Gba Ẹ̀bùn Ìrònúpìwàdà Olúwa Mọ́ra
Ẹ máṣe jẹ́kí a dúró kí nkan le koko kí a tó yí sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ẹ máṣe jẹ́kí a dúró de òpin ayé-ikú wa kí a tó ronúpìwàdà.
Mo jẹ́ ẹ̀rí nípa olùfẹ́ni Baba Ọ̀run. Nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ti Oṣù Kẹrin ọdún 2019, àwọn àkókò díẹ̀ lẹ́hìn ìmúdúró mi nínú ojúṣe titun mi bí Aláṣẹ Gbogbogbo Àádọ́rin, àwọn akọrin kọ orin kan ti “Mo dúró Ní Gbogbo Ìyanu” tí ó wọnú ọkàn àti ẹ̀mí mi gan.
Bí mo ṣe gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nnì, ó jẹ́ gbogbo ìyàlẹ́nu mi. Mo nímọ̀lára pé láìka àwọn àìpé àti àbùkù mi sí, Olúwa bùkún mi láti mọ̀ pé “nínú agbára Rẹ̀ mo lè ṣe ohun gbogbo.”
Ìmọ̀lára tí ó wọ́pọ̀ ti àìpe, àìlera, tàbí páàpáà àìyẹ jẹ́ nkan èyítí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa nfigbàkan tiraka pẹ̀lú. Mo sì tún nja ìjàkadì pẹ̀lú èyí; Mo nímọ̀lára rẹ̀ lọ́jọ́ tí a pè mí. Mo ti nímọ̀lára rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, àti pé mo ṣì nímọ̀lára pé ó nbá yín sọ̀rọ̀ báyíi. Síbẹ̀síbẹ̀, Mo ti kẹkọọ pé èmi kò dá wà pẹ̀lú àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí. Ní pàtó, ọ̀pọ̀ ìtàn ló wà nínú àwọn ìwé mímọ́ nípa àwọn tó dà bíi pé wọ́n ní irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀. Fún àpẹrẹ, a rántí Néfì gẹ́gẹ́bí olóòótọ́ àti akíkanjú ìránṣẹ́ Olúwa. Nígbà míìràn, ó tilẹ̀ nbá ìmọ̀lára àìyẹ, àìlera, àti àìpé jà.
Ó wípé: “Bi o ti wu ki o ri laisi oore nla Oluwa, ni fifi awọn iṣẹ nla ati iyanu rẹ han mi, ọkan mi kigbe pe: Áà ọkùnrin òṣì tí mo jẹ́! Bẹ̃ni, ọkàn mi kún fún ìbànújẹ́ nítorí ti ẹran ara mi; ẹ̀mí mi kẹ́dùn nítorí ti àìṣedẽdé mi.”
Ó sọ̀rọ̀ nípa níní ìmọ̀lára “ìdálẹ́bi,” ní ìgbà èwe rẹ̀, “nítorí àìlera [rẹ̀] àti àwọn àìpé.” Ṣùgbọ́n àwọn ìmọ̀lára àìpé àti àníyàn Jósẹ́fù jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó mú kí ó ronú jinlẹ̀, wádì, kẹ́kọ̀ọ́, àti gbàdúrà. Bí ẹ ti lè rántí, ó lọ láti gbàdúrà nínú igbó-súrú-onígi tí ó wà nítòsí ilé rẹ̀ láti rí òtítọ́, àlàáfíà, àti ìdáríjì. Ó gbọ́ tí Olúwa wí fún un pé: “Joseph, ọmọ mi, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́. Máa lọ ní ọ̀nà rẹ, rìn nínú àwọn ìlànà mi, kí o sì pa àwọn òfin mi mọ́. Kíyèsíi, èmi ni Olúwa ògo. A kàn mí mọ́ igi fún aráyé, pé gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú orúkọ mi le ní ìyè ayérayé.”
Ìfẹ́ àtọkànwá Jósẹ́fù láti ronúpìwàdà kí ó sì wá ìgbàlà ọkàn rẹ̀ ràn án lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ Jésù Kristi kí ó sì gba ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ìtẹ̀síwájú ìgbìyànjú yíì ṣílẹ̀kùn sí lílọsíwájú ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere tí Jésù Krístì.
