Ní Àtìlẹhìn àwọn Ìran Tó Ndìde
Ó jẹ́ àwọn ìbáṣepọ̀ ní ìgbésí ayé àwọn ọ̀dọ́ tí ó ní ipa nlá jùlọ lórí àwọn yíyàn wọn.
Ní ìmúrasílẹ̀ láti bá yín sọ̀rọ̀, a ti fàmí sí ìtàn Hẹ́lámánì àti àwọn ọmọkùnrin ará Ámónì. Mo ti nímọ̀lára agbára àwọn wòlíì Ìwé Mọ́mọ́nì tó nkọ́ àwọn òbí, àwọn bíṣọ́pù, àti àwọn ọmọ wọ́ọ̀dù nípa ṣíṣàṣàrò àkọọ́lẹ̀ yìí.
Hẹlámánì jẹ́ ọkùnrin kan tí àwọn ọ̀dọ́ Ámónì lè gbẹ́kẹ̀lé. Ó ṣẹ̀rànwọ́ fún wọn láti gbèrú kí wọn sì dàgbá nínú òdodo. Wọ́n mọ̀ wọ́n sì nifẹ rẹ̀ wọ́n sì “fẹ́ pé kí [ó] jẹ́ olórí wọn.”
Hélámánì nifẹ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọ̀nyí bí ọmọ ó sì rí agbára wọn. Alàgbà Dale G. Renlund kọ́ni pé “láti sin àwọn ẹlòmíràn dáradára a nílati rí wọn … nípasẹ̀ ojú ti Baba Ọrun. Nígbànáà nìkan ni a le bẹ̀rẹ̀ sí ní òye ìkàyẹ òtítọ́ ti ọkàn kan. Nígbànáà nìkan ni a le wòye ìfẹ́ ti Baba Ọrun ní fún gbogbo àwọn … ọmọ Rẹ̀.” Àwọn Bíṣọ́pù loni ni a bùkún pẹ̀lú òye láti rí ìdánimọ̀ àtọ̀runwá ti àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n wà ní àbójútó wọn.
Hẹ́lámánì “ka iye” àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n wà ní àbójútó rẹ̀. Ó fi ìgbékalẹ̀ àwọn ìbáṣepọ̀ tó lágbára pẹ̀lú wọn síwájú.
Ní àkokò pàtàkì kan nígbàtí ìyè àti ikú dúró ní ìwọ̀ntunwọ̀nsì, Hẹ́lámánì àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin jagunjagun rẹ̀ pàdánù àkíyèsí ti àwọn ọmọ ogun tó nlépa wọn. Hẹ́lámánì gba àwọn ọ̀dọ́ nímọ̀ràn:
“Kíyèsĩ, a kò mọ̀ ṣùgbọ́n wọ́n ti dáwọ́ dúró fún ète pé kí a le wá dojú kọ wọ́n. …
“Nítorínáà kí ni ẹ̀yin wí, ẹ̀yin ọmọ mi … ?”
Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin olotọ yìí dáhùn pé, “Baba, kíyèsí i pé Ọlọ́run wa wà pẹ̀lú wa, kò sì ní jẹ́ kí a ṣubú; nígbànáà ẹ jẹ́ kí a jáde.” Wọ́n gba ọjọ́ náà, bí Hẹ́lámánì ti ṣe àtìlẹ́hìn fún àwọn ọ̀do wonyi ninú ìpinnu wọn láti gbé ìgbésẹ̀.
Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ará Ámónì ní ìdí nlá, wọ́n sì jẹ́ akíkanjú nínú “àtìlẹ́hìn àwọn ènìyàn.” “Alágbára kékeré yìí,” tí Hẹ́lámánì ṣe ìdarí, tan “ìrètí nlá àti ayọ̀ púpọ̀ kálẹ̀” sínú ọkàn àwọn ọmọ ogun Néfì tí wọ́n ti ní ìrírí. Bíṣọ́pù kan lónìí lè darí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ní ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ láti bùkún wọ́ọ̀dù náà àti ní kíkó Ísráẹ́lì jọ. Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé èyí ni iṣẹ́ nítorí “èyítí a fi [wọ́n] ránṣẹ́ sí ilẹ̀ ayé.”
Bíi ti àwọn ọ̀dọ́ ará Ámónì wọ̀nyí tí wọ́n jẹ́ “òtítọ́ nígbà gbogbo nínú ohun yòówù tí a fi lé wọn lọ́wọ́,” Hélámánì fi ìṣòtítọ́ tẹ̀ lé àwọn olùdarí rẹ̀. Láìbìkítà ìpèníjà tàbí ìfàsẹ́hìn, Hélámánì nígbàgbogbo máa ndúró “ṣinṣin pẹ̀lú ìpinnu kan” láti mú èrèdí wọn tẹ̀síwájú. Nígbàtí Ọlọ́run sọ pé kó “jáde lọ pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin [rẹ̀] kékèké,” ó gbọràn.
