Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìrọ̀rùn Ni Ẹ̀kọ́ Jésù Krístì
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


Ìrọ̀rùn Ni Ẹ̀kọ́ Jésù Krístì

Mo jẹ́ ẹ̀rí nípa iṣẹ́ mímọ́ ti kíkọ́ àwọn ọmọ Baba Ọ̀run ní ẹ̀kọ́ ìrọ̀rùn Jésù Krístì.

Gbogbo wa ní àwọn ọmọ ẹbí tí a nifẹ tí wọ́n ngba àdánwò àti ìdánwò nípasẹ̀ ìdàbí àwọn ipa Sátánì, olùparun, ẹnití yíò mú gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run banújẹ́ léraléra. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára wa, àwọn òru àìlèsùn ti wà. A ti gbìyànjú láti yí àwọn ènìyàn náà ká tí wọ̀n wà nínú ewu pẹ̀lú gbogbo ipa fún rere. A ti bẹ̀bẹ̀ nínú àdúrà fún wọn. A ti nifẹ wọn. A ti gbé àpẹrẹ dídárajùlọ tí a lè ṣe sílẹ̀.

Álmà, ọlọgbọ́n wòlíì kan láti ìgbà àtijọ́, kojú ìrú àwọn àdánwò kannáà. Àwọn ènìyàn náà tí ó darí tí ó sì nifẹ wà lábẹ́ ìkọlù lémọ́lemọ́ nípasẹ̀ ìrorò ọ̀tá, síbẹ̀ wọ́n ṣì ngbìyànjú láti tọ́ àwọn ọmọ olódodo nínú ayé ìwà-búburú. Álmà ní ìmọ̀lára pé ìrètí rẹ̀ kanṣoṣo nípa ìṣẹ́gun ni ipa èyí tí a lè fojúrẹ́ mọ́lẹ̀ nígbàmíràn kí a sì lo kíkéré jù. Ó bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run.

Álmà mọ̀ pé fún Ọlọ́run láti rànwálọ́wọ́, a nílò ìrònúpìwàdà nípasẹ̀ àwọn tí ó ndarí, bíi ti àwọn ọ̀tá rẹ̀ bákannáà. Bayi, ó yọkúrò fún ọ̀nà yíyàtọ̀ kan láti jà.

Ìwé ti Mọ́mọ́nì júwe rẹ̀ ní ọ̀nà yí pé, “Àti nísisìyí, bí ìwãsù ọ̀rọ̀ nã ṣe ní ipa nlá láti darí àwọn ènìyàn nã sí ipa ṣíṣe èyítí ó tọ́—bẹ̃ni, ó ti ní agbára tí ó tobi jùlọ lórí ọkàn àwọn ènìyàn nã ju idà tàbí ohun míràn tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí nwọn rí—nítorínã Álmà rõ pé ó jẹ́ ohun tí ó tọ̀nà pé kí àwọn kí ó gbìyànjú ìwàrere ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ẹ̀kọ́ tí a kọ́ni nípasẹ̀ Jésù Krístì àti nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀. Álmà mọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ní agbára nlá.

Ní ìpín e kejìdínlógún ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, Olúwa fi ìpìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ Rẹ̀ hàn:

“Nítorí, kíyèsi, mo pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbigbogbo láti ronúpìwàdà. …

“Nítorí, kíyèsi, Olúwa Olùràpadà yín jìyà ikú nínú ẹran ara; nítorínáà òun jìyà fún ìrora gbogbo ènìyàn, kí gbogbo ènìyàn lè ronúpìwàdà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

“Àti pé òun ti tún jí dìde kúrò nínú òkú, kí òun lè mú gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ní orí ìpinnu ìrònúpìwàdà.”

“Ẹ̀yin yíò sì wólẹ̀, ẹ ó sì bu ọlá fún Baba ní orúkọ mi.

“… Ẹ gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà kí a sì ṣe ìrìbọmi fún yín, ní orúkọ Jésù Krístì.”

“Bèèrè lọ́wọ́ Baba ni orúkọ mi nínú ìgbàgbọ̀, ẹ gbàgbọ́ pé ẹ o ri gbà, ẹ o si ni Ẹ̀mí Mímọ́.”

“Àti nísisìyí, lẹ́hìn … tí ẹ bá gba èyí, ẹ gbọ́dọ̀ pa àwọn òfin mi mọ́ nínú ohun gbogbo.”

“Ẹ gba orúkọ Krístì lé orí yín, kí ẹ sì sọ òtítọ́ pẹ̀lú ìronújinlẹ̀.

