Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Ọjọ́ Tí A Kò Lè Gbàgbé Láé
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


Àwọn Ọjọ́ Tí A Kò Gbọ́dọ̀ Gbàgbé Láé

Àwọn àkokò tó nbọ̀ wọ̀nyí yíò pèsè àwọn ọmọ ìjọ níbigbogbo pẹ̀lú àlékún àwọn ànfàní láti pín ìròhìn ayọ̀ ti ìhìnrere Jésù Kristì.

Ọ̀rọ̀-ìṣíwájú

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ìwé-ìtàn Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní àkokò iṣẹ́ ìríjú yí ni ó dárapúpọ̀ pẹ̀lú àwọn ìrírí tọ̀run tí ó júwe bí Olúwa ti ntọ́ Ìjọ Rẹ̀ sọ́nà. Díkédì kan wà nínú ìwé-ìtàn wa, bákannáà, tí ó dúró ní ìyàlẹ́nu dájúdájú ju eyikeyi míràn—díkédì láti 1820 sí 1830. Ní bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrírí Ààrẹ Joseph Smith nínú igbó ṣúúrú mímọ́ ní ìgbà-ìrúwé ti 1820, nígbàtí ó rí Ọlọ́run Baba àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, àti títẹ̀síwájú títí di Ọjọ́ Kẹfà Oṣù Kẹ́rin, 1830, díkédì náà kò dàbí eyikeyi míràn.

Mórónì ngbé àwọn àwo wúrà kalẹ̀.
Ìmúpadàbọ̀sípò Oyèàlùfáà Mẹ́lkìsédékì
Oliver Cowdery.

Ẹ yẹ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó lápẹrẹ wọ̀nyí wò! Ọ̀dọ́ wòlíì náà bá ángẹ́lì Mórónì sọ̀rọ̀, ó ṣe ìyírọ̀pada-èdè ti àwọn àwò wúrà, ó sì tẹ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì jáde! Ó jẹ́ ohun-èlò nípasẹ̀ èyí tí Oyè-àlùfáà Áárọ́nì àti Mẹ́lkìsédẹ́kì ti padàbọ̀sípò, tí ó sì gbé Ìjọ kalẹ̀ lẹ́hìnnáà! Oliver Cowdery júwe àkokò náà dáadáa: “Ìwọ́nyí ni àwọn ọjọ́ tí a kò lè gbàgbé láé.” Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ oníyanu ti tẹ̀síwájú di ọjọ́ òní gan an.

Njẹ́ kí nní ìgboyà gidi láti daba pé ní ọdún yí a ti bẹ̀rẹ̀ díkédì kan tí ó lé jẹ́wọ́ ní jíjẹ́ ipa bí eyikeyi tí ó ti tẹ̀lé díkédì àìlẹ́gbẹ́ tí a gbékalẹ̀ ní bíi sẹ́ntúrì mẹ́jì sẹ́hìn.

Díkédì Wa.

Ẹ jẹ́ kí nṣe àlàyé. Ní àárín ìsisìyí 2024, àti 2034, a ó ní ìrírí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbèrú tí yíò yọrísí àwọn ànfàní títayọ láti sìn, láti dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ìjọ àti ọ̀rẹ́, àti láti fi Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn hàn sí àwọn ènìyàn púpọ̀ si ju ti ìṣíwájú lọ.

Ayẹyẹ ọgọrun ọdún ọjọ́-ìbí Ààrẹ Nelson.

A ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹri agbára àkokò onítàn tòótọ́ bí a ti ṣe ayẹyẹ pẹ̀lú àwọn mílíọ́nù mẹ́wa-mẹ́wa ti ọjọ̀-ìbí ọgọrun ọdún Ààrẹ Russell M. Nelson.

Jíjíhìn lórí ọjọ́-ìbí Ààrẹ Nelson, Ọ̀sẹ̀-ìròhìn kọ àkọlé kan tí ó kà pé, “Olórí Ẹ̀sìn Tó Dàgbà Jùlọ Di Ọgọrun Ọdún.” Nígbànáà wọ́n dárúkọ àwọn olórí onígbàgbọ́ mẹwa tó dàgbà jùlọ—pẹ̀lú Ààrẹ Nelson ní àkọ́kọ́ lóri ìlà náà pẹ̀lú Pope Francis àti Dali Lama.

