Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ayọ̀ Gígajù Kan
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


15:37

Ayọ̀ Gígajù Kan

Njẹ́ kí gbogbo wa wá kí a sì rí ayọ̀ gígajù tí ó nwá látinú ìfọkànsìn ìgbésí ayé wa sí Baba Ọ̀run àti àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀.

Mo ti ní ìbùkún nlá ti sísọ̀rọ̀ ní Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò fún àwọn díkédì mẹ́ta nísisìyí. Ní ìgbà náà, a ti bi mí ní àwọn ìbèèrè tí ó wà ní ìbámu sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní àyíká ayé. Láìpẹ́, ìbèèrè kan pàtàkì nwá léraléra. Ó máa nlọ bí ohunkan báyìí: “Alàgbà Uchtdorf, mo fetísílẹ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ tókọjá ṣùgbọ́n … èmi kò gbọ́ ohunkóhun nípa ibùdókọ̀ ọkọ̀ òfúrufú?”

Ó dára, lẹ́hìn òní, èmi lè má tilẹ̀ gbọ́ ìbèèrè náà fún ìgbà pípẹ́.

Lórí “Ṣíṣubú Ire-ayọ̀ ti Ìkúùkù Ìpín-òòrùn”

Ó le láti gbàgbọ́ pé ó jẹ́ ọgọ́fà ọdún sẹ́hìn nígbàtí Wilbur àti Orville Wright kọ́kọ́ gbéra sókè tí wọ́n sì fò lórí yanrìn ti Kitty Hawk, Àríwá Carolina. Fífò kúkurú mẹ́rin ní Oṣù Kejìlá ọjọ́ náà yí ayé padà ó sì ṣí ìlẹ̀kùn sí ọ̀kan lára àwọn ọgbọ́n-titun títóbijùlọ nínú àkọọ́lẹ̀-ìtàn ayé.

Fífò léwu ní àwọn ọjọ́ ìṣíwájú wọnnì. Àwọn arákùnrin náà mọ èyí. Bẹ́ẹ̀náà sì ni baba wọ́n, Milton. Lotitọ, ẹ̀rù pípàdánù ọmọkùnrin rẹ̀ méjì nínú ìjàmbá fífò kan báà gidi tí wọ́n fi ṣe ìlérí fun pé wọn kò ní fò papọ̀ mọ́ láéláé.

Wọn kò sì ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́—pẹ̀lú àyọkúrò kan. Ọdún méje lẹ́hìnnáà ọjọ́ onítàn náà ní Kitty Hawk, Milton Wright fúnni ní ìfọwọ́sí rẹ̀ nígbẹ̀hìn ó sì nwò bí Wilbur àti Orville ti fò lọ papọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́. Lẹ́hìn bíbalẹ̀, Orville yí baba rẹ̀ lọ́kàn padà láti mú fífò àkọ́kọ́ àti ọ̀kanṣoṣo lọ àti láti rí ohun tí ó dàbí.

Bí ọkọ̀ òfúrufú ti gbéra kúrò nílẹ̀, ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rin Milton wà ní ìrọ̀mọ́ nínú ìfihàn gbangba fífò náà tí gbogbo ẹ̀rú ti fi í sílẹ̀. Orville rẹrin bí baba rẹ ti kígbe pẹ̀lú ìdùnnú, “Gígajù, Orville, Gígajù!”

Èyí ni ọkùnrin kan ẹni bí ọkàn mi!

Bóyá èrèdí náà tí mò fi nsọ̀rọ̀ nípa ibùdókọ̀ ọkọ̀ òfúrufú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni pé mo mọ ohunkan nípa ohun tí Wright ní ìmọ̀lára rẹ̀. Èmi bákannáà ti “yọ̀ nínú ìsopọ̀ ẹ̀rù ti ayé tí mo sì jó sí òfúrufú lórí ẹ̀rín ìyẹ́-apá onífàdákà.”

Fífò àkọ́kọ́ àwọn Arákùnrin Wright, èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní bíi ọdún mẹtadinlogoji ṣíwájú ìbí mi, ṣí àwọn ilẹ̀kùn ti ìdáwọ́lé, ìyanu, àti ayọ̀ mímọ́ sínú ayé mi.

