Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Gbọ́ Tirẹ̀!”
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Gbọ́ Tirẹ̀!”

Bàbá wa mọ̀ pé nígbàtí àìnírètí àti ẹ̀rù bá yí wa ká, ohun tí yíò rànwálọ́wọ́ jùlọ ni láti gbọ́ ti Ọmọ Rẹ̀.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, bí mo ṣe lọ́pẹ́ tó pé nípasẹ̀ lílo ẹ̀rọ̀ ìgbàlódé a ti lè pàdé papọ̀ láti jọ́sìn ní òwúrọ̀ Ọjọ́-ìsinmi. Bí a ti jẹ́ alábùkún tó láti mọ̀ pé ìhìnrere Jésù Krístì ti padàbọ̀sípò sí ilẹ̀ ayé.

Ní àwọn ọ̀sẹ̀ tó kọjá, púpọ̀ làra wa ní ìrírí ìdíwọ́ nínú ayé arawa. Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀, iná, àgbàrá, àjàkálẹ̀ àrùn, àti àbájáde wọn ti ṣèdíwọ́ ipa ọ̀nà iṣẹ́ àti àìsì oùnjẹ tó, ohun ọjà, àti ìfowópamọ́.

Ní àárín gbogbo èyí, yìn yín àti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún yíyàn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa ní àkokò rògbòdìyàn yí nípa dídarapọ̀ pẹ̀lú wa fún ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Òkùnkùn tó npọ̀ si tí ó pẹ̀lú ìpọ́njú nmú ìmọ́lẹ̀ Jésù Krístì tàn dídán láé. Kàn ronú nípa rere tí a lè ṣe lọ́kộọ̀kan làkokò rògbòdìyàn àgbáyé yí. Ìfẹ́ yín nípa àti ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà lè jẹ́ amúṣẹ́yá gan fún ẹnìkan láti wá Ìmúpadàpọ̀sípò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere Jésù Krístì rí.

Ní ọdún méjì sẹ́hìn, Arábìnrin Nelson àti èmi pàdé àwọn ẹgbẹ̀rún yín káàkiri ayé. A ti pàdé yín ní àwọn agbègbè ìta àti ní yàrá-bọ́ọ̀lu ilé ìtura. Ní ibi kọ̀ọ̀kan, mo ti nímọ̀lára pé èmi wà níwájú àwọn tí Olúwa yàn bí mo ti nrí ìkójọ Ísráẹ́lì tó nṣẹlẹ̀ lóju mi.

À ngbé ní ọjọ́ náà “àwọn bàbánla wa ti dúró pẹ̀lú ìgbìrò ìtara.“ A ní àwọn ijoko ìlà-iwájú láti jẹri láàyè ohun tí wòlíì Néfì rí nínú ìran nìkan, pé “agbára Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run“ yíò sọ̀kalẹ̀ “sórí àwọn ènìyàn májẹ̀mú Olúwa, tí a fọ́nká ní gbogbo orílẹ̀ ayé; tí a ró wọn pẹ̀lú òdodo àti pẹ̀lú agbára Ọlọ́run nínú ògo nlá.“

Ẹ̀yin, arákùnrin àti arábìnrin mi, wà lára àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọ tí Néfì rí. Ronú nípa èyíinì!

Láìka ibikíbi tí ẹ̀ ngbé tàbí ipò tí ẹ wà sí, Olúwa Jésù Krístì ni Olùgbàlà yín, wòlíì Ọlọ́run Joseph Smith ni wòlíì yín. A ti yàn ań ṣíwájú ìpìlẹ̀ ilẹ̀-ayé yí láti jẹ́ wòlíì ti àkokò ìkẹhìn yí, nígbàtí “a kò ní di ohunkóhun mú“ kúrò lọ́dọ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́. Ìfihàn ntẹ̀síwájú láti ṣàn látọ̀dọ̀ Olúwa nínú ètò Ìmúpadàbọ̀sípò tó nlọ lọ́wọ́.

