Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Dojúkọ Jésù Krístì àti Ìhìnrere Rẹ̀
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024


10:50

Fojúsun Sórí Jésù Krístì àti Ìhìnrere Rẹ̀

Nígbàtí a bá pa àwọn ìyọnu ti ayé tì tí a sì dojúkọ Jésù Krístì àti Ìhìnrere Rẹ̀, a ó yege dájúdájú.

Ní 1996, ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ti àwọn ọkùnrin ará Nigeria gba wúrà níbi eré Òlímpíkì tí a ṣe ní Atlanta, Georgia, ní United States. Bí àṣekágbá náà ṣe parí, àwọn èrò tí wọ́n nṣe àjọyọ̀ tú yáyá sí àwọn òpópónà gbogbo ìlú-nlá àti ìlú kékèké; orílẹ̀-èdè yí tí ó ní mílíọ́nù àádọ́fà ènìyàn ni a yí-nípò-padà lọ́gán sínú ayẹyẹ títóbi kan ní aago méjì òwúrọ̀! Ó jẹ́ ayọ̀, ìdùnnú, àti àríyá alákòóràn bí àwọn ènìyàn ti jẹun, kọrin, tí wọ́n sì jó. Ní àkokò náà, Nigeria wà nírẹ́pọ̀, àti pé olukúlùkù ará Nigeria ló ní ìtẹ́lọ́rùn jíjẹ́ ara Nigeria.

Ṣíwájú Òlímpíkì, ẹgbẹ́ yí dojúkọ onírurú àwọn ìpènijà. Bí eré-ìje ti nbẹ̀rẹ̀, owó àtìlẹhìn wọn dé òpin. Ẹgbẹ́ náà díje láìsí àwọn ohun èlò ìmúra, ibi idanilẹkọ, oúnjẹ́, tàbí àwọn ibi ìfọṣọ tó péye.

Ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá pẹ̀lú àmì-ẹ̀yẹ wúrà.

Àwọn àwòrán Jerome Prevost/Getty

Ní ọ́gangan àsìkò kan, wọ́n wà ní àwọn ìṣẹ́jú díẹ̀ kúrò ní yíyọkúrò nínú ìdíje, ṣùgbọ́n ẹgbẹ́ àwọn ará Nígeria náà ṣẹ́gun lòdì sí gbogbo àtakò. Àkokò pàtàkì yí ṣe ayípadà bí wọ́n ti rí ara wọn. Pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé titun tí wọ́n ní, àti pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára ti ẹnìkọ̀ọ̀kan àti ti ẹgbẹ́ àti ìpinnú fíforítì, wọ́n fi ìrẹ́pọ̀ pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyọnu tì wọ́n sì dojúkọ bíborí. Ìdojúkọ yí fún wọn ní àmì-ẹ̀yẹ wúrà, àti pé àwọn ará Nigeria sọ wọ́n ní orúkọ “Ẹgbẹ́ Alálàá.” Ẹgbẹ́ Alálàá ní Òlímpíkì Atlanta 1996 tẹ̀síwájú láti jẹ́ ìtọ́kasí nínú àwọn eré-ìje ti awọn ará Nigeria.

Ẹgbẹ́ Alala ti Nigeria.

Àwọn Àwòrán David Cannon/Allsport/Getty

Nígbàtí ẹgbẹ́ bọ́ọ̀lù àfẹsẹgbá náà kọ́ láti pa àwọn ìyọnu tí ó dojúkọ́ wọn tì tí wọ́n sì fojúsùn sórí ibi-afẹ́dé wọn, wọ́n yege kọjá ohun tí wọ́n rò pé ó ṣeéṣe wọ́n sì ní ìrírí ayọ̀ nlá. (Bí àwọn ìyókù wa ti ṣe ní Nigeria!)

Ní irú ọ̀nà kannáà, nígbàtí a ba pa àwọn ìyọnu ti ayé tì tí a sì fojúsùn lórí Jésù Krístì àti Ìhìnrere Rẹ̀, a ó gba ẹ̀rí ìyege kọjá ohun tí a lè lérò ní kíkún àti pé a ó lè ní ìmọ̀lára ayọ̀ nlá. Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé “Nígbàtí ìdojúkọ ìgbésí ayé wa bá wà lórí … Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ, a lè ní ìmọ̀lára ayọ̀ láìkà ohun tó nṣẹlẹ̀—tàbí tí kò máa ṣẹlẹ̀ sí—nínú ìgbé ayé wa.”

Mo gbàdúrà pé Ẹ̀mí Mímọ́ yíò ran ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ láti gbọ́ ìfipè Ààrẹ Nelson láti ṣe ìdojúkọ ìgbésí-ayé wa lórí Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀” kí a lè ní ìrírí ayọ̀ nínú Krístì láìka ohun tí ó nṣẹlẹ̀ tàbí tí kò ṣẹlẹ̀ sí nínú ìgbésí-ayé wa.

