Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àtakò nínú Ohun Gbogbo
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Àtakò nínú Ohun Gbogbo

Láti lè lo agbára òmìnira, a nílò láti ní àwọn àṣàyàn àtakò láti ronú lé.

Làìpẹ́ yìí, bí mo ṣe nwakọ̀ nílùú kan tí a kò mọ̀, mo ṣìnà, èyí tó mú kí ìyàwó mi àti èmi já sí òpópónà kan fún àìlópin máìlì, tí a kò sì tún lè yí padà. A ti gba ìpè onínúure kan sí ilé ọ̀rẹ́ kan a sì dàmú pé a ó dé pẹ́ gan-an ju bí a ti retí lọ.

Lákokò tí a wà ní òpópónà yí tí a nwá ọ̀nà àbáyọ lẹ́ẹ̀kansi, mo dá ara mi lẹ́bi nítorí mí ò ṣàkíyèsí to dara julọ si eto lilọ kiri. Ìrírí yí mú kí nronú nípa bí a ṣe nṣe àwọn ìpinnu ti kò tọ́ nínú ìgbésí ayé wa nígbà míràn àti bí a ṣe lè fi ìrẹ̀lẹ̀ àti sùúrù gbé pẹ̀lú àbájáde rẹ̀ títí tí a ó fi lè tún ipa ọ̀nà wa ṣe padà.

Ìgbésí ayé jẹ́ nípa gbogbo ṣíṣe àwọn yíyàn. Baba wa ní Ọ̀run fún wa ní ẹ̀bùn agbára láti yàn ní pàtó kí a baà lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn yíyàn wa—láti inú èyí tí ó tọ́ àti láti inú àwọn tí kò tọ́ pẹ̀lú. A nṣe àtúnṣe àwọn àṣìṣe ìpinnu wa nígbàtí a bá ronúpìwàdà. Èyí ni ibi tí ìdàgbásòkè ti ṣẹlẹ̀. Ètò Baba Ọ̀run fún gbogbo wa jẹ́ nípa kíkọ́ ẹ̀kọ́, dídàgbàsókè, àti lìlọsíwájú sí ìyè àìnípẹ̀kun.

Láti ìgbà tí àwọn òjíṣẹ̀ ìhìnrere ti kọ́ ìyàwó mi àti èmi tí a sì ti darapọ̀ mọ́ Ìjọ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, àwọn ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ tí Léhì fi fún Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì máa nwú mi lórí nígbàgbogbo. Ó kọ́ ọ pé “Olúwa Ọlọ́run fi fún ènìyàn kí ó lè ṣe fún ara rẹ̀.” àti pé “ó di dandan, pé kí àtakò wà ní ohun gbogbo.” Láti lè lo agbára láti yàn wa, a nílò láti ní àwọn àṣàyàn àtakò láti ronú lé. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Ìwé ti Mọ́mọ́nì tún rán wa létí pé a ti “kọ́ wa dáadáa” àti pé “Ẹ̀mí Krístì” ni a ti fi fún olúkúlùkù wa láti “mọ rere kúrò nínú ibi.”

Ní ayé, a nkojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn yíyàn pàtàkì nígbàgbogbo. Fún àpẹrẹ:

  • Yíyàn bóyá tàbí a kò lè tẹ̀lé àwọn òfin Ọlọ́run.

  • Yíyàn láti ní ìgbàgbọ́ àti láti dáamọ̀ nígbàtí àwọn iṣẹ́ ìyanu bá ṣẹlẹ̀ tàbí fi iyèméjì dúró fún ohun kan láti ṣẹlẹ̀ ṣaájú yíyàn láti gbàgbọ́ nìkan nígbànáà.

  • Yíyan láti mú ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run dàgbà tàbí fi ìbẹ̀rù máa retí ìpèníjà míràn ní ọjọ́ kejì.