“Àti pé iye àwọn tí wọ́n bá ronúpìwàdà tí a sì rìbọmi ní orúkọ mi, èyí tíi ṣe Jésù Krístì, àti tí wọ́n forítì í dé òpin, àwọn kannáà ni a ó gbàlà.”

Nínú àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì díẹ̀, tí Olùgbàlà fún wa ní àpẹrẹ pípé ti bí a ṣe níláti kọ́ ẹ̀kọ́ Rẹ̀. Ẹ̀kọ́ yí ni ìgbàgbọ́ náà nínú Olúwa Jésù Krístì, ìrònúpìwàdà, ìrìbọmi, gbigbá ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, àti fíforítì dé òpin nbùkún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.

Bí a ti nkọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ wọ̀nyí sí àwọn wọnnì tí a nifẹ, Ẹ̀mí Mímọ́ yíò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́. Nítorí a nílò àwọn ìṣílétí Ẹ̀mí Mímọ́, a gbọ́dọ̀ yẹra fún ìgbìrò tàbí ìtumọ̀ araẹni tí ó lọ kọjá ìkọ́ni ẹ̀kọ́ òtítọ́.

Tí ó lè le láti ṣe nígbàtí ẹ bá nifẹ ẹni náà tí ẹ ngbìyànjú láti ní ipá lé lórí. Òun lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin lè pa ẹ̀kọ́ tí a ti kọ́ tì. Ó máa njẹ́ ìdánniwò láti gbìyànjú ohun titun tàbí wíwuni. Ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Mímọ́ yíò fi ẹ̀mí òtítọ́ hàn nìkan bí a ti nní ìfura tí a sì nfi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ṣe àìkọjá kíkọ́ni ní ẹ̀kọ́ òtítọ́. Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tí ó dájú jùlọ láti yẹra fún àní dídé ìtòsí ẹ̀kọ́ èké ni láti yàn láti jẹ́ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìkọ́ni wa. Ààbò ni à njèrè nípa rírọrùn náà, tí a sì nsọ díẹ̀ nù.

Ìkọ́ni kàn fi àyè gba wa láti pín ẹ̀kọ́ ìgbàlà láti ìṣíwájú, nígbàtí àwọn ọmọdé dúrò láìfọwọ́kàn nípasẹ̀ àwọn àdánwò ẹlẹ́tàn tí yíò dojúkọ wọ́n lẹ́hìnwá, pípẹ́ ṣíwájú àwọn òtítọ́ tí wọ́n nílò láti kọ́ ni a mú jáde nípa aruwo ìbákẹ́gbẹ́ àwùjọ, ẹlẹ́gbẹ́, àti àwọn ìlàkàkà ti araẹni wọn. A níláti já gbogbo ànfàní gbà láti pín àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì pẹ̀lú àwọn ọmọdé. Àwọn àkokò ìkọ́ni wọ̀nyí jẹ́ iyebíye ó sì kéré gan an ní àfiwé sí àwọn ìtiraka àìdúró ti àwọn ipa àtakò. Fún gbogbo wákàtí tí a bá lò ní fifi ẹ̀kọ́ sínú ìgbésí ayé ọmọ kan, àwọn àìlónkà wákàtí ti àtakò kún pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ àti àwòrán tí ó npeni níjà tàbí pa àwọn òtítọ́ ìgbàlà wọ̀nyí tì.

Àwọn díẹ̀ lára yín lè ní ìyàlẹ́nu bóyá ó lè dára si láti kàn fà súnmọ́ àwọn ọmọ yín nípa níní ìgbádùn, tàbí ẹ lè bèèrè bóyá ọmọ náà lè bẹ̀rẹ̀ láti ní ìmọ̀lára ìbonimọ́lẹ̀ nípa àwọn ìkọ́ni yín. Dípò bẹ́ẹ̀, a níláti ṣe àyẹ̀wò, “Pẹ̀lú àkokò díẹ̀ àti àwọn ànfàní díẹ̀ , irú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wo ni mo lè pín tí yíò fún wọn lókun ní àtakò sí àwọn ìpènijà àìlèrò sí ìgbàgbọ́ wọn?” Àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹ npín ní òní lè jẹ́ àwọn wọnnì tí wọ́n gbé pẹ̀lú wọn, àti pé òní yíò kọjá lọ láìpẹ́.

Mo ti nfi ìgbàgbogbo nífẹ́sí ìfọkànsìn ìyá-mi-àgbà Màríà Bommeli sí pípín ẹ̀kọ́ Jésù Krístì. Ẹbí rẹ̀ ni a kọ́ nípasẹ̀ àwọn òjíṣẹ́-ìhìnrere ní Switzerland nígbàtí ó wà ní ọmọ ọjọ́-orí mẹ́rìnlélógún.

