Àwọn Ìwé-mímọ́—Àwọn Ìpìlẹ̀ Ìgbàgbọ́
A kò lè rẹ-ìdíyelé ti pàtàkì àwọn ìwé mímọ́ sílẹ̀ nínú ìyípada àti ní dídúró nínú òtítọ́ inú ìhìnrere.
Ìyàwó mi, Màríà, àti èmí láìpẹ́ rí T-ṣẹ́ẹ̀tì pẹ̀lú àwọ̀rán ìwé kan àti ọ̀rọ̀ ní iwájú èyí tí ó kà pé, “Àwọn ìwé: Ojúlówó Ẹ̀rọ Ìdìmú.”
Mo ronú nípa ọ̀rọ̀ wíwuni yí àti bí àwọn ẹ̀rọ̀ àmúlọ́wọ́ ṣe jẹ́ pàtàkì lára gbogbo onírurú tí wọ́n ti dà. Lórí gbígbèrò síwájú síi, mo damọ̀ pé ẹ̀rọ eyikeyi tàbí àní ọ̀kan tí a dá pẹ̀lú ayédèrú òye kò lè jẹ́ pàtàkì tàbí kókó bí ìtọ́nisọ́nà ti-ẹ̀mí tí ó nwá látinú ìfihàn tọ̀run.
Bóyá àmúlọ́wọ́ tàbí oní-nọ́mbà, Bíbélì Mímọ́ àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Ẹ̀rí Míràn ti Jésù Krístì npèsè ìtọ́nisọ́nà ti-ẹ̀mí àti ìkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Jésù Krístì, Olùgbàlà aráyé. Àwọn ìwé wọ̀nyí ṣe pàtàkì sí wa fún ojúṣe ìjìnlẹ̀ ní ṣíṣe ákọsílẹ̀ ìdarí Ọlọ́run sí àwọn wòlíì àti àwọn ènìyàn àtijọ́ àti ìtọ́nisọ́nà tí wọ́n pèsè fún ìgbésí-ayé ti ara wa.
Ní àpapọ̀ pẹ̀lú ìkọ́ni àwọn wòlíì alààyè, àwọn ìwé-mímọ́ wọ̀nyí pèsè ìdarí ti-ẹ̀kọ́ fún wa ní ayé òní. Àwọn ìwé-mímọ́ wọ̀nyí jẹ́ alágbára jùlọ nígbàtí wọ́n bá fúnni ní ẹ̀kọ́, ìbáwí, ìtùnú, àti ṣíṣípẹ̀ fún àwọn olúkúlùkù àti ẹbí tí wọ́n nwá ìtọ̀nisọ́nà láti ọ̀dọ̀ Olúwa.
Àwọn ìwé-mímọ́, ní àpapọ̀ pẹ̀lú ìmísí ti-ẹ̀mí látọ́dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, tẹ̀síwájú láti jẹ́ kókó orísun tí ó nmú ìdẹrùn bá ìyípadà àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìrorà ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́ àti ìfẹ́-inú láti tẹ̀lé Jésù Krístì. Àwọn ìwé-mímọ́ ṣèrànwọ́ láti kọ́ ìpìlẹ̀ kan tí ó lè kojú ìtiraka ọ̀tá léraléra láti jin ìgbàgbọ́ lẹ́sẹ̀.
Olùyípadà titun ti bùkúnni wọ́n sì ti jẹ́ ìyè-ẹ̀jẹ̀ Ìjọ káàkiri àkọọ́lẹ̀ ìtàn rẹ̀. Àpẹrẹ kan nípàtàkì jẹ́ iyebíye sí mi. Nígbàtí mo jẹ́ ọ̀dọ́ bíṣọ́ọ̀pù, àwọn arábìnrin òjíṣẹ́ ìhìnrere ìyanu méjì nkọ ẹbí William Edward Mussman. Baba náà, agbẹjọ́rò tí ó lókun gidi, ni olùdámọ̀ràn gbogbogbò ti ilé-iṣẹ́ pàtàkì kan. Olùfọkànsìn ìyàwó rẹ̀, Janet, ni ó nṣèrànwọ́ fún àwọn ẹbí láti gbé ìgbésí-ayé bíi ti Krístì púpọ̀ sí i.
Ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn títayọ, àwọn méjèjì ní àṣẹ̀ṣẹ̀-bẹ̀rẹ̀ ogun ọdún wọn, ni à nkọ́ bákannáà. Gbogbo àwọn mẹ́rin náà ti gba àwọn ẹ̀kọ́ wọ́n sì nlọ sí ilé ìjọsìn. Arábìnrin àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere ti tẹnumọ´ kíka Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti gbígbàdúrà fún ẹ̀rí ti ìwé mímọ́ náà. Pẹ̀lú àmì, ẹbí náà fi tàdúrà-tàdúrà ka gbogbo Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní àkokò kúkurú.
Àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere, méjèjì tí wọ́n jẹ́ àwọn ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ṣíwájú, tẹ̀lé wọn lọ sí àwọn ìpàdé oúnjẹ Olúwa.
Bí ẹbí náà ti nsúnmọ́ ìrìbọmi, wọ́n gba àkójọ àwọn ìwé tí ó ṣe àtakò nípa Ìjọ. Èyí jẹ́ ṣíwájú Ayélujára, ṣùgbọ́n ohun-èlò náà kún àpótí káàdìbọ́ọ̀dì títóbi kan.
Arábìnrin òjíṣẹ́ ìhìnrere pè mi bí bíṣọ́ọ̀pù ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n tí a pè láìpẹ́ láti dáhùn àwọn ìbèèrè tí wọ́n gbé jáde. Nígbàtí a kórajọ nínú yàrá ìgbàlejò wọn, àpótí títóbi ti àwọn ìwé pẹlẹbẹ tí ó ṣe àtakò nípa Ìjọ wà ní àárín yàrá. Mo ti fi pẹ̀lú àdúrà débi ìyànsíṣẹ́ yí. Nínú àdúrà ìbẹ̀rẹ̀, Ẹ̀mí kùn sí mi létí pé, “Òun mọ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́ tẹ́lẹ̀.” Èyí ṣe pàtàkì! Àwọn arábìnrin gbàgbọ́ pé ìyókù ẹbí ti ní ẹ̀rí tẹ́lẹ̀. Wọn kò ní ìdánilójú nípa baba náà.
Mo wí fun un ní kíákíá pé Ẹ̀mí ti ṣímilétí pé òun ti ní ẹ̀rí tẹ́lẹ̀. “Ṣé ìyẹn jẹ́ òtítọ́?” Ó wò mí pẹ̀lu èrò-inú ó sì wípé Ẹ̀mi ti fi ẹsẹ̀ òtítọ́ múlẹ̀ nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti Ìjọ sí òun.
Nígbànáà mo bèèrè bóyá ó lè pọndandan láti ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà, bí wọ́n bá ti ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ti-ẹ̀mí tẹ́lẹ̀.
Baba fèsì pé kò ní pọndandan. Àwọn ìyókù ẹbí náà faramọ ìdáhùn rẹ̀.
Ó wípé òun ní ìbèèrè pàtàkì kan: Èrèdí kan tí wọ́n ti gbà àwọn ìwé gan an tí ó ntako Ìjọ ni pé àwọ́n ti jẹ́ ọmọ-ìjọ ti ìgbàgbọ́ míràn tẹ́lẹ̀. Ní àfikún, ó ti dá ẹ̀jẹ̀ nlá láti ṣèrànwọ́ láti kọ́ ilé-ìjọsìn titun fún ìgbàgbọ́ náà. Ó wí fún mi pé àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere arábìnrin ti kọ́ ọ nípa pàtàkì idamẹwa, èyí tí ó fi ìmoore tẹ́wọ́gbà, ṣùgbọ́n ó nròó bi yíò bá jẹ́ àṣìṣe láti bu-ọlá fún ẹ̀jẹ́ tí òun ti ṣe tẹ́lẹ̀ bákannáà. Mo mu dá a lójú pé ìsanwó ẹ̀jẹ́ náà yíò jẹ́ ọlọ́lá àti títọ́.
Gbogbo ẹbí ṣe ìrìbọmi. Ọdún kan lẹ́hìnnáà wọ́n ṣe èdìdi bí ẹbí ní Tẹ́mpìlì California Oakland. Mo ní ànfàní láti wà nijoko. Ọmọkùnrin náà parí ilé-ìwé amòfin, ó yege ìdánwò Báà California, àti pé ní kété ó sin míṣọ̀n òtítọ́ ní Japan. Mo ti wò ó ní àwọn ọdún sẹ́hìn bí àwọn ìràn tí ó ntẹ̀le ti dúró ní òtítọ́ sí ìhìnrere. Mo ní ànfàní láti ṣe ipò-iṣẹ́ níbi fífi èdìdi dì ti ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ọmọ náà.