Bí ìgbà tí mo yà níbití kò tọ́ lórí òpópónà márosẹ̀, ìjìyà lọ́wọ́ àwọn àbájáde àwọn ìpinnu ti ara wa tí kò dára lè jẹ́ dídunni púpọ̀ nípàtàkì nítorípé ara wa nìkan la ní láti dá lẹ́bi. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, a lè yàn nígbàgbogbo láti gba ìtùnú nípasẹ̀ ìlànà àtọ̀runwá ti ìrònúpìwàdà, kí a tún àwọn nkan tí kò tọ́ ṣe lẹ́ẹ̀kansíi, àti ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kí a kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tí nyí ìgbésí ayé padà.

Nígbà míràn a tún lè ní ìrírí àtakò àti àwọn ìdánwò láti inú àwọn nkan tí ó wà ní ìta ìṣàkóso wa, gẹ́gẹ́bí:

  • Àwọn àkokò ìlera àti àwọn àkokò àìsàn.

  • Àwọn ìgbà àláfíà àti ti ogun.

  • Wákàtí ti ọ̀sán àti ti òru àti àwọn àkokò ti ooru àti ti ìgbà òtútù.

  • Àwọn ìgbà iṣẹ́ tẹ̀lé àwọn ìgbà ìsinmi.

Bíótilẹ̀jẹ́pé a kò lè yan irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n kàn nṣẹlẹ̀ ni, a ní òmìnira láti yàn bí a ó ṣe ṣe sí wọn. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìwà rere tàbí pẹ̀lú ìwà àìnírètí. A lè wá ọ̀nà láti kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìrírí náà kí a sì bèrè fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtìlẹ́hìn Olúwa wa, tàbí a lè rò pé a wà fúnra wa nínú àdánwò yìí àti pé a gbọ́dọ̀ dá nìkan jìyà rẹ̀. A lè “ṣàtúnṣe àwọn ọkọ̀ ojú-omi wa” sí òtítọ́ titun, tàbí a lè pinnu láti má yi ohunkohun padà. Ní òkùnkùn alẹ́, a lè tan ìmọ́lẹ̀ wa. Ní òtútù ìgbà òtútù, a yàn láti wọ àwọn aṣọ tógbóná. Ní àwọn àkokò àìsàn, a lè wá ìrànlọ́wọ́ ti ìṣègùn àti ti tẹ̀mí. A nyàn bí a ó ti ṣe sí àwọn ipò wọ́nyì.

Ṣe àtúnṣe, kọ́ ẹkọ, wá kiri, yíyàn gbogbo wọn jẹ́ ọ̀rọ̀-ìṣe. Ẹ rántí pé àwa jẹ́ aṣoju, a kìí ṣe àwọn nkan èlò lásán. Ẹ má sì jẹ́ kí a gbàgbé láé pé Jésù ṣèlérí láti “gbé àwọn ìrora àti àìsàn àwọn ènìyàn rẹ̀ … kí òun lè … ṣe àtìlẹ́hìn,” tàbí rànwá lọ́wọ́, bí a ti yípadà sí I. A lè yàn láti kọ́ ìpìlẹ̀ wa sórí àpáta tí í ṣe Jésù Kristi, pé nígbàtí ìjì náà bá dé “kì yíò ní agbára lórí [wa].” Ó ti ṣèlérí pé “ẹnikẹ́ni tí yíò bá wá [sọ́dọ̀ Rẹ̀], òun ni [Yíò] gbà; ìbùkún sì ni fún àwon tí wọ́n wá sọ́dọ̀ [Rẹ̀].”

