![](https://www.churchofjesuschrist.org/imgs/https%3A%2F%2Fassets.churchofjesuschrist.org%2F07%2F0a%2F070a7e14deae2394140bf5c6408aba3deb0c191c%2F070a7e14deae2394140bf5c6408aba3deb0c191c.jpeg/full/!250,/0/default)
Ohun Gbogbo fún Rere Wa
Ní ìgbà àti àìlópin, èrèdí ìṣẹ̀dá àti ìwà-ẹ̀dá Ọlọ́run Fúnrarẹ ni láti mú ohun gbogbo wá papọ̀ fún rere wa.
Òní ni Ọjọ́ Kẹfà Oṣù Kẹ́rin, àjọyọ̀ Jésù Krístì tí ó mú Ìjọ Rẹ̀ ọjọ́-ìkẹhìn padàbọ̀sípò—àti pé ara àkokò Ọdún Àjínde, nígbàtí à nfi pẹ̀lú ayọ jẹri nípa ìgbésí ayé pípé Jésù Krístì, ìrúbọ ètùtù, àti Àjínde ológo.
Ìtàn Chinese kan bẹ̀rẹ̀ bí ọmọkùnrin ọkùnrin kan ṣe rí ẹṣin rírẹwà kan.
“Bí oríre ti tó,” ni àwọn aladugbo wí.
“A ó ri,” ni ọkùnrin náà wí.
Nígbànáà ọmọkùnrin náà ṣubú látorí ẹṣin ó sì ní ìpalára títíláé.
“Bí oríre ti tó,” ni àwọn aladugbo wí.
“A ó ri,” ni ọkùnrin náà wí.
Ológun tí a fi tipatipa kó wá ṣùgbọ́n tí wọn kò mú ọmọkùnrin tó ní ìpalára lọ.
“Bí oríre ti tó,” ni àwọn aladugbo wí.
“A ó ri,” ni ọkùnrin náà wí.
Ayé àìní-àdéhùn ìgbàkugbà nní ìmọ̀ ẹ̀fúfù-líle, àìní-ìdánilójú, ìgbàmíràn ní dídára, àti—ìgbàkugbà pẹ̀lú—àìdára. Síbẹ̀síbẹ̀, nínú ayé ìpọ́njú yí, “a mọ̀ pé ohun gbogbo nṣiṣẹ́ papọ̀ fún rere àwọn tí ó fẹ́ràn Ọlọ́run.” Lootọ, bí a ti nrìn nítòótọ́ tí a sì nrántí àwọn májẹ̀mú wa, “gbogbo ohun yíò ṣiṣẹ́ papọ̀ fún rere yín.”
Ohun Gbogbo fún Rere Wa.
Ìlérí alámì kan! Ìdánilójú títuni-nínú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Fúnrarẹ̀! Ní ọ̀nà ìyanu kan, èrèdí Ìṣẹ̀dá àti ìwà-ẹ̀dá Ọlọ́run ni láti mọ ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin; láti mú gbogbo ohun tí ó wà fún rere wa ṣẹ; àti láti ràn wá lọ́wọ́ láti di yíyàsímímọ́ àti mímọ́ nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti Ètùtù Jésù Krístì.
Ètùtù Jésù Krístì lè gbà wá ó sì lè ràwápadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n Jésù Krístì bákannáà ní òye tímọ́tímọ́ ti gbogbo ìrora, ìnira, àìsàn, ìkorò, ìyapa. Ní àkokò àti àìlópin, ìṣẹ́gun Rẹ̀ lórí ikú àti ọ̀run-àpáàdì lè mú ohun gbogbo dára. Ó nṣèrànwọ́ láti wo onírora àti onírẹ̀wẹ̀sì sàn, ó làjà oníbínú àti olùyapa, ó tu àdánìkanwà àti olùpatì nínú, ó gba aláìnírètí àti aláìpé níyànjú, ó sì mú àwọn iṣẹ́ ìyànú tó ṣeéṣe pẹ̀lú Ọlọ́run nìkan jáde wá.
