Jẹ́ Mímọ́
Ìrònúpìwàdà ojojúmọ́ nfi àyè gbà wá láti ní ìwòye ìtọ́nisọ́nà Olúwa nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.
Nígbàtí mo wà ní nkan bí ọmọ ọdún márùn-ún, mo nbá àwọn ọ̀rẹ́ mi gbá bọ́ọ̀lù lẹ́hìn ilé ìjọsìn tó wà ní abúlé kékeré mi ní Côte d’Ivoire. Mo rántí dáadáa ìpè oníwàásù náà sí ìjọ rẹ̀ láti fọ aṣọ wọn mọ́ ní ìmúrasílẹ̀ fún dídé Olùgbàlà. Ní jíjẹ́ ọ̀dọ̀, mo gba ipè yìí bí ó ti rí gan-an. Mo sáré lọ sílé bí àwọn ẹsẹ̀ kékeré mi ṣe lè gbé mi sáré tó, mo sì bẹ ìyá mi pé kí ó fọ àwọn aṣọ mi díẹ̀ mọ́ kí nlè jẹ́ aláìlábàwọ́n kí nsì múra sílẹ̀ fún dídé Olùgbàlà ní ọjọ́ kejì. Bíótilẹ̀jẹ́pé ìyá mi ṣiyèméjì nípa ìpadàbọ̀ Olùgbàlà tó sún mọ́lé, ó ṣì fọ aṣọ mi tó dára jùlọ.
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, mo wọ aṣọ náà tí kò tíì gbẹ dáadáa mo sì fi ìtaragàgà dúró de ìkéde dídé Olùgbàlà. Bí ọjọ́ ti ngorí ọjọ́ tí kò sì sí ohun tó ṣẹlẹ̀, mo pinnu láti lọ sí ilé ìpàdé. Mo ní ìjákulẹ́ gan-an láti ríi pé ilé ìjọsìn náà ṣófo àti pé Olùgbàlà kò ì tíì de. Ẹ lè fojú inú wo inú mi bí mo ṣe nrìn lọ sílé díẹ̀díẹ̀.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́hìnwá, bí mo ṣe ngba àwọn ẹ̀kọ́ míṣọ́nnárì ní ìmúrasílẹ̀ láti darapọ̀ mọ́ Ìjọ ti Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn, mo ka ohun tí ó tẹ̀lé yìí: “Kò sì sí ohun àìmọ́ kan tí ó lè wọ inú ìjọba rẹ̀; nítorínã kò sì sí ohunkóhun tí ó wọ inú ìsinmi rẹ̀ bíkòṣe àwọn tí ó ti fọ aṣọ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ mi, nítorí ìgbàgbọ́ wọn, àti ìronúpìwàdà lórí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àti òtítọ́ wọn títí dé òpin.”
Òye tí mo rí gbà lákòókò náà ràn mí lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́ pàtàkì náà tí ó ti fo ọkàn ọ̀dọ́ mi ru ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣaájú. Ọ̀rọ̀ oníwàásù náà dá lórí pàtàkì jíjẹ́-mímọ́ ti-ẹ̀mí. Ó rọ ìjọ láti wá ìrònúpìwàdà, ṣe àwọn ìyípadà nínú ìgbésí ayé wọn, kí wọ́n sì yíjú sí Olùgbàlà fún ìràpadà.
Baba wa Ọ̀run lóye ìrìn àjò ikú wa àti àìleyẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa. Mo dúpẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ pé Ó ti pèsè Olùgbàlà láti ṣe ètùtù fún àwọn ìrékọjá wa. Nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Olùgbàlà, olúkúlùkù wa lè ronúpìwàdà kí a sì wá ìdáríjì kí a sì di mímọ́. Ìrònúpìwàdà, ìlànà ẹ̀kọ́-ìpilẹ ìhìnrere, ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè ti ẹ̀mí àti ìdúróṣinṣin bí a ṣe nlọ kiri láàrin àwọn ìpèníjà ìgbésí ayé.
Nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022, Ààrẹ Russell M. Nelson pe gbogbo ọmọ Ìjọ láti ní ìrírí ayọ̀ ti ìrònúpìwàdà ojoojúmọ́. Ó wípé:
“Ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe bẹ̀rù tàbí dẹ́kun ríronúpìwàdà. Inú Sátánì ndùn sí ìbànújẹ́ yín. Ké e kúrú. Ẹ lé ipa rẹ̀ jáde kúrò nínú ayé yín. Ẹ bẹ̀rẹ̀ ní òní láti ní ìrírí ayọ̀ ti mímú ènìyàn ẹlẹ́ran ara kúrò. Olùgbàlà fẹ́ràn wa nígbàgbogbo ṣùgbọ́n nípàtàkì nígbàtí a bá ronúpìwàdà. …
“Bí ẹ bá nímọ̀lára pé ẹ ti ṣìnà kúrò ní ipá ọ̀nà májẹ̀mú jìnnà gan tàbí gígùn gan tí kò sì ọ̀nà láti padà, ìyẹn kìí ṣe òtítọ́ rárá.”
