Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Májẹ̀mú Ìgbẹ́kẹ̀lé nípasẹ̀ Jésù Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Májẹ̀mú Ìgbẹ́kẹ̀lé nípasẹ̀ Jésù Krístì

Nígbàtí a bá wọ ilé Olúwa, à nbẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò mímọ́ kan nípa ikẹkọ láti di ọmọẹ̀hìn gígajù áti mímọ́jù ti Krístì.

Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin, mo gbàdúrà pé kí a lè di àtúnbí níti-ẹ̀mí nípa àwọn ọ̀rọ̀ ìmísí tí a ó gbọ́ láti ẹnu àwọn olórí wa ní òpin ọ̀sẹ̀ yí kí a sì yọ̀ nínú ohun tí mo nifẹ láti pè ní “májẹ̀mú ìgbẹ́kẹ̀lé nípasẹ̀ Jésù Krístì.” Ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ yí ni jẹ́jẹ́ àní ìdánilójú tó dájú nípa gbígba àwọn ìbùkún tí Ọlọ́run ṣe ìlérí fún àwọn wọnnì tí wọ́n pa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́ tí a sì nílò gidi ní àárín àwọn ipò pípeniníjà ti ọjọ́ wa.

Kíkọ́ àwọn ilé Olúwa káàkiri àgbáyé, lábẹ́ ipò ìmísí olórí Ààrẹ Russell M. Nelson, ti mú kí ayọ̀ nlá wá ní àárín àwọn ọmọ Ìjọ tí ó sìn dúró bí àmì pàtàkì ti gbígbòòrò ìjọba Olúwa.

Ríronú lórí ìrírí ìmísí ìyanu níbi ìyàsímímọ́ ti Tẹ́mpìlì Odò Feather California ní Oṣù Kẹwa tó kọjá, ó yàmílẹ́nú nígbàmíràn bí a bá nsọnù sínú ìdùnnú ti níní àwọn tẹ́mpìlì titun nínú àwọn ìlú wa àti àwọn ìletò tí a sì npa èrèdí mímọ́jù tí àwọn tẹ́mpìlì npèsè tì.

Àkọlé iwájú tẹ́mpìlì kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀là-ọ̀rọ̀: “Ìwà-mímọ́ sí Olúwa.” Àwọn ọ̀rọ̀ ìmísí wọ̀nyí jẹ́ ìpè kedere kan pé nígbàtí a bá wọ ilé Olúwa, à nbẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò mímọ́ kan nípa ikẹkọ láti di ọmọẹ̀hìn gígajù áti mímọ́jù ti Krístì. Bí a ti à ndá àwọn májẹ̀mú nínú ìwà-mímọ́ níwájú Ọlọ́run tí a sì nfarasìn láti tẹ̀lé Olùgbàlà, à ngba agbára láti yí ọkàn wa pada, tún àwọn ẹ̀mí wa ṣe, àti láti mú ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Rẹ̀ jinlẹ si. Irú iṣe náà nmú ìyàsímímọ́ wá sí ọkàn wa ó sì ndi ìdè mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run àti Jésù Krístì, ẹni tí ó ṣe ìlérí pé a lè jogún ẹ̀bùn ìyè ayérayé. Àbájáde ìrìn-àjò mímọ́ yí ni pé à ngba ìgbẹ́kẹ̀lé mímọ́jù àti gígajù kan fún ọjọ́-dé-ọjọ́ wa a sì ngbé nínú àwọn májẹ̀mú tí a dá nípasẹ̀ Jésù Krístì.

Irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀ ni ténté ti ìsopọ̀ àtọ̀runwá wa pẹ̀lú Ọlọ́run ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú ìfọkànsìn wa sí àti ìmoore fún Jésù Krístì àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀ pọ̀ si. Ó ndá ààbò bo okun wa láti nifẹ àti láti sin àwọn ẹlòmíràn, kí a sì fún ẹ̀mí wa lókun láti gbé nínú ayé àìmọ́ tí ó ndúdú si lọ́pọ̀lọpọ̀ tí ó sì jẹ́ àìnírètí. Ó nfún wa lágbára láti borí àwọn èso iyèméjì àti àìní-ìrètí, ẹ̀rù àti ìjákulẹ̀, ìrora-ọkàn àti àìnírètí tí ọ̀tá gbogbo ngbìyànjú láti yí wọnú ọkàn wa, nípàtàkì nígbàtí ìgbé ayé bá le, àwọn àdánwò jẹ́ gígùn, tàbí àwọn ipò tí ó le. Ẹsẹ bíbélì kan fúnni ní àmọ̀ràn dídára fún ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa bí a ti ngbaralé afẹ́fẹ́ líle àwọn ìpènijà ayé ti òní: “Nítorínáà máṣe sọ igbẹ́kẹ̀lé rẹ nù.”

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, àwọn wọnnì tí wọ́n jèrè ìgbẹ́kẹ̀lé tòótọ́ nínú àwọn májẹ̀mú tí a dá nínú ilé Olúwa nípasẹ̀ Jésù Krístì gba ọ̀kan lára ipa alágbára jùlọ tí a lè ní àyè sí nínú ayé yí.

Bí a ti nṣe àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì nínú Wá, Tẹ̀lé Mi ọdún yí, a ti jẹri bí Néfì ti ṣàpẹrẹ irú agbára májẹ̀mú ìgbẹ́kẹ̀lé dáradára yí nípasẹ̀ ìṣòtítọ́ rẹ̀ nígbàtí ó dojúkọ àwọn ìfàsẹ́hìn àti ìpènijà, bíi gbígba àwọn àwo bí a ti paláṣẹ nípasẹ̀ Olúwa. Néfì, bíótilẹ̀jẹ́pé ó ní ìbànújẹ́ púpọ̀ jọjọ fún ẹ̀rù àti àìní ìgbàgbọ́ Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì, ó dúró ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Olúwa yíò gba àwọn àwo náà fún wọn. Ó wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀, “Bí Olúwa ti mbẹ, àti bí àwa ti mbẹ, àwa kì yíò sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ bàbá wa nínú ijù títí àwa ó fi ṣe ohun tí Olúwa ti pàṣẹ fún wa parí.” Nítorí ìgbẹ́kẹ̀lé Néfì nínú àwọn ìlérí Olúwa, ó le ṣe àṣeyọrí ohun tí a paláṣẹ fún láti ṣe. Lẹ́hìnáà, nínú ìran rẹ̀, Néfì ti kíyèsí ipá irú ìgbẹ́kẹ̀lé yí, ó kọ pé “Èmi, Néfì, kíyèsí agbára Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, tí ó sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn mímọ́ ti ìjọ Ọ̀dọ́-àgùtàn náà, àti sórí àwọn ènìyàn májẹ̀mú ti Olúwa, … wọ́n sì gbáradì pẹ̀lú òdodo àti pẹ̀lú agbára Ọlọ́run nínú ògo nlá.”

Mo ti rí àwọn ìlérí ìfẹ́ni àti agbára Olúwa tí ó nṣàn sínú ìgbé ayé àwọn ọmọ Ọlọ́run lakọkọ, tí ó nfún wọn lókun láti dojúkọ àwọn ipò ìgbé ayé. Ní ọjọ́ náà ìyàwó mi wá sílé lẹ́hìn ìjọ́sìn rẹ̀ nínú tẹ́mpìlì ó sì wí fún mi bí òun ti ní ìfọwọ́tọ́ jíjinlẹ̀ nípa ohun tí ó ní ìrírí níbẹ̀. Bí ó ti wọnú ilé Olúwa, ó rí ọkùnrin kan lọ́rí àga-yíyí tí ó nrin díẹ̀díẹ̀ àti obìnrin kan tí ó nrìn pẹ̀lú ìṣòrò nlá ní lílo ẹgba, tí ó nfi pẹ̀lú ìgboyà wá láti jọ́sìn Olúwa nínú ilé Rẹ̀. Bí ìyàwó mi ṣe rìn wọnú ibi ìgbaniwọlé, ó rí arábìnrin rere kan ẹnití ó sọ apá kan nù tí ó sì ní apákan ara apá míràn nìkan tí ó nṣe iṣẹ́kíṣẹ́ tí a fun dáradára àti níti sẹ̀lẹ́stíà.