Àwọn ọ̀dọ́ lónìí jẹ́ alábùkún bí àwọn bíṣọ́pù ti ntẹ̀lé ìtọ́sọ́nà ti àwọn olórí wa láti “gbamọ̀ràn pẹ̀lú àwọn Ààrẹ Àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin ní wọ́ọ̀dù.” Àwọn Ààrẹ èèkàn, nípasẹ̀ àjọ ààrẹ Ọ̀dọ́mọkùnrin èèkàn àti àwọn àjọ ààrẹ Ọ̀dọ́mọbìnrin èèkàn, nkọ́ àwọn bíṣọ́pù àti àwọn Ààrẹ Ọ̀dọ́mọbìnrin ní ìmúṣẹ ojúṣe wọn sí àwọn ọ̀dọ́.
Hẹ́lámánì bu ọlá fún àwọn májẹ̀mú. Nígbàtí Ámọ́nì kọ́ àwọn òbí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tó nbọ̀ ní ìhìnrere, wọ́n gbá a mọ́ra pẹ̀lú ọkàn wọn. Wọ́n fi ara wọn lélẹ̀ fún ìgbésí ayé titun ti jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn òlódodo débi pé wọ́n dá májẹ̀mú láti “kó àwọn ohun ìjà ìṣọ̀tẹ̀ wọn lélẹ̀.” Ohun kan ṣoṣo tí ó mú kí wọ́n gbèrò láti sẹ́ májẹ̀mú yi, ní lílọ padà sí ìgbà àtẹ̀hinwá tí ìjà jíjà, ni rírí àwọn ará Néfì nínú ewu.
Àwọn ará Ámónì fẹ́ ran àwọn èèyàn wọ̀nyí lọ́wọ́ tí wọ́n fún wọn ní ilé ààbò. Hẹ́lámánì, pẹ̀lú àwọn míràn, rọ wọn láti pa májẹ̀mú wọn mọ́ láti máṣe jagun mọ́. Ó gbẹ́kẹ̀lé agbára tí Ọlọ́run yíò pèsè ju agbára tí àwọn ará Ámónì wọ̀nyí lè pèsè pẹ̀lú àwọn idà àti ọfà wọn.
Nígbàtí Hẹ́lámánì àti àwọn ọ̀dọ́ jagunjagun rẹ̀ dojúkọ àwọn ìpèníjà tó bani lẹ́rù, Hẹ́lámánì ṣe ìpinnu. “Ẹ kíyèsí, kò já mọ́ nkan—a ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run yíò gbà wá.” Ní àpẹrẹ kan, ní etí-bèbè ti ebi pípa kú, ìdáhùn wọn ní láti “tú ẹ̀mí [wọn] jáde nínú àdúrà sí Ọlọ́run, pé kí ó lè fún [wọn]; … lókun kí ó sì gbà [wọ́n]… Olúwa [sí] … bẹ̀ [wọ́n] wò pẹ̀lú ìdánilójú pé yíò gbà wọ́n là” “nítorí ìgbàgbọ́ títayọ wọn nínú ohun tí a ti kọ́ wọn láti gbàgbọ́.”
A kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Hélámánì pé àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọ̀nyí jẹ́ títìlẹ́hìn nipasẹ̀ àwọn òbí wọn. Àwọn òbí olõtọ́ wọ̀nyí mọ̀ pé àwọn ní ojúṣe pàtàkì fún kíkọ́ àwọn ọmọ wọn. Wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn láti pa àwọn òfin mọ́ kí wọ́n ó sì “rìn ní ìdúróṣinṣin” níwájú Olúwa. Àwọn ìyá wọn kọ́ wọn, pé tí nwọ́n kò bá ṣiyèméjì, Ọlọ́run yíò gbà wọ́n.” Àwọn baba wọn ṣètò àpẹrẹ alágbára májẹ̀mú dídá. Àwọn jagunjagun tẹ́lẹ̀ rí yìí mọ àwọn ẹ̀rù ogun. Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn aláìní ìrírí sí àbójútó Hẹ́lámánì wọ́n sì ntì wọ́n lẹ́hìn nípa fífi “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpèsè ránṣẹ́.”
