Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Jẹ́ Ọ̀kan pẹ̀lú Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


15:5

Jẹ́ Ọ̀kan pẹ̀lú Krístì

A ní ìrẹ́pọ̀ nípa ìfẹ́ wa nípa àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀. Àkójá ti wíwà-nínú lódodo ni láti jẹ́ ọ̀kàn pẹ̀lú Krístì.

Mo ti ní ìmọ̀lára ìjìnlẹ̀ nípa Ètùtù Jésù Krístì látigbà tí mo ti jẹ́ ọ̀dọ̀ gan, ṣùgbọ́n òdodo ti Ètùtù Olùgbàlà wá sílé sọ́dọ̀ mi nígbàtí mo wà ní ọdún marundinlọgbọn. Mo ṣẹṣẹ gboyè láti Ilé-ìwé Amòfin Stanford mo sì nkàwé fún ìdánwò ẹgbẹ́-lọ́yà ní California. Ìyá mi pè ó sì wípé baba-àgbà mi Crozier Kimball, ẹnití ó ngbé ní Utah, nku lọ. Ó wípé bí mo bá fẹ́ láti ri, kí njẹ́ máa bọ nílé. Baba-àgbà mi jẹ́ ọdún mẹrindinlaadọwa ó sì nṣàárẹ̀ gidi. Mo ni ìbẹ̀wò oníyanu kan. Inú rẹ̀ dùn gan láti rí mi ó sì ṣe àbápín ẹ̀rí rẹ̀ pẹ̀lú mi.

Nígbàtí Crozier ṣì jẹ́ ọdún mẹ́ta, baba rẹ̀, David Patten Kimball, kú ní ọjọ́ orí mẹrinlelogojì. Crozier ti nírètí pé baba rẹ̀ àti baba-àgbà rẹ̀, Heber C. Kimball yíò fàṣẹ sí ìgbésí ayé rẹ̀ àti pé kí ó ní ìmọ̀lára jíjẹ́ òtítọ́ sí ogún rẹ̀.

Kókó àmọ̀ràn baba-àgbà mi sí mi ni láti yẹra fún eyikeyi ìtọ́sí tàbí ànfàní nítorí ti àwọn babanla olótítọ́ wọ̀nyí. Ó wí fún mi pé ìdojúkọ mi níláti wà lórí Olùgbàlà àti Ètùtù Olùgbàlà. Ó wípé gbogbo wa ni ọmọ olùfẹ́ni Baba Ọrun. Láìka ẹni tí àwọn babanlá ti ayé wá jẹ́ sí, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa yíò jíhìn sí Olùgbàlà lórí bí a ti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ dáradára sí.

Baba-àgbà tọ́ka sí Olùgbàlà bí “Olùpamọ́ Ẹnu-ọ̀nà,” ìtọ́ka kan sí 2 Nefi 9:41. Ó wí fún mi pé òun ti ní ìrètí pé òun ti ronúpìwàdà púpọ̀ tó láti yege fún àánú Olùgbàlà.

Mo ní ìfọ̀wọ́kàn jíjinlẹ̀. Mo mọ̀ pé òun ti jẹ́ olódodo ọkùnrin. Òun ni babanlá ó sì ti sìn ní oríṣiríṣi àwọn míṣọ̀n. Ó kọ́ mi pé kò sí ẹnìkan tí ó lè padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa àwọn iṣẹ́ rere nìkan láìsí èrè Ètùtù Olùgbàlà. Mo lè rántí di ọjọ́ òní ìfẹ́ nlá àti ìmoore tí Baba-àgbà ní fún Olùgbàlà àti Ètùtù Rẹ̀.

Ní 2019 nínú ìyàni-síṣẹ́ kan ní Jerusalem, mo ṣèbẹ̀wò sí yàrá òkè èyí tí ó lè ti súnmọ́ ibi tí Olùgbàlà ti fọ ẹsẹ̀ àwọn Ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ ṣíwájú Ìkànmọ́-ágbélèbú. A fọwọ́kàn mi níti-ẹ̀mí mo sì ronú nípa bí Ó ti pàṣẹ fún àwọn Ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ láti fẹ́ràn ara wọn.

Mo rántí àdúrà ẹ̀bẹ̀ Olùgbàlà tí ó nbẹ̀ ní ìtìlẹhìn wa. Àdúrà yí ṣẹlẹ̀ ní bíi àwọn wákàtí ìparí ayé ikú Rẹ̀ bí a ti kọsílẹ̀ nínú Ìhìnrere Jòhánù.

