Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2024 Abala Òwúrọ̀ Sátidé Abala Òwúrọ̀ SátidéAbala òwúrọ̀ Sátidé ti Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Ìkẹrìnléláàdọ́wá Ìlàjì-ọlọ́dọdún ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí a ṣe ní Ọjọ́ ikarun sí ìkẹfà Oṣù Kẹwa, 2024. Henry B. EyringÌmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò Neil L. AndersenÌṣẹ́gun ti ÌrètíAlàgbà Andersen kọ́ni pé nígbàtí a bá ní ìrètí nínú Krístì tí a sì fi ìgbẹ́kẹ̀lé wa sínú Rẹ̀, a ó ní ìmọ̀lára àláfíà Rẹ̀. Emily Belle FreemanEmily Belle Freeman Karl D. HirstÀyànfẹ́ Ọlọ́runAlàgbà Hirst kọ́ wa bí a ó ṣe ní ìmọ̀lára ìfẹ́ àtọ̀runwá ti Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì. Dale G. Renlund“Èyí Ni Ìhìnrere Mi”—“Èyí Ni Ìjọ Mi”Alàgbà Renlund kọ́ni pé àpapọ̀ ìnìnrere Olùgbàlà àti Ìjọ Olùgbàlà yíò fún wa ní àyè sí agbára Ọlọ́run yíò sì ràn wá lọ́wọ́ láti di mímọ́. David P. HomerGbígbẹ́kẹ̀lé Baba waAlàgbà Homer kọ́ni pé à ngba ìbùkún nígbàtí a bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run tí a sì ntẹ̀lé àwọn òfin Rẹ̀. Gregorio E. CasillasỌlọ́run Fẹ́ràn Gbogbo Àwọn Ọmọ Rẹ̀Alàgbà Casillas kọ́ni pé a lè bùkún ìgbésí-ayé àwọn ọmọ Ọlọ́run nípasẹ̀ iṣẹ́-ìránṣẹ́ àti jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn. Dallin H. OaksTítẹ̀lé KrístìÀàrẹ Oaks kọ́ni ní pàtàkì ti títẹ̀lé àwọn òfin Jésù Krístì, pẹ̀lú àtẹnumọ́ lórí òfin Rẹ̀ láti yẹra fún ìjà. Abala Ọ̀sán Ọjọ́ Sátidé Abala Ọ̀sán Ọjọ́ SátidéAbala Ọ̀sán Sátidé ti Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Ìkẹ́rìnléláàdọ́wá Ìlàjì-ọlọ́dọdún ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí a ṣe ní Ọjọ́ ìkarun sí ìkẹfà Oṣù Kẹwa, 2024. D. Todd ChristoffersonRíri àwọn Ohun Ìjà-ogun ti Ọ̀tẹ̀ Wa Mọ́lẹ̀Alàgbà Christofferson gbà wá níyànjú láti ri eyikeyi ohun-èlò ọ̀tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní ìlòdì sí Ọlọ́run nínú ayé wa, bóyá ó jẹ́ ṣíṣe àìgbọ́ran pẹ̀lú ìtàra sí àwọn òfin Rẹ̀ tàbí fi sùúrù pa ifẹ́ Rẹ̀ tì. José A. TeixeiraSísopọ̀ Mọ́ Jésù Krístì: Dídi Iyọ̀ AyéAlàgbà Teixeira kọ́ni ní àwọn ọ̀nà ìrọ̀rùn mẹ́rin ṣùgbọ́n jíjìnlẹ̀ tí a lè dúró ní rírọ̀mọ́ sí Jésù Krístì. Juan Pablo VillarỌwọ́ Rẹ̀ Ṣetán Láti Rànwá Lọ́wọ́Alàgbà Villar kọ́ni pé Olùgbàlà wà níbẹ̀ láti rànwálọ́wọ́ láti borí eyikeyi ìpènijà bí a bá ní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ nígbàgbogbo. Patrick KearonẸ Káàbọ̀ sí Ìjọ Ayọ̀ náàAlàgbà Kearon kọ́ni nípa ayọ̀ náà tí a le rí ninu Ìjọ ti Jésù Krístì. David L. Buckner“Ẹ̀yin Ni Ọ̀rẹ́ Mi”Alàgbà