Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Òpó àti Ìtànṣán
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


11:17

Àwọn Òpó àti Ìtànṣán

Àwa pẹ̀lú lè ní òpó ìmọ́lẹ̀ tiwa—ìtànṣán kan ní àkokò kan.

Ọ̀rọ̀ mí wà fún àwọn tí wọ́n nṣe àníyàn nípa àwọn ẹ̀rí wọn nítorí wọn kò tíì ní àwọn ìrírí ti ẹ̀mí tí o lagbára. Mo gbàdúrà pé kí n lè pèsè àwọn àláfíà àti ìdánilójú kan.

Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìtànkálẹ̀ ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́! Ọ̀dọ́mọkùnrin kan ní ìhà àríwá New York, pẹ̀lú orúkọ lásán ti Joseph Smith, wọ inú igbó ṣúúrú ti àwọn igi kan láti gbàdúrà. Ó ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí rẹ̀ àti ìdúró rẹ̀ níwájú Ọlọ́run. Ó nwá ìdáríjì fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Àti pé ó ní ìdàmú nípa irú ìjọ tí yíò darapọ̀ mọ́. Ó nílò kedere áti àláfíà—ó nílò ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀.

Bí Joseph ṣe kúnlẹ̀ láti gbàdúrà tó sì “fi àwọn ìfẹ́-ọkàn [rẹ̀] fún Ọlọ́run,” òkùnkùn biribiri bò ó mọ́lẹ̀. Ohun ibi kan, aninilára, àti èyí tó wà gidi gbìyànjú láti dá a dúró—láti so ahọ́n rẹ̀ ki o má ba lè sọ̀rọ̀. Àwọn ipá òkùnkùn náà ní agbára tó bẹ́ẹ̀ tí Joseph rò pé ohun yío kú. Ṣùgbọ́n ó “sa gbogbo agbára [rẹ̀] láti ké pe Ọlọ́run láti dá [òun] nídè kúrò lọ́wọ́ agbára ọ̀tá yìí tí ó ti mú [òun].” Àti nígbànáà, “ní àkókò gan-an tí [ó] ti múra tán láti rì sínú àìnírètí, kí ó sì fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ìparun,” nígbàtí kò mọ̀ bóyá òun lè faradà mọ́, ìmọ́lẹ̀ ológo kún igbó ṣúúrú náà, ó sì nfọ́n òkùnkùn àti ọ̀tá ẹ̀mí rẹ̀ ká.

“Òpó ìmọ́lẹ̀” kan tí ó mọ́lẹ̀ ju oòrùn lọ sọ̀kalẹ̀ sórí rẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Ènìyàn kan farahàn, àti nígbànáà òmíràn. “Ìmọ́lẹ̀ àti ògo wọn tayọ gbogbo àpèjúwe.” Èkíní, Baba wa Ọ̀run, sọ orúkọ rẹ̀, “ní títọ́ka sí èkejì—[Joseph!] Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ Tirẹ̀!

Àti pẹ̀lú títú ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ náà síta, Ìmúpadàbọ̀sípò ti bẹ̀rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkún omi ìfihàn àti àwọn ìbùkún àtọ̀runwá yíò tẹ̀lé: ìwé mímọ́ titun, àṣẹ oyè àlùfáà tí a mú padàbọ̀sípò, àwọn àpóstélì àti àwọn wòlíì, àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú, àti ìmúpadàbọ̀sípò ti Ìjọ òtítọ́ àti alààyè Olúwa, èyítí yíò kún ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ kan pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ àti ẹ̀rí nipa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò.

Gbogbo èyí, àti púpọ̀ díẹ̀ síi, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà onítara ọmọdékùnrin kan àti òpó iná.

Àwa náà ní àwọn ohun àìnírètí tiwa. Àwa náà nílò òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìdàrúdàpọ̀ ti ẹ̀mí àti òkùnkùn ti ayé. Àwa pẹ̀lú nílò láti mọ̀ fúnra wa. Èyí ni ìdí kan tí Ààrẹ Russell M. Nelson fi pè wá láti “tẹ ara [wa] rì nínú ìmọ́lẹ̀ ológo ti Ìmúpadàbọ̀sípò náà.”

