kí njoko lórí Kéyákì náà, dípò ìsàlẹ̀ nínú rẹ̀. Nígbàtí mo dé inú kéyákì náà, gbùngbun ìwà-pẹ̀sẹ̀ mi ga gan an ju bí ó ṣe mọ́ mi lára, mo sì wà ní ìdínkù ìdúróṣinṣin nínú omi.

Bi a ṣe bẹ̀rẹ̀, mo yára yíkọ̀ ju Ruth àti Ashley. Lẹ́hìn ìgbà díẹ̀, mo kọjá ṣíwájú wọn. Bíótilẹ̀jẹ́pé mo nígbéraga ti ààyè akọni mi, mo dáwọ́ ìyíkọ̀ dúró mo si dúró fún wọn láti bá mi. Ìjì nlá kan—bí sẹ́ntímítà mẹ́tàlá—kọlu ẹ̀gbẹ́ kéyákì mi ó si jù mí sókè sínú omi. Nígbàtí mo fi máa yí kéyákì mi padà tí mo sì tiraka láti bọ́ sórí rẹ̀, Ruth àti Ashley ti kọjá mi, ṣùgbọ́n atẹ́gùn ti pọ̀jù fún mi láti bẹ̀rẹ̀ ìyíkọ̀. Ṣaájú kí ntó lè ríra mi, atẹ́gùn míràn, ọ̀kan èyí tí ó le gidi—tí ó kéréjù ogún sẹntímítà—kọlu kéyákì mi ó sì jù mí sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kansi. Nígbàtí mo gira tán láti mú kéyákì mi sípò, ẹ̀mí mi ti fẹ́rẹ̀ bọ́ dé bi pé mo bẹ̀rù pé èmi kò ní lè gùn ún mọ́.

Ní wíwo ipò mi, atọ́nà ná yí wá ó sì mú kéyákì mi dúróṣinṣin, tí ó mu rọrùn fún mi láti gun orí rẹ̀. Nígbàtí ó ri pé ó ṣì rẹ̀ mi jù láti yíkọ̀ fúnra ara mi, ó lọ́ okùn ìyíkọ̀ mọ́ kéyákì mi ó sì bẹ̀rẹ̀sí yi lọ, ó ntì mi lẹgbẹ pẹ̀lú rẹ̀. Láìpẹ́ mo jára mi mo sì bẹ̀rẹ̀ sí yíkọ̀ déédé fúnra ara mi. Ó fi okùn náà sílẹ̀, mo sì dé erékùṣù àkọ́kọ́ láìsí ìrànlọ́wọ́ mọ́. Ní dídé bẹ̀, mo ṣubú sílẹ̀ lórí yanrìn, ní rírẹ̀ni.

Lẹ́hìn tí ẹgbẹ́ náà ti simi, atọ́nà náà wí fún mi jẹ́jẹ́, “Arákùnrin. Relund, bí ìwọ bá tẹramọ́ ìyíkọ, ní mímú ipa rẹ dúró, mo lérò pè ìwọ ó wà dáradára.” Mo tẹ̀lé àmọ̀ràn yí bí a ti nyíkọ̀ lọ sí erékùṣù keji àti lẹ́hìnnáà padà sí ibi àmì ìbẹ̀rẹ̀ wa. Lẹ́ẹ̀méjì atọ́nà yíkọ̀ kọjá ó sì wí fún mi pé mo nṣe dáadáa. Àní ìjì púpọ̀jù kọlu kéyákì mi láti ẹ̀gbẹ́, ṣùgbọ́n èmi kò jábọ́.

Nípa títẹramọ́ yíyí kéyákì náà, mo dúró ní níní ipa mo sì ní ìlọsíwájú, tí ó mú ìpalára kíkọlù mi ìjì láti ẹ̀gbẹ́ wá. Irú ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kannáà wúlò sí ìgbé ayé ti ẹ̀mí wa. À ndi pípalára nígbàtí a bá dẹra sílẹ̀ tàbí tí a bá dúró. Bí a bá ṣe ímúdúró ipa ti ẹ̀mí nípa “yíyí” lemọ́lemọ́ síwájú Olùgbàlà, a o wà láìléwu a ó sì ní ààbò si nítorí ìyè ayérayé wa dálé orí ìgbàgbọ́ wa nínú Rẹ̀.