Ẹ̀là-ọ̀rọ̀ yí látinú àtẹ̀kọ Ìròhìn New York rọ́pò ẹ̀mí ọ̀pọ̀ àtẹ̀jáde káríayé: “Nínú agbo ìdìbò ti-ààrẹ [United State] tí ó ti mú ìwákiri-ẹ̀mí nípa ọjọ́-orí àti jíjẹ́ olórí wá, ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì ti Mr. Nelson ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì ti ó daba pé, ó kérejù nínú ìjọ rẹ̀, nọ́mba mẹ́ta ti ọjọ́-ìbí kò yẹ púpọ̀ ní ìfọwọ́-lọ́. Ó dúró bí ẹni ọlọ́lá kan ní àárín àwọn ọmọ ìjọ, tí wọ́n nwo ààrẹ wọn kìí ṣe bí ọ̀gá-iṣẹ́ kàn ṣùgbọ́n bí ‘wòlíì, aríran, àti olùfihàn.’”

Bí a ti dúpẹ́ tó pé ọjọ́-ìbí tó lápẹrẹ ti Ààrẹ Nelson ti fún wa ní ànfàní láti fi àwọn èrò hàn káríayé sí wólíì Ọlọ́run, ayẹyẹ kan tí a kò lè gbàgbé láé.

Àtúnṣe gbàgede Ilé-iṣẹ́ Ìjọ.

Ṣíwájú ìgbà ìrúwé yí, gbàgede tí a túnṣe ní igùn-mẹ́rin tẹ́mpìlì—tó nṣe àfihàn àwọn àsíá ilẹ̀ òkèèrè tí ó ndúró fún àwọn orílẹ̀-èdè níbití Ìjọ ti jẹ́ dídámọ̀—ni a ṣí ìbojú rẹ̀ kúrò. Ẹnu-ọ̀nà gbàgede ni a sàmìsí nípa àràbarà gíránáìtì lórí èyí tí a hà àwọn ọ̀rọ̀ ti-wòlíì wọ̀nyí sí: “Yíò si ṣe ní ọjọ́ ìkẹhìn, a ó fi òkè ilé Olúwa kalẹ̀ lórí àwọn òkè nlá, a ó sì gbée ga ju àwọn òkè kékèké lọ; gbogbo orílẹ̀-èdè ni yíò si wọ́ wá sí inú rẹ̀.”

Dájúdájú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àràbarà náà yíò ṣẹlẹ̀ ní ọdún mẹwa tó nbọ̀ láti jẹ́ ìfihàn kan pé àsọtẹ́lẹ̀ Ísáíàh yí ti nwá sí ìmúṣẹ.

Tẹ́mpìlì Salt Lake

Ẹ yẹ oye àìlèròtẹ́lẹ̀ ti àwọn ìṣílé tẹ́mpìlì àti ìyàsímímọ́ tí yíò lè ṣẹlẹ̀ ní díkédì tó nbọ̀ wò, àní ìlèṣe ti àwọn tẹ́mpìlì mẹ́rìnléláádọ́jọ tí a ṣì nkàá. E ro àwọn mílíọ́nù mẹwa-mẹwa lára yín àti àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n nrìn nínú ilé Olúwa. Oókan alámì ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí yíò jẹ́ àtún-yàsímímọ́ ti Tẹ́mpìlì Salt Lake àti àwọn ṣíṣe tí ó rọ̀ mọ́ ọ. Ìwọ̀nyí dájúdájú yíò jẹ́ àwọn ọjọ́ tí a kò lè gbàgbé láé.

