Wá kí o sì Wà Pẹ̀lú
A pè gbogbo ọmọ Ọlọ́run ní gbogbo àgbáyé láti darapọ̀ mọ́wa nínú ipa nlá yi.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn ní gbogbo àgbáyé jọ́sìn olùfẹ́ Bàbá wa Ọ̀run, Ọlọ́run àti Ọba gbogbo ayé, àti Olùfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. A ronú ìgbé ayé àti àwọn ẹ̀kọ́ Jésù Krístì—ẹ̀mi aláìlẹ́ṣẹ̀ kanṣoṣo ti o ti gbé àye, ọ̀dọ́ àgùtàn aláìlábàwọ́n Ọlọ́run. À njẹ oúnjẹ Olúwa ní ìrántí ẹbọ Rẹ àti láti mọ pé Òhun ni gbùngbùn nínú ayé wa.
A nifẹ Rẹ̀ a sì bu ọlá fún Un. Nítorí ìfẹ́ nla àti àìnípẹ̀kun Rẹ̀, Ó jìyà Ó si kú fún ẹ̀yin àti èmi. Ó ṣí àwọn ilẹ̀kùn ikú, fọ́ àwọn ìdènà ti o pìn àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn olùfẹ níyà,1 Ó sì mú ìrètí fún aínìreti, ìwòsàn fún aláìsàn, àti ìtúsílẹ̀ fún ondè.2
Òhun ni a fi ọkàn wa fún, ayé wa, àti ìfọkànsìn ojojumọ wa. Nítorí ìdí èyí, “a nsọ̀rọ̀ nípa Krístì, a nyọ̀ nínú Krístì, a si nwãsù nípa Krístì, … Pé kí àwọn ọmọ wa lè mọ́ orísun èwo ni àwọn lè wò fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”4
Kíkọ́ Ipò Ọmọ ẹ̀hìn
Síbẹ̀síbẹ̀, jíjẹ́ ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì ní ṣiṣe pẹ̀lú ju ọ̀rọ̀ sísọ àti wiwasu Krístì. Olùgbàlà Tìkararẹ mú Ìjọ Rẹ̀ bọ̀sípò láti rànwá lọ́wọ́ nípa ọ̀na láti dà bíi Rẹ̀. Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn jẹ́ ibì kan fún àwọn ènìyàn pẹ̀lú gbogbo onírurú àwọn Ipò ọmọ ẹ́hìn. Nípa ìkópa wa nínú Ìjọ, a kọ láti mọ̀ àti láti ní ìṣe lórí àwọn ìṣílétí ti Ẹ̀mí Mímọ́. A mú ìwà nínọwọ́ ní àánú àti inú rere sí àwọn ẹlòmíràn gbèrú si.
Èyí jẹ akitiyan ìgbésí ayé, o si gba kíkọ́.
Àwọn alaṣeyọri eléré ìdárayá lo wákàtí àìlóùnkà fùn kíkọ́ àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ eré ìdárayá wọn. Àwọn Nọ́ọ̀sì, àwọn oníṣẹ ayélujára, àwọn ẹlẹ́rọ núkílíà, pàápàá àwọn olùdíje alásè di alágbára àti oloye nìkan bí wọ́n ṣe fi taratara kọ́ iṣẹ́ ọnà wọn.
Gẹ́gẹ́ bi balógun ọkọ̀ òfúrufú, mo n fi ìgbà gbogbo kọ́ àwọn awakọ̀ òfúrufú nípa lílo òfúrufú onítẹ̀síwájú—ẹ̀rọ ìgbàlódé kan ti o rọ́pò ìrírí tí o n fò. Onítẹ̀síwájú kò ran àwọn awakọ̀ òfúrufú lọ́wọ́ láti kọ àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ fífò nìkan; o tún ma n gbà wọ́n láyè láti ní ìrírí àti láti dáhùn sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀ tí wọ́n le kojú nígbà tí wọ́n bá gba àṣẹ tí ọkọ̀ òfúrufú gidi.
Àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kannáà wà fún àwọn ọmọẹ̀hìn ti Jésù Krístì.
