Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Káàbọ̀ sí Ìjọ Ayọ̀ náà
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


13:1

Ẹ Káàbọ̀ sí Ìjọ Ayọ̀ náà

Nítorí ìranipadà ayé àti iṣẹ́ ti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, a lè—a sì níláti—jẹ́ ènìyàn aláyọ̀ jùlọ ní orí ilẹ̀ ayé!

Mo ti jẹ́ ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn láti Àṣálẹ́ Kérésìmesì ti 1987, ó súnmọ́ ọdún mẹ́tàdínlógójì sẹ́hìn. Èyí jẹ́ ọjọ́ ìyanu nítòótọ́ nínú ayé mi àti ninu ìrìn-ajò ayérayé mi, mo sì fi dúpẹ́ jìnlẹ̀jinlẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n pèsè ọ̀nà ti wọ́n sì mú mi wá sí ibi awọn omi ti ìbí titun náà.

Bóyá irìbọmi rẹ jẹ́ ní àná tàbi awọn ọdún sẹ́hìn, bóyá ẹ npàdé ninu ilé Ìjọ nlá oní wọ́ọ̀dù púpọ̀, tàbí lábẹ́ àtíbàbà ewéko kan, bóyá ẹ ngba oúnjẹ Olúwa ní ìrántí Olùgbàlà ní Thai tàbí Swahili, mo fẹ́ láti sọ fún yín pé, ẹ káàbọ̀ sí ìjọ ayọ̀ náà! Ẹ káàbọ̀ sí ìjọ ayọ̀ náà!

Ìjọ Ayọ̀ náà

Nítorí ètò olùfẹ́ni ti Baba wa Ọ̀run fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Rẹ̀, àti nítorí ìranipadà ayé àti iṣẹ́ ti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, a lè—a sì níláti—jẹ́ ènìyàn aláyọ̀ jùlọ ní orí ilẹ̀ ayé! Àní bí awọn ìjì ayé ninu ayé tí ó nfi ìgbàkúgbà ní ìdààmú ti ngbá wa lára, a lè ṣe itọ́jú èrò orí ayọ̀ ati àlàáfíà àtinúwá tó ndàgbà tó sì npẹ́ nítorí ìrètí wa ninu Krístì ati òye wa ní ti ààyè tiwa ninu ètò ìdùnnú rírẹwà náà.

Àpóstélì Àgbà ti Olúwa, Ààrẹ Russell M. Nelson, ti sọ̀rọ̀ nípa ayọ̀ tí ó nwá láti inú ìgbesí ayé tí a fi Jésù Krístì sí ààrin gbùngbùn rẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ninu gbogbo ọ̀rọ̀ sísọ rẹ̀ láti ìgbà tí ó ti di Ààrẹ Ìjọ. Ó ṣe àròpọ̀ rẹ̀ ní kúkúrú tòbẹ́ẹ̀ pé: “Ayọ̀ nwá láti ọ̀dọ̀ àti nítorí Rẹ̀. … Fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, Jésù Krístì ni ayọ̀!”

Àwa jẹ́ ọmọ ìjọ ti Ìjọ Jésù Krístì. Àwa jẹ́ ọmọ ìjọ ti ìjọ ayọ̀ náà! Àti pé kò sí ibi tí ayọ̀ àwa bí ènìyàn kan ti le hànde ju ìgbàti a bá kórajọ papọ̀ ní ọjọ́ Ìsinmi kọ̀ọ̀kan ninu awọn ìpàdé oúnjẹ Olúwa láti sin Orísun gbogbo ayọ̀ náà! Níhin a npéjọ pẹ̀lú àwọn ẹbí wa ti wọ́ọ̀dù àti ẹ̀ka láti ṣe àjọyọ̀ àmì májẹ̀mú ti Oúnjẹ-Alẹ́ Olúwa, ìtúsílẹ̀ wa láti inú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, àti oore ọ̀fẹ́ tó lágbára ti Olùgbàlà! Níhin a wá láti ní ìrírí ayọ̀, ìsádi, ìdáríjì, ìdúpẹ́, ati jíjẹ́-ara-kan tí a nrí nípasẹ̀ Jésù Krístì!