Lẹ́hìn ṣíṣe ìrìbọmi, Màríà ní ìfẹ́-inú láti darapọ̀ mọ́ àwọn Ènìyàn-mímọ́ ní Amẹ́ríkà, nítorínáà ó wá ọ̀nà rẹ̀ láti Switzerland lọ sí Berlin ó sì rí iṣẹ́ pẹ̀lú obìnrin kan tí ó gbà á síṣẹ̀ láti hun aṣọ fún ìwọṣọ ti ẹbí. Màríà gbé ní yàrá ìránṣẹ́ kan ó sì gbé ibi-iṣẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ sí agbègbè ilé-ìgbàlejò.

Ní àkokò náà, kíkọ́ ẹ̀kọ́ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn jẹ́ ìrúfin ní berlin. Ṣùgbọ́n Màríà rí i pé òun kò lè wà ní ìpamọ́ láìpín àwọn ohun tí òun ti kọ́. Obìnrin ilé náà àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ yíò kórajọ yíká ibi-iṣẹ́ náà láti gbọ́ tí Màríà nkọ́ni. Ó sọ̀rọ̀ ìwò Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì sí Joseph Smith, íbẹ̀wò àwọn ángẹ́lì, àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Rírántí àwọn àkọsílẹ̀ Álmà, ó kọ́ni nípa ẹ̀kọ́ Àjínde. Ó jẹri pé àwọn ẹbí le tún darapọ̀ nínú ìjọba Sẹ̀lẹ́stíà.

Inúdídùn Màríà láti pín ẹ̀kọ́ ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere láìpẹ́ fa wàhálà. Kò pẹ́ tí àwọn ọlọ́pá fi mú Màríà lọ sẹ́wọ̀n. Ní ọ̀nà, ó bèèrè lọ́wọ́ ọlọ́pá náà fún orúkọ adájọ́ tí òun ó farahàn níwájú rẹ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì. Bákannáà ó bèèrè nípa ẹbí rẹ̀ àti pé bí ó bá jẹ́ baba àti ọkọ rere. Ọlọ́pá náà júwe adájọ́ náà bí ọkùnrin ayé kan.

Nínú ẹ̀wọ̀n, Màríà bèèrè fún lẹ́ẹ̀dì kan àti ìwé díẹ̀. Ó lo òru náà ní kíkọ lẹ́tà sí adájọ́, ní jíjẹ́ ẹ̀rí sí Àjínde Jésù Krístì bi a ti júwe nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ní sísọ̀rọ̀ ayé ikú, àti ṣíṣe àlàyé ìrònúpìwàdà. Ó daba pé adájọ́ yíò nílò àkokò láti ronú lórí ìgbésí ayé rẹ̀ ṣíwájú dídojúkọ ìdájọ́ ìgbẹ̀hìn. Ó kọ pé òun mọ̀ pé ó ní ohun púpọ̀ láti ronúpìwàdà fún, púpọ̀ èyí tí yíò ba inú ẹbí rẹ̀ jẹ́ jinlẹ̀jinlẹ̀ tí yíò sì mú ìkorò nlá wá fún un. Ní òwúrọ̀ náà, nígbàtí ó kọ lẹ́tà rẹ̀ tán, ó fún ọlọ́pa náà ó sì ní kí ó bá òun fi fún adájọ̀ náà, ó sì faramọ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Lẹ́hìnnáà, a pe ọlọ́pá náà nípa adájọ́ náà lọ sí ibi-iṣẹ́ rẹ̀. Lẹ́tá náà tí Màríà kọ ni ẹ̀rí tí a kò lè sẹ́ pé ó nkọ́ ẹ̀kọ́ ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere àti pé, nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó nrú òfin. Bákannáà, kò pẹ́ kí ọlọ́pa náà tó padà sí àtìmọ́lé Màríà. Ó wí fún un pé gbogbo ẹ̀sùn rẹ̀ ni a ti mú kúrò àti pé ó ní òmìnira láti lọ. Kíkọ́ ẹ̀kọ́ ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì rẹ̀ ti mú kí a jù ú sínú ẹ̀wọ̀n. Àti pé kíkéde ẹ̀kọ́ ìrònúpìwàdà sí adájọ́ ti mú kí a le jáde kúrò ní ẹ̀wọ̀n.

Ìkọ́ni Màríà Bommeli kò parí pẹ̀lú ìdásílẹ̀ rẹ̀. Àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kọjá ẹ̀kọ́ òtítọ́ lọ nínú àwọn ìran tí a kò tíì bí. Ìgbàgbọ́ rẹ̀ pé olùyípada titun lè kọ́ ẹ̀kọ́ Jésù Krístì ti mudájú pé àwọn ìrandíran rẹ̀ yíò ní okun nínú àwọn ìjà ara wọn.