Àwọn ìyípadà ti ó nṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wa jẹ́ ìdọ́gba alámì. Ní Oṣù Kẹfà tó kọjá, Akọ́ni-mọ̀ọ́gbá Andy Reid, olórí akọ́ni-mọ̀ọ́gbá bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ti àwọn Olóyè Ìlú Kansas, àti èmi, lẹgbẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n nṣojú ìgbàgbọ́ wa àti àwọn ìgbàgbọ́ míràn, sọ̀rọ̀ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀pọ̀-ìgbàgbọ́ ní Ìjọ Ẹ̀gbẹ́-odò ní Ìlú New York. Akọ́ni-mọ̀ọ́gbá Reid tẹnumọ́ àwọn àyè ẹ̀ẹ̀kejì àti fífèsí sí àwọn ìfipè àti ànfàní, èyí tí ó jẹ́ ohun gbogbo tí ìhìnrere Jésù Krístì wà nípa rẹ̀. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, pẹ̀lú àwọn ìyàwó wa, Tammy Reid àti Mary, a lọ sí ìpàdé oúnjẹ Olúwa ní Wọ́ọ̀dù Kejì ní Manhattan. Ó jẹ́ iṣẹ́-ìsìn ti-ẹ̀mí kan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùyípadà titun wà nínú ìjọ. Àwọn ọmọ-ìjọ marun tí a ṣe ìrìbọmi fún láìpẹ́, ọkùnrin mẹ́rin àti ọ̀dọ́mọkùnrin kan, wà ní àárín àwọn ọmọ Oyè-àlùfáà Árọ́nì tí wọ́n ngbé oúnjẹ Olúwa ká. Inú mi dùn láti ròhìn pé irú dídà-gììrì ti ọmọ-ìjọ titun bẹ́ẹ̀ ni ó nṣẹlẹ̀ káàkiri Ìjọ.
A fi ìmoore hàn fún àfiyèsí púpọ̀ nínú àwọn wọnnì tí wọ́n nfèsì sí àwọn ìfipè mímọ́, tí wọ́n nyí ìgbésí-ayé padà, tí wọ́n sì ntẹ́wọ́gba ànfàní láti tẹ̀lé Jésù Krístì. Wọ́n wọnú ipà-ọ̀nà májẹ̀mú nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, ìrònúpìwàdà, ìrìbọmi, àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ bí a ti kọ́ni nínú Bíbélì Mímọ́ àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì.
A kò lè rẹ-ìdíyelé ti pàtàkì àwọn ìwé mímọ́ sílẹ̀ nínú ìyípada àti ní dídúró nínú òtítọ́ inú ìhìnrere. Àwọn wòlíì tí a júwe nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì mọ̀ nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ Jésù Krístì wọ́n sì kọ́ni ní ìhìnrere Rẹ̀. Ìwé ti Mọ́mọ́nì nràn wá lọ́wọ́ láti fà súnmọ́ Ọlọ́run bí a ti nkẹkọ, ní ìmọ̀, tí a sì nlo àwọn ìkọ́ni rẹ̀. Wòlíì Joseph Smith kọ́ni pé, “ọkùnrin [tàbí obìnrin] kan yíò súnmọ́ Ọlọ́run si nípa gbígbé nípa àwọn èrò [ìwé náà] ju, nípa eyikeyi ìwé míràn lọ.”
Láti mọ̀ pé Ìwe ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a nílò láti kà á, jíròrò, kí a sì gbàdúrà nípa rẹ̀ àti nígbànáà kí a ṣe ìṣe gẹ́gẹ́bí àwọn èrò rẹ̀. Wòlíì Moroni ṣe ìlérí pé Ọlọ́run yíò fi òtítọ́ ìwé náà hàn sí wa bí a ti ngbàdúrà pẹ̀lú ọkàn òdodo, pẹ̀lú èrò òtítọ́, àti pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Krístì. Ṣíṣe àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ pàtàkì fún ìyípadà ìforítì.