Ọ̀kan nínú àwọn òtítọ́ nla ti Ìmúpadàbọ̀sípò ni pé àwọn ọ̀run ṣi—pé àwa pẹ̀lú lè gba ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀ láti òkè. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé òtítọ́ ni.

Ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ìdẹkùn ti ẹ̀mí. Nígbàmíràn àwọn ọmọ ìjọ tòótọ́ máa nrẹ̀wẹ̀sì wọ́n sì máa nṣáko lọ nítorípé wọn kò tíì ní àwọn ìrírí tó lágbára ti ẹ̀mí—nítorípé wọn kò tíì ní ìrírí òpó ìmọ́lẹ̀ tiwọn. Ààrẹ Spencer W. Kimball kìlọ̀ pé, “ní fífi ìgbà gbogbo retí ohun àgbàyanu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ yíò pàdánù pátápátá ní ti ìṣàn léraléra ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tí a ti fihàn.”

Ààrẹ Joseph F. Smith bákanáà rántí pé, “Olúwa fa àwọn ohun ìyàlẹ́nu sẹ́hìn fún mi [nígbà tí mo wà ní ọ̀dọ́], ó sì fi òtítọ́ hàn mí, ìlà lórí ìlà, ìkọ́ni lórí ìkọ́ni, nihin díẹ̀ àti lọhun díẹ̀.”

Èyí ni àpẹrẹ àwòrán Olúwa, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin. Dípò kí ó rán òpó ìmọ́lẹ̀ sí wa, Olúwa rán ìtànṣán ìmọ́lẹ̀, àti lẹ́hìnnáà òmíràn, àti òmíràn.

Àwọn ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ náà njẹ́ dídà sórí wa títílọ. Àwọn ìwé mímọ́ kọ́ni pé Jésù Krístì ni “ìmọ́lẹ̀ àti … ìyè ayé,” pé “Ẹ̀mí Rẹ̀ nfi ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ọkùnrin [àti obìnrin] tí wọ́n nbọ̀ wá sí ayé,” àti pé ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ “kún ọ̀pọ̀lọpọ̀ [àwọn] àlàfo,” ní fífúnni ní “ìyè sí ohun gbogbo.” Ìmọ́lẹ̀ Krístì wa ní àyíká wa gangan.

Bí a bá ti gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ tí a sì nlàkàkà láti lo ìgbàgbọ́, ronúpìwàdà, àti buọlá fún àwọn májẹ̀mú wa, nígbànáà a jẹ́ yíyẹ láti gba àwọn ìtànṣán àtọ̀runwá wọ̀nyí nígbàgbogbo. Nínú gbólóhùn mánigbàgbé ti Alàgbà David A. Bednar, “a ‘ngbé nínú ìfihàn.’”

Àti síbẹ̀síbẹ̀, olukúlùkù wa yàtọ̀. Kò sí ènìyàn méjì tí wọ́n ní ìrírí ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ Ọlọ́run ní ọ̀nà kannáà gan. Ẹ lo àkokò díẹ̀ láti ronú nípa bí ẹ ṣe ní ìrírí ìmọ́lẹ̀ àti Ẹ̀mí Olúwa.

Ẹ lè ti ní ìrírí àwọn ìtànṣán ẹ̀rí wọ̀nyí bí “àláfíà [tí a sọ] sí ọkàn yín nípa [ọ̀rọ̀] kan” tí ó dà yín láàmú.

Tàbí ìrísí kan—ohùn jẹ́jẹ́, kékeré kan—tí ó dúró “ni inú àti ọkàn yín” tí ó nrọ̀ yín láti ṣe nkan tí ó dára, bí ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ fún ẹnìkan.

Bóyá ẹ ti wà ní kíláàsì nínú ìjọ—tàbí ní àgọ́ àwọn ọ̀dọ́—ẹ sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ líle láti tẹ̀ lé Jésù Krístì kí ẹ sì dúró bí olootọ. Bóyá ẹ̀yin pàápàá dúró láti pín ẹ̀rí pé ẹ nírètí pé ó jẹ́ òtítọ́ àti lẹ́hìnnáà nímọ̀lára pé ó jẹ́ bẹ́ẹ̀.

