Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Gbé Ìgbésí Ayé Tó Kájú Àwọn Ànfààní Yín
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


11:45

Ẹ Gbé Ìgbésí Ayé Tó Kájú Àwọn Ànfààní Yín

Ẹ kọ́ bi awọn ìlànà oyè-àlùfáà ati awọn ìlérí májẹ̀mú yio ṣe gba agbára Ọlọ́run láàyè láti ṣàn sinu ayé yín.

Láìpẹ́ yi ọkọ mi, Greg, gba àyẹ̀wò kan tí yío nílò iṣẹ́ abẹ ẹlẹgẹ́ àti oṣù mẹ́fa ìtọ́jú pẹ̀lú òògùn tó lágbára. Bíi ti púpọ̀ ninu yín tí ó ti dojúkọ ipò tó jọra, lọ́gán a bẹ̀rẹ̀sí gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ ti ọ̀run ati agbára Ọlọ́run. Ní Ọjọ́ Ìsinmi tó tẹ̀lé iṣẹ́ abẹ Greg, wọ́n mú oúnjẹ Olúwa wá sí yàrá wa ni ilé iwosan.

Ní akókò yí, emi nìkan ni mo ngba oúnjẹ Olúwa naa. Èrúnrún kan ti búrẹ́dì. Ife kan ti omi. Ni ilé ìjọsìn, iyè mi máa nfojúsùn sórí ètò ìpínfúnni ti oúnjẹ Olúwa—pípèsè, sísúre sí, áti pípín ká. Ṣùgbọ́n ní ọ̀sán ọjọ́ náà, mo ronújinlẹ̀ lórí ẹ̀bùn agbára Ọlọ́run to wà fúnwa nípasẹ̀ ìlànà mímọ́ náà fúnrarẹ̀ ati ìlérí májẹ̀mú ti mo nṣe bí mo ti nmú èérún búrẹ́dì ati ife omi náà. Èyí ni àkókò kan tí èmi nílò agbára láti ọ̀run. Ní ààrin ìrora ọkan nlá, àárẹ̀, ati iyèméjì, mo ronu nípa ẹ̀bùn yí tí yio gbàmi láàyè láti fà ninu agbára láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ tí mo nílò ní kiakia tóbẹ́ẹ̀. Kíkópa nínú oúnjẹ Olúwa yío fikún jíjẹ́ ojúgbà mi pẹ̀lú Ẹ̀mí Olúwa, tí yío fúnmi ní àyè láti fà ninu ẹ̀bùn agbára Ọlọ́run, pẹ̀lú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti àwọn ángẹ́lì ati okun ìrólágbára ti Olùgbàlà láti borí.

Emi kò rò pé mo ti mọ̀ pẹ̀lu òye kedere púpọ̀ báyí ṣáajú pé kìí ṣe ẹni tó nṣe iṣẹ́ ninu ìlànà náà ló jámọ́ nkan—ju ohun tí ìlànà náà àti májẹ̀mú wa ṣ̣e ìlérí láti ṣí tí ó sì yẹ fún ìdojúkọ ti àkíyèsí wa bákannáà. Àwọn ìlànà oyè-àlùfáà àti pípa àwọn ìlérí májẹ̀mú mọ́ nfún Ọlọ́run láàyè láti yà wá sí mímọ́ kí Ó sì ṣe àwọn ìyanu ninu ayé wa. Ṣùgbọ́n báwo ni èyí ti nṣẹlẹ̀?

Ìkínni, fún ìlànà kan láti fi agbára Ọlọ́run hàn ninu ayé wa, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ṣíṣe pẹ̀lú àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Ọmọ Ọlọ́run. Ètò ìfunni ṣe pàtàkì. Baba gbẹ́kẹ̀lé Jésù Krístì pẹ̀lú awọn kọ́kọ́rọ́ ati àṣẹ láti mójútó ìfúnni ti awọn ìlànà oyè-àlùfáà Rẹ̀. Ní abẹ́ ìdarí Rẹ̀, láàrin ètò ti oyè-àlùfáà Rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin Ọlọ́run ti jẹ́ yíyàn láti dúró ní ààyè ti Ọmọ Ọlọ́run náà.

