Áà Ẹ̀yin Ọ̀dọ́ ti Ogún-ìbí Ọlọ́lá
Ọlọ́run gbẹkẹle yín, ẹ̀yin ọmọ májẹ̀mú náà, láti ṣèrànwọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ Rẹ ní mímú gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ wá sí ilé lọ́dọ̀ Rẹ̀ láìléwu.
Alàgbà Stevenson, èyí ni ìpàdé àpapọ̀ tí a kò ní gbàgbé láé.
Ẹbí wa ti máa ngbádùn ìwé kékeré kan tí wọ́n npè ní Lẹ́tà Àwọn Ọmọdé sí Ọlọ́run. Nihin ni àwọn díẹ̀:
“Ọlọrun ọ̀wọ́n, dípò jíjẹ́ kí àwọn ènìyàn máa kú kí o sì ní láti ṣe àwọn titun, kíníṣe tí ẹ kò kúkú pa àwọn tí ẹ ní nísisìyí mọ́?”
“Báwo ni ẹ ṣe ní àwọn òfin mẹwa péré, ṣùgbọ́n ilé-ìwé wa ní àwọn mílíọ̀nù?”
“Kínìṣe ti ẹ fi àwọn okùn ahọ́n ọ̀nà ọ̀fun sí inú bí ẹ bá kàn tún máa yọ wọn jáde?”
Ní òní kò sí àkokò láti dáhùn gbogbo àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ìbéèrè míràn wà tí mo nfi ìgbàgbogbo gbọ́ láti ẹnu àwọn ọ̀dọ́ tí èmi yìó fẹ́ láti sọ̀rọ̀ lé lórí. Láti Ulaanbaatar, Mongolia, dé Thomas, Idaho, ìbéèrè náà jẹ́ ìkannáà: “Kíníṣe? Kíníṣe tí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn fi gbọ́dọ̀ gbé ní ìyàtọ̀ tóbẹ́ẹ̀ sí àwọn míràn?”
Mo mọ̀ pé ó ṣòro láti yàtọ̀—pàápàá nígbàtí ẹ jẹ́ ọ̀dọ́ àti pé ẹ fẹ́ kí àwọn ènìyàn míràn fẹ́ràn yín. Gbogbo ènìyàn fẹ́ wà ní ìbámu, àti pé ìfẹ́ náà pọ̀ sí àwọn ìwọ̀n àìlèra ní ayé díjítà òní tí ó kún fún ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn àti ìpániláyà orí ayélujára.
Nítorínáà, pẹ̀lú gbogbo pákánleke náà, kíníṣe tí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn fi ngbé lọ́nà tó yàtọ̀ tóbẹ́ẹ̀? Àwọn ìdáhùn púpọ̀ ló wà tó dára: Nítorípé ìwọ jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Nítorípé a ti gbà ọ́ là fún àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Nítorípé o jẹ́ ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì.
Ṣùgbọ́n àwọn ìdáhùn wọ̀nyí kìí fi gbogbo ìgbà yà yín sọ́tọ̀ Ẹnìkọ̀ọ̀kan jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Ẹnìkọ̀ọ̀kan ní orí ilẹ̀ ayé lọ́wọ́lọ́wọ́ yí ni a ránwá sihin ní àwọn ọjọ́-ìkẹhìn. Àti pé síbẹ̀síbẹ̀ kìí ṣe gbogbo ènìyàn ní wọ́n ngbé ìgbé ayé Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n tàbí òfin ìparaẹnimọ́ ní ọ̀nà bí ẹ ṣe ntiraka láti ṣe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akíkanjú ọmọẹ́hìn Krístì ló wà tí wọn kìí ṣe ọmọ Ìjọ yìí. Ṣùgbọ́n wọn kìí sín ní àwọn míṣọ̀n, wọn kìí sìí ṣe àwọn ìlànà nínú ilé Olúwa fún àwọn baba nlá bí ẹ̀yin ti nṣe. Díẹ̀ gbọ́dọ̀ wà sí i—ó sì wà.