Tàbí bóyá ẹ ti ngbàdúrà tí ẹ sì nímọ̀lára ìdánilójú aláyọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ yín.

Ẹ lè ti gbọ́ tí ẹnìkan ti jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì tí ó sì kan ọkàn yín tí ó sì mísí yín láti ṣe dáradára si.

Bóyá ẹ nka ẹsẹ kan nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì tí ó sọ̀rọ̀ sí ọkàn yín, bí ẹnipé Ọlọ́run ti fi í síbẹ̀ fún ẹ̀yin nìkan.

Ẹ lè ti nímọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run fún àwọn ẹlòmíràn bí ẹ ti nsìn wọ́n.

Tàbí bóyá ẹ ntiraka láti nímọ̀lára Ẹ̀mí nítorí ìbànújẹ́ tàbí àníyàn ṣùgbọ́n ní ẹ̀bùn iyebíye àti ìgbàgbọ́ láti wo ẹ̀hìn kí ẹ mọ “àwọn àánú Olúwa” ti àtẹ̀hìwá.”

Kókó mi ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà ló wà láti gba àwọn ìtànṣán ọ̀run ti ẹ̀rí. Ìwọ̀nyí ni àwọn díẹ̀, nínú dídájú. Wọ́n lè má jẹ́ àràọ̀tọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo wọ́n jẹ́ apákan àwọn ẹ̀rí wa.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, èmi ò tíì rí òpó ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n bíi ti ẹ̀yin, mo ti ní ìrírí ọ̀pọ̀ ìtànṣán tọ̀run. Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, mo ti gbìyànjú láti mọyì irú àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀. Mo rí pé bí mo ṣe nṣé, mo ndamọ̀ mo sì nrántí àní díẹ̀ síi nínú wọn. Níbí ni àwọn àpẹrẹ díẹ̀ látinú ìgbésí ayé mi. Wọ́n lè má wú àwọn kan lórí ​​gan-an, ṣùgbọ́n wọ́n ṣeyebíye sí mi.

Mo rántí pé mo jẹ́ ọ̀dọ́langba kan nígbà tí mo ṣèrìbọmi. Bí ìpàdé ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀, mo nímọ̀lára pé Ẹ̀mí rọ̀ mí láti joko kí nsì wà ní ipò ọ̀wọ̀. Mo joko, mo sì dákẹ́ fún ìpàdé tó kù.

Ṣaájú míṣọ̀n mi, mo bẹ̀rù pé ẹ̀rí mi kò lágbára tó. Kò sí ẹnikan nínú ẹbí mi tí ó tí ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ kan rí, àti pé èmi kò mọ̀ bóyá mo lè ṣé. Mo rántí bí mo ṣe nṣàṣàrò tí mo sì ngbàdúrà kíkankíkan láti gba ẹ̀rí tó dájú nípa Jésù Kristi. Lẹ́hìnnáà lọ́jọ́ kan, bí mo ṣe bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Baba Ọ̀run, mo nímọ̀lára ìmọ́lẹ̀ àti ọ̀yàyà tó lágbára. Èmí sì mọ. Mo kàn mọ̀.

Mo rántí bí a ṣe tamíjí ní òru ọjọ́ kan nípasẹ̀ ìmọ̀lára “òye mímọ́” tí ó sọ fún mi pé a ó pè mí láti sìn nínú iyejú àwọn alàgbà. Lẹ́hìn ọ̀sẹ̀ méjì ni wọ́n pè mí.

Mo rántí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò kan níbití ọmọ ẹgbẹ́ iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀rí gangan tí mo ti sọ fún ọ̀rẹ́ kan pé mo nírètí láti gbọ́.