Njẹ́ ẹ̀mí yi ti àjọyọ̀ papọ̀ ninu Krístì ni ohun tí ẹ rí? Njẹ́ èyí ni ohun tí ẹ mú wá bi? Bóyá ẹ nrò pé èyí kò ní ohun púpọ̀ láti ṣe pẹ̀lú yín, tàbí bóyá ó kàn ti mọ́ yín lára bi wọ́n ti nṣe àwọn nkan nígbà gbogbo. Ṣùgbọ́n gbogbo wa lè lọ́wọ́ nbẹ̀, ọjọ́ orí tàbí ìpè wa kò já mọ́ nkan, láti mú kí awọn ìpàdé oúnjẹ Olúwa wa ó jẹ́ kíkún-fún-ayọ̀, fífojú-sun-Krístì, wákàtí dáradára tí wọ́n le jẹ́, wíwà láàyè pẹ̀lú ẹ̀mí ìbọ̀wọ̀ aláyọ̀.

Ìbọ̀wọ̀ Aláyọ̀

Ìbọ̀wọ̀aláyọ̀ ? “Njẹ́ ohun kan ni èyí?” ẹ lè bèèrè. Ó dára, bẹ́ẹ̀ni, òun ni! A fẹ́ràn, bu ọlá, ati tẹríba fún Ọlọ́run wa jinlẹ̀, ọ̀wọ̀ wa sì nṣàn láti inú ọkàn tó nyọ̀ ninu ọ̀pọ̀ ìfẹ́, àánu, ati ìgbàlà ti Krístì!2 Ìbọ̀wọ̀ aláyọ̀ yí sí Olúwa gbọdọ̀ ṣe ìjúwe àwọn ìpàdé oúnjẹ Olúwa mímọ́ wa.

Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, ìbọ̀wọ̀ túmọ̀ sí èyí nìkan: kíká awọn ọwọ́ wa mọ́ àyà típẹ́típẹ́, títẹ orí wa ba, dídi ojú wa, kí a sì dúró jẹ́—láìlópin! Èyí lè jẹ́ ọ̀ná tó rannilọ́wọ́ láti kọ́ àwọn alágbára ọmọdé, ṣùgbọ́n bí a ti ndàgbà tí a sì nkọ́ ẹ̀kọ́, ẹ jẹ́kí a ríi pé ìbọ̀wọ̀ ju éyí lọ púpọ̀ síi gan-an. Njẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwa ó rí bí Olùgbàlà bá wà pẹ̀lú wa? Rárá, nítorí “ní ọ̀dọ̀ [Rẹ̀] ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ wà”!

Ó dára, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa àyípadà yí nínú àwọn ìsìn oúnjẹ Olúwa wa yío gba àṣetúnṣe.

Wíwà-níbẹ̀ dojúkọ Jíjọ́sìn

A kìí péjọ ní ọjọ́ Ìsinmi lásán láti wà ní ibi ìpàdé oúnjẹ Olúwa kí a sì máàkì rẹ̀ kúrò lórí àtòólẹ̀. A máa nwá papọ̀ láti jọ́sìn. Ìyàtọ̀ pàtàkì kan wà láàrin méjéèjì. Láti wà níbẹ̀ túmọ̀ sí láti jẹ́ àfojúrí ní ibìkan. Ṣùgbọ́n láti jọ́sìn jẹ́ láti fi tinútinú yìn kí a sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run wa ní ọ̀nà tí ó nyíwa padà!

Ní orí Pẹpẹ àti ninu Èrò Ìjọ

Bí a bá npéjọ ní ìrántí Olùgbàlà àti ìràpadà tí Ó ti mú kí ó ṣeéṣe, awọn ìwò ojú wa níláti ṣe àfihàn ayọ̀ àti ìmoore wa! Alàgbà F. Enzio Busche ti sọ ìtàn lẹ́ẹ̀kanrí nípa ìgbà tí òun jẹ́ ààrẹ ẹ̀ka kan tí ọmọdékùnrin kan ninu èrò ìjọ wo òun lórí pẹpẹ tí ó sì béèrè pẹ̀lú ariwo pe: “Kini ọkùnrin pẹ̀lú ìwò ojú ọ̀dájú yí nṣe ní òkè níbẹ̀?” Awọn tí wọ́n jókòó ní ibi pẹpẹ èyítí—àwọn olùsọ̀rọ̀, àwọn olùdarí, ẹgbẹ́ akọrin—ati awọn tí wọ́n péjọ ninu èrò ìjọ nbá ara wọn sọ “ẹ káàbọ̀ sí ìjọ aláyọ̀ yì” nípasẹ̀ awọn àfojúsọ tí wọ́n gbéwọ̀ sí ìwò ojú wọn!

