Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Ọ̀rọ̀ Ṣe Pàtàkì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


13:58

Àwọn Ọ̀rọ̀ Pọndandan

Àwọn ọ̀rọ̀ nfi ohùn sílẹ̀. Wọ́n nfi ohùn àwọn èrò, ìmọ̀lára, àti ìrírí, fún rere tàbí ibi wa hàn.

Ẹ̀yin arákùnrin, arábìnrin, àti ọ̀rẹ́ káàkiri ayé, mo ní ọlá láti bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn yí sọ̀rọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ ti Ìjọ wa àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ àti àwọn olùfetísílẹ̀ titun sí ìpàdé àpapọ̀ yí. Ẹ Káàbọ̀!

Àwọn ọ̀rọ̀ tí a ṣe àbápín láti orí pẹpẹ yí ni àwọn ọ̀rọ̀ ìbánisọ. A fúnni ní Èdè-òyìnbó tí a sì yírọ̀ rẹ̀ padà sí bíi ọgọrun àwọn èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nígbàgbogbo ìbẹ̀rẹ̀ náà jẹ́ ọ̀kannáà. Àwọn ọ̀rọ̀. Àti pé àwọn ọ̀rọ̀ ṣe pàtàkì gidi. Ẹ jẹ́ kí nsọ ìyẹn lẹ́ẹ̀kansi. Àwọn Ọ̀rọ̀ Ṣe Pàtàkì!

Wọ́n jẹ́ orísun bí a ti sopọ̀; wọ́n rọ́pò àwọn ìgbàgbọ́, ìwà, àti ìwòye wa. Nígbàmíràn a nsọ̀ àwọn ọ̀rọ̀, ìgbàmíràn à nfetísílẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ nfi ohùn sílẹ̀. Wọ́n nfi ohùn àwọn èrò, ìmọ̀lára, àti ìrírí, fún rere tàbí ibi wa hàn.

Láìdára, àwọn ọ̀rọ̀ lè jẹ́ àìlérò, ìyára, àti ìpalára. Tí a bá ti sọọ́, a kò lè mú wọn padà mọ́. Wọ́n lè ṣeniléṣe, fìyàjẹni, génisílẹ̀, àní kí ó sì dárí sí àwọn ìṣe pípanirun. Wọ́n lè nípa lé wa lórí gidigidi.

Ní ọ̀nà míràn, àwọn ọ̀rọ̀ le ṣàjọyọ̀ ìṣẹ́gun, kí ó nírètí kí ó sì gbani-níyànjú. Wọ́n lè ṣí wa létí láti tún inú rò, ṣe àtúnbẹ̀rẹ̀, kí a sì tún ìdarí ọ̀nà wa ṣẹ. Àwọn ọ̀rọ̀ lè ṣí iyè-inú wa sí òtítọ́.

Èyí ni ìdí, lákọ́kọ́ àti jíjùlọ, tí àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa fi ṣe pàtàkì.

Nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, wòlíì Almà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní Amẹ́ríkà àtijọ́ kojú ìjà àìlópin pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọn kò kà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí, tí wọ́n sé ọkàn wọn le, tí wọ́n sì ba ọ̀làjú wọn jẹ́. Bákannáà wọ́n wípé, “Àti nísisìyí, bí ìwãsù ọ̀rọ̀ nã ṣe ní ipa nlá láti darí àwọn ènìyàn nã sí ipa ṣíṣe èyítí ó tọ́—bẹ̃ni, ó ti ní agbára tí ó tobi jùlọ lórí ọkàn àwọn ènìyàn nã ju idà tàbí ohun míràn tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí nwọn rí—nítorínã Álmà rõ pé ó jẹ́ ohun tí ó tọ̀nà pé kí àwọn kí ó lo agbára tí ó wà nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”

Ọ̀rọ̀ “Ọlọ́run” kọjá gbogbo àwọn ìwò míràn. Ó ti rí bẹ́ẹ̀ látigbà ìṣẹ̀dá ayé nígbàtí Olúwa ti sọ̀rọ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wá: ìmọ́lẹ̀ sì wá.”

Láti ọ̀dọ̀ Olùgbàlà ni àwọn ìdánilójú inú Májẹ̀mú Titun wọ̀nyí ti wá: “Ọ̀run àti ayé yíò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi kò ní kọjá lọ.”

Àti èyí pé “Bí ẹnìkan bá fẹ́ràn mi, yíò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́: Baba mi yíò sì fẹ́ràn rẹ̀, àwa ó sì tọ̀ọ́ wá, a ó sì ṣe ibùgbé wa pẹ̀lú rẹ̀.”

Láti ẹnu Màríà, ìyá Jésù, ni ẹ̀rí ìrẹ̀lẹ̀ yí ti wá pé: “Kíyèsi ọmọ-ọdọ̀ ìránṣẹ́ Olúwa; kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ.”