Àdúrà yí ni a darí sí àwọn ọmọlẹ́hìn Krístì, pẹ̀lú gbogbo wa. Nínú ìbẹ̀bẹ̀ sí Baba Rẹ̀ “Kí wọn ó lè jẹ́ ọ̀kan; gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti jẹ́ nínú mi, àti èmi nínú rẹ, kí àwọn pẹ̀lú kí ó lè jẹ́ ọ̀kan nínú wa.” Nígbànáà Olùgbàlà tẹ̀síwájú, “Ògo èyí tí ìwọ fi fún mi ni mo fún wọn; kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan, àní bí àwa ti jẹ́ ọ̀kan.” Ọkannáà ni ohun tí Krístì gbàdúrà fún ṣíwájú ìfihàn àti Ìkànmọ́-àgbélèbú Rẹ̀. Ọkannáà pẹ̀lú Krístì àti Baba wa Ọ̀run ni a lè gbà nípasẹ̀ Ètùtù Olùgbàlà.

Àánú ìgbàlà Olúwa kìí dá lórí ìràn, ẹ̀kọ́, ipò ọ̀rọ̀-ajé, tàbí ẹ̀yà. Ó dálé jíjẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú Krístì àti àwọn òfin Rẹ̀.

Wòlíì Joseph Smith àti Oliver Cowdery gba ìfihàn lórí ìṣètò àti ìjọba Ìjọ ní 1830, láìpẹ́ lẹ́hìn tí a ṣètò Ìjọ. Bayi tí ó jẹ́ ìpín 20 ni a kà nípasẹ̀ Wòlíì Joseph ní ìpàdé àpapọ̀ Ìjọ àkọ́kọ́ tí ó sì jẹ́ ìfihàn àkọ́kọ́ ti a fàṣẹ sí nípa ìwọ́pọ̀ ìfọwọ́sí.

Àkóónú ìfihàn yí lódodo jẹ́ alámì. Ó kọ́wa ní pàtàkì àti ojúṣe Ètùtù Olùgbàlà àti bí a ó ti ní àyè sí agbára àti àwọn ìbùkún nípa oore-ọ̀fẹ́ ètùtù Rẹ̀. Wòlíì Joseph jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún ó sì ti gba onírurú àwọn ìfihàn ó sì ti parí ìyírọ̀padà-èdè Ìwé ti Mọ́mọ́nì nípa ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run. Joseph àti Oliver papọ̀ ni a fi hàn bí àwọn ọmọẹ̀hìn tí a yàn, bayi wọ́n ní àṣẹ láti ṣe àkóso lórí Ìjọ.

Àwọn ẹsẹ kẹtàdínlógún sí kẹrìndínlógójì ní àkópọ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì Ìjọ nínú, pẹ̀lú òdodo Ọlọ́run, Ìṣẹ̀dá ènìyàn, Ìṣubú, àti ètò Ìgbàlà Baba Ọ̀run nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì. Ẹsẹ kẹtàdínlógójì ní àwọn ìnílò pàtàkì nínú fún ìrìbọmi sínú Ìjọ Olúwa. Ẹsẹ karundinlọgọrin sí ọ̀kàndínlọgọrin ni ó gbé àdúrà oúnjẹ Olúwa tí a nlò ní ọjọọjọ́ Ìsìnmi kalẹ̀.

Ẹ̀kọ́, ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀, oúnjẹ Olúwa, àti àwọn ìṣe tí Olúwa gbékalẹ̀ nípasẹ̀ Joseph Smith, Wòlíì Ìmúpadàbọ̀sípò, jẹ́ idanilẹkọ nítòótọ́.

Àwọn ìnílò fún ìrìbọmi, nígbàtí ó jinlẹ̀, ó jẹ́ ìrọ̀rùn àìláfiwé. Ní kókó wọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ níwájú Ọlọ́run, ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́, ríronúpìwàdà gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀, gbígba orúkọ Jésù Krístì lé orí ara wa, fífaradà dé òpin, àti fífihàn nípa àwọn iṣẹ́ wa pé a ti gba Ẹ̀mí Krístì.

Ó ṣe pàtàkì pé gbogbo àwọn ìkàyẹ fún ìrìbọmi jẹ́ ti-ẹ̀mí. Kò sí ọrọ̀-ajé tàbí dídébí ìbákẹ́gbẹ́ tó ṣeéṣe. Òtòṣì àti ọlọ́rọ̀ ní irú àwọn ìnílò ti ẹ̀mí kannáà.

