Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
“Èmi Nìyí”
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


“Èmi Nìyí”

Ìfẹ́ Krístì—tó farahàn ninu ìṣòtítọ́ pípé sí ìfẹ́ àtọ̀runwá—tẹ̀síwájú ó sì ntẹramọ́ láti tẹ̀síwájú.

Ó jẹ́ Ọjọ́ Ìsinmi, a sì ti péjọ lati sọ̀rọ̀ nípa Krístì àti Òun tí a kàn mọ́ àgbélèbú. Mo mọ̀ pé Olùràpadà mi wà láàyè!

Ẹ gbé ìran yí yẹ̀wò láti inú ọ̀sẹ̀ tó kẹ́hìn ninu ayé ikú ti Jésù. Àwọn èrò ti péjọ, pẹ̀lú àwọn ológun ará Rómù tí wọ́n dì ìhámọ́ra pẹ̀lú ọ̀pá àti síso pẹ̀lú àwọn idà. Ní dídarí nípasẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà ẹnití ó ní àwọn iná ìléwọ́ ní ọwọ́, àwọn ikọ̀ onítara yí lọ lati ṣẹ́gun ilú kan. Ní alẹ́ yí wọ́n nwá ọkùnrin kanṣoṣo, ọkùnrin kan tí a kò mọ̀ láti máa gbé ohun ìjà, gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ológun, tàbí lọ́wọ́ ninu ìjà ìgboro ní àkókò kankan ní gbogbo ayé Rẹ̀.

Bí àwọn ológun ti nbọ̀, Jésù, ninu ìyànjú láti dáàbò bo àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀, bọ́ síwájú ó sì wí pé, “Tani ẹ̀yin nwá?” Wọ́n dáhùn pé, “Jésù ti Násárẹ́tì.” Jésù wí pé, “Èmi nìyí. … [Àti] lójúkannáà … bí ó ti wí fún wọn pé, Èmi nìyí, wọ́n sún sẹ̀hìn, wọ́n sì ṣubú sí ilẹ̀.”

Sí mi, èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlà tó ní ìmísí jùlọ nínú gbogbo ìwé mímọ́. Láàrin àwọn ohun míràn, ó sọ fún mi ní tààrà pé kí a kàn wà ní ọ̀dọ̀ Ọmọ Ọlọ́run—Jèhófàh nlá ti Májẹ̀mú Láéláé àti Olùṣọ́-àgùtàn Rere ti Titun—pé kí a kàn gbọ́ ohùn Ìsádi kúrò nínú Ìjì yí, Ọmọ-Aládé Àlãfíà yí, àti Àlùfáà Gíga ti Àwọn Ohun Rere tí Nbọ̀ ti tó láti rán àwọn alátakò kíkọsẹ̀ sí pípadà sẹ́hìn, ní kíkó wọn jọ nínú pàntí, àti mímú gbogbo ẹgbẹ́ náà ní ìfẹ́ inú pé wọn ìbá ti jẹ́ yíyàn sí ojúṣe ní ilé ìdáná ni alẹ́ náà.

Ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ ṣaáju, nígbátí Ó wọ ìlú náà bíi aṣẹ́gun, “gbogbo ilú náà mì tìtì,” ni ìwé mímọ́ wí, ní bíbéèrè pé, “Tani èyí?” Mo kàn le ròó nìkan pé “Tani èyí?” ni ìbéèrè tí áwọn ológun àìlétò wọnnì nbéèrè nísisìyí!

Ìdáhùn ìbéèrè yí kò le ti wà níbi ìwò ojú rẹ̀, nítorí Isáíàh ti sọtẹ́lẹ̀ ní àwọn sẹ́ntíúrì méje kan ṣaáju pé “ìrísí rẹ̀ kò dára, bẹ̃ni kò ní ẹwà; nígbàtí àwa yíò bá sì rí i, kò sí ẹwà tí àwa kò bá fi fẹ́ ẹ.” Dájúdájú kìí ṣe láti inú àpótí aṣọ Rẹ̀ dídán tàbí ọrọ̀ ti ara-ẹni, ninu èyítí Òun kò ní ọ̀kankan. Kò le jẹ́ láti inú ìdánilẹ́kọ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kankan ninu àwọn sínágọ́gù ìbílẹ̀ nítorí a kò ní ẹ̀rí pé Ó kẹ́kọ̀ọ́ rí ninú èyíkéyí wọn, bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀ àní ní ìgbà ọ̀dọ́ Rẹ̀ Ó le dààmú àwọn akọ̀wé àti àwọn agbẹjọ́rò ti wọ́n mura tán dáradára, ní yíyà wọ́n lẹ́nu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Rẹ̀ “bíi ẹnìkan tó ní àṣẹ.”