Àwọn àkọsílẹ̀ onírurú nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì júwe àwọn wọnnì tí wọ́n yí ìgbésí-ayé wọn padà nípa dídojúkọ Jésù Krístì àti Ìhìnrere Rẹ̀.

Ṣe Àyẹ̀wò Álmà Kékeré Ó ṣe oríkunkun ó sì jà ní ìlòdì sí Ìjọ. Baba rẹ̀, Álmà, gbàdúrà ó sì gbàwẹ̀. Ángẹ́lì kan farahàn ó sì pe Álmà Kékeré láti ronúpìwàdà. Ní àkokò náà, Álmà bẹ̀rẹ̀ láti jìyà “ìrora ẹni ìdálẹ́bi.” Nínú àwọn wákàtí ṣíṣókùnkùn, ó rántí baba rẹ tí ó nkọ́ni pé Krístì yíò wá láti ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé. Bí ọkàn rẹ̀ ti ṣe ìdìmú lórí èrò yí, ó bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run fún àánú. Ayọ̀ ni àbájáde náà, ayọ̀ tí ó júwe bí àìláfiwé! Àánú àti ayọ̀ wá sọ́dọ̀ Álmà nítorí òun àti baba rẹ̀ fojúsùn sórí Olùgbàlà.

Fún àwọn òbí tí wọ́n ní àwọn ọmọ tí wọ́n ti ṣáko lọ, ẹ mọ́kanle! Dípò ríronú ìdí tí ángẹ́lì kan kò ṣe wá láti ran ọmọ yín lọ́wọ́ láti ronúpìwàdà, ẹ mọ̀ pé Olúwa ti fi ángẹ́lì ayé-ikú kan sí ipa-ọ̀nà wọn lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin: bíṣọ́ọ̀pù, tàbí àwọn olórí Ìjọ míràn, tàbí oníṣẹ́ ìrànṣẹ́ arákùnrin tàbí arábìnrin kan. Bí ẹ bá tẹramọ́ gbígbàwẹ̀ àti gbígbàdúrà, bí ẹ kò bá gbé tábìlì-àkokò tàbí òpin-ìlà yín kalẹ̀ fún Ọlọ́run, àti bí ẹ ó bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Òun nnawọ́ síwájú láti ṣèrànwọ́, nígbànáà—láìpẹ́ tàbí lẹ́hìnwá—ẹ ó rí Ọlọ́run tí ó nfọwọ́tọ́ ọkàn ọmọ yín nígbàtí ọmọ yín bá yàn láti fetísílẹ̀. Èyí jẹ́ bẹ́ẹ̀ nítorí Krístì ni ayọ̀—Krístì ni ìrètí; Òun ni ìlérí “àwọn ohun rere tó nbọ̀.” Nítorínáà ẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jésù Krístì pẹ̀lú ọmọ yín, nítorí Òun ni okun ti gbogbo òbí àti gbogbo ọmọ.

Lẹ́ẹ̀kannáà tí ó ní ìrírí ayọ̀ nínú Krístì, Álmà Kékeré gbé pẹ̀lú ayọ náà ní gbogbo ayé rẹ̀. Àti pé báwo ni ó ṣe ṣe ìmúdúró irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀ àní nínú ìṣòrò àti àdánwò? Ó wípé:

“Àti láti ìgbà náà títí di ìsisìyí pẹ̀lú, èmi ti ṣiṣẹ́ láìsinmi, [láti] mú àwọn ọkàn wá sí ìronúpìwàdà; kí èmi kí ó lè mú wọn tọ́ wò nínú ọ̀pọ̀ ayọ̀ nínú èyítí èmi ti tọ́ wò. …

“… Àti pé … Olúwa ti fún mi ní ọ̀pọ̀ ayọ̀ nlá nínú èrè iṣẹ́ mi. …

“Èmi sì ti rí ìrànlọ́wọ́ gbà lábẹ́ awọn àdánwò àti ìyọnu onírurú.”.

Ayọ̀ nínú Krístì bẹ̀rẹ̀ fún Álmà nígbàtí ó lo ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ ti ó sì ké fún àánú. Nígbànáà Álmà lo ìgbàgbọ́ nínú Krístì nípa ṣíṣe iṣẹ́ láìsìmi láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti tọ́ irú ayọ̀ kannáà wò. Ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ wọ̀nyí mú ayọ̀ nlá jáde nínú Álmà àní nínú àdánwò àti ìyọnu onírurú. Ṣé ẹ ri, “Olúwa fẹ́ràn ìtiraka,” àti pé ìgbìyànjú ní ìdojúkọ Ọ́ nmú àwọn ìbùkún wá. Àní àwọn àdánwò líle lè di “gbígbémi nínú ayọ̀ Krístì.”

