Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìṣẹ́gun ti Ìrètí
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


Ìṣẹ́gun ti Ìrètí

Ìrètí ni ẹ̀bùn alààyè, ẹ̀bùn kan tí ó ndàgbà bí a ti nmú ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì pọ̀ si.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n káàkiri ayé, bi a ti bẹ̀rẹ̀ àkokò pàtàkì ti ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò yí, ojú ọ̀rùn yíò wà lórí wa dájúdájú. A ó gbọ́ ohùn Olúwa nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀; a ó ní ìmọ̀làra “ìtọ́nisọ́nà, dídarí, [àti] títuni-nínú” ipa Ẹ̀mí Mímọ́, a ó sì fún ìgbàgbọ́ wa lókun.

Ọdún mẹ́ta sẹ́hìn, Ààrẹ Russell M. Nelson bẹ̀rẹ̀ ìpàdé Àpapọ̀ gbogbogbò pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Ìfihàn mímọ́ fún àwọn ìbèèrè náà nínú ọkàn yín yíò mú ìpàdé àpapọ̀ yí jẹ́ elérè àti àìgbàgbé. Bí ẹ kò bá tíì lépa fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti Ẹmí Mímọ́ láti ràn yín lọ́wọ́ láti gbọ́ ohun tí Olúwa fẹ́ kí ẹ gbọ́ láàrin àwọn ọjọ́ méjì wọ̀nyí, mo pè yín láti ṣe bẹ́ẹ̀ nísisìyí. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ ṣe ìpàdé àpapọ̀ yí ní àkokò ṣíṣe àpèjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ lati ọ̀dọ̀ Olúwa nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀.”

Àwọn ìwé mímọ́ so àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́ta alágbára papọ̀: ìgbàgbọ́, ìrètí ìfẹ́-àìlẹ́gbẹ́. Ẹ̀bùn ìrètí jẹ́ ẹ̀bùn tẹ́mpìlì iyebíye láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Ọ̀rọ̀ náà ìrètí ni a nlò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun tí a fẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀. Fún àpẹrẹ, “Mo ní ìrètí pé òjò kò ní rọ̀,” tàbí “Mo ní ìrètí pé ẹgbẹ́ wa yíò yege.” Èrò mi ni láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìrètí mímọ́ àti àwọn ìrètí ayérayé ní oókan Jésù Krístì àti ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere àti “àwọn ìgbìrò ìgbẹ́kẹ̀lé wa nípa … ìlérí àwọn ìbùkún òdodo.”

Ìrètí Wa fún Ìyè Ayérayé

Ìrètí wa nípa ìyè ayérayé ní a mú dánilójú nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ Krístì àti àwọn àṣàyàn ti ara wa, fífi àyè ìbùkún alámì ti pípadà sí ilé ọ̀run wa gbà wá láàyè àti gbígbé títíláé ní àláfíà àti ìdùnnú pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run, Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, ẹbí olotitọ wa àti ọ̀rẹ́ iyebiye, àti àwọn ọkùnrin àti obìnrin olódodo ti ayé láti gbogbo ilẹ̀-ayé àti gbogbo sẹ́ntúrì.

Lórí ilẹ̀-ayé a ní ìrírí ayọ̀ àti ìkorò bí a ti ngba ìdánwò tí a sì nṣàfihàn. Ìṣẹ́gun wa nwá nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì bí a ti nborí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ìṣòrò, àdánwò, àìdára, àti àwọn ìpènijà ti ìgbésí ayé ikú yí.

Bí a ti nfún ìgbàgbọ́ wa lókun nínú Jésù Krístì, a rí kọjá àwọn ìlàkàkà wa sí àwọn ìbùkún àti ìlérí àìlópin. Bíi ti ìmọ́lẹ̀ kan tí mímọ́lẹ̀ rẹ̀ ndàgbà, ìrètí tí ó nmú òkùnkùn ayé dán, a sì nrí ọjọ́-ọ̀la ológo wa.

Ìrètí Nwá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Láti ìbẹ̀rẹ̀, Baba wa Ọ̀run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ ti fi ìtara bùkún olódodo pẹ̀lú ẹ̀bùn ti ìrètí iyebíye.