Látinú ìkọ́ni ti tẹ́mpìlì náà sí fífi ìṣẹ́gun Rẹ̀ wọnú Jérúsálẹ́mù àti òpin èyí, dídìmú ẹ̀bi, bí ìṣe Jésù ni a fi sínú àwọn ipò ìṣòrò, kíkorò léraléra nínú èyí tí Ó ti nṣẹ́gùn nígbàgbogbo—àwọn ìborí fún èyí tí a kò ní àlàyé sí bíkòṣe Ayẹ̀wò-gínì àtọ̀runwá.

Síbẹ̀ nínú ìwé-ìtàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí murọrùn, àní sọ àwòràn wa nípa Rẹ̀ àti ẹ̀rí Rẹ̀ nípa ẹni tí Ó jẹ́ di yẹpẹrẹ. Wọ́n ti dín òdodo Rẹ̀ kù sí àníyàn àṣejù lásán, ìdájọ́ Rẹ̀ sí ìbínú lásán, àánú Rẹ̀ sí àìkàsí lásán. A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nípa àwọn ẹ̀dà onírọ̀rùn Tirẹ̀ tí wọ́n rọra nfojú fo àwọn ìkọ́ni tí a rí pé kò tunilára. Jíjẹ̀wẹ̀ “sílẹ̀ yí” ti jẹ́ òtítọ́ àní ní kíka àsọyé ìwà-rere ìgbẹ̀hìn Rẹ̀ sí, ìfẹ́ Rẹ̀.

Nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀, Jésù kọ́ni pé àwọn òfin nlá méjì wà. A ti kọ́ wọn nínú ìpàdé àpapọ̀ yí a ó sì kọ́ wọn títíláé: “Ẹ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín [kí ẹ sì] fẹ́ràn ọmọlàkejì yín bí ara yín.” Nítorínáà bí a bá fẹ́ tẹ̀lé Olùgbàlà nítòótọ́ ninu àwọn ìlànà méjéèjì pàtàkì lílẹ̀pọ̀ àti tí kò ṣeé yà wọ̀nyí, ó yẹ kí a di ohun tí Ó sọ nítòótọ́ mú ṣinṣin. Àti pé ohun tí Ó sọ nítòótọ́ ni pé, “Bí ẹyin bá fẹ́ràn mi, ẹ pa àwọn òfin mi mọ́.” Ní ìrọ̀lẹ́ kannáà, Ó wí pé a níláti “fẹ́ràn ara yín; bí èmi ti fẹ́ràn yín.”

Ninu àwọn ìwé mímọ́ wọnní, àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ àmúyẹ tó ntúmọ̀ ìfẹ́, tòótọ́, bíi-ti-Kristì—tí a ntọ́kasí nígbà míràn bíi ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́—ṣe pàtàkì pátápátá.

Kínni wọ́n túmọ̀? Báwo ni Jésù ti fẹ́ràn?

Ìkínní, Ó fẹ́ràn pẹ̀lú “gbogbo ọkàn, agbára, iyè, ati ipá [Rẹ̀],” ní fífún Un ní agbára láti wo ìrora jíjinlẹ̀ sàn kí ó sì sọ awọn òtítọ́ líle. Ní kúkúrú, Òun ni ẹni náà tí ó le fi oore ọ̀fẹ́ fúnni kí ó sì dúró lórí òtítọ́ ní ìgbà kannáà. Bí Léhì ti súre fún ọmọkùnrin rẹ̀ Jákọ́bù, “Ìràpadà mbọ̀wá nínú àti nípasẹ̀ Messia Mímọ́ nã; nítorí ó kún fún õre-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.” Ìfẹ́ Rẹ̀ nfi àyè fún ìgbàmọ́ra gbígbàni-níyànjú kan nígbàtí a bá nílò àti ago kíkorò kan nígbàtí ó bá níláti jẹ́ gbígbémì. Nítorínáà a ngbìyànjú láti fẹ́ràn—pẹ̀lú gbogbo ọkàn, agbára, iyè, ati ipá wa nítorí ní ọ̀nà yí ni Òun fẹ́ràn wa.

