Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ̀rí Jésù
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


14:21

Ẹ̀rí Jésù

Ìpè mi ni láti ṣe ìṣe nísisìyí láti dá ààbò bo àyè wa bí ẹnìkan tí ó jẹ́ akọni nínú ẹ̀rí Jésù.

Ní 1832 Joseph Smith àti Sidney Rigdon gba ìran alámì kan nípa àyànmọ́ ayérayé ti àwọn ọmọ Ọlọ́run. Ìfihàn yí sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìjọba ọ̀run mẹ́ta. Ààrẹ Dallin H. Oaks sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ìjọba ológo” wọ̀nyí ní Oṣù Kẹ́wa tó kọjá, ní àkíyèsí pé “nípasẹ̀ ìṣẹ́gun àti ògò Ọ̀dọ́-àgùtàn,” gbogbo ènìyàn ṣùgbọ́n olúkúlùkú díẹ̀ gan nígbẹ̀hìn ni a ràpadà sínú ọ̀kan lára àwọn ìjọba wọ̀nyí, “gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú tí a fihàn nípasẹ̀ àwọn àṣàyàn wọn.” Ètò ìràpadà Ọlọ́run mú ànfàní gbogbogbò wá fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀, níbikíbi tí wọ́n lè ti gbé lórí ilẹ̀-ayé.

Nígbàtí ògo èyí tí ó kéréjùlọ lára àwọn ìjọba mẹ́ta, tẹ̀lẹ́stíà, “kọjá gbogbo óye,” ìrètí ti Baba wa ni pé a ó ṣe àṣàyàn—àti, nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọmọ Rẹ̀, yege fún—èyí tí ó ga jùlọ àti ológo jùlọ nínú àwọn ìjọba wọ̀nyí, sẹ̀lẹ́stíà, níbití a ti lè gbádùn ìyè ayérayé bí “àwọn ajogún-papọ̀ pẹ̀lú Krístì.” Ààrẹ Russell M. Nelson ti rọ̀ wá láti “ronú nípa sẹ̀lẹ́stíà,” mímú ìjọba Sẹ̀lẹ́stíà ṣe àfojúsùn ayérayé wa àti nígbànáà “fífi pẹ̀lú ìṣọ́ra máa gbèrò ibití ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìpinnu [wa] nígbàtí a wà níhĩn lórí ilẹ̀ ayé yío fi [wá] sí nínú ayé tó kàn.”

Àwọn tí ó wà nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà ni “àwọn tí wọ́n gba ẹ̀rí Jésù, … tí wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn olótítọ́ tí a ṣe ní pípé nípasẹ̀ Jésù olùlàjà májẹ̀mú titun.” Àwọn olùgbé ìkejì, tàbí ìjọba tẹ̀rẹ́stríàl, ni a júwe bí jíjẹ́ pàtàkì dáadáa, pẹ̀lú “àwọn ènìyàn ọlọ́lá ilẹ̀-ayé, àwọn ẹnití a ti fọ́ lójú nípa ẹ̀tàn àwọn ènìyàn.” Ìwa dídínkù olórí wọn ni pé wọ́n “kìí ṣe akọni nínú ẹ̀rí Jésù.” Ní ìlòdì sí, àwọn tí ó wà ní ìsàlẹ̀, ìjọba tẹ̀lẹ́stíà ni àwọn wọnnì tí wọn “kò gba ìhìnrere, tàbí ẹ̀rí Jèsù.”

Kíyèsi pé mímọ ìyàtọ̀ ìhùwàsí fún àwọn olùgbé ìjọba kọ̀ọ̀kan ni bí wọ́n ṣe báramu sí “ẹ̀rí Jésù,” lẹ́sẹẹsẹ láti (1) ìfọkànsìn àtinúwá sí (2) àìjẹ́ akọni sí (3) ìkọ̀sílẹ̀ pátápátá. Lórí àdẹ̀hìnbọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan ni ọjọ́-ọ̀la ayérayé lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin rọ̀mọ́.

1.

Kíní Ẹ̀rí Jésù?