Mo rántí pé mo kúnlẹ̀ pẹ̀lú ọgọ́gọ̀rún àwọn arákùnrin láti gbàdúrà fún ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n kan tó dùbúlẹ̀ láìlèsọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ atẹ́gùn kan ní ilé ìwòsàn kékeré kan, jìnnà-réré lẹ́hìn tí ọkàn rẹ̀ ti dáwọ́ dúró. Bí a ṣe fi àwọn ọkàn tiwa ṣe ọ̀kan láti bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀mí rẹ̀, ó jí ó sì fa ẹ̀rọ atẹ́gùn kúrò ní ọ̀fun rẹ̀. Ó nsìn lónìí bí ààrẹ èèkàn kan.

Mo sì rántí jíjí dìde pẹ̀lú àwọn ìmọ̀lára ti ẹ̀mí tí ó lágbára lẹ́hìn àlá tí ó hàn gbangba ti ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n kan àti olùtọ́nisọ́nà tí ó tètè kú púpọ̀, tí ó fi àlàfo nlá sílẹ̀ nínú ìgbésí ayé mi. Ó nrẹrin músẹ́ pẹ̀lú ayọ̀. Mo mọ̀ pé ó wà dáradára.

Ìwọ̀nyí ni díẹ̀ lára àwọn ìtànṣán mi. Ẹ ti ní àwọn ìrírí tiyín—àwọn ìtànṣán ẹ̀rí tiyín. Bí a ṣe ndamọ̀, tí a nrántí, tí a sì nkó àwọn ìtànṣán wọ̀nyí jọ “papọ̀ sí ọ̀kan,” ohun àgbàyanu kan bẹ̀rẹ̀ sí nṣẹlẹ̀. “Ìmọ́lẹ̀ nfi ara mọ́ ìmọ́lẹ̀”—“òtítọ́ gba òtítọ́ mọ́ra.” Òtítọ́ àti agbára ìtànṣán ẹ̀rí kan nṣe àtìlẹ́hìn ó sì ndàpọ̀ pẹ̀lú òmíràn, àti lẹ́hìnnáà òmíràn, àti òmíràn. Ìlà lórí ìlà, ìkọ́ni lórí ìkọ́ni, ìtànṣán nihin àti ìtànṣán lọhun—àkokò ti ẹ̀mi kekere, ti ìṣúra , kan ní ìgbà kan—níbẹ̀ ni àwọn ìrírí ti ẹ̀mí tí ó kún fún ìmọ́lẹ̀ tó ndàgbà laarin wa. Bóyá kò sí ìtànṣàn kan tí ó lágbára tó láti di ẹ̀rí kíkún kan, ṣùgbọ́n lápapọ̀ wọ́n lè di ìmọ́lẹ̀ tí òkùnkùn iyèméjì kò lè borí.

“Áà nígbànáà, njẹ́ èyí kò ha jẹ́ òdodo?” Álmà bèrè. “Èmi wí fún nyín, bẹ̃ni, nítorípé ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀.”

“Èyí nì tí íṣe ti Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀,” Olúwa kọ́ wa pe, “ẹni tí ó bá sì gbà ìmọ́lẹ̀, tí ó sì ntẹ̀síwájú nínú Ọlọ́run, ngba ìmọ́lẹ̀ sí; àti pé ìmọ́lẹ̀ náà sì ndàgbà síwájú àti síwájú sí i títí di ọjọ́ pípé.”

Ìyẹn túmọ̀ sí, àwọn arákùnrin àti arábìnrin, àkokò náà àti nípasẹ̀ “àìsimi nlá,” àwa pẹ̀lú lè ní òpó ìmọ́lẹ̀ tiwa—ìtànṣán kan ní àkokò kan. Àti ní àárín òpó náà, àwa pẹ̀lú yíò rí olùfẹ́ni Baba Ọ̀run, tí ó npè wá ní orúkọ, tí ó ntọ́ka wa sí Olùgbàlà wa Jésù Krístì, tí ó sì npè wá láti “Gbọ́ Tirẹ̀!”

Mo jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì, pé Òun ni ìmọ́lẹ̀ àti ìyè ti gbogbo aráyé—àti ti ayé ti araẹni tiyín àti tèmi.