Kí ni ó túmọ̀ sí fún yín pé ìhìnrere Jésù Krístì ti padàbọ̀sípò sí ilẹ̀ ayé.

Ó túmọ̀ sí pé ẹ̀yin àti ẹbí yín lè ṣe èdidì papọ̀ títíláé! Ó túmọ̀ sí pé nítorí ẹ ti ṣe ìrìbọmi nípasẹ̀ ẹnìkan tí ó ní àṣẹ ládọ̀tdọ̀ Jésù Krístì tí wọ́n sì ti gba ìgbọ́wọ́lé bí ọmọ Ìjọ Rẹ, ẹ lè gbádùn ojúgbà Ẹ̀mí Mímọ́ Léraléra. Òun yíò tọ́nisọ́nà yíò sì dáàbòbò yín. Ó túmọ̀ sí pé a kò ní fi yín sílẹ̀ láìní-ìtùnú tàbí láìsí ààyè sí agbára Ọlọ́run láti ràn yín lọ́wọ́. Ó túmọ̀ sí pé agbára oyèàlùfáà lè bùkún yín bí ẹ ṣe ngba àwọn ìlànà pàtàkì tí ẹ sì ndá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run tí ẹ sì npa wọ́n mọ́. Írú ìdákòró sí ẹ̀mí wa ni àwọn òtítọ́ wọ̀nyí, nípàtàkì ní àwọn ìgbà wọ̀nyí nígbàtí ìjì njà.

Ìtàn Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ òkìkí ìdìde àti ìṣubù àwọn ọ̀làjú méjì. Ìwé-ìtàn wọn júwe bí ó ti rọrùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti gbàgbé Ọlọ́run, kọ ìkìlọ̀ àwọn wòlíì Olúwa, wá agbára, òkìkí, àti ìgbádùn ti ara. Léralérá, àwọn wòlíì tẹ́lẹ̀ ti kéde “àwọn ohun nlá àti ìyanu sí ènìyàn, èyí tí wọn kò gbàgbọ́.“

Kò sí ìyàtọ̀ ní ọjọ́ wa. Ní ọ̀pọ̀ ọdún, a ti gbọ́ àwọn ohun nlá àti ìyanu látorí pẹpẹ káàkiri ilẹ̀-ayé. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ènìyàn gba òtítọ́ wọ̀nyí mọ́ra—nítorí bóyá wọn kò mọ ibi láti wá wọn tàbí nítorí wọ́n nfetísílẹ̀ sí àwọn tí kò ní gbogbo òtítọ́ tàbí wọ́n ti kọ òtítọ́ nínú ojúrere ìlépa ti-ayé.

Ọ̀tá jẹ́ olùjáfáfá. Fún mìllẹ́níà òun ti mú rere dàbí ibi àti ibi dàbí rere.7 Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ndàbí aruwò, ìgbójú, àti ìgbéraga.

Bákannáà, àwọn ọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Bàbá wa Ọ̀run yanilẹ́nu yàtọ̀. Ó nbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, jẹ́jẹ́, àti pẹ̀lú irú ìyàlẹ́nu kedere tí a kò lè ṣàìní ìmọ̀ Rẹ̀.

Fún àpẹrẹ, ìgbàkugbà tí Ó ti fi Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Níkanṣoṣo hàn sí ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé, Ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ alámì. Ní Òke Ìyípòpadà sí Pètèrù, Jákọ́bù, àti Jòhánnù, Ọlọ́run wípé, “Èyí ni àyànfẹ́ Ọmọ mi: gbọ́ tirẹ̀.“ Ọrọ̀ Rẹ̀ sí àwọn ará Néfì ní Bountiful àtijọ́ ni “Kíyèsi Àyànfẹ́ Ọmọ mi, tí inú mi dùn sí, nínú ẹnití mo ṣorúkọ mi lógo— ẹ gbọ́ tirẹ̀.“ Àti sí Joseph Smith, nínú ìkéde ìjìnlẹ̀ tí ó ṣí àkokò yí, Ọlọ́run wí jẹ́jẹ́ pé,“Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ Tirẹ̀!11

Báyìí, ẹ̀nyin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, gbèrò òtítọ́ pé nínú àwọn àpẹrẹ mẹ́ta wọ̀nyí tí mo ṣẹ dárúkọ, kí Bàbá tó fi Ọmọ hàn, àwọn ènìyàn ibẹ̀ wà ipò ìbẹ̀rù àti, dé ipò díẹ̀, àìnírètí.