Gbígbàgbọ́ àti gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yíò mú wá sún mọ́ Ọ si. Ààrẹ Russell M. Nelson ti ṣe ìlérí pé, “Bí ẹ bá ṣe àṣàrò àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, okun yín láti dà bíi Tirẹ̀ si yíò pọ̀si.”

Ṣe gbogbo wa kò fẹ́ jẹ́, bí orin náà ti wí pé , “bíbùkún àti mímọ́ síi—Olùgbàlà, bíi tìrẹ”?

Mo nwo àwòrán Joseph Smith lórí orókún rẹ̀ tí ó ngbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Baba Rẹ̀ ní Ọ̀run: “[Joseph,] Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ Tirẹ̀!”

A “ngbọ́ Tirẹ̀” nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́, ṣùgbọ́n ṣe à kàn njẹ́ kí wọ́n joko lásán lórí ojú-ewé ni, tàbí ṣe à ndamọ̀ pé Ó nsọ̀rọ̀ sí wa. Ṣé à nyípadà?

A “ngbọ́ Tirẹ̀” nínú ìfihàn ti araẹni àti ìṣílétí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, nínú ìdáhùn sí adúrà, àti àwọn àkokò wọnnì nígbàtí Jésù Krístì nìkan, nípasẹ̀ agbára Ètùtù Rẹ̀, lè gbé àjàgà wa sókè, fún wa ní ìdáríjì àti àláfíà, dì wá mú “nínú apá ìfẹ́ rẹ̀.”

Ìkejì, ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì ṣe pàtàkì.

Àwọn wòlíì jẹri nípa àtọ̀runwá Jésù Krístì. Wọ́n nkọni ní ìhìnrere Rẹ̀ wọ́n sì nfi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn fún gbogbo ènìyàn. Mo jẹ́ ẹ̀rí mi pé Wòlíì àlààye wa, Ààrẹ Russell M. Nelson, ngbọ́ ó sì nsọ ọ̀rọ̀ Olúwa.

Ààrẹ Nelson ní ọ̀nà kan pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀. Ó ti wípé, “Ẹ tẹramọ́ ipa-ọ̀nà májẹ̀mú,” “Ẹ kó Israẹ́lì jọ,” “Jẹ́kí Ọlọ́run borí,” “Ẹ gbé afára lílóye Ga,” “Ẹ Ṣọpẹ́,” “Ẹ mú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì Pọ̀si,” “Ẹ gba ipa ẹ̀rí yín,” àti “kí ẹ sì “Di onílàjà.”

Láípẹ́ jọjọ ó ti ní kí a “Ronú Sẹ̀lẹ́stíà.” “Nigbàtí ẹ bá ní ìdojúkọ pẹ̀lú wàhálà,” ó wípé,”ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà! Nígbàtí a bá dán yín wò nípasẹ̀ ìdánwò, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà! Nígbàtí ayé tàbí olùfẹ́ kan bá já yín kulẹ̀, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà! Nígbàtí ẹnìkan bá kú láìpé ọjọ́, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà. …Nígbàtí àwọn ẹrù ayé bá kórajọ lé yín lórí, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà! … Bí ẹ ti nronú sẹ̀lẹ́stíà, ọkàn yín yíò yípada díẹ̀díẹ̀, … ẹ ó rí àwọn àdánwò àti àtakò bí ìmọ́lẹ̀ titun, … [àti pé] ìgbàgbọ́ yín yíò pọ̀ si.”

“Nígbàtí a bá ronú sẹ̀lẹ́stíà, a ó rí àwọn ohun bí wọ́n ti wà lódodo àti bí wọn yíò ti wà lódodo.” Nínú ayé tí ó kún pẹ̀lú ìdàmú àti ìjà yí, gbogbo wa nílò ìwòye náà.

Alàgbà George Albert Smith, tipẹ́tipẹ́ ṣíwájú dída Ààrẹ Ìjọ, nsọ̀rọ̀ nípa ìmúdúró wòlíì tí wọ́n sì ngbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó wípé: “Ojúṣe tí a nṣe nígbàtí a bá gbé ọwọ́ wa sókè … ni ọ̀kan mímọ́ jùlọ. … Ó túmọ̀ sí … pé a ó dúró lẹ́hìn rẹ̀; a ó sì gbàdúrà fún un; … a ó sì tiraka láti gbé àwọn ìkọ́ni rẹ̀ jáde bí Olúwa ti darí.” Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, a ó ṣe ìṣe aápọn lórí àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì.