A ndá ipa ti-ẹ̀mí sílẹ̀ “ní ìgbà pípẹ́ bí a ti nrọ̀mọ́ ẹ̀kọ́ Krístì léraléra.” Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé, ó nmú “agbo ìwàrere alágbára jáde wá.” Lootọ, àwọn ohun-àmúlò ẹ̀kọ́ Krístì—bíi ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì, ìrònúpìwàdà, wíwọnú ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú kan pẹ̀lú Olúwa nípasẹ̀ ìrìbọmi, gbígba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, àti fífaradà títí dé òpin—kìí ṣe ìgbìrò láti ní ìrírí rẹ̀ bí ìgbà-kan, láti tẹ-àpótí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ní pàtàkì, “fífaradà títí dé òpin” kìí ṣe ìgbésẹ̀ yíyàtọ̀ nínú ẹ̀kọ́ Krístì—bí ẹnipé a ti parí àwọn ohun-àmúlò mẹ́rin àkọ́kọ́ lẹ́hìnnáà tí a sì ti dàánù, rún ẹyín wa, kí a sì dúró fún ikú. Rárá, ìfaradà títí dé òpin ni lílò àwọn ohun-àmúlò ẹ̀kọ́ Krístì míràn léraléra àti ní títúnṣe, dídá “agbo ìwàrere, alágbára” tí Ààrẹ Nelson ṣàpèjúwe sílẹ̀.

Léraléra túmọ̀ sí pé a ní ìrírí àwọn ohun-àmúlò ẹ̀kọ́ Krístì lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kan sí i ní gbogbo ayé wa. Títúnṣe túmọ̀ sí pé à ngbé lórí a sì ngbèrú pẹ̀lú àtúnṣe kọ̀ọ̀kan. Àní bíótilẹ̀jẹ́pé à nṣe àwọn ohun-àmúlò léraléra, a kò yí kiri lásán nínú àwọn agbo láìsí ìlọsíwájú àfọkànsí. Dípò bẹ́ẹ̀, a nfa súnmọ́ Jésù Krístì si ní ìgbà kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ agbo náà.

Ipa wà pẹ̀lú ìyára àti ìdarí méjèèjì. Bí mo bá ti yíkọ̀ Kéyákì mi lílelíle ní ọ̀nà àṣìṣe, èmi kì bá ti dá ipa pàtàkì sílẹ̀, ṣùgbọ́n èmi kì bá ti dé ibi tí mò nlọ tí mo lérò. Bákannáà, nínú ayé, a nílò láti “yíkọ̀” síwájú Olùgbàlà láti wá sọ́dọ̀ Rẹ̀.

A nílò làti ṣìkẹ́ ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì. À nṣìkẹ́ rẹ̀ bí a ti ngbàdúrà lójojúmọ́, ṣe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́ lojojúmọ́, ronú lórí inúrere Ọlọ́run lójojúmọ́, ronúpìwàdà lójojúmọ́, kí sì tẹ̀lé àwọn ìṣílétí Ẹ̀mí Mímọ́ lójojúmọ́. Gẹ́gẹ́bí kò ṣe ní dára láti yàtọ̀ ní jíjẹ gbogbo oúnjẹ wa títí di Ọjọ́ Ìsinmi àti nígbànáà kí a jẹ àjẹjù ìfúnni ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ oúnjẹ wa, ko dára níti ẹ̀mí láti dènà ìwà ìṣìkẹ́-ẹ̀rí wa sí ọjọ́ kan nínú ọ̀sẹ̀.

Nígbàtí a bá bẹ̀rẹ̀ ojúṣe wa fún àwọn ẹ̀ri ti ara wa, à njèrè ipa ti-ẹ̀mí a sì nrọra mú orísun ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì dàgbà, àti pé ẹ̀kọ́ Krístì ndi gbùngbun sí èrèdí ìgbé ayé. Ipa bákannáà ngbéniga bí a ti ntiraka láti gbọ́ràn sí àwọn òfin Ọlọ́run tí a sì nronúpìwàdà. Ìrònúpìwàdà jẹ́ ayọ̀ ó sì nfi àyè gbà wá láti kẹkọ látinú àwọn àṣìṣe wa, èyí tí ó jẹ́ bí a ṣe nní ìlọ̀síwájú ayérayé. Làìṣiyèméjì a ó ní àwọn ìgbà nígbàtí a ó jábọ́ nínú àwọn kéyákì wa tí a ó sì rí arawa nínú omi jíjìn. Nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà, a lè padà sókè kí a sì tẹ̀síwájú, oye ìgbà èyíówù kí a ti ṣubú sílẹ̀. Apákan pàtàkì ni pé a kò jùwọ lẹ̀.