Àwọn Àpọ́stélì bẹ̀rù nígbàtí wọ́n rí ìkuukù tó yí Jésù K Krístì ká ní Òke Ìyípòpadà.

Àwọn ará Néfì bẹ̀rù nítorí wọn ti rí ìparun àti òkùnkùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́.

Joseph Smith wà nínú apá lílè òkùnkùn kí àwọn ọ̀run tó ṣí.

Bàbá wa mọ̀ pé nígbàtí àìnírètí àti ẹ̀rù bá yí wa ká, ohun tí yíò rànwálọ́wọ́ jùlọ ni láti gbọ́ ti Ọmọ Rẹ̀.

Nítorí nígbàtí a bá wá láti gbọ́— lotítọ́ gbọ́—Ọmọ Rẹ̀ , àwa yíò gba ìtọ́nisọ́nà láti mọ ohun ti a ó ṣe nínú ipòkípò.

Ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ gan an nínú Ẹ̀kọ́ àti awọn Májẹ̀mú ni fetísílẹ̀.12 Ó túmọ̀ sí láti fetísílẹ̀ pẹ̀lú èrò láti gbọ́ran.”13 Láti fetísílẹ̀ túmọ̀ sí láti “Gbọ́ Tirẹ̀“—láti gbọ́ ohun tí Olùgbàlà sọ àti láti gbọ́ ìmọ̀ràn Rẹ̀. Nínú àwọn ọ̀rọ̀ méjì wọnnì— “Gbọ́ Tirẹ̀“—Ọlọ́run fún wa ní àwòṣe fún àṣeyege, ìdùnnú, àti ayọ̀ ní ayé yí. A níláti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa, fetísílẹ̀ sí wọn, àti gbọ́ ohun tí Ó sọ fún wa!

Bí àwọn ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì, ìtiraka wa láti gbọ́ Tirẹ̀ níláti jẹ́ mímọ̀ọ́mọ̀ si. Ó gba ìfura àti ìtiraka lemọ́lemọ́ láti kún inú ayé wa pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Rẹ̀, ìkọ́ni Rẹ̀, òtítọ́ Rẹ̀.

A kò lè gbáralé ìwífúnni tí a kàn rí lórí ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn. Pẹ̀lú àwọn âdọ́ta ọ̀kẹ́ méjì ọ̀rọ̀ lórí ayélujára àti ìtajà tó kún ríro ayé léraléra nípasẹ̀ ariwo, ìtiraka bíburújáì ọ̀tá, níbo ni a le lọ láti gbọ́ ti Rẹ̀?

A lè lọ sínú àwọn íwé mímọ́. Wọ́n kọ́ wa nípa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀, ọlánlá Ètùtù Rẹ̀, àti ètò ìdùnnú àti ìràpadà nlá ti Bàbá wa. Rírìraẹni sínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lojoojúmọ́ ṣe pàtàkì fún ìgbàlà ti ẹ̀mí nípàtàkì ní àwọn ọjọ́ wàhàlà púpọ̀si. Bí a ti nṣe àpèjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì lójoojúmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ Krístì yíò sọ fún wa bí a ó ṣe dáhùn sí àwọn ìṣòrò tí a kò rò pé a lè dojúkọ.