Lẹ́hìn fífi ọgbà sílẹ̀, Ádámù àti Éfà ni a kọ́ nípasẹ̀ àwọn ángẹ́lì nípa ìlérí ti Jésù Krístì. Ẹ̀bùn ìrètí nfún ìgbésí ayé wa lókun. Ádámù kéde, “Ojú mi ti là, àti pé nínú ayé yí èmi ó ní ayọ̀.” Éfà sọ̀rọ̀ nípa “ayọ̀ ti ìràpadà [wọn], àti ìyè ayérayé tí Ọlọ́run fi fún gbogbo olùgbọ́ran.”

Gẹ́gẹ́bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti nmú ìrètí wá fún Ádámù, agbára Ẹ̀mí Olúwa nfi òye fún àwọn olotitọ ní òní, ní títan òdodo ti ìyè ayérayé.

Olùgbàlà rán Olùtùnú kan, Ẹ̀mí Mímọ́, ojúgbà kan nmú ìgbàgbọ́, ìrètí, àláfíà wá “kìí ṣe bí ayé ti nfúnni.”

“Nínú ayé,” Olùgbàla wípé, “ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú: ṣùgbọ́n ẹ tújúká [kí ẹ pa ìrètí dídán mọ́]; mo ti ṣẹ́gun ayé.”

Ní àwọn ìgbà ìṣòrò, a yàn láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nínú ìgbàgbọ́. À ngbádúra jẹ́jẹ́, “Kìí ṣe ìfẹ́ mi ṣùgbọ́n tìrẹ ni ká ṣe.” A ní ìmọ̀lára àṣẹ Olúwa fún níní-ìfẹ́ tútù wa, a sì ndúró fún ìlérí àláfíà tí Olúwa yíò rán wá ní àkokò tí Ó yàn.

Àpóstélì Páùlù kọ́ni, “Ọlọ́run ìrètí [yíò] kún inú yín pẹ̀lú … ayọ̀ àti àláfíà … , kí ẹ lè gbé nínú ìrètí,” “yíyayọ̀ nínú ìrètí; sùúrù nínú ìpọ́njú;” “nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́.”

Ẹ̀kọ́ Ìrètí Kan

Wòlíì Mórónì mọ̀ ní àkọ̀kọ̀ nípa níní ìrètí nínú Krístì ní ìgbà ìpọ́njú. Ó ṣe àlàyé ipò olóró rẹ̀:

“Èmi dá wà. … Èmi kò ní … ibi kankan láti lọ.”

“Èmi kò sì fi ara mi hàn … ní ìbẹ̀rù pé wọn yíò pa mí run.”

Pẹ̀lú òkìkí, nínú wákàtí dúdú àti dídáwà yí, Mórónì ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ baba rẹ̀ nípa ìrètí;

“Bí ẹnikẹ́ni bá lè ní ìgbàgbọ́ ó níláti ní ìrètí; nítorí láìsí ìgbàgbọ́ kò lè sí ìrètí rárá.”

“Kí sì ni ẹ̀yin yíò ní ìrètí fún? … Ẹ̀yin ó ní ìrètí nípasẹ̀ ètùtù Krístì àti agbára àjínde rẹ̀, láti jí dìde sí ìyè ayérayé.”

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, ìrètí ni ẹ̀bùn alààyè, ẹ̀bùn kan tí ó ndàgbà bí a ti nmú ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì pọ̀ si. “Ìgbàgbọ́ ni [ẹ̀rínípa àwọn ohun tí a ní ìrètí fún.” A nkọ́ ohun yí—ẹ̀rí búlọ́kì ti ìgbàgbọ́ wa—nípasẹ̀ àdúrà, àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì, pípa àwọn òfin mọ́, ṣíṣe àpèjẹ léraléra lórí àwọn ìwé mímọ́ àti ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì òde-òní, jíjẹ oúnjẹ Olúwa, àti jíjọ́sìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àwọn Ènìyàn Mímọ́ ọmọ̀làkejì wa.

Ilé Ìrètí Kan

Láti fún ìrètí wa lókun lakoko i ìwà búburú tí ó npọ̀ sí i, Olúwa ti darí wòlíì Rẹ̀ láti káàkiri ayé pẹ̀lú àwọn tẹ́mpìlì Rẹ̀.