À nkọ hallelúyàh a sì ké hòsánnà Pẹ̀lú agbára ayérayé àti inúrere àìlópin, nínú ètò ìdùnnú Ọlọ́run ohun gbogbo lè ṣiṣẹ́ papọ̀ fún rere wa. A lè dojúkọ ayé pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé tí kìí sì ṣe ẹ̀rù.
Bí a bá fi wá sílẹ̀ fúnra wa a kò lè mọ rere ti ara wa. Nígbàtí “Mo bá yàn mí,” bákannáà mò nyan àwọn ìdínkù, àìlera, àìtó ti ara mi. Nígbẹ̀hìn, láti ṣe rere jùlọ, a gbúdọ̀ jẹ́ rere. Nígbà tó jẹ́ pé Ọlọ́run jẹ́ rere, à nwá jíjẹ́ pípé nínú Jésù Krístì. À ndi olotitọ jùlọ wa, dídárajùlọ arawa nìkan bí a ti nmú ọkùnrin tàbí obìnrin ẹlẹ́ran ara kúrò tí a sì ndà bí ọmọdé níwájú Ọlọ́run.
Pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run, àwọn àdánwò àti ìpọ́njú lè di yíyàsọ́tọ̀ fún rere wa. Jósẹ́fù, tí a tà sóko ẹrú ní Egypt, lẹ́hìnwá gba ẹbí àti àwọn ènìyàn rẹ̀ là. Wòlíì Joseph Smith nínú ìtìmọ́lé ní ẹ̀wọ̀n Liberty kọ́ ọ pé “àwọn nkan wọ̀nyí yìó fún ọ ní ìrírí, yíò sì jẹ́ fún rere rẹ.” Ẹ gbé pẹ̀lú ìgbàgbọ́, àwọn àdánwò àti rírúbọ tí a kò yàn rí lè bùkún wa àti àwọn ẹlòmíràn ní àwọn ọ̀nà tí a kò lérò.
À nmú ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé pọ̀si nínú Olúwa pé kí ohun gbogbo lè ṣiṣẹ́ papọ̀ fún rere wa bí a ti njèrè ìwòye ayérayé; ní òye àwọn àdánwò wa bóyá “ṣùgbọ́n fún àkokò kékeré kan”; da mọ̀ pé ìpọ́njú lè di yíyàsọ́tọ̀ fún èrè wa; a mọ̀ pé àwọn ìjámbá, ikú àìtọ́jọ́, ìrẹ̀lẹ̀ àìsàn àti àrùn jẹ́ ara ayé ikú; a sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé olùfẹ́ni Baba Ọ̀run kò ní fúnni ní àwọn àdánwò láti fìyà jẹni tàbí dáni lẹ́jọ́. Òun kò ní fi òkúta fún ẹnìkan tí ó nbèèrè fún búrẹ́dì tàbí ejò fún ọ̀kan tí ó nbèèrè fún ẹja.
Nígbàtí àwọn àdánwò bá dé, nígbàkugbà ohun tí a nfẹ́ jùlọ ni fún ẹnìkan láti fi etísílẹ̀ kí ó sì wà pẹ̀lú wa. Ní àkokò náà, àwọn ìdáhùn wíwọ́pọ̀ kò lè ṣèrànwọ́, bíótiwù kí ó tu èrèdí wọn nínú tó. Nígbàmíràn à nyọ́nú fún ẹnìkan tí yíò ṣọ̀fọ̀, nírora, tí ó sì nsọkún pẹ̀lú wa; ẹ jẹ́ kí a fi ìrora, ìjákulẹ̀, àní ìbínú hàn; kí a sì gbà fúnra wa pé àwọn ohun tí a kò mọ̀ wà.
Nígbàtí a bá gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa, àní àwọn ìrora ọkàn wa títóbi jùlọ ní ìgbẹ̀hìn lè ṣiṣẹ́ papọ̀ fún rere wa.