Fífi gbogbo ara kópa nínú Ìjọ Jésù Krístì àti oríṣiríṣi àwọn ànfàní tí yio ran wa lọ́wọ́ láti gbáradì dáradára fún àwọn ipò yíyípadà ayé, ohunkóhun àti eyikeyi ti o le jẹ́. Bí àwọn ọmọ Ìjọ, a gbàwá nímọ̀ràn lati ri ara wa sínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa àwọn wòlíì, àtijọ́ àti ìgbàlódé. Nípasẹ̀ àdúrà pípé àti ìrẹ̀lẹ̀ si Bàbá wa Ọ̀run, a kọ́ láti dá ohùn Ẹ̀mí Mímọ́ mọ̀. A gba àwọn ìpè láti sìn, kọ́, gbèrò, ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ àti láti bojúto. Àwọn ànfàní yi gbàwá láyè láti dàgbà nínú ẹ̀mí, iyè, àti ìwà.
Wọn o rànwá lọ́wọ́ láti ṣe àti láti pa àwọn májẹ̀mú mọ́ ti yio bùkún wa nínú ayé yí àti ní ayé tó n bọ̀.
Wá, Darapọ̀ pẹ̀lú Wa!
A pè gbogbo ọmọ Ọlọ́run ní gbogbo àgbáyé láti darapọ̀ mọ́wa nínú ipa nlá yi. Wá kí o sì Ríi! Pàápàá ní àkókó ìpèníjà COVID-19 yi, ẹ báwa pàdé ní orí ayélujára. Ẹ bá àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wa pàdé lórí ayélujára. Ẹ wadi fúnra yín ohun tí Ìjọ yi wà fún! Nígbà tí àkókò ìnira yi ba kọjá, ẹ báwa pàdé ní ilé wa àti àwọn ibi ìjọ́sìn wa!
A pè yín láti wá kí ẹ sì wa ṣe ìrànwọ́! Ẹ wá sìn pẹ̀lú wa, ní ṣíṣe ìránṣẹ́ sí àwọn ọmọ Ọlọ́run, ní títẹ̀lé ipa ẹsẹ̀ Olùgbàlà, kí a si ṣe ayé yí ní ibi dídára.
Wá kí o sì wà pẹ̀lú! Ẹ o mú wa ní agbára si. Ẹ̀ o si di dídára si, ìwà rere si, àti inú dídùn síi pẹ̀lú. Ìgbàgbọ́ yín yio jinlẹ̀ yio si dàgbà dáradára si—ti o lágbára láti dojúkọ àwọn rúdurùdu àti ìdánwò àìròtẹ́lẹ̀ ayé.
Àti pé báwo ni a ó ṣe bẹ̀rẹ̀? Àwọn ọ̀nà púpọ̀ ti o ṣeéṣe wa.
A pè yín láti ka Ìwé Mọ́mọ́nì. Bí ẹ ko bà ní ẹ̀dà kan, ẹ le kàá lóríi ChurchofJesusChrist.org4 tàbí ṣe ìgbàsílẹ̀ ápù Ìwé Mọ́mọ́nì. Ìwé ti Mọ́rmọ́nì ni ẹ̀rí kejì ti Jésù Krístì àti ojúgbà si àwọn Májẹ̀mú Láíláí àti Titun. A nifẹ àwọn ìwé mímọ́ wọ̀nyí a si n kẹkọ nínú wọn.
A pè yín láti lo àkókò díẹ̀ ní ComeuntoChrist.org láti wadi ohun tí àwọn ọmọ Ìjọ n kọ́ tí wọ̀n si gbàgbọ́.
Ẹ pe àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere láti bẹ̀wò pẹ̀lú yín lóri ayélujára tàbí ní ibi àṣírí ilé yín níbi ti èyí ti ṣeéṣe—wọ́n ní ìfiránṣẹ́ ìrètí àti ìwòsàn. Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere jẹ ojúlowo àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ti o sìn ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi ní àgbáyé pẹ̀lú àkókò àti owó ara wọn.
Ní ìjọ Jésù Krístì, ẹ o ri ẹbí àwọn ènìyàn kan tí kò yàtọ̀ si yín. Ẹ o ri àwọn ènìyàn tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ yín tí wọ́n si fẹ́ láti ràn yín lọ́wọ́ bí ẹ ṣe n tiraka láti jẹ́ ẹ̀yà dídára ti arayín—ẹni ti Ọlọ́run dá yin láti jẹ́.