Bí a ti ngbèrò ìbáṣepọ̀ ní àárín Bíbélì àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì bí ẹ̀rọ̀ àmúlọ́wọ́, ẹnìkan lè bèèrè ìbèèrè kan. Báwo ni ẹ ti rò wípé wíwúlò àti ìyìn ìwé méjì yíò ti jẹ́ bí Olúwa bá ti kéde pé wọn yíò jẹ́ dídara papọ̀ àti “dídi ọ̀kan ní ọwọ́ yín”? Èyí ni ohun tí Olúwa kéde nípa “igi ti Judah,” Bíbélì, àti “igi ti Joseph,” Ìwé ti Mọ́mọ́nì.
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà pàtàkì, Ìwe ti Mọ́mọ́nì npèsè ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí ó nmú gbòòrò tí ó sì nní ìgbéga lórí Bíbélì. Ẹ̀kọ́ ti Ètùtù Jésù Krístì ni àpẹrẹ ìjìnlẹ̀ kan.
Bíbélì npèsè àkọsílè pípé nípa iṣẹ́-ìránṣẹ́ ayé-ikú ti Jésù Krístì, pẹ̀lú ikú àti Àjínde Rẹ̀. Ìwé ti Mọ́mọ́nì ṣe kedere síi nípa Ètùtù Jésù Krístì, ohunkan tí àwọn wòlíì ṣe àlàyé ní kíkún ṣíwájú ikú Rẹ̀.
Àkórí sí Alma orí 42 fi ẹ̀kọ́ pàtàkì ti Ètùtù Jésù Krístì hàn.
Ó kà pé: “Ipò ara ìdibàjẹ́ jẹ́ ìgbà ìdánwò tí ó fún ènìyàn ní ànfãní láti ronúpìwàdà àti láti sin Ọlọ́run—Ìṣubú nnì mú ikú ti ara àti ti ẹ̀mí wá sí órí ọmọ aráyé—Ìràpadà wá nípa ìrònúpìwàdà—Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni ó ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ayé—ãnú jẹ́ tí àwọn tí ó ronúpìwàdà—Gbogbo àwọn tí ó kù wà lábẹ́ àìṣègbè Ọlọ́run—Àánú wá nítorí Ètùtù nã—Àwọn tí nwọn bá ronúpìwàdà nítõtọ́ nìkan ni a ó gbàlà.”
Ààrẹ Russell M. Nelson ti wípé: “Mo ṣe ìlérí pé bí ẹ ṣe nfi pẹ̀lú àdúrà ṣe àṣarò Ìwé ti Mọ́mọ́nì lójoojúmọ́, ẹ ó ṣe àwọn ìpinnu dídára si—lójoojúmọ́.” Mo ṣe ìlérí bákannáà pé bí “ẹ ṣe nri ara yín sínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì lójoojúmọ́, ẹ ó lè ní àjẹsára ní ìdojúkọ àwọn ibi ọjọ́ òní.”
Bí mo ti mẹnubà, mo ní ìwúrí pẹ̀lú èrò-orí ti ojúlówó ẹ̀rọ àmúlọ́wọ́—ìwé kan. Bákannáà, mo mọ ìjọlójú pàtàkì ti Ayélujára nínú ayé òní. Ẹ̀rọ ìgbàlódé àmúlọ́wọ́ kan lè pèsè ìwífúnni tí a ti ṣe àkọọ́lẹ̀-ìtàn rẹ̀ tí ó kún kókó ilé-ìkàwé kan. A fi ìmoore hàn láti gbé ní irú àkokò bí èyí. Èmi ní pàtàkì fi ìmoore hàn pé ó fi àyè gba àwọn ìwé mímọ́ àti ohun-èlò Ìjọ láti wà ní àrọ́wọ́tó ní oní-nọ́mbà. Ayélujára ni ohun-èlò alágbára fún ṣíṣe àṣàrò ìhìnrere. Ní òní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn npín ìwé mímọ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ nípa lílo ẹ̀rọ-ìgbàlódé. Áàpù Ìwé ti Mọ́mọ́nì, fún àpẹrẹ, ni ọ̀nà ìyanu láti ṣe ìfihàn àwọn ọ̀rẹ́ sí Ìwé ti Mọ́mọ́nì kí ẹ sì lè pin ní àwọn ọ̀nà déédé àti àdánidá nibikíbi ti ẹ lè wà.
Nígbàtí ayélujára bá npèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbùkún, ní àìdára, bíiti àwọn ìwé-pẹlẹbẹ kíkọ tí ó ṣe àtakò nípa Ìjọ tí mo júwe ṣíwájú, a ti lò ó bákannáà láti dá iyèméjì sílẹ̀ kí a sì rẹ ìgbàgbọ́ sílẹ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere iyebíye. Ó lè jẹ́ ara ti “àwọn ibi ti ọjọ́” tí Ààrẹ Nelson mẹ́nubà.