Iṣètò ti Ìjọ

Ọdún méjì àti ọgbọ̀n yíò mú àwọn ànfàní àgbáyé wá láti ṣe àjọ̀dún ìgba ọdún ti ìdásílẹ̀ Ìjọ. Bíotilẹ̀jẹ́pé ó ti yá jù láti wípé Ìjọ yíò ṣe ìdámọ̀ pàtàkì yí, yíò fi àyè gbà wá dájúdájú láti pe ẹbí, ọ̀rẹ́, ẹlẹgbẹ́, àti àwọn àlejò pàtàkì láti “wá láti rí” àti láti ní òye dídára ti ipá alágbára tí ó ní nínú ìgbésí-ayé àwọn ọmọ Ìjọ.

Òlímpìkì Ìgbà-òtútù 2002 ní Ìlú Salt Lake.

Ní 2034, ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn olóyè, àlejò, àti eléré láti àyíká ayé yíò kún òpópónà ti Ìlú Salt Lake, Ibi-ìtàgé fún àwọn Eré Olímpíkì Ìgbà Òtútù. Bóyá kò sí ìjúwe títobijù nípa ìrẹ́pọ̀ àgbáyé ju èyí tí ó wà nínú àwọn Eré Òlímpíkì. Ojú ayé yíò wà lórí Ìjọ àti àwọn ọmọ-ìjọ rẹ̀, ní fífi àyè gba ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ní ànfàní láti yọ̀ọ̀da, sìn, àti láti pín ìròhìn ayọ̀ nípasẹ̀ àwọn ìṣe rere—ìṣẹ̀lẹ̀ kàn tí a kò lè gbàgbé láé.

Dájúdájú àwọn àkokò tó nbọ̀ wọ̀nyí yíò pèsè àwọn ọmọ ìjọ níbigbogbo pẹ̀lú àlékún àwọn ànfàní láti pín ìròhìn ayọ̀ ti ìhìnrere Jésù Kristì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ìṣe, díkédì kan tí a kò lè gbàgbé láé.

Ìròhìn Ayọ̀

Nínú ìpàdé kan ṣíwájú ọjọ́-ìbi rẹ̀, Àárẹ̀ Nelson pín èrèdí tí òun fi ṣìkẹ́ gbólóhùn-ọ̀rọ̀ “ìròhìn ayọ̀.” Ní ojú tirẹ̀, ó ṣàkíyèsí, gbólóhùn-ọ̀rọ̀ àwọn ìró ayọ̀ àti ìdùnnú. Ṣùgbọ́n “ìròhìn ayọ̀” mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá ju ìyẹn lọ. Ó ṣe àlàyé pé gbólóhùn-ọ̀rọ̀ yí látinú ọ̀rọ̀ àtilẹ̀bá Greek euangelion, èyí tí ó túmọ̀ sí bí ọ̀rọ̀ “ìròhìn rere” tàbí “ìhìnrere.” Ìdùnnú àti ayọ nínú ayé yí àti tí ó nbọ̀ wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìhìnrere Jésù Krístì nígbàgbogbo. Bayi gbólóhùn-ọ̀rọ̀ náà “ìròhìn ayọ̀” di ìtumọ̀ méjì yí mú ní ọ̀nà ìyanu.

“Àwọn ọkùnrin [àti obìnrin] wà, kí wọ́n lè ní ayọ̀.” Baba Ọ̀run ti pèsè ètò ìdùnnú tí yíò fún wa láyọ̀ nípasẹ̀ àwọn ìbùkún Rẹ̀. Ìwọ̀nyí pẹ̀lú gbígbé ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ní ayérayé bi àwọn ẹbí. Ètùtù Jésù Krístì ni gbùngbun sí ètò Ọlọ́run láti rà wá padà. Láti gba ìyè ayérayé, a gbọ́dọ̀ wá sọ́dọ̀ Krístì. Bí a ti nṣe bẹ́ẹ̀ “tí a sì nran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣe bákannáà, a nkópa nínú iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga.”

Ọ̀rọ̀ yí nípa ìròhìn ayọ̀ ti ìhìnrere Jésù Krístì ni ọ̀rọ̀ pàtàkì jùlọ lórí ilẹ̀-ayé. Èyí sì ni ibi tí ó ti kan àwọn ọ̀dọ́ àti ọ̀dọ́ àgbà ti Ijọ.

Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́

Nísisìyí, nígbàtí díkédì tó nbọ̀ yí lè kún fún àwọn ọjọ́ tí a kò lè gbàgbé láé fún gbogbo ọmọ Ìjọ, èyí nípatàkì lè jẹ́ òtítọ́ fún ẹ̀yin ti ìran tó ndìde. Ẹ wà nihin lórí ilẹ̀-ayé nítorí a yàn yín láti wà nihin nísisìyí. Ẹ ní agbára àti okun láti jẹ́ ọmọẹ̀hìn Krístì ní ọ̀nà àìròtẹ́lẹ̀ kan.

Ààrẹ George Q. Cannon kọ́ni, “Ọlọ́run ti fi àwọn ẹ̀mí pamọ́ fún àkokò yí tí wọ́n nígboyà àti ìpinnu láti dojúkọ ayé àti gbogbo agbára ẹni ibi, [àti láti] … gbé Síónì Ọlọ́run ga láìbẹ̀rù gbogbo àbájáde.”

Dé òpin yí, mo fẹ́ láti sọ̀rọ̀ sí yín nípa ìran tó ndìde, láti pè yín láti lérò bí díkédì tó nbọ̀ ti ládùn, ọ̀kan tí a kò lè gbàgbé láé, lè jẹ́ fún yín. Èmì náà fi àwọn ọ̀rọ̀ ìrọ̀rùn díẹ̀ ti àmọ̀ràn àti ìgbani-níyànjú tí ó lè fún yín lágbára ní díkédì tí ó nbọ̀ yí fúnni.

Bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín, mo ní fóònù-ìyára tí, ní ìgbà àtì láìsí ìṣílétí eyikeyi, nfa kíká àwọn fọ́tò tí ó nfi ohun tí mò nṣe ní ọjọ́ kan pàtó papọ̀. Ó máa nyanilẹ́nu nígbàgbogbo láti rí bí àwọn ọ̀pọ̀ nkan ṣe nyípadà fún mi àti ẹbí mi ní àwọn ọdún díẹ̀.

Ẹ kàn ronú lórí àwọn fọ́tò tí fóònù yín yíò gbà dé ọdún mẹ́wá láti ìsìsìyí! Ẹ lè rí arayín tí ẹ̀ ngboyè jáde láti ilé-ìwé gíga tàbí kọ́lẹ́jì, tí ẹ ngba ẹ̀bùn agbára tẹ́mpìlì, lílọ sí míṣọ̀n, ṣíṣe ìgbeyàwó, àti níní àkọ́bí ọmọ yín. Fún ti araẹni yín, èyí yíò jẹ́ díkédì kan tí a kò lè gbàgbé láé. Láìṣiyèméjì yíò jẹ́ bẹ́ẹ̀ bí ẹ bá tiraka pẹ̀lú àápọn láti di ìmọ́lẹ̀ sí ayé nípa bí ìròhìn ayọ̀ ti ìhìnrere Jésù Krístì fi lè mú kìí ṣe ìgbésí ayé yín nìkàn ṣùgbọ́n àwọn wọnnì ti ẹbí yín, ọ̀rẹ́, àti àwọn àtẹ̀lé ìròhìn àwùjọ lọ́rọ̀ àti dàgbà.

Ẹ lè ní ìyàlẹ́nú bí ẹ ó ti ṣe èyí.

Àwọn wòlíì Ọlọ́run kọ́ wa pé èyí ni à nṣe nípasẹ̀ àwọn ìṣe ìrọ̀rùn mẹ́rin, tí a tọ́ka sí bí àwọn ojúṣe yíyàn àtọ̀runwá: àkọ́kọ́, gbígbé ìhìnrere ti Jésù Krístì; ìkejì, ṣíṣe ìtọ́jú fún àwọn wọnnì nínú àìní, ìkẹ́ta, pípe gbogbo ènìyàn láti gba ìhìnrere; àti ìkẹ́rin, dída àwọn ẹbí pọ̀ fún ayé àìlópin. Pẹ̀lú àpẹrẹ, ọ̀kọ̀ọ̀kan ni a lè ṣe nínú àwọn ọ̀nà déédé àti adánidá.

