Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Sísopọ̀ Mọ́ Jésù Krístì: Dídi Iyọ̀ Ayé
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


10:49

Sísopọ̀ Mọ́ Jésù Krístì: Dídi Iyọ̀ Ayé

Bí a ṣe ndúró ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa, ìgbésí ayé wa yóò fi ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ hàn níti ẹ̀dá, a ó sì di iyọ̀ ti ayé.

Olùgbàlà kọ́ni pé nígbàtí a bá “pè wá sínú ìhìnrere àìnípẹ̀kun [Rẹ̀], tí a sì ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú májẹ̀mú àìnípẹ̀kun, [àwa] ni a kà sí bíi iyọ̀ ilẹ̀ ayé.” Iyọ̀ jẹ́ àwọn èròjà méjì tí a so pọ̀. A kò lè jẹ́ iyọ̀ fúnra ara wa; bí a bá fẹ́ jẹ́ iyọ̀ ti ayé, a gbọ́dọ̀ di sísopọ̀ pẹ̀lú Olúwa, ohun tí mo sì rí nìyí bí mo ti ndàpọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ìjọ kárí ayé—àwọn ọmọ ìjọ olóotọ́ tí wọ́n so mọ́ Olúwa, tí wọ́n fi ara wọn lélẹ̀ nínú akitiyan wọn láti sin àwọn ẹlòmíràn àti jíjẹ́ iyọ̀ ayé.

Ìyàsímímọ́ rẹ tí kì í yẹ̀ jẹ́ àpẹrẹ dídán. Ìsìn rẹ jẹ̀ ohun tí a mọ rírì àti tí a ṣìkẹ́.

Àwọn ọ̀dọ́ wa ti fi ìgboyà àti ìfọkànsìn tó lápẹrẹ hàn. Wọ́n ti fi ìtara tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìtàn ẹbí, àti ìbẹ̀wò wọn déédéé sí ilé Olúwa jẹ́ ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn. Ìfẹ́ wọn láti ya àkókò sọ́tọ̀ láti sìn iṣẹ́-ìránṣẹ́ jákèjádò àgbáyé ṣe àfihàn ìgbàgbọ́ jíjinlẹ̀ àti tí ó dúró ṣinṣin. Kìí ṣe pé wọ́n kópa lásán ṣùgbọ́n wọ́n ndarí ọ̀nà dídi ọmọẹ̀hìn tó so mọ́ Jésù Krístì. Iṣẹ́ ìsìn wọn tan ìmọ́lẹ̀ àti ìrètí, tí ó kan àwọn ẹ̀mí àìlónkà. Síi yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́ ti Ìjọ, a fi ìdúpẹ́ àtọkànwá hàn fún iṣẹ́ ìsìn ìmísí yín. Ẹ̀yin kìí ṣe ọjọ́ ọ̀la ti ìjọ nìkan ṣùgbọ́n tirẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́. Nítòòtọ́ ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé!

Mo ní ìfẹ́ Olúwa Jésù Krístì mo sì ní ìmọ̀lára ìbùkún nípa ànfàní láti sìn lẹ́gbẹ pẹ̀lú yín nínú Ìjọ Olúwa. Ìṣọ̀kan àti okun wa, tí a gbé kalẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ tí a ṣe alábapín, fidá wa lójú pé a kò dá wà nínú ìrìn àjò yí. Lákopọ̀, a le tẹ̀síwájú láti kọ́ ìjọba Ọlọ́run, ní sísopọ̀ nínú iṣẹ́-ìsìn, ìfẹ́, àti ìgbàgbọ́ tí kò ṣiyèméjì.

Nígbàtí Jésù Krístì kọ́ni létí òkun Gálílì, Ó sáábà máa nlo àwọn ohun tó wà lójójúmọ́ tí àwọn olùgbọ́ rẹ́ mọ̀ láti ṣàlàyé àwọn ìjìnlẹ̀ òtítọ́ ti ẹ̀mí. Ọ̀kan irú èròjà bẹ́ẹ̀ jẹ́ iyọ̀. Jésù kéde pé, “[Ẹ̀yin] ni iyọ̀ ayé,” gbólóhùn kan tó nítumọ̀ gan tí ó sì jẹ́ pàtàkì, pàápàá jùlọ fún àwọn ènìyàn ìgbà Tirẹ̀ tí wọn lóye bí iyọ̀ ti níye lórí tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà.