Bákannáà a lè Gbọ́ Tirẹ̀ nínú tẹ́mpìlì. Ilé Olúwa ni ilé ìkẹ́ẹ̀kọ̀. Níbẹ Olúwa nkọ́ni ní ọ̀nà Ararẹ̀. Níbẹ̀ ìlànà kọ̀ọ̀kan nkọ́ni nípa Olùgbàlà. Níbẹ̀ a kọ́ bí a ṣe lè ṣí ìbòjú kí a sì bá ọ̀run sọ̀rọ̀ yèkéyéké si. Níbẹ̀ a kọ́ bí a ṣe lè bá ọ̀tá wí kí a sì fá agbára oyèàlùfáà Olúwa láti fún wa lókun àti àwọn tí a fẹ́ràn. Bí ó ti yẹ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wà nítara láti wá ààbò níbẹ̀.

Nígbàtí ìsélé COVID-19 ránpẹ́ wọ̀nyí bá kúrò, ẹ jọ̀wọ́ ẹ wá àkokò déédé láti jọ́sìn kí ẹ sìn nínú tẹ́mpìlì. Gbogbo ìṣẹ́jú àkokò náà yíò bùkún yín àti ẹbí yín ní àwọn ọ̀nà tí ohun míràn kò lè ṣe. Ẹ wá àkokò láti jíròrò ohun tí ẹ gbọ́ tí ẹ sì mọ̀lára nígbàtí ẹ wà níbẹ̀. Ẹ bèèrè lọ́wọ́ Olúwa láti kọ́ọ yín bí ẹ ó ṣe ṣí ọ̀run láti bùkún ìgbé ayé yín àti ìgbé ayé àwọn tí ẹ fẹ́ràn tí ẹ̀ nsìn.

Nígbàtí jíjọ́sìn nínú tẹ́mpìlì nísisìyí kò ṣeéṣe, mo pè yín láti mú ìkópa yín nínú ìwé-ìtàn ẹbí pọ̀si, pẹ̀lú ìwákiri ìwé ìtàn ẹbí àti ìtọ́kasí. Mo ṣèlérí pé bí ẹ ti nmú àkokò yín nínú tẹ́mpìlì àti iṣẹ́ ìwé-ìtàn ẹbí pọ̀si, ẹ ó pọ̀si ẹ ó sì gbèrú nínú okun yín láti gbọ́ ti Rẹ̀.

Bákannáà a Gbọ́ Tirẹ̀ yékéyéké si bí a ti ntún agbára wa ṣe láti da ìṣínilétí Ẹ̀mí Mímọ́ mọ̀. Kó jẹ́ tàṣẹtàṣẹ́ si rí láti mọ̀ bí Ẹ̀mí ṣe nsọ̀rọ̀ síi yín ju báyìí lọ. Nínú Olórí-ọ̀run, Ẹ̀mí Mímọ́ ni olùránṣẹ́. Òun ó mú àwọn èrò èyítí Bàbá àti Ọmọ nfẹ́ kí ẹ gbà wá sí òye-inú yín. Òun ni Olùtùnú. Òun yíò mú ìmọ̀lára àláfíà wá sínú ọkàn yín. Òun yíò jẹ́ ẹ̀rí òtítọ́ yíò sì fi ẹsẹ̀ ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ múlẹ̀ bí ẹ ti ngbọ́ tí ẹ sì nka ọ̀rọ̀ Olúwa.

Mo tún ẹ̀bẹ̀ mi bẹ̀ fún yín láti ṣe ohunkóhun tí ó gbà láti mú agbára ti ẹ̀mí yín pọ̀si láti gba ìfihàn araẹni.

Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yíò ràn yín lọ́wọ́ láti mọ̀ bí ẹ o ṣe rìn síwájú pẹ̀lú ayé yín, ohun tí ẹ ó ṣe nígbà ìdàmú, àti bí ẹ ó ṣe damọ̀ àti láti yẹra fún àwọn àdánwò àti àwọn ẹ̀tàn ti ọ̀tá.

Àti, ní òpin, a lè Gbọ́ Tirẹ̀ bí a ṣe nfetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì, aríran, àti olùfihàn. Àwọn Àpọ́stélì Jésù Krístì tí a yàn njẹ́ri Rẹ̀ nígbàgbogbo. Wọ́n njúwe ọ̀nà bí a ṣe nwá ọ̀nà kọjá nínú ọkàn-rírọ́ ìrújú àwọn ìrírí ayé ikù wa.

