Tí A Ti Yàn Tẹ́lẹ̀ Láti Sìn
Baba wa Ọ̀run nfẹ́ láti fi yíyàn-tẹ́lẹ̀ ti ara ẹni yín hàn sí yín, Òun ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ bí ẹ ti nlépa láti kọ́ ẹ̀kọ́ ati láti tẹ̀lé ìfẹ́ Rẹ̀.
Ní ìrọ̀lẹ́ yi, mo bá awọn ọ̀dọ́ Ìjọ sọ̀rọ̀, awọn ìran tó ndìde ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọ́n ngbé ọ̀pagun fùn ìran tó nbọ̀wá.
Ní Oṣù Kẹwa 2013, wòlíì wa ọ̀wọ́n, Ààrẹ Russell M. Nelson, wí pé: “Baba yín Ọ̀run ti mọ̀ yín fún ìgbà pípẹ́ gan-an. Ẹ̀yin, bí ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin Rẹ̀, ni a yàn nípa ọwọ́ Rẹ̀ láti wá sí ilẹ̀ ayé ní àkókò yí ní pàtó, láti jẹ́ olùdarí ninu iṣẹ̀ nlá Rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé.”
Ní ọdún méjì sẹ́hìn, Ààrẹ Nelson tẹ̀síwájú:
“Lóni mo tún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ṣe pẹ̀lú agbára pé Olúwa ti sọ fún gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin yíyẹ, tó ní okun láti múra fún sísìn ní míṣọ̀n kan. Fún ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, iṣẹ́ ìsìn ìránṣẹ́ ìhìnrere jẹ́ ojúṣe òyè àlùfáà. Ẹyin ọ̀dọ́mọkùnrin ni a ti pa mọ́ fún àkokò yí nígbàtí kíkójọ Ísráẹ́lì tí a ti ṣèlérí nwáyé.
“Fún ẹ̀yin arábìnrin ọ̀dọ́ àti tí ó ní okun, iṣẹ́ ìránṣẹ́ bákannáà jẹ́ ànfààní kan tó lágbára, ṣùgbọ́n bí ó bá wuni. … Ẹ gbàdúrà láti mọ̀ bí Olúwa bá fẹ́ kí ẹ sìn ní míṣọ̀n kan, Ẹ̀mí Mímọ́ yío sì fèsì sí ọkàn àti iyè yín.”
Àwọn ìtọ́ka wòlíì wa sí pé Olúwa mú àwọn ọ̀dọ́ ìgbà tiwa sí ìpamọ́ fún àkókò yí ninu kíkójọ Isráẹ́lì, àti ìfipè rẹ̀ láti gbàdúrà láti mọ ohun ti Olúwa fẹ́ kí ẹ ṣe jẹ́, ní apákan, àwọn ìtọ́ka sí ayé tí ẹ gbé àti àwọn ìbùkún tí ẹ gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kí a tó bíi yín sí ilẹ̀ ayé yí. Gbogbo wa tí a bí sí orí ilẹ̀-ayé kọ́kọ́ gbé pẹ̀lú Baba Ọ̀run bí àwọn ọmọ ẹ̀mí Rẹ̀. Olúwa sọ fún Mósè pé, “Èmi, Olúwa Ọlọ́run, dá ohun gbogbo … ni ti ẹ̀mí, ṣaájú kí wọn ó tó wà ní ti ara lórí ilè ayé.”
Nígbàtí Ó dá yín ní ti ẹ̀mí, Ó fẹ́ràn yín bíi ọmọkùnrin ati ọmọbìnrin ẹ̀mí Rẹ̀, Ó sì fi ìwà àtọ̀runwá kan ati àyànmọ́ ayérayé sí inú ẹnìkọ̀ọ̀kan yín.
Ní ìgbé ayé ṣaájú ayé ikú yín, “ẹ mú ìdánimọ̀ yín dàgbà ẹ sì mú kí àwọn agbára ìleṣe ti ẹ̀mí yín lé kún síi.” A bùkún yín pẹ̀lú ẹ̀bùn òmìnira, agbára láti ṣe àwọn àṣàyàn fún ara yín, ẹ̀yin sì ṣe awọn ìpinnu pàtàkì, bí irú ìpinnu láti tẹ̀lé ètò ìdùnnú ti Baba Ọ̀run, èyítí ó jẹ́ láti “gba ara àfojúrí kan kí ẹ sì jèrè ìrírí ti ilẹ̀ ayé láti tẹ̀síwájú … ati ní ìgbẹ̀hìn kí ẹ rí àyànmọ́ àtọrunwa [yín] bíi ajogún ìyè ayérayé.” Ìpinnu yi kan ìgbé ayé yín nígbànáà, ninu ìgbé ayé yín ṣaájú ayé ikú, ó sì tẹ̀síwájú láti máa kan ìgbé ayé yín nísisìyí. Bíi ọmọ Ọlọ́run tí ngbé ni ìgbé ayé yín ṣaájú ayé ikú, ẹ “dàgbà ninu ọgbọ́n orí ẹ sì kọ́ láti fẹ́ràn òtítọ́.”