Bí a ti nwọnú ilé Olúwá, à nní ìmọ̀lára Ẹ̀mí Ọlọ́run, ní yíyẹ ìrètí wa wò.

Tẹ́mpìlì jẹri ṣíṣófo ibojì àti ayé ìkọjá ìkelè tí ó ntẹ̀síwájú fún gbogbo ènìyàn.

Fún àwọn wọnnì tí wọ́n kò ní ojúgbà ayérayé, àwọn ìlànà alágbára fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pé gbogbo àwọn ẹni olódodo yíò gba gbogbo ìlérí ìbùkún.

Ìrètí ọlọ́lá wà bí ọ̀dọ́ lọ́kọ-láyà ṣe kúnlẹ̀ lẹba pẹpẹ láti ṣe èdìdi, kìí ṣe fún àkokò nìkan ṣùgbọ́n fún àìlópin.

Ọ̀pọ̀ ìrètí wà fún wa nínú àwọn ìlérí tí a ṣe fún àtẹ̀lé wa, eyikeyi àwọn ipò wọn lọ́wọ́lọ́wọ́.

Kò sí ìrora, kò sí àìsàn, kò sí àìṣòdodo, kò sí ìjìyà, kò sí ohun tí ó lè mú ìrètí wa ṣókùnkùn bí a ti gbàgbọ́ tí a sì dì àwọn májẹ̀mú wa mú tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run nínú ilé Olúwa. Ó jẹ́ ilé ìmọ́lẹ̀ kan, ilé ìrètí kan.

Nígbàtí ìrètí ti lọ.

À nsọkún ìkorò bí a ti nrí ìbànújẹ́ àti àìní-ìrètí nínú àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìrètí nínú Krístì.

Láìpẹ́ mo ṣe àkíyèsí láti ọ̀dọ̀ lọ́kọ-láyà jíjìnnà kan ní àkokò kan tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì ṣùgbọ́n nígbànáà wọ́n pinnu láti sọ ìgbàgbọ́ wọn nù. Wọ́n yege nínú ayé, wọ́n sì rí ìgbádùn nínú òye wọn àti ìkọ̀sílẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn.

Gbogbo rẹ̀ dàbí ó dára títí tí ọkọ náà, tí ó ṣì kéré àti olókun, lọ́gán ṣe àárẹ̀ ó sì kú. Bíiti òṣùpá ti òòrùn, wọ́n dí ìmọ́lẹ̀ ti Ọmọ náà, àti pé èsì náà ni òṣùpá ti ìrètí kan. Ìyàwó náà, nínú àìgbàgbọ́ rẹ̀, nísisìyí ní ìmọ̀lára ìdàmú, pẹ̀lú ìrora àìmúrasílẹ̀, láìlè tu àwọn ọmọ rẹ̀ nínú. Ọgbọ́n rẹ ti wí fun un pé ayé rẹ̀ wà ní èrò pípé títí lọ́gán kó tó di pé òun kò lè rí ọ̀la mọ́. Àìnìrètì rẹ̀ mú òkùnkùn àti ìdàmú wá.

Ìrètí nínú Àjálù Ìrora-ọkàn

Ẹ jẹ́ kí èmi ó ṣe àfiwé ìrora àìnírètí rẹ̀ pẹ̀lú ìrètí ẹbí míràn nínú Krístì ní ìgbà ìrora-ọkàn.

Ọdún mọ́kànlélógún sẹ́hìn àṣẹ̀ṣẹ̀-bí ọmọkùnrin nẹ́fíù mi, Ben Andersen, àti ìyàwó rẹ̀, Robbie, wà ní fífò-ìyè láti ìletò ìdáko wọn ní Idaho lọ sí Ìlú Salt Lake. Mo dé ilé-ìwòsàn, Ben sì ṣe àlàyé líle, ìlọ́lù ìdẹrùba-ìyè pẹ̀lú ọkàn ọmọ wọn. A gbé ọwọ́ wa lé orí Trey kékéré. Olúwa bùkún un pẹ̀lú ìtẹ̀síwájú ayé.