Kò sí ẹ̀yà, lákọlábo, tàbí àwọn ìnílò ẹlẹ́yàmẹ̀yà. Ìwé ti Mọ́mọ́nì mu hàn kedere pé gbogbo ènìyàn ni a pè láti ṣe àbápín inúrere Olúwa, “dúdú àti funfun, ìdè àti òmìnira, ọkùnrin àti obìnrin; … gbogbo wa dà bákannáà sí Ọlọ́run.” “Gbogbo ènìyàn ni ó ní ànfàní ọ̀kan bí ti òmíràn, kò sì sí ẹnìkan tí a dá lẹ́kun.”

Ní “jíjẹ́ bákannáà” níwàjú Ọlọ́run, ó kàn mú ọgbọ́n díẹ̀ wá ni láti tẹnumọ́ àwọn ìyàtọ̀ wa. Àwọn kan ti gbà wá níyànjú ìṣìnà “láti rò pé àwọn ènìyàn yàtọ̀ púpọ̀ síi kúrò lọ́dọ̀ arawa àti kúrò lọ́dọ̀ arawa ju bi wọ́n ti wà lódodo. [Àwọn kan] nmú òdodo ṣùgbọ́n àwọn ìyàtọ̀ kékèké wọ́n sì ngbé wọn ga sínú àwọn ọ̀gbun.”

Ní àfikún, àwọn kan ti lérò ìṣìnà pé nítorí gbogbo ènìyàn ni a pè láti gba inúrere Rẹ̀ àti ìyè ayérayé, kò sí áwọn ìnílò ìṣe.

Bákannáà, àwọn ìwé mímọ́ jẹri pé gbogbo ènìyàn olùjìhìn ni ó nílò láti ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kí a sì pa àwọn òfin mọ́. Olúwa nmu hàn kedere pé gbogbo ìwà agbára láti yàn àti pé “a ní òmìnira láti yan ìtúsílẹ̀ àti ìyè ayérayé, nípasẹ̀ Olùlàjà nlá gbogbo ènìyàn, … kí a sì fetísílẹ̀ sí àwọn òfin nlá Rẹ̀; kí a sì jẹ́ olótítọ́ sí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ, kí a sì yan ìyè ayérayé.” Láti gba àwọn ìbùkún Ètùtù Olùgbàlà, a gbúdọ̀ fi àtẹnumọ́ lo ìwà agbára òmìnira wa láti yan Krístì àti láti gbọ́ran sí àwọn òfin Rẹ̀.

Ní ìgbà ayé mi, ìtumọ̀ ti “agbára òmìnira” àti ”ìfẹ́-inú òmìnira” ni a ti gé ká tí a sì ti jọ sọ. Wọ́n ti wà wọ́n sì ti tẹ̀síwájú láti jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àríyànjiyàn olóye lórí àwọn àkọlé wọ̀nyí.

Lórí ojú-ewé àìpẹ́ ti kókó àtẹ̀jáde alúmínáì unifásítì, amòye onímọ̀-bàìlọ́lọ́jì wípé “Kò sí àyè fún ìfẹ́-inú òmìnira.” Láìyanilẹ́nu, amòye náà ṣe àyọsọ nínú àtẹ̀kọ ní sísọ pé, “Kò sí ohun kan bí Ọlọ́run, … àti pé kò sí ìfẹ́ òmìnira, … àti pé èyí ni ìyára, àìní-yàtọ̀, àgbáyé òfìfo.” Èmi kò lè ṣàì-faramọ́ ní líle síi.

Ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ ìgbàgbọ́ wa ni pé a kò ní ìwà agbára láti yàn, èyí pẹ̀lú ìfẹ́-inú òmìnira. Agbára òmìnira ni okun láti yàn àti láti ṣe ìṣe. Ó ṣe pàtàkì sí ètò ìgbàlà. Láìsí ìwà agbára òmìnira, a kò lè kẹkọ, lọsíwájú, tàbí yàn láti jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú Krístì. Nítorí ìwà agbára òmìnira, a “ní òmìnira láti yan ìtúsílẹ̀ àti ìyè ayérayé.” Ní ìgbìmọ̀ ìṣíwájú ayé ní ọ̀run, ètò Baba wà pẹ̀lú agbára òmìnira bí ohun elò pàtàkì. Luciferi ṣọ̀tẹ̀ ó sì “wá láti pa agbára òmìnira ènìyàn run.” Ní ìbámu, ànfàní níní ara ayé ikú ni a sẹ́ Sátánì àti àwọn wọnnì tí wọ́n tẹ̀le e.