Bí ọ̀kan lára àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn mẹẹdogun tí a múdúró ní àná nípasẹ̀ Ìjọ wa àgbáyé, mo fẹ́ láti pín ọ̀kàn lára àwọn ìrírí mi nípa ìmúdúró wòlíì àti gbígba àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú yín. Ó dá bíi ti wòlíì Jákọ́bù fún mi, tí ó tunsọ pé, “Mo gbọ́ ohùn Olúwa tí ó nsọ̀rọ̀ sí mi ní ọ̀rọ̀ náà gan.”

Alàgbà àti Arábìnrin Rasband ní Thailand.

Oṣù Kẹwa tó kọjá ìyàwó mi, Melanie, àti èmi wà ní Bangkok, Thailand, bí mo ṣe nmúrasílẹ̀ láti ya èyí tí yíò jẹ́ tẹ́mpìlì marundinlaadọwa Ìjọ sí mímọ́. Fún mi, ìyànsíṣẹ́ náà jẹ́ méjèjì ìrẹ̀lẹ̀ àti àìlèrò. Èyí ni tẹ́mpìlì àkọ́kọ́ ní gúsù-ìlà òòrùn Asia Peninsula. Ó jẹ́ àwòrán títayọ—àkàbà mẹ́fà, ilé ipa ọ̀nà títẹ̀-mẹsan, “fírémù-bíbáramu” láti lò fun ilé Olúwa. Fún àwọn oṣù mo ti ngbèrò ìyàsímímọ́ náà. Ohun tí ó ti kalẹ̀ nínú ọkàn àti inú mi ni pé orílẹ̀-èdè àti tẹ́mpìlì ti jẹ́ jòjòló ní apá àwọn wòlíì àti àpóstélì. Ààrẹ Thomas S. Monson ti kéde tẹ́mpìlì àti pé Ààrẹ Nelson ni ó yàá símímọ́.

Tẹ́mpìlì Bangkok Thailand.

Mo ti múra àdúra ìyàsímímọ́ sílẹ̀ ní àwọn oṣù ṣíwájú. Àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ wọnnì ni a ti yípadà sí àwọn èdè méjìlá. A ti ṣetán. Tàbí bẹ́ẹ̀ ni mo rò.

Ní alẹ́ ṣíwájú ìyàsímímọ́ náà, a ta mí jí látinú oorun mi pẹ̀lú ìmọ̀lára àìbalẹ̀, kánmọ́kánmọ́ nípa àdúrà ìyàsímímọ́ náà. Mo gbìyànjú láti gbé ìṣílétí sẹgbẹ, ní ríronú pé àdúrà náà wà déédé. Ṣùgbọ́n Ẹ̀mí náà kò fi mí sílẹ̀. Mo ròó pé àwọn ọ̀rọ̀ kan pàtó sọnù, àti pé nípa àwòṣe ọ̀run wọ́n wá sọ́dọ̀ mi nínú ìfihàn, mo sì fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sínú àdúrà náà súnmọ́ ìparí rẹ̀: “Njẹ́ kí a ronú sẹ̀lẹ́stíà, ní jíjẹ́ kí Ẹ̀mí Rẹ borí nínú ayé wa, kí a sì tiraka láti jẹ́ onílàjà nígbàgbogbo.” Olúwa nrán mi létí láti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì alààyè wa: “Ronú Sẹ̀lẹ́stíà,” “ẹ jẹ́ kí Ẹ̀mí borí,” “ẹ tiraka láti jẹ́ onílàjà.” Àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì ṣe pàtàkì sí Olúwa

Ìkẹ́ta, tí ó sì ṣe pàtàkì gan, ni àwọn ọ̀rọ̀ ara wa. Gbà mí gbọ́, nínú ayé emoji-kíkún àwọn ọ̀rọ̀ wa ṣe pàtàkì.

Àwọn ọ̀rọ̀ wa lè tini lẹ́hìn tàbí bíni nínú, jẹ́ aláyọ̀ tàbí àìnílárí, aláánú tàbí jíjú sẹgbẹ. Nínú ìgbóná àkokò náà, àwọn ọ̀rọ̀ wa lè tàni kí ó sì wọnilára jìnlẹ̀ pẹ̀lú ìrora sínú ọkàn—kí ó sì dúró síbẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ wa lórí ayélujára, àtẹ̀jíṣẹ́, ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn, tàbí twíítì gba ayé ti ara wọn. Nítorínáà ẹ ṣe pẹ̀lẹ́ nípa ohun tí ẹ ó sọ àti bí ẹ ó ti sọ ọ́. Nínú àwọn ẹbí wa, nípàtàkì pẹ̀lú àwọn ọkọ, ìyàwó, àti àwọn ọmọ, àwọn ọ̀rọ̀ wa lè mú wa wá papọ̀ tabí fi ìdènà sí àárín wa.

Ẹ jẹ́ kí ndá àbá gbólóhùn-ọ̀rọ jẹ́jẹ́ mẹta tí a lè lò láti mú ìtani kúrò nínú àwọn ìṣòro àti ìyàtọ̀, gbéga, kí a sì tún ara wa dálójú:

“Ẹ ṣé.”