Ìrírí yíyanilẹ́nu ti Wòlíì Joseph Smith yìí ṣàkàwé bí àwọn ìmọ̀lára àìlera àti àìpé ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ irú ẹ̀dá síṣubú wa. Wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ìgbẹ́kẹ̀lé wa lórí Jésù Krístì, àti bí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù, wọ́n lè ru ọkàn wa sókè ní ìfẹ́-ọkàn tòótọ́ láti yíjú sí Olùgbàlà pẹ̀lú èrò kíkún kí a sì ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.
Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ìrònúpìwàdà jẹ́ ayọ̀! Ìrònúpíwádá dídùn lé jẹ́ apákan ti ètò ojojúmọ́ nípasẹ̀ èyítì, “ẹsẹ lórí ẹsẹ, ìlànà lóri ìlànà,” Olúwa nkọ́ wa láti gbé ìgbésí-ayé tí ó wà ní gbùngbùn àwọn ẹ̀kọ́ Rẹ̀. Bíi ti Jósẹ́fù àti Néfì, a lè “sọkún sí [Ọlọ́run] fún àánú; nítorí ó lágbára láti gbàlà.” Ó lè mú gbogbo ìfẹ́-inú òdodo ṣẹ ó sì lè wo èyíkéyi ọgbẹ́ sàn nínú ìgbésí ayé wa.
Nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Májẹ̀mú mìíràn ti Jésù Krístì, ìwọ àti èmi lè rí àìlóǹkà àkọsílẹ̀ ti àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n kọ́ bí wọ́n ṣe lè wá sọ́dọ̀ Krístì nípa ìrònúpìwàdà àtọkànwá.
Èmi yíò fẹ́ láti ṣàbápín pẹ̀lú rẹ àwọn àánú Olúwa nípasẹ̀ ìrírí kan tí ó ṣẹlẹ̀ ní àyànfẹ́ erékùsù ilé mi ti Puerto Rico.
Ní ìlú mi Ponce, tí arábìnrin kan nínú Ìjọ, Celia Cruz, pinnu pé òun yíò fi Ìwé ti Mọ́mọ́nì fún ọ̀rẹ́ òun kan. Ó dì í ó sì lọ fi ẹ̀bùn yí jíṣẹ́, ó ṣe iyebíye síi ju òkúta iyebíye jùlọ tàbí àwọn iyùn lọ. Ní ọ̀nà rẹ̀, olè kan tọ̀ ọ́ wá, ó já àpamọ́wọ́ rẹ̀ gbà, ó sì sá lọ pẹ̀lú àkànṣe ẹ̀bùn inú rẹ̀.
Nígbàtí ó sọ ìtàn yí ní ilé ìjọsìn, ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ pé, “Tani ó mọ̀? Bóyá èyí ni ànfàní rẹ láti pín ihìnrere!”
Ó dára, ọjọ́ díẹ̀ lẹ́hìnnáà, ṣé ẹ mọ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀? Célia gba lẹ́tà kan. Mo di lẹ́tà náà mú, èyí tí Célia ṣe àbápín pẹ̀lú mi, nínú ọwọ́ mi loni. Ni ó sọ:
Ìyáàfin. Cruz:
Dáríjì mí, Dáríjì mí. Ìwọ kì yíò mọ bí mo ti kẹ́dùn tó fún ìkọlù rẹ. Ṣùgbọ́n nítorí rẹ̀, ìgbésí-ayé mi ti yípada àti pé yóò tẹ̀síwájú.
Ìwé náà [Ìwé ti Mọ́mọ́nì] ti ràn mí lọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé mi. Àlá ènìyàn Ọlọ́run náà ti mì mí. Mò ndá dọ́llàr márun rẹ padà, nítorí nkò lè ná wọn. Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé ó dàbí ẹnipé ó ní ìmọ́lẹ̀ ní àyíká rẹ. Ìmọ́lẹ̀ náà dàbí ẹnipé ó dá mi dúró [láti ṣe ìpalára fún ọ, nítorínáà] mo sálọ dípò rẹ̀.
Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé ìwọ ó tún padà rí mi, ṣùgbọ́n nígbàtí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ kò ní dá mi mọ̀, nítorí èmi yío jẹ́ arákùnrin rẹ. … Níhin, níbití mò ngbé, mo ní láti wá Olúwa kí nsì lọ sí ilé ìjọsìn tí ìwọ nlọ.