Kíkọ Orin Ìsìn

Bí a ti nkọrin, njẹ́ a ndarapọ̀ láti yin Ọlọ́run àti Ọba wa, bí ó ti wù kí ohùn wa rí, tàbí njẹ́ a kan njẹ awọn ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu tàbí tí a kò kọrin bí? Ìwé mímọ́ ṣe àkọsílẹ̀ pé “orin awọn olódodo jẹ́ àdúrà sí [Ọlọ́run]” ninu èyítí ọkàn Rẹ̀ láyọ̀. Nítorínáà ẹ jẹ́kí a máa kọrin! Kí a sì máa yìn Ín!

Àwọn Ọ̀rọ̀ àti Àwọn Ẹ̀rí

A gbé awọn ọ̀rọ̀ àti ẹ̀rí wa lé orí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì àti awọn èso ti fífi ìrẹ̀lẹ̀ gbé ìgbésí ayé ìhìnrere Wọn, àwọn èso tí wọ́n jẹ́ “dídùn tayọ gbogbo ohun tí ó dùn.” Nígbànáa tí a ṣe “àpèjẹ nítòótọ́ … àní títí tí [awa] fi yó, tí ebi kò pa [wá] mọ́, bẹ́ẹ̀ni … òùngbẹ,” àti tí awọn ẹrù wa di fífúyẹ́ nípasẹ̀ ayọ̀ ti Ọmọ.

Oúnjẹ Olúwa Náà

Èrò inú ológo pàtàkì ti àwọn ìjọsìn wa ni bíbùkún àti gbígba oúnjẹ Olúwa fúnrarẹ̀, àkàrà àti omi náà tó ndúró fún ẹ̀bùn ìṣètùtù ti Olúwa wa àti gbogbo èrèdí ìpéjọpọ̀ wa. Èyí ni “ìgbà mímọ́ ti àtúnṣe ẹ̀mí” nígbàtí à njẹri ọ̀tun pé a nfẹ́ láti gbé orúkọ Jésù Krístì lé orí arawa kí a sì dá májẹ̀mú lẹ́ẹ̀kansi láti rántí Olùgbàlà nígbàgbogbo kí a sì pà àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.

Ní àwọn ìgbà kan ní ayé, a le gba oúnjẹ Olúwa pẹ̀lú ọkàn tó wúwo àti àwọn ẹrù tó pọ̀ púpọ̀. Ní awọn ìgbà míràn, a nwá ní òmìnira àti láìsí ẹrù ti àwọn àníyàn àti ìdààmú. Bí a ti nfi tinútinú fetísílẹ̀ sí ìbùkún ti àkàrà àti omi náà ti a sì ṣe àbápín ninu àwọn àmì mímọ́ wọnnì, a le ní ìmọ̀lára lati ronú lori ìrúbọ Olùgbàlà, awọn ìrora Rẹ̀ ní Gẹ́tsémánè, àròkàn Rẹ̀ ní orí àgbélébu, àti àwọn ẹ̀dùn ọkàn ati ìrora ti Ó faradà ní ìtìlẹhìn wa. Èyí ni yío jẹ́ ohun tí ó tu ọkàn wa lára bí a ti nso ìjìyà wa pọ̀ mọ́ Tirẹ̀. Ní àwọn àkókò míràn, a ó ní ìmọ̀lára láti ní ìyanu pẹ̀lu ìyàlẹ́nu ìmoore fún “ayọ̀ rírẹwà áti dídùn” nípa ohun tí ẹ̀bùn títóbi Jésù ti mú kí ó ṣeéṣe ninu ìgbé ayé wa àti ni awọn ayé àìlópin wa! A ó yọ̀ fún ohun tí ó ṣì nbọ̀wá—a nṣìkẹ́ ìdàpọ̀ pẹ̀lú àyànfẹ́ Baba àti olùjínde Olùgbàlà.