Àbùdá kejì ti ìfẹ́ Jésù ni ìgbọràn Rẹ̀ sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó jáde wá láti ẹnu Ọlọ́run, ní fífi ìgbà gbogbo ṣe ìfẹ́ àti ìwà Rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lu ti Baba Rẹ̀ ti Ọ̀run.

Nígbàtí Ó dé sí agbedeméjì Ìwọ̀-òòrùn yí ní títẹ̀lé Àjínde Rẹ̀, Krístì sọ fún àwọn Ará Néfì pé: “Ẹ kíyèsi, èmi ni Jésù Krístì. … Èmi ti mu nínú ago kíkòrò èyítí Bàbá ti fifún mi, … nínú èyítí èmi ti gba ìfẹ́ Baba láàyè … lati àtètèkọ́ṣe.”

Ó ti máa nyà mí lẹ́nu pé ninu ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀nà tí Òun fi le ṣe àfihàn Ararẹ̀, Jésù ṣe bẹ́ẹ̀ nípa sísọ ìgbọràn Rẹ̀ sí ìfẹ́ ti Babaláì fọkànsíi pé láìpẹ́ ṣaájú ní wákàtí ìnílò Rẹ̀ jùlọ, Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Ọlọ́run yí ti ní ìmọ̀lára kíkọ̀sílẹ̀ pátápátá láti ọ̀dọ̀ Baba Rẹ̀. Ìfẹ́ ti Krístì—tó farahàn nínú òdodo pátápátá sí ìfẹ́ ti ọ̀runtẹramọ́ ó sì tẹ̀síwájú láti tẹramọ́, kìí ṣe ninu àwọn ọjọ́ tó rọrùn tó sì tunilára nìkan ṣùgbọ́n bákannáà ninu àwọn tó ṣókùnkùn jùlọ ati tó ṣòro jùlọ

Jésù ni “ọkùnrin oníbànújẹ́ kan,” ni ìwé mímọ́ wí. Ó ní ìrírí ìbànújẹ́, àárẹ̀, ìjákulẹ̀, àti oró àdánìkanwà. Ní àwọn àkókò wọ̀nyí àti ní gbogbo ìgbà, ìfẹ́ Jésù kò kùnà bẹ́ẹ̀ sì ni ti Baba Rẹ̀ náà. Pẹ̀lú irú ìfẹ́ òtítọ́, tó péye bẹ́ẹ̀—irú èyí tí ó nṣe àpẹrẹ, nró lágbára, àti tó nfi-fúnni—tiwa náà kò ní kùnà bẹ́ẹ̀.

Nítorínáà, nígbà míràn tó dàbí pé bí o ti ngbìyànjú líle síi tó, ni ó dàbí pé ó nṣòro síi; bí, lọ́gán tí o fẹ́ gbìyànjú láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn àbùkù àti àìpé rẹ, o rí ẹnìkan tàbi ohun kan tó ti pinnu láti pe ìgbàgbọ́ rẹ níjà; bí, bí o ti nṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìfọkànsìn, o ṣì nní ìmọ̀lára àwọn àkókò tí ìbẹ̀rù nṣàn lára rẹ, rántí pé ó ti rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn ìyanu tòótọ́ ní gbogbo sáà. Bákannáà rántí pé agbára kan wà ní àgbáyé tó pinnu láti tako gbogbo ohun rere tí o bá gbìyànjú láti ṣe.