Àti pé síbẹ̀síbẹ̀, bí ayọ̀ náà ti yanilẹ́nu tó, àní irú ayọ̀ gígajù kan wà. Ní òní, nínú ẹ̀mí ti igbe ìdùnnú Milton Wright, “Gígajù, Orville, gígajù,” èmi yíò fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa ayọ̀ gígajù yí—ibi tí ó ti wá, bí ó ti nwọnú ọkàn wa, àti bí a ṣe lè ní ìrírí rẹ̀ ní ìwọ̀n títóbijù.

Gbogbo Ìfojúsí ti Wíwà-láàyè Ènìyàn

Bóyá ó nlọ láì wípé gbogbo ènìyàn nfẹ́ láti ní inúdídùn. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, bákannáà ó nlọ láì wípé kìí ṣe gbogbo ènìyàn ní ó ní inúdídùn. Pẹ̀lú ìbanújẹ́, ó dàbíì pé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn, ìnúdídùn le láti rí.

Kínidí èyíìni? Bí inúdídùn bá jẹ́ ohun kan tí àwa ènìyàn nfẹ́ jùlọ, kínidí tí a kò fi ní àṣeyọrí ní wíwá a rí? Láti tún orin orílẹ̀-èdè kan kọ, bóyá a ti nwá ayọ̀ ní gbogbo àwọn ibi tí kò tọ́.

Níbo Ni Mo Ti Lè Rí Inúdídùn?

Ṣíwájú a sọ̀rọ̀ bí a ó ti rí ayọ̀, ẹ fi àyè gbà mí láti jẹ́wọ́ pé írẹ̀wẹ̀sì àti àwọn ìṣòrò ọpọlọ míràn àti àwọn ìpènijà ẹ̀dùn ọkàn jẹ́ òtítọ́, àti pé ìdáhùn náà kìí kàn ṣe, “Gbìyànjú láti jẹ́ onínúdídùn si.” Èrèdí mi ní òní kìí ṣe láti dínkù tàbí mú ọ̀ràn ìlera ọpọlọ yẹpẹrẹ. Bí ẹ bá dojúkọ irú àwọn ìpènijà bẹ́ẹ̀, mo kaanu pẹ̀lú mo sì dúró ní ẹ̀gbẹ́ yín. Fún àwọn ènìyàn kan, rírí ayọ̀ lè pẹ̀lú wíwá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ onímọ̀ tí a kọ́ ní ìlera ọpọlọ tí wọ́n fi ayé wọn sí ṣíṣe ìtọ́jú àrùn. A níláti ṣọpẹ́ fún irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀.

Ìgbésí ayé kìí ṣe ìtò-ẹsẹẹsẹ àìlópin ti ẹ̀dùn ọkàn gíga. “Nítorí o di dandan, pé kí àtakò wà nínú ohun gbogbo.” Àti pé bí Ọlọ́run Fúnrarẹ̀ bá sọkún, bí àwọn ìwé-mímọ́ ti tẹnumọ pé Ó ṣe, nígbànáà bẹ́ẹ̀ni ẹ̀yin àti èmi yíò sọkún bákannáà. Níní ìmọ̀lára ìbànújẹ́ kìí ṣe àmì ìjákulẹ̀. Nínú ayé yí, ó kéré jù, ayọ̀ àti ìkorò jẹ́ àwọn ojúgbà àìlèyàsọ́tọ̀. Bíiti gbogbo yín, mo ti ní ìmọ̀lára ìjákulẹ̀, ìkorò, ìbànújẹ́, àti àbámọ̀ tèmi.

Bákannáà, mo ní ìrírí ọ̀tun ológo fún arami tí ó nkún ọkàn mi pẹ̀lú ayọ̀ jíjinlẹ̀ gidi tí a kò fi lè paá mọ́ ní ìdínkù. Mo ti ṣàwárí fúnrami pé ìgbẹ́kẹ̀lé àláfíà yí nwá látinú títẹ̀lé Olùgbàlà àti rírìn ní ọ̀nà Rẹ̀.

Àláfíà tí Òun nfún wa kìí ṣe bíi ti ohun tí ayé nfúnni. Ó jẹ́ dídára. Ó jẹ́ gígajù àti mímọ́jù. Jésù wípé, “Èmi wá kí wọ́n lè ní ìyè, àti kí wọ́n lè níi lọ́pọ̀lọpọ̀ síi.”