“Má bínú.”

Àti “nífẹ́ rẹ.”

Ẹ máṣe fi àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí pamọ́ fún ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tàbí àjálù. Lò wọ́n léraléra àti pẹ̀lú òdodo, nítorí wọ́n nfi ìkàsí fún àwọn ẹlòmíràn hàn. Ọ̀rọ̀ ndàgbà ní pọ́ọ́kú; kò sì tẹ̀lé àwòṣe náà.

A lè wípé “ẹ sé” lórí àtẹ̀gùn, nínú ibùdókọ̀, ní ọjà, ní ibi iṣẹ́, ní orí ìlà, tàbí pẹ̀lú àwọn aladugbo tàbí ọ̀rẹ́. A lè wípé “mo káánú” nígbàtí a bá ṣe àṣìṣe, pàdánù ìpàdé, gbàgbé ọjọ́-ìbí, tàbí rí ẹnìkan nínú ìrora. A lè wípé “mo nifẹ rẹ” àti pé àwọn ọ̀rọ̀ náà gbé ìtumọ̀ “mo nronú nípa rẹ,” “mo ní ìkẹ́ fún ọ ,” “mo wà nihin fún ọ,” tàbí “Ìwọ jẹ́ ohun gbogbo sí mi.”

Ẹ jẹ́ ki nṣe àbápín àpẹrẹ araẹni kan. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ ṣọ́ra. Ẹ̀yin arábìnrin, èyí yíò ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú. Ṣíwájú ìyànsíṣẹ́ ìgbà kíkún mi nínú Ìjọ, mo rin ìrìn-àjò káàkiri fún ilé-iṣẹ́ mi. Mo ti lọ fún oye àkokò jíjìnnà jùlọ ní àgbáyé. Ní òpin ọjọ́ mi, ibi èyíówù kí nwà, mo máa nfi ìgbàgbogbo pe ilé. Nígbàtí ìyàwó mi, Melanie, bá mú fóònù tí mo sì dáhùn, ìbárasọ̀rọ̀ wa nígbàgbogbo máa ndarí sí sísọpé “mo nifẹ rẹ.” Ní ojojúmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì nsìn bí ìdákòro sí ọkàn mi àti ìṣe mi; wọ́n jẹ́ ààbò sí mi látinú àwọn àwòrán ibi. “Melanie, mo nífẹ́ rẹ” sọ̀rọ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé iyebiye ní àárin wa.

Ààrẹ Thomas S. Monson máa nwípé, “Kò sí ẹsẹ̀ láti dúró déédé, ọwọ́ láti dìmú, inú láti gbàníyànju, ọkàn láti mísí, àti ẹ̀mí láti gbàlà.” Wípé “ẹ ṣeun,” “mo káàánú,” “mo ní ìfẹ́ yín” yíò ṣe ìyẹn.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, àwọn ọ̀rọ̀ ṣe pàtàkì.

Mo ṣe ìlérí pé bí a bá “ṣe àpèjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì” pé yíò darí lọ sí ìgbàlà, àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì wa tí ó ntọ́sọ́nà tí ó sì ngbà wá níyànjú, àti àwọn ọ̀rọ̀ ara wa tí ó nsọ nípa ẹni tí a jẹ́ àti ohun tí ó ṣe pàtàkì sí wa, tí àwọn agbára ọ̀run yíò dà sílẹ̀ lé wa lórí. “Àwọn ọ̀rọ̀ Krístì yíò sọ fún yín gbogbo àwọn ohun èyí tí ó yẹ kí ẹ ṣe.” Àwa ni àwọn ọmọ Rẹ̀ Òun sì ni Ọlọ́run wa, Ó sì nretí wa láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú “ahọ́n àwọn ángẹ́lì” nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.

Mo fẹ́ràn Olúwa Jésù Krístì. Òun ni, ní àwọn ọ̀rọ wòlíì Isaiah Májẹ̀mú Láéláé, “Oníyanu, Alámọ̀ràn, Ọlọ́run alágbára, Baba ayérayé, Ọba Àláfíà.” Àti bí Àpóstélì Jòhánnù ti mu hàn kedere, Krístì Fúnrarẹ̀ ni “Ọ̀rọ̀ náà.”

Nípa èyí ni mo jẹ́ ẹ̀rí bí Àpóstélì kan tí a pè sí iṣẹ́-ìsìn àtọ̀runwá Olúwa—láti kéde ọ̀rọ̀ Rẹ̀—àti tí a pè láti dúró bi ẹlẹri pàtàkì Rẹ̀. Ní orúkọ mímọ́ ti Olúwa Jésù Krístì, àmín.