Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ní igbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Ní igbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.

Ìbáṣepọ wa pẹ̀lú Ọlọ́run máa dàgbà nìkan dé ìwọ̀n tí a nfẹ́ láti gbẹ́kẹ̀lé E.

Nínú ẹbí wa, nígbà míràn a máa nṣe eré kan tí a npè ní “ìdárayá Ìgbẹ́kẹ̀lé Aṣiwèrè.” Ẹ lè ti ṣeé bákanáà. Ènìyàn méjì á dúró ní ẹsẹ̀ bàtà díẹ̀ si ara wọn, ọ̀kan pẹ̀lú ẹ̀hìn wọn si èkejì. Lórí àmì ṣíṣe láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó wà lẹ́hìn, ẹni tí ó wà níwájú á ṣubú sẹ́hìn sínú àwọn apá dídúró ti ọ̀rẹ́ wọn.

Ìgbẹ́kẹ̀lé jẹ́ ìpìlẹ̀ gbogbo àwọn ìbáṣepọ̀. Ìbèèrè ìlóro sí èyíkèyí ìbáṣepọ̀ ni “Ṣé mo lè gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn míràn?” Ìbásepo ndi ṣíṣe nígbàtí awọn ènìyàn bá ṣetán láti fi ìgbékẹ̀lé sí inú ara wọn nìkan. Kìí ṣe ìbáṣepọ̀ bí ènìyàn kan bá gbẹ́kẹ̀lé pátápátá ṣùgbọ́n tí ìkejì ò nígbẹkẹ̀lé.

Ẹni kọ̀ọ̀kan wa jẹ́ àyànfẹ́ ọmọẹ̀mí ọkùnrin tàbí obìnrin olùfẹ́ni Baba Ọ̀run. Ṣùgbọ́n nígbàtí ìtàn ìrandíran nípa ti ẹ̀mí npèsè ìpìlẹ̀, kò fúnra rẹ̀ ṣe ẹ̀dá ìbáṣepọ̀ tó nítumọ̀ pẹ̀lú Ọlọrun. A lè kọ́ ìbáṣepọ̀ nígbàtí a bá yàn láto gbékẹ̀lé E.

Baba Ọ̀run nwa láti ṣètò ìbáṣepọ̀ tí ó jinlẹ, àti ti araẹni pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ ẹ̀mí Rẹ̀. Kí gbogbo wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan; gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti jẹ́ nínú mi, àti èmi nínú rẹ, kí àwọn pẹ̀lú kí ó lè jẹ́ ọ̀kan nínú wa.” Ìbáṣẹpọ̀ tí Olọ̀run nwa pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọkan ọmọ ẹ̀mí jẹ́ èyí tí ó súnmọ́ra àti ti araẹni tí Ó lè pín gbogbo ohun tí Ó ní àti ohun gbogbo ti Ó jẹ́. Irú jíjìn bẹ́ẹ̀, ìbáṣepọ̀ pípẹ́ lè dàgbà nígbàtí a bá kọ́ ọ lé orí ìgbẹ́kẹ̀lé pípé ati pátápátá nìkan.

Fún apá ọ̀dọ̀ Rẹ̀, Baba Ọ̀run ti ṣiṣẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ láti sọ nípa ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá Rẹ̀ nínú agbára àtọ̀runwá ti ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Rẹ̀. Ìgbẹ́kẹ̀lé wà lábẹ́ ètò tí Ó gbékalẹ̀ fún ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú wa ṣaájú wíwá wa sí ilẹ̀ ayé. Òun yíò kọ́ wa ní àwọn òfin ayérayé, ṣe ẹ̀dá ilẹ̀-ayé kan, fún wa ní ara ikú, fún wa ní ẹ̀bùn láti yàn fúnra wa, yíò sì gbàwá láyè láti kọ́ ẹ̀kọ́ àti láti dàgbà nípa ṣíṣe àwọn yíyàn ti wa. Ó fẹ́ kí a yàn láti tẹ̀lé àwọn òfin Rẹ̀ kí a sì padà wá gbádùn ìyè ayérayé pẹ̀lú Òun àti Ọmọ Rẹ̀.

Mímọ̀ pé a kì yíò fi ìgbà gbogbo ṣe yíyàn tí ó dára, Ó tún pèsè ọ̀nà kan sílẹ̀ fún wa láti bọ́ lọ́wọ́ àbájáde àwọn yíyàn búburú wa. Ó pèsè Olùgbàlà kan fún wa—Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì—láti ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kí ó sì sọ wa di mímọ́ lẹ́ẹ̀kansíi lórí ipò àjọsọ ìrònúpìwàdà. Ó pè wá láti máa lo ẹ̀bùn iyebíye ti ìrònúpìwàdà déédéé.