Mo rántí ọjọ́ náà tí mo gba ọ̀rọ̀ ti ìjàmbá ọkọ̀ líle èyí tí àwọn tí mo fẹ́ràn wà nínú rẹ̀. Ní iru àwọn ìgbà bẹ́ẹ̀, nínú ìrora àti ìgbàgbọ́, a lè wí pẹ̀lú Jóbù nìkan pé, “Olúwa fifúnni, Olúwa sì gbà á lọ; ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa.”
Káàkiri Ìjọ àgbáyé, àwọn 3,500 èèkan àti ẹ̀kùn àti àwọn wọ́ọ̀dù àti ẹ̀ká 30,000 npèsè ààbò àti ìsádi kúrò nínú àwọn ìjì. Ṣùgbọ́n nínú àwọn èèkan wa àti wọ́ọ̀dù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹbí àti olúkúlùkù onígbàgbọ́ ndojúkọ àwọn ìpènijà líle, àní nígbàtí wọ́n mọ̀ pé (láì tí mọ báwo síbẹ̀) àwọn ohun yíò ṣiṣẹ́ fún rere wa.
Ní Huddersfield, England, Arákùnrin Samuel Bridgstock ni a yẹ̀wò pẹ̀lú ipele kẹrin àrùn jẹjẹrẹ ní kété ṣíwájú pípe rẹ̀ bí ààrẹ titun èèkàn. Ní Fífúnni ní àyẹ̀wò líle rẹ̀, ó bèèrè lọ́wọ́ ìyàwó rẹ̀, Anna, àní ìdí tí òun yíò fi lọ fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.
“Nítorí,” Arábìnrin Bridgstock wípé, “wọn yíò pè ọ́ bí ààrẹ èèkàn.”
Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ a fun ní ọdún kan tàbí méjì láti gbé, Ààrẹ Bridgstock (ẹni tí ó wà nihin loni) wà ní ọdún kẹrin iṣẹ́-ìsìn rẹ̀. Ó ní àwọn ọjọ́ rere àti líle. Èèkàn Rẹ̀ nkórajọ pẹ̀lú àlékún ìgbàgbọ́, iṣẹ́-ìsìn, àti inú rere. Kò rọrùn, ṣùgbọ́n ìyàwó àti ẹbí rẹ̀ gbé pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ìmoore, àti pé níní ìmòye ìbànújẹ́ wọ́n, wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé yíò di ayọ nípasẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò Ètùtù Jèsù Krístì.
Nígbàtí a bá dúró, láwọ́, tí a sì ní ọ̀wọ̀, a lè ní ìmọ̀lára ẹwà, èrèdí, àti ìdákẹ́rọ́rọ́ wíwá-nínú májẹ́mú tí Olúwa fúnni. Ní àwọn àkokò mímọ́, Òun lè jẹ́ kí a rí fìrí ìmọ́lẹ̀ òdodo títóbi ayérayé nípa èyí tí ìgbé ayé wa ojojúmọ́ jẹ́ ara rẹ̀, níbi tí àwọn ohun kékeré àti jẹ́jẹ́ ti nṣiṣẹ́ papọ̀ fún rere olùfúnni àti olùgbà.
Rebekah, ọmọbìnrin ààrẹ míṣọ̀n mi àkọ́kọ́, ṣe àbápín bí Olúwa ti dáhùn àdúrà rẹ̀ fún ìtùnú pẹ̀lú ànfàní àìlerò láti dáhùn àdúrà ti ẹnìkan.