Hẹ́lámánì kò dá wà bí ó ṣe nsin àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ogun rẹ̀. Ó ní àwọn ènìyàn ní àyíká rẹ̀ tí ó máa nyípadà sí fún àtìlẹhìn àti ìtọ́ni. Ó nawọ́ sí NBalógun Mórónì fún ìrànlọ́wọ́, ó sì wá.
Kò sí ẹni tó nsìn nínú ìjọba Olúwa tó ndá nìkan sìn. Olúwa ti bùkún wa pẹ̀lú àwọn wọ́ọ̀dù àti àwọn èèkàn. Nípasẹ̀ ètò Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò, a ní àwọn ohun èlò, ọgbọ́n, àti ìmísí láti dojúkọ èyíkéyìí ìpèníjà.
Bíṣọ́pù kan nṣe àbojútó wọ́ọ̀dù nípasẹ̀ àwọn ìgbìmọ̀. Ó nṣe ìgbélárugẹ àwọn ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní oṣù métamẹ́ta, ó sì ngba àwọn alàgbà àti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ níyànjú láti ṣe ojúṣe wọn ti ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ẹbí. Àwọn àjọ ààrẹ wọ̀nyí nṣíwájú ní ṣíṣe àyẹ̀wò àwọn ìnílò àti wíwá àwọn ojutu tí ó nimisi. Àwọn ààrẹ èèkàn npèsè àtìlẹ́hìn nípa kíkọ́ iyejú àwọn alàgbà àti àwọn àjọ ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ nínú àwọn ojúṣe wọ̀nyí.
Ìtọ́ni ti a nílò fún àwọn olórí àti àwọn òbí wa nínú Ibi-ikàw Ìhìnrere àti àwọn áàpú Gbígbé Ìgbé Ayé Ìhìnrere. Nínú àwọn ohun èlò onimisi wọ̀nyí, a lè rí àwọn ìwé mímọ́, àwọn ìkọ́ni àwọn wòlíì òde òní, àti Ìwé-Ìléwọ́ Gbogbogbò. Táàbú àwọn ọ̀dọ́ nínú Ibi-Ikàwe Ìhìnrere ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun èlò fún iyejú àti àwọn àjọ́ ààrẹ kíláàsì ó sì ní Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́: Ìtọ́ni Kan fún Ṣíṣe Àwọn Yíyàn Bí gbogbo àwọn ọmọ-ìjọwọ́ọ̀dù ti nṣe àṣàrò àwọn orísun onímísí wọ̀nyí tí wọ́n sì nwá ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí, gbogbo ènìyàn lè jẹ́ dídarí láti ọwọ́ Olúwa ní fífún àwọn ọ̀dọ́ lókun.
Gbogbo wọ́ọ̀dù naa ni yíò jẹ́ alabukunfun àti fífún lókun bí àwọn ọmọ ìjọ ṣe nfojúsùn sórí ìran tó ndìde. Láìka àwọn àìpé àti àwọn àìyẹ wa sí, Baba Ọ̀run npe ẹnikọ̀ọ̀kan wa, nípasẹ̀ ìdàpọ̀ Ẹ̀mí Rẹ̀, láti nawọ́ sí àwọn ẹlòmíran. Ó mọ̀ pé à ndàgbà a sì di yíyàsímímọ́ bí a ti ntèlẹ́ àwọn ìṣílétí Ẹ̀mí Mímọ́. Kò já mọ́ nkan pé àwọn akitiyan wa jẹ́ àìpé. Nígbàtí a bá jẹ́ alabaṣepọ pẹ̀lú Olúwa, a lè nígbẹkẹ̀lé pé àwọn ìgbìyànjú wa yíò wà ní ìlà pẹ̀lú ohun tí Òun yìó ṣe fún àwọn ọ̀dọ́.
Nípa títẹ̀lé ìdarí ti Ẹ̀mí Mímọ́ ní nínawọ́ sí àwọn ọ̀dọ́, a di ajẹri ti ìfẹ́ Baba Ọ̀run nínú ìgbésí ayé wọn. Gbígbé ìgbésẹ̀ lórí àwọn ìṣílétí láti ọ̀dọ̀ Olúwa ngbé àwọn ìbáṣepọ̀ ti ìfẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé dúró. Ó jẹ́ àwọn ìbáṣepọ̀ ní ìgbésí ayé àwọn ọ̀dọ́ tí ó ní ipa nlá jùlọ lórí àwọn yíyàn wọn.
Àwọn ọ̀dọ́ náà yíò kọ́ àwòṣe ìfihàn bí wọ́n ṣe nkópa pẹ̀lú wa nínú ìgbékalẹ̀ wíwá àti ṣíṣe lórí ìṣílétí láti sin àwọn ẹlòmíràn. Bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe nyí sí Olúwa fún ìtọ́sọ́nà onímìísí yìí, ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀ yíò jinlẹ̀ síi.