Ìfiránṣẹ́ tí o kọ sínú ìwé náà mú omijé wá sí ójú mi. Láti alẹ́ Ọjọ́rú èmi kò tíì le dá kíkà rẹ̀ dúró. Mo ti gbàdúrà mo sì ti bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run láti dáríjì mí, [àti pé] mo bèèrè lọ̀wọ̀ rẹ láti dáríjì mí. … Mo rò wípé ẹ̀bùn rẹ tí a dì jẹ́ nkàn tí mo lè tà. [Dípò bẹ́ẹ̀,] ó ti jẹ́ kí nfẹ́ láti yí ìgbésí ayé mi padà. Dáríjì mí, dáríjì mí, mo bẹ̀ ọ́.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ìmọ́lẹ̀ Olùgbàlà lè dé ọ̀dọ̀ gbogbo wa, láìka ipò wa sí. “Kò ṣe é ṣe fún ọ láti rẹ ara rẹ sílẹ̀ ju bí ìmọ́lẹ̀ àìlópin ti Ètùtù Krístì tí tàn lọ,” ni Ààrẹ Holland wí.
Ní ti olùgbà ẹ̀bùn Célia láìròtẹ́lẹ̀, Ìwé ti Mọ́mọ́nì, arákùnrin yìí tẹ̀ síwájú láti jẹ́rìí púpọ̀ sí i nípa àánú Olúwa. Bótilẹ̀jẹ́pé ó gba àkókò kí arákùnrin yìí tó lè dáríji ara rẹ̀, ó rí ayọ̀ ninú ìronúpìwàdà. Ohun ìyanu lèyì! Arábìrin olódodo kan, ìwé ti Mọ́mọ́nì kan, ìrònúpíwàdà òdodo, àti agbára Olùgbàlà yọrísí ìgbádùn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ìbùkún ti ìhìnrere àti àwọn májẹ̀mú mímọ́ nínu ilé Olúwa. Àwọn ọmọ ìdílé míràn tẹ̀lé wọn wọ́n sì gba àwọn ojúṣe mímọ́ nínú ọgbà àjàrà Olúwa, pẹ̀lú iṣẹ́ ìsìn ìhìnrere ìgbà kíkún.
Bí a ṣe nwá sọ́dọ̀ Jésù Krístì, ipa ọ̀nà ìrònúpìwàdà àtọkànwá wa yíò tọ́ wa lọ sí tẹ́mpìlì mímọ́ ti Olùgbàlà níkẹìn.
Iró èrò òdodo láti tiraka láti jẹ́ mímọ́—láti yẹ fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ìbùkún ti Baba wa Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀ mú kó ṣeéṣe nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú mímọ́ tẹ́mpìlì! Sísìn déédé nínú ilé Olúwa àti títiraka láti pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ tí a ṣe níbẹ̀ mọ́ yíò ṣe àlékún ìfẹ́-inu wa àti agbára wa láti ní ìrírí ìyípadà ọkàn, agbára, iyè-inu, àti ẹ̀mí tó ṣe dandan fún wa láti dàbí Olùgbàlà wá síi. Ààrẹ Russell M. Nelson ti jẹ́rìí pé, “Kò sí ohun tí yóò ṣí ọ̀run sílẹ̀ ju [jíjọ́sìn nínú tẹ́mpìlì lọ]. Kò sí nkànkan!”
Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, njẹ́ ẹ nímọ̀lára àìpé bí? Njẹ́ ẹ ní ìmọ̀lára àìyẹ bi? Ṣé ò nṣàtúnrò-èkejì araàrẹ bí? Bóyá o lè máa ṣàníyàn kí o sì bèèré pé: Njẹ́ mo kójú-òṣùnwọ̀n bí? Ṣé ó ti pẹ́ jù fún mi? Kíni ìdí tí mo fi nkùnà nígbàtí mò ngbìyànjú mi dídára jùlọ?
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìrin, dájúdájú aó ṣe àwọn àṣìṣe ní ìgbésí ayé wa lójú ọ̀nà. Ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ẹ rántí pé, bí Alàgbà Gong ti kọ́ni, “Ètùtù ti Olùgbàlà wa jẹ́ àìlópin àti ayérayé. Olúkúlukú wa nṣìnà a sì nkùnà. A lè, fún àkókò kan, pàdánù ọ̀nà wa. Ọlọ́run fi tìfẹ́tìfẹ́ mú un dá wa lójú [pé] ibi yòówù kí a wà tàbí ohun tí a ti ṣe, kò sí ojú-àmì kankan tí kìí padà. Ó ndúró ní ṣíṣetán láti gbà wá mọ́ra.”
