Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Gbé Jésù Krístì Olúwa Wọ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Ẹ Gbé Jésù Krístì Olúwa Wọ̀

Nípasẹ̀ bíbu ọlá fún awọn májẹ̀mú wa, a jẹ́kí ó ṣeéṣe fún Ọlọ́run láti tú ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn ìbùkún tí a ti ṣèlérí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú awọn májẹ̀mú wọnnì jáde.

Bí àwọn ọmọ mi méjì tí wọ́n kéré jùlọ ti ndàgbà, mo ṣe àwárí àwọn ìwé tí wọ́n dánilárayá tí wọ́n sì gba ìfọkànsí ẹni ṣùgbọ́n tó tún lo àwọn àmì ninu àwọn ìtàn wọn. Bí a ṣe nkàwé papọ̀ ní àwọn ìrọ̀lẹ́, mo fẹ́ràn ríran àwọn ọmọ mi lọ́wọ́ láti ní òye àwọn àmì ti onkọ̀wé nlò láti kọ́ni ní ìjìnlẹ̀ àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́, àní àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere.

Mo mọ̀ pé èyí nwọlé sínú ní ọjọ́ kan nígbàtí ọmọdékùnrin mi wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún ọ̀dọ́. Ó ti bẹ̀rẹ̀ ìwé titun kan ó sì fẹ́ gbádùn ìtàn náà, sùgbọ́n ọkàn rẹ̀ ngbìyànjú láti wá ìtumọ̀ jíjinlẹ̀ síi ninu gbogbo ohun tó nkà. Ó ti wá sú u, ṣùgbọ́n mo nrẹ́rin ní inú mi.

Jésù kọ́ni nípasẹ̀ àwọn ìtàn àti àwọn àmì—hóró mústádì láti kọ́ni ní agbára ìgbàgbọ́, àgùtàn tó sọnù láti kọ́ni bí àwọn ẹ̀mí ti níyelórí tó, ọmọ onínakúna láti kọ́ni ní ìhùwàsí Ọlọ́run. Àwọn òwe Rẹ̀ jẹ́ àwọn àmì nípasẹ̀ èyítí Ó le kọ́ni ní àwọn ẹ̀kọ́ jíjinlẹ̀ sí àwọn ẹnití wọ́n ni “etí láti gbọ́.” Ṣùgbọ́n àwọn tí wọn kò wá ìtumọ̀ jíjinlẹ̀ kò le ní òye, gẹ́gẹ́bi púpọ̀ àwọn tí wọ́n ka àwọn ìwé kannáà ti mo kà sí àwọn ọmọ mi kò ṣe mọ̀ pé àwọn ìtumọ̀ jíjinlẹ̀ àti púpọ̀ síi wà láti mú jáde ninu àwọn ìtàn wọ̀nyí.

Nígbàtí Ọlọ́run Baba fi Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Kanṣoṣo sílẹ̀ fún wa, Jésù Krístì Fúnra Rẹ̀ di àmì gígajùlọ ti ìfẹ́ tí kìí kú tí Baba wa ní Ọ̀run fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa. Jésù Krístì di Ọ̀dọ́-àgùntan Ọlọ́run.

A ní ànfààní àti ìbùkún ti pípè sí inú ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú kan pẹ̀lú Ọlọ́run, ninu èyítí ìgbésí ayé wa ti le di àmì májẹ̀mú náà. Àwọn májẹ̀mú nṣẹ̀dá irú ìbáṣepọ̀ tó nfi ààyè gba Ọlọ́run láti mọ wá kí Ó sì yí wa padà bí àkókò ti nlọ, kí ó sì gbé wa sókè láti dàbí Olùgbàlà síi, ní fífà wá súnmọ́ àti súnmọ́ Òun àti Baba síi áti nígbẹ̀hìn ki ó pèsè wa láti wọlé sí ọ̀dọ̀ wọn.

Ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó wá sórí ilẹ̀ ayé jẹ́ àyànfẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run. Nigbàtí a bá yàn láti jẹ́ apákan májẹ̀mú kan, ó nṣe ìgbé-lárugẹ ó sì nmú ìbáṣepọ̀ wa pẹlú Rẹ̀ jinlẹ̀ síi. Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé nígbàtí a bá yàn láti dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Rẹ̀ le di sísúnmọ́ púpọ̀ síi ju bí ó ti wà lọ ṣaáju májẹ̀mú wa, ó sì nmú kí ó ṣeéṣe fún Un láti bùkún wa pẹ̀lú èlé ìwọ̀n ìfẹ́ àti àánú Rẹ̀, ìfẹ́ onímájẹ̀mú ti a ntọ́kasí bíi hesed ni èdè Hébérù. Ipa-ọ̀nà májẹ̀mú wà nípa ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run—ìbáṣepọ̀ hesed wa pẹ̀lú Rẹ̀.