Ìkejì, a kìí kan ṣe àwọn ilérí májẹ̀mú—a gbọ́dọ̀ pa wọ́n mọ́. Ninu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlànà ìhìnrere, a ndá àwọn májẹ̀mú mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run; Ó nṣèlérí láti bùkún wa bí a ti npa àwọn májẹ̀mú wọnnì mọ́. Njẹ́ a ríi pé àpapọ̀ àwọn ìlànà oyè-àlùfáà pẹ̀lú pípa àwọn ilérí májẹ̀mú mọ́ ni ó nfún wa láàyè láti gbà ninu agbára Ọlọ́run?

Ní ọ̀sán ọjọ́ náà mo ròó bí èmi, ọmọbìnrin májẹ̀mú Ọlọ́run, bá ní òye kíkún nípa bí mo ṣe le ní àyè sí ẹ̀bùn agbára Ọlọ́run nípasẹ̀ awọn ìlànà oyè-àlùfáà ati bí mo bá mọ̀ pé agbára Ọlọ́run nṣiṣẹ́ ninu mi.

Ní 2019 ìpè ti wòlíì kan jẹ́ níná si awa obìnrin Ìjọ, tí ó nkọ́ wa bí a ti le fa agbára Olùgbàlà sínú ayé wa. Ààrẹ Russell M. Nelson pè wá láti ṣe àṣàrò Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 25, ìfihàn kan tí a fifún Emma Smith ní Harmony, Pennsylẹania. Títẹ́wọ́gba ìfipè náà yí ìgbé ayé mi padà.

Ní oṣù tó kọjá mo ní ànfáání àìròtẹ́lẹ̀ kan lati ṣe ibẹ̀wò sí Harmony. Níbẹ, ní abẹ́ awọn igi mápù, a mú oyè-àlùfáà padàbọ̀sípò fún Joseph Smith ati Oliẹer Cowdery. Súnmọ́ àwọn igi wọnnì ni ilẹ̀kùn iwáju ilé Jósẹ́fù ati Emma. Ní odìkejì láti ibi ìdáná ninu ilé náà ni fèrèsé kan wà. Mo dúró ní ibi fèrèsé náà mo sì ronú ohun ti Emma le ti rò bí ó ti wo ìta kọjá àwọn igi náà.

Ní Oṣù Keje 1830, Emma jẹ́ ẹni ọdún 26; ó jẹ́ ọ̀dọ́ tóbẹ́ẹ̀. Ó ti pé ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ ninu ìgbeyàwó rẹ̀. Ó ti pàdánù ọmọdékùnrin kan—àkọ́kọ́ rẹ̀. Itẹ́ rẹ̀ kékeré kàn wà ní ìsàlẹ̀ ópópóná láti ilé rẹ̀. Ní dídúró ní ibi fèrèsé náà, ko nira fùnmi lati fi ojú-inu wo ohun tí ó le ti kún inú áwọn èrò ọkàn rẹ̀. Dájúdájú ó ṣàníyàn nípa awọn ìsúná wọn, nípa àlékún inúnibíni tó ndẹ́rùba ààbò wọn, nípa ọjọ́ iwájú wọn. Àti síbẹ̀, iṣẹ́ Ọlọ́run wà níbigbogbo ní àyíká rẹ̀. Njẹ́ ó ronú bákannáà nípa ipò rẹ̀ ninu ètò náà, èrèdí rẹ̀ ninu ìjọba Rẹ̀, àti agbára-ìleṣe rẹ̀ ni ojú Ọlọ́run?

Mo rò pé ó le ti ṣe bẹ́ẹ̀.

Ní ìsọdá ọ̀nà lásán, ẹ̀bùn aṣẹ oyè-àlùfáà ti Ọlọ́run ati awọn kọ́kọ́rọ́ ni a ti múpadàbọ̀sípò ní ilẹ̀ ayé. Èyí ni àkókò kan tí Emma nílò agbára láti ọ̀run nítòótọ́. Ní ààrin ìrora ọkan nlá, àárẹ̀, ati iyèméjì, mo fi ojú-inu wo bi Emma ti ronú nípa ẹ̀bùn oyè-àlùfáà ti Ọlọ́run yí tí ó le ṣí agbára láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ tí ó nílò ní kiakia tóbẹ́ẹ̀.

