Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu, Âwọn Angẹ́lì, àti Agbára oyè-àlùfáà
Tí o bá fẹ́ àwọn ìbùkún ti oyè àlùfáà, pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti àwọn ángẹ́li, rìn ní ipa ọ̀nà àwọn májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti mú wá.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lóde òní sọ pé àwọn iṣẹ́ ìyanu kò sí mọ́, pé àwọn áńgẹ́lì jẹ́ ìtàn àròsọ, àti pé àwọn ọ̀run ti padé. Mo jẹ́ri wípé àwọn iṣẹ́ ìyanu ko tíì dáwọ́dúró, àwọn angẹ́lì wà láarín wa, àti pé àwọn ọ̀run ṣí sílẹ̀ ní tòótọ́.
Nígbàtí Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, wà láyé, Ó fi kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà fún olórí Àpóstélì Rẹ̀, Pétérù. Nípasẹ̀ àwọn kọ́kọ́rọ́ wọ̀nyí, Pétérù àti àwọn Àpóstélì míràn darí Ìjọ Olùgbàlà. Ṣùgbọ́n nígbàtí àwọn Àpóstélì wọnnì kú, awọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà wọ̀nyi ni a mú kúrò lórí ilẹ̀ ayé.
Mo jẹ́rí pé àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà àtijọ́ ti jẹ́ mímúpadàbọ̀sípò. Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánnù àti àwọn wòlíì àtijọ́ míràn farahàn bí àwọn ẹ̀dá tó jínde, ní fífún Wòlíì Joseph Smith ní ohun tí Olúwa ṣe àpèjúwe bí “àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba mi, àti àkókò ti ìhìnrere.”
Awọn kọ́kọ́rọ́ wọ̀nyí ti kọjá láti ọwọ́ wòlíì sí wòlíì títí di òní yìí. Àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀dógún tí a múdúró gẹ́gẹ́bi àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn nlò wọ́n láti darí Ìjọ Olùgbàlà. Gẹ́gẹ́bí ìgbà àtijọ́, Àpóstélì àgbà kan wà tí ó dìmú tí a sì fún ní àṣẹ láti lo gbogbo àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà. Òun ni Ààrẹ Russell M. Nelson, wòlíì àti Ààrẹ Ìjọ ti Kristi tí a mú padàbọ̀sípò ní ọjọ́ wa: Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.
Nípasẹ̀ Ìjọ Olùgbàlà, a gba àwọn ìbùkún oyè àlùfáà—pẹ̀lú agbára Ọlọ́run láti ràn wá lọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé wa. Lábẹ́ àṣẹ àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà, à ṣe àwọn ìlérí mímọ́ sí Ọlọ́run a sì gba àwọn ìlànà mímọ́ tí ó múra wa sílẹ̀ láti gbé ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrìbọmi àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ lẹ́hin náà nínú tẹ́mpìlì, a tẹ̀síwájú nípa ọ̀nà àwọn májẹ̀mú tí yóò tọ́ wa padà sọ́dọ̀ Rẹ̀.
Pẹ̀lú àwọn ọwọ́ gbígbé lé orí wa, a ngba àwọn ìbùkún oyè-àlùfáà bákannáà, pẹ̀lú ìdarí, ìtùnú, ìmọ̀ràn, ìwòsàn, àti agbára láti tẹ̀lé Jésù Krístì. Ní gbogbo ayé mi mo ti ní ìbùkún nípasẹ̀ agbára nlá yi. Bí a ti fi hàn nínú ìwé mímọ́, a tọ́ka sí i bí agbára Oyè Àlùfáà mímọ́ ti Melchizedek.
Ní ìgbà èwe mi, mo jèrè ọ̀wọ̀ nlá fún agbára yìí, ní pàtàkì bí ó ṣe hàn nínú àwọn ìbùkún oyè àlùfáà. Nígbàtí mò nsìn bí iránṣẹ́ ìhìnrere ní Chile, ojúgbà mi àti èmi ni a fi òfin mú tí a sì pín-níyà. A kò sọ ìdí rẹ̀ fún wa rárá. Ó jẹ́ àkókò rúkèrúdò nlá kan ti òṣèlú. Ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn ni àwọn ọlọ́pa ológun mú sí àhámọ́ tí a kò sì gbúro wọn mọ́ rárá.
