Ìsopọ̀ Àwọn Òfin Nlá Méjì
Okun wa láti tẹ̀lé Jésù Krístì dá lórí agbára wa láti gbé àwọn òfin àkọ́kọ́ àti ìkejì pẹ̀lú ìfọkànsìn ìbámu àti ìdọ́gba sí méjèjì.
Ọ̀rọ̀-ìṣíwájú
Bí Lésà àti èmi ti nrin ìrìnàjò lórí ìyànni-síṣẹ́ káàkiri ayé, a rí adùn nínú ànfàní ìpàdé pẹ̀lú yín nínú àwọn agbo ìjọ nlá àti kékeré. Ìfọkànsìn yín sí iṣẹ́ Olúwa mú wa tají ó sì dúró bí ẹ̀rí kan sí ìhìnrere Jésù Krístì. A padà sílé láti ìrìn-àjò kọ̀ọ̀kan ní ìyàlẹ́nu bí ó bá ṣeéṣe kí a fúnni ní ọ̀pọ̀ bí a ti gbà á.
Nígbà tí a bá nrin ìrìn-àjò, àkokò díẹ̀ ni ó wà fún nínọjú. Bákannáà, nígbàtí ó bá ṣeéṣe, mo nlo àkokò díẹ̀ nínú ìwà kan ní pàtàkì. Mo nífẹ́sí ilékíkọ́ àti yíyàwòrán àti ìfanimọ́ra pàtàkì pẹ̀lú àwọn afárá. Àwọn afárá ìdádúró yà mí lẹ́nu. Bóyá ó jẹ́ afárá Òṣùmàrè ní Tokyo, Afárá Tsing Ma ní Hong Kong, Afárá Ilé-ìṣọ́ ní London, tàbí àwọn míràn tí mo ti rí, èmi kò lè ṣèrànwọ́ ṣùgbọ́n ní ìyàlẹ́nu nípa ìkọ́lé amòye iṣẹ́ ẹ̀rọ nínú àwọn ìrújú ilé-kíkọ́ wọ̀nyí. Àwọn afárá nmú wa lọ sí àwọn ibi tí a kìbá ti ní lè lọ. (Ṣíwájú kí ntó tẹ̀síwájú, mo kíyèsi pé látìgbà tí mo ti múra ọ̀rọ̀ yí sílẹ̀, ìjàmbá olóró afárá kan ti ṣẹlẹ̀ ní Baltimore. A ṣọ̀fọ̀ àdánù ìyè a si fúnni ní àwọn ikaanu sí àwọn ẹbí tí a palára.)
Afárá Ìdádúró Títóbi Kan
Láìpẹ́, ìyànsíṣẹ́ ìpàdé àpapọ̀ kan gbé mi lọ sí California, níbití mo ti bá Afárá Ilẹ̀kùn Onídẹ alámì kan pàdé lẹ́ẹ̀kansi, tí a kàsí bí iṣẹ́ ẹ̀rọ ìyanu ti ayé. Ohun ìrántí yí wọnuara ní àwòrán ẹlẹ́wà, èrèdí iṣẹ́, àti ọlọ́gbọ́n ọ̀gá iṣẹ́ ẹ̀rọ. Ó jẹ́ afárá ìdádúró ẹlẹ́gbẹgbẹ́ pẹ̀lú iparí àwọn ilé-ìṣọ́, tí a tìlẹ́hìn nípa afára títóbi yíyọ sínú omi. Ìwọn títóbi, ọlọ́lá tí ó ní ilé-ìṣọ́ méji fífò lókè òkun ni àwọn ohun èlò àkọ́kọ́ láti jẹ́ kíkọ́. Lápapọ̀ wọ́n gbé ẹrù gbígbà àwọn ẹ̀wọ̀n ìdádúró gan an àti ẹ̀wọ̀n ìnàró ìdádúró, èyí tí ó lọ lọ̀nà ìsàlẹ̀. Okun dídùrò àràọ̀tọ̀ náà—agbára ilé-ìṣọ̀—ni idán lẹ́hìn iṣẹ́ ẹ̀rọ̀ afárá.
Títètè kọ́ àwọn àwòrán afárá náà jẹ́ ẹ̀rí nípa ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ yí. Ohun èlò afárá kọ̀ọ̀kan nrí àtìlẹhìn gbígbé-ìwọ̀n látinú ìṣedéédé ilé-ìṣọ́, méjèèjì ní ìsopọ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé sí ara wọn.