Ní ọjọ́rọ̀ kan, Rebekah, nṣọ̀fọ̀ kíkọjá lọ àìpẹ́ ìyá rẹ̀, ó ní ìtẹ̀mọ́ra kedere kan láti lọ ra gáàsì fún ọkọ̀ rẹ̀. Nígbàtí ó dé ibùsọ̀ náà, ó pàdé obìnrin àgbàlàgbà kan tí ó nmí tí ó sì ntiraka pẹ̀lú òdù-nlá ọ́sígìn títóbi kan. Lẹ́hìnnáà, Rebekah fún obìnrin náà ní ẹ̀rọ gbígbé ọ́sígìn ti ìyà rẹ̀. Arábìnrin yí fi ìmoore wípé, “o ti fún mi ní òmìnira mi padà.” Àwọn ohun nṣiṣẹ́ papọ̀ fún rere nígbàtí a bá ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ bí bí Jésù Krístì ti ṣe.
Bí baba kan tí a yàn pẹ̀lú ọmọkùnrin rẹ ọjọ́ orí olùkọ́ bi àwọn ojúgba òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ṣàlàyé, “Ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ìgbàtí a bá kúrò ní jíjẹ́ aladugbo tí ó nmú àkàra-òyìnbó lọ fún ọ̀rẹ́ tí a gbẹ́kẹ̀lé, olùfèsì àkọ́kọ́ ti ẹ̀mí.” Wíwà-nínú májẹ̀mú nínú Jésù Krístì ntuni-nínú, ó nsoni-pọ̀, ó nyanisọ́tọ̀.
Àní nínú àjálù, ìmúrasílẹ̀ ti ẹ̀mí lè ránwalétí pé alaanu Baba Ọ̀run mọ ìgbàtí a bá nímọ̀ ìpalára àti àdánìkanwà jùlọ. Fún àpẹrẹ, ẹbí kan tí ọkọ̀-pàjáwìrì gbé ọmọ wọn lọ sí ilé-ìwòsàn lẹ́hìnnáà rí ìtùnú ní rírántí pé Ẹ̀mí Mímọ́ ti sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ṣaájú ohun tí wọ́n níláti retí.
Nígbàmíràn òdodo títóbi jùlọ ayérayé tí Olúwa njẹ́ kí a ní ìmọ̀lára rẹ̀ pẹ̀lú ẹbí ní ìsọdá ìkelè. Arábìnrin kan rí ayọ̀ nínú ìyípadà sí ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ìbàlọ́kànjẹ́ méjì ti pa ayé rẹ̀ lára jinlẹ̀jinlẹ̀—rírí ìjàmbá ọkọ̀-ojú omi kan àti àjálù sísọ ìyá rẹ̀ nù, ẹni tí ó gba ẹ̀mí ara rẹ̀.
Síbẹ̀ arábìnrin yí borí ẹ̀rù rẹ̀ nípa omi tótó láti ṣe ìrìbọmi nípa ìtẹ̀bọmi. Àti pé lórí ohun tó di ọjọ́ inúdídùn gan, ó ní ẹ̀rí ẹnìkan tí ó nṣe arọ́pò fún ologbe ìyá rẹ̀, tí à nṣe ìrìbọmi fún nínú tẹ́mpìlì. “Ìrìbọmi tẹ́mpìlì wo ìyá mi sàn, ó sì sọ mí di òmìnira,” ni arábìnrin náà wí. “Ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí mo ti ní àláfíà látìgbà tí ìyá mi ti kú.”
Orin mímọ́ wa nfọhùn ìdánilójú Rẹ̀ pé ohun gbogbo lè ṣiṣẹ́ papọ̀ fún rere wa.
Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni ẹ̀rí tí a lè dìmú ní ọwọ́ wa pé Jésù ni Krístì àti pé Ọlọ́run ti mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Rẹ̀ ṣẹ. Tí a kọ nípasẹ̀ àwọn wọ̀líì tí wọ́n rí ọjọ́ wa, Ìwé ti Mọ́mọ́nì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú eré-ìdárayá tútù—ẹbí kan tí ó nbá àwọn ìyàtọ̀ jíjinlẹ̀ yí. Síbẹ̀, bí a ti nṣe àṣàrò tí a sì njíròrò Néfì kínní lọ dé Mórónì kẹwa, à nsúnmọ́ Jésù Krístì pẹ̀lú ẹ̀rí pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ àti lẹ́hìnnáà lè bùkún wa nihin àti nisisìyí.