Buckner kọ́ni pe a gbọ́dọ̀ dáwọ́dúró ní wíwò fún àwọn ìdí láti pínyà, kí a sì lépa àwọn ànfààní láti “jẹ́ ọ̀kan.” D. Martin GouryJẹ́ Mímọ́Alàgbà Goury kọ́ni pé ìrònúpìwàdà ojojúmọ́ nràn wá lọ́wọ́ láti ni ìfura síi àti láti ṣísílẹ̀ sí ìtọ́nisọ́nà Olúwa àti àwọn ìṣílétí Ẹ̀mí Mímọ́. Aroldo B. CavalcanteAfẹ́fẹ́ Kìí Dáwọ́dúró Ní Fífẹ́ LáéláéAlàgbà Cavalcante kọ́ni pé Ọlọ́run lè ṣe ìmúdúró wa nípasẹ̀ àwọn àdánwò wa àti pé a lè ran ara wa lọ́wọ́ lórí ìrìnàjò ti-ẹ̀mí wa bákannáà. Ulisses SoaresFífi Ìfẹ́ Wa Sí Ìbámu pẹ̀lú Tirẹ̀Alàgbà Soares kọ́ni pé ìdánwò ìgbẹ̀hìn ti jíjẹ́-ọmọlẹ́hìn wa ni a rí nínú ìfẹ́ wa láti já ara wa àtijọ́ gbà kí a sì fi ọkàn wa sílẹ̀ àti gbogbo ẹ̀mí wa sí Ọlọ́run kí ìfẹ́ Rẹ̀ ó di tiwa. Abala Ìrọ̀lẹ́ Sátidé Abala Ìrọ̀lẹ́ SátidéAbala Ọ̀sán Sátidé ti Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Ìkejìléláàdọ́wá Ìlàjì-ọlọ́dọdún ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí a ṣe ní Ọjọ́ ikarun sí ìkẹfà Oṣù Kẹwa, 2024. Gerrit W. GongÌwàmímọ́ sí Olúwa nínú Ìgbésí-ayé Ojojúmọ́Alàgbà Gong pè wá láti mú ìwàmímọ́ jẹ́ ìgbésí ayé ojojúmọ́ wa, èyí tí yíò fà wá súnmọ́ Olúwa àti ara wa. Kristin M. YeeAyọ̀ Ìràpadà Wa.Arabinrin Yee kọ́ni pé nípasẹ̀ àjọṣe májẹ̀mú wa pẹ̀lú Ọlọ́run, a lè ráyè sí ìwẹ̀nùmọ́, ìwòsàn, àti agbára ìràpadà Jésù Krístì. Kyle S. McKayỌkùnrin Náà Tí Ó Bá Jèhófàh Sọ̀rọ̀Alàgbà McKay fúnni ni ẹ̀rí rẹ̀ nípa ìgbésí ayé ati ogún nlá ti Wòlíì Joseph Smith. Jorge M. AlvaradoGba Ẹ̀bùn Ìrònúpìwàdà Olúwa Mọ́raAlàgbà Alvarado kọ́ni nípa ìrònúpìwàdà ó sì jẹ́rìí sí ìwòsàn tí ó wà fún gbogbo ènìyàn nípasẹ̀ agbára ìràpadà Jésù Krístì. David A. BednarNínú Àlàfo tí Kìí Ṣe Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ỌdúnAlàgbà Bednar lo òwe ti Àwọn Ará Néfì ati Àwọn Ara Lámánì ninu Ìwé ti Mọ́mọ́nì láti kìlọ̀ tako jíjẹ́ kí ìgbéraga ó dá wa padà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa. Abala Òwúrọ̀ Ọjọ́-ìsinmi Abala Òwúrọ̀ Ọjọ́-ìsinmiAbala Òwúrọ̀ Ọjọ́-ìsinmi ti Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Ìkẹ́rinléláàdọ́wá Ìlàjì-ọlọ́dọdún ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí a ṣe ní Ọjọ́ ikarun sí ìkẹfà Oṣù Kẹwa, 2024. Jeffrey R. Holland“Èmi Nìyí”Ààrẹ Holland kọ́ni nípa ìgbọràn pípé ti Krístì sí Baba Rẹ̀ àti ìfẹ́ nlá Rẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa. Tracy Y. BrowningWíwá Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Tẹ̀míArábìnrin Browning kọ́ni pé Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí bí a ṣe nbéèrè àwọn ìbéèrè àtọkànwá, tí à