Àyànfẹ́ Ọlọ́run
Kíkún fún ìfẹ́ Ọlọ́run yíò dá ààbò bò wá nínú ìjì ayé ṣùgbọ́n bákannáà yíò mú wa ní àwọn àkokò ìdùnnú àti ìdùnnú síi.
Ṣaájú ki ntó bẹ̀rẹ̀, mo níláti sọ fún yín pé méjì nínú àwọn ọmọ mi ti dákú rí lásìkò sísọ̀rọ̀ níbi àwọn pẹpẹ, àtipé èmi kò tíì nímọ̀lára ìsopọ̀ pẹ̀lú wọn síi rí ju bí ti àkokò yí lọ. Èmi ti ní púpọ̀ nínú ọkàn mi ju ilẹ̀kùn gbígbésókè lásán.
Ẹbí wa ní ọmọ mẹ́fà, tí wọ́n máa nfi ara wọn ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà míràn pé àwọn ni ààyò ọmọ jù lọ. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ní àwọn oríṣiríṣi ìdí fún yíyàn. Ìfẹ́ wa fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ wá jẹ́ mímọ́ àti ìmúṣẹ àti pípé. A kò lè nífẹ̀ẹ́ èyíkéyìí nínú wọn ju òmíràn lọ—pẹ̀lú ìbí ọmọ kọ̀ọ̀kan ni ìmúgbòòrò ìfẹ́ wa tí ó rẹwà jù lọ wá. Mo nní ìbáṣe púpọ̀ júlọ sí ìfẹ́ Baba mi Ọ̀run sí mi nípasẹ̀ ìfẹ́ ti mo nímọ̀lára rẹ̀ fún àwọn ọmọ mi.
Bí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣe ntún àwọn ohun tí o mú wọ́n jẹ́ ọmọ tí a nífẹ̀ẹ́ jù lọ ṣe, ẹ lè rò pé ẹbí wa kò tíì ní iyàrá kan tí ó dàrú rí. Èrò-orí ti àwọn àlébù nínú ìbáṣepọ̀ laarin awọn òbí àti ọmọ máa ndínkù pẹ̀lú ìfojúsùn lórí ìfẹ́.
Lójú àmì kan, bóyá nítorípé mo lè ri pé à ndoríkọ ìhà rògbòdìyàn ẹbí kan tí kò lè ṣàìṣẹlẹ̀, èmi yíò sọ ohun kan bíi, “Ó DÁRA, ẹ ti jẹ́kó rẹ̀mí, ṣùgbọ́n èmi kì yíò kéde rẹ̀; ẹ mọ èwo nínú yín tó jẹ́ ààyò mi.” Ìlépa mi ni pé ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà yio nímọ̀lára ìṣẹ́gun tí a ó sì yẹra fún kí ogun gbòdekan—ó kéré jù títí di àkokò míràn!
Nínú Ìhìnrere rẹ̀, Jòhánnù ṣàpèjúwe ara rẹ̀ bí “ọmọẹ̀hìn tí Jésù fẹ́ràn,” bí ẹni pé ìṣètò náà jẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ bákan. Mo fẹ́ ròó pé èyí jẹ́ nítorípé Jòhánnù nímọ̀lára pé Jésù fẹ́ràn òun pátápátá. Néfì fún mi ní irú ìmọ̀lára kannáà nígbàtí ó kọ̀wé pé, “Mo ṣògo nínú Jésù mi.” Nítòótọ́, Olùgbàlà kìí ṣe ti Néfì ju bí Òun ti jẹ́ ti Jòhánnù, ṣùgbọ́n síbẹ̀ ìwà-ẹ̀dá ara-ẹni ti ìbáṣepọ̀ Néfì pẹ̀lú Jésù “rẹ̀” mú un lọ sí àpèjúwe ẹlẹgẹ́ náà.
Kò ha jẹ́ ìyàlẹ́nu pé àwọn àkokò kan wà nígbàtí a lè nímọ̀lára pé a jẹ́ fífiyèsí ati fífẹ́ràn ní kíkún àti ní ti-ara-ẹni bí? Néfì lè pè É ní Jésù “òun”, bẹ́ẹ̀ sì ni àwa náà lè ṣe. Ìfẹ́ Olùgbàlà wa ni irú ìfẹ́ “gíga jùlọ, tó lọ́lá jùlọ, tó lágbára jùlọ,” ati tí Ó npèsè títí tí a ó fi “kún.” Ìfẹ́ àtọ̀runwá kìí gbẹ, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sì jẹ́ àyànfẹ́ ààyò. Ìfẹ́ Ọlọ́run wà níbití, bí àwọn nkan yíyà róbótó lórí àwòrán Venn kan, gbogbo wa gbéra-léra. Eyikeyi àwọn ẹ̀yà ninu wa tí ó dàbí pé ó yàtọ̀, Ìfẹ́ Rẹ̀ wà níbití a ti rí àjọṣepọ̀.