Àwọn ẹgbẹ́ míràn nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì tí wọ́n fi Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ ṣe ìdojúkọ sí ìgbésí-ayé wọn tí wọ́n sì rí ayọ̀ ni àwọn wọnnì tí wọ́n ṣe ìpìlẹ̀ ìlú Hẹ́lámù—ibikàn tí wọ́n ti lè tọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n sì gbádùn lílo òmìnira ẹ̀sìn wọn. Àwọn ènìyàn olódodo yí tí wọ́n ngbé ìgbé ayé rere ni a fi sóko-ẹrú nípa ẹgbẹ́ apanirun tí wọ́n sì gba ẹ̀tọ́ ìpìlẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn wọn kúrò láti lo ẹ̀sìn. Nígbàmíràn àwọn ohun burúkú nṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rere:

“Olúwa rí i pé ó tọ́ láti bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wí; bẹ̃ni, òun dán sũrù nwọn àti ìgbàgbọ́ nwọn wò.

“Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀—ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ìgbẹ́kẹ̀lé sí inú rẹ̀ òun kannáà ni a ó gbé sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn. Bẹ̃ni, báyĩ ni ó sì rí fún àwọn ènìyàn yí.”

Báwo ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti ní ìforítì nípasẹ̀ àwọn àdánwò àti ìjìyà wọn? Nípa dídojúkọ Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀. Àwọn ìdàmú wọn ko sọ irú ẹnití wọ́n jẹ́; sànju bẹ́ẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yípadà sí Ọlọ́run nítorí wọn rí ara wọn bí ọmọ Ọlọ́run, ọmọ májẹ̀mú kan, àti ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì kan. Bí wọ́n ti rántí ẹnití wọ́n jẹ́ tí wọ́n sì ké pé Ọlọ́run, wọ́n gba àláfíà, okun, àti ayọ̀ ìgbẹ̀hìn nínú Krístì.

“Álmà àti àwọn ènìyàn sì … tú ọkàn wọn jáde sí [Ọlọ́run]; ó sì mọ ìrònú ọkàn wọn.

“Ó sì ṣe tí ohùn Olúwa tọ́ nwọ́n wá nínú ìpọ́njú nwọn, tí ó wípé: Ẹ gbé orí i yín sókè, kí ẹ sì tújúká, nítorítí èmi mọ́ májẹ̀mú tí ẹ̀yin ti dá pẹ̀lú mi; èmi yíò sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ènìyàn mi, èmi yíò sì gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú.”

Ní ìfèsì, Olúwa “mú àwọn ẹrù wọn rọrùn … lórí àwọn èjìká [wọn]. … Bẹ̃ni, Olúwa fún nwọn ní okun kí nwọ́n lè gbé ẹrù nã pẹ̀lú ìrọ̀rùn, nwọ́n sì jọ̀wọ́ ara sílẹ̀ fún ìfẹ́ Olúwa pẹ̀lú ọ̀yàyà àti pẹ̀lú sùúrù sí gbogbo ìfẹ́ Olúwa.” Kíyèsi pé àwọn Ènìyàn Mímọ́ wọ̀nyí jẹ́ kí àwọn wàhálà, ìjìyà, àti àdánwò wọn di gbígbémì nínú ayọ̀ Krístì! Nígbànáà ní àìpẹ́, Ó fi ọ̀nà fún ìyọkúrò wọn hàn fún Álmà, àti pé Álmà—wòlíì Ọlọ́run kan—darí wọn lọ sí ibi ààbò.

Bí a ti ndojúkọ Krístì tí a sì ntẹ̀lé wòlíì Rẹ̀, àwa bákannáà yíò gba ìdarí lọ sọ́dọ̀ Krístì àti ayọ̀ ìhìnrere Rẹ̀. Bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni pé: “Ayọ̀ lágbára, àti pé fífi ojúsùn sórí ayọ̀ nmú agbára Ọlọ́run wá sínú ayé wa. “Bí ohun gbogbo, Jésù Krístì alápẹrẹ ìgbẹ̀hìn wa, ‘nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ̀, tí ó farada àgbélèbú’ [Hébérù 12:2].”

Ìyá Alàgbà Egbo.
Alàgbà Egbo pẹ̀lú ìyá rẹ̀.

Ìyá mi kọjá lọ láìpẹ́ yí; ó jẹ́ ìjayà sí mi. Mo nifẹ ìyá mi èmi kò sì ṣètò sísọ ọ́ nù ní ọ̀dọ́. Ṣùgbọ́n nípa kíkọjá lọ rẹ̀, ẹbí mi àti èmi ti ní ìrírí ìkorò àti ayọ̀. Mo mọ̀ pé nítorí Rẹ̀, òun kò kú—ó wà láàyè! Mo sì mọ̀ pé nítorí Krístì àti àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà tí a múpadàbọ̀sípò nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, èmi ó wà pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansi. Ìkorò ti sísọ ìyá mi nù ti di gbígbémì nínú ayọ̀ Krístì! Mò nkọ́ pé láti “ronú sẹ̀lẹ́stíà” àti láti “jẹ́ kí Ọlọ́run borí” wà nínú ṣíṣe ìdojúkọ ayọ̀ tí ó wà nínú Krístì.

Ó fi pẹ̀lú ìfẹ́ pè, “Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó nṣiṣẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.