Sùgbọ́n Emma kò kàn dúró sí ibi fèrèsé náà kí o sì máa ronú.

Nígbàti Wòlíì Jósẹ́fù ngba ìkọ́ni ninu a`wọn kọ́kọ̀rọ́, àwọn ipò iṣẹ́, àwọn ìlànà ati bí yío ti ṣe àtilẹ́hìn ninu iṣẹ́-ìsìn ti oyè-àlùfáà, Olúwa Fúnrarẹ̀, nípasẹ̀ wòlíì Rẹ̀, fi ìfihàn kan fún Emma. Kìi ṣe Ààrẹ-Emma-Ẹgbẹ́-Ìrànlọ́wọ́-Nauvoo—ìfihàn yí ni a fún ẹni-ọdún-26 Emma ní Harmony. Nípasẹ̀ ìfihàn, Emma yío kọ́ nípa ìsọdi-mímọ́ ti inú àti àsopọ̀ májẹ̀mú tí yío ṣe àfikún agbàra àwọn ìlànà oyè-àlùfáà wọnnì láti ṣiṣẹ́ ninu ayé rẹ̀.

Ìkínní, Olúwa rán Emma létí ààyè rẹ̀ ninu ètò Rẹ̀, pẹ̀lú ẹni tó jẹ́ àti ti ẹni tí í ṣe—ọmọbìnrin ninu ìjọba Rẹ̀. A pè é láti “rin nínú àwọn ipa ìwà rere,” ipa kan ti ó ní àwọn ìlànà nínú tí yío ṣí agbára Ọlọ́run bí Emma bá di àwọn májẹ̀mú rẹ̀ mú.

Èkejì, ni igbà síṣe ọ̀fọ̀ rẹ̀ tó jinlẹ̀, Olúwa fún un ní èrèdí. Emma kò kàn ní ìjokòó apá iwájú sí Ìmúpadà bọ̀sípò náà; ó jẹ́ olùkópa pàtàkì ninu iṣẹ́ tó nṣẹlẹ̀ náà. Òun yio jẹ́ yíyà sọ́tọ̀ “láti ṣe àsọyé àwọn ìwé mímọ́, àti láti gba ìjọ níyànjú.” Àkókò rẹ̀ ni yio “jẹ́ fífi fún ìwé kíkọ, àti sí ẹ̀kọ́ kíkọ́ púpọ̀.” Emma ni a fún ni ipa mímọ́ kan láti ṣèrànwọ́ múra àwọn ènìyàn mímọ́ sílẹ̀ láti jọ́sìn; àwọn orin wọn sí Olúwa yio jẹ́ gbígbà bíi àdúrà yio sì “jẹ́ dídáhùn pẹ̀lú ìbùkún kan lé ori wọn.”

Ní ìparí, Olúwa ṣe àgbékalẹ̀ ìlànà kan fún ìsọdi-mímọ́ ti inú tí yio pèsè Emma sílẹ fún ìgbéga. “Bíkòṣepé ìwọ ṣe èyí,” Olúwa ṣàlàyé fún un, “nibití èmi wà ìwọ kò le wá.”

Bí a bá ka ìpín 25 dáradára, a rí ìlọsíwájú pàtàkì kan tí ó nṣẹlẹ̀. Emma yio lọ láti jíjẹ́ ọmọbìnrin kan ninu ìjọba náà sí “àyànfẹ́ ọmọbìnrin” sí ayaba. Àwọn ìlànà Oyè Àlùfáà Áárónì àti ti Melkísédékì papọ̀ pẹ̀lú pípa àwọn ìlérí májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ yio fi kún ìbákẹ́gbẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú Ẹ̀mí àti pẹ̀lú àwọn ángẹ́lì, ní ríró o lágbára láti darí ayé rẹ̀ pẹ̀lú ìtọ́ni àtọ̀runwá. Nípasẹ̀ agbára àtọ̀runwá Rẹ̀, Ọlọ́run yio wo ọkàn rẹ̀ sàn, sọ agbára rẹ̀ di nlá, yio sì yí i padà sí ẹ̀dà ti ara rẹ̀ ti Ó mọ̀ pé ó le dà. Ati nípasẹ̀ àwọn ìlànà ti Oyè Àlùfáà Melkísédékì, “agbára ti ìwà-bí-Ọlọ́run [yio jẹ́] fífihàn” ninu ayé rẹ̀, Olúwa yio sì pín ìkelè níyà kí ó lè gba òye láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Èyí ni bí ó ti rí fún agbára Ọlọ́run láti ṣiṣẹ́ nínú wa.

Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé:

Ohun gbogbo tó ṣẹlẹ̀ ní Harmony ní ìjìnlẹ̀ àyọrísí fún ìgbé ayé yín Ìmúpadàbọ̀sípò oyè-àlùfáà, lẹgbẹ pẹ̀lú ìmọ̀ràn Olúwa sí Emma, lè tọ́nisọ́nà kí ó sì bùkún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín. …

“… Níní ààyè sí agbàra Ọlọ́run nínú ayé yín nfẹ́ àwọn ohun kannáà tí Olúwa pàṣẹ fún Emma àti ẹnìkọ̀ọ̀kan [wa] láti ṣe.”

Àwọn nkan pàtàkì wà to nṣẹlẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ méjéèjì ti fèrèsé náà ni Harmony, pẹ̀lú ìfihàn tí a fifún àyànfẹ́ ọmọbìnrin náà ẹnití Olúwa ti pè—ìfihàn kan ti yio fún lókun, gbà á níyànjú, tí yio sì kọ́ Emma Smith, ọmọbìnrin Ọlọ́run lẹkọ.

Nígbàti a fún ọmọbìnrin-ọmọ wa Isabelle ni orúkọ kan àti ìbùkún, baba rẹ̀ súre fún un pẹ̀lú níní ìmọ̀ ti oyè-àlùfáà; pé òun yio tẹ̀síwájú láti máa dàgbà ninu àti láti kọ́ nipa ìbùkún tí yio pèsè ninu ayé rẹ̀; àti pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ninu oyè-àlùfáà yio dàgbà bí o ti tẹ̀síwájú láti dàgbà ninu ìmọ̀.

Kìí ṣe ìgbà gbogbo ni ọmọdébìnrin máa njẹ́ sísúre fún láti ní ìmọ̀ oyè-àlùfáà ati làti kọ́ bí awọn ìlànà ti oyè-àlùfáà náà ati awọn ìlérí májẹ̀mú yio ṣe ràn án lọ́wọ́ láti ní àyè sí agbára Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n mo rántí Emma mo sì ronú sí ara mi, Kínni ṣe tí kò rí bẹ́ẹ̀? Ọmọbìnrin kékeré yí ní agbára ìleṣe láti di àyànfẹ́ ọmọbìnrin kan ní ìjọba Rẹ̀ àti ayaba kan ní ìgbẹ̀hìn. Nípasẹ̀ awọn ìlànà oyè-àlùfáà Rẹ̀ ati pípamọ́ ti awọn ìlérí májẹ̀mú rẹ̀, agbára Ọlọ́run yio ṣiṣẹ́ ninu ati nípasẹ̀ rẹ̀ láti ràn án lọ́wọ́ borí ohunkóhun ti ayé le múwá kí o si di obìnrin tí Ọlọ́run mọ̀ pé o le dà. Èyí ni ohun tí mo fẹ́ kí ọ̀kọ̀ọ̀kan ọmọbìnrin ninu ijọba ní ìmọ̀ rẹ̀.

“Ẹ Gbé Ìgbésí Ayé Tó Kajú Àwọn Ànfààní Yín.”

Ẹ kọ́ bi awọn ìlànà oyè-àlùfáà ati awọn ìlérí májẹ̀mú yio ṣe gba agbára Ọlọ́run láàyè láti ṣàn sinu ayé yín pẹ̀lu ìwúlò gígajù, tí yio ṣiṣẹ́ ninu ati nípasẹ̀ yín, ní ríró yín lágbára ati mimúrasilẹ̀ fún yín láti dé ibi èrèdí ati agbára ìleṣe yín ní kíkún.

Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ṣe aṣàrò kí ẹ sì ronújinlẹ̀ lórí awọn ìlànà Oyè Àlùfáà Áárónì ati ti Melkísédékì, awọn ìlérí májẹ̀mú tí a nṣe pẹ̀lú ìkọ̀ọ̀kan, ati agbára Ọlọ́run ti a nní aayè sí nípasẹ́ awọn ìlànà wọnnì.

Ẹ rántí, kìí ṣe ẹni tó ṣe iṣẹ́ ninu ìlànà náà ló jámọ́ nkan; ju ohun tí ìlànà náà àti májẹ̀mú àti ìlérí májẹ̀mú tiyín nṣí sílẹ̀ tí ó yẹ fún ìdojúkọ ti àkíyèsí yín bákannáà.

Kíkópa ninu búrẹ́dì ati omi jẹ́ ìránnilétí ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti agbára Rẹ tó nṣiṣẹ́ ninu yín lati ràn yín lọ́wọ́ bori. Wíwọ ẹ̀wù ti oyè-àlùfáà mímọ́ jẹ́ ìránnilétí ojoojúmọ́ ti ẹ̀bùn agbára Rẹ̀ tó nṣiṣẹ́ ninu yín láti ràn yín lọ́wọ́ di rere.

Gbogbo wa ní ààyè sí ẹ̀bùn agbára Ọlọ́run.

Ní gbogbo àkókò tí a bá nkópa nínú oúnjẹ Oluwa.

Ní gbogbo àkókò tí a bá nkọjá ní ẹnu ọ̀nà tẹ́mpìlì kan.

Èyí ni kókó Ọjọ́ Ìsinmi mi. Èyí ni ìdí tí mo fi fẹ́ràn ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì mi.

“Nínú awọn ìlànà ibẹ̀, agbára ìwà-bí-Ọlọ́run nfarahàn.”

Nípa ẹ̀bùn yí ni mo jẹ́ ẹ̀rí ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 107:20.

  2. Alàgbà D. Todd Christofferson kọ́ni pé: “Nínú gbogbo awọn ìlànà, nípàtàkì awọn ti tẹ́mpìlì, a nbùkún wa pẹ̀lú alàgbà láti oke wá. ‘Agbára ìwà-bí-Ọlọ́run’ yí nwá ninu ẹni náà ati nípasẹ̀ ipá ti Ẹ̀mí Mímọ́. … Mo jẹ́ri pé Ọlọ́run yio pa awọn ìlérí Rẹ̀ sí yín mọ́ bí ẹ̀yin ti nbu ọlá fún àwọn májẹ̀mú yín pẹ̀lú Rẹ̀. … Òun yio, nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ̀, kún yín pẹ̀lú agbára ìwà-bi-ọlọ́run” (”Agbára ti Awọn Májẹ̀mú Náà,” Làìhónà, Oṣù Karun 2009, 22, 23).

  3. Wo Dallin H. Oaks, “Oyè Àlùfáà Árọ́nì àti Oúnjẹ Olúwa,” Làìhónà, Oṣù Kínní 1999, 45.

  4. “Gbogbo ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n nkópa nínú àwọn ìlànà oyè-àlùfáà àti tí wọ́n ndá tí wọ́n sì npa àwọn májẹ̀mú mọ pẹ̀lú Ọlọ́run ní ààyè tààrà sí agbára Ọlọ́run.” (Russell M. Nelson, “Májẹ̀mú Àìlópin Náà,” Làìhónà, Oṣù Kẹwàá 2022, 10).

  5. Wo Jóṣúà 3:5, , footnote a. Alàgbà Dale G. Renlund ṣe àlàyé: “Tnípasẹ̀ májẹ̀mú wọ̀nyí, a ní àyè sí agbára [ti Olúwa] . Láti hàn kedere, àwọn májẹ̀mú ìrìbọmi àti tẹ́mpìlì kìí ṣe, orísun agbára nínú àti nípa ara wọn. Orísun agbára ni Olúwa Jésù Krístì àti Baba wa Ọ̀run. Dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ ndá ọ̀nà sílẹ̀ fún agbára Wọn nínú ayé wa. (“Ẹ̀kọ́ Alágbára, Agbo Ìwàrere ti Krístì,” Liahona, May 2024, 82.)

