Àwọn Ọ̀rọ̀ Krístì àti Ẹ̀mí Mímọ́ Yío Darí Wa Sí Òtítọ́ Náà
Mímọ̀ ètò ìyanu yí yío ràn wá lọ́wọ́ láti mọ pé a jẹ́ ọmọ Ọlọ́run àti pé a lè dàbíi Rẹ̀.
Ọlọ́run ni Baba wa ọ̀run. Awa ni àwọn ọmọ ẹ̀mí Rẹ̀, a sì dá wa ní àwòrán Rẹ̀. Nítorináà, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa, bí ọmọ Ọlọ́run, ní agbára àtọ̀runwá kan láti dàbí Rẹ̀.
A gbé pẹ̀lú Rẹ̀ bíi àwọn ọmọ ẹ̀mí ṣaájú ki a tó wá si ilẹ̀ ayé. Baba Ọ̀run, bíi òbí ẹ̀mí wa, fẹ́ràn wa, fẹ́ ohun dídárajùlọ fún wa, Ó sì pèsè ètò kan fún wa láti gba àwọn ìbùkún Rẹ̀ gígajùlọ, èyítí í ṣe àìkú ati ìyè ayérayé. Ní ìbámu sí ètò náà, àwa, bíi ọmọ ẹ̀mí, ni a ó fún ní agbára òmìnira láti yàn ètò Rẹ̀. Nípa wíwá sí ilẹ̀ ayé, a ó fi ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, a ó gbàgbé ìgbé ayé wa ṣaájú ayé ikú, a ó gba àgọ́-ara ti ẹran ati egungun, a ó gba ìrírí tiwa, a ó sì mú ìgbàgbọ́ dàgbà. Pẹ̀lú awọn àgọ́-ara wa ti ẹran ati egungun, bíi ènìyàn nípa ti ara a ó jọ̀wọ́ ara sí ìdánwò, a o di àìmọ́ ati jíjìnnà sí Ọlọ́run, a kì yio sì le padà sí ọ̀dọ̀ mímọ́ Rẹ̀. Nítorí ìfẹ́ àìlópin ti Baba Ọ̀run fún wa, Ó rán Àkọ́bí Ọmọkùnrin Rẹ̀, Jésù Krístì, láti jẹ́ Olùgbàlà wa. Nípasẹ̀ ìrúbọ Rẹ̀, Ètùtù náà, Jésù Krístì mú kí ó ṣeéṣe fún wa láti jẹ́ ríràpadà kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a sì di jíjí dìde àti kí a gba ìyè ayérayé.
Mo ní imoore gidigidi fún àwọn òtítọ́ ológo yí—ohun tí a pè ní ètò ìgbàlà ti Baba, ètò àánú Rẹ̀, tàbí ètò ìdùnnú nlá Rẹ̀. Kíkọ́ awọn òtítọ́ pàtàkì wọ̀nyí ti rànmilọ́wọ́ mọ ìdánimọ̀ mi tòótọ́ àti awọn ìbùkún nlá ti ìgbéga àti ìyè ayérayé tí Ọlọ́run ti pèsè fúnwa. Wòlíì Néfì kọ́ wa ní ọ̀nà náà: “Nítorí náà, … ẹ ṣe àpéjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì; nítorí kíyèsíi, àwọn ọ̀rọ̀ Krístì yíò sọ ohun gbogbo fún yín èyí tí ẹ̀yin ó ṣe.” Ó fikún pé, “Bí ẹ̀yin yíò bá wọlé nípasẹ̀ ọ̀nà nã, kí ẹ sì gba Ẹ̀mí Mímọ́, òun yíò fi hàn sí yín gbogbo àwọn ohun èyí tí ẹ̀yin ó se.” Lóni èmi fẹ́ láti ṣe àbápín bí awọn ọ̀rọ̀ Krístì àti Ẹmí Mímọ́ ṣe rànmílọ́wọ́ rí àwọn òtítọ́ pàtàkì to nfúnni ní àlàáfíà wọ̀nyí ni àwọn ọdún ọ̀dọ́-langba mi.
“Àwọn Ọ̀rọ̀ Krístì Yíò Sọ Fún Yín Gbogbo Àwọn Ohun Tí Ẹ̀yin ó Se.