Ìhìnrere ti Jésù Krístì nítòótọ́ jẹ́ “ìròhìn rere ayọ̀ nlá”! Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ àìlẹ́gbẹ́ ìrètí kan! Ọ̀rọ̀ kan nípa gbígba àjàgà àti gbígbe-ẹ̀rù sókè. Nípa ìkórajọ-fífúyẹ̀. Nípa ojúrere tọ̀run, òye gígajù, ààbò ayérayé, àti ògo àìlópin!

Ayọ̀ ni èrèdí gan nípa ètò Ọlọ̀run fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Ó jẹ́ ohun tí a bíi yín fún—“pé [ẹ̀yin] lè ní ayọ̀”! a gbé e yín ga fún èyí!

Baba wa ní Ọ̀run kò fi ipa-ọ̀nà sí inúdídùn pamọ́. Kì í ṣe ìkọ̀kọ̀. Ó wà fún gbogbo ènìyàn!

Ó jẹ́ ìlérí sí àwọn tí wọ́n rìn ní ipa-ọ̀nà ipò-ọmọlẹ̀hìn, tí wọ́n tẹ̀lé àwọn ìkọ́ni àti àpẹrẹ Olùgbàlà, tí wọn pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, tí wọ́n sì bu-ọlá fún àwọn màjẹ́mú tí wọ́n dá pẹ̀lú Rẹ̀. Irú ìlérí alámì kan ni èyí!

Ọlọ́run Ní Ohunkan Síi láti Fúnni

Gbogbo wa mọ àwọn ènìyàn tí wọ́n wípé wọn kò nílò Ọlọ́run láti ní inúdídùn, pé inú wọn dùn tó láìsí ẹ̀sìn.

Mo jẹ́wọ́ mo si fi ọ̀wọ̀ fún àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí. Àyànfẹ́ Baba wa ní Ọ̀run nfẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ ní inúdídùn púpọ̀ bí ó ti ṣeéṣe, nítorínáà Òun ti kún inú ayé yí pẹ̀lú ẹwà, àwọn ìgbádùn àti ìdùnnú dídára, “méjèèjì láti mú ojú wuni àti láti … mú ọkàn yọ̀.” Fún mi, fífò nmú ìnúdídùn púpọ̀ wá. Àwọn ẹlòmíràn rí i nínú orin, iṣẹ́-ọnà, ohun tí a fẹ́ràn, tàbí àbínibí.

Ní pípín ìròhìn rere ayọ púpọ̀ ti Olùgbàlà, a kò yọ eyikeyi lára àwọn orísùn ayọ̀ wọ̀nyí kúrò. A kàn nsọ pé Ọlọ́run ní ohunkan síi láti fún wa ni. Ayọ̀ jíjinlẹ̀ síi àti gígajù—ayọ̀ tí ó tayọ ohunkóhun tí ayé yí níláti fúnni. O jẹ́ ayọ̀ tí ó nfarada ìrora-ọkàn, tí ó nwọnú ìkorò, tí ó sì ndín dídánìkanwà kù.

Inúdídùn ti ayè, nípa àtakò, kìí pẹ́. Kò lè pẹ́. Ó jẹ́ àbínibí ti gbogbo àwọn ohun ti ayé láti gbèrú dàgbà, jẹrà, gbó, tàbí di ìbàjẹ́. Ṣùgbọ́n ayọ̀ tọ̀run jẹ́ ayérayé, nítorí Ọlọ́run jẹ́ ayérayé. Jésù Krístì wá láti gbé wa kúrò nínú ti ara kí ó sì rọ́pò ìdíbàjẹ́ pẹ̀lú àìdíbàjẹ́. Òun nìkan ni ó ní agbára, àti pé ayọ̀ Rẹ̀ nìkan ni ó wà títí.

Bí ẹ bá ní ìmọ̀ pé irú ayọ̀ púpọ̀ yí lè wà nínú ayé yín, mo pe yín láti bẹ̀rẹ̀ lórí ìrìn-àjò ti títẹ̀lẹ́ Jésù Krístì àti Ọ̀nà Rẹ̀. Ó jẹ́ ìrìn-àjò ìgbésí-ayé kan—àti ìkọjá. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ kí ndaba àwọn ìgbésẹ̀ bíbẹ̀rẹ̀ díẹ̀ lórí ìrìn-àjò yíyẹ ti ṣíṣàwárí ayọ̀ mímọ́ yí.