A nfi ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú àwọn ọ̀dọ́ hàn nípa ṣíṣe àtìlẹhìn àti ìtọ́sọ́nà, láì gbà jọba. Bí a ṣe nfà sẹ́hìn tí a sì ngba àwọn ọ̀dọ́ láyè láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ gbígbàmọ̀ràn papọ̀, yíyan ipa-ọna onímìísí, àti fífi ètò wọn sí ìṣe, wọn yíò ní ìrírí ayọ̀ àti ìdàgbàsókè tòótọ́.
Ààrẹ Henry B. Eyring kọ́ni pé “Ohun tí yío já mọ́ nkan jùlọ ni ohun tí wọ́n bá kọ́ ní ara [yín] nípa ẹni tí wọ́n jẹ́ gãn àti ohun tí wọn le dà nítòótọ́. Èrò inú mi ni pé wọn kò le kọ́ ọ púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀ láti inú àwọn ìkọ́ni ọ̀rọ̀ sísọ. Wọn yío rí i láti inú àwọn ìmọ̀lára ẹni tí ẹ jẹ́, ẹni tí ẹ rò pé wọ́n jẹ́, àti ohun tí ẹ rò pé wọ́n le dà.”
Àwọn ọ̀dọ́ wa máa nfi ìgboyà, ìgbàgbọ́, àti àwọn agbára wọn yà wá lẹ́nu. Bí wọ́n ṣe yàn láti jẹ́ ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì ní kíkún, ihinrere Rẹ̀ yíò wọ̀ ọkàn wọn. Títẹ̀lé E yíò di apákan irú ẹni tí wọ́n jẹ́, kìí ṣe ohun tí wọ́n nṣe nìkan.
Hélámánì ran àwọn ọ̀dọ́ Ámónì lọ́wọ́ láti rí bí ọmọẹ̀hìn Jésù Kristi tó jẹ́ akíkanjú ṣe gbé ìgbésí ayé rẹ̀. A lè jẹ́ àwọn àpẹrẹ tó lágbára fún àwọn ọ̀dọ́ nípa bí àwọn ọmọẹ̀hìn Krístì ṣe ngbé lónìí. Àwọn òbí olotọ ngbàdúrà fún àwọn àpẹrẹ wọ̀nyí nínú ìgbésí ayé àwọn ọmọ wọn. Kò sí ètó tí ó lè rọ́pò ipa ti àwọn olufẹni àgbàlagbà, olùpa májẹ̀mú mọ́.
Bí ààrẹ iyejú àwọn àlùfáà, bíṣọ́pù lè fi àpẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ nipa bí wọ́n ṣe lè jẹ́ olotọ ọkọ àti olùfẹni baba nípa dídáàbò bò, pípèsè, àti ṣíṣe àkóso ní àwọn ọ̀nà òdodo. Àwọn Bíṣọ́pù, pẹ̀lú ìfojúsùn bíi-lésà lórí àwọn ọ̀dọ́, yíò ní ipa tí yíò pẹ́ títí fún àwọn ìran.
Àwọn ọ̀dọ́ loni wa laarin àwọn ẹ̀mí ọlọ́lá jùlọ ti Baba Ọ̀run. Wọ́n wà nínù àwon olùgbèjà otitọ àti agbára òmìnira ní ayé ṣaájú ikú. Wọ́n bí wọn ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí láti kó Ísírẹ́lì jọ nípasẹ̀ ẹ̀rí wọn tó lágbára nípa Olúwa Jésù Kristi. Ó mọ ọ̀kọ̀ọkan wọn ó sì mọ agbára nlá wọn. Ó ní sũrù bí wọ́n ti ndàgbà. Yíò rà wọ́n padà yíò sì dábàbò wọ́n. Òun yíò wò wọ́n sàn, yíò sì tọ́ wọn sọ́nà. Òun yíò mí sí wọn. Àwa, òbí àti olùdarí wọn, ti múra láti ṣe àtìlẹ́hìn fún wọn. A ni Ìjọ Olùgbàlà láti ràn wá lọ́wọ́ bí a ṣe ntọ́ ìran tó nbọ̀ dàgbà.
Mo jẹ́rìí pé Ìjọ Krístì, tí a múpadàbọ̀sípò nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith tí Ààrẹ Russell M. Nelson sì ndarí lónìí, ni a ṣètò láti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti mú èrèdí nlá wọn ṣẹ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.