Gbígbàwọlé Olùgbàlà nawọ́ si gbogbo ènìyàn
Ẹ lè má ro wípé, “Mo ti ṣe àṣìṣe ni ayé mi. Mi o lérò wípé mo lè ni ìmọ̀lára wíwà pẹ̀lú ni Ìjọ Jésù Krístì. Ọlọ́run kò lè nifẹ si irú ẹni bi èmi.”
Jésù Krístì náà, bi o tilẹ̀ jẹ́ “Ọba àwọn ọba,”5 Mèsáyà, “Ọmọ bíbi kanṣoṣo Ọlọ́run alàyè,”6 n tọ́jú ara wọn àti gbogbo ọmọ Ọlọ́run. Ó n tójú láì ka ipò ẹnìkan sí—bí o ṣe tálákà tàbí lówó tó, bi o ṣe ṣedéédé tàbí àìṣedéédé to. Ní àkókò ayé ikú Rẹ, Olùgbàlà ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ si gbogbo ènìyàn: sí ìdùnnú àti àṣeyọrí, sí fífọ́ àti sìsọnù, àti si àwọn ti wọn wà láì nírètí. Nígbàgbogbo, àwọn ènìyàn ti Ó sìn ti o sì ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ si kìí ṣe ènìyàn pàtàkì, ẹwà, tàbí ọlá. Nígbàgbogbo, àwọn ènìyàn tí Ó gbé sókè ni ohun díẹ̀ láti san padà ṣugbọ́n ọpẹ́, ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ kan, àti ìfẹ́ láti ní ìgbàgbọ́.
Njẹ́ bí Jésù bá lo ayé ikú Rẹ láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ sí “èyí ti o kéréjù nínú àwọn wọ̀nyí,”7 ṣé Ko ni nifẹ wọn loni? Ṣé kò sí ibi kan ní Ìjọ Rẹ fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run? Pàápàá fún àwọn ti o ni ìmọ̀lára àìyẹ, ìgbàgbé, tàbí dáwà?
Kò sí ìlóro pípé ti ẹ ni láti dé láti lè di yíyẹ fún oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Àdúrà yín ko nilati ní ariwo tàbí mọ ọ̀rọ̀ sísọ tàbí mọ gẹ̀ẹ́sì láti lè dé ọ̀run.
Ní òtítọ́, Ọlọ́run kìí ṣe ojúṣaju8—ohun ti o jọ ayé lójú ko jámọ́ ohun kan. Ó mọ ọkan yín, O fẹ́ràn yín láìfi àkọ́lé yin pè, ìṣúná owó, tàbí nọ́mbà àtẹ̀lé lórí ínstágíràmù.
Bí a ṣe n tẹ ọkàn wa si ti Bàbá wa Ọ̀run tí a sì n súnmọ́ Ọ, a ó ní ìmọ̀lára pé O súnmọ́ wa.9
A jẹ́ olóùfẹ́ ọmọ Rẹ̀.
Pàápàá àwọn ti wọn kọ̀ Ọ́.
Pàápàá àwọn, bí olórí líle, aláìgbọràn ọmọ, bínú sí Ọlọ́run àti Ìjọ Rẹ, ko àwọn àpò wọn, tí wọn si jáde lẹ́nu ilẹ̀kùn ni kikede pe wọn n sálọ àti pe wọn ki yio pada láí.
Nígbàtí ọmọ kan sa kúrò nílé, obìnrin tàbi ọkùnrin náà le ma fọkàn sí àwọn òbí alafiyesi tí ó wò láti fèrèsé. Pẹ̀lú àwọn ọkàn tútù, wọn wo ọmọbìnrin tàbí ọmọkùnrin wọn lọ—ní ìrètí pe ọmọ wọn iyebíye yio kọ ohunkan ní ìrírí yíya ọkàn yi àti bóyà rí ayé pẹ̀lú ojú titun—àti níkẹhìn pada sílé.
Bẹ́ẹ̀ni ó rí pẹ̀lú olùfẹ́ Bàbá wa Ọ̀run. Ó n dúró fún ìpadàbọ̀ wa.