Bí a ti nṣe dídárajùlọ wa láti kọ́ àwọn wọnnì tí a nifẹ nípa ẹ̀kọ́ Jésù Krístì, àwọn kan ṣì lè mátilẹ̀ fèsì. Àwọn iyèméjì lè gbóríwọlé sínú ọkàn yín. Ẹ lẹ̀ bèèrè bóyá ẹ mọ ẹ̀kọ́ Olùgbàlà dáradára tó láti kọ́ọ dáadáa. Àti pé bí ẹ bá ti ṣe ìgbìyànjú tẹ́lẹ̀ láti kọ́ ọ, ó lè yà yín lẹ́nu ìdí tí kìí fi rí àbájáde rere sójú. Ẹ máṣe juwọ́lẹ̀ fún àwọn iyèméjì wọnnì. Ẹ yípadà sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́.

“Bẹ́ẹ̀ni, kí ẹ sì képe Ọlọ́run fún gbogbo àtìlẹhìn yín; … ẹ jẹ́ kí ọkàn yín dúró lé Olúwà títíláé.”

“Àti nísisìyí, èmi rọ̀ yín kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn, kí ẹ sì tẹríba, kí ẹ sì ṣe ìwà-pẹ̀lẹ́; kí ẹ ní ìwà tútù; kí ẹ kún fún ìfaradà àti ìlọ́ra; pẹ̀lú ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ohun gbogbo; sí ìtẹramọ́ pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ ní ìgbà gbogbo; ní ìbẽrè ohunkóhun tí ẹ̀yin ṣe aláìní, ní ti ẹ̀mí àti ti ara; kí ẹ sì mã fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nínú ohun gbogbo tí ẹ̀yin bá rí gbà.”

Bí ẹ bá gbàdúrà, bí ẹ bá sọ̀rọ̀ sí Ọlọ́run, àti pé bí ẹ bá bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ fún àyànfẹ́ yín, àti pé bí ẹ bá dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀ kìí ṣe fún ìrànlọ́wọ́ nìkan ṣùgbọ́n fún sùúrù àti ìwà-pẹ̀lẹ́ tí ó nwá láti inú àìgba gbogbo ìfẹ́-inú yín lójúkannáà tàbí láéláé, nígbànáà mo ṣe ìlérí fún yín pé ẹ ó súnmọ́ Ọ́ si. Ẹ ó di onítara àti ìpamọ́ra. Àti nígbànáà ẹ lè mọ̀ pé ẹ ti ṣe gbogbo ohun tí ẹ lè ṣe láti ran àwọn wọnnì tí ẹ nifẹ lọ́wọ́ àti àwọn wọnnì tí ẹ̀ ngbàdúrà fún láti la ìgbìdánwò Sátánì kọjá láti ṣìwọ́n lọ́nà.

“Ṣùgbọ́n àwọn ẹnití ó dúró de Olúwa yíò tún agbára wọn ṣe; wọn yío fi ìyẹ́ gun òkè bí ìdì; wọn ó sáré, kì yíò rẹ̀ wọ́n; wọn ó rìn, àárẹ̀ kì yíò mú wọn.”

A lè rí ìrètí nínú àkọsílẹ̀ ti ìwé mímọ́ àwọn ẹbí. A kà nípa àwọn wọnnì tí wọ́n nyí kúrò nínú ohun tí a kọ́ wọn tàbí tí wọ́n nja ìjàkadì pẹ̀lú Ọlọ́run fún ìdáríjì, bí irú Álmà Kékeré, àwọn ọmọ Mòsíàh, àti Ẹnọ́sì. Ní àwọn àkokò ìdàmú wọn, wọ́n rántí àwọn ọ̀rọ̀ òbí wọn, àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Jésù Krístì. Rírántí gbà wọ́n là. Ìkọ́ni yín nípa ẹ̀kọ́ mímọ́ ni a ó rántí.

Mo jẹ́ ẹ̀rí nípa iṣẹ́ mímọ́ ti ìkọ́ni ẹ̀kọ́ ìrọ̀rùn àwọn ọmọ Baba Ọ̀run nípa Jésù Krístì, èyí yíò fi àyè gbà wá láti jẹ́ wíwẹ̀mọ́ níti-ẹ̀mí àti nígbẹ̀hìn kí a kí wa káàbọ̀ sí iwájú Ọlọ́run, láti gbé pẹ̀lú Rẹ̀ àti Ọmọ Rẹ̀ nínú ògo títí láé nínú àwọn ẹbí. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.