Àwọn Ojúṣe Yíyàn Àtọ̀runwá

Mo ṣe ìlérí fún yín pé èyí yíò jẹ́ díkédì tí a kò ní gbàgbé fún yín bí ẹ bá rọ̀mọ́ àwọn ojúṣe yíyàn àtọ̀runwá mẹ́rin wọ̀nyí. Ẹ jẹ́ kí a yẹ ohun yí tí ó lè gbà wò

Àwọn Ojúṣe Yíyàn Àtọ̀runwá Mẹ́rin.
ọmọdébìnrin ńgbàdúrà.

Àkọ́kọ́, gbígbé ìhinrere Jésù Krístì. Ṣíṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ ti àwọn wòlíì, àti kíkọ́ láti fẹ́ràn Baba ní Ọ̀run. Ẹ fi ìnífẹ́sí ọkàn yín sí I, kí ẹ sì tiraka láti rìn ní ọ̀nà Rẹ̀. Ẹ di gbígbéga nípasẹ̀ “májẹ̀mú ìgbẹ́kẹ̀lé” tí Alàgbà Ulisses Soares ti júwe. Ìgbẹ́kẹ̀lé yí nwá látinú dídá àwọn májẹ̀mú láti tẹ̀lé Jésù Krístì, ní mímọ̀ pé Olùgbàlà ní àyídà yíò fún yín lókun yíò sì tì yín lẹ́hìn.

Ẹ jẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ yín ní ayọ̀ tí ẹ ní ìmọ̀lára rẹ̀ ní gbígbé ìhìnrere, ẹ ó sì jẹ́ ọ̀rọ̀ ìhìnrere dídárajùlọ tí wọ́n máa gbà láé.

Ìkejì, ẹ nawọ́ jáde nínú àánú láti ṣètọ́jú fún àwọn wọ̀nnì nínú àìní. Ìran yín jẹ́ àìwọpọ̀ àfiyèsí ti àwọn tí kò ní orire tó. Níbikíbi tí àjálù bá ti ṣẹlẹ̀ tí àwọn ọmọ Ìjọ bá ti rọ lọ láti ṣèrànwọ́ láti pá àwọn ìdọ̀tí mọ́ kúrò kí wọ́n sì tu àwọn olùpọ́njú nínú, ó dàbí àwọn púpọ̀jù nwọ “Ọwọ́ Ìrannilọ́wọ́” àwọn T-Ṣẹ́ẹ̀tì ni àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn tí ó lé lógún. Ó jẹ́ ìwà-ẹ̀dá láti “gbé ẹrù ara wa” àti “láti tu àwọn wọnnì tí wọ́n dúró nínú àìní àti ìtùnú nínu.” Nípa ṣíṣe èyí a lè “mú òfin Krístì ṣẹ.”

Àwọn ọmọdé nkó jáàmù jọ fún àwọn wọnnì nínú àìní.

Evan, ọmọdékùnrin ọjọ́ orí Alakọbẹrẹ, pinnu láti lo àkokò ìsìnmi ìrúnwé rẹ̀ láti ìlé-ìwé ní kíkó àwọn ìpèsè fún pínọtì bọtà àti jẹ́lì sándwíṣì pamọ́ láti mu lọ sí ibi-ìkònjẹ́ pamọ́ ìbílẹ̀ rẹ̀. Ó rí iṣẹ́ náà lórí ibi-wẹ́ẹ̀bù JustServe. Evan kékeré kó gbogbo kílásì ilé-ìwé jọ láti ṣèrànwọ́ láti kó ó jú ìgò ẹgbẹ̀rún-méje ti jẹ́lì jọ! Ẹ jẹ́ kí gbogbo ènìyàn tí ẹ̀ nsìn mọ̀ pé àníyàn yín fún wọn jinlẹ̀ gidi nínú ìfẹ́ yín fún Ọlọ́run àti ìfẹ́-inú láti bojútó aladugbo yín bí ara yín.

Àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere ní Brazil.