Ó jẹ́ ẹ̀rí Ẹ̀mí Mímọ́ pé Òun ni Ọmọ àtọ̀runwá Ọlọ́run, Mèssíà àti Olùràpadà. Ó jẹ́ ẹ̀rí Jòhànù pé Jésù wà ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé, àti pé “nínú rẹ̀ ni ìhìnrere, àti pé ìhìnrere ni ìyè, àti pé ìyè ni ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn.” Ó jẹ́ “ẹ̀rí àwọn Àpóstélì àti Wòlíì, … pé Ó kú, a si ín, Ó sì dìde lẹ́ẹ̀kansi ní ọjọ́ kẹ́ta, Ó sì gòkè re ọ̀run.” Ó jẹ́ ìmọ̀ pé “kò sí orúkọ̀ míràn tí a fúnni nínú èyítí ìgbàlà ti wá.” Ó jẹ́ “ẹ̀rí, ìgbẹ̀hìn ju gbogbo rẹ̀ lọ,” tí a fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith “pé ó wà láàyè! … Pé òun ni Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo Baba—pé nípasẹ̀ rẹ̀, àti nínú rẹ̀, àti pé nípa rẹ̀, ni àwọn ayé wà tí a sì dásílẹ̀, àti pé àwọn olùgbé ibẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin bíbí sí Ọlọ́run.”

ll.

Kọjá ẹ̀rí yí ni ìbèèrè náà: Kíni kí a ṣe nípa rẹ̀?

Àwọn ajogún ìjọba sẹ̀lẹ́stíà “gba” ẹ̀rí Jésù ní ọgbọ́n ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa ṣíṣe ìrìbọmi, gbígba Ẹ̀mí Mímọ́, àti ṣíṣẹ́gun nípa ìgbàgbọ́. Àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àti òtítọ́ ìhìnrere Jésù Krístì nṣe àkóso àwọn ìṣíwájú ipò àti àṣàyàn wọn. Ẹ̀rí Jésù ni a fihàn nínú ohun tí wọ́n jẹ́ àti ohun tí wọ́n ndàbí. Èrò wọn ni ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, “ìfẹ́ àìléérí Krístì.” Ìkọjúsí wọn wà lórí lílépa “ìwọ̀n ìdàgbà ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Krístì.”

Ó kéréjù díẹ̀ làra àwọn wọnnì tí a ó rí nínú ìjọba tẹ̀rrẹ́stríàl bákannáà tẹ́wọgba ẹ̀rí Jésù, ṣùgbọ́n a mọ̀ wọ́n yàtọ̀ nípa ohun tí wọn kò ṣe nípa rẹ̀. Aìjẹ́ akọni nínú ẹ̀rí Olùgbàlà daba ipò àìbìkítà tàbí àìkàsí—jíjẹ́ “àìláápọn”— bí àtakò sí àwọn ènìyàn Ámmọ́nì nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, fún àpẹrẹ, tí wọ́n jẹ́ “àwọn tí a yà sọ́tọ̀ fún aápọn wọn síwájú Ọlọ́run.”

Àwọn Olùgbé ìjọba tẹ̀lẹ́stíà ni àwọn wọnnì tí wọ́n kọ ẹ̀rí Jésù lẹgbẹ pẹ̀lú ihìnrere Rẹ̀, àwọn májẹ̀mú Rẹ̀, àti àwọn wòlíì Rẹ̀. Abinadi júwe wọn bíi “nítorítí wọ́n ti lọ sí ipa ìfẹ́-ara wọn; tí wọn kò sì képe Olúwa nígbàtí a na ọwọ́ àánú sí wọn; nítorítí a na ọwọ́ àánú sí wọn wọn kò sì gbà á.”

lll.

Kíni ó túmọ̀ sí láti jẹ́ akọni nínú ẹ̀rí Jésù?

Onírurú àwọn ìlèṣeéṣe tí a lè yẹ̀wò ní dídáhùn ìbèèrè yí ni ó wà. Èmi ó dárúkọ díẹ̀. Jíjẹ́ akọni nínú ẹ̀rí Jésù dájúdájú pẹ̀lú títọ́jú àti fífún ẹrí wa lókun. Àwọn ọmọẹ̀hìn tòótọ́ kìí pa àwọn ohun tó dàbí ohun kékeré tí ó nmúdúró tí ó sì nfún ẹ̀rí wọn nínú Jésù lókun tì, bí irú àdúrà, ṣíṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́, kíkíyèsí Ọjọ́ Ìsinmi àti ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa, ìrònúpìwàdà, ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti ìjọ́sìn nínú ilé Olúwa. Ààrẹ Nelson rán wa létí pé “pẹ̀lú ìyára ẹ̀rù, ẹ̀rí tí kò bá gba ìtọ́jú ojojúmọ́ ‘nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run’ [Mórónì 6:4] lè ṣubú. Bayi, … a nílò àwọn ìrírí jíjọ́sìn Olúwa ojojúmọ́ àti ṣíṣe àṣàrò ìhìnrere Rẹ̀.” Nígbànáà ó fikun pé: “Mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti jẹ́kí Ọlọ́run borí nínú ayé yín. Ẹ fún Un ní ìpín dáadáa ti àkokò yín. Bí ẹ ti nṣe é, ẹ kíyèsí ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ sí ipa dídára ti-ẹ̀mí yín.”