Ọ̀tá àti àwọn wọnnì tí wọ́n nràn án lọ́wọ́, ní mímọ̀ àti ní àìmọ̀ọ́mọ̀, ti ṣe ìdásílẹ̀ ìdọ́gba ti àpótí kíkún fún ohun-èlò kíkọ tó tako Ìjọ lórí Ayélujára bí mo ti júwe ṣíwájú, ní ìgbìrò láti fà yín kúrò nínú òtítọ́ Ọlọ́run.
Àwọn ọ̀ràn tí a sọ láti dá iyèméjì sílẹ̀ ní àwọn ọdún sẹ́hìn ti jẹ́ alámì irúkannáà. Èyí jẹ́ pàtàkì ní òtítọ́ nígbàtí ẹ bá ṣe àfiwé ọjọ́ wa pẹ̀lú 1960, nígbàtí mo wà nínu ogun ọdún ó lé.
Àwọn ìwé mímọ́ kọ́ wa láti lo dídálẹ́jọ́ kí a sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú ohun gbogbo. Ayélujára ni a lè lò ní ọ̀nà dídára tàbí ọ̀nà ìparun.
Méjèjì àwọn ọmọ-ìjọ tipẹ́tipẹ́ àti àwọn wọnnì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ nṣe àṣàrò ìhìnrere nílò láti jẹ́ alámọ̀ọ̀mọ́ ṣe nípa ohun tí wọn nwò. Ẹ máṣe gba ohun-èlò àìmọ́, àìní-òótọ́, tàbí àìṣòdodo. Bí ẹ bá ṣeé, ètò-ìsirò alúgọ́rídímù lè darí yín lọ sílẹ̀ sí ipa tí ó npa ìgbàgbọ́ run tí yíò sì pa ìlọsíwájú ayérayé yín lára. Ẹ lè ṣe ìṣe lórí dídára tàbí àìdára. Ẹ wá òdodo kí ẹ sì yẹra fún ihò òkété dúdú Ayélujára àti ìyíkiri-ìparun. Ẹ kún inú ayé yín pẹ̀lú ohun dídára, àwọn èrò òdodo, ẹ jẹ́ aláyọ̀, kí ẹ si ní ìgbádùn ṣùgbọ́n ẹ yẹra fún ìwà-àìlọ́gbọ́n. Ìyàtọ̀ kan wa. Nkan Nkan ìgbàgbọ́ kẹtàlá ni àtọ́nisọ́nà ìyanu. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ri arayín mọ́ inú Ìwé ti Mọ́mọ́nì déédé, èyí tí yíò fá Ẹ̀mí wá sínú ayé yín yíò sì ràn yín lọ́wọ́ láti ní ìwòye òtítọ́ kúrò nínú àṣìṣe.
Àmọ̀ràn mi fún àwọn wọnnì tí wọ́n ti yàkúrò ní ọ̀nàkọnà ní ipa-ọ̀nà májẹ̀mú ni pé kí wọ́n pada sí àwọn ìwé mímọ́, ìtọ́nisọ́nà ti-wòlíì, ìṣàkíyèsí ẹ̀sìn ní ilé, àti orin ìgbàgbọ́. Gbogbo ẹ̀mí ni ó jẹ́ iyebíye sí Olúwa. A nílò yín! Olúwa nílò yín, ẹ sì nílò Rẹ̀! A ó kíi yín káàbọ̀ nígbàgbogbo. Nínú àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún iṣẹ́-ìsìn Ìjọ mo ti ṣìkẹ́ àwọn ènìyàn ìyanu tí wọ́n padà sí ipa-ọ̀nà májẹ̀mú àti nígbànáà tí wọ́n sì sìn tí wọ́n sì bùkún gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn tàbí pẹ̀lú ẹnití wọ́n bá pàdé.
Àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn wòlíì alààyè jẹ́ kókó ọ̀nà ìfẹ́ni kan tí Baba Ọ̀run fi nmú ètò ìdùnnú Rẹ̀ wà ní àrọ́wọ́tó fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀.
Mo jẹ́ ẹ̀rí mi tó dájú nípa àtọ̀runwá Jésù Krístì àti òdodò Ètùtù Rẹ̀, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.