Kíni yíò ṣẹlẹ̀ bí ẹ ti nmọ̀ọ́mọ̀ gbọ́, fetísílẹ̀, àti gbà ohun tí Olùgbàlà ti sọ àti ohun tí Ó nsọ báyìí nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀? Mo ṣèlérí pé ẹ ó di alábùkún pẹ̀lú àlékún agbára láti dojúkọ àdánwò, ìlàkàkà, àti àìlera. Mo ṣèlérí àwọn iṣẹ́ ìyanu nínú ìgbeyàwó yín, ìbáṣepọ̀ ẹbí, àti iṣẹ́ ojoojúmọ́. Mo sì ṣèlérí pé agbára yín láti ní ìmọ̀lára ayọ̀ yíò pọ̀si àní bí èwu tilẹ̀ pọ̀si nínú ìgbé ayé yín.

Ìpàdé àpapọ gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020 yí ni àkokò wa láti ṣayẹyẹ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó yí ayé padà. Bí a ti nretí àjọ̀dún igba ọdún Ìran Kínní Joseph Smith yí, Àjọ Ààrẹ Kínní àti Ìgbìmọ̀ àwọn Àpọ́stélì mèjìlá jíròrò ohun tí a ṣe láti ṣayẹyẹ déédé ní ìṣẹ̀lẹ̀ kanṣoṣo yí.

Ìfihàn náà bẹrẹ Ìmúpadàbọ̀sípò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere Jésù Krístì ó sì mú àkokò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ìgbà wá.

À ròó bí a bá lè ya ohun-ìrántí kan. Ṣùgbọ́n bí a ti gbèrò ipa onítàn àràọ̀tọ̀ àti kárí-ayé Ìràn Àkọ́kọ́ náà, a nímọ̀lára ìwọnilọ́kàn láti dá ohun-ìrántí kan sílẹ̀ tí kìí ṣe gránáítì tàbí òkúta ṣùgbọ́n ti àwọn ọ̀rọ̀—àwọn ọ̀rọ̀ ọ̀wọ̀ àti ìkéde mímọ́—tí a kọ, kìí ṣe gbígbẹ́ lórí “àwọn tábìlì òkúta“ ṣùgbọ́n síbẹ̀ láti kọ́ sí “ara ẹran tábìlì“ ti ọkàn wa.

Látìgbà tí a ti ṣètò Ìjọ, àwọn ìkéde marun ní a ti tẹ̀ jáde, pẹ̀lú ìkẹ́hìn tó jẹ́ “Ẹbí Náà: Ìkéde kan sí Àgbáyé,“ tí a gbékalẹ̀ látọwọ́ Ààrẹ Gordon B. Hinckley ní 1995.

Báyìí bí a ti nrò ìgbà pàtàkì yí nínú ìwé ìtàn ayé àti àṣẹ Olúwa lái kó àwọn olùfọ́nká Ísráẹ́lì jọ ní mímúrasílẹ̀ fún Bíbọ Ẹ̀ẹ̀kejì Jésù Krístì, àwa, Àjọ Ààrẹ Kínni àti Ìgbìmọ̀ àwọn Méjìlá, tẹ ìpolongo wọ̀nyí jáde. Àkọlé rẹ̀ ni “Ìmúpadàbọ̀sípò Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhinrere Jésù Krísti: ÌPolongo Igba Ọdún Kan Sí Àgbáyé,” Apr. 2020. Tí a kọ látọwọ́ Àjọ Ààrẹ Kínní àti Ìgbìmọ̀ àwọn Méjìlá ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Tí a ṣe ní Oṣù Kẹrin 2020. Láti múrasílẹ̀ fún òní, mo ti kọ ìpolongo yí sílẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nínú Igbó Mímọ́, níbití Joseph Smith ti kọ́kọ́ rí Bàbà àti Ọmọ.

A fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ polongo pé Ọlọ́run nifẹ àwọn ọmọ Rẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè ti ayé. Ọlọ́run Bàbá ti fún wa ní ìbí tọ̀run, ìgbé ayé àìlẹ́gbẹ́, àti ètùtù ìrúbọ àìlópin Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Nípa agbára Bàbá, Jésù dìde lẹ́ẹ̀kansi ó sì jèrè ìṣẹ́gun lórí ikú. Òun ni Olùgbàlà wa, Alápẹrẹ wa, àti Olùràpadà wa.

“Igba ọdún sẹ́hìn, ní òwúrọ̀ kan ìgbà ìrúwé ní 1820, Joseph Smith kékeré, nwá láti mọ ìjọ ẹ̀yítí yíò darapọ̀mọ́, lọ sínú igi láti gbàdúrà nítòsí ilé rẹ̀ ní ípínlẹ̀òkè New York, USA. Ó ní àwọn ìbèèrè ní ìkàsí sí ìgbàlà ẹ̀mí rẹ̀ àti ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run yíò darí rẹ̀.

“Nínú ìrẹ̀lẹ̀, a kéde pé ní ìdáhùn sí àdúrà rẹ̀, Ọlọ́run Bàbá àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, farahàn sí Joseph ó sì fì ’ìmúpadà ohun gbogbo’ (Ìṣe àwọn Àpọ́stélì 3:21) bí a ṣe sọtẹ́lẹ̀ nínú Bíbélì. Nínú ìran yí, a kọ́ pé lẹ́hìn ikú àwọn Àpọ́stélì àkọ́kọ́, Ìjọ Krístì ti Májẹ̀mú Titun sọnù kúrò ní ilẹ̀ ayé. Joseph yíò jẹ́ ohun-èlò nínú ìpadàbọ̀ rẹ̀.

“A tẹnumọ pé lábẹ́ ìdarí Bàbá àti Ọmọ, àwọn olùránṣẹ́ ọ̀run wá láti pàṣẹ fún Joseph àti láti tún Ìjọ Jésù Krístì gbé kalẹ̀. Jòhánù onírìbọmi olùjíìnde mú àṣẹ láti ṣe ìrìbọmi nípa rírini-sínú omi padàbọ̀sípò fún ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀. Mẹ́ta nínú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá àkọ́kọ́—Pétérù, Jákọ́bù, àti pé Jòhánù—mú jíjẹ́ àpọ́stélì àti kọ́kọ́rọ́ àṣẹ oyèàlùfáà padàbọ̀sípò. Àwọn míràn wá bákannáà, pẹ̀lú Èlíjàh, tí ó mú àṣẹ láti so áwọn ẹbí pọ̀ títíláé nínú àwọn ìbáṣepọ̀ ayérayé tí ó kọjá ikú.

A jẹ́ẹ̀rí síwájúsi pé Joseph Smith ni a fún ní ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run láti ṣe àyípadà-èdè àkọsílẹ̀ àtijọ́ kan: Ìwé ti Mọ́mọ́nì— Ẹ̀rí Míràn ti Jésù Krístì. Àwọn ojú-ewé àtẹ̀kọ mímọ́ yí pẹ̀lú àkọsílẹ̀ nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ araẹni ti Jésù Krístì ní àári\n ènìyàn ní Ìwọ-òòrùn Àwòrán Ìlàjì Ayé làìpẹ́ lẹ́hìn Àjíìnde Rẹ̀. Ó kọ́ni ní èrò ayé ó sì ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Krístì, èyí tí ó jẹ́ gbùngbun sí èrò náà. Bí ojúgbà ìwé mímọ́ kan sí Bíbélì, Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ẹ̀rí pé gbogbo ènìyàn ẹlẹ́ran-ara jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin olùfẹ́ni Bàbá Ọ̀run, pé Òun ní ètò tọ̀run kan fún ìgbé ayé wa, àti pé Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, nsọ̀rọ̀ loni bákannáà bí ìgbà àtijọ́.