  6. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 107:1–3; Ìyírọ̀padà ti Joseph Smith, Hébérù 7:3 (ninu àlẹ̀mọ́ Bíbélì); Álmà 13:2,16. Ààrẹ Dallin H. Oaks kọ́ni pé: “Láti inú àwọn ìwé mímọ́ a mọ̀ bákannáà pé awọn ti wọn ṣe iṣẹ́ ipò ninu oyè-àlùfáà ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìdúró-fún Olúwa (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 1:38; 36:2). Èmi yio dábàá nisisìyí bí àwọn olùkọ́ni àti àwọn àlùfáà àti àwọn díákónì ti níláti ṣe àwọn ojúṣe mímọ́ wọn láti ṣiṣẹ́ ní ìdúró-fún Olúwa ní pípèsè, sísúre-sí, àti pípín oúnjẹ Olúwa” (“Oyè Àlùfáà Áárónì àti Oúnjẹ Olúwa,” Làìhónà, Oṣù Kínní 1999, 45).

  7. Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 3.5.1-2, Ibi ìkàwé Ìhìnrere.

  8. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 107:18–20; Fílípì 1:6.

  9. Russell M. Nelson, “Àwọn Ìṣúra ti Ẹ̀mí,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2019, 77.

  10. Wo “Ilé Joseph ati Emma Smith” (history.ChurchofJesusChrist.org) fún àlàyé díẹ̀ sìi nípa àtúntẹ̀ ti Ilé Smith ni ibi ìtàn Ìjọ ní Harmony, Pennsylvania.

  11. Àṣ̣ẹ àti awọn kọ́kọ́rọ́ ti oyè-àlùfáà nígbànáà yio fi aaye gba agbára Ọlọ́run láti ṣàn sínú ayé awọn tí wọ́n gba awọn ìlànà oyè-àlùfáà tí wọ́n dá tí wọ́n sì ṣe ìpamọ́ awọn májẹ̀mú tó rọ̀ mọ́ọ (wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 3.5, Ibi Ìkàwé Ìhìnrere).

  12. Wo Joseph Smith—Ìtàn 1:71, àkíyèsí ránpẹ́.

  13. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 25.

  14. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 25:1.

  15. Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 25:2.

  16. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 25:13 “Ọ̀rọ̀ náà májẹ̀mú jẹ́ ti Latin ní ìṣẹ̀da, con venire,, àti bí ó ti rí gan-an ti ó túmọ̀ sí ‘wíwá papọ̀.’ Ninu awọn ọ̀rọ̀ pàtàkì ti oyè-àlùfáà, ‘májẹ̀mú’ ni wíwá papọ̀ tàbí àdéhùn kan láàrin Ọlọ́run ati ènìyàn. Ó ronú-ṣíwájú pé Ọlọ́run ati ènìyàn wá papọ̀ láti ṣe àdéhùn kan, láti gbà lórí àwọn ìlérí, àlàkalẹ̀, ànfààní, ati awọn ojúṣe. …

    “Májẹ̀mú tí a bá ṣe ni ọ́ná yí jẹ́ àìlè-takò ati àìlè-yípadà. Ó ngbé ẹ̀mí ró, ó nṣẹ̀dá ìpìlẹ̀ tó dúró ṣinṣin ati tó dájú fún awọn ìrètí ọjọ́ iwájú” (Dale G. Renlund and Ruth Lybbert Renlund, Oyèàlùfáà Melchizedek: Níní òye Ẹ̀kọ́ náà, Gbígbé Àwọn Ìpìlẹ̀ Ẹ̀kọ́ náà [2018], 60).

  17. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 25:7.

  18. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 25:8.

  19. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 25:12,

  20. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn májẹ̀mú 25:15.

  21. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 25:15. Ààrẹ Dallin H. Oaks kọ́ni pé: “Ìlànà ìrìbọmi àti àwọn májẹ̀mu tí ó rọ̀ mọ́ ọ jẹ́ awọn àmúyẹ fún wíwọlé sí inu ìjọba sẹ̀lẹ́stíà. Àwọn ìlànà tẹ́mpìlì àti àwọn májẹ̀mu tí ó rọ̀ mọ́ wọn jẹ́ awọn àmúyẹ fún ìgbéga ní ìjọba sẹ̀lẹ́stíà, èyítí í ṣe iyè ayérayé, ‘èyítí ó tóbi jùlọ nínú gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run.’ [Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 14:7]” (“Àwọn Májẹ̀mú ati Àwọn Ojúṣe,” Làìhónà, Oṣù Karun 2024, 96).