Iṣẹ́ ọnà ìgbàanì ti ìkórè iyọ̀ ní Algarve, ẹkùn gúúsù orílẹ̀-èdè mi ní Portugal, ti bẹ̀rẹ̀ láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ní sànmánì Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Pẹ̀lú ìyàlẹ́nu, àwọn ọ̀nà tí àwọn òṣìṣẹ́ iyọ̀ lò, tí à mọ̀ bí márnótósì, ti yípadà díẹ̀ láti ìgbà náà. Àwọn olùfarajì òṣìṣẹ́ ọnà wọ̀nyí nlo àwọn ọgbọ́n ọ̀nà ìbílẹ̀, tí wọ́n nfi ọwọ́ ṣe iṣẹ́ wọn pátápátá, tí wọ́n npa ogún kan mọ́ tí ó ti fara dàá jálẹ̀ àwọn sẹ́ntíúrì.

Ọ̀nà ìgbàanì yi nkórè ohun tí wọ́n pè ní “òdòdó iyọ̀.” Láti mọ rírì ìlànà ìnira ti kíkórè òdòdó iyọ̀ náà ní kíkún, ó ṣe pàtàkì láti lóye ibi tí a ti ṣé jáde. Iyọ̀ etí òkun ti Algarve’s pèsè àwọn ipò tí ó dára jùlọ fún ṣíṣe iyọ̀. Omi òkun jẹ́ dídarí sí inú àwọn adágún tí kò jìn, tí á mọ̀ sí àwọn páànù iyọ̀, níbití a fi sílẹ̀ sí láti gbẹ kúrò lábẹ́ oòrùn tó lágbára. Bí omí ti ngbẹ, òdòdó iyọ̀ náà nṣe àwọn krístálì ẹlẹgẹ́ sóri àwọn páànù iyọ̀ náà. Àwọn krístálí wọ̀nyí jẹ́ mímọ́ yíyànilẹ́nu wọ́n sì ní ìmọ̀lára líle àrà-ọ̀tọ̀ ní gbígbámú. Àwọn márnótósì á farabalẹ̀ yọ́ àwọn krístálì láti ojú omi ní lílo àwọn irinṣẹ́ àmọ̀já, ìlànà tó nílò ọgbọ́n nlá àti dédé. Ní Portugal, iyọ̀ dídára-níye yi ni a tọ́ka sí bí “kíríìmù iyọ̀” nítorípé ó lè rọra yọ́ kúrò bí kíríìmù tó ngbéra lọ sí òkè wàrà. Iyọ̀ ẹlẹgẹ yi ni a ṣìkẹ́ fún àìlábàwọ́n àti adùn rẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́, tí ó mú un jẹ́ èròja tí ó níyelórí nínú àwọn iṣẹ́ ọnà oúnjẹ.

Gẹ́gẹ́bí márnótósì ti ṣe ìgbìyànjú nlá láti ri dájú wípé wọ́n kórè iyọ̀ dídára jùlọ, bẹ́ẹ̀ni àwa náà, gẹ́gẹ́bí ènìyàn májẹ̀mú Olúwa, nígbàgbogbo níláti sa ipá wa kí ìfẹ́ àti àpẹrẹ wa lè jẹ́, bí ó ti ṣeéṣe tó, ìrísí mímọ́ ti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.

Ní ayé àtijọ́, iyọ̀ ju ohun tí a fi nmú nkan dùn nìkan—ó jẹ́ ohun pàtàkì kan fún ìtọ́jú nkan àti àmì jíjẹ́ mímọ́ àti májẹ̀mú. Àwọn ènìyàn mọ̀ pé iyọ̀ ṣe pàtàkì fún títọ́jú oúnjẹ àti ìmúdára adùn. Wọ́n tún lóye àyọrísí búburú tí iyọ̀ fi pàdánù jíjẹ́-iyọ̀, tàbí àdídùn, nípa dídi bíbàjẹ́ tàbí pípópọ̀.