Gẹ́gẹ́bí ìyàwó mi ọ̀wọ́n, Cari Lu, ti kọ́ mi pẹ̀lú, gbogbo wa ní láti ronúpìwàdà, padà sẹ́yìn, kí a sì tún àkókò náà padà sí “òdo wákàtí” ní gbogbo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.
Àwọn ìdíwọ́ yíò wa. Àwọn ìpèníjà yíò wá, ṣùgbọ́n ẹ máṣe jẹ́kí a dúró kí nkan le koko kí a tó yíjú sí Ọlọ́run. Ẹ máṣe jẹ́kí a dúró de òpin ayé-ikú wa kí a tó ronúpìwàdà lótítọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a dojúkọ̀ agbára Jésù Krístì àti ìfẹ́ Bàbá Ọ̀run fún wa láti padà sọ́dọ̀ Rẹ̀ nísisìyí, láìka apákan èyìkéyi ipa ọ̀nà májẹ̀mú tí a wà lórí rẹ̀ sí.
Ilé Olúwa, àwọn ìwé mímọ́ Rẹ̀, àwọn wòlíì mímọ́ Rẹ̀ àti àwọn àpóstélì nmísí wa láti tiraka síwájú ìwà mímọ́ ti ara-ẹni nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ ti Krístì.
Néfì sì wípé: “Àti nísisìyí, kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èyí ni ọ̀nà nã; kò sì sí ọ̀nà míràn tàbí orúkọ tí a fi fún ni lábẹ́ ọ̀run nípa èyí tí a lè fi gba ènìyàn là ní ìjọba Ọlọ́run. Àti nísisìyí, kíyèsĩ i, èyí ni ẹ̀kọ́ ti Krístì, àti ẹ̀kọ́ kanṣoṣo àti òtítọ́ ti Baba, àti ti Ọmọ, àti ti Ẹ̀mí Mímọ́.”
Ìlànà wa ti “è-tù-tù” pẹ̀lú Ọlọ́run lè jẹ́ pípeni-níjà. Ìwọ àti Èmi lè dákẹ́, dúró jẹ́ẹ́, bojú wo Olùgbàlà, láti ṣèwádíi àti ṣàwárí lóri kíni Ó fẹ́ kí àwa yípadà. Ti a bá ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àníyàn kíkún, àwa yíò jẹ́ri ìwòsàn náà. A ó sì ronú nípa bí àwọn ìran wa yíò ṣe rí ìbùkún gbà bí a ṣe ngba ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà Olúwa mọ́ra!
Ọ̀gá Amọ̀kòkò, tí baba mi kọ́ni, yíò mọ wá yíò sì tún wa ṣe, èyí tí ó lè ṣòro. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọ̀gá Olùwòsàn yíò wẹ̀ wá mọ́ bákannáà. Tìkáraàmi, mo ti ní ìrírí mo sì tẹ̀síwájú láti máa ní ìrírí agbára ìwòsàn nnì. Ó nwá nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti ìrònúpìwàdà ojoójúmọ́.
Mo jẹ́rìí sí ìfẹ́ Ọlọrun Baba Ayérayé àti ti agbára àìlópin ti Ètùtù Ọmọ Rẹ̀. A lè nímọ̀lára rẹ̀ jinlẹ̀ bí a bá ṣe nronúpìwàdà lótitọ́ àti tọkàntọkàn.
Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, mo jẹ́ ẹlẹ́rìí Ìmúpadàbọ̀sípò ológo ti ìhìnrere nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith àti ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá lọ́wọ́lọ́wọ́ ti Olùgbàlà nípasẹ̀ wòlíì Rẹ̀, Ààrẹ Russell M. Nelson. Mo mọ̀ pé Jésù Krístì nbẹ láàyè Òun sì ni Ọ̀gá Olùwòsàn ti ẹ̀mí wa. Mo fi tọkàntọkàn jẹ́rìí pé òtítọ́ ni nkan wọ̀nyí, ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.