Lẹ́hìn tí wọ́n ti fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò, mo dá jóko ní àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n kan, láìmọ̀ bóyá màá tún rí àwọn olólùfẹ́ mi mọ́. Mo yípadà sí Bàbá mi Ọ̀run, ní bíbẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìtara: “Baba a ti kọ́ mi nígbà gbogbo pé Ẹ̀yin nṣe ìṣọ́ lórí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere Yín. Jọ̀wọ́ Baba, èmi kii ṣe nkànkan pataki, ṣùgbọ́n mo ti gbọràn mo sì nílò ìrànlọ́wọ́ Rẹ ní alẹ́ òní.”
Àwọn èso ìrànlọ́wọ́ yi ni a ti gbìn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn. Lẹ́hìn ìribọmi mi, wọ́n fẹsẹ̀ mi múlẹ̀ bí ọmọ ìjọ a sì fúnmi ní ẹ̀bùn Ẹmí Mímọ́. Bí mo ṣe ngbàdúrà, èmi nìkan, lẹ́hìn àwọn àhámọ́, Ẹ̀mí Mímọ́ tọ̀ mí wá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sì tù mí nínú. Ó mú àyọkà kan pàtó wá sí ọkàn mi láti inú ìbùkún babanlá mi, èyí tí ó jẹ́ ìbùkún míràn ti oyè àlùfáà. Nínú rẹ̀, Ọlọ́run ṣèlérí fún mi pé nípasẹ̀ ìṣòtítọ́ mi èmi yíò lè jẹ́ fífi èdìdì dì nínú tẹ́mpìlì fún àkókò àti ayérayé sí obìnrin kan tí ó kún fún ẹ̀wà àti ìwà rere àti ìfẹ́, pé a ó di òbí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí wọ́n ṣe iyebíye, àti pé èmi ó di alábùkún fún a ó sì gbé mi ga bí baba ní Ísráelì.
Àwọn ọ̀rọ̀ onímísí wọ̀nyí nípa ọjọ́ ọ̀la mi kún ọkàn mi pẹ̀lú àlàáfíà. Mo mọ̀ pé wọ́n ti wá láti ọ̀dọ̀ olùfẹ́ni Baba mi Ọ̀run, ẹnití npa àwọn ìlérí Rẹ̀ mọ́ nígbà gbogbo. Ní àkókò náà, mo ní ìdánilójú pé èmi ó jẹ́ dídásílẹ̀ èmi ó sì wà láàyè láti rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí wọ̀nyí.
Ní ìwọ̀n bí ọdún kan lẹ́hìn náà, Bàbá Ọ̀run bùkún mi pẹ̀lú aya kan ẹnití ó kún fún ẹwà àti ìwà rere àti ìfẹ́. Lynette àti èmi di sísopọ̀ ni tẹ́mpìlì. A bùkún wa pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ iyebíye àti àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin tí wọ́n jẹ́ iyebíye. Mo di baba, gbogbo rẹ̀ ní ìbámu sí àwọn ìlérí Ọlọ́run nínú ìbùkún babanlá tí mo gbà bí ọmọdékùnrin ẹni ọdún-mẹ́tàdínlógún kan.
“Nítorínáà, ẹ̀yin arákùnrin mi olùfẹ̀ [àtì arábìrin], njẹ́ àwọn iṣẹ́ ìyanu ti dáwọ́dúró nítorípé Kristi ti gòkè lọ sí ọ̀run bi? …
“… Rárá; bẹ̃ni àwọn ángẹ́lì kò dáwọ́dúró láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ọmọ ènìyan.”