npa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, tí a sì fi ìgbẹ́kẹ̀lé wa sínú Rẹ̀. Brook P. HalesAyé-ikú Nṣiṣẹ́Alàgbà Hales kọ́ni pé nítorí i`hìnrere Jésù Krístì àti ètò ìgbàlà, ayé ikú nṣiṣẹ́! L. Todd BudgeWá A Pẹ̀lú Gbogbo Ọkàn RẹBíṣọ́pù Budge sọ̀rọ̀ nípa pàtàkì ti àkokò ìdákẹ́jẹ́ láti jọ́sìn àti bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Gary E. StevensonÀwọn Ọjọ́ Tí A Kò Lè Gbàgbé LáéAlàgbà Stevenson wo ọjọ́ iwájú sí ọdún mẹwa tó nbọ̀ bí ànfàní `ìlèròtẹ́lẹ̀ láti pín ìròhìn ayọ̀ ti ìhìnrere Jésù Krístì pẹ̀lú ayé. Bradley R. WilcoxÁà Ẹ̀yin Ọ̀dọ́ ti Ogún-ìbí Ọlọ́láSísọ̀rọ̀ sí àwọn ọ̀dọ́, Arákùnrin Wilcox yanjú ìbèèrè náà, Kínìdí tí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn fi ngbé ní yíyàtọ̀ sí àwọn míràn? Henry B. EyringÌrọ̀rùn Ni Ẹ̀kọ́ Jésù KrístìÀàrẹ Eyring gbà wá níyànjú kí a kàn kọ́ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ Jésù Krístì Nígbànáà àwọn olólùfẹ́ wa yíò rántí rẹ̀ nígbàtí àwọn àdánwò bá wá, a ó sì di alábùkún. Abala Ọ̀sán Ọjọ́-ìsinmi Abala Ọ̀sán Ọjọ́-ìsinmiAbala Ọ̀sán Ọjọ́-ìsinmi ti Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Ìkẹrìnléláàdọ́wá Ìlàjì-ọlọ́dọdún ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí a ṣe ní Ọjọ́ ikarun sí ìkẹfà Oṣù Kẹwa, 2024. Dieter F. UchtdorfẸ Tọ́jú Àwọn Gbòngbò, Àwọn Ẹ̀ka Yío sì DàgbàAlàgbà Uchtdorf kọ́ni pé àwọn ẹ̀ka ẹ̀rí wa yíò dàgbà bí a ti nṣìkẹ́ àwọn gbòngbò náà: ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti Baba wa Ọ̀run. Takashi WadaÀwọn Ọ̀rọ̀ Krístì àti Ẹ̀mí Mímọ́ Yío Darí Wa Sí Òtítọ́ NáàAlàgbà Wada kọ́ni bí ṣíṣe àpèjẹ lori awọn ọ̀rọ̀ Krístì ati fífetísílẹ̀ sí Ẹ̀mí yio ṣe darí wa sí ìyè ayérayé. Ronald A. Rasband“Ẹ Kíyèsi Èmi Ni Ìmọ́lẹ̀ Èyí Tí Ẹ̀yin Ó Máa Gbé Sókè”Alàgba Rasband kọ́ni nípa ṣíṣe ìmúdúró wòlíì alààyè nípa títẹ̀lé àwọn ìkọ́ni àti apẹrẹ rẹ̀. Quentin L. CookÀwọn Ìwé-mímọ́—Àwọn Ìpìlẹ̀ Ìgbàgbọ́Àwọn Alàgbà cook kọ́ni nípa pàtàkì àwọn ìwé mímọ́, pàápàá Ìwé ti Mọ́mọ́nì, nínú ìyípadà tó nlọ lọ́wọ́. Rubén V. AlliaudÀwọn Ọmọkùnrin àti Ọmọbìnrin Ọlọ́runAlàgbà Alliaud kọ́ni pé gbogbo wa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run gangan. I. Raymond EgboDojúkọ Jésù Krístì àti Ìhìnrere Rẹ̀Alàgbà Egbo kọ́ni pé nígbàtí a bá dojúkọ Jésù Krístì àti Ìhìnrere Rẹ̀, a lè ní ìmọ̀lára ayọ̀ ní ìgbà àwọn àdánwò àti ìpènijà. Russell M. NelsonOlúwa Jésù Krístì Yíò Wá Lẹ́ẹ̀kansiÀàrẹ Nelson kọ́ni pé ìsisìyí ni àkokò láti mú Jésù Krístì jẹ́ ìpìlẹ̀ ìgbésí ayé wa kí a sì múrasílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Rẹ̀.