Kí a tó bíi yín, Ọlọ́run yan ọ̀kọ̀ọ̀kan yín láti mú àwọn iṣẹ́ ìhìnrere kan pàtó ṣẹ ní ìgbà ìgbé ayé iku yín ní orí ilẹ̀ ayé. Bí ẹ bá dúró ni yíyẹ, àwọn ìbùkún ti àṣẹ ṣaájú ayé ikú náà yío ró yín ní agbára láti ní onírúurú àwọn ànfààní láti sìn ninu Ìjọ àti láti kópa ninu iṣẹ́ pàtàkì jùlọ tí ó nṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé loni: kikójọ ti Isráẹ́lì. Àwọn ìlérí àti àwọn ìbùkún ti ṣaájú-ayé-ikú wọnnì ni a pè ní yíyàn-tẹ́lẹ̀. “Ẹ̀kọ́ ti yíyàn-tẹ́lẹ̀ ní í ṣe sí gbogbo àwọn ọmọ ti Ìjọ.” Yíyàn-tẹ́lẹ̀ kò fúnni ní ìdánilójú pé ẹ gba àwọn ìpè tàbí àwọn ojuṣe kan pàtó. Àwọn ìbùkún a`ti àwọn ànfààní wọ̀nyí nwá ní ayé yí bí àyọrisí bí ẹ ti lo agbára òmìnira yín ní ọ̀nà òdodo sí, gẹ́gẹ́bí yíyàn-ṣaájú yìn ninu ìgbé ayé yín ṣaájú ayé ikú ṣe wá bí àyọrísí ìṣòdodo. Bí ẹ ti nfi ara yín hàn ní yíyẹ tí ẹ sì ntẹ̀síwájú ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú, ẹ ó gba àwọn ànfààní láti sìn ninu kíláàsì ti Awọn Ọ̀dọ́mọbìnrin tàbí iyejú ti àwọn oyè-àlùfáà yín. Ẹ ó jẹ́ bíbùkún fún láti sìn ninu tẹ́mpìlì, láti di arákùnrin tàbí arabìnrin oníṣẹ́ ìránṣẹ́, àti lati sìn ní mísọ̀n kan bíi ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì.
Kínni ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì láti lépa láti mọ̀ àti kí ẹ sì ní òye yíyàn-tẹ́lẹ̀ yín? Ní ọjọ́ tí àwọn ìbéèrè bá pọ̀, nígbàtí púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀ nlépa láti mọ ìdánimọ̀ wọn tòótọ́, òtítọ́ pé Ọlọ́run mọ̀ wá Ó sì ti bùkún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lọ́kọ̀ọ̀kan ṣaájú kí a tó di bíbí rárá ní orí ilẹ̀ ayé, pẹ̀lú “[awọn] ìwà tó ṣe kókó ti … ìdánimọ̀ ati èrèdí ti ṣaájú-ayé-ikú, ti ayé-ikú, ati ti ayérayé” nmú àlàáfíà dídùn ati ìdánilójú wá sí inú ati ọkàn wa. Mímọ ẹnití ẹ jẹ́ bẹ̀rẹ̀ pẹlú òye àwọn ìbùkún yíyàn-tẹ́lẹ̀ ti Ọlọ́run, tí a ti fi fún yín ṣaájú a tó bí yín rárá ní orí ilẹ̀ ayé yi. Baba wa Ọ̀run nfẹ́ láti fi yíyàn-tẹ́lẹ̀ ti ara ẹni yín hàn sí yín, Òun ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ bí ẹ ti nlépa láti kọ́ ati láti tẹ̀lé ìfẹ́ Rẹ̀.