Ni òní èmi yìó fẹ́ láti fojúsùn sórí àfikùn ìdí kan tí ó ti ní ìtumò nínú ìgbésí ayé mi. Ní 1988 Àpóstélì kékeré kan tí à pè ní Russell M. Nelson sọ ọ̀rọ̀ kan ni Unifásítì Brigham Young tí a pè ní “O ṣeun Fún Májẹ̀mú náà.” Nínú rẹ̀, Alàgbà Nelson ṣàlàyé pé nígbàtí a bá lo ìwà agbára òmìnira wa láti dá àti láti pa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, a di ajogún májẹ̀mú ayérayé tí Ọlọ́run ti dá pẹ̀lú àwọn aṣaájú wa ní gbogbo àkokò iṣẹ ìríjú. Sísọ ní ọ̀nà míràn, a di “àwọn ọmọ májẹ̀mú.” Èyíinì yà wá sọ́tọ̀. Èyí fún wa láǹfààní sí àwọn ìbùkún kannáà tí àwọn baba nlá wa àti àwọn ìyá nlá wa gbà, títí kan ogún-ìbí.
Ogún-ìbí! Ẹ lè ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. A tilẹ̀ nkọ orin nípa rẹ̀ pé: “Áà ọ̀dọ́ ti ogún-ìbí ọlọ́lá náà, ẹ tẹ̀síwájú, ẹ tẹ̀síwájú, ẹ tẹ̀síwájú!” Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó lágbára. Ṣùgbọ́n kíni ó túmọ̀ sí?
Ní àwọn àkokò Májẹ̀mú Láéláé bí baba kan bá kú, ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ ní ojúṣe fún ìtọ́jú ìyá àti àwọn arábìnrin rẹ̀. Àwọn arákùnrin rẹ̀ a gba ogún wọn, wọ́n sì jáde lọ láti ṣe ọ̀nà wọn nínú ayé, ṣùgbọ́n ọmọkùnrin ti ogún-ìbí kò lọ sí ibì kankan. Òun yíò gbéyàwó yíò sì ní ẹbí tirẹ̀, ṣùgbọ́n yíò dúró títí di òpin ọjọ́ rẹ̀ láti ṣe àkóso àwọn àlámọ̀rí ìjọba baba rẹ̀. Nítorí àfikún ojúṣe yìí, a fún un ní àfikún ìwọ̀n ogún kan síi. Njẹ́ dídarí àti ṣíṣe àmojútó fún àwọn míràn jẹ́ ohun púpọ̀jù láti béèrè bí? Kìíṣe nígbàtí ẹ bá ro nípa àfikún ogún ìní tí a fi fún un.
Ní òní a kò sọ̀rọ̀ nípa ètò ìbímọ yín nínú àwọn ẹbí ti ayé tàbí àwọn ipa akọ tàbí abo ti Májẹ̀mú Láéláé. À nsọ̀rọ̀ nípa ogún ìní tí ẹ̀ ngbà bí àjùmọ̀-jogún pẹ̀lú Krístì nítorí májẹ̀mú ìbáṣepọ̀ tí ẹ ti yàn láti wọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ àti Baba yín ní Ọ̀run. Njẹ́ ó pọ̀jù fún Ọlọ́run láti nírètí pé kí ẹ gbé ní ìyàtọ̀ ju àwọn ọmọ Rẹ̀ míràn lọ kí ẹ lè ṣe ìtọ́sọ́nà kí ẹ sì sìn wọ́n dáradára? Kìí ṣe nígbàtí ẹ bá ro ti àwọn ìbùkún—ti ara àti ti ẹ̀mí—tí a ti fifún yín.
Njẹ́ ogún-ìbí yín túmọ̀ sí pé ẹ dára ju àwọn míràn lọ bí? Rárá, ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí pé a nretí yín láti ran àwọn míràn lọ́wọ́ láti dára síi. Njẹ́ ogún-ìbí yín túmọ̀ sí pé a yàn yín bí? Bẹ́ẹ̀ni, ṣùgbọ́n a kò yàn yín láti ṣàkóso lórí àwọn ẹlòmíràn; a yàn yín láti sìn wọ́n. Njẹ́ ogún-ìbí yín jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ Ọlọ́run? Bẹ́ẹ̀ni, ṣùgbọ́n pàtàkì díẹ̀ si, ó jẹ́ ẹ̀rí ìgbẹ́kẹ̀lé Rẹ̀.