Gẹ́gẹ́bí Néfì ṣe sọ ninu ẹṣẹ tó nṣí ìwé ti Néfì kínní, èmi bákannáà ni a “bí nipasẹ̀ awọn òbí dídára.” Mo dàgbà ni Nagano, Japan, ninu ilé kan nibiti ìwà-ìṣòtítọ́, aápọn, ati ìrẹ̀lẹ̀ ti jẹ́ gbígbani-níyànjú pẹlú agbára ati tí wíwà ní ìbámu sí awọn àṣà àtijọ́ jẹ́ títẹ̀lé daindain. Baba mi jẹ́ ènìyàn ẹlẹ́sìn gidi. Mo wò ó ní gbígbàdúrà níwájù pẹpẹ Shinto àti Bhuddist náà ni àrààrọ̀ ati ní alalalẹ́. Aní bí-ó-tilẹ̀-jẹ́-pé èmi kò òye ẹnití tó ngbàdúrà sí ati ohun to ngbàdúra fún, mo gbàgbọ́ pé irú agbára tàbí Ọlọ́run àìrí kan yío “lágbára láti gbàla” tàbí rànwá lọ́wọ́ bí a bá gbàdúrà pẹ̀lú òtítọ́.
Bíi ti àwọn ọ̀dọ́-langba mìràn, mo ni ìrírí ọ̀pọ̀ àwọn ìnira. Mo tiraka, ní ríròó pé ayé kò pin nkan dọ́gbà ó sì ní àwọn òkè ati àwọn ìsàlẹ̀ púpọ̀ jọjọ. Mo ní ìmọ̀lára sísọnù, láìní ọgbọ́n ti dídarí ninu ayé mi. Ìgbésí ayé dàbí pé ó kúrú tóbẹ́ẹ̀ nítorípé yío parí nígbàtí a bá kú. Ìgbésí ayé láì mọ ètò ìgbàlà jẹ́ onídààmú sí mi.
Kò pẹ́ nígbàtí mo bẹ̀rẹ̀ láti kọ́ Èdè Òyìnbó ni ìpele kékeré ti ilé-ìwé gíga, gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ile-ìwé wa gba ẹ̀dà kan ti Májẹ̀mú Titun. Bí-ó-tilẹ̀-jẹ́-pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ nbẹ̀rẹ̀ àṣàrò wa ní ti Èdè Òyìnbó, olùkọ́ wa sọ fúnwa pé a níláti ṣe àṣàrò Èdè Òyìnbó nípasẹ̀ kíkà á.nbṣp Mo ṣí i mo sì gbé awọn àkóónú rẹ̀ yẹ̀wò. Àwọn ọ̀rọ̀ inú Májẹ̀mú Titun jẹ́ síṣòro fun mi gidigid. Àwọn ọ̀rọ̀ náà ni Èdè Japan jẹ́ ṣíṣòro bákannáà. Bí-ó-tilẹ̀-rí bẹ́ẹ̀, a fà mí sí àtòkọ àwọn ìbéèrè ti ọkàn tí wọ́n ti fi pẹ̀lú ní kété ṣaájú ọ̀rọ̀ títẹ̀ ti bíbélì ninu Bíbélì Gídéónì yí—àwọn ìbéèrè nípa níní ìmọ̀lára ìdánìkanwà, ṣe àìní ìgbẹ́kẹ̀lé, jíjẹ́ dídààmú, dídojúkọ àwọn àdánwò ayé, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ohun kọ̀ọ̀kan lórí àtòkọ náà jẹ́ títẹ̀lé pẹ̀lú atọ́ka kan sí àwọn ẹsẹ ati awọn ojú ewé ninu Májẹ̀mú Titun náà. A fà mí nípàtàkì sí ìbéèrè náà “Nígbàtí ó bá rẹ̀ ọ́.” Atọ́ka náà darí mi láti ṣí Máttéù 11:28–30, ninu èyítí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ pe:
“Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó ńṣiṣẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.
“Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmí: ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.
“Nítorí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.”
Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mo rántí kíka àwọn ọ̀rọ̀ ti Jésù Krístì. Bí-ó-tilẹ̀-jẹ́-pé èmi kò ní òye gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí Ó sọ, àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tùmí ninu, gbé ọkàn mi sókè, ó sì fúnmi ní ìrètí. Bí mo ṣe nka àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sí, bẹ́ẹ̀ ni mo nní ìmọ̀lára sí bíi kí ngbìyànjú ìwà rere àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Èmi kò tíì ní ìmọ̀ ara bí mo ti ní ní ọjọ́ náà rí láé. Mo nímọ̀lára pé a fẹ̀ràn mi. Mo nímọ̀lára pé Jésù Krístì ni ẹnìkan tí mo mọ̀.