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Òun ni Ọmọ òtítọ́ àti alààyè ti Ọlọ́run alààyè, àti pé Ó dúró sí orí ìjọ òtítọ́ àti alààyè yìí, tí a ndarí tí a sì ntọ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlíì àti àpóstélì òtítọ́ àti alààyè Rẹ̀.

Njẹ́ kí á mọ̀ kí á sì gba ìmọ́lẹ̀ ológo Rẹ̀ àti lẹ́hìnnáà kí a yàn Án lórí òkùnkùn ayé—ní ìgbàgbogbo àti ayérayé. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Wo Ìtàn—Josefu Smith 1:10–13.

  2. Wo Ìtàn—Josefu Smith 1:14–16.

  3. Wo Joseph Smith, Journal, 9–11 Oṣù kọkànlá, 1835, 24, josephsmithpapers.org.

  4. Ìtàn—Josefu Smith 1:17.

  5. Wo Ìtàn—Josefu Smith 1:20. Nígbàtí Joseph Smith padà sí ilé lẹ́hìn Ìran Àkọ́kọ́, ìyá rẹ bèrè bóyá ó wà dáradára. Ó fèsì pé, “Èmi wà dáradára tó yàtọ̀.… Mo ti kọ́ fún ara mi pé ṣíṣe Prẹsibitarian kìí ṣe òtítọ́” (àfikún àtẹnumọ́).

  6. Russell M. Nelson, “Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìparí,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2019, 122.

  7. Spencer W. Kimball, nínú Ìròhìn Ìpàdé Àpapọ̀, Ìpàdé Àpapọ̀ Agbègbè, Munich Germany, 1973, 77; tí a fàyọ nínú Graham W. Doxey, “Ohùn náà Tún Kéré,” Ẹ́nsáìn, Oṣù Kọkànlá 1991, 25.

  8. Àwọn Ìkọ́ni Àwọn Ààrẹ ti Ìjọ: Joseph F. Smith (1998), 201: “Nígbàtí èmi gẹ́gẹ́bí ọmọkùnrin kan kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́, nígbàgbogbo èmi yíò jáde lọ láti béèrè lọ́wọ́ Olúwa láti fi ohun ìyanu kan hàn mi, kí èmi ba lè gba ẹ̀rí kan. Ṣùgbọ́n Olúwa fawọ́ àwọn ohun ìyanu sẹ́hìn fún mi,ó sì fi òtítọ́ hàn mí, ilà lórí ìlà, ìlànà lórí ìlànà, díẹ̀ síhìn-ín díẹ̀ lọhun, títí ó fi jẹ́ kí nmọ òtítọ́ láti orí mi dé àtẹ́lẹsẹ̀ mi. , àti títí iyèméjì àti ìbẹ̀rù fi di fífọ̀ mọ́ pátápátá kúrò lọ́dọ̀ mi. Kò ní láti rán áńgẹ́lì kan láti ọ̀run wá láti ṣe bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní láti fi ìpè olú-áńgẹ́lì sọ̀rọ̀. Nípa ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ti ohùn kékeré Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè, ó fi ẹ̀rí tí mo ní fún mi. Àti nípa ìlànà àti agbára yí òun yíò fún gbogbo àwọn ọmọ ènìyàn ní ìmọ̀ òtítọ́ tí yíò dúró pẹ̀lú wọn, àti pé yíò jẹ́ kí wọ́n mọ òtítọ́, gẹ́gẹ́bí Ọlọ́run ti mọ̀ ọ́, àti láti ṣe ìfẹ́ Baba bí Krístì ti ṣe é.”

  9. Mòsíàh 16:9.

  10. Ẹ̀kọ́ àti ǎwọn Májẹ̀mú 84:46; bákannáà wo Jòhánù 1:9.

  11. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 88:12–13.

  12. David A. Bednar, Ẹ̀mí Ìfihàn (2021), 7.

  13. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:23.

  14. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 8:2; bákannáà wo Hẹ́lẹ́mánì 5:30.