Ó jẹ́ ohun kan láti nifẹ ẹni àti ohun míràn pátápátá láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹni. Nínú ìtọ́nisọ́nà Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, a kà pé: “Baba Yín ni Ọ̀run gbẹ́kẹ̀lé yín. Ó ti fún yín ní àwọn ìbùkún nla, pẹ̀lu ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere àti àwọn ìlànà mímọ́ àti àwọn májẹ̀mú tí ó so yín pọ̀ mọ́ Ọ tí ó sì mú agbára Rẹ̀ wá sínú ayé yín. Pẹ̀lú àwọn ìbùkún wọ̀nyẹn ni àfikun ojúṣe wá. Ó mọ̀ pé ẹ lè ṣe ìyàtọ̀ nínú ayé, ìyẹn sì nílò, ní ọ̀pọlọ̀pọ̀ ìgbà, yíyàtọ̀ sí ayé.”
A lè fi ìrírí ayé ikú wa wé ọkọ̀ ojú omi kan nínú èyítí Ọlọ́run ti rán gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ bí wọ́n ṣe nrin ìrìnàjò láti etí òkun kan sí òmíràn. Ìrìnàjò náà kún fún àwọn ànfààní láti kẹkọọ, dàgbà, ní ìdùnnú, àti láti lọsíwájú, ṣùgbọ́n ó tún kún fún àwọn ewu. Ọlọ́run fẹ́ràn gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ ó sì ṣàníyàn nípa àláfíà wọn. Kò fẹ́ pàdánù èyíkéyìí nínú wọn, nítorínáà Ó pe àwọn tí wọ́n fẹ́ láti di ọmọ ẹgbẹ́ atukọ̀ Rẹ—ẹ̀yin niyẹn. Nítorí yíyàn yín láti ṣe àti pa àwọn májẹ̀mú mọ́, Ó fún yín ní ìgbẹ́kẹ̀lé Rẹ̀. Ó gbẹ́kẹ̀lé yín láti yàtọ̀, jẹ́ ọ̀tọ̀, tí a yà sọ́tọ̀ nítorí iṣẹ́ pàtàkì tí Ó gbẹ́kẹ̀lé yín láti ṣe.
Ronú nípa rẹ̀! Ọlọ́run ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú yín—nínú gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, ẹ̀yin ọmọ májẹ̀mú náà—ọmọ atúkọ̀ Rẹ̀—láti ṣèrànwọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ Rẹ ní mímú gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ wá sí ilé lọ́dọ̀ Rẹ̀ láìléwu. Abájọ ti Ààrẹ Brigham Young sọ nígbà kan pé, “Gbogbo àwọn ángẹ́lì ọ̀run nwo àwọn ènìyàn iye kékeré yi.”
Nígbàtí ẹ bá wò yíká lórí ọkọ̀ ojú-omi kékeré yí tí a npè ní ilẹ̀ ayé, ẹ lè rí àwọn ènìyàn míràn tí wọ́n joko nínú àwọn àga ijoko rọ̀gbọ̀kú ti wọ́n nmu ohun mímu, ta àyò ní àwọn ilé-ìtatẹ́tẹ́, ní wíwọ aṣọ tí ó ṣe àfihàn ara púpọ̀jù, ní yíyí orí àwọn fóònù alágbèká lọ lailópin, tí wọ́n sì nfi àkokò púpọ̀jù ṣòfò ní ṣíṣe àwọn eré ẹ̀rọ ìtànná. Ṣùgbọ́n dípò ìyàlẹ́nu, “Kíníṣe tí èmi kò lè ṣe yẹn?,” ẹ lè ràntì pé ẹ kìí ṣe èrò lásán. Ẹ̀yín jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ti àwọn atukọ̀ náà. Ẹ ní àwọn ojuṣe tí àwọn èrò kò ní. Bí Arábìnrin Ardeth Kapp ti sọ nígbàkan, “Ẹ kò lè jẹ́ [olùṣọ́]ẹ̀mí tí ẹ bá dàbí gbogbo àwọn olùwẹ̀ míràn ní etí òkun.”