Mo fẹ̀ràn láti máa ka àwọn ìfiránṣẹ́ Ààrẹ Nelson lórí instágíramù. Ọ̀kan lára àwọn ààyò mi ni ti ogúnjọ́ Oṣù Keje, 2022. Ó kọ pé:
“Mo gbàgbọ́ pé bí Olúwa bá nbá yín sọ̀rọ̀ tààrà, ohun àkọ́kọ́ ti Òun ó ri dájú pé ẹ ní òye rẹ̀ ni ìdánimọ́ yín tòótọ́. Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ̀yin jẹ́ ọmọ ẹ̀mí Ọlọ́run bi ọ̀rọ̀ ti rí gan-an. …
“… Máṣe ṣe àṣìṣe nípa rẹ̀: Agbára yín jẹ́ àtọ̀runwá. Pẹ̀lú aápọn yín ni wíwá, Ọlọ́run yio fún yín ní àwọn ìríran firi nípa ẹnití ẹ le da.”
Njẹ́ mo le ṣe àbápín pẹ̀lú yín bí baba mi ti ayé ti kọ́ mi láti ṣe àwárí ìdánimọ̀ mi ati ètò Ọlọ́run ninu ayé mi?
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Sátidé kan nígbàtí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá, mo nfi ẹ̀rọ gé koríko bíi apákan iṣẹ́ ilé mi ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Nígbàti mo ṣetán, mo gbọ́ tí ìlẹ̀kùn padé ní ẹ̀hìn ilé wa mo sì wò láti rí baba mi tí npè mí láti darapọ̀ mọ́ òun. Mo rìn lọ sí ẹ̀hìnkùlé, ó sì pè mí láti jókòó pẹ̀lú rẹ̀ nii orí àwọn àtẹ̀gùn. Ó jẹ́ òwúrọ̀ rírẹwà kan. Mo ṣì rántí bí ó ti jókóó súnmọ́ mi tóbẹ́ẹ̀ ti àwọn èjìká wa nkanra. Ó bẹ̀rẹ̀ nipa sísọ fúnmi pé òun fẹ́ràn mi. Ó bèèrè ohun tí àwọn àfojúsùn mi jẹ́ nínú ayé. Mo rò pé, “Ó dára. Èyí náà rọrùn.” Mo mọ àwọn ohun méjì dájú: Mo fẹ́ ga sìi, mo sì fẹ́ máa lọ sí ìpàgọ́ léraléra síi. Mo jẹ́ ọkàn tí kò nira. Ó rẹ́rin músẹ́, ó sinmi fún ìgbà díẹ̀, ó sì wí pé: “Steve, mo fẹ́ ṣe àbápín ohun kan pẹ̀lú rẹ tí ó ṣe pàtàkì sí mi. Mo ti gbàdúrà pé Baba wa Ọ̀run yío mú ohun tí mo bá sọ nísisìyí kí ó jẹ́ títẹ̀ láìṣeéparẹ́ mọ́ iyè inú rẹ áti ọkàn rẹ kí o má baà gbàgbé láé.”
Baba mi ní àfiyèsí mi ní kíkún ní àkókò náà. Ó yí ó sì wò mí nínú ojú ó sì wí pé, “Ọmọ, dáàbò bo àwọn àkókò àdáni ti ayé rẹ.” Ìdánudúró gígùn kan wà bí ó ti jẹ́ kí ìtumọ̀ náà ó wọlé jinlẹ̀ sí inú ọkàn mi.
Ó tẹ̀síwájú lẹ́hìnnáà: “Ṣé o mọ̀, àwọn àkókò wọnnì nígbàtí ó jẹ́ pé ìwọ nìkan ṣoṣo ni ó wà ní àyíká àti tí ẹnikẹ́ni míràn kó mọ ohun tí ò nṣe? Àwọn àkókò wọnnì nígbàtí o rò pé, ‘Ohunkóhun tí mo bá ṣe nísisìyí kò kan ẹnikẹ́ni míràn, àfi èmi nìkan ṣoṣo’?”
Lẹ́hìnnáà ó wí pé, “Ju èyíkéyi àkókò míràn lọ ninu ayé rẹ, ohun tí o bá ṣe ninu àwọn àkókò àdáni ti ayé rẹ yío ní ipa títóbijùlọ lórí bí ìwọ ó ti kojú àwọn ìpèníjà ati ìrora-ọkàn tí ìwọ ó dojúkọ; ohun tí o bá sì ṣe ninu àwọn àkókò àdáni ti ayé rẹ yio ni ipa gígajù bákannáà lórí bí ìwọ ó ti kojú àwọn àṣeyọrí ati ayọ̀ tí ìwọ ó ni ìrírí rẹ̀ ju èyíkéyi àkókò míràn lọ ninu ayé rẹ.”