Njẹ́ ó jẹ́ ìyàlẹ́nu kankan pé àwọn òfin tó tóbi jùlọ ni láti fẹ́ràn Ọlọ́run àti láti fẹ́ràn àwọn tó yí wa ká? Nígbàtí mo bá rí àwọn èèyàn tí wọ́n nfi ìfẹ́ bíi ti Kristi hàn síra wọn, ó máa nrí sí mi bíi pé ìfẹ́ náà ní nkan nínú ju ìfẹ́ wọn lọ; ó jẹ́ ìfẹ́ tó tún ní ti ọ̀run nínú rẹ̀. Nígbàtí a bá fẹ́ràn ara wa lọ́nà yí, ní pípé àti kíkún bí a ti le ṣe tó, ọ̀run nlọ́wọ́ síi pẹ̀lú.
Nítorínáà, bí ẹnìkan tí a bìkítà nípa rẹ̀ bá dàbí ẹnipé ó jìnnà sí ìmọ̀lára ìfẹ́ àtọ̀runwá, a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yìí—nípa ṣíṣe àwọn ohun tí ó nmú wa súnmọ́ Ọlọ́run fúnra wa àti ṣíṣe àwọn ohun tí yíó mú wa sún mọ́ wọn—jíjuwọ́sí kan láìsọ̀rọ̀ láti wá sọ́dọ̀ Kristi.
Ó wùmí kí nlè joko pẹ̀lú yín kí nbèèrè lọ́wọ́ yín àwọn ipò wo ni ó mú kí ẹ nímọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run. Àwọn ẹsẹ ìwé-mímọ́ wo, àwọn ìṣe iṣẹ́-ìsìn wo ní pàtó? Níbo ni ìwọ yíò wà? Orin wo? Nínú àjùmọ̀-kẹ́gbẹ́ tani? Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò jẹ́ ibi ọlọ́rọ̀ kan láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa sísopọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ ọ̀run.
Ṣùgbọ́n bóyá ẹ nímọ̀lára jíjìnà sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Bóyá ègbè àwọn ohùn ti àìnírètí àti òkùnkùn tí ó nrẹ ẹ̀rò inú yín sílẹ̀ lè wà, àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n nwí fún yín pé a ti pa yín lára ẹ sì ti ní ìdàmú púpọ̀jù, ní àìlera jù àti fífojúfòjá, yíyàtọ̀ jù tàbí àìrí-ìbàlẹ̀ ọkàn tí ó nmú ìfẹ́ tọ̀run wá ní ọ̀nà òdodo gan. Bí ẹ bá gbọ́ àwọn èrò-orí wọnnì, nígbànáà jọ̀wọ́ gbọ́ èyí: àwọn ohùn wọnnì kàn jẹ́ àṣìṣe. A lè má ka ìròbìnújẹ́ sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé ọ̀nà eyikeyi tí yíò fi mú wa jẹ́ àìyege nínú ìfẹ́ tọ̀run—gbogbo ìgbà tí a bá kọ orin tí ó nrán wa létí pé àyànfẹ́ wa àti aláìlẹ́bi Olùgbàlà yàn láti di “pípalára, bíbàjẹ́, [àti] fífàya fún wa,” ní gbogbo ìgbà tí a bá gba búrẹ́dì jíjá. Nítõtọ́ Jésù mú gbogbo ìtìjú kúrò nínú àwọn ìbàjẹ́. Nípasẹ̀ ìbàjẹ́ Rẹ̀, Ó di pípé, Ó lè sọ wá di pípé láìka ìbàjẹ́ wa sí. Bíbàjẹ́, dídáwà, fífàya, àti pípalára ni Ó jẹ—a sì lè nímọ̀lára pé àwa náà wà bẹ́ẹ̀—ṣùgbọ́n ní yíyapa kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, a kò rí bẹ́ẹ̀. “Àwọn ènìyàn bíbàjẹ́; ìfẹ́ pípé,” bí orin náà ti lọ.
Ẹ lè mọ ohun ìkọ̀kọ̀ nípa ara yín tí ó nmú yín ní ìmọ̀lára àìlefẹ́ràn. Bíótiwù kí ẹ jẹ́ títọ́ to nípa ohun tí ẹ mọ̀ nípa ara yín, ó jẹ́ àṣìṣe fún yín láti rò pé ẹ ti fi ara yín sí ibi tí ó kọjá ìfẹ́ Ọlọ́run. Nígbà míràn a máa njẹ́ ònrorò ati aláìní-sùúrù sí ara wa lọ́nà tí a kò lè fojú inú wò sí ẹnikẹ́ni míràn. Púpọ̀ wa fun wa lati ṣe ní ìgbésí ayé yí, ṣùgbọ́n ìkórira-ara-ẹni àti ìdálẹ́bi ara ẹni tó tinilójú kò sí nínú àtòkọ náà. Bíótiwù kí á nímọ̀lára àṣìṣe tó àwọn, apá Rẹ̀ kò kúrú. Rárá. Wọ́n máa ngùn tó nígbà gbogbo láti “[dé] ibi dídé wa” kí wọ́n sì gbá ẹnì kọ̀ọ̀kan wa mọ́ra.