Olùgbàlà yín, omi ojú àánú àti ìfẹ́ ní ojú Rẹ, dúró fún ìpadàbọ̀ yín. Pàápàá nígbà ti ẹ ni ìmọ̀lára fífà sẹ́hìn lọ́dọ̀ Ọlọ́run, Yio ri yín; Yio ṣàánú fún yín sáré láti gbà yín mọ́ra.10
Wá kí o sì Wà Pẹ̀lú.
Ọlọ́run Gbà Wá láyè láti Kẹkọ lára Àṣìṣe Wa
A jẹ́ arìnrìn àjò ní ojú ọ̀nà ayé ikú ní wíwá ìtumọ̀ àti òtítọ́. Nígbàgbogbo, gbogbo ohun ti a ri ni ọ̀nà tààrà níwájú—a kò lè rí ibi tí àwọn títẹ̀ ni ọ̀nà náà yio yọrí si. Olùfẹ́ Bàbá wa Ọ̀run kò fún wá ní gbogbo ìdáhun. Ó fẹ́ kí á wá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun fúnra wa. Ó fẹ́ kí á gbàgbọ́—pàápàá nìgbátì o bá nira láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Ó fẹ́ kí á mú èjìká wa dúró ki a ṣe ìpinnu kékeré—ọ̀pá ẹ̀hìn kékeré—ki a sì gbésẹ̀ míràn síwájú.
Ìyẹn ni ọ̀nà tí a le kẹkọ kí á sì dàgbà.
Ṣé ẹ fẹ́ kí a fi òtítọ́ ka ohun gbogbo jáde ni yékéyéké? Ṣé ẹ fẹ́ kí a fi òtítọ́ dáhùn gbogbo ìbéèrè? Kí á ya àwòrán gbogbo ibi ti a n lọ jáde?
Mo gbàgbọ́ pé yio rẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára wa kíákíá nípa ìsásókè kékeré tọ̀run yi. A kọ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì ayé nípa ìrírí. Nípa kíkọ lára àwọn àṣìṣe wa. Nípa ríronúpìwàdà àti mímọ̀ fún ra wa pé ìwà búburú kò jẹ́ inú dídùn rí.”11
Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, kú kí àṣìṣe wa ma bàá dáwa lẹ́bi ki o ma sì dá ìlọsíwájú wa dúró. Nítorí Rẹ, a lè ronúpìwàdà, àwọn àṣìṣe wa yio si di òkúta-ìgbésẹ̀ sí ògo ti o tóbi jùlọ.
Ẹ kò ní láti dá nìkan rin ọ̀nà yí. Bàbá wa Ọ̀run kò fi wá sílẹ̀ láti ráre nínú òkùnkùn.
Èyí ni ìdí, ni ìgbà ìrúwé 1820, Ó yọ pẹ̀lú Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, sí ọ̀dọ́mọkùnrin kan, Joseph Smith.
Ronú nípa ìyẹn fún àkokò kan! Ọlọ́run àgbáyé yọ sí ọkùnrin kan!
Èyí jẹ àkọ́kọ́ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbápàdé tí Joseph ní pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn ẹ̀dá ọ̀run míràn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínu àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn ẹ̀dá ti ọ̀run wọ̀nyí sọ wà ni àkọsílẹ̀ àwọn ìwé mímọ́ ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Wọ́n rọrùn láti wa. Ẹnikẹ́ni le kà wọn àti láti kọ́ fúnra wọn ìfiránṣẹ́ tí Ọlọ́run ní fún wa ni ọjọ́ wa.
A pè yín láti wá kí ẹ sì ṣàṣàrò fùnra yín.
Joseph Smith kéré púpọ̀ nígbà ti o gba àwọn ìfihàn wọ̀nyí. Púpọ̀ nínú wọn wa kí ó tó pé ọgbọ̀n ọdún.12 Kò ní ìrírí, àti sí àwọn ènìyàn míràn, kò kàwé tó láti jẹ́ wòlíì Olúwa.
Àti pé síbẹ̀ Olúwa pè é bẹ́ẹ̀náà—títẹ̀lé àwòṣe kan tí a ri káàkiri àwọn ìwé mímọ́.
Ọlọ́run kò dúró láti rí ẹni pípé láti mú ìhìnrere padàsípò.