Súnmọ́ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Ṣé ẹ rántí obìnrin nínú Májẹ̀mú Titun tí ó farada àrùn ìsun-ẹ̀jẹ̀ fún ọdún méjìlá? Ó ti lo gbogbo ohun tí ó ní lórí àwọn olùwòsàn, ṣùgbọ́n àwọn nkan kàn nburú si ni. Ó ti gbọ́ nípa Jésù; agbára Rẹ̀ láti wòsàn ni a mọ̀ dáadáa. Ṣùgbọ́n ṣe Òun lè wòó sàn? Àti pé báwo ni ó ṣe le dé itòsí Rẹ̀? Àìsàn rẹ̀ mu di “àláìmọ́” gẹ́gẹ́bí òfin Mósè, nítorínáà a sì mu láti dúró síta kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn.

Dídé ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ní gbangbà àti bíbèèrè fún ìwòsàn dàbí kìí ṣe ara rẹ̀ rárá.

Síbẹ̀, ó ronú pé, “Bí mo bá sá lè fọwọ́kan aṣọ rẹ̀, ara mi yíò dá.”

Nígbẹ̀hìn, ìgbàgbọ́ rẹ̀ borí ẹ̀rù rẹ̀. Ó fi ìgboyà kọ ìbáwí àwọn ẹlòmíràn ó sì tẹ̀síwájú Olùgbàlà.

Nígbẹ̀hìn, ó wà ní àrọ́wọ́tó. Ó na ọwọ́ rẹ̀.

Ó sì rí ìwòsàn.

Njẹ́ àwa kìí fi ìgbà míràn dà bí obìnrin yí?

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èrèdí lè wà tí a fi nlọ́ra láti súnmọ́ Olùgbàlà. A lè dojúkọ ẹ̀sín tàbí ìdálẹ́bi láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Nínú ìgbéraga wa, a lè mú ìṣeéṣe ohunkan tí ó rọrùn gidi jẹ́ oníyì púpọ̀ gidi. A lè ronú pé ipò wa bákannáà kò mú wa di aláìyẹ kúrò nínú ìwòsàn Rẹ̀—pé jíjìnà rẹ̀ ti pọ̀jù tàbí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ti pọ̀jù.

Bíiti obìnrin yí, mo ti kọ́ pé bí a bá súnmọ́ Ọlọ́run tí a sì nawọ́ jáde láti fọwọ́ kàn Án, nítòótọ́ a lè rí ìwòsàn, àláfíà, àti ayọ̀.

Wá a A

Jésù kọ́ni, “Ẹ wá, ẹ̀yin ó sì rí.”

Mo gbàgbọ́ pé gbólóhùn jẹ́jẹ́ yí kìí ṣe ìlérí ti-ẹ̀mí nìkan; ó jẹ́ ẹ̀là-ọ̀rọ̀ òtítọ́.

Bí a bá wá èrèdí kiri láti bínú, láti ṣiyèméjì, láti ní ìkorò tàbí àdánìkanwà, a ó rí wọn.

Bákannáà, bí a bá wá ayọ̀—bí a bá wo àwọn èrèdí láti yayọ̀ kí a sì fi inúdídùn tẹ̀lé Olùgbàlà, a ó rí wọn.

Ó ṣọ̀wọ́n kí a tó rí ohunkan tí a kò wá kiri.

Ṣé ẹ nwá ayọ̀?

Ẹ wá, ẹ̀yin ó sì rí.

Ẹ Gbé Ẹrù Wúwo Arayín

Jésù kọ́ni, “Ó jẹ́ bíbùkún síi láti fúnni ju láti gbà.”

Ṣé ó lè jẹ́ èyìinì nínú ìwákiri wa fún ayọ̀, ọ̀nà dídárajùlọ láti rí i ni láti mú ayọ̀ wá fún àwọn ẹlòmíràn.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ẹ mọ̀ èmi sì mọ̀ pé òtítọ́ ni èyí! Ayọ̀ dà bí àgbá ìyẹ̀fun tàbí ìgò òróró tí kò ní tán rárá. Ayọ̀ òtítọ́ ndi púpọ̀ nígbàtí a bá pín in.

Kò nílò ohun ọlọ́lá kankan tàbí díjú.

A lè ṣe ohun ìrọ̀rùn.

Bíiti gbígbàdúrà fún ẹnìkan pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa.

Fífúnni ní ìyìn àtinúwá.

Ríran ẹnìkan lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìyárí, ọ̀wọ̀, iyì, àti ìfẹ́ni.