Ìkẹ́ta, pípe gbogbo-ènìyàn láti gba ìhìnrere. Ní ọdún yí a ṣí àwọn míṣọ̀n titun mẹ́rìndínlógójì káàkiri àgbáyé láti fàyé gba gbogbo ẹni tí ó bá ní ìfẹ́-inú láti sin míṣọ̀n ìgbà-kíkún. Ní àkokò ìgbàtí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ nkúrò nínú ìṣe ẹ̀sìn bí-àṣà lápapọ̀, èyí jẹ́ olókìkí ó sì nsọ̀rọ̀ ìwà-ẹ̀dá ọlọ́lá ti ẹ̀rí yín. Bóyá sísìn ìgbà-kíkún tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, ẹ jọ̀wọ́ ẹ da okun títóbi yín mọ̀ láti ní ipá lórí àwọn ọ̀gbà yín bí ẹ ti nfẹ́ràn, pín, tí ẹ sì npè wọ́n láti ṣe ìwákiri ìhìnrere Jésù Krístì.

Àwọn ọ̀dọ́ ní Tẹ́mpìlì Preston.

Ìkẹ́rin, ẹ ṣe ìdàpọ̀ ẹbí fún ayé-àìlópin. Bí mo ti nṣe ìbẹ̀wò àwọn tẹ́mpìlì yíká ayé, yàrá-ìdúró-nìkàn ti èrò àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ndúró níbi ìrìbọmi àti ní àlékún àwọn oye ọ̀dọ́ àgbà tí wọ́n nsìn bí àwọn òṣìṣẹ́ ìlànà yàmílẹ́nu. Láìpẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ ó jú ọgọ́rún-mẹ́fà láti Scotland àti Ireland rin ìrìnàjò lọ sí Tẹ́mpìlì Preston England, wọ́n ṣe ó jú àwọn ìlànà ẹgbẹ̀rún mẹ́rin lọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èyí tí ó jẹ́ àwọn olóògbé babanlá ti-ara wọn! Mo rọ̀ yín láti di òṣìṣẹ́ nínú ìwé-ìtàn ẹbí, lo àkokò nínú tẹ́mpìlì, kí ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ múra arayín sílẹ̀ láti jẹ́ ọ̀kùnrin tàbí obìnrin onínúrere tí ó ṣetán láti ṣe ìgbeyàwó sí ojúgbà yíyẹ ìbádọ́gba nínú tẹ́mpìlì. Ẹ gbèrú àwòṣe kan nínú ìgbésí-ayé yín nísisìyí láti mú tẹ́mpìlì jẹ́ déédé ara ìgbésí-ayé yín.

Íparí

Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀dọ́ mi ọ̀wọ́n, ó ṣeéṣe pé àwọn ìṣòro yíò wà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa ní àwọn ọjọ́ iwájú. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, bí a ṣe nwọnú díkédì àìròtẹ́lẹ̀ àwọn àkokò tí ó nbọ̀ yí, njẹ́ kí a pín àwọn ìròhìn ayọ̀ nípasẹ̀ àwọn ìṣe ìrọ̀rùn ti gbígbé ìgbésí-ayé, ìtọ́jú, ìpè, àti rírẹ́pọ̀. Bí a ti nṣe bẹ́ẹ̀, Olúwa yíò bùkún wa pẹ̀lú àwọn ìrírí tí a kò lè gbàgbé Láé.

Mo jẹri pé àwọn wọnnì tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Olúwa pẹ̀lú ọkàn àtinúwá àti èrò òtítọ́, àwọn wọnnì tí wọ́n ní orúkọ Olùgbàlà ní ẹnu wọn àti Ẹ̀mí Mímọ́ nínú ọkàn wọn, àwọn wọnnì tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ lórí ìrìnàjò ọlọ́lá àti ológo yí yíò ṣe àwárí ẹ ó sì ní ìrírí àwọn ìbùkún sẹ̀lẹ́stíà tó pọ̀ jọjọ ẹ ó sì gba ẹ̀rí pé Ọlọ́run ngbọ́ ọ yín, mọ̀ yín, àti pé Ó fẹ́ràn yín. Ẹ ó ní ìrírí àwọn ọjọ́ tí ẹ kò lè gbàgbé láé. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.