Bí mo ti tẹ̀síwájú ní ṣíṣe àṣàrò, mo nimọ̀lára bí ẹnipé Òun nbá mi sọ̀rọ̀ tààrà nígbàtí Ó wípé: “Alábùkún-fún ni àwọn tí ebi npa tí wọ́n sì npòngbẹ fún òdodo: nítorití a ó kún wọn.”
Àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kún ọkàn mi, àní bí-ó-tilẹ̀-jẹ́-pé èmi kò le ṣàpéjúwe àwọn ìmọ́lára mi ní àkókò náà. Bí-ó-tilẹ̀-jẹ́-pé Jésù Krístì gbé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ sẹ́ntíúrì sẹ́hìn ní ilẹ̀ kan tí kò jẹ́ mímọ̀ sí mi, mo rò pé èmi le gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi. Mo nírètí pe ni ọjọ́ iwájú kan èmi ó le kọ́ nípa Jésù Kristi síi.
“Ẹ̀mí Mímọ́ Yíò Fi Hàn Yín Ohun Gbogbo Ti Ẹ̀yin Yio Ṣe
Lọ́jọ́kan náà wá ni àwọn ọdún díẹ̀ péré lẹ́hìnwá. Mo pàdé olùfọkànsìn, ọ̀dọ́, àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ní kíkún ti Ìjọ Jésù Krístì tí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn. Àti láìpẹ́ mo pàdé ẹgbẹ́ kékeré kan ti aláànú àti aláyọ̀ Awọn enìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí wọ́n ntiraka láti tẹ̀lé Jésù Krístì. Láìka pé ó gbà mi lákokò díẹ̀ sí láti gbẹ́kẹ̀ lé wọn, mo wá ríi ninu ìhìnrere tí-a-mú-padàbọ̀-sípo ohun ti mo pòngbẹ fún nígbàtí mo ṣàṣàrò Májẹ̀mú Titun náà—àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Krístì àti ìrètí ati àlàáfíà tí ó nwá lati inú wọn.
Ìrírí kan tó jẹ́ mímọ́ ní pàtó ni nígbàtí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere kọ́ mi láti gbàdúrà. Mo kọ́ pé a níláti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípa orúkọ. Nígbàtí a bá ngbàdúrà, a níláti sọ̀rọ̀ láti inú ọkàn wa, kí a fi ìmoore wa hàn, kí a sì ṣe àbápín àwọn ìrètí àti àwọn ìfẹ́ inú wa. Bí a bá ti sọ gbogbo ohun tí a fẹ́ sọ, a nparí àdúrà wa nípa sísọ pé, “Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.” A nṣe èyí nítorípé Jésù pàṣẹ fún wa láti máa gbàdúrà ní orúkọ orúkọ Rẹ̀. Gbígbàdúrà si Baba Ọ̀run rànmilọ́wọ́ láti mọ ẹniti Í ṣe ati ìbáṣepọ̀ mi pẹ̀lú Rẹ̀—pé mo jẹ́ àyànfẹ́ ọmọkùnrin ti ẹ̀mí Rẹ̀ Mo kọ́ ẹ̀kọ́ pé nítorípé Baba Ọ̀run mọ̀ Ó sì fẹ́ràn mi, Òun yío bá mi sọ̀rọ̀ ní ti ara-ẹni, ní àìláfiwé, àti ní àwọn ọ̀nà tí ó yé mi nípasẹ̀ Ẹmí Mímọ́.
Àkókò kan wà nígbàtí èmi kò le dá Ẹmí Mímọ́ mọ̀ ní tòótọ́. Mo ṣìí gbọ́, ní ríronú pé gbogbo ohun tí mo ni láti ṣe ni títẹ̀lé àwọn ìgbésẹ̀ àdúrà ati pé ohun kan bíi idán yío ṣẹlẹ̀. Ni ọjọ́ kan, ní ìgbà ẹ̀kọ́ kan pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere, mo bọ́ síta láti ibi ẹ̀kọ́ náà láti ní ìsinmi díẹ̀. Mo ṣì ní ìdààmú nípa ohun tí mo níláti ṣe pẹ̀lú ayé mi bí ìhìnrere Jésù Krístì bá jẹ́ òtítọ́ ní tòótọ́.