Baba mi gba ohun tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀. Ìró àti dídún ohùn rẹ̀, àti ìfẹ́ ti mo mọ̀lára ninu àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, jẹ́ títẹ̀ láìṣeéparẹ́ mọ́ iyè inú mi áti ní ọkàn mi ní ọjọ́ náà.
Mo ti kọ́ nínu àwọn ọdún pé iṣẹ́ ìyanu títóbijùlọ ti ọjọ́ náà ni orí àwọn àtẹ̀gùn ti ibùgbé ìgbà èwe mi ni pé, ninu àwọn àkókò àdáni ti ayé mi, mo le tọ Ọlọ́run lọ ninu àdúrà láti gba ìfihàn. Baba mi nkọ́ mi bi mo ti le kọ́ ẹ̀kọ́ nipa àwọn ìbùkún Ọlọ́run tí a ti yàn-tẹ́lẹ̀. Ninu àwọn àkókò àdáni wọnnì, mo kọ́ pé Ìwé Ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Mo kọ́ pé Ọlọ́run ti yàn mí tẹ́lẹ̀ láti sìn ní mísọ̀n kan. Mo kọ́ pé Ọlọ́run mọ̀ mí àti pé Ó ngbọ́ Ó sì ndáhùn àwọn àdúrà mi. Mo kọ́ pé Jésù ni Krístì, Olùgbàlà àti Olùràpadà wa.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ṣe àwọn àṣìṣe púpọ̀ láti ọjọ́ mọ́nigbàgbé náà pẹ̀lú baba mi, títiraka láti dáàbò bo àwọn àkókò àdáni ti ayé mi ti dúró bíi ìdákọ̀ró ní ààrin àwọn ìjì ayé, ó sì ti ró mi lágbára láti wá èbúté àìléwu àti ìwòsàn, àwọn ìbùkún ti nfúnni lókun ti ìfẹ́ àti ẹbọ ọrẹ ètùtù ti Olùgbàlà
Ẹ̀yin ọ̀dọ́ arákùnrin ati arábìnrin mi, bí ẹ ti ndáàbò bo àwọn àkókò àdáni ti ayé yín pẹ̀lú ìdárayá rere, fífetísí àwọn orin tó ngbéniga, kíka àwọn ìwé mímọ́, gbígba àdúrà tó nítumọ̀ dèèdè; àti ṣíṣe akitiyan làti gbà ati lati ronú ì̀bùkún pátríákì yín jinlẹ̀, ẹ ó gba ìfihàn. Ní àwọn ọ̀rọ̀ Ààrẹ Nelson, ojú yín yío di “lílà kedere sí òtítọ́ pé ayé yí nítòótọ́ jẹ́ àkókò nigbàtí ẹ le pinnu irú ayé ti ẹ̀yin fẹ́ gbé títí láé.”
Baba wa Ọ̀run yíó dáhùn àwọn àdúrà yín, nípàtàkì àwọn àdúrà ti ẹ gbà ninu àwọn àkókò àdáni ti ayé rẹ. Òun yio fi àwọn ẹ̀bùn àti àwọn tálentì yíyàn-tẹ́lẹ̀ yín hàn sí yín, ẹ̀yin ó sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀ yíkà yín, bí ẹ̀yin bá bèèrè nitòótọ́ tí ó sì jẹ́ nitòótọ́ ni ẹ ní ìfẹ́ inú láti mọ̀. Bí ẹ ti ndáàbò bo àwọn àkókò àdáni ti ayé yín, ìkópa yín ninu àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú ti ìhìnrere yío túbọ̀ nítumọ̀ síi. Ẹ ó so ara yín pọ̀ ní kíkún síi pẹ̀lú Ọlọ́run ninu àwọn májẹ̀mú tí ẹ ndá pẹ̀lú Rẹ̀, ẹ ó sì di gbígbé sókè láti ní ìrètí, ìgbàgbọ́, àti ìdánilójú gíga síi ninu áwọn ìlérí tí Ó ti ṣe fún yín. Njẹ́ ẹ fẹ́ láti mọ ètò Ọlọ́run fún yín? Mo jẹ́ri pé Ó fẹ́ kí ẹ mọ̀, Ó sì mí sí wòlíì Rẹ̀ sí aráyé láti pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wa láti gbàdúrà kí a sì gba àwọn ìrírí tó nṣíni-lójú yí fún ara wa. Mo jẹ́ri sí jíjẹ́ òtítọ́ àti agbára ẹbọ ètùtù ti Olùgbàlà wa tí ó mú kí ó ṣeéṣe láti gbé àti láti gbádùn gbogbo àwọn ìbùkún tí a ti yàn-tẹ́lẹ̀, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.