Nítorínáà, ninu ọ̀pọ̀ tàbí àìní, ninu ìyìn kọ̀rọ̀ bákannáà pẹ̀lú àtakò gbangba, ninu àwọn èròjà tọ̀run fún Ìmúpadàbọ̀sípò bákannáà pẹ̀lú awọn àlébù ti ẹ̀dá ènìyàn tí yío jẹ́ apákan rẹ̀ láìleyẹ̀, a ndúró ní ọ̀nà náà pẹ̀lú Ìjọ òtítọ́ ti Krístì. Kínìdí? Nítorípé, bíi ti Olùràpadà wa, a ṣe ìfọwọ́sí fún gbogbo iṣẹ́ náà—kìí ṣe ìfigagbága kúkúrú ti ìṣaáju kan ṣùgbọ́n títí dé ìdánwò ìparí. Ayọ̀ tó wà ninu èyí ni pé Olùkọ́-àgbà náà fún gbogbo wa ní ìwé-ṣíṣí àwọn ìdáhùn kí iṣẹ́ náà tó bẹ̀rẹ̀. Síwájú síi, a ní ogunlọ́gọ̀ àwọn olùkọ́ tí wọ́n nránwa létí nípa àwọn ìdáhùn wọnnì ni awọn ibi ìdúró ni ojú ọ̀nà náà. Sùgbọ́n ní tòótọ́, kò sí èyí tí ó nṣiṣẹ́ nínú èyí bí a bá tẹ̀síwájú láti máa gé kíláàsì.

“Tani ẹ̀yin nwá?” Pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa a dáhùn pé, “Jésù ti Násárẹ́tì.” Nígbàtí Ó bá wí pé, “Èmi nìyí,” kí a tẹ eékún wa ba kí a sì jẹ́wọ́ pẹ̀lú ahọ́n wa pé Òun ni Krístì alààyè, pé Óun nìkan ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, pé Ó ngbé wa àní nígbàtí a rò pé ó ti pa wá tì. Nígbàtí a bá dúró níwájú Rẹ̀ tí a sì rí àwọn àpá ní ọwọ́ Rẹ̀, ẹsẹ̀ Rẹ̀, áti ẹ̀gbẹ́ Rẹ̀, a ó bẹ̀rẹ̀ sí ní òye ohun tí ó túmọ̀ sí fún Òun láti jẹ́ olùgbọ́ràn pátápátá sí Baba, láti gbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kí Ó sì jẹ́ ojúlùmọ̀ pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn—gbogbo rẹ̀ nítorí ìfẹ́ àìlábàwọ́n fún wa. Láti fi ìgbàgbọ, ìrònúpìwàdà, ìrìbọmi, ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn, kí a sì gba àwọn ìbùkún nínú ilé Olúwa—ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀kọ́ “ìpìlẹ̀ àti ìlànà” tí ó nfi ìfẹ́ Ọlọ́run àti ọmọlàkejì àti ìwà aláyọ̀ Ìjọ òtítọ́ Krístì hàn.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo jẹ́ri pé Ìjọ Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni ọkọ̀ tí Ọlọ́run ti pèsè fún ìgbéga wa. Ìhìnrere tí ó nkọni jẹ́ òtítọ́, àti pé oyè-àlùfáà tí ó fi àṣẹ rẹ̀ múlẹ̀ kìí ṣe ìtọsẹ̀. Mo jẹ́ri pé Russell M. Nelson ni wòlíì Ọlọ́run wa, bí àwọn aṣaájú Rẹ̀ ti wà àti bí àwọn àtẹ̀lé Rẹ̀ yío jẹ́. Àti pé ní ọjọ́ kan ìtọ́ni ti wòlíì náà yío darí àwọn ìran kan láti rí Ìránṣẹ́ Ìgbàlà wa tí yío sọ̀kalẹ̀ bíi “mọ̀námọ̀ná … jáde láti ìlà oòrùn,” a ó sì pariwo, “Jésù ti Násárẹ́tì.” Pẹ̀lú àwọn apá nínà jáde títí láé àti ifẹ́ àìṣẹ̀tàn, Òun yío fèsì pé, “Èmi nìyí.” Mo ṣe ìlérí bẹ́ẹ̀ ní agbára ti àpóstélì ati àṣ̣ẹ ti orúkọ mímọ́ Rẹ̀, àní Jésù Krístì, àmín.