Nígbàtí a kò bá ní ìtara ìfẹ́ àtọ̀runwá, kò tíì lọ kúrò. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni pé “àwọn òkè nlá yíò lọ, a ó sì ṣi àwọn òkè kéékèèké kúrò; ṣùgbọ́n inú rere [Rẹ̀] kì yíò yà kúrò lọ́dọ̀ [wa].” Nítorínáà, láti lè ṣe kedere, èrò náà pé Ọlọ́run ti dáwọ́ ìfẹ́ dúró gbọ́dọ̀ wà ní ìsàlẹ̀ àwọn àlàyé tó ṣeéṣe kó wà nínú ìgbésí ayé tí a kò fi ní débẹ̀ títí di ẹ̀hìn ìgbà tí àwọn òkè-nlá ti lọ àti tí àwọn òkè kéékèèké ti lọ!
Mo gbádùn àpẹrẹ-àmì yí gan-an ti àwọn òkè-nlá ní jíjẹ́ ẹ̀rí ti ìdánilójú ìfẹ́ Ọlọ́run. Àpẹrẹ-àmì alágbára náà sọ ìtàn àwọn tó lọ sí òkè-nlá láti gba ìfihàn àti àpèjúwe Isáíàh nípa “òkè-nlá ti ilé Olúwa” tí a “fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní orí àwọn òkè-nlá.” Ilé Olúwa ni ilé àwọn májẹ̀mú tí ó ṣeyebíye jùlọ àti ibikan fún gbogbo wa láti sinmi kí a sì rì jinlẹ̀ sínú ẹ̀rí ìfẹ́ Baba wa fún wa. Mo tún ti gbádùn ìtùnú tí ó nwá sí ọkàn mi nígbàtí mo bá di májẹ̀mú ìrìbọmi mi mọ́ ara mi ní líle díẹ̀ sí ti mo sì wá ẹnìkan tí o nṣọ̀fọ̀ àdánù kan tàbí tó nbanújẹ́ nítorí ìjákulẹ̀ kan àti tí mo gbìyànjú láti rànwọ́n lọ́wọ́ láti di àwọn ìmọ̀lára wọn mú kí wọn ó sì ṣiṣẹ lori rẹ̀. Njẹ́ àwọn ọ̀nà ni ìwọ̀nyí láti di rírì díẹ̀ síi sínú ìfẹ́ ti májẹ̀mú tó ṣe iyebíye náà bí, ìfẹ́ àìnípẹ̀kun?
Nítorínáà, bí ìfẹ́ Ọlọ́run kò bá fi wá sílẹ̀, kílódé tí a kì í fi í nímọ̀lára rẹ̀ nígbà gbogbo? Láti kàn ṣàkóso àwọn àfọjúsọ́nà yín: Èmi kò mọ̀. Ṣùgbọ́n jíjẹ́ fífẹ́ràn dájúdájú kìí ṣe ìkanáà bìi nínímọ̀lára fifẹ́ràn, àtipé mo ní àwọn èrò díẹ̀ tó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín bí ẹ ṣe nlépa àwọn ìdáhùn yín sí ìbéèrè náà.
Bóyá ẹ njìjàkadì pẹ̀lú ìbànújẹ́, ìsoríkọ́, ìwà ọ̀dàlẹ̀, ìdánìkanwà, ìjákulẹ̀, tàbí ìyọlẹ́nu alágbára míràn sínú agbára yín láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run fún yín. Bíóbáríbẹ́ẹ̀, àwọn nkan wọ̀nyí lè ṣíwọ́ tàbí dá agbára wa dúró láti nímọ̀lára bí a ti lè nímọ̀lára bíbẹ́ẹ̀ kọ́. Fún àkokò kan o kéré jù, bóyá ẹ̀yin kò ní lè nímọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀, tí ìmọ̀ yíò sì níláti tó. Ṣùgbọ́n mo nrò ó bóyá ẹ lè ṣe àyẹ̀wò—ní pẹ̀lẹ́-pẹ̀lẹ́—pẹ̀lú oríṣiríṣi àwọn ọ̀nà ṣíṣe àfihàn àti gbígba ìfẹ́ àtọ̀runwá. Njẹ́ ẹ lè gbé ìgbésẹ̀ kan padà látinú ohunkóhun tí ó wà níwájú yín àti bóyá ìgbésẹ̀ míràn àti òmíràn, títí ẹ̀yin o fi rí àlà-ilẹ̀ tó gbòòrò, tó gbòòrò àti gbígbòòrò síbẹ̀ tó bá jẹ́ ṣeéṣe, títí ẹ̀yin ó fi jẹ́ “ríronú sẹ̀lẹ́stíà gan” nítorí ẹ nwo àwọn ìràwọ̀ tí ẹ sì nrántí àwọn ayé láìní ònkà àti nípasẹ̀ wọn Ẹlẹda wọn?