Trey ṣe iṣẹ́-abẹ ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ ayé rẹ̀, àwọn iṣẹ́-abẹ púpọ̀ sì tẹ̀lé e. Bí àwọn ọdún ti kọjá, ó hàn kedere pé Trey ó nílò àtúngbìn ọkàn. Bíotilẹ̀jẹ́pé àwọn ìṣe ti-ara rẹ̀ ní òpin, ìgbàgbọ́ rẹ̀ gbòòrò. Ó kọ pé, “Èmi ko ní ìmọ̀lára ìkáànú fún arami rí nítorí mo ti mọ pàtàkì ti níní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krísti àti ẹ̀rí ètò ìgbàlà ní ìgbagbogbo.”

Trey Andersen

Trey pa àyọsọ yí láti ẹnu Ààrẹ Nelson mọ́ sí orí fóònù rẹ̀ wípé: “Ayọ̀ tí à ní ìmọ̀lára rẹ̀ ní díẹ̀ íṣe pẹ̀lú àwọn ipò ti ìgbésí ayé wa àti pé ohungbogbo ní íṣe pẹ̀lú ìdojúkọ àwọn ìgbésí ayé wa.”

Trey Andersen

Trey kọ wìpè: “Mo ti nfojúsọ́nà sí sísin míṣọ̀n ìgbà-kíkún kan, ṣùgbọ́n … àwọn dókítà mi kò ní jẹ́ kí nsìn ní míṣọ̀n títí ọdún kan ó kéréjù lẹhìn àtùngbìn mi. … Mo ti fi ìgbàgbọ́ mi sínú Jésù Krístì.”

Inú Trey dùn ní gbígbà sínú ẹ̀ka ìṣirò ní BYU láti bẹ̀rẹ̀ ní ìgbà-ìkàwé yí, ṣùgbọ́n àní inú rẹ̀ dùn lọ́pọ̀lọpọ̀ ní òpin Oṣù Kéje ni ìgbàtí ó gba ìpè tẹ́lifóònù tó ti nretí gan láti wá sí ilé-ìwòsàn fún àtúngbìn ọkàn rẹ̀.

“Ọdún kan,” Trey wípé, “èmi ó sì wà ní míṣọ̀n mi.”

Àwọn ìretí nlá wà bí a ti nwọnú yàrá iṣẹ́-abẹ. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, ní àkokò iṣẹ́-abẹ àwọn ìlọ́lù púpọ̀, Trey kò sì jí sáyé mọ́.

Ìyá rẹ̀, Robbie, wípé: “Ọjọ́-ẹtì ti jẹ́ ọjọ́ ìròra-ọkàn jùlọ … a kàn ngbìyànjú láti mú ọkàn wa yíka rẹ̀. … Mo dúró pẹ́ ní gbígbìyànjú láti ro ohungbogbo. … Ṣùgbọ́n ní Sátidé, mo jí dìde pẹ̀lú ìmọ̀lára ayọ̀ tán pátápátá. Kìí ṣe àláfíà lásán, kìí ṣe ìkọjálẹ̀. Mo ní ìmọ̀lára ayọ̀ fún ọmọkùnrin mi, mo sì ní ìmọ̀lára ayọ̀ fún ìyá rẹ̀. … Ben ti dìde ṣíwájú mi gan an, àti pé nígbàtí a wá ní àyè láti sọ̀rọ̀ nígbẹ̀hìn, Ben ti ní ìtají pẹ̀lú irú ìmọ̀lára kannáà.”

Robbie àti Ben Andersen

Ben ṣe àlàyé pé: “Mímọ́ gaara wá sínú ẹ̀mí mi bí Ọlọ́run ti kọ́ mi nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Mo jí ní aago mẹ́rin òwúrọ̀ mo sì kún fún àláfíà àti ayọ̀ àìlèjúwe. Ṣùgbọ́n báwo ni ó ti ṣeéṣe? … Ìkọjá lọ Trey jẹ́ ìrora gidi gan ni, mò sì ṣe àfẹ́rí rẹ̀ púpọ̀ gidi. Ṣùgbọ́n Olúwa kò fi wá sílẹ̀ láìní-ìtùnú. … Mo fojúsọ́nà sí àtún-dàpọ̀ aláyọ̀ kan.”

