Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ọkùnrin Náà Tí Ó Bá Jèhófàh Sọ̀rọ̀
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


11:8

Ọkùnrin Náà Tí Ó Bá Jèhófàh Sọ̀rọ̀

Joseph Smith di “alábùkún-fún láti ṣí àkókò iṣẹ ìríjú ìkẹhìn,” àwa sì di alábùkún-fún pé ó ṣe bẹ́ẹ̀.

Èrò mi ní òní àti nígbà gbogbo ni láti jẹ́ri nípa Jésù Krístì, pé Òun ni Ọmọ Ọlọ́run, Ẹlẹ́dã àti Olùgbàlà aráyé, Olùtúsílẹ̀ ati Olùràpadà wa. Nítorípé “àwọn ìpìlẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì ti ẹ̀sìn wa ni ẹ̀rí àwọn àpóstélì àti àwọn wòlíì, nípa Jésù Krístì,” loni mo pín ìmọ̀ ati ẹ̀rí mi nípa Olùgbàlà pẹ̀lú yín bí a ti fún un lókun ati mú jinlẹ̀ nipa ìgbésí ayé àti àwọn ìkọ́ni ti àpóstélì àti wòlíì kan pàtàkì.

Ìpilẹ̀sẹ̀ Ọgbọ́n

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ rírẹwà kan ní ibẹ̀rẹ̀ igbà irúwé ti 1820, Joseph Smith ẹni ọdún mẹ́rìnlá wọ igbó ṣúúrú ti awọn igi ní ẹ̀bá ibùgbé ẹbí rẹ̀ láti gbàdúrà nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kí ó sì béèrè ijọ tí yio darapọ̀ mọ́. Àdúrà tòótọ́ rẹ̀, tí ó gbà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àìyẹsẹ̀, gba àkíyèsí àwọn ipá tó lágbára jùlọ ní gbogbo ayé, pẹ̀lú ti Baba ati Ọmọ. Àti èṣù náà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn wọ̀nyí ní ìfẹ́ líle kan ninu àdúrà náà ati ọmọkùnrin náà.

Ohun ti a npè ní Ìran Àkọ́kọ́ nísisìyí ṣe àmì ìbẹ̀rẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo ní àkókò iṣẹ ìríjú ti ìkẹhìn yí. Ṣùgbọ́n fún Jósẹ́fù, ìrírí náà jẹ́ ti araẹni àti ti ìmúrasílẹ̀ bákannáà. Gbogbo ohun tí ó fẹ́ ni ìdáríjì àti ìdarí. Olúwa fún un ní méjéèjì. Ìkọ́ni láti máṣe “darapọ̀ mọ́ ọ̀kankan ninu [àwọn ijọ náà]” jẹ́ dídarí. Àwọn ọ̀rọ̀ náà, “Awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a dáríjì ọ́” jẹ́ ríranipadà.

Fún gbogbo àwọn òtítọ́ rírẹwà tí a lè kọ́ lati inú Ìran Kinní náà, bóyá kókó àmúrelé ti Jósẹ́fù kàn ni pé, “Èmi ti rí ẹ̀rí Jákọ́bù pé ó jẹ́ òtítọ́—pé ẹni tí ó ba ku ọgbọ́n fún le béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí ó sì gbà.”

Bí ọ̀mọ̀wé kan ti sọ: “ìró ìmọ̀làra tòótọ́ ti Ìran Kinní lóni ni láti mọ̀ pé ó jẹ́ ìwà àdánidá Ọlọ́run láti fifún àwọn tí ó ku ọgbọ́n fún. … Ọlọ́run tí ó fi Ara Rẹ̀ hàn sí Joseph Smith ninu igbó ṣúúrú mímọ́ náà jẹ́ Ọlọ́run tó ndáhùn àwọn ọ̀dọ́mọdé ní awọn àkókò ìdààmú.”

Ìrírí Jósẹ́fù ninu igbó ṣúúrú fún un ní ìgboyà láti bèèrè fún ìdáríjì àti ìdarí fún ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀. Ìrírí rẹ̀ bákannáà ti fún èmi ní ìgboyà láti béèrè fún ìdáríjì àti ìdarí fún ìyókù ayé mi.