Bayi, àfikún ìlànà kan wa tí ó ṣe pàtàkì jùlọ. Léhì wí pé “àtakò … gbọdọ̀ wà nínú ohun gbogbo.” Èyí túmọ̀ sí pé àwọn àtakò kò wà yàtọ̀ sí ara wọn. Wọ́n lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ara wọn pàápàá. A kì yíò ní ànfàní láti ṣe ìdánimọ̀ ayọ̀ àyàfi tí a bá ti ní ìrírí ìbànújẹ́ ní ààyè kan. Níní ìmọ̀lára ebi ní àwọn ìgbà míràn nrànwá lọ́wọ́ láti mọrírì gan-an nígbà tá a bá tún ní ànító láti jẹ. A kì yíò ní ànfàní làti dá òtítọ́ mọ̀ àyàfi tí a bá ti tún rí àwọn irọ́ nihin àti lọhun.

Àwọn àtakò gbogbo wọ̀nyí dàbí àwọn ẹ̀gbẹ́ méjì ti owo ẹyọ kan kannáà. Àwọn ẹ̀gbẹ́ méjèèjì wà nígbàgbogbo. Charles Dickens ṣe àpẹrẹ ti ìmọ̀ràn yí nígbàtí ó kọ̀wé pé “Ó jẹ́ àwọn àkokò tí ó dára jùlọ, o jẹ àwọn àkokò tí ó burú jùlọ.”

Jẹ́ kí nṣe àpẹrẹ kan láti ìgbésí ayé tiwa. Ṣíṣe ìgbéyàwó, dídá ẹbí sílẹ̀, àti níní àwọn ọmọ mú àwọn àkokò ayọ̀ títóbi jùlọ tí a ti ní ìrírí rí nínú ìgbésí ayé wa wá fún wa, ṣùgbọ́n bákannáà àwọn àkokò ìrora, ìdààmú, àti ìbànújẹ́ tí ó jinlẹ̀ jùlọ nígbàtí ohun kan ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni nínú wa. Ayọ̀ àìlópin àti ìdùnnú pẹ̀lú àwọn ọmọ wa ní àwọn ìgbà míràn tún tẹ̀lé pẹ̀lú àwọn àkokò àìsàn lóòrèkóòrè, lílọ sí ilé-ìwòsàn, àti àwọn alẹ̀ àìsùn tí ó kún fún ìpọ́njú, àti bákannáà wíwá ìtura nínú àwọn àdúrà àti àwọn ìbùkún oyèàlúfà. Àwọn ìrírí tí ó yàtọ̀ síra wọ̀nyí kọ́ wa pé a kò dá wà ní àwọn àkokò ìjìyà, wọ́n sì tún fi bí a ṣe lè gbé pẹ̀lú ìtìlẹ́hìn àti ìrànlọ́wọ́ Olúwa hàn wá. Àwọn ìrírí wọ̀nyí rànwá lọ́wọ́ láti mọ wá lọ́nà àgbàyanu, gbogbo rẹ̀ sì ti wúlò pátápátá. Njẹ́ èyí kìí ṣe ohun tí a wà nibi fún?

Nínú àwọn ìwé mímọ́ a tún rí àwọn àpẹrẹ àtàtà kan:

  • Léhì kọ́ ọmọ rẹ̀ Jékọ́bù pé àwọn ìpọ́njú tí ó jìyà nínú aginjù ràn án lọ́wọ́ láti mọ títóbi Ọlọ́run àti pé “[Ọlọ́run] yíò yà àwọn ìpọ́njú [rẹ̀] sọ́tọ̀ fún èrè [rẹ̀].”

  • Nígbà àhámọ́ ìkà Joseph Smith ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Liberty, Olúwa sọ fún un pé “gbogbo nkan wọ̀nyí yíò fún [un] ní ìrírí, yíò sì jẹ́ fún rere [rẹ̀].”

  • Níkẹhìn, ìrúbọ àìlópin Jésù Krístì dájúdájú jẹ́ àpẹrẹ tí ó tóbi jùlọ tí ìrora àti ìjìyà tí a ti rí rí, ṣùgbọ́n ó tún mú àwọn ìbúkún àgbàyànu Ètùtù Rẹ̀ wá fun gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.