Ìlérí ti Ìrètí

Trey ti ṣàkíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nínú ìwé-ìròhìn rẹ̀ látinú ọ̀rọ̀ Ààrẹ Nelson ti ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbo: “kò dàbí pé ó ṣeé ṣe láti ní ìdùnnú nígbàtí ọmọ rẹ bá ní àìsàn tí kò ní wòsàn tàbí nígbàtí o bá pàdánù iṣẹ́ ẹ rẹ̀ tàbí nígbàtí lọ́kọláya rẹ bá dà ọ́. Síbẹ̀ èyí gan an ni ayọ̀ tí Olùgbàlà nfún ni. Ayọ̀ Rẹ̀ wà lemọ́lemọ́, ó nmu dáwa lójú pé ‘àwọn ìpọ́njú wa yíò jẹ́ ṣùgbọ́n fún àkokò díẹ̀’ [Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 121:7] a ó sì yàásọ́tọ̀ fún èrè wa.”

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, àláfíà tí ẹ̀ nwá lè má tilẹ̀ wá ní kíákíá bí ẹ ti fẹ́, ṣùgbọ́n mo ṣe ìlérí fún yín pé bí ẹ ti nní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa, àláfíà Rẹ̀ yíò wá

Njẹ́ kí a ṣìkẹ́ ìgbàgbọ́ iyebíye wa, ní títẹ̀síwájú pẹ̀lú ìrètí dídán pípé. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé ìrètí wa ni Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. Nípasẹ̀ Rẹ̀, gbogbo àlá òdodo yíò wá sí ìmúṣẹ. Òun ni Ọlọ́run ìrètí—ìṣẹ́gun ti Ìrètí. Ó wà láàyè Ó sì fẹ́ràn yín. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Russell M. Nelson, “Ìfihàn fún Ijọ, Ìfihàn fún Ìgbé Ayé Wa,” Liahona, May 2018, 96.

  2. Russell M. Nelson, “Òtítọ́ Mímọ́, Ẹ̀kọ́ Mímọ́, àti Ìfihàn Mímọ́,” Làìhónà, Nov. 2021, 6–7.

  3. “Ṣe ẹ ti ṣàkíyèsí nínú ìwé-mímọ́ pé ìrètí kìí fi bẹ́ẹ̀ dá dúró? Ìrètí máa nsomọ́ ìgbàgbọ́ nígbàkugbà. Ìrètí àti ìgbàgbọ́ máa nsopọ̀ ní ìwọpọ̀ sí ìfẹ́-àìlẹ́gbẹ́. Kínìdí? Nítorí ìrètí jẹ́ pàtàkì sí ìgbàgbọ́; ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì sí ìrètí; ìgbàgbọ́ àti ìrètí ṣe pàtàkì sí ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ (wo 1 Kọ́ríntì 13:13, Álmà 7:24, Étérì 12:28, Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 4:5). Wọ́n nti arawọn lẹ́hìn bíiti ẹsẹ̀ lórí stúùlù ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta. Gbogbo mẹ́tẹ̀ta bá Olùràpadà wa mu.

    Ìgbàgbọ́ [ni gbòngbò nínú] Jésù Krístì. Ìrètí ni oókan nínú ètùtù rẹ̀. Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ni a fihàn nínú ‘ìfẹ́ mímọ́ Krístì’ (wo Moroni 7:47). Àwọn ìhùwàsí mẹ́ta wọ̀nyí wọ inú ara wọn bíiti okùn wáyà tí a kò lè yàsọ́tọ̀ rẹ́gírẹ́gí nígbàgbogbo. Lápapọ̀, wọ́n di tẹ́tà wa sí ìjọba Sẹ̀lẹ́stíà” (Russell M. Nelson,“Ìrètí Títayọ Kan Síi” [Brigham Young University devotional, Jan. 8, 1995], speeches.byu.edu).

  4. Àwọn Àkórí Ìhìnrere, “Ìrètí,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

  5. Nítorí èyí, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run lè ní ìrètí dájúdájú fún ayé tí ó dára jù, … àní àyè ní apá ọ̀tún Ọlọ́run, ìrètí èyítí nwá nípa ìgbàgbọ́, tí ó sì rọ̀ mọ́ ọkàn ènìyàn, [èyítí yíò mú] wọn dúró gbọningbọnin àti ní ìdúróṣínṣin” (Ẹtérì 12:4).