Àwọn ẹ̀mí ìṣíwájú ayé míràn lo agbára òmìnira wọn ní títẹ̀lé ètò Baba Ọ̀run. Àwọn ẹmí tí a bùkún nípa ìbí sí ayé ikú yí tẹ̀síwájú láti ní agbára òmìnira. A ní òmìnira láti yàn àti láti ṣe ìṣe, ṣùgbọ́n a kò ní àkóso lórí àwọn àbájáde náà. “Àwọn àṣàyàn rere àti òdodo ndarí sí inúdídùn, àláfíà àti ìyè ayérayé nígbàtí àwọn àṣàyàn ẹ̀ṣẹ̀ àti ibi nígbẹ̀hìn ndarí sí ìrora ọkàn àti òṣì.” Bí Álmà ti wípé, “Ìwà búburú kìí ṣe inúdídùn láéláé.”

Ninú ayé dídíje jùlọ yí, ìtiraka kàn wà láti yege. Lílàkàkà láti jẹ́ dídára jùlọ tí a lè jẹ́ ni ìṣe òdodo àti yíyẹ. Ó wà láìyẹsẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Olúwa Àwọn ìtiraka láti dínkù tàbí mú àwọn míràn rẹlẹ̀ tàbí dá ìdènà sí àṣeyege wọn ni ìlòdì sí ẹ̀kọ́ Olúwa sílẹ̀. A kò lè dá àwọn ipò wa tàbí àwọn míràn lẹ́bi fún ìpinnu láti ṣe ìṣe tí ó lòdì sí àwọn òfin Ọlọ́run.

Nínú ayé òní, ó rọrùn láti dojúkọ àṣeyege ohun èlò àti iṣẹ́. Àwọn kan sọ ìwò ti ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ayérayé nù àti àwọn àṣàyàn tí ó ní pàtàkì ayérayé. A ó lọ́gbọ́n láti tẹ̀lé àmọ̀ràn Ààrẹ Russell M. Nelson láti “ronú nípa Sẹ̀lẹ́stíà.”

Àwọn àṣàyàn pàtàkì jùlọ ni a fẹ́rẹ̀ lè ṣe nípasẹ̀ gbogbo ènìyàn láìka àwọn ẹ̀bùn, okun, ànfàní, tàbí àwọn ipò ọrọ̀-ajé sí. Àtẹnumọ́ kan lórí fífi àwọn àṣàyàn ẹbí ṣaájú ṣe pàtàkì. Èyí hàn kedere nínú àwọn ìwé-mímọ́. Ronú nípa àkọsílẹ̀ nínú 1 Néfì níbití Léhì “ti kúrò lọ sínú aginjù. Ó sì fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, àti ilẹ̀ ìní rẹ̀, àti wúrà rẹ̀, àti fàdákà rẹ̀, àti àwọn ohun oníyebíye rẹ̀, kò sì mú ohunkóhun pẹ̀lú rẹ̀, àfi ìdílé rẹ̀.”

Bí a ti ndojúkọ àyídà ayé, àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ lè ṣẹ̀ lórí èyí tí a ní kékeré tàbí àìsí àkóso. Àwọn ìpènijà ìlera àti àwọn ìjàmbá híhàn gbangba lè wà ní ìbámu sínú ipele yí. Àjàkálẹ̀ àrùn àìpẹ́ ti pa àwọn ènìyàn tó ṣe ohungbogbo dáadáa lára gidigidi. Fún púpọ̀jù àwọn àṣàyàn pàtàkì, a kò ní àkóso. Lílọ padà sí àwọn ọjọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi, Alàgbà Marion D, Hanks, ààrẹ míṣọ̀n wa, ri pé gbogbo wa kọ́ apákan ewì láti ọwọ́ Ella Wheeler Wilcox sórí:

Kò sí àyè, kò sí àyànmọ́, kò sí ìdarísí,

Tí ó lè yípadà tàbí dádúró tàbí ṣàkóso

Ìyànjú daindain nípa ẹmí onípinnu kan.

Lórí àwọn ọ̀ràn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀, ìṣe, àkíyèsí ẹ̀sìn, àti gbígbé òdodo, a wà ní ìṣàkóso. Ìgbàgbọ́ wa nínú àti ìjọ́sìn Ọlọ́run Baba àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ni àṣàyàn tí a ṣe.

