Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, nísisìyí yíò jẹ́ ànfàní mi láti gbé àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, àwọn Àádọ́rin Agbègbè, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò Ìjọ kalẹ̀ fún ìbò ìmúdúró yín.

A bèèrè pé kí ẹ jọ́wọ́ fi àtìlẹhìn yín hàn bí ẹ ti nṣe, níbikíbi tí ẹ lè wà. Bí a bá rí àwọn wọ̀nni tí wọ́n tako eyikeyi nínú àwọn àbá náà, a bèèrè pé kí ẹ kàn sí ààrẹ èèkàn yín.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró Russell Marion Nelson bí wòlíì, aríran, àti olùfihàn àti Ààrẹ Ìjọ Jésù Kristì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn; Dallin Harris Oaks bí Olùdámọ̀ràn Ìkínní; àti Henry Bennion Eyring bí Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkinní.

Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.

Àwọn wọnnì tó bá tàkòó, tí ẹnikẹ́ni bá wà, lè fihàn.

A dalaba pé kí ṣe imúdúró Dallin H. Oaks bí Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá àti Jeffrey R. Holland bí Aṣojú Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá.

Àwọn to bá faramọ, jọ̀wọ́ ṣàpẹrẹ.

Alátakò kankan tó bá wa lè fihàn.

A dalaba kí a ṣe imúdúró àwọn wọ̀nyí bí ọmọ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá: Jeffrey R. Holland, Dieter F. Uchtdorf, David A. Bednar, Quentin L. Cook, D. Todd Christofferson, Neil L. Andersen, Ronald A. Rasband, Gary E. Stevenson, Dale G. Renlund, Gerrit W. Gong, Ulisses Soares, àti Patrick Kearon

Àwọn tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Alátakò kankan lè ṣe àmì bẹ́ẹ̀.

A dalaba kí a ṣe ìmúdúró àwọn olùdámọ̀ràn nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá bí àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Ìlòdì, tí ẹnìkankan bá wá, nípa irú àmì kannáà.

A ṣe àkíyèsí pé àwọn Àádọ́rin Agbègbè titun mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ni a múdúró nínú àwọn ìpàdé olórí àpapọ̀ gbogbogbò ní Ọjọ́bọ̀, Ọjọ́ Kẹta Oṣù Kẹwa, lẹ́hìnnáà a sì kéde rẹ̀ sí orí ibi ayélujára Ìjọ. A pè yín láti ṣe ìmúdúró àwọn arákùnrin wọ̀nyí nínú yíyàn síṣẹ́ wọn titun.

Àwọn tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Àwọn alátakò, nípa irú àmì kannáà.

A dalaba pé kí a ṣè ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò bí a ṣe gbé wọn kalẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa nínawọ́ sọ́kè.

Àwọn alátakò, to báwa.

A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, fún ìtẹ̀síwájú ìgbàgbọ́ yín àti àdúrà ní ìtìlẹhìn àwọn olórí Ìjọ.

Àwọn Ìyípadà sí Àwọn Àádọ́rin Agbègbè

Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a ṣe ìmúdúró fún nínú abala àwọn olórí kan tí a ṣe bí ara ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò:

Miguel A. Avila, Jean Pierre A. L. Haboko, Ramiro Ibarra Sanchez, George Katembo Njogu Munene, A. Enrique Texeira, Francisco Villanueva Rojas.