Bí Olúwa, nípasẹ̀ àwọn wòlíì alààyè Rẹ̀, ti nmú àwọn ilé Olúwa súnmọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa síi ní àwọn ibìkan, a nrí àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì tí ó nṣiṣẹ́ papọ̀ fún rere wa. A wá nípa májẹ̀mú àti ìlànà sọ́dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jésù Krístì kí a sì jèrè ìwòye ayérayé ní ayé ikú. Ọ̀kọ̀ọ̀kan, orúkọ sí orúkọ, à nfún àwọn olólùfẹ́ ọmọ ẹbí—àwọn babanlá—ní àwọn ìlànà ìgbàlà àti àwọn ìbùkún májẹ̀mú nínú àwòṣe àwọn olùgbàlà lórí Òkè Síónì.
Bí tẹ́mpìlì ti nwá sí tòsí wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ibìkan, ìrúbọ tẹ́mpìlì tí a lè fúnni ni láti wá ìwà-mímọ́ nínú ilé Olúwa léraléra síi. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, a ti ní ipamọ́, ṣètò, a sì ti rúbọ láti wá sí tẹ́mpìlì. Nísisìyí, bí àwọn ipò ti fi àyè gbà, ẹ jọ̀wọ́ ẹ wá léraléra sí ilé mímọ́ Olúwa. Ẹ jẹ́ kí ìjọ́sìn déédé tẹ́mpìlì àti ìsìn bùkún, dá ààbò bo, kí ó sì mísí yín àti ẹbí yín—ẹbí tí ẹ ti ní àti ẹbí tí ẹ ṣì má a ní àti tí ẹ ó dà ní ọjọ́ kan.
Bákannáà, níbití àwọn ipò yín bá fi àyè gbà, ẹ jọ̀wọ́ ẹ yẹ ìbùkún níní àwọn aṣọ tẹ́mpìlì wo. Ìyá-àgbà kan láti ẹbí onírẹ̀lẹ̀ kan wípé ní ohunkóhun nínú ayé, ohun tí òun nfẹ́ jùlọ ni àwọn aṣọ tẹ́mpìlì ti ara òun. Ọmọ-ọmọ rẹ̀ wípé, “Ìyá-àgbà sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé, ‘Èmi ó sìn nínú aṣọ tẹ́mpìlì ti ara mi, àti pé nígbàtí mo bá kú, a ó simi nínú wọn.’” Àti pé ìgbàtí àkokò dé, a sin ín bẹ́ẹ̀.
Bí ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni, “Ohun gbogbo tí a gbàgbọ́ àti gbogbo ìlèrí tí Ọlọ́run ti ṣe sí àwọn ènìyàn májẹ̀mú Rẹ̀ wá papọ̀ nínú tẹ́mpìlì.”
Ní ìgbà àti àìlópin, èrèdí ìṣẹ̀dá àti ìwà-ẹ̀dá Ọlọ́run Fúnrarẹ ni láti mú ohun gbogbo wá papọ̀ fún rere wa.
Èyí ni èrèdí ayérayé Olùwa. Ó jẹ́ ìwò ayérayé Rẹ̀. Ó jẹ́ ìlérí ayérayé Rẹ̀.
Nígbatí ayé bá díjú tí èrèdí kò bá sìn hàn kedere, nígbàtí ẹ bá fẹ́ láti gbé ìgbésí ayé dídára ṣùgbọ́n tí ẹ kò mọ báwo, ẹ wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jésù Krístì. Ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Wọ́n wà láàye, nifẹ yín, àti pé wọ́n nfẹ́ ohun gbogbo fún rere yín. Mo jẹri pé Wọ́n nṣeé, ní àìlópin àti ayérayé, ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.