Jíjẹ́ akọni bákannáà dá àwọn àbá dídúró fún àti ní gbángba nípa ẹ̀rí ẹni. Nínú ìrìbọmi, a fi ìfẹ́ wa múlẹ̀ “láti dúró bí àwọn ẹlẹri Ọlọ́run ni ìgbà gbogbo àti nínú ohun gbogbo, àti ní ibi gbogbo tí [a] lè wà, àní dójú ikú.” Ní àkokò ọdún àjínde yí nípàtàkì, à nfi tayọ̀tayọ̀, ní gbangba, àti láìdádúró kéde ẹ̀rí wa nípa olùjínde, Krístì àlààyè.

Ara jíjẹ́ akọni kan nínú ẹ̀rí Jésù ni láti fetísílẹ̀ sí àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀. Ọlọ́run kìí fipá mú wa sí ipa-ọ̀nà dídára jùlọ̀, ipa-ọ̀nà májẹ̀mú, ṣùgbọ́n ó nkọ́ àwọn wòlíì Rẹ̀ láti mú wa mọ àbájáde àwọn àṣàyàn wa ní kíkún. Kìí sì íṣe nípa àwọn ọmọ Ìjọ Rẹ̀ nìkan. Nípasẹ̀ àwọn wòlíì àti àpóstélì Rẹ̀, Ó fi tìfẹ́tìfẹ́ bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ayé láti fetísílẹ̀ sí òtítọ́ tí yíó sọ wọ́n di òmìnira, tí a tú wọ́n sílẹ̀ kúrò nínú ìjìyà tí kò wúlò, tí a sì mú ayọ pípẹ́ wá fún wọn.

Jíjẹ akọni nínú ẹrí Jésù túmọ̀ sí gbígba àwọn ẹlòmíràn ní ìyànjú, nípa ọ̀rọ̀ àti àpẹrẹ, láti jẹ́ akọni bákannáà, nípàtàkì àwọn wọnnì ti wọ́n jẹ́ ẹbí ti arawa. Alàgbà Neal A. Maxwell sọ̀rọ̀ nígbàkan pé “àwọn pàtàkì ‘ọlọ́lá’ ọmọ [ti Ìjọ] tí wọ́n nré ìfofò kúrò lókè dípò mímú ipò-ọmọẹ̀hìn wọn jinlẹ̀ tí wọ́n sì nṣiṣẹ́ láìrò sànju ‘ṣíṣiṣẹ́ taratara’ [Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 76:75; 58:27].” Kíkíyèsi pé gbogbo ènìyàn ni ó ní òmìnira láti yàn, Alàgbà Maxwell pohùnréré pé: “Láìdára, bákannáà, nígbàtí àwọn kan bá yan ìfàsẹ́hìn, kìí ṣe pé wọ́n nyàn fún ara wọn nìkan, ṣùgbọ́n fún ìran tó nbọ̀ àti tó nbọ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ irọ́ kékèké nínú àwọn òbí lè mú ìjádé yíyàtọ̀ púpọ̀ wá nínú àwọn ọmọ wọn. Àwọn ìran ìṣíwájú nínú ẹbí kan lè ti fi ìfarajì wọn hàn, nígbàtí àwọn kan nínú ìran lọ́wọ́lọ́wọ́ nfi ọ̀rọ̀ irọ hàn. Pẹ̀lú ìbànújẹ́, nínú èyí tó nbọ, àwọn kan lè yan ìyapa bí àgbàrá tí ó nsa ipá tirẹ̀.”