Orin-ẹyẹ, nínímọ̀lára oòrùn tàbí afẹ́fẹ́ tàbí òjò lórí awọ ara mi, àti àwọn àkokò nígbàtí àdánidá bá fi àwọn ìmọ̀-ara mi sí ìyanu Ọlọ́run—ọ̀kọ̀ọkan ti ní ipa nínú pípèsè mi pẹ̀lú àsopọ̀ ti ọ̀run. Bóyá ìtùnú àwọn ọ̀rẹ́ òtítọ́ yìó ṣèrànwọ́. Bóyá orin? Tàbí sísìn? Njẹ́ ẹ ti tọ́jú ìgbàsílẹ̀ tàbí ìwé àkọsílẹ̀ ti àwọn àkokò nígbàtí àsopọ̀ yín pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe kedere sí yín? Bóyá ẹ lè pe àwọn wọnni tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé láti pín àwọn orísun àsopọ̀ àtọ̀runwá pẹ̀lú yín bí ẹ ṣe nwá ìrànlọ́wọ́ àti òye.
Ó yàmílẹ́nu pé, bí Jésù bá yan ibi kan tí ẹ̀yin àti Òun ti lè pàdé, ibi ìkọ̀kọ̀ kan tí ẹ̀yin yíò lè ní ìfojúsùn kan ṣoṣo sí ara Rẹ̀, njẹ́ Ó lè yan ibi àrà-ọ̀tọ̀ ti ìjìyà ara-ẹni rẹ̀, ibi àìní rẹ tó jinlẹ̀ jùlọ, ibi ti ẹlòmíràn kò lè lọ? Ibìkan tí ẹ bá ti nímọ̀lára àdáwà pé ẹ gbọ́dọ̀ dá nìkan wà nitòótọ́ ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ tán, ibì kan tó jẹ́ pé bóyá Òun níkan ni ó ti rin ìrìn-àjò débẹ̀ ṣùgbọ́n dájúdájú ó ti múra sílẹ̀ láti pàdé nyín níbẹ nígbàtí ẹ bá dé. Bí ẹ bá ndúró dè É láti wá, njẹ́ Òun lè wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ àti ní àrọwọ́tó bí?
Bí ẹ bá nnímọ̀lára kíkún fún ìfẹ́ ní àkokò ìgbésí ayé yín yí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ gbìyànjú kí ẹ dìímú nítòótọ́ bí asẹ́ ṣe ndi omi mú. Ẹ fún un ká níbi gbogbo tí ẹ bá lọ. Ọ̀kan nínú àwọn iṣẹ́ ìyanu ti ọrọ̀-ajé àtọ̀runwá ni pé nígbàti a bá gbìyànjú láti pín ìfẹ́ Jésù, a ri pé a nkún wa ní ìyàtọ̀ ní ìlànà tí “ẹnìkẹ́ni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi yìó ríi.”
Kíkún fún ìfẹ́ Ọlọ́run ndáàbò bò wá nínú àwọn ìjì ìgbésí ayé ṣùgbọ́n ó tún nmú kí àwọn àkokò aláyọ̀ ní ayọ̀ púpọ̀ síi—àwọn ọjọ́ aláyọ̀ wa, nígbà tí oòrùn bá wà ní ojú ọ̀run, a máa nmú kí ìmọ́lẹ̀ túbọ̀ tàn sí i nípasẹ̀ oòrùn nínú ọkàn wa.
Ẹ jẹ́kí á di “fífìdímúlẹ̀ àti jíjinlẹ” nínú Jésù wa àti nínú ìfẹ́ Rẹ̀. Ẹ jẹ́kí á wá kí á sì ṣe ìṣúra àwọn ìrírí mímọ̀ ìfẹ́ àti agbára Rẹ̀ lára nínú ìgbésí ayé wa. Ayọ̀ ìhìnrere wa fún gbogbo ènìyàn: kìí ṣe awọn onínúdídùn nìkan, kìí ṣe àwọn oníròbìnújẹ́ nikan. Ayọ̀ ni èrèdí wa, kìí ṣe ẹ̀bùn àyè wa. A ní gbogbo ìdí tó dára láti “yọ̀ kí á sì kún fún ìfẹ́ sí Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn.” Ẹ jẹ́kí a kún. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.