Ìrònúpìwàdà Déédé

Ní Ọjọ́ Kọkànlélógún Oṣù Kẹsan, 1823, Jósẹ́fù gbàdúrà pẹ̀lú ìtara fún ìdáríjì, pẹ̀lú ìgbẹkẹ̀lé pé nítorí ìrírí rẹ̀ ninu igbó ṣúúrú ní ọdún mẹ́ta ṣaájú, Ọ̀run yío tún dáhùn lẹ́ẹ̀kansìi. Ó sì rí bẹ́ẹ̀! Olúwa rán ángẹ́lì kan—Mórónì—láti kọ́ Jósẹ́fù ati láti sọ fún un nípa àkọsílẹ̀ àtijọ́ kan tí òun yío túmọ̀ lẹ́hìnwá nípa ẹ̀bùn ati agbára Ọlọ́run—Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

Ó fẹ́rẹ̀ tó ọdún mẹ́tàlá lẹ́hìn náà, Jósẹ́fù àti Oliver Cowdery kúnlẹ̀ ninu àdúrà ọ̀wọ̀, ìdákẹ́jẹ́ ninu Tẹ́mpìlì Kirtland tí a ṣẹ̀sẹ̀ yàsọ́tọ̀ ní titun. A kò mọ ohun tí wọ́n gbàdúrà fún, ṣùgbọ́n àwọn àdúrà wọn ṣeéṣe kí ó ní ẹ̀bẹ̀ ninu fún ìdáríjì, nítorí, bí wọ́n ti dìde, Olùgbàlà farahàn Ó sì wí pé, “Ẹ kíyèsíi, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín; ẹ̀yin jẹ́ mímọ́ níwájú mi.”

Ní àwọn oṣù àti awọn ọdún lẹ́hìn ìrírí yí, Jósẹ́fù àti Oliver yio tún dẹ́ṣẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi. Àti lẹ́ẹ̀kansíi. Ṣùgbọ́n ni àkókò náà, nítorí àkókò náà, ní ìdáhùn sí ẹ̀bẹ̀ wọn ati ní ìmúrasílẹ̀ fún ìmúpadàbọ̀sípò ológo ti awọn kọ́kọ́rọ́ náà ti ó fẹ́ ṣẹlẹ̀, Jésù ṣe wọ́n ní àìlẹ́ṣẹ̀.

Ayé Jósẹ́fù ti ìrònúpìwàdà déédé fúnmi ní ìgbẹkẹ̀lé láti “wá pẹ̀lú ìgboyà sí ibi ìtẹ́ oore ọ̀fẹ́ náà, pé kí [èmi] le gba àánú.” Mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ pé Jésù Krístì nítòótọ́ jẹ́ “olùdáríjì ní ti ìwà àdánidá.” Kìí ṣe iṣẹ́ Rẹ̀ tàbí ìwà Rẹ̀ láti dá lẹ́bi. Ó wá láti gbàlà.

Ẹ béèrè lọ́wọ́ Olúwa.

Bíi apákan “idápadà ohun gbogbo” tí a ṣèlérí, Olúwa, nípasẹ̀ Joseph Smith, mú Ìwé ti Mọ́mọ́nì jáde wá àti àwọn ìfihàn míràn tí wọ́n ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere Rẹ̀ ninu. Àwọn òtítọ́ pàtàkì ni a fúnni ní mímọ̀-kedere àti jíjẹ́-pípé bí Jósẹ́fù ti nfi lemọ́lemọ́ béèrè lọ́wọ́ Olúwa fún ìdarí. Ẹ yẹ àwọn wọ̀nyí wò:

  1. Baba ati Ọmọ ní àwọn àgọ́ ara “tó jẹ́ àfojurí bíi ti ènìyàn.”

  2. Kìí ṣe àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa nìkan ni Jésù gbé lé Ararẹ̀ ṣùgbọ́n bákannáà àwọn àìsàn wa, àwọn ìpọ́njú, àti àwọn àìlera.

  3. Ètùtù Rẹ̀ jẹ́ onírora tóbẹ́ẹ̀ tí ó mú kí Òun ṣẹ̀jẹ̀ láti gbogbo ihò ara.

  4. A di gbígbàlà nípa oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ “lẹ́hìn ohun gbogbo tí a lè ṣe.”

  5. Àwọn ipò wà fún àánú Krístì.

  6. Bí a ti nwá sí ọ̀dọ̀ Krístì, Òun kì yío dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì nìkan, ṣùgbọ́n Òun yío yí ìwà àdánidá wa gan-an padà bákannáà, pé “kí àwa ó má baà ní ìwà àdánidá mọ́ láti ṣe ibi.”

  7. Krístì nfi ìgbà gbogbo pàṣẹ fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ láti kọ́ àwọn tẹ́mpìlì, níbití Òun ti n fi ara Rẹ̀ hàn sí wọn Ó sì nfún wọn ní ẹ̀bùn agbára láti òkè wá.

Mo jẹ́ri pé gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́ otítọ́ ati pé ó pọndandan. Wọ́n dúró fún apákan péré ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ tí a múpadàbọ̀sípò lati ọwọ́ Jésù Krístì nípasẹ̀ Joseph Smith ní ìdàhùn sí ìbéèrè àwítúnwí ti Jósẹ́fù fún ìdarí.