Pípín ìwé-mímọ́ tí a fẹ́ràn àti ohun tí ó túmọ̀ sí fún wa.

Tàbí àní kí a kàn fetísílẹ̀.

“Nígbàtí ẹ bá wà nínú ìsìn ọmọlàkejì yín ẹ wà nínú ìsìn Ọlọ́run yín,” Ọlọ́run ó sì san ẹ̀san inúrere yín pẹ̀lú oore. Ayọ̀ tí ẹ bá fún àwọn ẹlòmíràn yíò padà sí yín ní “ìwọ̀n rere, kì mọ́lẹ̀, kí ó sì gbọ̀nrìrì papọ̀, àti títẹ̀ mọ́lẹ̀.”

Kíni A Ó Ṣe Nígbànáà?

Ní àwọn ọjọ́, ọ̀sẹ̀, àti oṣù tí ó nbọ̀, njẹ́ kí npè yín láti:

  • Lo àkokò nínú òdodo, ìtiraka ọkàn-kíkún láti súnmọ́ Ọlọ́run.

  • Wá aápọn fún àkokò ìrètí, àláfíà, àti ayọ̀ ojojúmọ́.

  • Mú ayọ̀ wá fún àwọn ẹlòmíràn ní àyíká yín.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, bí ẹ ti nwá ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún lílóye jíjinlẹ̀ ètò ayérayé Ọlọ́run, tí ẹ̀ ntẹ́wọ́gba àwọn ìfipè wọ̀nyí, tí ẹ sì tiraka láti rìn ní Ọ̀nà Rẹ̀, ẹ ó ní ìrírí “àláfíà Ọlọ́run, èyí tí ó kọjá òye,” àní ní àárín àwọn ìkorò. Ẹ ó ní ìwọ̀n ìmọ̀lára títóbijù ti Ọlọ́run tí ó kọjá ìfẹ́ tí ó nrú nínú ọkàn wa. Ọ̀tun ìmọ́lẹ̀ sẹ̀lẹ́stíà yíò wọnú àwọn òjìji ti àdánwò yín, àti pé ẹ ó bẹ̀rẹ̀ láti tán àwọn ògo àìlèsọ wò àti àwọn ìyanu ti àìrí, pípé, àyíká tọ̀run. Ẹ ó ní ìmọ̀lára ẹ̀mí yín tí ó ngbé sókè látinú ìwà-àgbà ti ayé yí.

Àti bíiti Milton Wright rere, bóyá ẹ̀yin yíò gbé ohùn yín sókè ní yíyayọ̀ àti kíké, “Gígajù, Baba, gígajù!”

Njẹ́ kí gbogbo wa wá kí a sì rí ayọ̀ gígajù tí ó nwá látinú ìfọkànsìn ìgbésí ayé wa sí Baba Ọ̀run àti àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀. Èyí ni àdúrà àtinúwá àti ìbùkún mi ni orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. John Gillespie Magee Jr., “Fífò Gíga,” poetryfoundation.org.

  2. Wo Christopher Klein, “Àwọn ohun mẹwa nípa Àwọn Arákùnrin Wright,” Àkọọ́lẹ̀-ìtàn, Mar. 28, 2023, history.com.

  3. Magee, “Fífò Gíga.”

  4. Ọgọrun mẹrinlelogun ọdún sẹ́hìn, Aristotle ṣàkíyèsí pé ìdùnnú ni ohun kan tí gbogbo ènìyàn fẹ́ràn jùlọ. Nínú ìhìn rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Ìwà-rere Nicomachean, ó kọ́ni pé ire títóbijùlọ nínú ayé ni ohun tí à nlépa bí òpin kan fúnrarẹ̀ (bí àtakò sí àwọn ohun wọnnì tí a nlépa tí ó jẹ́ ọ̀nà sí àwọn òpin míràn). Ìdùnnú, ju gbogbo òmíràn, ni irú ohun kan lásán. “À nfẹ́ ìnúdídùn nígbàgbogbo fún ire ti ararẹ̀,” ni ó wí, “kìí sì ṣe bí ọ̀nà sí ohunkan míràn” (The Nicomachean Ethics of Aristotle, trans. J. E. C. Weldon [1902], 13–14).