“A kéde pé Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, tí a ṣètò ní Ọjọ́ Kẹfà Oṣù Kẹ́rin, 1830, ni Ìjọ Krístì Májẹ̀mú Titun tí a múpadàbọ̀sípò. Ìjọ yí ni ó rọ̀mọ́ ìgbé ayé pípé ti olórí igun-òkúta, Jésù Krístì, àti Ètùtù Àìlópin Rẹ̀ àti bí ọ̀rọ̀ Àjíìnde. Jésù Krístì ti pe àwọn Àpọ́stélì lẹ́ẹ̀kansi ó sì ti fún wọn ní àṣẹ oyèàlùfáà. O pe gbogbo wa láti wá sọ́dọ̀ Rẹ̀ àti Ìjọ Rẹ̀, láti gba Ẹ̀mí Mímọ́, àwọn ìlànà ìgbàlà, àti láti jèrè ayọ pípẹ́.

“Igba ọdún ti kọjá báyìí látìgbà tí Ìmúpadàbọ̀sípò ti wá látọwọ́ Ọlọ́run Bàbá àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Àwọn míllíọ̀nù káàkiri ayé ti gba ìmọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí mọ́ra.

“A fi tìdùnnú-tìdùnnú kéde pé ìlérí Ìmúpadàbọ̀sípò nlọ síwájú nípasẹ̀ ìtẹ̀síwájú ìfihàn. Ilẹ̀ ayé kò ní rí bákannáà mọ́ láé, bí Ọlọ́run yíò ti “kó gbogbo ohun papọ̀ ní ọ̀kan nínú Krístì.“

Pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìmoore, àwa bí Àpọ́stélì Rẹ̀ pe gbogbo ènìyàn láti mọ̀—bí a ti ṣe—pé àwọn ọ̀run ti ṣí. A tẹnumọ pé Ọlọ́run nfi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn fún àwọn àyànfẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Rẹ̀. “A jẹri pé àwọn wọnnì tí yíò fi tàdúrà-tàdúrà ṣàṣàrò ọ̀rọ̀ Ímúpadàbọ̀sípò àti ìṣe nínú ìgbàgbọ́ yíò di alábùkúnfún láti jèrè ẹ̀rí ti arawọn nípa àtọ̀runwá rẹ̀ àti nípa èrò rẹ̀ láti múra ayé sílẹ̀ fún ìlérí Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.”

Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin, èyí ni ìpolongo igba ọdún wa sí àgbáyé ní ìkàsí Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀. A ti ṣe àyípadà-èdè rẹ̀ sí ọ̀nà méjìlá. Àwọn èdè míràn yíò tẹ̀le láìpẹ́. Yíò wa lorí ibiwẹ́ẹ̀bù Ìjọ lọ́gán, látinú èyí tí ẹ lè ti gba ẹ̀dà kan. Ẹ ṣe àṣàrò ìkọ̀kọ̀ àti pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí yín àti àwọn ọ̀rẹ́. Ẹ jíròrò àwọn òtítọ́ kí ẹ sì ronú ipa tí àwọn òtítọ́ wọnnì yíò ní lórí ìgbé ayé yín bí ẹ bá gbọ́ wọn, fetísí wọn, kí ẹ sì gbà àwọn òfin àti májẹ̀mú tí ó wà pẹ̀lú wọn.

Mo mọ̀ pé Joseph Smith ni wòlíì ti a ti yàn ẹnití Olúwa yàn láti ṣí àkokò ìkẹhìn yí. Nípasẹ̀ rẹ̀ Ìjọ Olúwa ti padàbọ̀sípò ní ilẹ̀ ayé. Joseph di ẹ̀rí rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Bí a ṣe nifẹ rẹ̀ tí a sì buọlá fun tó!

Ọlọ́run wà láàyè! Jésù ni Krístì. Ìjọ Rẹ̀ ni ati mú padàbọ̀sípò! Òun àti Bàbá Rẹ̀, Bàbá wa Ọ̀run, mbojú tó wa. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