Bí ohun kan bá wà ti ẹ kò tíì ṣe ìrònúpìwàdà rẹ̀ ní kíkún, mo gbà yín níyànjú láti tẹ́tísí ipè Ààrẹ Nelson láti ma fi ìrònúpìwàdà yín falẹ̀. Ó lè nílò ìgbóyà díẹ̀ láti ṣe alabapin nínú ọ̀nà yí; síbẹ̀síbẹ̀, mo lè fi dáyin lójú pé ayọ̀ tí ó wá látinú ìrònúpìwàdà tòótọ́ kọjá òye. Nípa ìrònúpìwàdà, àwọn ẹrù ìdálẹ́bi wa ni a gbé sókè tí a sì rọ́pò pẹ̀lú ìmọ̀lára àláfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀. Bí a ṣe nronúpìwàdà tọkàntọkàn, a ti sọ wá di mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Olùgbàlà, ní ṣíṣe àlékún ìfura wa sí àwọn ìṣílétí àti àwọn ipa ti Ẹ̀mí Mímọ́.
A bí ojúgbà mi ayérayé pẹ̀lú àìgbọ́ran àti bí àbájáde rẹ̀ o gbọ́dọ̀ wọ ohun èlò ìgbọràn. Eruku àti òógùn lè ní ipa lórí iṣẹ́ àwọn ẹ̀rọ wọ̀nyí, àti nítorínáà ní òwúrọ̀ kọ̀ọ̀kan mo ṣe àkíyèsí rẹ̀ ní nínu àwọn ihò-àpò ṣaájú wíwọ àwọn ohun èlò ìgbọ́ran náà. Ìṣe tó rọrùn síbẹ̀ tó ṣe déédé yí nmú eyikeyi ìdọ̀tí, ọ̀rìnrìn, tàbí ìsunmi, nípa bẹ́ẹ̀ nṣe ìmúdára agbàra rẹ̀ láti gbọ́ àti láti bánisọ̀rọ̀ dáadáa. Nígbàtí ó bá fojú fo àṣà ojoojúmọ́ yìí, agbára rẹ̀ láti gbọ́ràn máa njìyà ní gbogbo ọjọ́; àwọn ọ̀rọ̀ sísọ máa nparẹ́ díẹ̀díẹ̀ àti níkẹhìn a di àìgbọ́yé. Gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ìgbọ́ran rẹ̀ lójoójúmọ́ ṣe ngbà á láàyè làti gbọ́ran kedere, ìrònúpìwàdà ojoojúmọ́ ngbà wá láàyè láti mọ ìtọ́nisọ́nà Olúwa nípasẹ̀ Ẹmí Mímọ́.
Ní sísúnmọ́ ìparí iṣẹ́-ìránṣẹ́ ti aye ikú àti ṣaájú lílọkúrò Rẹ̀ sí Ọgbà Gẹ́tísémánì, Ó mura àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ sílẹ̀ láti kojú àwọn àdánwò tó nbọ̀. Ó fi dáwọn lójú pé: “Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, èyí tíi ṣe Ẹ̀mí Mímọ́, ẹnití Baba yíò rán ní orúkọ mi, òun yíò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yíò sì ràn yín létí ohun gbogbo, tí mo ti sọ fún yín.”
Ọ̀kan nínú àwọn iṣẹ́ pàtàkì ti Ẹ̀mí Mímọ́ ní láti kìlọ̀, darí, àti tọ́ sọ́nà fún gbogbo ènìyàn tí ó tẹ́tísí ohùn inú rírọ̀ náà. Gẹ́gẹ́bí dídí àwọn túùbù ìbánisọ̀rọ̀ ti ohun èlò ìgbọ́ràn náá ṣe lè dí ṣíṣe iṣẹ́ dáadáa lọ́wọ́, ìsopọ̀ ti ẹ̀mí wa pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run tún lè jẹ́ bíbàjẹ́ bákannáà, tó nyọrí sí àwọn èrò tó lòdì tí ó léwu tàbí ìkùnà láti kọbi ara sí ìmọ̀ràn Rẹ̀. Wíwà ti íntánẹ́ẹ̀tì ti jẹ́ kí ìwífúnni wà síwájú síi ju ti tẹ̀lẹ́ lọ. Èyí lè darí wa láti yípadà sí ayé fún ìtọ́sọ́nà dípò sí Ọlọ́run. Ààrẹ Nelson kọ́ni pé, “Ní àwọn ọjọ́ tó nbọ̀, kò ní ṣeéṣe láti wà láàyè nípa ti ẹ̀mí, láìsí ìtọ́nisọ́nà, ìdarí, ìtùnínú àti ipa ti Ẹ̀mí Mímọ́ léraléra.”
