Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Pè, Máṣe Ṣubú
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


10:9

Pè, Máṣe Ṣubú

Bí a bá pè sí Ọlọ́run, Mo jẹ́ ẹ̀rí pé a kì yíò ṣubú.

Loni èmi yíò fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ nípa jíjẹ́ ẹ̀rí ti ìdánilójú pípé nínú ọkàn mi pé Ọlọ́run ngbọ́ àdúrà wa ó ndáhùn wọn ní ọ̀nà ti ara ẹni.

Nínú ayé tí ó nla àwọn àkokò àìdánilójú, ìrora, ìbànújẹ́, àti ìjánikulẹ̀ kọjá, a lè nímọ̀lára láti gbẹ́kẹ̀lé àwọn agbára àti àwọn àyànfẹ́ ti ara ẹni díẹ̀ si, pẹ̀lú bákanáà ìmọ̀ àti ààbò tí ó wá láti inú ayé. Èyí lè mú kí a fi orísun ìrànwọ́ àti ìtìlẹ́hìn gidi sí abẹ́lẹ̀ tí ó lè tako àwọn ìpèníjà ti ìgbésí-ayé ikú yìí.

Yàrá ilé ìwòsàn

Mo rántí ìgbà kan tí a gbémi lọ sí ilé ìwòsàn fún àìlera kan, ó sì ṣòro fún mi láti sùn. Nígbàtí mo pa àwọn iná tí yàra náà sì ṣókùnkùn, mo rí àmì àfihàn kan lórí àjà níwájú mi ​​tí o sọ́ pé, “Pè, máṣe ṣubú.” Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi, lọ́jọ́ kejì mo ṣàkíyèsí ọ̀rọ̀ kan náà tí wọ́n tún sọ láwọn apá ibì kan nínú yàrá náà.

Pè, Máṣe ṣubú àpẹrẹ.

Kínìdí tí ọ̀rọ̀ yí fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Nígbàtí mo bèrè lọ́wọ́ nọ́sì nípa rẹ̀, ó wí pé, “Ó jẹ́ láti yàgò fún ìkọlù tí ó lè mú ìrora tí o ní tẹ́lẹ̀ pọ̀ si.”

Ayé yí, nípasẹ̀ ẹ̀dá rẹ̀, nmú àwọn ìrírí ìrora wa, díẹ̀ jẹ́ àdámọ́ sí inú àwọn àgọ́ ara wa, díẹ̀ nítorí àwọn àìlera tàbí àwọn ìpọ́njú wa, díẹ̀ nítorí ọ̀nà ti àwọn míràn gbà nlò agbára láti yàn wọ̀n, àti díẹ̀ nítorí lílò agbára láti yàn wa.

Njẹ́ ìlérí kan wà tí ó lágbára ju èyí tí Olùgbàlà fúnra rẹ̀ ṣe nígbàtí Ó kéde pé, “Bèrè, a ó sì fi fún ọ; wá kiri, ìwọ o si ri; kànkùn,” tàbí pè, “a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún ọ”?

Àdúrà jẹ́ ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run tí ó nfi àyè gbà wá láti “pè kí a máṣe ṣubú.” Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ipò kan wà nínú èyítí a lè rò pé ipè náà kò tíì di gbígbọ́ nítorí a kò gba èsì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tàbí ọ̀kan tí ó bá àwọn ìrètí wa mu.

Èyí máa nyọrí sí àníyàn, ìbànújẹ́, àti ìjákulẹ̀ nígbà míràn. Ṣùgbọ́n rántí bi Néfì ti fi ìgbàgbọ́ nínú Olúwa hàn nígbàtí ó wípé, “Báwo ni ó ṣe jẹ́ tí òun kò lè fún mi ní ìtọ́ni, kí èmi lè kan ọkọ̀ ojú omi?” Nísisìyí, mo bèrè pé báwo ni Olúwa kò ṣe lè tọ́ọ yín, kí ẹ má bàá ṣubú?

Ìgbẹ́kẹ̀lé ninu àwọn ìdáhùn Ọlọ́run túmọ̀ sí gbígbà pé àwọn ọ̀nà Rẹ̀ kìí ṣe àwọn ọ̀ná wa àti pé “ohun gbogbo gbọ́dọ̀ wá sí ìmùṣẹ ní àkokò wọn.”

Dídánilójú ti mímọ̀ pé a jẹ́ ọmọ Baba Ọ̀run olùfẹ́ni àti alaanu gbọ́dọ̀ jẹ́ ìwúrí láti “pè” nínú àdúrà ìfọkànsìn pẹ̀lú ìṣesí “gbígbàdúrà nígbà gbogbo, àti láì rẹ̀wẹ̀sì; … kí iṣẹ́ [wa] lè jẹ́ fún ire [àwọn]ọkàn [wa].” Fojúinú wo ìmọ̀lára Baba Ọ̀run nígbàtí a bá ntọrọ ẹ̀bẹ̀ nínú àdúrà kọ̀ọ̀kan ní orúkọ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Kristi. Irú agbára àti ìrẹ̀lẹ̀, mo gbàgbọ́, ni a fihan nígbàtí a bá ṣe bẹ́ẹ̀!