Nígbàtí afárá náà parí, pẹ̀lú ilé-ìṣọ́ méjì alágbára dídúró gbọingbọin ti wà, àti ìdákòró afárá tí ó yọ sínú omi nínú ìpìnlẹ̀ orísun, ni àwòrán okun àti ẹwà.
Ní òní mo pè yín láti wo afára daindain yí, pẹ̀lú àwọn ilé-ìṣọ́ fífò rẹ̀ méjì tí a kọ́ lórí ìpìnlẹ̀ alágbára—nípasẹ̀ àwọn jígí ìhìnrere.
Ní àfẹ̀mọ́jú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Jésù Krístì, nígbà ohun tí a pè ní Ọ̀sẹ̀ Rere nísisìyí, Farisí kan tí ó jẹ́ amòfin bèèrè ìbèèrè kan lọ́wọ́ Olùgbàlà tí òun mọ̀ pé kò ní fẹ́rẹ̀ ṣeéṣe láti dáhùn: “Olùkọ́ni, èwo ni àṣẹ nlá jùlọ nínú òfin?” Amòfin náà, “ndan an wò” ó sì nwá ìdáhùn olófin, pẹ̀lú èrò-inú dídàbí ẹ̀tàn, ó gba ìfèsì òtítọ́, ọ̀wọ̀, mímọ́, àtọ̀runwá.
“Jésù wí fún un pé, Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ.
“Èyí ni èkínní àti òfin ńlá.“ Fífetísílẹ̀ sí ìfiwé afára wa, ilé-ìṣọ́ àkọ́kọ́!
“Èkejì sì dàbíi rẹ̀, Ìwọ yíò fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.” Èyí ni ilé-ìṣọ́ kejì!
“Nínú àwọn òfin méjèjì yí ni gbogbo òfin àti wòlíì rọ̀ mọ́.” Àwọn ohun èlò tókù nípa afárá!
Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn òfin nlá méjì wò, tí a fihàn tí a sì sọọ nínú ìfèsì Jésù Krístì. Bí ẹ ti nṣe bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí àwòrán ìdádúró afárá títóbijùlọ, pẹ̀lú ilé-ìṣọ́ dídúró rẹ̀ ní fífò síwájú ọ̀run, jáde nínú iyè-inú ojú yín.
Ẹ Fẹ́ràn Olúwa
Àkọ́kọ́, láti fẹ́ràn Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn, ẹ̀mí, àti inú yín.
Nínú ìdáhùn yí, Jésù Krístì ṣe ìdìpọ̀ àkójá òfin tí ó wàpapọ̀ nínú àwọn ìkọ́ni mímọ́ Májẹ̀mú Láéláé. Láti fẹ́ràn Olúwa lakọkọ dá lórí ọkàn yín—ìwàẹ̀dá yín gan. Olúwa nígbánáà ní kí ẹ fẹ́ràn pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí yín—gbogbo ìyàsọ́tọ̀ ìwà-láàyè yín—àti ní òpin, láti fẹ́ràn pẹ̀lú gbogbo inú yín—òyè àti ẹ̀kọ́ yín. Ìfẹ́ fún Ọlọ́run kò dínkù tàbí lópin. Ó jẹ́ àìlópin àti ayérayé.
Fún mi, ìlò òfin nlá àkọ̀kọ̀ nígbàmíràn lè dàbí ìmúkúrò, àní dídẹ́rùbani. Pẹ́lú ọpẹ́, bí mo ti nyẹ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù wò síwájú síi, òfin yí ndi dídìmú púpọ̀ síi: “Bí ẹ bá fẹ́ran mi, ẹ pa òfin mi mọ́.” Mo lè ṣe èyí. Mo lè fẹ́ràn Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì, èyí tí yíò darí sí àdúrà, àṣàrò ìwé mímọ́, àti ìjọ́sìn tẹ́mpìlì nígbànáà. A fẹ́ràn Baba àti Ọmọ nípasẹ̀ sísan idamẹwa, pípa Ọjọ́-ìsinmi mọ́ ní mímọ́, gbígbé ìgbésí ayé ìwàrere àti ìwàmímọ́, àti jíjẹ́ olùgbọ́ran.
Fífẹ́ràn Olúwa ni à nṣe òdiwọ̀n rẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìṣe kékèké ojojúmọ́, àwọn ìṣísẹ̀ lórí ipa-ọ̀nà májẹ̀mú: fún àwọn ọ̀dọ́, lílo ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn láti gbéniga sànju kí a rẹnisílẹ̀; fífi ibi ayẹyẹ sílẹ̀, ìwòràn, tàbí iṣeré níbití àwọn òṣùwọ̀n ti lè ní ìpénijà; fífi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn ohun mímọ́.