  6. Alàgbà Dieter F. Uchtdorf wípé: “Ẹ fi àyè gbà mí láti jẹ́wọ́ pé írẹ̀wẹ̀sì àti àwọn ìṣòrò ọpọlọ míràn àti àwọn ìpènijà ẹ̀dùn ọkàn jẹ́ òtítọ́, àti pé ìdáhùn náà kìí kàn ṣe, ‘Gbìyànjú láti jẹ́ onínúdídùn si.’ Èrèdí mi ní òní kìí ṣe láti dínkù tàbí mú ọ̀ràn ìlera ọpọlọ yẹpẹrẹ. Bí ẹ bá dojúkọ irú àwọn ìpènijà bẹ́ẹ̀, mo kaanu pẹ̀lú mo sì dúró ní ẹ̀gbẹ́ yín. Fún àwọn ènìyàn kan, rírí ayọ̀ lè pẹ̀lú wíwá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ onímọ̀ tí a kọ́ ní ìlera ọpọlọ tí wọ́n fi ayé wọn sí ṣíṣe ìtọ́jú àrùn. A níláti dúpẹ́ fún irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀” (“Ayọ̀ Gígajù Kan,” Liahona, May 2024, 66).

  7. Baba wa Ọ̀run ti kéde pé iṣẹ́ àti ògo Rẹ̀ ni láti mú ìyè ayérayé wa wá sí ìmúṣẹ (wo Mose 1:39).

  8. Wo Mósè 1:39.

  9. Mósè 5:10.

  10. Mósè 5:11.

  11. Wo Mosiah 5:9.

  12. Johanu 14:27.

  13. Johanu 16:33.

  14. Wo Lúkù 22:42.

  15. Àwọn Ará Rómù 15:13.

  16. Àwọn Ará Rómù 12:12.

  17. Àwọn Ará Rómù 15:13.

  18. Mormon 8:5.

  19. Moroni 1:1.

  20. Moroni 7:42.

  21. Moroni 7:41.

  22. Hébérù 11:1. Nínú Ìyírọ̀padà-èdè ti Joseph Smith ó kà pé, “Ìgbàgbọ́ ni ìdánilójú nípa àwọn ohun tí à nretí, ẹ̀rí àwọn ohun tí a kò rí” (nínú Àlẹ̀mọ́ Bíbélì). A rí ìdánilójú ti ìgbàgbọ́ wa nínú àwọn ìbùkún tí ó nwá sọ̀dọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n bá pa àwọn májẹ̀mú mọ́ tí wọ́n ti ṣe pẹ̀lú Olúwa.

  23. Russell M. Nelson, “Ayọ̀ àti Ìtúsílẹ̀ Ẹ̀mí,” Liahona, Nov. 2016, 82.

  24. Ọ̀rọ̀ tí a fúnni nípasẹ̀ Robbie Andersen níbi ìsìnkú ọmọ rẹ̀, Trey Andersen, ní Ọjọ́ Kejìlá Oṣù Kẹ́jọ, 2024. Trey ní iṣẹ́ abẹ rẹ̀ ní Ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n Oṣù Kéje, 2024. Ó kọjá lọ kúrò ní ayé yí ní Ọjọ́ Kẹ́ta Oṣù Kẹ́jọ, 2024.

  25. Ọ̀rọ̀ tí a fúnni nípasẹ̀ Ben Andersen níbi ìsìnkú ọmọ rẹ̀, Trey Andersen, Ọjọ́ Kejìlá Oṣù Kẹ́jọ, 2024.

  26. Russell M. Nelson, “Ayọ̀ àti Yíyè Ti Ẹ̀mí,” 82.

  27. Wo 2 Néfì 31:20. Ìrètí tí Néfì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jẹ́ pípé àti dídán nítorí ó wà ní oókan nínú Krístì. Òun jẹ́ pípé, àti Ètùtù Rẹ̀, èyí fi ìrètí dídán fúnni, bákannáà ó jẹ́ pípé.