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ ní òye pé èmi kò gbẹnusọ fún ìdínkù ìwuni nínú ẹ̀kọ́ tàbí iṣẹ́. Ohun tí èmi nsọ ni pé nígbàtí àwọn ìtiraka tí ó rọ̀mọ́ ẹkọ́ àti iṣẹ́ bá ga ju ẹbí tàbí jíjẹ̀ ọ̀kan nínú Krístì, àwọn àbájáde àìlèrò le ní ikọlù tó lápẹrẹ.

Ẹ̀kọ́ híhàn kedere àti ìrọ̀rùn tí a gbékalẹ̀ nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20 nfọwọ́tọ́ni ó sì nmu nípá bí ó ti nmú títóbi àti ìsọdimímọ̀ ìgbìrò ti ẹ̀mí hàn. Ó nkọ́ni pé ìgbàlà nwá bí Jésù Krístì nyà olùrònúpìwàdà ọkàn símímọ́ nítorí oore-ọ̀fẹ́ Olùgbàlà. Ó gbé ipele náà kalẹ̀ fún ojúṣe ipò-ti Ètùtù Rẹ̀.

A níláti tiraka láti mú àwọn míràn wọ inú agbo jíjẹ́ òkannáà wa. Bí a ti ntẹ̀lé ìkìlọ̀ ti Ààrẹ Rusell M. Nelson láti kó àwọn olùfọ́nká Ísráẹ́lì jọ ní ẹ̀gbẹ́ méjèjì ìkelè, a nílò láti mú àwọn míràn wọ inú agbo jíjẹ́ ọ̀kannáà wa. Bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni dáradára pe: “Ní gbogbo ayé àti káàkiri erékùṣù òkun, àwọn olótítọ́ ènìyàn ni à nkójọ sínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Àwọn ìyàtọ̀ nínú àṣà, èdè, lákọlábo, ẹ̀yà, àti jíjẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè nṣá lọ sínú àìdára bí àwọn olótítọ́ ti nwọnú ìpa-ọ̀nà májẹ̀mú tí wọ́n sì nwá sọ́dọ̀ àyànfẹ́ Olùràpadà wa.”

A ní ìrẹ́pọ̀ nípa ìfẹ́ wa ti àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti bí ọmọ olùfẹ́ni Baba Ọ̀run. Àkójá ti wíwà-nínú lódodo ni láti jẹ́ ọ̀kàn pẹ̀lú Krístì. Àwọn ìlànà ìrìbọmi àti oúnjẹ Olúwa ni a gbé kalẹ̀ nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20, papọ̀ pẹ̀lú àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì wa ndà wá pọ̀ ní àwọn ọ̀nà pàtàkì ó sì nfi àyè gbà wá láti jẹ́ ọ̀kan nínú gbogbo ọ̀nà ti ayérayé pàtàkì àti láti gbé ní àláfíà àti ìbámu.

Mo jẹ́ ẹ̀rí tòótọ́ àti dídájú mi pé Jésù Krístì wà láàyè, àti pé nítorí Ètùtù Rẹ̀, a lè jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú Krístì. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. David, ọmọ ọjọ́ orí mẹ́tàdínlógún ti ṣèrànwọ́ láti gbé àwọn Ènìyàn Mímọ́ díẹ̀ kọjá Odò Omi-dídùn tí ó kún-fún yìnyín nígbàtí wọ́n ní ìdádúró lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ gíga ti Wyoming (wo Àwọn Ẹ̀nìyàn Mímọ́: Ìtàn Ìjọ ti Jésù Krístì ní àwọn Ọjọ́ Ìkẹhìn, volume 2, Kò Sí Ọwọ́ Àìmọ́, 1846–1893 [2020], 237).

  2. Wo Mórónì 7:27–28.

  3. Olóyè Rabbi ti Norway, Rabbi Michael Melchior, àti èmi jẹ́ kókó olùsọ̀rọ̀ níbi ìsọ̀rọ̀ olùkàwé ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn ti Jew tí a ṣe ní Oṣù Kẹfà Ọkọ́ Karun, 2019, ní gbọ̀ngan BYU Jerusalem ní Israel.

  4. Wo Jòhánù 17:20.

  5. Jòhánnù 17:21–22.

  6. Wo “Àwọn Ìròhìn Ìpàdé Àpapọ̀ àti Ìwé Àkọsílẹ̀ nípa Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 1838–1839, 1844” (tí a mọ̀ ní ìwọ́pọ̀ bí Àkọsílẹ̀ Jíjìn Ìwọ̀-òòrùn), June 9, 1830, Ilé-ìkówé pamọ́ Àkọọ́lẹ̀ Ìjọ, Salt Lake City; Steven C. Harper, Mímú Ọgbọ́n Wá Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú (2008), 75.