Àwọn ọdún sẹ́hìn, Alàgbà John H. Groberg sọ ìtàn nípa ẹbí ọ̀dọ́ tí wọ́n ngbé ní ẹ̀ká kékeré kan ní Hawaii ní ìbẹ̀rẹ̀ 1900. Wọ́n ti jẹ́ ọmọ Ìjọ fún bíi ọdún méjì nígbàtí ọkàn lára àwọn ọmọbìnrin wọn nṣe àìsàn pẹ̀lú àrùn àìlèyẹ̀wò tí wọ́n sì fi sílé ìwòsàn. Ní ìjọ, lọ́jọ́ Ìsinmi tó tẹ̀le, baba àti ọmọkùnrin rẹ̀ múra oúnjẹ Olúwa sílẹ̀ bí wọ́n ti nṣe ní àwọn ọ̀sẹ̀ púpọ̀jùlọ, ṣùgbọ́n bí baba ọ̀dọ́ náà ti kúnlẹ̀ láti bùkún búrẹ́dì, ààrẹ ẹ̀ka, lójijì da ẹni tí ó wà níbi tábìlì oúnjẹ Olúwa mọ̀, ó fò sókè ó sì kígbe pé, “Dúró. Ìwọ kò lè fọwọ́kan oúnjẹ Olúwa. Ọmọbìnrin rẹ ní àrùn àìmọ̀. Kúró lọ́gán nígbàtí ẹlòmíràn ó ṣe búrẹ́dì titun. A kò lè gbà ọ́ nihin. Lọ.” Baba tó ní ìyàlẹ́nu náà wo ààrẹ ẹ̀ká pẹ̀lú ìwákiri àti gbogbo ìjọ ó sì rí ìjìnlẹ̀ àníyàn àti ìdàmú látọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn, ó nawọ́ sí àwọn ẹbí rẹ̀, wọ́n sì tò jáde jẹ́jẹ́ kúrò ní ilé-ìjọsìn.

Wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kankan bí, bíbànújẹ́ gidi, ni ẹbí náà rìn lẹgbẹ ọ̀nà lọ sí ilé wọn kékeré. Níbẹ̀ ni wọ́n joko nínú agbo, baba wọ́n sì wípé, “Ẹ jọ̀wọ́ ẹ dákẹ́ títí èmi ó fi ṣetán láti sọ̀rọ̀.” Ọ̀dọ́mọkùnrin náà nronú ohun tí wọ́n lè ṣe láti gbẹ̀san fún àbùkù tí wọ́n jìyà rẹ̀: ṣe wọn ó pa àwọn ẹlẹ́dẹ́ ààrẹ ẹ̀ka ni, tàbí jó ilé rẹ̀, tàbí darapọ̀ mọ́ ìjọ míràn ni? Ìṣẹ́jú marun, mẹwa, marunlelogun kọjá nínú ìdákẹ́jẹ́.

Ìfúnwọ́ baba náà bẹ̀rẹ̀sí rọlẹ̀, omijé sì bẹ̀rẹ̀. Ìyá bẹ̀rẹ̀sí nsọkún, àti pé láípẹ́ àwọn ọmọ nsọkún jẹ́jẹ́. Baba náà yípadà sí ìyàwó rẹ̀ ó sì wípé, “Mo ní ìfẹ́ rẹ” nígbànáà ó sì tún àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyì sọ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ wọn. “Mo nifẹ gbogbo yín mo sì fẹ́ kí a wà papọ̀, títíláé, bí ẹbí kan. Ọ̀nà kanṣoṣo tí ó lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni fún gbogbo wa láti jẹ́ ọmọ ìjọ rere Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn kí a si ṣe èdidì nípa oyè-àlùfáà mímọ́ nínú tẹ́mpìli. Èyí kìí ṣe ìjọ ààrẹ ẹ̀ka. Ìjọ ti Jésù Krístì ni. A kò ní fi àyè gba ẹnikẹ́ni tàbí ìpalára tàbí ìdàmú tàbí ìgbéraga kí ó pa wá mọ́ kúrò ní wíwà papọ̀ títíláé. Ọjọ́ Ìsinmi tó nbọ̀ a ó lọ padà sí ìjọ. A ó dúró pẹ̀lú arawa títí tí a ó fi mọ àìsàn ọmọbìnrin wa, ṣùgbọ́n a ó lọ padà.”