  15. Wo Mòsíàh 5:2; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 11:12.

  16. Wo 2 Néfì 4:21; Hẹ́lẹ́mánì 5:44.

  17. Olúwa ti ṣe ìdánimọ̀ agbára láti gbàgbọ́ lóri ẹ̀rí àwọn elòmíràn gẹ́gẹ́bí ẹ̀bùn ti ẹ̀mí (see Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 46:13–14).

  18. Ìfihàn òde-òní kọ́ni pé àwọn ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ “nípasẹ̀ Ẹ̀mí mi ni a fi fún yín, … bí kò bá jẹ́ pé nípa agbára mi ẹ̀yin kò lè ní wọn; nítorí-èyi, o lè jẹ́ ẹ̀rí pé o ti gbọ́ ohùn mi, o sì mọ àwọn ọ̀rọ̀ mi” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 18:35–36.

  19. Wo Mòsíàh 2:17; Mórónì 7:45–48.

  20. 1 Néfì 1:20. Alàgbà Gerrit W. Gong ti sọ̀rọ̀ nípa “wí[wo] pẹ̀lú ojú láti rí kí a sì máa n[yọ̀] nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú Olúwa nínú ìgbésí ayé wa” (“Iṣẹ́ ìránṣẹ́,” Làìhónà, Oṣù karun 2023, 18) àti nípa bí “Ọwọ́ Olúwa nínú ìgbésí ayé wa ṣe rí ní gbogbo ìgbà ní kedere ní ẹ̀hìn” (“Rántí Rẹ̀ Nígbàgbogbo,” Làìhónà, Oṣù karun 2016, 108). Ẹ̀bùn ìmoore tí a mọ̀ àti jíjẹ́wọ́ ọwọ́ Olúwa nínú ayé wa, àní tí a kò bá dá a mọ̀ tàbí ní ìmọ̀lára rẹ̀ ní àkokò náà, jẹ́ alágbára. Àwọn ìwé mímọ́ máa nsọ̀rọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà nípa agbára ẹ̀mí ti ìrántí (wo Hélámánì 5:9–12; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20:77, 79), èyí tí ó lè jẹ́ ṣíṣẹ sí ìfihàn (wo Mórónì 10:3–4).

  21. Joseph Smith kọ́ni pé: “Ẹnikẹ́ni lè jẹ ànfàní nípa kíkíyèsí ìfetísí àkọ́kọ́ ti ẹ̀mí ìfihàn; fún àpẹrẹ, nígbàtí ẹ bá ní ìmọ̀lára òye mímọ̀ tó nṣàn sínú yín, ó lè fún yín ní àwọn ìrò ti àwọn ìmọ̀ràn lójijì, pé nípa ṣíṣe àkíyèsí rẹ̀, ó lè ri pé ó ní ìmúse ní ọjọ́ kannáà tàbí láìpẹ́; (i.e.) àwọn ohun wọnnì tí a ti gbékalẹ̀ sí ọkàn yín láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run, yíò ṣẹ; àti ní báyìí nípa kíkọ́ Ẹ̀mí Ọlọ́run àti lílóye rẹ̀, ẹ lè dàgbà sínú ìlànà ìfihàn, títí ẹ ó fi di pípé nínú Krístì Jésù” (Àwọn Ẹ̀kọ́ ti Àwọn Ààrẹ ti Ìjọ: Joseph Smith [2007], 132).

  22. Éfésù 1:10.

  23. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 88:40: ”Nítorí òye lẹ̀ mọ́ òye; ọgbọ́n gba ọgbọ́n; òtítọ́ gba òtítọ́; ìwà rere ní ìfẹ́ ìwà rere; ìmọ́lẹ̀ lẹ̀ mọ́ ìmọ́lẹ̀.”

  24. Álmà 32:35. Álmà tẹnumọ́ pé àwọn ìrírí tí ó kún ìmọ́lẹ̀ wọ̀nyí, bíótilẹ̀jẹ́ ìgbàgbogbo kékeré, jẹ́ gidi ní gbogbo àwọn ọ̀nà. Òtítọ́ wọn di agbára díẹ̀ si nígbàtí wọ́n bá parapọ̀ láti ṣe odidi alágbára kan.

  25. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 50:24.

  26. Álmà 32:41.