A lè ti fiwá sí ipo láti rò pé èrèdí oúnjẹ Olúwa ni láti jókòó ninu píù ki a sì ronú nípa gbogbo àwọn ọ̀nà tí a ti ṣe àṣìṣe nìkan ninú ọ̀sẹ̀ tó kọjá. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́kí á yí ìṣe náà sí orí rẹ̀. Nínú ìdákẹ́jẹ́ náà, a lè ṣe àròjinlẹ̀ lorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà tí a ti rí Olúwa tí nfi àìsinmi lé wa kiri pẹ̀lú ìfẹ́ yíyanilẹ́nu Rẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ náà! A le ronú lórí ohun tí ó túmọ̀ sí láti “ṣe àwárí ayọ̀ tó wà ninu ìrònúpìwàdà ojojúmọ́.” A lè dúpẹ́ fún awọn àkókò tí Olùgbàlà wọlé sínú awọn ìtiraka wa ati awọn ìṣẹ́gun wa ati awọn àkókò nígbàtí a ti ní ìmọ̀lára oore ọ̀fẹ́, ìdáríjì, ati agbára Rẹ̀ tí ó nfún wa ni okun lati borí awọn ìṣòro wa àní ki a sì gbé awọn ẹrù wa pẹ̀lú sũrù ati ọ̀yàyà.

Bẹ́ẹ̀ni, a nṣe àròjinlẹ̀ awọn ìjìyà ati àìṣe-òdodo tó ṣẹlẹ̀ sí Olùràpadà wa fún awọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí èyí sì nṣe àmúwá ìdorìkodò. Ṣùgbọ́n nígbàmíràn a máa nhá síbẹ̀—ninu ọgbà, ni ibi agbélèbú, ni inú isà-òkú. A nkùnà láti sún sókè si ayọ̀ bí isà-òkú ti di ṣíṣí sílẹ̀, ìjákulẹ̀ ti ikú, ati ìṣẹ́gun ti Krístì lórí gbogbo ohun tí ó le dí wa lọ́wọ́ ní gbígba àlàáfíà ati pípadà sí ilé wa ọ̀run. Bóyá a sun ẹkún ti ìkorò tàbí ẹkún ti ìmoore ní àkókò oúnjẹ Olúwa, ẹ jẹ́ kí ó jẹ́ ti ìyanu ọ̀wọ̀ fún ìròhìn rere ti ẹ̀bùn Baba nípa Ọmọ Rẹ̀!

Àwọn Òbí pẹ̀lú Àwọn Ọmọ Tí Wọ́n jẹ́ Ọ̀dọ́ tàbí Ní Àwọn Ìnílò Pàtàkì

Nísisìyí, fún àwọn òbí ti àwọn ọmọ tí wọ́n kéré tàbí ní àwọn ìnílò pàtàkì, kò nfi ìgbàkugbà sí irú nkan bẹ́ẹ̀ bíi àkókò ìdákẹ́jẹ́ àti ìrònú jẹ́jẹ́ ní ìgbà oúnjẹ Olúwa. Ṣùgbọ́n ní awọn àkókò kékeré ní ààrin ọ̀sẹ̀, nípa àpẹrẹ, ẹ lè kọ́ni ní ìfẹ́, ìmoore, ati ayọ̀ tí ẹ mọ̀lára fún ati lati ọ̀dọ̀ Olùgbàlà bí ẹ ti nfi léraléra ṣe ìtọ́jú fún awọn àgùtàn Rẹ̀ kékèké. Aápọn kankan kò ṣòfò ninu ìlépa yí. Ọlọ́run mọ̀ nípa yín.

Ẹbí, Wọ́ọ̀dù, àti àwọn ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka

Bíi ti ilé, a le bẹ̀rẹ̀ láti ṣe kóríyá àwọn ìrètí ati àfojúsọ́nà wa fún àkókò wa ní ilé ìjọsìn. Nínú awọn ìgbìmọ̀ ẹbí, a lè sọ̀rọ̀ lórí bí ẹnìkọ̀ọ̀kan ṣe lè lọ́wọ́ sí kíkí ẹni gbogbo káàbọ̀ si ìjọ ayọ̀ náà ní awọn ọ̀nà tó nítumọ̀. A lè ṣètò kí a sì fojúsọ́nà láti ní ìrírí aláyọ̀ ni ilé ìjọsìn.