Ohun-àmúlò tó kàn nípa ẹ̀kọ́ Krístì ni ìrìbọmi, èyí tí ó wà pẹ̀lú ìrìbọmi ti omi àti, nípasẹ̀ ìfẹsẹ̀múlẹ̀, ìrìbọmi ti Ẹ̀mí Mímọ́. Nígbàtí ìrìbọmi jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kanṣoṣo, à ntún májẹ̀mú ìrìbọmi wa ṣe léraléra nígbàtí a ba ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa. Oùnjẹ Olúwa kò lè rọ́pò ìrìbọmi, ṣùgbọ́n ó rọ̀mọ́ àwọn ohun-àmúlò ìṣíwájú nínú ẹ̀kọ́ Krístì—ìgbàgbọ́ àti ìrònúpìwàdà—pẹ̀lú ìtẹ́wọ́gbà Ẹ̀mí Mímọ́. Bí a ti nfi pẹ̀lú ìtara ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa, a npè Ẹ̀mí Mímọ́ sínú ayé wa, gẹ́gẹ́bí ìgbàtí a ṣe ìrìbọmi àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀. Bí a ṣe npa májẹ̀mú wa mọ́ tí a júwe nínú àwọn àdúra oúnjẹ Olúwa, Ẹ̀mí Mímọ́ ó di ojúgba wa.

Bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe nní agbára títóbiju nínú ayé wa, à nfi ìlọsíwájú àti títúnṣe dàgbà nínú ìhùwàsí bíiti Krístì. Ọkàn wa yípadà. Ìdarísí wa láti ṣe ibi ndínkù. Ìtẹ́sí wa láti ṣe rere npọ̀ si títí tí a ó fẹ́ “láti ṣe rere lemọ́lemọ́ nìkan.” Àti pé ní bẹ́ẹ̀ a ó ní àyè sí agbára tọ̀run tí a nílò láti farada títí dé òpin. Ìgbàgbọ́ wa ti pọ̀ si, a sì ti ṣetán láti tún agbo ìwàrere, alágbára ṣe lẹ́ẹ̀kansi.

Ìtẹ̀síwájú ipa ti-ẹ̀mí bákánnáà nmú wa ṣe àfikún àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run nínú ilé Olúwa. Onírurú àwọn májẹ̀mú nfà wá súnmọ́ Krístì ó sì nso wá pọ̀ pẹ̀lú agbára sí I. Nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí, a ní àyè títóbì jù sí agbára Rẹ̀. Láti hàn kedere, àwọn májẹ̀mú ìrìbọmi àti tẹ́mpìlì kìí ṣe, orísun agbára nínú àti nípa ara wọn. Orísun agbára ni Olúwa Jésù Krístì àti Baba wa Ọ̀run. Dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ ndá ọ̀nà sílẹ̀ fún agbára Wọn nínú ayé wa. Bí a ti ngbé gẹ́gẹ́bí àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí, nígbẹ̀hìn a ó di ajogún sí gbogbo ohun tí Baba Ọ̀run ní. Ipa tí a mújáde nípasẹ̀ gbígbé ẹ̀kọ́ Krístì kìí mú agbára fún ìyípadà ìwà-ẹ̀dá wa wá sínú àyànmọ́ ìpín ayérayé wa nìkan, ṣùgbọ́n bákannáà ó nfún wa ní ìwúrí láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ní àwọn ọ̀nà títọ́.

Ẹ yẹ bí atọ́nà ìrìn-àjò ṣe ràn mí lọ́wọ́ lẹ́hìn tí mo jábọ́ nínú Kéyákì wò. Òun kò kígbe láti ọ̀nà jíjìn bí ìbèèrè àìní ìrànlọ́wọ́ bí irú, “Arákùnrin. Renlund, kíni ò nṣe nínú omi?” Òun kò yíkọ̀ sókè kí ó sì bá mi wí, wípé, “Arákùnrin. Renlund, ìwọ kò ní wà nínù ipò yí bí ìwọ ba wà dáadáa níti ara.” Kò bẹ̀rẹ̀ sí nyí kéyákì mi nígbàtí mo ṣì ngbìyànjú láti wá sókè lórí rẹ̀. Òun kò bá mi wí ní iwájú ẹgbẹ́ náà. Dípò bẹ́ẹ̀, ó fún mi ní ìrànlọ́wọ́ tí mo nílò ní ìgbà tí mo nílò rẹ̀. Ó fún mi ni àmọ̀ràn nígbàtí mo tẹ́wọ́gbàá. Ó sì ṣe kọjá agbára rẹ̀ láti gbà mi níyànjú.