  7. Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20 ni ìfihàn àkọ́kọ́ tí a tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròhìn Ìjọ tí a sì lo nípasẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere pẹ̀lú ọ̀wọ̀ sí ẹ̀kọ́ àti àkóso àwọn ìlànà ìrìbọmi àti oúnjẹ Olúwa (wo Harper, Mímú Ọgbọ́n Wá Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, 75).

  8. Wo 2 Néfì 2:7.

  9. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20:37.

  10. 2 Nefi 26:33.

  11. 2 Néfì 26:28.

  12. Peter Wood, Onírurú: The Invention of a Concept (2003), 20.

  13. Nehor gba ipò yí (wo Alma 1:4).

  14. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 29:49–50.

  15. 2 Nefi 2:27-28.

  16. Stanford (àtẹ̀jáde Stanford Alumni Association), Dec. 2023, cover.

  17. Nínú Sam Scott, “Bí Ẹnipé Ẹ Ní Àṣàyàn,” Stanford, Dec. 2023, 44. Àtẹ̀kọ náà fi Ọ̀mọ̀wé náà hàn bí Robert Sapolsky, Ọ̀mọ̀wé bàìọ́lọ́jì, ọpọlọ, àti iṣẹ́-abẹ ọpọlọ ti Stanford, àti olùkọwé àwọn ìwé sáyẹ́nsì tí ó ntà jùlọ. Àtẹ̀kọ náà wà pẹ̀lú àwọn ìwò àtakò Alfred Mele, òmòwé ìmọ̀ ènìyàn ní Unifásítì Ìpínlẹ̀ Florida, tí ó darí Iṣẹ́ Ìpìlẹ̀ títóbi John Templeton lórí ìfẹ́-inú òmònira. Ó wípé, “onímọ̀ sáyẹ́nsì jùlọ dájúdájú ti jẹ́wọ́ pé ìfẹ́-inú òmìnira—àní ìfẹ́-ipá ìfẹ́-inú òmìnira—jẹ́ ìṣìnà” (in Scott, “As If You Had a Choice,” 46).

  18. Wo D. Todd Christofferson, “Ìwà Agbára láti yàn” (Brigham Young University devotional, Jan. 31, 2006).

  19. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 58:27.

  20. 2 Néfì 2:27.

  21. Mose 4:3.

  22. Òtítọ́ sí Ìgbàgbọ́: Ìtọ́kasí Ìhìnrere Kan (2004), 12.

  23. Álmà 41:10.

  24. Wo Russell M. Nelson, “Ronú Sẹ̀lẹ́stíà,” Lìàhónà, Oṣù Kọkànlá 2023, 117–20.

  25. 1 Néfì 2:4.

  26. Àwọn Iṣẹ́ ti Ewì Ella Wheeler Wilcox (1917), 129.

  27. Mo ti fẹ́ràn àyọsọ tí a pín nípa Alágbà Neal A. Maxwell nígbàgbogbo pé èyí ni ẹ̀ṣọ́ àṣepọ̀ jùlọ: “Bí ẹ kò bá tíì yan ìjọba Ọlọ́run lakọkọ, kì yíò já mọ́ nkankan ní ìgbẹ̀hìn ohun tí ẹ bá yàn dípò rẹ̀” (attributed to William Law, an 18th-century English clergyman; quoted in Neal A. Maxwell, “Ìdáhùn sí Ìpè Kan,” Ensign, May 1974, 112).

  28. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20:29–31. Èto ẹ̀kọ́-ẹ̀sìn tẹnumọ́ ìdáláre àti ìyàsímímọ́ ti àwọn ọkàn ṣíṣubú nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ Jésù Krístì. Ó kọ́ni pé nígbàtí Ọlọ́run ti yan ọ̀kàn tẹ́lẹ̀ fún ìgbàlà, kò sí ohun tí ó lè yí àbájáde náà padà. Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20 ṣe ìjákúrò mímọ́ pẹ̀lú Ètò ẹ̀sìn. Ó kà pé, “Ó sì ṣeéṣe pé ènìyàn lè ṣubú látinú oore-ọ̀fẹ́ kí ó sì kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè” (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20:32–34; Harper, Mímọ́gbọ́n wá ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, 74).

  29. Russell M. Nelson, “Gbígbé Ààbò Ga,” Làìhónà, Dec. 2018, 51.