Yẹ àpẹrẹ jẹ́jẹ́ yí wò. Ó jẹ́ Ọjọ́-ìsinmi àwẹ̀ bí Vance àti èmí ti kan ìlẹ̀kùn, ilé kékeré, ìrẹ̀lẹ̀ wọn. Àwa àti àwọn díákónì míràn nínú iyeju ti nretí àwọn ọ̀rọ̀, “Jọ̀wọ́ wọlé,” igbe pẹ̀lú ìyári nínú èdè Germani tó nípọn tó láti gbọ́ nínú ilẹ̀kùn. Arábìnrin Muellar ni ọ̀kan lára àwọn opó olùṣílọ nínú wọ́ọ̀dù. Kò lè dáhùn lẹ́nu ọ̀nà dáradára, bí ó ti jẹ́ afọ́jú níti òfin. Gbígbẹ́sẹ̀ wọ ilé tí ó dúdú díẹ̀, ó kí wa pẹ̀lú irú ìbèèrè pé: kíni àwọn orúkọ yín? Báwo ni ẹ ṣe wà? Ṣé ẹ fẹ́ràn Olúwa? A dáhùn a sì ṣe àbápín pé a wá láti gba ọrẹ àwẹ̀ rẹ. Àní ní ọjọ orí ọ̀dọ́ wa, àwọn ipò kékeré rẹ̀ hàn dáadáa, ìfèsì rẹ̀ sì kún fún ìgbàgbọ́ tí ó wọnilára jinlẹ̀jinlẹ̀: “Mo fi dáìmù kan le orí káúntà ṣíwájú ní òwúrọ̀ yí. Mo dúpẹ́ gan láti fúnni ní ọ̀rẹ àwẹ̀ mi. Ṣé ẹ̀yin ó ní inúrere tó láti gbé e sínú àpò-ìwé kí nsì kọ ìwé ìjẹ́wọ́ àwẹ̀ ọrẹ mi jáde?” Ìfẹ́ rẹ̀ nípa Olúwa gbé ìgbàgbọ́ wa sókè ní ìgbà kọ̀ọ̀kan tí a bá fi ilé rẹ̀ sílẹ̀.
Ọba Benjamin ṣe ìlérí agbára alámì fún àwọn wọnnì tí wọ́n bá tẹ̀lé òfin nlá àkọ́kọ́. “Èmi yío fẹ́ pé kí ẹyin ronú lórí ipò alábùkún-fún àti ìdùnnú ti àwọn wọnnì tí wọ́n pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. … Wọ́n di alábùkún-fún nínú ohun gbogbo, … àti pé bí wọ́n bá dìí mú lódodo dé òpin a ó gbà wọ́n sí ọ̀run … nínú ipò ìdùnnú àìlópin.”
Fífẹ́ràn Olúwa ndarí sí ìdùnnú ayérayé!
Ẹ Fẹ́ràn Àwọn Ọmọnìkejì Yín
Nígbànáà Jésù wípé,“Èkejì sì dàbíi rẹ̀, Ìwọ yíò fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.” Èyí ni ilé-ìṣọ́ kejì afárá.
Níhin Jésù nmú ìsopọ̀ tọ̀run gbé ìwò wa sókè, láti fẹ́ràn Olúwa, pẹ̀lú ìwò ìta ti ayé wa, láti fẹ́ràn ọmọnìkeji wa. Ọ̀kan ngbẹ́kẹ̀lé òmíràn. Ìfẹ́ Olúwa kò pé bí a bá pa àwọn ọmọlàkejì wa ti. Ìfẹ́ òde yí pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run láìsí ìkàsí sí lákọlábo, ẹgbẹ́ àwùjọ, ẹ̀yà, owó-oṣù, ọjọ́ orí, tàbí ẹlẹ́yàmẹ̀yà. À nwá àwọn wọnnì tí a palára tí a sì bàlọ́kànjẹ́ jáde, tí a rẹ̀sílẹ̀, nítorí “gbogbo ènìyàn jẹ̀ bákannáà sí Ọlọ́run.” A “ntu aláìlera nínú, gbé ọwọ́ èyítí ó rẹlẹ̀ sókè, kí a sì fún orókún àìlágbára lókun.”