Kání Ó ṣe bẹ̀ẹ́, Ohun yio ṣi máa dúró ni.
Joseph jẹ́ púpọ̀ bí ẹ̀yin àti èmi. Biotilẹ̀jẹ́pé Joseph ṣe àwọn àṣìṣe, Ọlọ́run lo o láti ṣe àṣepé àwọn ètò nla Rẹ̀.
Ààrẹ Thomas S. Monson fì ìgbàgbogbo tún àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú yi sọ: “Ẹni ti Olúwa pe, Olúwa kàá yẹ.”13
Àpóstélì Páúlù ròó pẹ̀lú àwọn Ènìyàn Mímọ́ ni Kọ́ríntì: “Ẹ sa wo ìpè yin, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin: kìí ṣe ọ̀pọ̀ yín ni ọlọgbọ́n ènìyàn nípa ti ara, kìí ṣe ọ̀pọ̀ ni o lágbára, kìí ṣe ọ̀pọ̀ ni a bí bíi ọlọ́lá.”14
Ọlọ́run n lo àìlera àti títẹ́jú láti mú àwọn èrò Rẹ̀ ṣẹ. Òtítọ́ yi dúró bi ẹ̀rí pé agbára Ọlọ́run ni, kìí ṣe ti ènìyàn, tí o n mú iṣẹ́ Rẹ̀ ṣẹ ni ayé.15
Gbọ́ Tirẹ̀, Tẹ̀lé E
Nígbà ti Ọlọ́run yọ sí Joseph Smith, Ó júwe ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ó sì wípé, “Gbọ́ Tirẹ̀!”16
Josep lo ìyókù ayé rẹ ní gbígbọ́ Ọ àti títẹ̀le E.
Bí ó ti wà pẹ̀lú Joseph, ipò ọmọ ẹ̀hìn wa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpinnu láti gbọ́ àti láti tẹ̀lé Jésù Krístì Olùgbàlà.
Bí o bá fẹ́ tẹle E, kó ìgbàgbọ́ rẹ jọ ki o si gbe agbelebu Rẹ si orí ara rẹ.
Wa ri pe ìwọ jẹ́ wíwà pẹ̀lú Ìjọ Rẹ̀—ibi ìfẹ́ àti ìkíni káàbọ níbi ti ẹ tì lè dàpọ̀ mọ́ ìlépa nla ipò ọmọ ẹ̀hìn àti ìdùnnú.
Ìrètí mi ni pé, ní Igba ọdún Ìran Àkọ́kọ́ yi, bi a ṣe n ṣe àṣàrò ti a sì n kọ́ nípa Ìmúpadàbọ̀sípò ti Ìjọ Jésù Krístì, a ó mọ pé kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ onítàn nìkan. Ìwọ àti Èmi ní ipa pàtàkì nínú ìtàn nla onítẹ̀síwájú yi.
Kíni, nígbànáà, ni tìrẹ àti èmi?
Ó jẹ́ láti kọ́ nípa Jésù Krístì. Láti ṣàṣàrò àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Láti gbọ́ àti láti tẹ̀lé E nípa fífi aápọn ṣe àbápín nínú iṣẹ́ nla yi. Mo pè yín láti wá kí ẹ sì Wà Pẹ̀lú!
Ẹ kò ní láti jẹ́ pípé. Ẹ kàn nílò láti nifẹ láti mú ìgbàgbọ̀ yín dàgbà àti láti sún mọ́ Ọ lójojúmọ́.
Ipa wa ni láti nifẹ àti láti sin Ọlọ́run kí a sí nifẹ àti ki a sì sin àwọn ọmọ Ọlọ́run.
Bí ẹ ti nṣe bẹẹ, Ọlọ́run yio yi yin ká pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ, ayọ̀, àti àwọn ìtọ́sọ́nà nínú ayé yi, àní lábẹ́ àwọn ipò líle jùlọ, àní àti ìkọjá.
Nípa èyí ni mo jẹ́rí tí mo sì fi ìbùkún mi sílẹ̀ nínú ìjìnlẹ̀ ìmoore àti ìfẹ́ fún ẹnikọ̀ọ̀kan yín, ní orúkọ mímọ́ Olùgbàlà wa, Ọ̀gá wa—iní orúkọ Jésù Krístì, àmín.