  5. Wo Harry Enten, “Inúdídùn Amẹ́ríkà Dé Igbasilẹ Awọn Irẹlẹ,” CNN, Oṣù Kejì Ọjọ́ Kejì, 2022, cnn.com; tun wo Tamara Lush, “Amẹrika Ni Ainidunnu Ti Wọn Ti Ni 50 Ọdun,” Associated Press, Okudu 16, 2020, apnews.com; “Bíríbírí Títóbi: Ní 2023, Àwọn Òṣìṣẹ́ Kò Ní Inúdídùn Rí Ju Titẹ́lẹ̀. Kínìdí?” BambooHR, bamboohr.com.

  6. Wo Wanda Mallette, Bob Morrison, àti Patti Ryan, “Nwá Ìfẹ́ (ní Àwọn Ibi Tí Kò Tọ́)” (1980).

  7. 2 Néfì 2:11.

  8. Wo Jòhánnù 11:35; Mósè 7:28–37.

  9. Wo 2 Néfì 2:11.

  10. Wo Jòhánnù 14:27.

  11. Jòhánnù 10:10.

  12. Lúkù 2:10, New Revised Standard Version.

  13. Wo Máttéù 11:28–30.

  14. 2 Néfì 2:25.

  15. Bí ẹ bá ní àníyàn kankan nípa bóyá tàbí pé bóyá Baba ní Ọ̀run yíò tẹ́wọ́gbà yín kí ó sì fi àyè gba yín láti gba ayọ̀ Rẹ̀, mo pè yín láti ka òwe Krístì nípa ọmọ oninakuna pẹ̀lú àdúrà (wo Luku 15:11–32). Nínú òwe náà, a kọ́ bí Baba wa Ọ̀run ṣe ní ìmọ̀lára nípa àwọn ọmọ Rẹ̀ àti bí Òun ṣe dúró tí ó sì nṣe ayẹyẹ ìpadàbọ̀ wa lẹ́hìn tí a bá ti ṣákolọ kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀! Láti ìgbà tí a ti “wá fúnrawa” (wo ẹsẹ 17) tí a sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjó sílé, Òun yíò rí wa, nítorí Ó dúró ní wíwò àti dídúró. Àti pé ohun tí Ó ndúró fún? Fún wa! Bí a ti nfà súnmọ́ Ọ, Òun yíò ṣe ayẹyẹ ìpadàbọ̀ wa yíò sì pè wá ní Ọmọ Rẹ̀.

  16. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 59:18. Ìfihàn yí bákannáà ṣe àlàyé, “Ó dùn mọ́ Ọlọ́run nínú pé Òun ti fúnni ní gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí fún ènìyàn; nítorí fún ìdí èyí ni a ṣe dá wọn” (ẹsẹ 20).

  17. Sí àwọn wọnnì tí wọ́n nfà súnmọ́ Ọlọ́run, Ó fún wọn ní ìlérí Ọlọ́lá yí pé: “Èmi ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ yín” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 88:63; bákannáà wo Jákọ́bù 4:8).

  18. Wo Markù 5:24–34.

  19. Wo Ìtumọ̀ Ọ̀rọ̀ Bíbélì, “Mímọ́ àti Àìmọ́.”

  20. Márkù 5:28.

  21. Máttéù 7:7.

  22. Nípa gbígbé àjàgà ara wa, a “nmú àṣẹ Krístì ṣẹ” (Galatians 6:2; bákannáà wo Mosiah 18:8).

  23. Ìṣe Àwọn Àpóstélì 20:35.

  24. Wo 1 Àwọn Ọba 17:8–16.

  25. Mòsíàh 2:17.

  26. Nínú Ìwààsú rẹ̀ sí áwọn ará Rómù, Páùlù sọ wípé Ọlọ́run “yíò fi fún gbogbo ẹnikọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́bí àwọn ìṣe rẹ̀: sí àwọn tí wọ́n fi sùúrù tẹ̀síwájú ní ṣíṣe rere láti wá ògo àti ọlá àti àìkú, ìyè ayérayé: … ògo, ọlá, àti àláfíà, sí gbogbo ẹni tí ó ṣiṣẹ́” (Romans 2:6–7, 10).

  27. Lúkù 6:38. Ìgbàlà wa àti ìdùnnú ayérayé gan lè dálé àánú wa àti inúrere sí àwọn ẹlòmíràn (wo Máttéù 25:31–46).

  28. Lúkù 3:10.

  29. Fílíppì 4:7.