Yẹ àpẹrẹ yí wò: Ó ya Arákùnrin Evans lẹ́nu nígbàtí ó gba ìṣílétí láti dá ọkọ̀ rẹ̀ dúró kí ó sì kan ìlẹ̀kùn àìmọ̀ ti ẹbí àìmọ̀ kan. Nígbàtí opo kan ìyá ọmọ mẹwa dáhùn lẹ́nu ìlẹ̀kùn, àwọn ipò líle wọn àti àìní nlá di híhàn kedere sí i. Èyí àkọ́kọ́ tí ó rọrùn, ọ̀dà fún ilé wọn, èyí tẹ̀lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọdún iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti-ara àti ti-ẹ̀mí sí ẹbí yí.
Ìyá ọlọ́pẹ́ yí lẹ́hìnnáà kọ nípa ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí a rán látọ̀rúnwá: “O ti lo ìgbé ayé rẹ ní nínawọ́ jáde sí èyí tí ó kéréjù lára wa. Bí èmi ìbá ti fẹ́ràn láti gbọ́ àwọn ohun tí Olúwa ní láti sọ sí yín bí Ó ti nfi ìmoore Rẹ̀ hàn fún rere tí ẹ ti ṣe níti-owó àti níti-ẹ̀mí, fún àwọn ènìyàn tí ẹ̀yin nìkan àti Òun yíò mọ̀ nípa rẹ̀ títíláé. Ẹ ṣé fún bíbùkún wa ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà, … fún àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere tí ẹ ti pèsè fún. … Nígbàkugbà ó nyà mi lẹ́nu bí Olúwa bá dá yín mú nìkan, tàbí bí ẹ bá kàn jẹ́ ẹnìkan tí ó nfetísílẹ̀.”
Láti fẹ́ràn ọmọlàkejì pẹ̀lú àwọn ìṣé ìnúrere àti iṣẹ́ ìsìn bíiti Krístì. Njẹ́ ẹ̀yin ó fi ìkùnsínú sílẹ̀, kí ẹ dáríji àwọn ọ̀tá, kí ẹ gbàmọ́ra kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ọmọlàkejì yín, kí ẹ sì ran àwọn àgbàlàgbà lọ́wọ́? Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yíò gba ìmísí bí ẹ ti ngbé ilé-ìṣọ́ ti ìfẹ́ yín ga fún ọmọlàkejì.
Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé: “Fífún àwọn ẹlòmíràn ní ìrànlọ́wọ́—ṣíṣe ìtiraka taratara láti tọ́jú àwọn ẹlòmíràn gan an tàbí jubí a ṣe ntọ́jú arawa—ni ayọ̀ wa. Nípàtàkì … nígbàtí kò bá rọrùn àti nígbàtí ó bá nmú wá kúrò ní ibi ìtura wa. Gbígbé òfin nlá kejì náà ni kókó dída ọmọẹ̀hìn òtítọ́ ti Jésù Krístì.”
Gbígbẹ́kẹ̀lé Kan
Jésù síwájú síi kọ́ni pé, “Nínú àwọn òfin méjèjì yí ni gbogbo òfin àti wòlíì rọ̀ mọ́.” Èyí jẹ́ ìkọ́ni gidi. Gbígbẹ́kẹ̀lé pàtàkì kàn wà ní àárín fífẹ́ràn Olúwa àti fífẹ́ràn ara wa. Fún Afára Ilẹ̀kùn Onídẹ láti ṣe iṣẹ́ tí a yàn fun, àwọn ilé-ìṣọ́ méjèjì níláti lágbára dọ́gbadọ́gba kí wọ́n sì gba ìwọn àwọn ẹ̀wọ̀n ìdádúró mọ́ra dọ́gbadọ́gba, ní ọ̀nà náà, àti àwọn arìnnà tí wọ́n nsọdá afárá. Láìsí ìdọ́gba iṣẹ́ ẹ̀rọ yí, afárá náà lè di ìdíbàjẹ́, àní tí yíò já sí wíwólulẹ̀. Fún ìdádúró afárá eyikeyi láti ṣe ohun tí a kọ fún láti ṣe, àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀ gbúdọ̀ ṣiṣẹ́ papọ̀ ní ìbámu pípé. Bákannáà, okun wa láti tẹ̀lé Jésù Krístì dá lórí agbára wa láti gbé àwọn òfin àkọ́kọ́ àti ìkejì pẹ̀lú ìfọkànsìn ìbámu àti ìdọ́gba sí méjèjì.