Mó jẹ́ri pé àwọn iṣẹ́ ìyanu àti àwọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ ntẹ̀síwájú lọ nínú ìgbésí ayé wa, nígbàkugbà bí àbájáde tààrà ti agbára oyè-àlùfáà. Díẹ̀ nínu àwọn ìbùkún oyè-àlùfáà njẹ́ mímúṣẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ní àwọn ọ̀nà tí a lè rí àti tí a le ní òye rẹ̀. Àwọn míràn njẹ́ fífihàn díẹ̀díẹ̀ a kì yíò sì dá wọ́n mọ̀ ní kíkún ní ayé yi. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run npa gbogbo àwọn ìlérí Rẹ̀ mọ́, nígbà gbogbo, bí a ti ṣe júwe rẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ yìí láti inú ìtàn ẹbí wa:
Baba baba mi, Grant Reese Bowen jẹ́ ọkùnrin onígbàgbọ́ nlá. Mo rántí dáadáa tí mo gbọ́ tí ó nròyìn bí òun ṣe gba ìbùkún babanlá tirẹ̀. Nínú ìwé ìròhìn rẹ̀, ó ṣe àkọ̀sílẹ̀ pé: “Babanlá ṣèlérí ẹ̀bùn ìwòsàn fún mi. Ó ní: ‘Àwọn aláìsàn ni a ó wòsàn. Bẹ́ẹ̀ni, àwọn òkú ni a ó jí dìde lábẹ́ awọn ọwọ́ rẹ.’”
Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́hìn náà, Baba àgbà nkó koríko jọ nígbà tó ní ìmọ̀lára ìṣílétí láti padà sílé. Ó pàdé baba rẹ̀ tí ó nbọ̀ níwájú rẹ̀. “Grant, ìyá rẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá lọ,” ni baba rẹ̀ sọ.
Mo ṣe àyọsọ lẹ́ẹ̀kansíi láti inú ìwé ìròhìn Baba-àgbà pé: “èmi kò dúró ṣùgbọ́n mo lọ ní ìkánjú sí inú ilé mo sì jáde sí ìloro iwájú níbi tó dùbúlẹ̀ sí lórí àkéte kan. Mo wò ó mo sì ríi pé kò sí àmì wíwàláàyè kankan nínú rẹ̀ mọ́. Mo rántí ìbùkún babanlá mi àti ìlérí pé bí mo bá jẹ́ olootọọ, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ mi a ó mú àwọn aláìsàn lára dá; a ó sì jí àwọn òkú dìde. Mo gbe àwọn ọwọ́ mi le ori rẹ, mo si sọ fun Oluwa pe bí ileri tí O ṣe fun mi nípasẹ̀ babanlá náà ba jẹ otitọ, lati jẹ ki o farahàn ni àkókò yii ki o si gbe iya mi dide padà sí ayé. Mo ṣèlérí fún Un bí Òun bá ṣe èyí, èmi kò gbọ́dọ̀ lọ́tìkọ̀ rárá láti ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní agbára mi fún gbígbé ìjọba Rẹ̀ ga. Bí mo ṣe gbàdúrà, ó la ojú rẹ̀ ó sì wí pé, ‘Grant, gbé mi dìde. Mo ti wa ninu Aye Ẹmi, ṣugbọn iwọ ti pe mi pada. Jẹ́ kí èyí jẹ́ ẹ̀rí nígbàgbogbo fún ẹ̀yin àti fún àwọn ìyókù ìdílé mi.”
Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ wa láti lépa àti láti retí àwọn iṣẹ́ ìyanu. Mo jẹ́rí pé nítorípé a ti mú oyè àlùfáà padàbọ̀sípò, agbára àti àṣẹ Ọlọ́run wà lórí ilẹ̀ ayé. Nípasẹ̀ àwọn ìpè àti àwọn ìgbìmọ̀, àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin, ọ̀dọ́ àti àgbà, lè kópa nínú iṣẹ́ oyè àlùfáà. O jẹ iṣẹ ti àwọn iṣẹ́ ìyanu ni, tí nṣe nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì. O jẹ iṣẹ ti ọ̀run, o si nbukun gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun.