Níbití òòrùn bá wà, àwọn òjìjí gbọdọ̀ wà níbẹ̀ bákanáà. Ìkún-omi lè mú ìparun wá, ṣùgbọ́n wọ́n sábà máa nmú ìwàláàyè wá. Omijé ìbànújẹ́ sábà máa ndi omijé ìtura àti ayọ̀. Àwọn ìmọ̀lára ìbànújẹ́ nígbàtí àwọn olùfẹ́ bá lọ kúrò ni a san padà nígbà míràn pẹ̀lú ayọ̀ pípàdé lẹ́ẹ̀kansi. Lákokò ogun àti ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣe inú rere àti ìfẹ́ nṣẹlẹ̀ fún àwọn tó ní “ojú láti rí, àti etí láti gbọ́.”

Ìbẹ̀rù àti àníyàn ló sábà máa nwà nínú ayé wa lónìí—ìbẹ̀rù ohun tí ọjọ́ iwájú lè mú wá fún wa. Ṣùgbọ́n Jésù ti kọ́ wa láti gbẹ́kẹ̀lé, kí a sì “máa wo [Òun] nínú gbogbo èrò; má siyèméjì, má bẹ̀rù.”

Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ìgbìyànjú atọkànwá léraléra láti rí àwọn ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ti gbogbo owó ẹyọ tí a pín fún wa nínú ìgbésí ayé wa. Àní bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ẹ̀gbẹ́ méjèèjì lè má hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sí wa nígbà míràn, a lè mọ̀ a sì lè gbẹ́kẹ̀lé pé wọ́n wà níbẹ̀ nígbàgbogbo.

A lè ní ìdánilójú pé àwọn ìṣoro wa, àwọn ìbànújẹ́, àwọn ìpọ́njú, àti àwọn ìrora kò júwe wa; dípò bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ bí a ṣe nrìn nípa wọn ni yíò ràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà, kí a sì sún mọ́ Ọlọ́run. Àwọn ìwà àti àwọn yíyàn wa ni ó júwe wa dára jùlọ ju àwọn ìpèníjà wa lọ.

Nígbàtí ẹ bá ní ìlera, ẹ mọyì kí ẹ sì dúpẹ́ fún un ni gbogbo ìgbà. Nígbàtí a bá nṣàìsàn, ẹ lépa láti fi sùúrù kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀ kí ẹ sì mọ̀ pé èyí lè yí padà lẹ́ẹ̀kan síi ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run. Nígbàtí a bá wà nínú ìbànújẹ́, ẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ayọ̀ wà ní tòsí; ní ọ̀pọ̀ ìgbà a kò kàn tíì lè ri i ni. Ẹ fi òye yí ìdojúkọ yín padà kí ẹ gbé àwọn èrò yín ga sí àwọn ààyè rere tí àwọn ìpèníjà, nítorí láìṣe àníàní nígbà gbogbo wọ́n wà níbẹ̀ bákannáà! Ẹ máṣe gbàgbé láé láti dúpẹ́. Ẹ yàn láti gbàgbọ́ Ẹ yàn láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Ẹ yàn láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run nígbàgbogbo. Ẹ yàn láti “ronú sẹ̀lẹ́stíà,” gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ wa láìpẹ́!

Ẹ jẹ́ kí a máa fi ìgbàgbogbo rántí ètò àgbàyanu Baba wa Ọ̀run fún wa. Ó nifẹ wa ó sì rán Ọmọ rẹ̀ Olùfẹ́ láti ṣèrànwọ́ nínú àwọn àdánwò wa àti láti ṣílẹ̀kùn fún wa láti padà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Jésù Krístì wà láàyè ó sì dúró níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà, ndúró fún wa láti yàn láti képè É láti pèsè ìtìlẹ́hìn, agbára, àti ìgbàlà. Nípa àwọn ohun wọ̀nyí ni mo jẹ́ ẹ̀rí ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