Bí ìyàwó mi àti èmi ṣe nsọ̀rọ̀ nípa ìrírí náà, a parí pé ìgbẹ́kẹ̀lé mímọ́ àti àtinúwá nínú àwọn ìlérí tí Ọlọ́run npèsè nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú mímọ́ tí a dá pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ilé Rẹ̀ nìkan ni ó lè mú kí àwọn oníyanu ọmọẹ̀hìn Krístì wọnnì fi ilé wọn sílẹ̀ ní ọjọ́ dídì náà gan, pẹ̀lú àwọn ipò ìgbé ayé ti araẹni wọn.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, bí ohun kan bá wà tí a ní—àti ohun kan tí a lè fún àwọn ọmọ àti ọmọ-ọmọ wa tí yíò ran ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ nínú àwọn ìdánwò àti àdánwò iwájú—yíò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn májẹ̀mú tí a dá nípasẹ̀ Jésù Krístì. Gbígba irú ìní tọ̀run bẹ́ẹ̀ yíò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbé bí Olúwa ti ṣe ìlérí fún àwọn ọmọlẹ́hìn Rẹ̀ tòótọ́: “Àwọn ọmọẹ̀hìn mi yíò dúró ní àwọn ibi mímọ́, wọn kì yíò sì yẹsẹ̀.”

Báwo ni a ṣe lè jèrè irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Krístì? Ó nwá nípa ìrẹ̀lẹ̀, ó ndá lé àwọn ìgbé ayé wa lórí Olùgbàlà, gbígbé nípa àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ ti ìhìnrere Jésù Krístì, gbígba àwọn ìlànà ìgbàlà àti ìgbéga, àti bíbu-ọlá fún àwọn májẹ̀mú tí a dá pẹ̀lú Ọlọ́run nínú ilé mímọ́ Rẹ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ ìparí rẹ̀ ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2019, wòlíì wa ọ̀wọ́n rán wa létí nípa ìgbésẹ̀ pàtàkì ní ṣíṣe àṣeyọrí májẹ̀mú ìgbẹ́kẹ̀lé, ó wípé: “Yíyẹ ẹnìkọ̀ọ̀kan láti wọnú ilé Olúwa bèèrè fún ìmúrasílẹ̀ ti-ẹ̀mí púpọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan. Yíyẹ ẹnìkọ̀ọ̀kan nfẹ́ ìyípadà ti inú àti ọkàn pátápátá sí dídàbíi Olúwa, láti jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè òtítọ́, láti jẹ́ àpẹrẹ dídárasi, àti láti di ẹni mímọ́jù.” Nítorínáà, bí a bá yí ìmúrasílẹ̀ wa padà láti wọnú tẹ́mpìlì, a ó yí ìrírí wa padà nínú tẹ́mpìlì, èyí yíò yí ìgbé ayé wa padà ní òde tẹ́mpìlì. “Nígbànáà ni ìgbẹ́kẹ̀lé yín yíò lágbára síi níwájú Ọlọ́run; àti pé ẹ̀kọ́ ti oyè àlùfáà yíò kán lé ọkàn yín bí ìrì látì ọ̀run.”