  22. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 25:1.

  23. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 25:3.

  24. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn májẹ̀mú 25:15.

  25. Dallin H. Oaks, “Oyè Àlùfáà Árọ́nì àti Oúnjẹ Olúwa; Làìhónà, Oṣù Kínní 1999, 44–45. Ààrẹ Oaks kọ́ni pé:

    “Ní ọ̀nà kan tó súnmọ́ra gidi, àwọn ìlànà Oyè Àlùfáà Áárónì wọ̀nyí bákannáà jẹ́ kókó sí iṣẹ́-ìránṣẹ́ ti àwọn ángẹ́lì. …

    “… Àwọn ọ̀rọ̀ bíi ti ángẹ́lì le jẹ́ fífúnni nípa ohùn, tàbí nipa àwọn èrò ọkàn, tàbí ìmọ̀lára lásán ní sísọ sí iyè-inú” (“Oyè Àlùfáà Áárónì ati ounjẹ Olúwa,” Làìhónà, Oṣù Kínní 1999, 44, 45).

    Ní àfikún, Wòlíì Joseph Smith fi ìlérí yí fún a`wọn arábìnrin Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́: “Bí ẹ bá gbé ìgbé ayé kájú àyè àwọn ànfàní yín, a kò lè dẹ́kun àwọn ángẹ́lì ní jíjẹ́ alabárìn yín” (Àwọn Ìkọ́ni Ààrẹ Ìjọ : Joseph Smith [2011], 454).

  26. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 84:19–20.

  27. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 107:18–19.

  28. Russell M. Nelson, “Àwọn Ìṣúra ti ẹ̀mí,” 77. “Willard Richards reported: ‘Ààrẹ Joseph Smith ka ìfihàn ti a [fifún] Emma Smith … ó sì sọ pé … kìí ṣe òun nìkán, ṣùgbọ́n àwọn míràn, le yege sí àwọn ìbùkún kannáà’” (Àwọn Ìkọ́ni ti Àwọn Ààrẹ Ìjọ: Joseph Smith, 453–54). Bákannáà wo Ìwé Ìròhìn Ìpàdé Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ti Nauvoo, 17 Oṣù Kẹta, 1842, Àádọ́ta Ọdún Àkọ́kọ́ ti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́: Àwọn Ìwé Pàtàkì nínú Ìtàn ti Àwọn Obìnrin Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn (2016), 1.2.1, churchhistorianspress.org.

  29. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 24, àkọlé ìpín. Èyí sọ pé “àwọn ìfihàn mẹ́ta tó tẹ̀lé yí ni a fifúnni ní àkókò yí láti fún lókun, gbà-níyànjú, àti kọ́ ní ẹ̀kọ́.”

  30. Àwọn Ìkọ́ni: Joseph Smith, 454.

  31. Wo Russell M. Nelson, “Àwọn Ìṣúra ti ẹ̀mí,” 77. “Mo rọ̀ yín láti fi pẹ̀lú àdúrà ṣàṣàrò gbogbo òtítọ́ tí ẹ lè rí nípa agbára oyèàlùfáà. Ẹ lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú àwọn ìpín 84 àti 107. Àwọn ìpín wọnnì yíò darí yín sí àwọn ẹsẹ míràn. Àwọn ìwé mímọ́ àti awọn ìkọ́ni látọ̀dọ̀ àwọn wòlíì òde òní, àwọn aríran, àti àwọn olùfihàn kún fún àwọn òtítọ́ wọ̀nyí. Bí ìmọ̀ yín ṣe npọ̀ si àti bí ẹ ṣe nlo ìgbàgbọ́ yín nínú Olúwa àti agbára oyè-àlùfáà Rẹ̀, okun yín láti fa ìṣura ti ẹ̀mí tí Olúwa ti pèsèsílẹ̀ yíò pọ̀ si.” (Russell M. Nelson, “Àwọn Ìṣúra ti ẹ̀mí,” 79).

  32. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 109:22.

  33. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 84:20.