Àwọn Ìwé Mímọ́ kún fún àpẹrẹ àwọn tí wọ́n kígbe pe Ọlọ́run kí wọ́n má bàa ṣubú. Hẹlámánì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, nígbàtí wọ́n dojúkọ àwọn ìpọ́njú wọn, “pè” Ọlọ́run, ní títú ọkàn wọn jáde nínú àdúrà. Wọ́n gba ìdánilójú, àláfíà, ìgbàgbọ́, àti ìrètí, ní jíjèrè ìgboyà àti ìpinnu títí tí wọ́n fi ṣe àṣeyọrí àfojúsùn wọn.

Fojúinú wo bí Mósè ṣe lè pè kí ó sì kígbe sí Ọlọ́run nígbàtí ó nrí ara rẹ̀ ní aarin méjì Òkun Pupa àti àwọn ará Égíptì tí wọ́n nsúnmọ́ láti kọlù, tàbí Ábráhámù nígbàtí o ngbọ́ran sí àṣẹ láti fi Ísáákì ọmọ rẹ̀ rúbọ.

Ó dá mi lójú pé ọ̀kọ̀ọ̀kan yín ti ní, ẹ ó sì ní àwọn ìrírí níbi tí pípè yíò ti jẹ́ ìdáhùn sí má ṣubú.

Ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́hìn, nígbàtí ìyàwó mi àti èmi nmúra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó ti àṣà ìlú àti ìgbéyàwó tẹ́mpìlì wa, a gba ìpè kan tó nsọ fún wa pé wọ́n ti fagilé ìgbéyàwó ti àṣà ìlú nítorí ìdáṣẹ́sílẹ̀ kan. A gba ìpè náà ní ọjọ́ mẹ́ta ṣaájú ayẹyẹ tí a ti ṣètò. Lẹ́hìn àwọn ìgbìyànjú púpọ̀ ní àwọn ọ́físì míràn tí a kò sì rí àwọn ìpinnu ní àrọ́wọ́tó, a bẹ̀rẹ̀ sí nímọ́làra àìbalẹ̀ ọkàn àti iyèméjì pé a lè ṣe ìgbéyàwó ní tòótó bí a ti pèrò.

Àfẹ́sọ́nà mi àti èmi “pè,” ní títú ọkàn wa jáde sí Ọlọ́run nínú àdúrà. Níkẹhìn, ẹnìkan sọ fún wa nípa ọ́físì kan tó wà ní ìlú kékeré kan tó wà lẹ́hìn odi ìlú náà, níbi tí ojúlùmọ̀ kan ti jẹ́ olórí ìlú. Láìjáfara, a lọ bẹ̀ ẹ́ wò, a sì bèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó lè ṣeéṣe láti sowá pọ̀. Pẹ̀lú ìdùnnú wa, ó gbà. Akọ̀wé rẹ̀ tẹnu mọ́ fún wa pé a gbọ́dọ̀ gba ìwé ẹ̀rí ní ìlù náà, kí á sì kó gbogbo àwọn ìwé náà wá kó tó di ọ̀sán ọjọ́ kejì.

Lọ́jọ́ kejì, a kó lọ sí ìlù kékeré náà, a sì lọ sí àgọ́ ọlọpa láti bèrè ìwé tí a nílò. Sí ìyàlẹ́nu wa, ọlọpa náà sọ pé òun kò ní fún wa, nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tọkọtaya ló ti nsá kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹbí wọn láti ṣègbéyàwó ní ìkọ̀kọ̀ ní ilù náà, èyítí kì í ṣe ọ̀ràn tiwa. Lẹ́ẹ̀kànsi, ìbẹ̀rù àti ìbànújẹ́ bá wa.

Mo rántí bí mo ṣe kígbe ní ìdákẹ́jẹ́jẹ́ sí Baba mi Ọ̀run kí nmá bàa ṣubú. Mo gba ìmọ̀lára kedere nínú ọkàn mi, ní sísọ léraléra pé, “Ìkaniyẹ tẹ́mpìlì, ìkaniyẹ tẹ́mpìlì.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni mo mú ìkaniyẹ tẹ́mpìlì mi jáde mo sì fún ọlọpa, sí ìdàmú ìyàwó àfẹ́sọ́nà mi.

Ó ti jẹ́ ìyàlẹ́nu tó fún wa nígbàtí a gbọ́ tí ọlọpa náà sọ pé, “Kí ló dé tí ẹ kò sọ fún mi pé ẹ wá láti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn? Mo mọ ìjọ yín dáadáa.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ síí múra ìwé náà sílẹ̀. Ó tún yà wá lẹ́nu si nígbàtí ọlọpa náà kúrò ní àgọ́ náà láìsọ ohunkóhun.

Àádọ́ta ìṣẹ́jú kọjá, kò sì padà. A ti wà ní 11:55 òwúrọ̀, àti pé a ní títí di ọ̀sán láti fi àwọn ìwé náà jíṣẹ́. Lójijì ó farahàn pẹ̀lú arẹwà ọmọ ajá kan ó wí fún wa pé ẹ̀bùn ìgbéyàwó ni ó sì fi fún wa pẹ̀lú ìwé náà.