Bi mo ti fẹ́ padà sí yàrá náà níbití àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ti ndúró, mo gbọ́ ohùn ọ̀kan ninu àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere náà. Mo gbọ́ orúkọ mi. Dípò ṣíṣí ilẹ̀kùn, mo fetísílẹ̀ sí ohùn náà ní ẹ̀gbẹ́ kejì ìlẹ̀kùn. Ẹ̀rù bà mí. Wọ́n kàn ngbàdúrà sí Baba Ọ̀run ni. Èyí tí ngbàdúrà nbẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run pé kí Ó gbọ́ àdúrà mi. Bí-ó-tilẹ̀-jẹ́ pé èdè Japan rẹ̀ kò dánmọ́rán tó, gbígbọ́ àdúrà tòótọ́ rẹ̀ mú ọkàn mi rọ̀. Mo ròó ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi ṣàníyàn púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀ nípa èmi. Nígbànáà mo ríi pé àdúrà wọn ní ìtìlẹ́hìn mi jẹ́ ìfihàn ìfẹ́ ti Baba Ọ̀run àti Olùgbàlà fún mi. Ìfẹ́ náà fún mi ní ìrètí, ati lẹ́hìnwá mo béèrè lọ̀wọ́ Ọlọ́run ninu ìgbàgbọ́ àti pẹ̀lu èrò-inú toótọ́. Nígbàtí mo ṣe bẹ́ẹ̀, mo ní ìmọ̀lára kíkún fún ayọ̀ ati kíkún fún àláfíà pé mo jẹ́ ọmọ Ọlọ́run nitòótọ́ ati pé mo ni agbára-ìleṣe àti àyànmọ́-ìpín àtọ̀runwá. Ètò ìgbàlà rì jinlẹ̀ sínú ọkàn mi.
Ààrẹ Nelson ti sọ pé, “Bí o ti nronú nípa ẹni tí o … jẹ́ nkan … gbogbo ìpinnu ti ẹ ó máa ṣe láe.” Ó jẹ́ òtítọ́ tóbẹ́ẹ̀ fún èmi. Ìpinnu láti tẹ̀lé Olùgbàlà Jésù Krístì nípa jíjẹ́ rírìbọmi àti gbígba ẹbùn Ẹmí Mímọ́ bùkún ayé mi ju bí mo ti le lérò lọ láe. Bí a ti nwọnú májẹ̀mú ìrìbọmi pẹ̀lú Ọlọ́run, a ṣe ìlérí pé a ní ìfẹ́ láti gbé orúkọ Jésù Krístì lé orí arawa, pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, kí a sì sìn Ín fún ìyókù ìgbésí ayé wa. Baba wa Ọ̀run, ní àyídà, ṣe ìlérí fún wa pé a lè ní Ẹ̀mí Rẹ̀ láti wà pẹ̀lú wa nígbàgbogbo—ìtọ́nisọ́nà lemọ́lemọ́ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.
Mo pè yín láti ní ìgbàgbọ́ ninu ọ̀rọ̀ tí Néfì kọ́ wa—pé àwọn ọ̀rọ̀ Krístì àti Ẹ̀mí Mímọ́ yíò fi hàn sí yin “gbogbo àwọn ohun èyí tí [ẹ̀yin] níláti ṣe.” Gbogbo Nkan! Èyí jẹ́ ẹ̀bùn ìyanu kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo dúpẹ́ fún ètò ìdùnnú ti Baba wa Ọ̀run. Nítorípé Ó fẹ́ràn wa, Ó pèsè ọ̀nà láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nípasẹ̀ Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Kanṣoṣo, Jésù Krístì. Mímọ̀ ètò ìyanu yí yío ràn wá lọ́wọ́ láti mọ pé a jẹ́ ọmọ Ọlọ́run àti pé a lè dàbíi Rẹ̀. Mo dúpẹ́ fún òtítọ́ pàtàkì yí. Mo jẹ́ ẹ̀rí mi síi yín pé àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Krístì àti Ẹ̀mí Mímọ́ yío darí wa láti gba ìyè ayérayé. Mo mọ pé àwọn ohun wọnnì jẹ́ òtítọ́. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.