Baba wa nfẹ́ ìbáṣepọ̀ jíjinlẹ̀ síi pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Rẹ̀, ṣùgbọ́n ó jẹ́ àṣàyàn wa. Bí a ti nyàn láti fà súnmọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nípasẹ̀ májẹ̀mú ìbáṣepọ̀ kan, ó nfún Òun ní ààyè láti fà súnmọ́ wa síi kí ó sì bùkún wa ní kíkún síi.

Ọlọ́run ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ipò àti àwọn ojúṣe ti àwọn májẹ̀mú tí a dá. Nígbàtí a bá yàn láti wọ inú ìbáṣepọ̀ náà, a njẹ́rìí sí I nípasẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ bí àmì ti májẹ̀mú kọ̀ọ̀kan, pé a ṣetán láti tẹ̀lé àwọn ìlànà tí Ó ti gbé kalẹ̀. Nípasẹ̀ bíbu ọlá fún awọn májẹ̀mú wa, a jẹ́kí ó ṣeéṣe fún Ọlọ́run láti tú ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn ìbùkún tí a ti ṣèlérí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú awọn májẹ̀mú wọnnì, pẹ̀lú àlékún agbára láti yípadà kí a sì dàbí Olùgbàlà síi. Jésù Krístì wà ní ààrin gbùngbùn gbogbo àwọn májẹ̀mú ti a dá, àti pé àwọn ìbùkún májẹ̀mú ni a mú kí ó ṣeéṣe nítorí ìrúbọ ètùtù Rẹ̀.

Ìrìbọmi nípa rírì bọ omi ni àmì ẹnu ọ̀nà náà nípasẹ̀ èyítí a nwọlé sí inú ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run. Jíjẹ́ rírì bọ inú omi àti jíjáde padà jẹ́ bíi àmì ti ikú Olùgbàlà àti Àjínde sí ayé titun. Bí a ti njẹ́ rírì bọmi, a ṣe àmì kíkú a sì di àtúnbí sí inú ẹbí Krístì, a sì fihàn pé a ṣetán láti gba orúkọ Rẹ̀ sí ara wa. Àwa funra wa ṣe àpẹrẹ àmì májẹ̀mu náà. Ninu Májẹ̀mú Titun a kà pé, “Nítorí iye ẹ̀yin tí a ti rì bọmi sínú Krístì ti gbé Krístì wọ̀.” Pẹ̀lú ìrìbọmi wa a ti se àmì gbígbé Krístì wọ̀.

Ìlànà ounjẹ Olúwa bákannáà ntọ́ka sí Olùgbàlà. Búrẹ́dì àti omi náà jẹ́ àmì ẹran ara Krístì àti ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀ fún wa. Ẹ̀bùn ètùtù Rẹ̀ ni a nṣe àmì fífúnni rẹ̀ sí wa ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan nígbàtí olùdimú oyè àlùfáà kan, ní ṣíṣojú Olùgbàlà Funra Rẹ̀, bá nfún wa ni búrẹ́dì àti omi náà. Bí a ti nṣe ìgbésẹ̀ jíjẹ àti mímu àwọn àpẹrẹ ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀, Krístì nfi pẹ̀lú àmì di apákan wa. Lẹ́ẹ̀kansíi a ngbé Krístì wọ̀ bi a ti ndá májẹmu titun ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.

Bí a ti ndá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run ninu ilé Olúwa, a nmú ìbáṣepọ̀ wa pẹlú Rẹ̀ jinlẹ̀ síwájú síi. Ohun gbogbo tí a nṣe ninu tẹ́mpìlì ntọ́ka sí ètò Baba wa fún wa, ní ibi ọkàn èyítí Olùgbàlà àti ìrúbọ ìṣètùtù Rẹ̀ wà. Olúwa yío kọ́ wa ní ìlà lórí ìlà nípasẹ ṣíṣe àmì àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú bí a ti nṣí ọkàn wa ti a sì nfi pẹ̀lú àdúrà lépa láti ní òye àwọn ìtumọ̀ jíjinlẹ̀ síi.