Bíṣọ́ọ̀pù kan tí mo mọ̀ tọ́ka sí kílásì tópẹ́jùlọ nínú Alakọbẹrẹ kìí ṣe bí kílásì “Alakọbẹrẹ” ṣùgbọ́n bí kílásì “ìmúrasílẹ̀ tẹ́mpìlì”. Ní Oṣù Kínní bíṣọ́ọ̀pù náà jẹ́ kí àwọn ọmọ kílásì àti olùkọ́ wọn wá sí yàrá ìbi-iṣẹ́ rẹ̀ níbi tí wọ́n ti sọ̀rọ̀ nípa bí wọn yíò ti lo gbogbo ọdún ní mímúrasílẹ̀ láti wọnú tẹ́mpìlì. Bíṣọ́ọ̀pù náà gba àkokò láti lọ sínú ìwúlò àwọn ìbèèrè ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ìkaniyẹ, èyí tí ó wà nínú àwọn ẹ̀kọ́ Alakọbẹrẹ wọn nígbànáà. Ó pe àwọn ọmọdé láti múrasílẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé, májẹ̀mú ìgbẹ́kẹ̀lé, nígbàtí wọ́n bá wá sí yàrá ibi-iṣẹ́ bíṣọ́ọ̀pù ní ọdún kan, kí wọ́n ṣetán láti gba ìkaniyẹ tẹ́mpìlì kí wọ́n sì wọnú ilé Oluwa. Ní ọdún yí bíṣọ́ọ̀pù ní àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mẹ́rin tí inú wọ́n dùn gidi, tí wọ́n múrasílẹ̀, tí wọ́n sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé láti lọ sí tẹ́mpìlì tí wọ́n fi fẹ́ kí bíṣọ́ọ̀pù tẹ àwọn ìkaniyẹ wọn jáde ní Ọjọ́ Ọdún Titun ní aago méjìlá àti ìṣẹ́jú kan.

Mímúrasílẹ̀ kìí kàn ṣe fún àwọn tí ó nlọ sí tẹ́mpìlì fún ìgbà àkọ̀kọ́ nìkàn. Gbogbo wa níláti máa múrasílẹ̀ títí-lọ láti lọ sí ilé Olúwa. Èèkan kan tí mo mọ̀ tẹ́wọ́gba ọ̀rọ̀-àkọlé “Gbùngbun ilé, àtìlẹhìn Ìjọ, àti dídojúkọ tẹ́mpìlì.” Dídè ni ọ̀rọ̀ wíwuni kan nítorípé ó túmọ̀ sí ìdojukọ ní ọ̀nà tààrà kan, ṣùgbọ́n bákannáà ó túmọ̀ sí ìdìmú sí tàbí ìmúdúró nípa, yíyanjú àti ìpinnu, dídájú. Nítorí wíwà ní ìdojúkọ sí tẹ́mpìlì nmú wa dúró sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà, ó nfún wa ní ìdarí dídára àti ìdúróṣinṣin nígbàtí ó nmudájú pé a ní májẹ̀mú ìgbẹ́kẹ̀lé nípasẹ̀ Jésù Krístì. Nítorínáà, gbogbo wa níláti mọ̀ọ́mọ̀ mú irú dídojúkọ bẹ́ẹ̀ gbòòrò nípa ṣíṣe ìpàdé-yíyán wa tó nmbọ̀ pẹ̀lú Olúwa nínú ilé mímọ́ Rẹ̀, bóyá tẹ́mpìlì wà nítosí tàbí ó jìnnà.

Àyànfẹ́ wòlíì wa, Ààrẹ Russell M. Nelson, rán wa létí nípa àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ pàtàkì wọ̀nyí pé: “Tẹ́mpìlì wà ní oókan ìfúnlókun ìgbàgbọ́ wa àti ìtìlẹ́hìn ti-ẹ̀mí nítorí Olùgbàlà àti ẹ̀kọ́ Rẹ̀ jẹ́ ọkàn tẹ́mpìlì gan-an. Ohun gbogbo tí a nkọ́ni ní tẹ́mpìlì, nípasẹ̀ ìkọ́ni àti nípasẹ̀ Ẹmí, nmú òye wa nípa Jésù Krístì pọ̀ síi. Àwọn ìlànà pàtàkì Rẹ̀ nso wá mọ́ Ọ nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú mímọ́ oye-àlùfáà. Bí a ti npa àwọn májẹ̀mú wa mọ́, Ó nbùkún wa pẹ̀lú agbára ìwòsàn, ìmúlókun Rẹ̀ . Àti pé áà, bí a ó ṣe nílò agbára Rẹ̀ tó ní àwọn ọjọ́ iwájú.”