Àti pé kí o tó ní ìrẹ̀wẹ̀sì nípasẹ̀ gbogbo àwọn àfikún ojúṣe, jọ̀wọ́ rántí pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ atukọ̀ gba nkan tí àwọn arìnrìnàjò míràn kò gbà: ìsanpadà. Alàgbà Neil L. Andersen ti wí pé, “Agbára ti-ẹ̀mí ìsanpadà kan wà fún àwọn olódodo,” pẹ̀lú “ìdánilójú gígajù, ìfẹsẹ̀múlẹ̀ gígajù, àti ìgbẹ́kẹ̀lé gígajù.” Bíi Ábráhámù ti ìgbàanì, ẹ̀yin gba ìdùnnú àti àláfíà nlá, òdodo nlá, ìmọ̀ nlá. Ìsanpadà yín kìí ṣe ilé nlá kan ní ọ̀run àti àwọn òpópónà tí a fi góòlù ṣe. Yíò rọrùn fún Baba Ọ̀run láti fún yin ní gbogbo ohun tí Ó ní. Èrò Rẹ̀ ni láti ràn yín lọ́wọ́ láti dàbí gbogbo ohun ti Ó jẹ̀. Nítorínáà, àwọn ìfarajì yín nílò yín díẹ̀ síi nítorípé bẹ́ẹ̀ni Ọlọ́run ṣe nṣe yín dáraára síi.
Ó jẹ́ “ọ̀pọ̀ láti bèèrè lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kìí ṣe ẹnikẹ́ni”! Ẹ jẹ́ ọ̀dọ́ ogún-ìbí ọlọ́lá. Ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú yín pẹ̀lú Ọlọ́run àti Jésù Krístì jẹ́ ìbáṣepọ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé nínú èyí tí ẹ ní ààyè sí ìwọ̀n títóbi ti oore-ọ̀fẹ́ Wọn—Ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá Wọn, ẹ̀bùn agbára àtọrunwa, àti agbára ìlèṣe. Agbára yẹn kìí ṣe ìrònú ìfẹ́-inú oògùn oríire, tàbí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ araẹni lásán. Ó jẹ́ tòótọ́.
Bí ẹ ṣe nṣe àwọn ojúṣe ẹ̀tọ́ ìbí yín, ẹ kò dá wà rí. Olúwa Ọgbà àjàrà nbá yin ṣiṣẹ́. Ẹ nṣiṣẹ́ ní ọwọ́ nínú ọwọ́ pẹ̀lú Jésù Krístì. Pẹ̀lú májẹ̀mú titun kọ̀ọ̀kan—àti bí ìbáṣepọ̀ yín pẹ̀lú Rẹ̀ ṣe njinlẹ̀ síi—ẹ ndi ara yín mú ṣinṣin síi títí tí ẹ ó fi di ara yín papọ̀.. Nínú àmì mímọ́ ti oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ náà, ẹ̀yin yìó ri méjèèjì ìfẹ́-inú àti agbára láti gbé ní déédé bí Olùgbàlà ti gbé—ní ìyàtọ̀ sí ayé. Ẹ ti ní eleyi nítorí Jésù Krístì ti ní yín!
Nínú 2 Néfì 2:6 a kà pé, “Nítorí-èyi, ìràpadà nwá nínú àti nípasẹ̀ Messia Mímọ́ nã; nítorí ó kún fún õre-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.” Nítorí Ó kún fún òtítọ́, Ó rí yín bí ẹ ṣe rí gan-an—àwọn àbùkù, àwọn àìlágbára, àwọn àbámọ̀, àti gbogbo rẹ̀. Nítorí Ó kún fún oore ọ̀fẹ́, Ó rí yín bí ẹ ṣe lè rí. Ó pàdé yín níbití ẹ wà ó sì ṣèrànwọ́ fún yin láti ronúpìwàdà àti láti dára síi, kí ẹ borí kí ẹ sì dà.
“Áà ẹ̀yin ọ̀dọ́ ti ogún-ìbí ọlọ́lá náà, ẹ tẹ̀síwájú, ẹ tẹ̀síwájú, ẹ tẹ̀síwájú!” Mo jẹri pé a nifẹ yín—àti pé a gbẹ́kẹ̀lé yín—lónìí, ní ogun ọdún, àti títíláé. Ẹ máṣe ta ogún-ìbí yín fún ìpẹ̀tẹ̀ àsáró kan. Ẹ máṣe ṣòwò ohun gbogbo fún ohun lásán. Ẹ máṣe jẹ́ kí ayé yí yín padà nígbàtí a bíi yín láti yí ayé padà. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.