Bíi apákan gbígba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, a fún wa ní àṣẹ láti wọ ẹ̀wù oyè-àlùfáà mímọ́. Ó jẹ́ ojúṣe mímọ́ kan àti ànfààní mímọ́ kan.

Ní púpọ̀ àwọn àṣà ẹ̀sìn, aṣọ àwọ̀sóde pàtàkì máa njẹ́ wíwọ̀ bí àmì àwọn ìgbàgbọ́ àti ìfọkànsìn ẹnìkan sí Ọlọ́run, àti pé aṣọ ayẹyẹ máa njẹ́ wíwọ̀ nígbà gbogbo láti ọwọ́ àwọn tó ndarí àwọn ètò ìjọsìn. Irú àwọn aṣọ mímọ́ wọ̀nyí ní ìtumọ̀ tó jinlẹ̀ fún àwọn tó nwọ̀ wọ́n. A kà ninu ìwé mímọ́ pé ni àwọn ìgbà atijọ́, àwọn aṣọ ayẹyẹ mímọ́ máa njẹ́ wíwọ̀ bákannáà ní ìbáṣe pẹ̀lú àwọn ètò tẹ́mpìlì.

Bíi ọmọ-ìjọ ti Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, àwọn wọnnì ninu wa tí wọ́n bá ti yàn láti dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run ninu ilé Olúwa nwọ aṣọ ayẹyẹ awọ̀sóde mímọ́ ninu ìjọsìn tẹ́mpìlì, tó ṣe àmì aṣọ wíwọ̀ ninu àwọn ètò tẹ́mpìlì ní ìgbà atijọ́. A máa nwọ ẹ̀wù oyè-àlùfáà mímọ́ bákannáà, àti ninu ìjọsìn tẹ́mpìlì àti ni ìgbé ayé wa ojojúmọ́.

Ẹ̀wù oyè-àlùfáà mímọ́ jẹ́ àmì jíjinlẹ̀ áti bákannáà ó ntọ́ka sí Olùgbàlà. Nígbàtí Ádámù àti Éfà jẹ ninu eso tí wọ́n sì níláti kúrò ninu Ọgbà Édẹ́nì, a fún wọn ni àwọn kóòtù awọ bíi ìbora fún wọn. Ó ṣeéṣe pé ẹranko kan jẹ́ fífi rúbọ láti ṣe àwọn kóòtu awọ wọnnì—tó jẹ́ àmì ìrúbọ ti Olùgbàlà fún wa. Kaphar ni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù fún ètùtù, ọ̀kan ninu àwọn ìtumọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ “láti bò.” Ẹ̀wù tẹ́mpìlì wa nrán wa létí pé Olùgbàlà àti àwọn ìbùkún Ètùtù Rẹ̀ bò wá jákèjádò ìgbé ayé wa. Bí a ti nwọ ẹ̀wù oyè-àlùfáà mímọ́ náà ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, àmì rírẹwà náà ndi apákan ara wa.

Ninu iwé Rómù ti Májẹ̀mú Titun, a kà pe: Òru bùkọjá tán, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ mọ́; nitorínáà ẹ jẹ́kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí á sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀. … Ẹ Gbé Jésù Krístì Olúwa Wọ̀.”

Mo fi ìmoore hàn fún ànfààní ti wíwọ ẹ̀wù oyè-àlùfáà mímọ́ láti rán mi létí pé Olùgbàlà àti àwọn ìbùkún ti Ètùtù àìlópin Rẹ̀ nfi gbogbo ìgbà bò mí jákèjádò ìrìn ajò mi ní ayé ikú. Ó nrán mi létí bákannáá pé bí mo ti npa àwọn májẹ̀mú ti mo ti dá pẹ̀lú Ọlọ́run ninu ilé Olúwa mọ́, mo ti fi pẹ̀lú àmì gbé Krístì wọ̀, ẹnití Òun Fúnra Rẹ̀ jẹ́ ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀. Yio dáàbò bò mí kúrò lọ́wọ́ ibi, yio fún mi ni agbára àti alékún ìleṣe, yio sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ati atọ́nà mi la òkùnkùn ati awọn iṣòro ayé yi já.