Olùgbàlà nfẹ́ kí a di mímúrasílẹ̀ láti ní òye, pẹ̀lú híhàn kedere, bí a ti nṣe ìṣe déédé bí a ó ti dá àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú Baba Ọ̀run ní orúkọ Rẹ̀. Ó nfẹ́ kí a múrasílẹ̀ láti ní ìrírí àwọn ànfàní, ìlérí, àti ojúṣe wa; láti jẹ́ mímúrasílẹ̀ láti ní ìmòye ti-ẹ̀mí àti ìtanijí tí a nílò nínú ayé yí. Mo mọ̀ pé nígbàtí Olúwa bá rí àní ìpẹ́pẹ́ ìfẹ́-inú tàbí bàìbàì ìgbìyànjú òdodo nínú ìfẹ́ wa láti fi ìgbé ayé wa sorí Rẹ̀, àti sórí àwọn ìlànà àti májẹ̀mú tí a dá nínú ilé Rẹ̀, Òun yíò bùkún wa, ní ọ̀nà pípé, pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìyànu àti ìrọ́nú àánú tí a nílò.

Ilé Olúwa ni ibi tí a ti lè yípadà ní àwọn ọ̀nà gígajù àti mímọ́jù. Nítorínáà, nígbàtí a bá rìn níta tẹ́mpìlì, ní ìyípadà nípa ìrètí àwọn májẹ̀mú wa, ní ìrọ̀mọ̀ agbára láti òkè wá, a nmú tẹ́mpìlì pẹ̀lú wa lọ sínú ilé wa àti ìgbé ayé wa. Mo mu dáa yín lójú pé níní Ẹ̀mí ilé Olúwa nínú wa nyí wa pada, pátápátá.

A nmọ̀ látinú tẹ́mpìlì bí a bá fẹ́ kí Ẹ̀mí Olúwa wà láìní-ìdádúró nínú ayé wa, a kò ní a kò sì gbúdọ̀ ní àwọn ìmọ̀lára àìdára síwájú ẹnikẹ́ni. Fífi àyè gbà àwọn ìmọ̀lára àìdára àti èrò ní ọkàn tàbí nínú wa yíò mú àwọn ọ̀rọ̀ àìdára àti ìṣe jáde, bóyá lórí ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn tàbí nínú ilé wa, ní mímú Ẹ̀mí Olúwa láti fàsẹ́hìn kúrò nínú ọkàn wa. Nítorínáà, ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe ju ìgbẹ́kẹ̀lé yín sọnù, ṣùgbọ̀n sànjú bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí ìgbẹ́kẹ̀lé yín lágbára síi.

Ìyára àti lílọlọ́wọ́ kíkọ́ àwọn tẹ́mpìlì yíò tẹ̀síwájú làti dunninínú, mísíni, àti láti bùkún wa. Síbẹ̀síbẹ̀ ju gbogbo rẹ̀ lọ, bí a ti nyí mímúrapadà wa padà láti wọnú tẹ́mpìlì, a ó yí ìrírí wa padà nínú tẹ́mpìlì, èyí yíò yí ìgbé ayé wa padà ní òde tẹ́mpìlì. Njẹ́ kí yíyípadà yí kún inú wa pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn májẹ̀mú mímọ́ tí a dá pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Krístì. Ọlọ́run wà láàyè, Jésù ni Olùgbàlà, àti pé èyí ni ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé. Mo fi pẹ̀lú ọ̀wọ̀ kéde àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ní orúkọ mímọ́ ti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