Gbogbo òbí mọ bí ó ti ṣòro tó láti gbẹ́kẹ̀lé ọmọ kan láti ṣe àwọn ìpinnu, pàápàá nígbàtí òbí bá mọ̀ pé ọmọ náà yíò ṣe àwọn àṣìṣe kí ó sì jìyà bíi àbájáde rẹ̀. Síbẹ̀ Baba Ọ̀run gbàwá láyè láti ṣe àwọn yíyàn tí yíò rànwálọ́wọ́ láti débi agbára àtọ̀runwá wa! Bí Alàgbà Dale G. Renlund ti kọ́ni, “Àfojúsùn [Rẹ̀] nínú síṣe òbí kìí ṣe láti mú àwọn ọmọ Rẹ̀ ṣe ohun tí ó tọ́; ó jẹ́ láti mú àwọn ọmọ Rẹ̀ yàn láti ṣe ohun tí ó tọ́ ati nígbẹ̀hìn kí wọn ó dà bí Rẹ̀.”

Bíótiwùkíórí láìka ìgbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun nínú wa sí, ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Rẹ̀ lè dàgbà dé ìwọ̀n àyè tí a fẹ́ láti gbẹ́kẹ̀lé E. Ìpèníjà náà ni pé a ngbé nínú ayé tí ó ti ṣubú a sì ti pàdánù ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ẹlòmíràn nítorí àìṣòótọ́, àṣìlò, ìwà ọ̀dàlẹ̀, tàbí àwọn ipò míràn. Bí a bá ti dà wá lẹ́ẹ̀kan, a máa nrí pé ó nira láti tún ní ìgbẹkẹ̀lé. Àwọn ìrírí ìgbẹ́kẹ̀lé òdì pẹ̀lú àwọn ènìyàn aláìpé ní ipa lórí agbára àti ìfẹ́ wa láti gbẹ́kẹ̀lé Baba Ọ̀run pípé.

Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, àwọn ọ̀rẹ́ mi méjì, Leonid àti Valentina, fi ìfẹ́ wọ́n hàn láti di ọmọ Ìjọ. Bí Leonid ṣe bẹ̀rẹ̀síí kọ́ ìhìnrere, ó ṣòro fún Leonid láti gbàdúrà. Ní ìṣaájú nínú ìgbésí ayé rẹ̀, Leonid ti ní ìrírí ìlòkulò àṣẹ àti ìṣekúṣe àti ìṣàkóso nípasẹ̀ àwọn ajunilọ ó sì ti di aláìnígbẹkẹ̀lé sí àṣẹ. Àwọn ìrírí yí mú kí ó ṣòro fún un láti ṣí ọkàn rẹ̀ kí ó sì sọ ìmọ̀lára rẹ̀ fún Baba Ọ̀run. Pẹ̀lú àkokò àti àṣàrò, Leonid ní òye dáadáa síi nípa ìwà Ọlọ́run ó sì bẹ̀rẹ̀sí ní àwọn ìrírí níní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run. Lẹ́hìn-ọ̀-rẹhìn, àdúrà di ọ̀nà àdánidá fún un láti dúpẹ́ àti láti fi ìfẹ́ tí ó nímọ̀lára rẹ̀ fún Ọlọ́run. Ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nínú Ọlọ́run npọ̀ síi, ó sì ní darí òun àti Valentina láti fún ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú Ọlọ́run lókun nípa wíwọ inú àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀ àti ọ̀kọ̀ọkan wọn.

Bí sísọ ìgbẹ́kẹ̀lé nù ní ìṣaajú bá ndí yín lọ́wọ́ láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, ẹ jọ̀wọ́ tẹ̀lé àpẹrẹ Leonid. Pẹ̀lú sùúrù ẹ túnbọ̀ máa kọ́ síi nípa Baba Ọ̀run, ìwà Rẹ̀, àwọn èròjà Rẹ̀, àti àwọn èrèdí Rẹ̀. Ẹ wá kí ẹ sì ṣe ìgbàsílẹ̀ àwọn ìrírí ìmọ̀lára ìfẹ́ àti agbára Rẹ̀ nínú ìgbésí ayé yín. Wòlíì wa alààyè, Ààrẹ Russell M. Nelson, ti kọ́ni pé bí a bá ṣe nkọ́ nípa Ọlọ́run tó, bẹ́ẹ̀ ni yíò ṣe rọrùn fún wa láti gbẹ́kẹ̀lé E.