Bí a ṣe nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn, a kò nílò láti bèèrè àwọn ìbèèrè àìní-ìrànwọ́ tàbí sọ bí ó ti rí. Ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n nlàkàkà mọ̀ pé wọ́n nlàkàkà. A kò níláti jẹ́ olùdájọ́; ìdájọ́ wa kò ní ìrànlọ́wọ́ tàbí jẹ́ gbígbà tí ó sì máa njẹ́ àṣìsọ nígbàkugbà jùlọ.

Àfiwé arawa sí àwọn ẹlòmíràn lè darí wa láti ṣe àṣìṣe líle, nípàtàkì bí a bá parí rẹ̀ pé a jẹ́ olódodo ju àwọn wọnnì tí wọ́n nlàkàkà. Irú àfiwé náà dà bíi rírì láìnírètí sínú mítà mẹ́ta omi, wíwo alabarin yín tí ó nrì sínú mítà mẹ́rin omi, dída a lẹ́jọ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀ títóbijù, àti níní ìmọ̀lára rere nípa arayín. Lẹ́hìn gbogbo rẹ̀, gbogbo wa ni ó nlàkàkà ní ọ̀nà ti ara wa. Kò sí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa tí ó yẹ fún ìgbàlà. A kò lè ṣeé láéláé. Jákọ́bù, nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, kọ́ni, “Rántí pé, lẹ́hìn tí [a] bá bá Ọlọ́run làjà, pé nínú àti nípasẹ̀ ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nìkanṣoṣo ni [a] ní ìgbàlà.” Gbogbo wa ló nílò Ètùtù àìlópin Olùgbàlà, kìí ṣe apákan rẹ̀ lásán.

A nílò gbogbo àánú, ìrọ́nú, àti ìfẹ́ bí a ti nbárawaṣe pẹ̀lú àwọn tí wọ́n wà ní àyíká wa. Àwọn wọnnì tí wọ́n nlàkàkà “nílò láti ní ìrírí ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ti Jésù Krístì tí ó hàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe [wa].” Bí a ti nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, à ngba àwọn ẹlòmíràn ní ìyànjú lemọ́lemọ́ a sì nfúnni ní ìrànlọ́wọ́. Àní bí ẹnìkan kò bá tẹ́wọ́gbà, a ó tẹ̀síwájú ní ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ bí wọ́n ṣe fi àyè gbà. Olùgbàlà kọ́ni pé “nítorítí irú àwọn bẹ̃ ni ẹ̀yin yíò tẹramọ́ láti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún; nítorí ẹ̀yin kò mọ̀ bóyá wọn yíò padà tí wọn yíò sì ronúpìwàdà, tí wọn yíò sì wá sí ọ̀dọ̀ mi tọkàn-tọkàn, tí èmi yìo sì wò wọ́n sàn; ẹ̀yin yíò sì jẹ́ ipa èyítí a fi mú ìgbàlà bá wọn.” Iṣẹ̀ Olùgbàlà ni láti wòsàn. Iṣẹ́ wa ni láti ní ìfẹ́—láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní irú ọ̀nà kan tí àwọn ẹlòmíràn ó fi fà súnmọ́ Jésù Krístì. Èyí ni ọ̀kan lára a`wọn èso alágbára, agbo ìwàrere ti ẹ̀kọ́ Krístì

Mo pè yín láti gbé ìgbésí ayé ẹ̀kọ́ Krístì léraléra, kí ẹ ṣe àtúnṣe, àti ìmọ̀ọ́mọ̀ àti ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlòmíràn ní ọ̀nà wọn. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ̀kọ́ Krístì ni gbùngbun sí ètò Baba Ọ̀run; ju gbogbo rẹ̀ lọ, òun ni, ẹ̀kọ́ Rẹ̀. Bí a ti nlo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀, a ntì wá síwájú lẹgbẹ ipa-ọ̀nà májẹ̀mú à sì nní ìwúrí láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti di àwọn ọmọẹ̀hìn òtítọ́ Jésù Krístì. A lè di ajogún nínú ìjọba Baba Ọ̀run, èyí tí ó jẹ́ ìparísí ìgbé ayé òtítọ́ ẹ̀kọ́ Krístì. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