A sáré lọ sí ọ́físì olórí ìlú náà, pẹ̀lú ìwé wa àti ajá wa titun. Lẹ́hìn náà a rí ọkọ̀ ibi iṣẹ́ kan tó nbọ̀ wá sọ́dọ̀ wa. Mo dúró ní iwájú rẹ̀. Ọkọ̀ náà dúró, a sì rí akọ̀wé nínú rẹ̀. Bí ó ti rí wa, ó ní, “Ẹ ma binu, mo wí fún yín pé ọ̀sán. Mo gbọ́dọ̀ lọ jẹ́ iṣẹ́ míràn. ”

Mo rẹ ara mi sílẹ̀ ní ìdákẹ́jẹ́, ní pípe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi sí Baba mi Ọ̀run, ní bíbèrè fún ìrànlọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kan si láti “má ṣubú.” Lójijì, ìyanu náà ṣẹlẹ̀. Akọ̀wé náà sọ fún wa pé, “Ajá yín yi ti lẹ́wà tó. Níbò ni mo ti lè rí irú èyí fún ọmọkùnrin mi?”

“O wà fun ọ,” a dáhùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Akọ̀wé náà wò wá pẹ̀lú ìyanu ó sì wí pé, “Ó dára, ẹ jẹ́ ká lọ sí ọ́físì ká sì ṣe àwọn ètò.”

Ní ọjọ́ méjì lẹ́hìn náà, èmi àti Carol ṣègbéyàwó lọ́nà ti àṣà ilú, gẹ́gẹ́ bí a ti pèrò, lẹ́hìn náà a fi èdìdì dì wá nínú Tẹ́mpìlì Lima Peru.

Nítòótọ́, a nílò láti rántí pé pípè jẹ́ ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ìṣe—ìgbàgbọ́ láti mọ̀ pé a ní Baba Ọ̀run kan tí ó ndáhùn àdúrà wa ní ìbámu sí ọgbọ́n Rẹ̀ tí kò lópin, àti lẹ́hìn náà, ìgbésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a béèrè fún. Gbígbàdúrà—pípè—lè jẹ́ àmì ìrètí wa. Ṣùgbọ́n ṣíṣe ìṣe lẹ́hìn gbígba àdúrà, jẹ́ àmì pé ìgbàgbọ́ wa jẹ́ òtítọ́—ìgbàgbọ́ tí a dánwò ní àwọn àkókò ìrora, ìbẹ̀rù, tàbí ìjákulẹ̀.

Mo daba pé kí ẹ ro nkan wọ̀nyí:

  1. Ẹ máa fi ìgbà gbogbo ro Olúwa bi àṣàyàn àkọ́kọ́ yín fún ìrànlọ́wọ́.

  2. Pè, Máṣe ṣubú. Yípadà sí Ọlọ́run nínú àdúrà tòótọ́.

  3. Lẹ́hìn àdúrà gbígbà, ẹ sa gbogbo ipá yín láti rí àwọn ìbùkún tí ẹ gbàdúrà fún.

  4. Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ láti gba ìdáhùn ní àkokò Rẹ̀ àti ni ọ̀nà Rẹ̀.

  5. Ẹ Máṣe Dúró! Ẹ tẹ̀síwájú ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú nígbàtí ẹ ndúró fún ìdáhùn.

Bóyá ẹníkan wà bayi tí ó, nítorí àwọn àyídàyídà, ní ìmọ̀lára bí ẹnipé wọ́n ti fẹ́rẹ̀ ṣubú àti pé yíò fẹ́ láti pè bí Joseph Smith ti ṣe nígbàtí ó kígbe pé, “Ọlọ́run, níbo ni ìwọ wà? … Yíò ti pẹ́ tó tí ìwọ yíò dá ọwọ́ rẹ dúró?”

Àní nínú àwọn ipò bí ìwọ̀nyí, gbàdúrà pẹ̀lú “ipa ti ẹ̀mí,” bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni, nítorí àwọn àdúrà yín njẹ́ gbígbọ́ nígbàgbogbo!

Rántí orin ìsìn yi:

Kí o tó kúrò ní yàrá rẹ ní òwúrọ̀ yi,

Njẹ́ o ronú láti gbàdúrà?

Ní orúkọ Krístì, Olùgbàlà wa,

Njẹ́ o bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere ìfẹ́

Bí ààbò loni?

Ah, bí àdúrà gbígbà ṣe nfún àárẹ̀ nísimi!

Àdúrà yíò yí òru padà sí ọ̀sán.

Nítorínáà, nígbàtí ayé bá ṣókùnkùn tí ó dúró,

Máṣe gbàgbé láti gbàdúrà.9

Bí a ṣe ngbàdúrà a lè ní ìmọ̀lára ìgbámọ́ra Baba wa Ọ̀run, ẹni tí ó rán Ọmọ bíbí Rẹ̀ Kanṣoṣo láti mú àwọn ẹrù wa fúyẹ́, nítorí tí a bá ké pe Ọlọ́run, mo jẹ́ ẹ̀rí pé a kì yíò ṣubú. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.