Ìjìnlẹ̀ àti arẹwà ìtumọ̀ àmì wà nínú ẹ̀wù oyè-àlùfáà mímọ́ náà àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀ sí Krístì. Mo gbàgbọ́ pé ṣíṣetán mi láti máa wọ ẹ̀wù mímọ́ náà di àmì mi sí Òun. Ó jẹ́ àmì ti ara-ẹni tèmi sí Ọlọ́run, kìí ṣe àmì fún àwọn ẹlòmiran.

Mo fi ìmoore hàn gidigidi fún Olùgbàlà mi, Jésù Krístì. Ìrúbọ ètùtù Rẹ̀ fún wa di àmì títóbi jùlọ ti ìfẹ́ àìlópin Rẹ̀ àti ti Baba wa ní Ọ̀run fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, pẹ̀lú àwọn àmì àfojúrí ti ìfẹ́ àti ìrúbọ náà—àwọn àpá ní ọwọ́, ẹsẹ̀, àti ìhà Olùgbàlà—tí o wà títí àní lẹ́hìn Àjínde Rẹ̀.

Bí mo ti npa àwọn májẹ̀mú àti àwọn ojúṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́, ninu eyiti wíwọ ẹ̀wù oyè-àlùfáà mímọ́ wà, ìgbé ayé mi gan-an le di àmì ara-ẹni ti ìfẹ́ àti ìmoore jíjinlẹ̀ mi fún Olùgbàlà mi, Jésù Krístì, àti ìfẹ́ inú mi láti ní Òun pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.

Bi ẹ kò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀, mo pè yín láti yàn ìbáṣepọ̀ jíjinlẹ̀ kan pẹ̀lú Ọlọ́run nípa dídá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀ ninú ilé Olúwa. Ṣe àṣàrò àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì wa (pẹ̀lú awọn koko ti ìkọ́ni ninu awọn àkọsílẹ̀-ìsàlẹ̀ awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, èyítí púpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ máa nní). Ó ti sọ̀rọ̀ ní àwítúnwí nipa awọn májẹ̀mú fún ọ̀pọ̀ ọdún àti pàapàa láti ìgbà dídi Ààrẹ Ìjọ. Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ láti ara awọn ìkọ́ni rẹ̀ nipa awọn ìbùkún rírẹwà ati àlékún agbára ati ìleṣe tí ó le jẹ́ tiyín nípasẹ̀ dídá ati pípa awọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.

Ìwé Ìléwọ́ Gbogbogbò sọ pé kò ṣe dandan láti ní ìpè mísọ̀n kan tàbí jẹ́ fífẹ́sọ́nà láti ṣe ìgbéyàwó láti dá àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì. Ènìyàn gbọdọ́ jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún ó kéré tán, kò gbọdọ̀ jẹ́ pé ó ṣì nlọ ilé iwé gíga tàbí irú rẹ̀, kí ó sì ti jẹ́ ọmọ-ìjọ fún ọdún kan ó kéré tán. Bákannáà awọn òsùwọ̀n jíjẹ́ mímọ́ ti ara-ẹni wa tí a nílò. Bí ẹ bá ni ìfẹ́ inú láti mú ìbáṣepọ̀ yín pẹ̀lú Baba yín ní Ọ̀run ati Jésù Krístì jinlẹ̀ síi nipa dídá awọn májẹ̀mú mímọ́ ninu ilé Olúwa, mo pè yín láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú bíṣọ́pù tàbí ààrẹ ẹ̀ka yín kí ẹ sì jẹ́ kí ó mọ̀ nipa ìfẹ́ inú yín. Òun yío ràn yín lọ́wọ́ mọ bí ẹ ti le múrasílẹ̀ láti gbà ati láti bu ọlá fún awọn májẹ̀mú wọnnì.

Nípasẹ̀ ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú kan pẹ̀lú Ọlọ́run, ìgbé ayé tiwa le di alààyè àmì ti ìfọkànsìn wa sí àti ìfẹ́ jíjinlẹ̀ wa fún Baba wa Ọ̀run, hesed wa fún Un, àti ìfẹ́ inú wa láti tẹ̀síwájú àti nígbẹ̀hìn kí a dàbí Olùgbàlà wa, ní mímúra wa láti wọlé sí ọ̀dọ̀ Wọn lọ́jọ́ kan. Mo jẹri pé àwọn ìbùkún nlá ti ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú náà yẹ dáradára fún ìdíyelé náà. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