Bí iyọ̀ ṣe lè pàdánù jíjẹ́ pàtàkì rẹ̀, àwa bákannáà lè pàdánù agbára ti-ẹ̀mí wa bí ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Kristi bá di àìlétò. A lè rí bákannáà ní ìta, ṣùgbọ́n láìsí ìgbàgbọ́ inú tó lágbára, a npàdánù agbára wa láti ṣe ìyàtọ̀ nínú ayé kí a sì mú àwọn ohun dídára jùlọ jáde nínú àwọn tí wọ́n wà ní àyíká wa.

Nítorínà báwo ni a ṣe lè lo agbára àti ìgbìyànjú wa láti ṣe ìyàtọ̀ àti láti jẹ́ ìyípadà tí àgbáyé nílò lóni? Báwo ni a ṣe le pa jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn mọ́ kí a sì tẹ̀síwájú láti jẹ́ ipa rere?

Ọ̀rọ̀ wòlíì wa ọ̀wọ́n ṣì ndún lọ́kàn mi: “Ọlọ́run nfẹ́ kí a ṣiṣẹ́ papọ̀ kí a sì ran ara wa lọ́wọ́. Ìdí nìyí tí Ó fi rán wa wá sí ilẹ̀ ayé nínú àwọn ẹbí tí Ó sì ṣètò wa sínú àwọn wọ́ọ̀dù àti àwọn èèkàn. Ìdí nìyí tí Ó fi sọ fúnwa láti sìn kí a sì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ara wa. Ìdí nìyí tí Ó fi sọ fúnwa láti gbé nínú ayé ṣùgbọ́n kí a máṣe jẹ́ ti ayé.”

Nígbàtí ìgbésí ayé wa bá kún fún èrèdí àti iṣẹ́ ìsìn, a nyẹra fún ìdágunlá ti-ẹ̀mí; ní ọ̀nà kejì, nígbàtí ìgbésí ayé wa kò bá ní èrò àtọ̀runwá, iṣẹ́-ìsìn tí ó nítumọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, àti àwọn àǹfààní mímọ́ fún ṣíṣe àṣàrò àti ìrònú, ní díẹ̀díẹ̀ a ndi dídílọ́wọ́ nípa ìṣe tìwa àti ìmọtara-ẹni-nìkan, ní fífi pípàdánù àdídùn wa sínú ewu. Òògùn sí èyí ni láti tẹ̀síwájú láti máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn—kí a máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ rere àti ìlọsíwájú ti arawa àti àwùjọ tí a ngbé nínú rẹ̀.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ẹ wo irú ìbùkún tí gbogbo wa ní lónìí láti jẹ́ ti Ìjọ Jésù Krístì tí a sì ní ànfàní láti sìn nínú Ìjọ Rẹ̀. Àwọn ìpò wa le yàtọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo wa le ṣe ìyàtọ̀.

Rántí márnótósi, àwọn òṣìṣẹ́ iyọ; wọ́n lo àwọn irin-iṣẹ́ tó rọrùn láti ṣe ìkórè àwọn krísítálì tí ó dára jùlọ, iyọ̀ tí ó dára jùlọ! Àwa pẹ̀lú lè ṣe àwọn ohun tí ó rọrùn, pẹ̀lú ìsapá lemọ́lemọ́ nínú àwọn ìṣe kéékèèké àti tí ó nítumọ̀, kí ó lè mú jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn àti ìfarajìn wa sí Jésù Kristi jinlẹ̀ sí i. Èyí ni àwọn ọ̀nà mẹ́rin rírọrùn ṣùgbọ́n tó jinlẹ̀ síbẹ̀ tí a le tiraka láti jẹ́ iyọ ayé:

  1. Fífi ilé Olúwa sí aarin gbùngbùn ifokansin wa. Ní báyìí tí àwọn tẹ́mpìlì ti sún mọ́ra ju ti ìgbàkan rí lọ, fífi ìjọsìn déédé nínú ilé Olúwa ṣe ààyò yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fojúsùn sí ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ, kí a sì jẹ́ kí ìgbésí ayé wa dá lórí Kristi. Nínú tẹ́mpìlì, a nrí ọkàn ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì àti ọkàn ìfọkànsìn wa sí I.