Mímú Ìjọba Yí Tẹ̀síwájú

Ní 1842, Jósẹ́fù kọ nípa àwọn ohun iyanu tí yío wá sí ìmúṣẹ ni àkókò iṣẹ ìríjú ìkẹhìn yí. Ó kéde pé ní ìgbà tiwa, “oyè-àlùfáà ti ọ̀run yío dàpọ̀ pẹ̀lú ti ayé, láti mú àwọn èrèdí nlá wọnnì wáyé; àti pé nígbàtí a bá darapọ̀ báyìí ninu iṣẹ́ àjùmọ̀ṣe kan, láti mú ìjọba Ọlọ́run tẹ̀síwájú, àwọn Oyè-àlùfáà ti ọ̀run kò ní jẹ́ aláìníṣẹ́ olùwòran.”

Nínú ọ̀rọ̀ kan tó jọra sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Bẹ́njámínì Johnson, Jósẹ́fù sọ pé, “Bẹ́njámínì, [bí mo bá kú] èmi kì yío jìnnà sí ọ, ati pé bí ó bá jẹ́ ní ẹ̀gbẹ́ kejì ìkelè, èmi [yío] sì máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú rẹ síbẹ̀, ati pẹ̀lú agbára tó ti lékún jọjọ, láti mú ìjọba yí tẹ̀síwájú.”

Ní Ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n Oṣù Kẹfà, 1844, Joseph Smith àti arákùnrin rẹ̀ Hyrum di pípa. Àgọ́ ara Jósẹ́fù di gbígbé sin, ṣùgbọ́n ẹ̀rí rẹ̀ tẹ̀síwájú láti máa fọhùn káàkiri ayé àti ninú ọkàn mi pé:

“Èmi ti rí ìran kan; mo mọ̀ ọ́, mo sì mọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ ọ́, èmi kò sì lè sẹ́ ẹ.”

“Èmi kò sọ fún yín rí pe mo jẹ́ pípé; ṣùgbọ́n kò sí àṣìṣe nínú àwọn ìfihàn tí mo ti kọ́ni.”

“Àwọn ìpìlẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì ti ẹ̀sìn wa ni ẹ̀rí àwọn Àpóstélì àti àwọn Wòlíì, nípa Jésù Krístì, pé Ó kú, a sín I, Ó sì tún jí ní ọjọ́ kẹ́ta, ó sì gòkè re ọ̀run; àti pé gbogbo àwọn nkan míràn tí ó jẹmọ́ ẹ̀sìn wa jẹ́ àwọn àfikún nìkan sí i.”

Ohun tí a sọ nípa Johanu onítẹ̀bọmi might also be said of Joseph Smith: “Ọkùnrin kan wà tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ [Joseph]. … Òun kọ́ ni Ìmọ́lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n a rán an láti jẹ́ ẹ̀rí nípa Ìmọ́lẹ̀ náà,” “pé kí gbogbo ènìyàn le gbàgbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.”

Mo gbàgbọ́. Mo gbàgbọ́ ó sì dámi lójú pé Jésù ni Krístì, Ọmọ Ọlọ́run alãyè. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run alààyè ni olùfẹ́ni Baba wa. Mo mọ èyí nítorípé ohùn Olúwa ti sọ ọ́ sí mi, bẹ́ẹ̀ sì ni ohùn àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ ti ṣe, àwọn àpóstélì ati àwọn wòlíì, pẹ̀lú àti ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Joseph Smith.

Mo jẹri pé Joseph smith jẹ́ ó sì njẹ́ wòlíì Ọlọ́run kan, ẹlẹ́rìí àti ìránṣẹ̀ kan ti Olúwa Jésù Krístì. Òun jẹ́ “alábùkún-fún láti ṣí àkókò iṣẹ ìríjú ìkẹhìn,” àwa sì jẹ́ alábùkún-fún pé ó ṣe bẹ́ẹ̀.

Olúwa pàṣe fún Oliver Cowdery pé, “Dúró ti ìránṣẹ́ mi Jósẹ́fù, pẹ̀lú òtítọ́.” Mo jẹ́ ẹ̀rí pe Olúwa ndúró ti ìránṣẹ́ Rẹ Jósẹ́fù ati Ìmupadà-bọ̀sípò náà ti a ṣe nípasẹ̀ rẹ̀.

Joseph Smith nísisìyí jẹ́ ara oyè-àlùfáà ti ọ̀run nípa èyítí ó sọ̀rọ̀ rẹ̀. Bí ó ti ṣèlérí fún ọ̀rẹ́ rẹ̀, òun kò jinnà síwa, ati pé ní ẹ̀gbẹ́ kejì ìkelè, ó ṣì nṣiṣẹ́ pẹ̀lú wa síbẹ̀, ati pẹ̀lú agbára tí ó ti lékún jọjọ, láti mú ìjọba yí tẹ̀síwájú. Pẹ̀lú ayọ̀ ati ìdúpẹ́, mo gbé ohùn mi sókè nínú “ìyìn sí ọkùnrin náà tó bá Jèhófàh sọ̀rọ̀.” Àti pé ní ìparí gbogbo rẹ̀, ìyìn sí Jèhófàh tó bá ọkùnrin náà sọ̀rọ̀! Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.