Nígbà míràn ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti kọ́ láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run nìkan ni nípa gbígbẹ́kẹ̀lé Rẹ̀. Bíi “Ìdárayá Ìgbẹ́kẹ̀lé Ìríkùrí,” nígbàmíràn a kàn nílò láti múratán láti ṣubú sẹ́hìn kí á jẹ́ kí Ó mú wa. Ìgbésí ayé ti-ikú jẹ́ ìdánwó ránpẹ́ kan. Àwọn ìpèníjà tí ó nà wá tàn kọjá agbára tiwa nwá léraléra. Nígbàtí ọgbọ́n àti òye wa kò bá tó, a máa nwá ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn orísun míràn. Nínú ayé tí ó kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwífúnni, a kò le ṣàìnító àwọn orísun ojutu tiwọn sí àwọn ìpèníjà wa. Bíótiwùkíórí, ìmọ̀ràn rírọrùn, tí kò ní àkokò tó wà nínú Ìwé Òwe pèsè ìmọ̀ràn tí ó dára jùlọ fún wa pé: “Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.” A fi ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run hàn nípa yíyípadà sí I lakọkọ nígbàtí a bá kojú àwọn ìpèníjà.

Lẹ́hìn tí mo parí ilé-ìwé amòfin, ẹbí wa kojú ìpinnu pàtàkì ibi tí a ò ti ṣiṣẹ́ kí á sì ṣe ilé wa. Lẹ́hìn ìbádámọ̀ràn pẹ̀lú ara wa àti Olúwa, a nímọ̀lára ìdarí láti kó ẹbí wa lọ sí ìlà-oòrùn United States, tí ó jìnnà sí àwọn òbí àti ọmọ ìyá. Níbẹ̀rẹ̀, nkan lọ dáadáa, a sì nímọ̀lára ìfẹsẹ̀múlẹ̀ pé Ọlọ́run ló darí ìpinnu náà. Ṣùgbọ́n nígbànáà àwọn nkan yípadà. Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì wà ní ilé iṣẹ́ amòfin, mo sì dojú kọ ìpàdánù owó tó nwọlé àti ètò ìdójútòfò ní àkókò gan-an tí a bí ọmọbìnrin wa Dora tó ndojú kọ àwọn ìpèníjà íṣègùn líle àti àwọn àkànṣe àìní ọlọ́jọ́ pípẹ́. Nígbàtí mo nṣiṣẹ́ larin àwọn ìpèníjà wọ̀nyí, mo gba ìpè Ìjọ kan tí yíò nílò àkokò pàtàkì àti ìfọkánsìn.

Èmi kò ì tíì dojúkọ ìpèníjà tí ó bonimọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ rí. Mo bẹ̀rẹ̀ síí bèrè ìpinnu tí a ṣe àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ tí ó tẹ̀le. A ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa, àti pé ó yẹ kí àwọn nkan ṣeéṣe. Mo ti ṣubú sẹ́hìn, ó sì dà bíi pé kò sẹ́ni tó fẹ́ mú mi.

Ní ọjọ́ kan àwọn ọ̀rọ̀ “Máṣe bèrè kínìdí; bèrè ohun tí mo fẹ́ kí o kọ́” wá sínú èrò inú àti ọkàn mi ṣinṣin. Nísisìyí ọkàn mi túbọ̀ pòrúurùú síi. Ní àkokò tí mo ntiraka pẹ̀lú ìpinnu mi ìṣaájú, Ọlọ́run npè mí láti gbẹ́kẹ̀lé E àní púpọ̀ díẹ̀ síi. Wíwo ẹ̀hìn, èyí jẹ́ kókó pàtàkì kan nínú ìgbésí ayé mi—ó jẹ́ àkokò náà tí mo rí i pé ọ̀nà tó dára jù lọ láti kọ́ láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run ni nípa gbígbẹ́kẹ̀lé E lásán. Ní àwọn ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀lé e, mo wò pẹ̀lú ìyàlẹ́nu bí Olúwa ṣe ṣí ètò rẹ̀ lọ́nà ìyanu láti bùkún ẹbí wa.