Ìgbìmọ̀ wọ́ọ̀dù àti ẹ̀ka le ní ìrírsí kí wọn sì ṣẹ̀dá àṣà ọ̀wọ̀ aláyọ̀ kan fún wákàtí oúnjẹ Olúwa wa, ní ṣíṣe ìdámọ̀ àwọn ìgbésẹ̀ àmúlò ati awọn àmì aláwòrán láti ṣèrànwọ́.

Ayọ̀

Ayọ̀ máa nyàtọ̀ sí awọn ènìyàn tó yàtọ̀. Fún awọn kan, ó le jẹ̀ ìkíni ọlọ́yàyà ní ẹnu ọ̀nà. Fún awọn míràn, ó le jẹ́ fífi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ran awọn ènìyàn lọ́wọ́ ní ìmọ̀lára ìtura nípa rírẹ́rin músẹ́ àti jìjókòó ní ẹ̀gbẹ́ wọn pẹ̀lú ọkàn àánú ati tó ṣí sílẹ̀. Fún àwọn tí wọ́n nímọ̀lára pé a fiwọ́n sílẹ̀ ni etí ìlà, ọ̀yàyà ti ìkíni-kúàbọ̀ yí yío jẹ́ pàtàkì. Ní ìgbẹ̀hìn, a lè bi ara wa léèré bí Olùgbàlà yio ti fẹ́ ki wákàtí oúnjẹ Olúwa wa ó rí. Báwo ni Òun yio ti fẹ́ kí ọ̀kọ̀ọ̀kan awọn ọmọ Rẹ̀ ó jẹ́ kíkí káàbọ̀, ṣíṣe ìtọ́jú fún, bíbọ́, ati fífẹ́ràn? Báwo ni Òun yió ṣe fẹ́ kí a ní ìmọ̀lára nígbàtí a bá wá láti jẹ́ sísọ-dọ̀tun nípasẹ̀ rírántí àti jíjọ́sìn Rẹ̀?

Íparí

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ìgbàgbọ́ mi, ayọ̀ ninu Jésù Krístì ni àkọ́kọ́ àwárí nlá mi, ó sì yí ayé mi padà. Bí ẹ kò bá tíì ṣe àwárí ayọ̀ yí síbẹ̀, ẹ bẹ̀rẹ̀ ìwádi rẹ̀. Eyí ni ìpè láti gba ẹ̀bùn àlàáfíà, ìmọ́lẹ̀, ati ayọ̀ ti Olùgbàlà—láti ṣe àjọyọ̀ ninu rẹ̀, lati ní ìyanu nípa rẹ̀, ati lati yọ̀ ninu rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ Ìsinmi.

Ámọ́nì Nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì sọ awọn ìmọ̀lára inú ọkàn mi nígbàtí ó wípé:

“Nísisìyí njẹ́ àwa kò ha ní ìdí láti yọ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ni, èmi wí fún yín, kò tíì sí [awọn ènìyàn] rí láe tí wọ́n ní èrèdí nlá bẹ́ẹ̀ láti yọ̀ bí àwa, láti ìgbà tí ayé ti bẹ̀rẹ̀; bẹ́ẹ̀ni, ayọ̀ mi sì jẹ́ gbígbé lọ, àni sí yíyangàn nínú Ọlọ́run mi; nítorítí ó ní gbogbo agbára, gbogbo ọgbọ́n, àti gbogbo òye; ó ní òye ohun gbogbo, òun sì jẹ́ Ẹni alãnú, àní sí ìgbàlà, fún àwọn tí wọ́n bá ronúpìwàdà tí nwọ́n sì gba orúkọ rẹ̀ gbọ́.

“Nísisìyí bí èyí bá jẹ́ ìyangàn, àni bẹ̀ẹ̀ ni èmi yíò yangàn; nítorítí èyí ni ìyè mi àti ìmọ́lẹ̀ mi, … ayọ̀ mi, àti ìdúpẹ́ nlá mi.”