Ní 1989, ìdílé wa tó jẹ́ ẹni méje npadà bọ̀ láti òde wọ́ọ̀dù kan. Ó ti pẹ́. Lynette nretí ọmọ wa kẹfà. Ó ní ìṣílétí tó lágbára láti de ìgbànú ìjókó rẹ̀, èyítí ó ti gbàgbé láti ṣe. Láìpẹ́ lẹ́hìnnáà a dé ọ̀nà tó tẹ̀ ni òpópónà; ọkọ kan sọdá ila sinu ọna wa. A nlọ ní nkan bí àádọ́rin máìlì [112] kìlómítà [112] ní wákàtí kan, mo yí ọwọ́ láti yẹra fún kíkọlu ọkọ̀ tó nbọ̀. Ọkọ̀ wa yípo, ó fò sọ̀kalẹ̀ ọ̀nàgíga náà, ó sì yọ̀ kúrò ní ojú ọ̀nà nígbẹhìn ó wá sí ìdúró, ó balẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbẹ́ èrò sinú ìdọ̀tí.
Ohun tó tẹ̀le tí mo ràntí gbígbọ́ ni ohùn Lynette: “Shayne, a nílò láti gba ẹnu-ọ̀nà rẹ jáde.” Mo di sísorọ̀ nínú afẹ́fẹ́ nípasẹ̀ ìgbánú ìjòkó mi. Ó gba ìṣẹ́jú díẹ̀ láti le ronú. A bẹ̀rẹ̀sí gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ jáde kúrò nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà gba ojú fèrèsé mi, èyí tó jẹ́ òrùlé ọkọ̀ náà báyìí. Wọ́n nsọkún, wọ́n ní ìyàlẹ́nu ohun tó ṣẹlẹ̀.
Kò pẹ́ tí a fi ríi pé ọmọbìnrin wa ẹni ọdún mẹ́wa, Emily, ti sọnù. A kígbe orúkọ rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí èsì. Àwọn ọmọ ijọ wọ́ọ̀dù, tí wọ́n nrin ìrìn-àjò lọ sí ilé bákannáà, wà ní ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà wọ́n nfi ìtara wá a kiri. Òkùnkùn ṣú gidi. Mo wo inú ọkọ̀ náà lẹ́ẹ̀kansíi pẹ̀lú iná ìléwọ́ àti sí ìbàlẹ́rù mi, mo ríi pé ara kékeré Emily wà ní idẹkùn lábẹ́ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà. Mo kígbe sókè pẹ̀lú ìtara, “A ní láti gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kúrò lórí Emily.” Mo di òrùlé náà mú mo sì fàá sẹ́hìn. Àwọn díẹ̀ miran nìkan ni wọ́n ngbé e, ṣùgbọ́n ọkọ̀ náà lọ́nà ìyanu ṣí sórí àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ̀, tí ó nfi ara àìlèmí Emily hàn.
Emily kò mí. Ojú rẹ̀ jẹ́ ti àwọ̀ pọ́pù ìyeyè. Mo sọ pé, “A nílò láti fún un ní ìbùkún kan.” Ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n kan àti ọmọ-ijọ ní wọ́ọ̀dù kúnlẹ̀ pẹ̀lú mi àti nípa àṣẹ Oyè Àlùfáà ti Mẹlikisẹdẹki, ní orúkọ Jésù Krístì, a pàṣẹ fún un láti wà láàyè. Ní àkókò náà, Emily mí èémí gígùn kan.
Lẹ́hìn ohun tí ó dàbí àwọn wákàtí, ọkọ̀ aláìsàn dé nígbẹ̀hìn. Wọ́n gbé Emily lọ sí ilé ìwòsàn. Ó ní àìlera ẹ̀dọ̀fóró àti ike ẹran yíya ní orókún rẹ̀. Ìbàjẹ́ sí ọpọlọ jẹ́ àníyàn nítorí àkókò tí ó ti wà láìsí atẹ́gùn. Emily wà ní kómà fún ọjọ́ kan àti ààbọ́. A tẹ̀síwájú láti máa gbàdúrà àti láti gbàwẹ̀ fún un. A bùkún fún un pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmúláradá. Lóni, Emily àti ọkọ rẹ̀, Kevin, jẹ́ òbí àwọn ọmọbìrin mẹ́fà.