Ìjà tí ó npọ̀ si nínú ayé bákannáà dá àbá, pé àwa nígbámíràn nkùnà láti rí tàbí rántí èyí. Àwọn kan dojúkọ pípa àwọn òfin mọ́ gan tí wọ́n fi nfí ìfaradà díẹ̀ hàn sí àwọn wọnnì tí wọ́n rí bí aláìní òdodo tó. Ó le fún àwọn kan láti fẹ́ràn àwọn wọnnì tí wọ́n nyàn láti gbé ìgbé ayé níta májẹ̀mú tàbí àní jáde kúrò ní ìkópa ẹ̀sìn eyikeyi.
Ní ìdàkejì, àwọn kan wà tí wọ́n tẹnumọ́ pàtàkì fífẹ́ràn àwọn ẹlòmíràn láì damọ̀ pé gbogbo wa wà ní ìjíhìn sí Ọlọ́run. Àwọn kan kọ ìrò jálẹ̀jalẹ̀ pé irú ohun kan bíi òtítọ́ àìníye tàbí títọ́ àti àṣìṣe wà àti pé wọ́n gbàgbọ́ pé ohunkan tí a nílò ni ìfaradà pípé àti ìtẹ́wọ́gbà àṣàyàn ti àwọn ẹlòmíràn. Eyikeyi àwọn àìdọ́gba wọ̀nyí lè fa kí afárá ti-ẹ̀mí araẹni wa yí tàbí kí ó wó.
Ààrẹ Dallin H. Oaks júwe èyí nígbàtí ó wípé: “A pàláṣẹ fún wa láti fẹ́ràn gbogbo ènìyàn, níwọ̀n ìgbà tí òwe Jésù ti Ará Samáríà rere kọ́ni pé gbogbo ènìyàn ni ọmọnìkejì wa. Ṣùgbọ́n ìtara wa láti pa òfin kejì yi mọ́ kò gbúdọ̀ mú wa láti gbàgbé ti àkọ́kọ́, láti fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn, ẹ̀mí, àti inú wa.”
Ìparí.
Nítorínáà ìbèère náà fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ni, báwo ni a ó ṣe kọ́ afárá ìgbàgbọ́ àti ìfọ̀kànsìn ti ara wa—ní gbígbé àwọn ilé-ìṣọ́ afárá gíga ti fífẹ́ràn Ọlọ́run àti fífẹ́ràn ọmọnìkejì wa dúró? Ó dára, a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Àwọn ìtiraka ìṣaájú lè dàbí ètò lórí ẹ̀hìn aṣọ-ìnuwọ́ tàbí ipele ìṣíwájú àwòṣe ti afárá tí à nretí láti kọ́. Ó lè pẹ̀lú àwọn àfojúsùn díẹ̀ tí kò ṣeéṣe láti ní òye ìhìnrere Olúwa jù tàbí làti búra láti ṣe ìdájọ́ àwọn ẹlòmíràn ní ìdínkù. Kò sí ẹni tí ó kéré jù tàbí dàgbà jù láti bẹ̀rẹ̀.
Ní ìgbà díẹ̀, pẹ̀lú àdúrà àti ìṣètò elérò, à ntún àwọn èrò ṣe. Àwọn ìṣe titun ndi ìwà bánbákú. Àwọn àkọwò ó di àwòṣe títúnṣe. A nkọ́ afára ti ẹ̀mí araẹni wa pẹ̀lú ọkàn àti inú ìfọkànsìn sí Baba Ọ̀run àti Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Nìkànṣoṣo bákannáà sí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa pẹ̀lú ẹnití à nṣiṣẹ́, ṣeré, àti gbé pẹ̀lú.
Ní àwọn ọjọ́ iwájú, nígbàtí tí ẹ bá sọdá ìdádúró afárá ọlọ́lá kan tàbí àní nígbàtí ẹ bá rí àwòrán kan, pẹ̀lú àwọn ilé-ìṣọ́ tí ó ngòkè, mo pé yín láti rántí àwọn òfin nlá méjì, tí a júwe nípasẹ̀ Jésù Krístì nínú Májẹ́mú Titun. Njẹ́ kí àwọn ìkọ́ni Olúwa mísí wa. Njẹ́ kí ọkàn àti inú wa lé gbésóke síwájú láti fẹ́ràn Olúwa kí a sì yí síta láti fẹ́ràn aladúgbo wa.
Njẹ́ kí èyí fún ìgbàgbọ́ wa lókun nínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀, nípa èyí tí mo jẹri ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.