Wọ́n padà lọ sí ìjọ, ara ọmọbìnrin wọn dá, ẹbí náà sì ṣe èdidì ní Tẹ́mpìlì Laie Hawaii nígbàtí wọ́n parí rẹ̀. Nì òní, ó pọ̀ju ọgọrun àwọn ọkàn tí wọ́n npe baba wọn, baba-baba, àti baba-baba-baba ni alábùkún nítorí ó pa ojú rẹ̀ mọ́ sórí ayérayé.

Ara jíjẹ́ akọni tó kẹ́hìn nínú ẹ̀rí Jésù tí èmi ó dárúkọ ni ìlépa ìwà-mímọ́ ti araẹni olúkúlùkù wa. Jésù ni Olùràpadà pàtàkì wa, Ó sì nbẹ̀bẹ̀ pé “Ẹ ronúpìwàdà, gbogbo ẹ̀yin ìkangun ayé, ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì ṣe ìrìbọmi ní orúkọ mi, kí ẹ̀yin ó di mímọ́ nípa gbígba Ẹ̀mí Mímọ́, kí ẹ̀yin ó lè dúró ní àìlábàwọ́n níwájú mi ní ọjọ́ ìkẹhìn.”

Wòlíì Mọ́mọ́nì júwe ẹgbẹ́ àwọn Ènìyàn mímọ́ kan tí wọ́n nífarada nínú irú ọ̀nà yí bíótilẹ̀jẹ́pé wọ́n níláti “lọ nínú àwọn ọ̀pọ̀ ìpọ́njú”:

“Bíótilẹ̀ríbẹ̃ nwọ́n gbàdúrà nwọ́n sì gba ãwẹ̀ nígbà-kũgbà, nwọ́n sì túbọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ síi, nwọ́n sì túbọ̀ dúró ṣinṣin síi nínú ìgbàgbọ́ Krístì, títí ọkàn nwọn fi kún fún ayọ̀ àti ìtùnú, bẹ̃ni, àní títí dé ìsọdimímọ́ àti ìyàsímímọ́ ọkàn nwọn, ìsọdimímọ́ èyítí ó bá nwọn nítorítí nwọn jọ̀wọ́ ọkàn nwọn sílẹ̀ fún Ọlọ́run.” Ìyípadà ọkàn nlá yí—jíjọ̀wọ́ ọkàn wa sí Ọlọ́run àti dídi àtúnbí níti-ẹ̀mí nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ Olùgbàlà—tí à nwá.

Ìpè mi ni láti ṣe ìṣe nísisìyí láti dá ààbò bo àyè wa bí ẹnìkan tí ó jẹ́ akọni nínú ẹ̀rí Jésù. Bí a ti lè nílò ìrònúpìwàdà, “ẹ máṣe fi ọjọ́ ìrònúpìwàdà yín dọ́la,” kí ó má jẹ́ pé “ní wákátí tí ẹ kò lérò pé ìgbà ìrúnwé máa kọjá, tí ìkórè ó sì parí, tí a kò sì ní gbà ọkàn yín là.” Ẹ ní ìtara ní pípa àwọn májẹ́mú yín pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́. Ẹ máṣe “bínú [nípa] líle ọ̀rọ̀ náà.” “Ẹ rántí láti mú orúkọ nã [ti Krístì] dúró ní kíkọ lé oókan àyà nyín nígbà-gbogbo, ṣùgbọ́n pé kí ẹ gbọ́ kí ẹ sì mọ ohùn náà nípa èyítí a ó fi pè nyín, àti pẹ̀lú, orúkọnáà èyítí yíò fi pè yín.” Ní òpin, “ẹ ṣe àtúnṣe èyí nínú ọkàn yín, pé ẹ̀yin ó ṣe ohun èyí tí [Jésù] ó kọ́, àti paláṣẹ fún yín.”

Baba wa fẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ tí yíò fẹ́ gbádùn ìyè ayérayé pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà. Jésù jìyà, kú, ó sì jínde láti mú ìyẹn ṣeéṣe. Ó “tí gòkè re ọ́run, ó sì jóko ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, láti gbà ẹ̀tọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ Bàbá èyítí ó ní nípa ṣíṣe ãnú fún àwọn ọmọ ènìyan.” Mo gbàdúrà pé kí a lè di alábùkún pẹ̀lú ẹrí mímúná nípa Olúwa Jésù Krístì, kí a yọ̀ kí a sì jẹ́ akọni nínú ẹ̀rí náà, kí a sì gbádùn àwọn èso oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ nínú ayé wa lemọ́lemọ́. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.