Mo dúpẹ́ pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ ní àkókò ìfẹsẹ̀múlẹ̀ wa. Bákannáà, Ààrẹ Dallin H. Oaks kìlọ̀ pé “àwọn ìbùkún tí ó wà nípasẹ̀ ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ ni ó wà nípò lórí yíyẹ [àti pé] ‘Ẹ̀mí Olúwa kò lè gbé nínú àwọn tẹ́mpìlì àìmọ́’ [Helaman 4:24].”
Nígbàtí a bá yàn láti tẹ̀lé ìtọ́sọ́nà àwọn wòlíì àti àpọ́sítélì, agbára wa láti ní Ẹ̀mí Mímọ́ gẹ́gẹ́bí ojúgbà ìgbà gbogbo ndàgbà si. Ẹ̀mí Mímọ́ npèsè ìṣe-kedere nínú ìpinnu-ṣíṣe, àwọn èrò inú ìṣílétí àti àwọn ìtẹ̀mọ́ra tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ ti Baba Ọ̀run. Níní Ẹ̀mí Mímọ́ bí ojúgbà nígbà gbogbo ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè ti ẹ̀mí wa.
Láìpẹ́ ni a yàn mí làti darí ìpàdé àpapọ̀ èèkàn kan ni Salt Lake Granger West Stake ní Utah. Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, mo pàdé ààrẹ èèkàn kan tí ó ti fi pẹ̀lú aápọn ṣe ìmúdàgbà agbára rẹ̀ láti fi òye mọ àwọn ìṣílétí ti Ẹ̀mí Mímọ́ nípasẹ̀ ìgbé ayé òdodo àti ìrònúpìwàdà ojoojúmọ́. Bí abala àwọn ìtiraka wa ní ti ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, a ṣètò ìbẹ̀wò sí agbo ilé mẹ́ta. Lẹ́hìn píparí ìbẹ̀wò wa ìkẹhìn, a rí ara wa pẹ̀lú bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú tó kù ṣaájú iṣẹ́ tí ó tẹ̀le. Bí a ṣe nrìnrìn àjò padà sí gbùngbùn èèkàn, Ààrẹ Chesnut gba ìtẹ̀mọ́ra kan láti ṣàbẹ̀wò sí ẹbí kan ní àfikún. Àwa méèjèjì gbà láti tẹ̀lé ìṣílétí yii.
A tẹ̀síwájú láti ṣàbẹ̀wò sí ẹbí Jones, níbití a ti rí Arábìnrin Jones tí a fi sí ibùsùn nítorí àìsàn. Ó hàn gbangba pé ó nílò ìbùkún oyè-àlùfáà. Pẹ̀lú ìgbaniláàyè rẹ̀, a ṣe ìtọ́jú rẹ̀. Bí a ṣe nmúra láti lọ, Arábìnrin Jones béèrè báwo ní a ṣe mọ̀ nípa ìnílò kíákíá rẹ̀ fún ìbùkún. Òtítọ́ ni pé, a kò mọ̀. Ṣùgbọ́n, Baba wa Ọ̀run, tí ó mọ̀ nípa àwọn àìní rẹ̀, ó mọ̀ ó sì mísí Ààrẹ Chesnut láti bẹ ilé rẹ̀ wò. Nígbàtí a bá tẹ́wọ́ gba ìtọ́sọ́nà tí ohùn jẹ́ẹ́jẹ́, kékeré náà, a njẹ́ ríró lágbára dárajù láti ṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ fún àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú àìní.
Mo jẹ́ ẹ̀rí nípa onínúure àti olùfẹ́ni Baba Ọ̀run. Jésù Krístì ní Olùgbàlà àti Olùràpadà ẹ̀dá ènìyàn. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Ètùtù Jésù Krístì jẹ́ òtítọ́ àti pé bí a ṣe kọ́ láti tẹ̀lé ìtọ́sọ́nà ti Ẹ̀mí Mímọ́, Òun yíò tọ́ wa lọ láti ronúpìwàdà àti láti lo agbára Ètùtù Olùgbàlà nínú ayé wa. Ààrẹ Russell M. Nelson jẹ́ wòlíì tòótọ́ àti alààyè ti Olúwa, pẹ̀lú gbogbo kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.