Àwọn olùkọ́ àti àwọn olù̀kọ́ni rere mọ̀ pé ìdàgbàsókè ọgbọ́n orí àti agbára ti ara lè ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ nína àwọn ọkàn àti àwọn iṣan nìkan. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ọlọ́run npé wa láti dàgbà nípa gbígbẹ́kẹ̀lé ìdánilẹ́kọ̀ ẹ̀mí Rẹ̀ nípasẹ̀ nína-kàn. Nítorínáà, a lè ní ìdánilójú pé irú ìgbẹ́kẹ̀lé yòówù tí a lè ti ṣe àfihàn tẹ́lẹ̀rí nínú Ọlọ́run, ìrírí míràn tó nna ìgbẹ́kẹ̀lé tàn ṣì wà níwájú. Ọlọ́run nfojúsùn sí ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú wa. Òun ni olùkọ àgbà, olù̀kọ́ni pípé náà ẹni tí ó nnà wá nígbàgbogbo láti rànwá lọ́wọ́ láti mọ díẹ̀ si nípa agbára àtọ̀runwá wa. Èyi yíò fì ìgbà gbogbo ní ìfìpè ọjọ́ iwájú ninu láti gbẹ́kẹ̀lé E kékeré díẹ̀ síi.

Ìwé ti Mọ́mọ́nì kọ́ni ní ìlànà tí Ọlọ́run nlò láti nà wá kí a lè kọ́ àwọn ìbáṣepọ̀ tó lágbára pẹ̀lú wa. Nínú Wá, Tẹ̀lé Mi, a kọ́ ẹ̀kọ́ láìpẹ́ yi nípa bí a ṣe dán ìgbẹ́kẹ̀lé Néfì nínú Ọlọ́run wò nígbàtí a pàṣẹ fún òun ati awọn arákùnrin rẹ̀ láti padà sí Jerúsálẹ́mù láti gba àwọn àwo idẹ. Lẹ́hìn tí ìgbìyànjú wọn àkọ́kọ́ kùnà, àwọn arákùnrin rẹ̀ jáwọ́, wọ́n sì ṣetán láti padà láìsí àwọn àwo náà. Ṣùgbọ́n Néfì yàn láti gbé ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ pátápátá sínú Olúwa ó sì ṣe àṣeyọrí ní gbígba àwọn àwo náà. Ó ṣeé ṣe kí ìrírí náà fún ìgbẹ́kẹ̀lé Néfì nínú Ọlọ́run lókun nígbàtí ọrun rẹ̀ ṣẹ́ tí ẹbí náà sì ndojúkọ ebi ní aginjù. Lẹ́ẹ̀kansi, Néfì yàn láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, a sì gba ẹbí náà là. Àwọn ìrírí tí ó tẹ̀lera wọ̀nyí fún Néfì ní ìgbẹ́kẹ̀lé jíjinlẹ̀ síi nínú Ọlọ́run fún ànfààní mímú ìgbẹ́kẹ̀lé-nínà iṣẹ́ kíkọ́ ọkọ̀ ojú omi kan.

Nípasẹ̀ àwọn ìrírí tí ó tẹ̀léra, Néfì fún ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run lókun nípa gbígbẹ́kẹ̀lé E déédéé àti títí lọ. Ọlọ́run nlo àpẹrẹ kannáà pẹ̀lú wa. Ó nfún wa ní àwọn ìfipè ti ara ẹni láti fún wa lókun àti láti mú ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Rẹ̀ jinlẹ̀ si. Ní ìgbà kọ̀ọ̀kan tí a bá gbà tí a sì gbé ìgbésẹ̀ lórí ìfipè kan, ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Ọlọ́run ndàgbà si. Bí a bá fojú parẹ́ tàbi kọ ìfipè kan sílẹ̀, ìlọsíwájú wa á dúró títí di ìgbà tí a ba gbé ìgbésẹ̀ lórí ìfipè titun kan.

Ìròhìn dídára náà ni pé láìbìkítà ìgbẹ́kẹ̀lé tí a lè ti tàbí lè má ti yàn láti fi sínú Ọlọ́run láti ẹ̀hìn wá, a lè yàn láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run loni àti ní gbogbo ọjọ́ lọ siwájú. Mo ṣèlérí pé ìgbà kọ̀ọ̀kan tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run yíò wà níbẹ̀ láti mú wa, àjọṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wa yíò sì máa lágbára sí i títí di ọjọ́ tí a bá di ọ̀kan pẹ̀lú Rẹ̀ àti Ọmọ Rẹ̀. Nígbànáà a lè kéde bí Néfì, “Ah Olúwa, èmi ti gbẹ́kẹ̀lé ọ, èmi yíò sì gbẹ́kẹ̀lé ọ títí láé.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