Ẹ káàbọ̀ sí ìjọ ayọ̀ náà! Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé “Ayọ̀ lágbára, àti pé fífi ojú sùn sórí ayọ̀ nmú agbára Ọlọ́run wá sínú ayé wa. “Bí ohun gbogbo, Jésù Krístì alápẹrẹ ìgbẹ̀hìn wa, ‘nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ̀, tí ó farada àgbélèbú’ [Hébérù 12:2]. Ronú nípa èyíinì! Ní èrò fún Un láti farada ìrírí olóró jùlọ tí a faradà rí nílẹ̀ ayé, Olùgbàlà wa dojúkọ ayọ̀! Ati pé kíni ayọ̀ náà tí a gbé kalẹ̀ níwájú Rẹ̀? Dájúdájú ó ní ayọ̀ ti ìwẹ̀nùmọ́, ìwòsàn, àti fífúnwa-lokun nínú; ayọ̀ sísan gbèsè fún awọn ẹ̀ṣẹ̀ ti gbogbo ẹni tí yíò ronúpìwàdà; ayọ̀ ti mímu ṣeéṣe fún ẹ̀yin àti èmi láti padà sílé—ní mímọ́ àti yíyẹ—láti gbé pẹ̀lú àwọn Òbí àti awọn ẹbí wa Ọ̀run. Bí a bá fojú sùn sórí ayọ̀ tí yíò wá sọ́dọ̀ wa, tàbí sí ọ̀dọ̀ àwọn tí a fẹ́ràn, kíni a lè faradà tí ó dàbí ohun tí ó lágbára, ronilára, bànilẹ́rù, tí kò dára, tàbí tí kò kàn ṣeéṣe lọ́wọ́lọ́wọ́?” (“Ayọ̀ àti Ìtúsílẹ̀ Ti Ẹ̀mí,” Lìàhónà, Oṣù Kọkànlá 2016, 82–83).

  2. Orin Dáfídì 16:11.

  3. F. Enzio Busche, “Àwọn Ẹ̀kọ́ láti ọwọ́ Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run,” Olùkọ́ni ti Ẹ̀sìn, vol. 9, no. 2 (2008), 3.

  4. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 25:12.

  5. Wo Orin Dáfídì 100:1.

  6. Álmà 32:42.

  7. Wo Álmà 33:23.

  8. Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 29.2.1.1, Ibi ìkàwé Ìhìnrere.

  9. Wo Russell M. Nelson, ìdánilẹ́kọ ti jíjẹ́ olùdarí mísọ̀n, Oṣù Kẹfà 2019; títúnsọ ninu Dale G. Renlund, “Ìfarajìn Àìyẹsẹ sí Jésù Krístì,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2019, 25.

  10. Gordon B. Hinckley kọ́ni pé: “Nígbàtí ìwọ, bíi àlùfáà kan, bá kúnlẹ̀ ní ibi tábìlì oúnjẹ Olúwa tí o sì gba àdúrà náà, èyítí ó wá nípa ìfihàn, o nfi gbogbo olùjọ́sìn sí abẹ́ májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa. Njẹ́ ohun kékeré kan ni eyí bi? Ó jẹ́ ohun kan pàtàkì àti tí ó lápẹrẹ jùlọ” (“Oyè-àlùfáà ti Áárọ́nì—Ẹ̀bùn kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,” Ensign, Oṣù Karun 1988, 46).

    Àwọn ti wọ́n npèsè, súre sí, tàbí pín oúnjẹ Olúwa nṣe ìpínfúnni ìlànà yí sí àwọn ẹlòmíràn ni ìtìlẹ́hìn Olúwa. Ẹnìkọ̀ọ̀kan ti ó di oyè-àlùfáà mú níláti ṣe iṣẹ́ rírán yí pẹ̀lú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ati ọ̀wọ̀. Ó níláti wà ní ìrísí dáradára, mímọ́, àti ìwọṣọ ní iwọ̀ntún-wọ̀nsì. Ìfarahàn ti araẹni níláti fi jíjẹ́ mímọ́ ìlànà hàn” (“Àwọn Ìlànà àti àwọn Ìbùkún Oyè-àlùfáà,” Ìwé Ìtọ́nisọ́nà Ẹbí [2006], 22).

  11. Álmà 36:21.

  12. Russell M. Nelson, “Agbára Ìwúrí ti Ẹ̀mí,” Lìàhónà, Oṣù Karun 2022, 98.

  13. Wo Mosiah 24:13–15..

  14. Wo Jòhánnù 3:16–17.

  15. Álmà 26:35–37.