  2. Jíjẹ́ àmọ̀ọ́mọ̀ṣe nínú àwọn ìgbìyànjú wa láti fún àwọn ẹlòmiràn lókun nípa gbígbé ìgbé ayé ìhìnrere papọ̀. A lè fún àwọn ẹbí wa lókun nípa ìgbìyànjú lemọ́lemọ́ àti àmọ̀ọ́mọ̀ṣe láti mú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere wá sínú ayé wa àti àwọn ilé wa.

  3. Níní ìfẹ́ láti gba ìpè àti láti sìn nínú Ìjọ. Iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ ìbílẹ̀ wa nfi àyè gbà wá láti ti ara wa lẹ́hìn kí á sì dàgbà papọ̀. Nígbàtí iṣẹ̀-ìsìn kò rọrùn nígbàgbogbo, ó nfi ìgbàgbogbo ní èrè.

  4. Àti ní òpin, lílo àwọn ohun-èlò irinṣẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ pẹ̀lú èrèdí. Lóni, àwọn ohun-elo irinṣẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ gbà wá láàyè láti sopọ̀ bí kò ti rí ṣáájú tẹ́lẹ̀. Bíi púpọ̀ jùlọ lára yín, mo nlo àwọn irinṣẹ́ wọ̀nyí láti sopọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú ìjọ àti pẹ̀lú ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́ mi. Bí mo ti sopọ̀ mọ́ wọn, mo ní ìmọ̀làra sísúnmọ́ wọn si; a lè ṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ sí arawa ní àwọn ìgbà àìní nígbàtí a kò lè wà níbẹ̀ níti-ara. Àwọn ohun-èlò wọ̀nyí jẹ́ ìbùkún láìṣiyèméjì, síbẹ̀ àwọn ohun-èlò wọ̀nyí kannáà gan lè fà wá kúrò nínú ìbáṣepọ̀ onítumọ̀ jíjinlẹ̀ kí ó sì mú wa di títìdànù sínú àwọn ìwà tí yíò sọ àkokò wa nù nínú àwọn ìṣe tí ó dínkù ní èrò. Títiraka láti jẹ́ iyọ̀ ayé pẹ̀lú púpọ̀ díẹ̀ síi ju yíyí lọ àìlópin ti àwọn kẹ̀kẹ́ lórí ìbòjú ínṣì-mẹ́fà.

Bí a ṣe jẹ́ kí ilé Olúwa jẹ́ àárín gbùngbùn nínú ìgbésí ayé wa, tí a mọ̀ọ́mọ̀ nfún àwọn ẹlòmíràn lókun nípa gbígbé ìgbésí ayé ìhìnrere, gba àwọn ìpè láti sìn, tí a sì nlo àwọn ohun-èlò irinṣẹ́ pẹ̀lú èrèdí, a lè pa agbára ti ẹ̀mí wa mọ́. Gẹ́gẹ́bí iyọ̀ ní ìrísí mímọ́ jùlọ rẹ̀ ṣe lágbára láti mú dárasíi kí ó sì ṣe ìpamọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Kristi ṣe rí nígbà tí a bá ṣìkẹ́ rẹ̀ tí a sì dáàbò bò ó nípasẹ̀ ìfarajì wa fún iṣẹ́ ìsìn àti ìfẹ́ bíi ti Kristi.

Bí a ṣe ndúró ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa, ìgbésí ayé wa yóò fi ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ hàn níti ẹ̀dá, a ó sì di iyọ̀ ti ayé. Nínú ìlàkàkà yìí, kì í ṣe pé a nṣìkẹ́ ìgbésí ayé tiwa nìkan, ṣùgbọ́n a tún nfún àwọn ẹbí wa àti ìletò wa lókun bákannáà. Njẹ́ kí a tiraka láti ṣe ìmúdúró ìsopọ̀ yí pẹ̀lú Olúwa, láì sọ adùn wa nù, kí ó sì kéré, kírístálì kékeré ti iyọ̀ tí Olúwa nfẹ́ kí a jẹ́. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.