Lọ́nà ìyanu, gbogbo àwọn yòókù lè rìn lọ. Ọmọ tí Lynette ngbé ni Tyson. Òun pẹ̀lú kò ní ìpalára kankan wọ́n sì bí i nínú Oṣù Kejì tó tẹ̀le. Ní oṣù mẹ́jọ lẹ́hìn náà, lẹ́hìn gbígba ara ti ayé rẹ, Tyson padà sílé sọ́dọ̀ Bàbá wa Ọ̀run. Òun ni ọmọ ángẹ́lì olùtọ́jú wa. A ní ìmọ̀lára ipa rẹ̀ nínú ẹbí wa a sì nretí láti wà pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi.
Àwọn tí wọ́n gbé ọkọ̀ ẹrù náà kúrò lórí Emily ṣe àkíyèsí pé ọkọ̀ ẹrù náà dàbí ẹnipé kò ní ìwọ̀n kànkan. Mo mọ̀ pé àwọn ángẹ́lì ọ̀run ti dara pọ̀ mọ́ àwọn ángẹ́lì ti ilẹ̀ ayé láti gbé ọkọ̀ ẹrù náà kúrò lórí Emily. Mo mọ̀ bákannáà pé Emily di mímú padà wá sí ìyè nípa agbára oyè àlùfáà mímọ́.
Olúwa fi òtítọ́ yìí hàn fún àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀: “Nítorí èmi yíò lọ niwaju ìwò ojú yín. Èmi yíó wà ní ọwọ́ ọ̀tún yín àti ní ọwọ́ òsì, Ẹ̀mí mi yíó sì wà nínú ọkàn yín, àwọn ángẹ́lì mi yío rọ̀gbà yíi yín ká, láti gbée yín sókè.”
Mo jẹ́rìí pé “Oyè Àlùfáà Mímọ́, ní àtẹ̀lé Ètò ti Ọmọ Ọlọ́run”Oyè Àlùfáà ti Melkisedeki—pẹ̀lú àwọn kọ́kọ́rọ́, àṣẹ, àti agbára rẹ̀ ni a ti mú padà bọ̀ sípò sórí ilẹ̀ ayé, ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Mo mọ̀ pé nígbàtí kìí ṣe gbogbo àwọn ipò ni wọ́n nní àbájáde bí a ti lè nírètí àti gbàdúrà fún, àwọn iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run yóò wa nígbà gbogbo ní ìbámu sí ìfẹ́ Rẹ̀, àkókò Rẹ̀, àti ètò Rẹ̀ fún wa.
Tí ẹ bá ní ìfẹ́ inú fún àwọn ìbùkún ti oyèàlùfáà, pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti àwọn áńgẹ́lì, mo pè yín láti rìn ní ipa ọ̀nà àwọn májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti fi sí àrọ́wọ́tó fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Àwọn ọmọ-ìjọ àti àwọn olùdarí ti Ìjọ tí wọ́n fẹ́ràn yín yíò ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe ìgbésẹ̀ tí ó tẹ̀lé.
Mo jẹ́rí pé Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, ngbé, ó sì ndarí Ìjọ Rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlíì alààyè tí wọ́n di àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà mú tí wọ́n sì nlò wọ́n. Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ òtítọ́. Olùgbàlà fi ẹ̀mí Rẹ̀ lélẹ̀ láti wò wá sàn, láti gbà wá padà, àti láti mú wa wá sílé.
Mo jẹ́ri pé àwọn iṣẹ́ ìyanu ko tíì dáwọ́dúró, àwọn angẹ́lì wà láarín wa, àti pé àwọn ọ̀run ṣí sílẹ̀ ní tòótọ́. Àti pé ah, bí wọ́n ti ṣí sílẹ̀ tó! Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.